quranm◉

Surah Al-Baqarah transliteration

◉ Súrá · ∞

2:1

الٓمٓ ﴿1﴾

Transliteration: Aliflammeem

Translation: ’Alif lām mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

2:2

ذَٰلِكَ ٱلۡكِتَٰبُ لَا رَيۡبَۛ فِيهِۛ هُدٗى لِّلۡمُتَّقِينَ ﴿2﴾

Transliteration: Thalika alkitabu la rayba feehi hudan lilmuttaqeena

Translation: Tírà yìí, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Ìmọ̀nà ni fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

2:3

ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡغَيۡبِ وَيُقِيمُونَ ٱلصَّلَوٰةَ وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ ﴿3﴾

Transliteration: Allatheena yuminoona bialghaybi wayuqeemoona alssalata wamimma razaqnahum yunfiqoona

Translation: (Àwọn olùbẹ̀rù Allāhu ni:) àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ìkọ̀kọ̀àti àwọn tó ń kírun àti àwọn tó ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn,

2:4

وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡكَ وَمَآ أُنزِلَ مِن قَبۡلِكَ وَبِٱلۡأٓخِرَةِ هُمۡ يُوقِنُونَ ﴿4﴾

Transliteration: Waallatheena yuminoona bima onzila ilayka wama onzila min qablika wabialakhirati hum yooqinoona

Translation: àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ àti ohun tí A sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú rẹàti àwọn tó ní àmọ̀dájú nípa Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.2

2:5

أُوْلَـٰٓئِكَ عَلَىٰ هُدٗى مِّن رَّبِّهِمۡۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ ﴿5﴾

Transliteration: Olaika AAala hudan min rabbihim waolaika humu almuflihoona

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn wà lórí ìmọ̀nà láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè.

2:6

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ سَوَآءٌ عَلَيۡهِمۡ ءَأَنذَرۡتَهُمۡ أَمۡ لَمۡ تُنذِرۡهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿6﴾

Transliteration: Inna allatheena kafaroo sawaon AAalayhim aanthartahum am lam tunthirhum la yuminoona

Translation: Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, bákan náà ni fún wọn, yálà o kìlọ̀ fún wọn tàbí o kò kìlọ̀ fún wọn, wọn kò níí gbàgbọ́.1

2:7

خَتَمَ ٱللَّهُ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ وَعَلَىٰ سَمۡعِهِمۡۖ وَعَلَىٰٓ أَبۡصَٰرِهِمۡ غِشَٰوَةٞۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ عَظِيمٞ ﴿7﴾

Transliteration: Khatama Allahu AAala quloobihim waAAala samAAihim waAAala absarihim ghishawatun walahum AAathabun AAatheemun

Translation: Allāhu fi èdídí dí ọkàn wọn àti ìgbọ́rọ̀ wọn. Èbìbò sì bo ìríran wọn. Ìyà ńlá sì wà fún wọn.

2:8

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَبِٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَمَا هُم بِمُؤۡمِنِينَ ﴿8﴾

Transliteration: Wamina alnnasi man yaqoolu amanna biAllahi wabialyawmi alakhiri wama hum bimumineena

Translation: Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” Wọn kì í sì ṣe onígbàgbọ́ òdodo.

2:9

يُخَٰدِعُونَ ٱللَّهَ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَمَا يَخۡدَعُونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡ وَمَا يَشۡعُرُونَ ﴿9﴾

Transliteration: YukhadiAAoona Allaha waallatheena amanoo wama yakhdaAAoona illa anfusahum wama yashAAuroona

Translation: Wọ́n ń tan Allāhu àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Wọn kò sì tan ẹnì kan bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.

2:10

فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ فَزَادَهُمُ ٱللَّهُ مَرَضٗاۖ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡذِبُونَ ﴿10﴾

Transliteration: Fee quloobihim maradun fazadahumu Allahu maradan walahum AAathabun aleemun bima kanoo yakthiboona

Translation: Àrùn kan wà nínú ọkàn wọn nítorí náà Allāhu ṣe àlékún àrùn fún wọn.2 Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn nítorí pé wọ́n ń parọ́.

2:11

وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ لَا تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ قَالُوٓاْ إِنَّمَا نَحۡنُ مُصۡلِحُونَ ﴿11﴾

Transliteration: Waitha qeela lahum la tufsidoo fee alardi qaloo innama nahnu muslihoona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Àwa kúkú ni alátùn-únṣe.”

2:12

أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلۡمُفۡسِدُونَ وَلَٰكِن لَّا يَشۡعُرُونَ ﴿12﴾

Transliteration: Ala innahum humu almufsidoona walakin la yashAAuroona

Translation: Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òbìlẹ̀jẹ́, ṣùgbọ́n wọn kò fura.

2:13

وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ ءَامِنُواْ كَمَآ ءَامَنَ ٱلنَّاسُ قَالُوٓاْ أَنُؤۡمِنُ كَمَآ ءَامَنَ ٱلسُّفَهَآءُۗ أَلَآ إِنَّهُمۡ هُمُ ٱلسُّفَهَآءُ وَلَٰكِن لَّا يَعۡلَمُونَ ﴿13﴾

Transliteration: Waitha qeela lahum aminoo kama amana alnnasu qaloo anuminu kama amana alssufahao ala innahum humu alssufahao walakin la yaAAlamoona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ ní òdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe gbàgbọ́.” Wọ́n á wí pé: “Ṣé kí á gbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn òmùgọ̀ ṣe gbàgbọ́ ni?” Ẹ kíyè sí i! Dájúdájú àwọn gan-an ni òmùgọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.

2:14

وَإِذَا لَقُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَوۡاْ إِلَىٰ شَيَٰطِينِهِمۡ قَالُوٓاْ إِنَّا مَعَكُمۡ إِنَّمَا نَحۡنُ مُسۡتَهۡزِءُونَ ﴿14﴾

Transliteration: Waitha laqoo allatheena amanoo qaloo amanna waitha khalaw ila shayateenihim qaloo inna maAAakum innama nahnu mustahzioona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì kù wọ́n ku àwọn (ẹni) èṣù wọn, wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwa ń bẹ pẹ̀lú yín, àwa kàn ń ṣe yẹ̀yẹ́ ni.”

2:15

ٱللَّهُ يَسۡتَهۡزِئُ بِهِمۡ وَيَمُدُّهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ﴿15﴾

Transliteration: Allahu yastahzio bihim wayamudduhum fee tughyanihim yaAAmahoona

Translation: Allāhu máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Ó sì máa mú wọn lékún sí i nínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.1

2:16

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلضَّلَٰلَةَ بِٱلۡهُدَىٰ فَمَا رَبِحَت تِّجَٰرَتُهُمۡ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ ﴿16﴾

Transliteration: Olaika allatheena ishtarawoo alddalalata bialhuda fama rabihat tijaratuhum wama kanoo muhtadeena

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà.Nítorí náà, òkòwò wọn kò lérè, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.

2:17

مَثَلُهُمۡ كَمَثَلِ ٱلَّذِي ٱسۡتَوۡقَدَ نَارٗا فَلَمَّآ أَضَآءَتۡ مَا حَوۡلَهُۥ ذَهَبَ ٱللَّهُ بِنُورِهِمۡ وَتَرَكَهُمۡ فِي ظُلُمَٰتٖ لَّا يُبۡصِرُونَ ﴿17﴾

Transliteration: Mathaluhum kamathali allathee istawqada naran falamma adaat ma hawlahu thahaba Allahu binoorihim watarakahum fee thulumatin la yubsiroona

Translation: Àpèjúwe wọn dà bí àpèjúwe ẹni tí ó tan iná, ṣùgbọ́n nígbà tí ìmọ́lẹ̀ tàn sí àyíká rẹ̀ tán, Allāhu mú ìmọ́lẹ̀ wọn lọ, Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àwọn òkùnkùn; wọn kò sì ríran mọ́.

2:18

صُمُّۢ بُكۡمٌ عُمۡيٞ فَهُمۡ لَا يَرۡجِعُونَ ﴿18﴾

Transliteration: Summun bukmun AAumyun fahum la yarjiAAoona

Translation: Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; nítorí náà wọn kò níí ṣẹ́rí padà.

2:19

أَوۡ كَصَيِّبٖ مِّنَ ٱلسَّمَآءِ فِيهِ ظُلُمَٰتٞ وَرَعۡدٞ وَبَرۡقٞ يَجۡعَلُونَ أَصَٰبِعَهُمۡ فِيٓ ءَاذَانِهِم مِّنَ ٱلصَّوَٰعِقِ حَذَرَ ٱلۡمَوۡتِۚ وَٱللَّهُ مُحِيطُۢ بِٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿19﴾

Transliteration: Aw kasayyibin mina alssamai feehi thulumatun waraAAdun wabarqun yajAAaloona asabiAAahum fee athanihim mina alssawaAAiqi hathara almawti waAllahu muheetun bialkafireena

Translation: Tàbí (àpèjúwe wọn) dà bí òjò ńlá tí ń rọ̀ láti sánmọ̀. Ó mú àwọn òkùnkùn, àrá sísán àti mọ̀nàmọ́ná lọ́wọ́. Wọ́n ń fi ìka wọn sínú etí wọn nítorí àwọn iná láti ojú sánmọ̀ fún ìbẹ̀rù ikú. Allāhu sì yí àwọn aláìgbàgbọ́ ká.

