quranm◉

Ojúewé 15

Range
from 2:94 to 2:101
Surahs covered
Ìtumọ̀
8 Ìtumọ̀

◉

2:94

قُلۡ إِن كَانَتۡ لَكُمُ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ ٱللَّهِ خَالِصَةٗ مِّن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿94﴾

Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé tiyín nìkan ni Ilé Ìkẹ́yìn tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu, tí kò sì níí jẹ́ ti àwọn ènìyàn (mìíràn), ẹ tọrọ ikú, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

2:95

وَلَن يَتَمَنَّوۡهُ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿95﴾

Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.

2:96

وَلَتَجِدَنَّهُمۡ أَحۡرَصَ ٱلنَّاسِ عَلَىٰ حَيَوٰةٖ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمۡ لَوۡ يُعَمَّرُ أَلۡفَ سَنَةٖ وَمَا هُوَ بِمُزَحۡزِحِهِۦ مِنَ ٱلۡعَذَابِ أَن يُعَمَّرَۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ ﴿96﴾

Dájúdájú o máa rí wọn pé àwọn ni ènìyàn tó l’ójú kòkòrò jùlọ nípa ìṣẹ̀mí ayé, (wọ́n tún l’ójú kòkòrò ju) àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ. Ìkọ̀ọ̀kan wọn ń fẹ́ pé tí A bá lè fún òun ní ẹgbẹ̀rún ọdún lò láyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kì í ṣe ohun tí ó máa là á nínú ìyà ni pé, kí Á fún un ní ìṣẹ̀mí gígùn lò. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:97

قُلۡ مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّـجِبۡرِيلَ فَإِنَّهُۥ نَزَّلَهُۥ عَلَىٰ قَلۡبِكَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿97﴾

Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,(ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

2:98

مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّلَّهِ وَمَلَـٰٓئِكَتِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَجِبۡرِيلَ وَمِيكَىٰلَ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَدُوّٞ لِّلۡكَٰفِرِينَ ﴿98﴾

Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, mọlāika Jibrīl àti mọlāika Mīkāl, dájúdájú Allāhu ni ọ̀tá fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

2:99

وَلَقَدۡ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖۖ وَمَا يَكۡفُرُ بِهَآ إِلَّا ٱلۡفَٰسِقُونَ ﴿99﴾

Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ọ. Ẹnì kan kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ àyàfi àwọn arúfin.

2:100

أَوَكُلَّمَا عَٰهَدُواْ عَهۡدٗا نَّبَذَهُۥ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿100﴾

Àti pé ṣé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dá májẹ̀mu kan ni apá kan nínú wọn yóò máa jù ú nù? Rárá, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gan-an ni kò gbàgbọ́.

2:101

وَلَمَّا جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ نَبَذَ فَرِيقٞ مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَرَآءَ ظُهُورِهِمۡ كَأَنَّهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿101﴾

Àti pé nígbà tí Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu dé bá wọn, tí ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú ohun tó wà pẹ̀lú wọn, apá kan nínú àwọn tí A fún ní Tírà gbé Tírà Allāhu jù s’ẹ́yìn lẹ́yìn wọn bí ẹni pé wọn kò mọ̀ (pé àsọọ́lẹ̀ nípa Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà nínú rẹ̀)!