quranm◉

Ojúewé 147

Range
from 6:143 to 6:146
Surahs covered
Ìtumọ̀
4 Ìtumọ̀

◉

6:143

ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۖ مِّنَ ٱلضَّأۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡمَعۡزِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ نَبِّـُٔونِي بِعِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿143﴾

(Allāhu dá ẹran) mẹ́jọ ní takọ- tabo; méjì nínú àgùtàn (takọ-tabo), méjì nínú ewúrẹ́ (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Ẹ fún mi ní ìró pẹ̀lú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

6:144

وَمِنَ ٱلۡإِبِلِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ أَمۡ كُنتُمۡ شُهَدَآءَ إِذۡ وَصَّىٰكُمُ ٱللَّهُ بِهَٰذَاۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا لِّيُضِلَّ ٱلنَّاسَ بِغَيۡرِ عِلۡمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿144﴾

Méjì nínú ràkúnmí (takọ-tabo) àti méjì nínú màálù (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Tàbí ṣé ẹ̀yin wà níbẹ̀ nígbà tí Allāhu pa yín láṣẹ èyí ni?” Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí tó tún tayọ ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

6:145

قُل لَّآ أَجِدُ فِي مَآ أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٖ يَطۡعَمُهُۥٓ إِلَّآ أَن يَكُونَ مَيۡتَةً أَوۡ دَمٗا مَّسۡفُوحًا أَوۡ لَحۡمَ خِنزِيرٖ فَإِنَّهُۥ رِجۡسٌ أَوۡ فِسۡقًا أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿145﴾

Sọ pé: “Èmi kò rí nínú ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran (yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà) tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú pípe orúkọ mìíràn lé e lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Nítorí náà, ẹni tí ìnira (ebi) bá mú, yàtọ̀ sí ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà,2 dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.3

6:146

وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٖۖ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ وَٱلۡغَنَمِ حَرَّمۡنَا عَلَيۡهِمۡ شُحُومَهُمَآ إِلَّا مَا حَمَلَتۡ ظُهُورُهُمَآ أَوِ ٱلۡحَوَايَآ أَوۡ مَا ٱخۡتَلَطَ بِعَظۡمٖۚ ذَٰلِكَ جَزَيۡنَٰهُم بِبَغۡيِهِمۡۖ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ ﴿146﴾

A ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi gbogbo ẹran tó ní èékánná tàbí pátákò tó ṣùpọ̀ mọ́ra wọn. Nínú ẹran màálù àti àgùtàn, A tún ṣe ọ̀rá àwọn méjèèjì ní èèwọ̀ fún wọn àfi èyí tí ó bá lẹ̀mọ́ ẹ̀yìn wọn tàbí ìfun tàbí èyí tí ó bá yípọ̀ mọ́ eegun. Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Dájúdájú Àwa sì ni Olódodo.