2:20

يَكَادُ ٱلۡبَرۡقُ يَخۡطَفُ أَبۡصَٰرَهُمۡۖ كُلَّمَآ أَضَآءَ لَهُم مَّشَوۡاْ فِيهِ وَإِذَآ أَظۡلَمَ عَلَيۡهِمۡ قَامُواْۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَذَهَبَ بِسَمۡعِهِمۡ وَأَبۡصَٰرِهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿20﴾

Transliteration: Yakadu albarqu yakhtafu absarahum kullama adaa lahum mashaw feehi waitha athlama AAalayhim qamoo walaw shaa Allahu lathahaba bisamAAihim waabsarihim inna Allaha AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Mọ̀nàmọ́ná náà fẹ́ẹ̀ mú ìríran wọn lọ. Ìgbàkígbà tí ó bá tan ìmọ́lẹ̀ sí wọn, wọ́n á rìn lọ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá sì ṣóòòkùn mọ́ wọn, wọ́n á dúró si. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá gba ìgbọ́rọ̀ wọn àti ìríran wọn. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

2:21

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ ٱعۡبُدُواْ رَبَّكُمُ ٱلَّذِي خَلَقَكُمۡ وَٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿21﴾

Transliteration: Ya ayyuha alnnasu oAAbudoo rabbakumu allathee khalaqakum waallatheena min qablikum laAAallakum tattaqoona

Translation: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jọ́sìn fún Olúwa yín, Ẹni tí Ó dá ẹ̀yin àti àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè ṣọ́ra (fún ìyà Iná).1

2:22

ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ فِرَٰشٗا وَٱلسَّمَآءَ بِنَآءٗ وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجَ بِهِۦ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ رِزۡقٗا لَّكُمۡۖ فَلَا تَجۡعَلُواْ لِلَّهِ أَندَادٗا وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿22﴾

Transliteration: Allathee jaAAala lakumu alarda firashan waalssamaa binaan waanzala mina alssamai maan faakhraja bihi mina alththamarati rizqan lakum fala tajAAaloo lillahi andadan waantum taAAlamoona

Translation: (Ẹ jọ́sìn fún) Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ fún yín ní ìtẹ́, (Ó ṣe) sánmọ̀ ní àjà (le yín lórí), Ó sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ (fún yín), Ó sì fi mú àwọn èso jáde ní ìjẹ-ìmu fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣe bá Allāhu wá akẹgbẹ́, ẹ sì mọ̀ (pé kò ní akẹgbẹ́).

2:23

وَإِن كُنتُمۡ فِي رَيۡبٖ مِّمَّا نَزَّلۡنَا عَلَىٰ عَبۡدِنَا فَأۡتُواْ بِسُورَةٖ مِّن مِّثۡلِهِۦ وَٱدۡعُواْ شُهَدَآءَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿23﴾

Transliteration: Wain kuntum fee raybin mimma nazzalna AAala AAabdina fatoo bisooratin min mithlihi waodAAoo shuhadaakum min dooni Allahi in kuntum sadiqeena

Translation: Tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ohun tí A sọ̀kalẹ̀ fún ẹrúsìn Wa, nítorí náà, ẹ mú sūrah kan wá bí irú rẹ̀, kí ẹ sì pe àwọn ẹlẹ́rìí yín, yàtọ̀ sí Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

2:24

فَإِن لَّمۡ تَفۡعَلُواْ وَلَن تَفۡعَلُواْ فَٱتَّقُواْ ٱلنَّارَ ٱلَّتِي وَقُودُهَا ٱلنَّاسُ وَٱلۡحِجَارَةُۖ أُعِدَّتۡ لِلۡكَٰفِرِينَ ﴿24﴾

Transliteration: Fain lam tafAAaloo walan tafAAaloo faittaqoo alnnara allatee waqooduha alnnasu waalhijaratu oAAiddat lilkafireena

Translation: Tí ẹ kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ kò wulẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra fún Iná, èyí tí ìkoná rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn àti òkúta tí wọ́n pa lésè sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

2:25

وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ كُلَّمَا رُزِقُواْ مِنۡهَا مِن ثَمَرَةٖ رِّزۡقٗا قَالُواْ هَٰذَا ٱلَّذِي رُزِقۡنَا مِن قَبۡلُۖ وَأُتُواْ بِهِۦ مُتَشَٰبِهٗاۖ وَلَهُمۡ فِيهَآ أَزۡوَٰجٞ مُّطَهَّرَةٞۖ وَهُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿25﴾

Transliteration: Wabashshiri allatheena amanoo waAAamiloo alssalihati anna lahum jannatin tajree min tahtiha alanharu kullama ruziqoo minha min thamaratin rizqan qaloo hatha allathee ruziqna min qablu waotoo bihi mutashabihan walahum feeha azwajun mutahharatun wahum feeha khalidoona

Translation: Fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé, dájúdájú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan ń bẹ fún wọn, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ìgbàkígbà tí A bá p’èsè jíjẹ-mímu kan fún wọn nínú èso rẹ̀, wọn yóò sọ pé: “Èyí ni wọ́n ti pèsè fún wa tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” - Wọ́n mú un wá fún wọn ní ìrísí kan náà ni (àmọ́ pẹ̀lú adùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀). - Àwọn ìyàwó mímọ́ sì ń bẹ fún wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:26

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَسۡتَحۡيِۦٓ أَن يَضۡرِبَ مَثَلٗا مَّا بَعُوضَةٗ فَمَا فَوۡقَهَاۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فَيَعۡلَمُونَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡۖ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَيَقُولُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلٗاۘ يُضِلُّ بِهِۦ كَثِيرٗا وَيَهۡدِي بِهِۦ كَثِيرٗاۚ وَمَا يُضِلُّ بِهِۦٓ إِلَّا ٱلۡفَٰسِقِينَ ﴿26﴾

Transliteration: Inna Allaha la yastahyee an yadriba mathalan ma baAAoodatan fama fawqaha faamma allatheena amanoo fayaAAlamoona annahu alhaqqu min rabbihim waamma allatheena kafaroo fayaqooloona matha arada Allahu bihatha mathalan yudillu bihi katheeran wayahdee bihi katheeran wama yudillu bihi illa alfasiqeena

Translation: Dájúdájú Allāhu kò níí tijú láti fí ohun kan (tí ó mọ) bí ẹ̀fọn tàbí ohun tí ó jù ú lọ ṣàkàwé ọ̀rọ̀. Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò wí pé: “Kí ni ohun tí Allāhu gbàlérò pẹ̀lú àkàwé yìí?” Allāhu ń fi ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Ó sì ń fi tọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sọ́nà. Kò sì níí fi ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àyàfi àwọn arúfin.1

2:27

ٱلَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهۡدَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مِيثَٰقِهِۦ وَيَقۡطَعُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ ﴿27﴾

Transliteration: Allatheena yanqudoona AAahda Allahi min baAAdi meethaqihi wayaqtaAAoona ma amara Allahu bihi an yoosala wayufsidoona fee alardi olaika humu alkhasiroona

Translation: (Àwọn arúfin náà ni) àwọn tó ń yẹ májẹ̀mu Allāhu lẹ́yìn tí májẹ̀mu náà ti fìdí múlẹ̀, wọ́n tún ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

2:28

كَيۡفَ تَكۡفُرُونَ بِٱللَّهِ وَكُنتُمۡ أَمۡوَٰتٗا فَأَحۡيَٰكُمۡۖ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿28﴾

Transliteration: Kayfa takfuroona biAllahi wakuntum amwatan faahyakum thumma yumeetukum thumma yuhyeekum thumma ilayhi turjaAAoona

Translation: Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.1

2:29

هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ لَكُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَسَوَّىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖۚ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿29﴾

Transliteration: Huwa allathee khalaqa lakum ma fee alardi jameeAAan thumma istawa ila alssamai fasawwahunna sabAAa samawatin wahuwa bikulli shayin AAaleemun

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun tó wà lórí ilẹ̀ fún yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó wà l’ókè sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.1

2:30

وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي جَاعِلٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ خَلِيفَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَجۡعَلُ فِيهَا مَن يُفۡسِدُ فِيهَا وَيَسۡفِكُ ٱلدِّمَآءَ وَنَحۡنُ نُسَبِّحُ بِحَمۡدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَۖ قَالَ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿30﴾

Transliteration: Waith qala rabbuka lilmalaikati innee jaAAilun fee alardi khaleefatan qaloo atajAAalu feeha man yufsidu feeha wayasfiku alddimaa wanahnu nusabbihu bihamdika wanuqaddisu laka qala innee aAAlamu ma la taAAlamoona

Translation: (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.”Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Ọ. A óò máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọ sẹ́!” Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

2:31

وَعَلَّمَ ءَادَمَ ٱلۡأَسۡمَآءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمۡ عَلَى ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ فَقَالَ أَنۢبِـُٔونِي بِأَسۡمَآءِ هَـٰٓؤُلَآءِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿31﴾

Transliteration: WaAAallama adama alasmaa kullaha thumma AAaradahum AAala almalaikati faqala anbioonee biasmai haolai in kuntum sadiqeena

Translation: Allāhu fi gbogbo àwọn orúkọ náà mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ ìwọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

2:32

قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ لَا عِلۡمَ لَنَآ إِلَّا مَا عَلَّمۡتَنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿32﴾

