quranm◉

Ojúewé 219

Range
from 10:89 to 10:97
Surahs covered
Ìtumọ̀
9 Ìtumọ̀

◉

10:89

قَالَ قَدۡ أُجِيبَت دَّعۡوَتُكُمَا فَٱسۡتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَآنِّ سَبِيلَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿89﴾

(Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀.”

10:90

وَجَٰوَزۡنَا بِبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱلۡبَحۡرَ فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ وَجُنُودُهُۥ بَغۡيٗا وَعَدۡوًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَدۡرَكَهُ ٱلۡغَرَقُ قَالَ ءَامَنتُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱلَّذِيٓ ءَامَنَتۡ بِهِۦ بَنُوٓاْ إِسۡرَـٰٓءِيلَ وَأَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ﴿90﴾

A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami òkun já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti ìlara àti ìtayọ ẹnu-ààlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”1

10:91

ءَآلۡـَٰٔنَ وَقَدۡ عَصَيۡتَ قَبۡلُ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴿91﴾

Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́?

10:92

فَٱلۡيَوۡمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنۡ خَلۡفَكَ ءَايَةٗۚ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ عَنۡ ءَايَٰتِنَا لَغَٰفِلُونَ ﴿92﴾

Nítorí náà, ní òní ni A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa.

10:93

وَلَقَدۡ بَوَّأۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ مُبَوَّأَ صِدۡقٖ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ فَمَا ٱخۡتَلَفُواْ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ﴿93﴾

A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé dáadáa. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa-ẹnu (lórí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn.Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

10:94

فَإِن كُنتَ فِي شَكّٖ مِّمَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ فَسۡـَٔلِ ٱلَّذِينَ يَقۡرَءُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكَۚ لَقَدۡ جَآءَكَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ﴿94﴾

Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú at-Taorāt àti al-’Injīl), bi àwọn tó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò.Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

10:95

وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَتَكُونَ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿95﴾

O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò.

10:96

إِنَّ ٱلَّذِينَ حَقَّتۡ عَلَيۡهِمۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿96﴾

Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́,

10:97

وَلَوۡ جَآءَتۡهُمۡ كُلُّ ءَايَةٍ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ﴿97﴾

gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.1