quranm◉

Ojúewé 112

Range
from 5:24 to 5:31
Surahs covered
Ìtumọ̀
8 Ìtumọ̀

◉

5:24

قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِنَّا لَن نَّدۡخُلَهَآ أَبَدٗا مَّا دَامُواْ فِيهَا فَٱذۡهَبۡ أَنتَ وَرَبُّكَ فَقَٰتِلَآ إِنَّا هَٰهُنَا قَٰعِدُونَ ﴿24﴾

Wọ́n wí pé: “Ìwọ Mūsā, dájúdájú àwa kò níí wọ inú ìlú náà láéláé níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá sì wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, kí ìwọ àti Olúwa rẹ lọ (síbẹ̀). Kí ẹ̀yin méjèèjì jà wọ́n lógun. Dájúdájú ibí yìí ni àwa yóò jókòó sí ná.”

5:25

قَالَ رَبِّ إِنِّي لَآ أَمۡلِكُ إِلَّا نَفۡسِي وَأَخِيۖ فَٱفۡرُقۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡفَٰسِقِينَ ﴿25﴾

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú èmi kò ní ìkápá lórí ẹnì kan bí kò ṣe (lórí) ara mi àti arákùnrin mi. Nítorí náà, ya àwa àti ìjọ òbìlẹ̀jẹ́ sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”1

5:26

قَالَ فَإِنَّهَا مُحَرَّمَةٌ عَلَيۡهِمۡۛ أَرۡبَعِينَ سَنَةٗۛ يَتِيهُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ فَلَا تَأۡسَ عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡفَٰسِقِينَ ﴿26﴾

(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú ó ti di èèwọ̀ fún wọn (láti wọnú ìlú náà) fún ogójì ọdún tí wọn yóò fi rin àrìnnù lórí ilẹ̀. Nítorí náà, má ṣe banújẹ́ nítorí ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”1

5:27

وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ ٱبۡنَيۡ ءَادَمَ بِٱلۡحَقِّ إِذۡ قَرَّبَا قُرۡبَانٗا فَتُقُبِّلَ مِنۡ أَحَدِهِمَا وَلَمۡ يُتَقَبَّلۡ مِنَ ٱلۡأٓخَرِ قَالَ لَأَقۡتُلَنَّكَۖ قَالَ إِنَّمَا يَتَقَبَّلُ ٱللَّهُ مِنَ ٱلۡمُتَّقِينَ ﴿27﴾

Ka ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ (Ànábì) Ādam méjèèjì fún wọn pẹ̀lú òdodo. (Rántí) nígbà tí àwọn méjèèjì ṣe ọrẹ àsè (láti fi súnmọ́ Allāhu). A gba ti ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì, A kò sì gba ti ìkejì. (Ẹni tí A kò gba tirẹ̀) wí pé: “Dájúdájú èmi yóò pa ọ́.” (Ìkejì) sì sọ pé: “(Ọrẹ àsè) tàwọn olùbẹ̀rù nìkan ni Allāhu máa gbà.

5:28

لَئِنۢ بَسَطتَ إِلَيَّ يَدَكَ لِتَقۡتُلَنِي مَآ أَنَا۠ بِبَاسِطٖ يَدِيَ إِلَيۡكَ لِأَقۡتُلَكَۖ إِنِّيٓ أَخَافُ ٱللَّهَ رَبَّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿28﴾

Dájúdájú tí o bá na ọwọ́ rẹ sí mi láti pa mí, èmi kò sì níí na ọwọ́ mi sí ọ láti pa ọ́, nítorí pé dájúdáju èmi ń bẹ̀rù Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

5:29

إِنِّيٓ أُرِيدُ أَن تَبُوٓأَ بِإِثۡمِي وَإِثۡمِكَ فَتَكُونَ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلنَّارِۚ وَذَٰلِكَ جَزَـٰٓؤُاْ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿29﴾

Dájúdájú èmi fẹ́ kí o padà (sí ọ̀dọ̀ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde) pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ (bí ó ṣe pa) mí àti ẹ̀ṣẹ̀ tìrẹ nítorí kí o lè jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn èrò inú Iná. Ìyẹn sì ni ẹ̀san àwọn alábòsí.”

5:30

فَطَوَّعَتۡ لَهُۥ نَفۡسُهُۥ قَتۡلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُۥ فَأَصۡبَحَ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿30﴾

Ó mú ọkàn ara rẹ̀ gírí láti pa arákùnrin rẹ̀. Ó pa á. Ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ẹni òfò.

5:31

فَبَعَثَ ٱللَّهُ غُرَابٗا يَبۡحَثُ فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيُرِيَهُۥ كَيۡفَ يُوَٰرِي سَوۡءَةَ أَخِيهِۚ قَالَ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ أَعَجَزۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِثۡلَ هَٰذَا ٱلۡغُرَابِ فَأُوَٰرِيَ سَوۡءَةَ أَخِيۖ فَأَصۡبَحَ مِنَ ٱلنَّـٰدِمِينَ ﴿31﴾

Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde, tí ó ń fi ẹsẹ̀ walẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkúarákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmí bá mi o! Ṣé mo kágara ni láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí èmi náà sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀?” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.