Transliteration: Qaloo subhanaka la AAilma lana illa ma AAallamtana innaka anta alAAaleemu alhakeemu

Translation: Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

2:33

قَالَ يَـٰٓـَٔادَمُ أَنۢبِئۡهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡۖ فَلَمَّآ أَنۢبَأَهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَأَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ ﴿33﴾

Transliteration: Qala ya adamu anbihum biasmaihim falamma anbaahum biasmaihim qala alam aqul lakum innee aAAlamu ghayba alssamawati waalardi waaAAlamu ma tubdoona wama kuntum taktumoona

Translation: Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”

2:34

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿34﴾

Transliteration: Waith qulna lilmalaikati osjudoo liadama fasajadoo illa ibleesa aba waistakbara wakana mina alkafireena

Translation: (Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.”Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs.2 Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

2:35

وَقُلۡنَا يَـٰٓـَٔادَمُ ٱسۡكُنۡ أَنتَ وَزَوۡجُكَ ٱلۡجَنَّةَ وَكُلَا مِنۡهَا رَغَدًا حَيۡثُ شِئۡتُمَا وَلَا تَقۡرَبَا هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿35﴾

Transliteration: Waqulna ya adamu oskun anta wazawjuka aljannata wakula minha raghadan haythu shituma wala taqraba hathihi alshshajarata fatakoona mina alththalimeena

Translation: A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”1

2:36

فَأَزَلَّهُمَا ٱلشَّيۡطَٰنُ عَنۡهَا فَأَخۡرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِۖ وَقُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ وَلَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُسۡتَقَرّٞ وَمَتَٰعٌ إِلَىٰ حِينٖ ﴿36﴾

Transliteration: Faazallahuma alshshaytanu AAanha faakhrajahuma mimma kana feehi waqulna ihbitoo baAAdukum libaAAdin AAaduwwun walakum fee alardi mustaqarrun wamataAAun ila heenin

Translation: Lẹ́yìn náà, Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: “Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fún yín lórí ilẹ̀ títí di ìgbà kan.”

2:37

فَتَلَقَّىٰٓ ءَادَمُ مِن رَّبِّهِۦ كَلِمَٰتٖ فَتَابَ عَلَيۡهِۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿37﴾

Transliteration: Fatalaqqa adamu min rabbihi kalimatin fataba AAalayhi innahu huwa alttawwabu alrraheemu

Translation: Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:38

قُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ مِنۡهَا جَمِيعٗاۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿38﴾

Transliteration: Qulna ihbitoo minha jameeAAan faimma yatiyannakum minnee hudan faman tabiAAa hudaya fala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: A sọ pé “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

2:39

وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿39﴾

Transliteration: Waallatheena kafaroo wakaththaboo biayatina olaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Àwọn tó bá sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.”

2:40

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَوۡفُواْ بِعَهۡدِيٓ أُوفِ بِعَهۡدِكُمۡ وَإِيَّـٰيَ فَٱرۡهَبُونِ ﴿40﴾

Transliteration: Ya banee israeela othkuroo niAAmatiya allatee anAAamtu AAalaykum waawfoo biAAahdee oofi biAAahdikum waiyyaya fairhabooni

Translation: Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl,ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Ẹ mú májẹ̀mu Mi ṣẹ, Mo máa mú (ẹ̀san) májẹ̀mu yín ṣẹ. Èmi nìkan ni kí ẹ sì páyà.

2:41

وَءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلۡتُ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَكُمۡ وَلَا تَكُونُوٓاْ أَوَّلَ كَافِرِۭ بِهِۦۖ وَلَا تَشۡتَرُواْ بِـَٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗا وَإِيَّـٰيَ فَٱتَّقُونِ ﴿41﴾

Transliteration: Waaminoo bima anzaltu musaddiqan lima maAAakum wala takoonoo awwala kafirin bihi wala tashtaroo biayatee thamanan qaleelan waiyyaya faittaqooni

Translation: Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú.Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.

2:42

وَلَا تَلۡبِسُواْ ٱلۡحَقَّ بِٱلۡبَٰطِلِ وَتَكۡتُمُواْ ٱلۡحَقَّ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿42﴾

Transliteration: Wala talbisoo alhaqqa bialbatili wataktumoo alhaqqa waantum taAAlamoona

Translation: Ẹ má da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì má fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo).

2:43

وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱرۡكَعُواْ مَعَ ٱلرَّـٰكِعِينَ ﴿43﴾

Transliteration: Waaqeemoo alssalata waatoo alzzakata wairkaAAoo maAAa alrrakiAAeena

Translation: Ẹ kírun, ẹ yọ zakāh, kí ẹ sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).

2:44

أَتَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبِرِّ وَتَنسَوۡنَ أَنفُسَكُمۡ وَأَنتُمۡ تَتۡلُونَ ٱلۡكِتَٰبَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿44﴾

Transliteration: Atamuroona alnnasa bialbirri watansawna anfusakum waantum tatloona alkitaba afala taAAqiloona

Translation: Ṣé ẹ̀yin yóò máa pa àwọn ènìyàn l’áṣẹ ohun rere, ẹ sì ń gbàgbé ẹ̀mí ara yín, ẹ̀yin sì ń ké Tírà, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni!

2:45

وَٱسۡتَعِينُواْ بِٱلصَّبۡرِ وَٱلصَّلَوٰةِۚ وَإِنَّهَا لَكَبِيرَةٌ إِلَّا عَلَى ٱلۡخَٰشِعِينَ ﴿45﴾

Transliteration: WaistaAAeenoo bialssabri waalssalati wainnaha lakabeeratun illa AAala alkhashiAAeena

Translation: Ẹ wá oore (Allāhu) pẹ̀lú sùúrùàti ìrun kíkí. Dájúdájú ó lágbára (láti ṣe bẹ́ẹ̀) àyàfi fún àwọn olùpáyà (Allāhu),

2:46

ٱلَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَٰقُواْ رَبِّهِمۡ وَأَنَّهُمۡ إِلَيۡهِ رَٰجِعُونَ ﴿46﴾

Transliteration: Allatheena yathunnoona annahum mulaqoo rabbihim waannahum ilayhi rajiAAoona

Translation: (Àwọn olùpáyà Allāhu ni) àwọn tó mọ̀ dájúdájú pé, àwọn yóò pàdé Olúwa wọn, àti pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

2:47

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَنِّي فَضَّلۡتُكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿47﴾

Transliteration: Ya banee israeela othkuroo niAAmatiya allatee anAAamtu AAalaykum waannee faddaltukum AAala alAAalameena

Translation: Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo fi ṣèdẹ̀ra fún yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).

2:48

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا يُؤۡخَذُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿48﴾

Transliteration: Waittaqoo yawman la tajzee nafsun AAan nafsin shayan wala yuqbalu minha shafaAAatun wala yukhathu minha AAadlun wala hum yunsaroona

Translation: Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.2

2:49

وَإِذۡ نَجَّيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ ﴿49﴾

Transliteration: Waith najjaynakum min ali firAAawna yasoomoonakum sooa alAAathabi yuthabbihoona abnaakum wayastahyoona nisaakum wafee thalikum balaon min rabbikum AAatheemun

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

2:50

وَإِذۡ فَرَقۡنَا بِكُمُ ٱلۡبَحۡرَ فَأَنجَيۡنَٰكُمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿50﴾

Transliteration: Waith faraqna bikumu albahra faanjaynakum waaghraqna ala firAAawna waantum tanthuroona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami odò sí (ọ̀nà méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) fún yín, A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).

2:51

وَإِذۡ وَٰعَدۡنَا مُوسَىٰٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ ﴿51﴾

Transliteration: Waith waAAadna moosa arbaAAeena laylatan thumma ittakhathtumu alAAijla min baAAdihi waantum thalimoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.

2:52

ثُمَّ عَفَوۡنَا عَنكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿52﴾

Transliteration: Thumma AAafawna AAankum min baAAdi thalika laAAallakum tashkuroona

Translation: Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fún yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).

2:53

وَإِذۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡفُرۡقَانَ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿53﴾

Transliteration: Waith atayna moosa alkitaba waalfurqana laAAallakum tahtadoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.1

2:54

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِنَّكُمۡ ظَلَمۡتُمۡ أَنفُسَكُم بِٱتِّخَاذِكُمُ ٱلۡعِجۡلَ فَتُوبُوٓاْ إِلَىٰ بَارِئِكُمۡ فَٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ عِندَ بَارِئِكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿54﴾

Transliteration: Waith qala moosa liqawmihi ya qawmi innakum thalamtum anfusakum biittikhathikumu alAAijla fatooboo ila bariikum faoqtuloo anfusakum thalikum khayrun lakum AAinda bariikum fataba AAalaykum innahu huwa alttawwabu alrraheemu

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn tó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fún yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:55

وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡكُمُ ٱلصَّـٰعِقَةُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿55﴾

Transliteration: Waith qultum ya moosa lan numina laka hatta nara Allaha jahratan faakhathatkumu alssaAAiqatu waantum tanthuroona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbàgbọ́ nínú rẹ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀.

2:56

ثُمَّ بَعَثۡنَٰكُم مِّنۢ بَعۡدِ مَوۡتِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿56﴾

Transliteration: Thumma baAAathnakum min baAAdi mawtikum laAAallakum tashkuroona

Translation: Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).1

2:57

وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡغَمَامَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴿57﴾

Transliteration: Wathallalna AAalaykumu alghamama waanzalna AAalaykumu almanna waalssalwa kuloo min tayyibati ma razaqnakum wama thalamoona walakin kanoo anfusahum yathlimoona

Translation: A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnuàti (ohun jíjẹ) salwā2 kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

2:58

وَإِذۡ قُلۡنَا ٱدۡخُلُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ فَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ رَغَدٗا وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُولُواْ حِطَّةٞ نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطَٰيَٰكُمۡۚ وَسَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿58﴾

Transliteration: Waith qulna odkhuloo hathihi alqaryata fakuloo minha haythu shitum raghadan waodkhuloo albaba sujjadan waqooloo hittatun naghfir lakum khatayakum wasanazeedu almuhsineena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí.Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.2 Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.

2:59

فَبَدَّلَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ قَوۡلًا غَيۡرَ ٱلَّذِي قِيلَ لَهُمۡ فَأَنزَلۡنَا عَلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ ﴿59﴾

Transliteration: Fabaddala allatheena thalamoo qawlan ghayra allathee qeela lahum faanzalna AAala allatheena thalamoo rijzan mina alssamai bima kanoo yafsuqoona

Translation: Àwọn tó ṣàbòsí yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí ọ̀rọ̀ mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé àwọn tó ṣàbòsí lórí nítorí pé, wọ́n ń rú òfin.

2:60

وَإِذِ ٱسۡتَسۡقَىٰ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ فَقُلۡنَا ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡحَجَرَۖ فَٱنفَجَرَتۡ مِنۡهُ ٱثۡنَتَا عَشۡرَةَ عَيۡنٗاۖ قَدۡ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٖ مَّشۡرَبَهُمۡۖ كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ مِن رِّزۡقِ ٱللَّهِ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ ﴿60﴾

Transliteration: Waithi istasqa moosa liqawmihi faqulna idrib biAAasaka alhajara fainfajarat minhu ithnata AAashrata AAaynan qad AAalima kullu onasin mashrabahum kuloo waishraboo min rizqi Allahi wala taAAthaw fee alardi mufsideena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā tọrọ omi fún ìjọ rẹ̀. A sì sọ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na òkúta.” Orísun omi méjìlá sì ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti mọ ibùmu wọn. Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu nínú arísìkí Allāhu. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.

2:61

وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نَّصۡبِرَ عَلَىٰ طَعَامٖ وَٰحِدٖ فَٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُخۡرِجۡ لَنَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۢ بَقۡلِهَا وَقِثَّآئِهَا وَفُومِهَا وَعَدَسِهَا وَبَصَلِهَاۖ قَالَ أَتَسۡتَبۡدِلُونَ ٱلَّذِي هُوَ أَدۡنَىٰ بِٱلَّذِي هُوَ خَيۡرٌۚ ٱهۡبِطُواْ مِصۡرٗا فَإِنَّ لَكُم مَّا سَأَلۡتُمۡۗ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ وَٱلۡمَسۡكَنَةُ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ ﴿61﴾

Transliteration: Waith qultum ya moosa lan nasbira AAala taAAamin wahidin faodAAu lana rabbaka yukhrij lana mimma tunbitu alardu min baqliha waqiththaiha wafoomiha waAAadasiha wabasaliha qala atastabdiloona allathee huwa adna biallathee huwa khayrun ihbitoo misran fainna lakum ma saaltum waduribat AAalayhimu alththillatu waalmaskanatu wabaoo bighadabin mina Allahi thalika biannahum kanoo yakfuroona biayati Allahi wayaqtuloona alnnabiyyeena bighayri alhaqqi thalika bima AAasaw wakanoo yaAAtadoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí ṣe ìfaradà lórí oúnjẹ ẹyọ kan. Nítorí náà, pe Olúwa rẹ fún wa. Kí Ó mú jáde fún wa nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde ní ewébẹ̀ rẹ̀ àti kùkúḿbà rẹ̀ àti fūmu rẹ̀ (wíìtì àti àlùbọ́sà áyù) àti ọkàbàbà rẹ̀ àti àlùbọ́sà rẹ̀.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò fi èyí tó yẹpẹrẹ pààrọ̀ èyí tí ó dára jùlọ ni? Ẹ sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú (mìíràn). Dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún ń bẹ (níbẹ̀) fún yín.” A sì mú ìyẹpẹrẹ àti òṣì bá wọn. Wọ́n sì padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n sì ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.

2:62

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلصَّـٰبِـِٔينَ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿62﴾

Transliteration: Inna allatheena amanoo waallatheena hadoo waalnnasara waalssabieena man amana biAllahi waalyawmi alakhiri waAAamila salihan falahum ajruhum AAinda rabbihim wala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.1

2:63

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿63﴾

Transliteration: Waith akhathna meethaqakum warafaAAna fawqakumu alttoora khuthoo ma ataynakum biquwwatin waothkuroo ma feehi laAAallakum tattaqoona

Translation: Ẹ rántí nígbà tí A gba àdéhùn yín, A sì gbé àpáta wá sókè orí yín, (A sì sọ pé): “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára, kí ẹ sì rántí ohun tó wà nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).

2:64

ثُمَّ تَوَلَّيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَۖ فَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ لَكُنتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿64﴾

Transliteration: Thumma tawallaytum min baAAdi thalika falawla fadlu Allahi AAalaykum warahmatuhu lakuntum mina alkhasireena

Translation: Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín, ẹ̀yin ìbá wà nínú ẹni òfò.

2:65

وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلَّذِينَ ٱعۡتَدَوۡاْ مِنكُمۡ فِي ٱلسَّبۡتِ فَقُلۡنَا لَهُمۡ كُونُواْ قِرَدَةً خَٰسِـِٔينَ ﴿65﴾

Transliteration: Walaqad AAalimtumu allatheena iAAtadaw minkum fee alssabti faqulna lahum koonoo qiradatan khasieena

Translation: Dájúdájú ẹ mọ àwọn tó kọjá ẹnu-ààlà nínú yín nípa ọjọ́ Sabt. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni-ìgbéjìnnà sí ìkẹ́ (ẹni àbùkù ẹni yẹpẹrẹ).”

2:66

فَجَعَلۡنَٰهَا نَكَٰلٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهَا وَمَا خَلۡفَهَا وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ ﴿66﴾

Transliteration: FajaAAalnaha nakalan lima bayna yadayha wama khalfaha wamawAAithatan lilmuttaqeena

Translation: A sì ṣe é ní ìyà (àríkọ́gbọ́n) fún ẹni tó ṣojú rẹ̀ àti ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Ó tún jẹ́) wáàsí (ìṣítí) fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

2:67

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُكُمۡ أَن تَذۡبَحُواْ بَقَرَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَتَّخِذُنَا هُزُوٗاۖ قَالَ أَعُوذُ بِٱللَّهِ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ ﴿67﴾

Transliteration: Waith qala moosa liqawmihi inna Allaha yamurukum an tathbahoo baqaratan qaloo atattakhithuna huzuwan qala aAAoothu biAllahi an akoona mina aljahileena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa abo màálù kan.” Wọ́n wí pé: “Ṣé ò ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ni!” Ó sọ pé: “Mò ń sádi Allāhu kúrò níbi kí n̄g jẹ́ ara àwọn òpè.”

2:68

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا فَارِضٞ وَلَا بِكۡرٌ عَوَانُۢ بَيۡنَ ذَٰلِكَۖ فَٱفۡعَلُواْ مَا تُؤۡمَرُونَ ﴿68﴾

Transliteration: Qaloo odAAu lana rabbaka yubayyin lana ma hiya qala innahu yaqoolu innaha baqaratun la faridun wala bikrun AAawanun bayna thalika faifAAaloo ma tumaroona

Translation: Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ ògbólógbòó, kò sì níí jẹ́ gódógbó. Ọdún rẹ̀ máa wà láààrin (méjèèjì) yẹn. Nítorí náà, ẹ ṣe ohun tí wọ́n ń pa yín láṣẹ.”

2:69

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا لَوۡنُهَاۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ صَفۡرَآءُ فَاقِعٞ لَّوۡنُهَا تَسُرُّ ٱلنَّـٰظِرِينَ ﴿69﴾

Transliteration: Qaloo odAAu lana rabbaka yubayyin lana ma lawnuha qala innahu yaqoolu innaha baqaratun safrao faqiAAun lawnuha tasurru alnnathireena

Translation: Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí àwọ̀ rẹ̀ bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù, aláwọ̀ omi-ọsàn ni. Àwọ̀ rẹ̀ sì máa mọ́ fónífóní, tí ó máa dùn-ún wò lójú àwọn olùwòran.

2:70

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَ إِنَّ ٱلۡبَقَرَ تَشَٰبَهَ عَلَيۡنَا وَإِنَّآ إِن شَآءَ ٱللَّهُ لَمُهۡتَدُونَ ﴿70﴾

Transliteration: Qaloo odAAu lana rabbaka yubayyin lana ma hiya inna albaqara tashabaha AAalayna wainna in shaa Allahu lamuhtadoona

Translation: Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa sẹ́.” Dájúdájú àwọn abo màálù jọra wọn lójú wa. Àti pé dájúdájú, tí Allāhu bá fẹ́, àwa máa mọ̀nà (tí a ó gbà rí i.)”

2:71

قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا ذَلُولٞ تُثِيرُ ٱلۡأَرۡضَ وَلَا تَسۡقِي ٱلۡحَرۡثَ مُسَلَّمَةٞ لَّا شِيَةَ فِيهَاۚ قَالُواْ ٱلۡـَٰٔنَ جِئۡتَ بِٱلۡحَقِّۚ فَذَبَحُوهَا وَمَا كَادُواْ يَفۡعَلُونَ ﴿71﴾

Transliteration: Qala innahu yaqoolu innaha baqaratun la thaloolun tutheeru alarda wala tasqee alhartha musallamatun la shiyata feeha qaloo alana jita bialhaqqi fathabahooha wama kadoo yafAAaloona

Translation: Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ màálù yẹpẹrẹ tí ó ń kọ ebè sórí ilẹ̀ (tó ń ro oko) àti èyí tí ó ń fomi wọ́n oko. Ó máa ní àlàáfíà, kò sì níí ní àbàwọ́n kan lára.” Wọ́n wí pé: “Nísinsìn yìí lo mú òdodo wá.” Wọ́n sì pa màálù náà. Wọ́n fẹ́ẹ̀ má ṣe é mọ́.

2:72

وَإِذۡ قَتَلۡتُمۡ نَفۡسٗا فَٱدَّـٰرَ ٰٔتُمۡ فِيهَاۖ وَٱللَّهُ مُخۡرِجٞ مَّا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ ﴿72﴾

Transliteration: Waith qataltum nafsan faiddaratum feeha waAllahu mukhrijun ma kuntum taktumoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.

2:73

فَقُلۡنَا ٱضۡرِبُوهُ بِبَعۡضِهَاۚ كَذَٰلِكَ يُحۡيِ ٱللَّهُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴿73﴾

Transliteration: Faqulna idriboohu bibaAAdiha kathalika yuhyee Allahu almawta wayureekum ayatihi laAAallakum taAAqiloona

Translation: Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).”Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

2:74

ثُمَّ قَسَتۡ قُلُوبُكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَٱلۡحِجَارَةِ أَوۡ أَشَدُّ قَسۡوَةٗۚ وَإِنَّ مِنَ ٱلۡحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنۡهُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخۡرُجُ مِنۡهُ ٱلۡمَآءُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَهۡبِطُ مِنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿74﴾

Transliteration: Thumma qasat quloobukum min baAAdi thalika fahiya kaalhijarati aw ashaddu qaswatan wainna mina alhijarati lama yatafajjaru minhu alanharu wainna minha lama yashshaqqaqu fayakhruju minhu almao wainna minha lama yahbitu min khashyati Allahi wama Allahu bighafilin AAamma taAAmaloona

Translation: Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ.Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:75

أَفَتَطۡمَعُونَ أَن يُؤۡمِنُواْ لَكُمۡ وَقَدۡ كَانَ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَسۡمَعُونَ كَلَٰمَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُحَرِّفُونَهُۥ مِنۢ بَعۡدِ مَا عَقَلُوهُ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ ﴿75﴾

Transliteration: AfatatmaAAoona an yuminoo lakum waqad kana fareequn minhum yasmaAAoona kalama Allahi thumma yuharrifoonahu min baAAdi ma AAaqaloohu wahum yaAAlamoona

Translation: Ṣé ẹ̀ ń rankàn pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.

2:76

وَإِذَا لَقُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَا بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ قَالُوٓاْ أَتُحَدِّثُونَهُم بِمَا فَتَحَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ لِيُحَآجُّوكُم بِهِۦ عِندَ رَبِّكُمۡۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿76﴾

Transliteration: Waitha laqoo allatheena amanoo qaloo amanna waitha khala baAAduhum ila baAAdin qaloo atuhaddithoonahum bima fataha Allahu AAalaykum liyuhajjookum bihi AAinda rabbikum afala taAAqiloona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fún yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”

2:77

أَوَلَا يَعۡلَمُونَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ ﴿77﴾

Transliteration: Awala yaAAlamoona anna Allaha yaAAlamu ma yusirroona wama yuAAlinoona

Translation: Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀?

2:78

وَمِنۡهُمۡ أُمِّيُّونَ لَا يَعۡلَمُونَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّآ أَمَانِيَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَظُنُّونَ ﴿78﴾

Transliteration: Waminhum ommiyyoona la yaAAlamoona alkitaba illa amaniyya wain hum illa yathunnoona

Translation: Àti pé ó wà nínú wọn, àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, tí wọn kò nímọ̀ nípa Tírà àfi àwọn irọ́. Kí ni wọ́n (ń sọ) bí kò ṣe pé wọ́n ń dá àbá (àròsọ).

2:79

فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ يَكۡتُبُونَ ٱلۡكِتَٰبَ بِأَيۡدِيهِمۡ ثُمَّ يَقُولُونَ هَٰذَا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ لِيَشۡتَرُواْ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلٗاۖ فَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا كَتَبَتۡ أَيۡدِيهِمۡ وَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا يَكۡسِبُونَ ﴿79﴾

Transliteration: Fawaylun lillatheena yaktuboona alkitaba biaydeehim thumma yaqooloona hatha min AAindi Allahi liyashtaroo bihi thamanan qaleelan fawaylun lahum mimma katabat aydeehim wawaylun lahum mimma yaksiboona

Translation: Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:80

وَقَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَةٗۚ قُلۡ أَتَّخَذۡتُمۡ عِندَ ٱللَّهِ عَهۡدٗا فَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ عَهۡدَهُۥٓۖ أَمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿80﴾

Transliteration: Waqaloo lan tamassana alnnaru illa ayyaman maAAdoodatan qul attakhathtum AAinda Allahi AAahdan falan yukhlifa Allahu AAahdahu am taqooloona AAala Allahi ma la taAAlamoona

Translation: Wọ́n sì wí pé: “Iná kò lè fọwọ́ bà wá tayọ ọjọ́ tó lóǹkà.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ti rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Allāhu ni?”Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Àbí ṣé ẹ̀yin yóò máa pa irọ́ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ Allāhu ni?

2:81

بَلَىٰۚ مَن كَسَبَ سَيِّئَةٗ وَأَحَٰطَتۡ بِهِۦ خَطِيٓـَٔتُهُۥ فَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿81﴾

Transliteration: Bala man kasaba sayyiatan waahatat bihi khateeatuhu faolaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:82

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿82﴾

Transliteration: Waallatheena amanoo waAAamiloo alssalihati olaika ashabu aljannati hum feeha khalidoona

Translation: Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:83

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ لَا تَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَانٗا وَذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَقُولُواْ لِلنَّاسِ حُسۡنٗا وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ ثُمَّ تَوَلَّيۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنكُمۡ وَأَنتُم مُّعۡرِضُونَ ﴿83﴾

Transliteration: Waith akhathna meethaqa banee israeela la taAAbudoona illa Allaha wabialwalidayni ihsanan wathee alqurba waalyatama waalmasakeeni waqooloo lilnnasi husnan waaqeemoo alssalata waatoo alzzakata thumma tawallaytum illa qaleelan minkum waantum muAAridoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù.Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn).

2:84

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ لَا تَسۡفِكُونَ دِمَآءَكُمۡ وَلَا تُخۡرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ ثُمَّ أَقۡرَرۡتُمۡ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ ﴿84﴾

Transliteration: Waith akhathna meethaqakum la tasfikoona dimaakum wala tukhrijoona anfusakum min diyarikum thumma aqrartum waantum tashhadoona

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yínpé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i.

2:85

ثُمَّ أَنتُمۡ هَـٰٓؤُلَآءِ تَقۡتُلُونَ أَنفُسَكُمۡ وَتُخۡرِجُونَ فَرِيقٗا مِّنكُم مِّن دِيَٰرِهِمۡ تَظَٰهَرُونَ عَلَيۡهِم بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَإِن يَأۡتُوكُمۡ أُسَٰرَىٰ تُفَٰدُوهُمۡ وَهُوَ مُحَرَّمٌ عَلَيۡكُمۡ إِخۡرَاجُهُمۡۚ أَفَتُؤۡمِنُونَ بِبَعۡضِ ٱلۡكِتَٰبِ وَتَكۡفُرُونَ بِبَعۡضٖۚ فَمَا جَزَآءُ مَن يَفۡعَلُ ذَٰلِكَ مِنكُمۡ إِلَّا خِزۡيٞ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُرَدُّونَ إِلَىٰٓ أَشَدِّ ٱلۡعَذَابِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿85﴾

Transliteration: Thumma antum haolai taqtuloona anfusakum watukhrijoona fareeqan minkum min diyarihim tathaharoona AAalayhim bialithmi waalAAudwani wain yatookum osara tufadoohum wahuwa muharramun AAalaykum ikhrajuhum afatuminoona bibaAAdi alkitabi watakfuroona bibaAAdin fama jazao man yafAAalu thalika minkum illa khizyun fee alhayati alddunya wayawma alqiyamati yuraddoona ila ashaddi alAAathabi wama Allahu bighafilin AAamma taAAmaloona

Translation: Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin wọ̀nyí lẹ̀ ń pa ara yín. Ẹ tún ń lé apá kan nínú yín jáde kúrò nínú ilé wọn. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àti àbòsí ṣèrànwọ́ (fún àwọn ọ̀tá) lórí wọn. Tí wọ́n bá sì wá ba yín (tí wọ́n ti di) ẹrú, ẹ̀yin ń rà wọ́n (láti fi’ra yín ṣẹrú). Èèwọ̀ sì fẹ̀ẹ̀kan ni fún yín láti lé wọn jáde. Ṣé ẹ̀yin yóò gba apá kan Tírà gbọ́, ẹ sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan? Nítorí náà, kí ni ẹ̀san fún ẹni tó ṣè yẹn nínú yín bí kò ṣe àbùkù nínú ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọjọ́ Àjíǹde, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìyà tó le jùlọ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:86

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا بِٱلۡأٓخِرَةِۖ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿86﴾

Transliteration: Olaika allatheena ishtarawoo alhayata alddunya bialakhirati fala yukhaffafu AAanhumu alAAathabu wala hum yunsaroona

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé.Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

2:87

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَقَفَّيۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ بِٱلرُّسُلِۖ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ أَفَكُلَّمَا جَآءَكُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُكُمُ ٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ فَفَرِيقٗا كَذَّبۡتُمۡ وَفَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ ﴿87﴾

Transliteration: Walaqad atayna moosa alkitaba waqaffayna min baAAdihi bialrrusuli waatayna AAeesa ibna maryama albayyinati waayyadnahu biroohi alqudusi afakullama jaakum rasoolun bima la tahwa anfusukumu istakbartum fafareeqan kaththabtum wafareeqan taqtuloona

Translation: Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì mú àwọn Òjíṣẹ́ wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé lẹ́yìn rẹ̀. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú.A sì fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, Mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Ṣé gbogbo ìgbà tí Òjíṣẹ́ kan bá wá ba yín pẹ̀lú ohun tí ọkàn yín kò fẹ́ ni ẹ ó máa ṣègbéraga? Ẹ sì pe apá kan (àwọn Ànábì) ní òpùrọ́, ẹ sì ń pa apá kan!

2:88

وَقَالُواْ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَل لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَقَلِيلٗا مَّا يُؤۡمِنُونَ ﴿88﴾

Transliteration: Waqaloo quloobuna ghulfun bal laAAanahumu Allahu bikufrihim faqaleelan ma yuminoona

Translation: Wọ́n sì wí pé: “Èbìbò bò wá lọ́kàn.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn ni, nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Ṣebí díẹ̀ ni wọ́n ń gbàgbọ́.

2:89

وَلَمَّا جَآءَهُمۡ كِتَٰبٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ وَكَانُواْ مِن قَبۡلُ يَسۡتَفۡتِحُونَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَمَّا جَآءَهُم مَّا عَرَفُواْ كَفَرُواْ بِهِۦۚ فَلَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿89﴾

Transliteration: Walamma jaahum kitabun min AAindi Allahi musaddiqun lima maAAahum wakanoo min qablu yastaftihoona AAala allatheena kafaroo falamma jaahum ma AAarafoo kafaroo bihi falaAAnatu Allahi AAala alkafireena

Translation: Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn (ìyẹn tírà Taorāt), bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́.1

2:90

بِئۡسَمَا ٱشۡتَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡ أَن يَكۡفُرُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بَغۡيًا أَن يُنَزِّلَ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ فَبَآءُو بِغَضَبٍ عَلَىٰ غَضَبٖۚ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٞ مُّهِينٞ ﴿90﴾

Transliteration: Bisama ishtaraw bihi anfusahum an yakfuroo bima anzala Allahu baghyan an yunazzila Allahu min fadlihi AAala man yashao min AAibadihi fabaoo bighadabin AAala ghadabin walilkafireena AAathabun muheenun

Translation: Aburú ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn nípa bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ní ti ìlara pé Allāhu ń sọ (Tírà) kalẹ̀ nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Wọ́n sì padà pẹ̀lú ìbínú (mìíràn) lórí ìbínú (Allāhu tí ó ti wà lórí wọn tẹ́lẹ̀). Ìyà tí í yẹpẹrẹ (ẹ̀dá) sì ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.

2:91

وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ ءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ نُؤۡمِنُ بِمَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا وَيَكۡفُرُونَ بِمَا وَرَآءَهُۥ وَهُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَهُمۡۗ قُلۡ فَلِمَ تَقۡتُلُونَ أَنۢبِيَآءَ ٱللَّهِ مِن قَبۡلُ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ ﴿91﴾

Transliteration: Waitha qeela lahum aminoo bima anzala Allahu qaloo numinu bima onzila AAalayna wayakfuroona bima waraahu wahuwa alhaqqu musaddiqan lima maAAahum qul falima taqtuloona anbiyaa Allahi min qablu in kuntum mumineena

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tó wà lẹ́yìn rẹ̀, òhun sì ni òdodo, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?

2:92

وَلَقَدۡ جَآءَكُم مُّوسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ ﴿92﴾

Transliteration: Walaqad jaakum moosa bialbayyinati thumma ittakhathtumu alAAijla min baAAdihi waantum thalimoona

Translation: Àti pé dájúdájú (Ànábì) Mūsā ti mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá ba yín. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.”

2:93

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱسۡمَعُواْۖ قَالُواْ سَمِعۡنَا وَعَصَيۡنَا وَأُشۡرِبُواْ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡعِجۡلَ بِكُفۡرِهِمۡۚ قُلۡ بِئۡسَمَا يَأۡمُرُكُم بِهِۦٓ إِيمَٰنُكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ ﴿93﴾

Transliteration: Waith akhathna meethaqakum warafaAAna fawqakumu alttoora khuthoo ma ataynakum biquwwatin waismaAAoo qaloo samiAAna waAAasayna waoshriboo fee quloobihimu alAAijla bikufrihim qul bisama yamurukum bihi eemanukum in kuntum mumineena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yín, A sì gbé àpáta s’ókè orí yín, (A sọ pé:) “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára. Kí ẹ sì tẹ́tí gbọ́rọ̀.” Wọ́n wí pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì yapa (rẹ̀).” Wọ́n ti kó ìfẹ́ bíbọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù sínú ọkàn wọn nípasẹ̀ àìgbàgbọ́ wọn. Sọ pé: “Aburú ni ohun tí ìgbàgbọ́ (ìbọ̀rìṣà) yín ń pa yín láṣẹ rẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”

2:94

قُلۡ إِن كَانَتۡ لَكُمُ ٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ ٱللَّهِ خَالِصَةٗ مِّن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿94﴾

Transliteration: Qul in kanat lakumu alddaru alakhiratu AAinda Allahi khalisatan min dooni alnnasi fatamannawoo almawta in kuntum sadiqeena

Translation: Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé tiyín nìkan ni Ilé Ìkẹ́yìn tí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu, tí kò sì níí jẹ́ ti àwọn ènìyàn (mìíràn), ẹ tọrọ ikú, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

2:95

وَلَن يَتَمَنَّوۡهُ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿95﴾

Transliteration: Walan yatamannawhu abadan bima qaddamat aydeehim waAllahu AAaleemun bialththalimeena

Translation: Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn tì síwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.

2:96

وَلَتَجِدَنَّهُمۡ أَحۡرَصَ ٱلنَّاسِ عَلَىٰ حَيَوٰةٖ وَمِنَ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْۚ يَوَدُّ أَحَدُهُمۡ لَوۡ يُعَمَّرُ أَلۡفَ سَنَةٖ وَمَا هُوَ بِمُزَحۡزِحِهِۦ مِنَ ٱلۡعَذَابِ أَن يُعَمَّرَۗ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا يَعۡمَلُونَ ﴿96﴾

Transliteration: Walatajidannahum ahrasa alnnasi AAala hayatin wamina allatheena ashrakoo yawaddu ahaduhum law yuAAammaru alfa sanatin wama huwa bimuzahzihihi mina alAAathabi an yuAAammara waAllahu baseerun bima yaAAmaloona

Translation: Dájúdájú o máa rí wọn pé àwọn ni ènìyàn tó l’ójú kòkòrò jùlọ nípa ìṣẹ̀mí ayé, (wọ́n tún l’ójú kòkòrò ju) àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ. Ìkọ̀ọ̀kan wọn ń fẹ́ pé tí A bá lè fún òun ní ẹgbẹ̀rún ọdún lò láyé. Bẹ́ẹ̀ sì ni, kì í ṣe ohun tí ó máa là á nínú ìyà ni pé, kí Á fún un ní ìṣẹ̀mí gígùn lò. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:97

قُلۡ مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّـجِبۡرِيلَ فَإِنَّهُۥ نَزَّلَهُۥ عَلَىٰ قَلۡبِكَ بِإِذۡنِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَهُدٗى وَبُشۡرَىٰ لِلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿97﴾

Transliteration: Qul man kana AAaduwwan lijibreela fainnahu nazzalahu AAala qalbika biithni Allahi musaddiqan lima bayna yadayhi wahudan wabushra lilmumineena

Translation: Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,(ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

2:98

مَن كَانَ عَدُوّٗا لِّلَّهِ وَمَلَـٰٓئِكَتِهِۦ وَرُسُلِهِۦ وَجِبۡرِيلَ وَمِيكَىٰلَ فَإِنَّ ٱللَّهَ عَدُوّٞ لِّلۡكَٰفِرِينَ ﴿98﴾

Transliteration: Man kana AAaduwwan lillahi wamalaikatihi warusulihi wajibreela wameekala fainna Allaha AAaduwwun lilkafireena

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀, mọlāika Jibrīl àti mọlāika Mīkāl, dájúdájú Allāhu ni ọ̀tá fún àwọn aláìgbàgbọ́.”

2:99

وَلَقَدۡ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ ءَايَٰتِۭ بَيِّنَٰتٖۖ وَمَا يَكۡفُرُ بِهَآ إِلَّا ٱلۡفَٰسِقُونَ ﴿99﴾

Transliteration: Walaqad anzalna ilayka ayatin bayyinatin wama yakfuru biha illa alfasiqoona

Translation: Dájúdájú A ti sọ àwọn āyah tó yanjú kalẹ̀ fún ọ. Ẹnì kan kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ àyàfi àwọn arúfin.

2:100

أَوَكُلَّمَا عَٰهَدُواْ عَهۡدٗا نَّبَذَهُۥ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۚ بَلۡ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿100﴾

Transliteration: Awakullama AAahadoo AAahdan nabathahu fareequn minhum bal aktharuhum la yuminoona

Translation: Àti pé ṣé gbogbo ìgbà tí wọ́n bá dá májẹ̀mu kan ni apá kan nínú wọn yóò máa jù ú nù? Rárá, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn gan-an ni kò gbàgbọ́.

2:101

وَلَمَّا جَآءَهُمۡ رَسُولٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ نَبَذَ فَرِيقٞ مِّنَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ كِتَٰبَ ٱللَّهِ وَرَآءَ ظُهُورِهِمۡ كَأَنَّهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿101﴾

Transliteration: Walamma jaahum rasoolun min AAindi Allahi musaddiqun lima maAAahum nabatha fareequn mina allatheena ootoo alkitaba kitaba Allahi waraa thuhoorihim kaannahum la yaAAlamoona

Translation: Àti pé nígbà tí Òjíṣẹ́ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu dé bá wọn, tí ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú ohun tó wà pẹ̀lú wọn, apá kan nínú àwọn tí A fún ní Tírà gbé Tírà Allāhu jù s’ẹ́yìn lẹ́yìn wọn bí ẹni pé wọn kò mọ̀ (pé àsọọ́lẹ̀ nípa Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - wà nínú rẹ̀)!

2:102

وَٱتَّبَعُواْ مَا تَتۡلُواْ ٱلشَّيَٰطِينُ عَلَىٰ مُلۡكِ سُلَيۡمَٰنَۖ وَمَا كَفَرَ سُلَيۡمَٰنُ وَلَٰكِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ كَفَرُواْ يُعَلِّمُونَ ٱلنَّاسَ ٱلسِّحۡرَ وَمَآ أُنزِلَ عَلَى ٱلۡمَلَكَيۡنِ بِبَابِلَ هَٰرُوتَ وَمَٰرُوتَۚ وَمَا يُعَلِّمَانِ مِنۡ أَحَدٍ حَتَّىٰ يَقُولَآ إِنَّمَا نَحۡنُ فِتۡنَةٞ فَلَا تَكۡفُرۡۖ فَيَتَعَلَّمُونَ مِنۡهُمَا مَا يُفَرِّقُونَ بِهِۦ بَيۡنَ ٱلۡمَرۡءِ وَزَوۡجِهِۦۚ وَمَا هُم بِضَآرِّينَ بِهِۦ مِنۡ أَحَدٍ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَتَعَلَّمُونَ مَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡۚ وَلَقَدۡ عَلِمُواْ لَمَنِ ٱشۡتَرَىٰهُ مَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖۚ وَلَبِئۡسَ مَا شَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡۚ لَوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ﴿102﴾

Transliteration: WaittabaAAoo ma tatloo alshshayateenu AAala mulki sulaymana wama kafara sulaymanu walakinna alshshayateena kafaroo yuAAallimoona alnnasa alssihra wama onzila AAala almalakayni bibabila haroota wamaroota wama yuAAallimani min ahadin hatta yaqoola innama nahnu fitnatun fala takfur fayataAAallamoona minhuma ma yufarriqoona bihi bayna almari wazawjihi wama hum bidarreena bihi min ahadin illa biithni Allahi wayataAAallamoona ma yadurruhum wala yanfaAAuhum walaqad AAalimoo lamani ishtarahu ma lahu fee alakhirati min khalaqin walabisa ma sharaw bihi anfusahum law kanoo yaAAlamoona

Translation: Wọ́n sì tẹ̀lé ohun tí àwọn èṣù àlùjànnú ń kà (fún wọn nínú idán lásìkò) ìjọba (Ànábì) Sulaemọ̄n. (Ànábì) Sulaemọ̄n kò sì di kèfèrí, ṣùgbọ́n àwọn èṣù àlùjànnú ni wọ́n di kèfèrí, wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn ní idán àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwọn mọlāika méjèèjì, Hārūt àti Mọ̄rūt ní ìlú Bābil.Àwọn mọlāika méjèèjì náà kò sì níí kọ́ ẹnikẹ́ni àyàfi kí wọ́n sọ pé: “Àdánwò ni wá. Nítorí náà, má di kèfèrí.” Wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí wọn yóò fi ṣòpínyà láààrin ọmọnìyàn àti ẹnì kejì rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn. - Wọn kò sì lè kó ìnira bá ẹnikẹ́ni àyàfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. - Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ó máa kó ìnira bá wọn, tí kò sì níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. Wọ́n kúkú ti mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ra idán, kò níí sí ìpín rere kan fún un ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Aburú sì ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀.

2:103

وَلَوۡ أَنَّهُمۡ ءَامَنُواْ وَٱتَّقَوۡاْ لَمَثُوبَةٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ خَيۡرٞۚ لَّوۡ كَانُواْ يَعۡلَمُونَ ﴿103﴾

Transliteration: Walaw annahum amanoo waittaqaw lamathoobatun min AAindi Allahi khayrun law kanoo yaAAlamoona

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì bẹ̀rù (Allāhu), dájúdájú ẹ̀san tí ó máa wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore jùlọ (fún wọn), tí wọ́n bá mọ̀.

2:104

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقُولُواْ رَٰعِنَا وَقُولُواْ ٱنظُرۡنَا وَٱسۡمَعُواْۗ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٞ ﴿104﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la taqooloo raAAina waqooloo onthurna waismaAAoo walilkafireena AAathabun aleemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má sọ pé “rọ̄‘inā”. (Àmọ́) ẹ sọ pé “unṭḥurnā” kí ẹ sì máa tẹ́tí gbọ́ (ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.

2:105

مَّا يَوَدُّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ وَلَا ٱلۡمُشۡرِكِينَ أَن يُنَزَّلَ عَلَيۡكُم مِّنۡ خَيۡرٖ مِّن رَّبِّكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَخۡتَصُّ بِرَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ ﴿105﴾

Transliteration: Ma yawaddu allatheena kafaroo min ahli alkitabi wala almushrikeena an yunazzala AAalaykum min khayrin min rabbikum waAllahu yakhtassu birahmatihi man yashao waAllahu thoo alfadli alAAatheemi

Translation: Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn tí A fún ní Tírà àti àwọn ọ̀ṣẹbọ kò níí fẹ́ kí wọ́n sọ oore kan kan kalẹ̀ fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Allāhu ló ń fi ìkẹ́ Rẹ̀ ṣa ẹni tí Ó bá fẹ́ lẹ́ṣà. Allāhu sì ni Olóore ńlá.

2:106

مَا نَنسَخۡ مِنۡ ءَايَةٍ أَوۡ نُنسِهَا نَأۡتِ بِخَيۡرٖ مِّنۡهَآ أَوۡ مِثۡلِهَآۗ أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ ﴿106﴾

Transliteration: Ma nansakh min ayatin aw nunsiha nati bikhayrin minha aw mithliha alam taAAlam anna Allaha AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Ohunkóhun tí A bá parẹ́ (tàbí pààrọ̀) nínú āyah kantàbí tí A sọ di ìgbàgbé, A máa mú èyí tó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan?

2:107

أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ وَمَا لَكُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ ﴿107﴾

Transliteration: Alam taAAlam anna Allaha lahu mulku alssamawati waalardi wama lakum min dooni Allahi min waliyyin wala naseerin

Translation: Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Kò sì sí aláàbò àti alárànṣe kan fún yín lẹ́yìn Allāhu.

2:108

أَمۡ تُرِيدُونَ أَن تَسۡـَٔلُواْ رَسُولَكُمۡ كَمَا سُئِلَ مُوسَىٰ مِن قَبۡلُۗ وَمَن يَتَبَدَّلِ ٱلۡكُفۡرَ بِٱلۡإِيمَٰنِ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ ﴿108﴾

Transliteration: Am tureedoona an tasaloo rasoolakum kama suila moosa min qablu waman yatabaddali alkufra bialeemani faqad dalla sawaa alssabeeli

Translation: Tàbí ẹ fẹ́ máa bèèrè (ọ̀rọ̀kọ́rọ̀) lọ́wọ́ Òjíṣẹ́ yín ni gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe bèèrè (ọ̀rọ̀kọ́rọ̀) lọ́wọ́ (Ànábì) Mūsā ṣíwájú? Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi àìgbàgbọ́ rọ́pò ìgbàgbọ́, dájúdájú ó ti ṣìnà (kúrò) l’ójú ọ̀nà tààrà.

2:109

وَدَّ كَثِيرٞ مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ لَوۡ يَرُدُّونَكُم مِّنۢ بَعۡدِ إِيمَٰنِكُمۡ كُفَّارًا حَسَدٗا مِّنۡ عِندِ أَنفُسِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ ٱلۡحَقُّۖ فَٱعۡفُواْ وَٱصۡفَحُواْ حَتَّىٰ يَأۡتِيَ ٱللَّهُ بِأَمۡرِهِۦٓۗ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿109﴾

Transliteration: Wadda katheerun min ahli alkitabi law yaruddoonakum min baAAdi eemanikum kuffaran hasadan min AAindi anfusihim min baAAdi ma tabayyana lahumu alhaqqu faoAAfoo waisfahoo hatta yatiya Allahu biamrihi inna Allaha AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn tí A fún ní Tírà fẹ́ láti da yín padà sípò kèfèrí lẹ́yìn tí ẹ ti ní ìgbàgbọ́ òdodo, ní ti kèéta láti inú ẹ̀mí wọn, (àti) lẹ́yìn tí òdodo (’Islām) ti fojú hàn sí wọn. Nítorí náà, ẹ foríjìn wọ́n, kí ẹ ṣàmójú kúrò fún wọn (nípa ìnira tí wọ́n ń fi kàn yín) títí Allāhu yó fi mú àṣẹ Rẹ̀ wá (láti jà wọ́n lógun). Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

2:110

وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَۚ وَمَا تُقَدِّمُواْ لِأَنفُسِكُم مِّنۡ خَيۡرٖ تَجِدُوهُ عِندَ ٱللَّهِۗ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ﴿110﴾

Transliteration: Waaqeemoo alssalata waatoo alzzakata wama tuqaddimoo lianfusikum min khayrin tajidoohu AAinda Allahi inna Allaha bima taAAmaloona baseerun

Translation: Ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh; ohunkóhun tí ẹ bá sì tì síwájú fún ẹ̀mí ara yín ní rere, ẹ máa bá a lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:111

وَقَالُواْ لَن يَدۡخُلَ ٱلۡجَنَّةَ إِلَّا مَن كَانَ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰۗ تِلۡكَ أَمَانِيُّهُمۡۗ قُلۡ هَاتُواْ بُرۡهَٰنَكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿111﴾

Transliteration: Waqaloo lan yadkhula aljannata illa man kana hoodan aw nasara tilka amaniyyuhum qul hatoo burhanakum in kuntum sadiqeena

Translation: Wọ́n wí pé: “Ẹnì kan kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi ẹni tí ó bá jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.” Ìyẹn ni ohun tí wọ́n ń fẹ́. Sọ pé: “Ẹ mú ẹ̀rí ọ̀rọ̀ yín wá tí ẹ bá jẹ́ olódodo.

2:112

بَلَىٰۚ مَنۡ أَسۡلَمَ وَجۡهَهُۥ لِلَّهِ وَهُوَ مُحۡسِنٞ فَلَهُۥٓ أَجۡرُهُۥ عِندَ رَبِّهِۦ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿112﴾

Transliteration: Bala man aslama wajhahu lillahi wahuwa muhsinun falahu ajruhu AAinda rabbihi wala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Bẹ́ẹ̀ kọ́ (wọn kò níí wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra àfi) ẹni tí ó bá ju ara rẹ̀ sílẹ̀ (sínú ’Islām) fún Allāhu,tí ó sì jẹ́ olùṣe rere. Nítorí náà, ẹ̀san (rere) rẹ̀ ń bẹ fún un lọ́dọ̀ Olúwa rẹ̀. Kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn.2 Wọn kò sì níí banújẹ́.3

2:113

وَقَالَتِ ٱلۡيَهُودُ لَيۡسَتِ ٱلنَّصَٰرَىٰ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَقَالَتِ ٱلنَّصَٰرَىٰ لَيۡسَتِ ٱلۡيَهُودُ عَلَىٰ شَيۡءٖ وَهُمۡ يَتۡلُونَ ٱلۡكِتَٰبَۗ كَذَٰلِكَ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ مِثۡلَ قَوۡلِهِمۡۚ فَٱللَّهُ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ﴿113﴾

Transliteration: Waqalati alyahoodu laysati alnnasara AAala shayin waqalati alnnasara laysati alyahoodu AAala shayin wahum yatloona alkitaba kathalika qala allatheena la yaAAlamoona mithla qawlihim faAllahu yahkumu baynahum yawma alqiyamati feema kanoo feehi yakhtalifoona

Translation: Àwọn yẹhudi wí pé: “Àwọn nasọ̄rọ̄ kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn).” Àwọn nasọ̄rọ̄ náà wí pé: “Àwọn yẹhudi kò rí n̄ǹkan kan ṣe (nínú ẹ̀sìn.)” Wọ́n sì ń ké Tírà! Báyẹn ni àwọn tí kò nímọ̀ ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Nítorí náà, Allāhu á dájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

2:114

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن مَّنَعَ مَسَٰجِدَ ٱللَّهِ أَن يُذۡكَرَ فِيهَا ٱسۡمُهُۥ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَآۚ أُوْلَـٰٓئِكَ مَا كَانَ لَهُمۡ أَن يَدۡخُلُوهَآ إِلَّا خَآئِفِينَۚ لَهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا خِزۡيٞ وَلَهُمۡ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٞ ﴿114﴾

Transliteration: Waman athlamu mimman manaAAa masajida Allahi an yuthkara feeha ismuhu wasaAAa fee kharabiha olaika ma kana lahum an yadkhulooha illa khaifeena lahum fee alddunya khizyun walahum fee alakhirati AAathabun AAatheemun

Translation: Àti pé ta ló ṣàbòsí ju ẹni tí ó ṣe àwọn mọ́sálásí Allāhu ní èèwọ̀ láti ṣèrántí orúkọ Allāhu nínú rẹ̀, tí ó tún ṣiṣẹ́ lórí ìparun àwọn mọ́sálásí náà?Àwọn wọ̀nyẹn, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti wọ inú rẹ̀ àyàfi pẹ̀lú ìbẹ̀rù. Àbùkù ń bẹ fún wọn n’ílé ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run.

2:115

وَلِلَّهِ ٱلۡمَشۡرِقُ وَٱلۡمَغۡرِبُۚ فَأَيۡنَمَا تُوَلُّواْ فَثَمَّ وَجۡهُ ٱللَّهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ ﴿115﴾

Transliteration: Walillahi almashriqu waalmaghribu faaynama tuwalloo fathamma wajhu Allahi inna Allaha wasiAAun AAaleemun

Translation: Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí wọ́n bá dojú yín kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ojú rere Allāhu (ìyẹn ni pé, ẹ ti dojúkọ Allāhu ní ibi tí wọ́n bá pa yín láṣẹ pé kí ẹ dojúkọ kírun.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.1

2:116

وَقَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ بَل لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ كُلّٞ لَّهُۥ قَٰنِتُونَ ﴿116﴾

Transliteration: Waqaloo itakhatha Allahu waladan subhanahu bal lahu ma fee alssamawati waalardi kullun lahu qanitoona

Translation: Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” Mímọ́ ni fún Un! Ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, (àmọ́) tiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kan sì ni olùtẹ̀lé-àṣẹ Rẹ̀.1

2:117

بَدِيعُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ وَإِذَا قَضَىٰٓ أَمۡرٗا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُۥ كُن فَيَكُونُ ﴿117﴾

Transliteration: BadeeAAu alssamawati waalardi waitha qada amran fainnama yaqoolu lahu kun fayakoonu

Translation: Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni (Allāhu). Nígbà tí Ó bá sì pèbùbù kiní kan, Ó kàn máa sọ fún un pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀.

2:118

وَقَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ لَوۡلَا يُكَلِّمُنَا ٱللَّهُ أَوۡ تَأۡتِينَآ ءَايَةٞۗ كَذَٰلِكَ قَالَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِم مِّثۡلَ قَوۡلِهِمۡۘ تَشَٰبَهَتۡ قُلُوبُهُمۡۗ قَدۡ بَيَّنَّا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يُوقِنُونَ ﴿118﴾

Transliteration: Waqala allatheena la yaAAlamoona lawla yukallimuna Allahu aw tateena ayatun kathalika qala allatheena min qablihim mithla qawlihim tashabahat quloobuhum qad bayyanna alayati liqawmin yooqinoona

Translation: Àwọn tí kò nímọ̀ wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń bá wa sọ̀rọ̀ ni tàbí kí àmì kan wá bá wa (àwa ìbá gbàgbọ́)?” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe sọ irú ọ̀rọ̀ wọn (yìí). Ọkàn wọn jọra wọn. A kúkú ti ṣe àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ní àmọ̀dájú.

2:119

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ بِٱلۡحَقِّ بَشِيرٗا وَنَذِيرٗاۖ وَلَا تُسۡـَٔلُ عَنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡجَحِيمِ ﴿119﴾

Transliteration: Inna arsalnaka bialhaqqi basheeran wanatheeran wala tusalu Aaan ashabi aljaheemi

Translation: Dájúdájú Àwa fi òdodo rán ọ níṣẹ́. (O sì jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀ (fún gbogbo ayé). Wọn kò sì níí bi ọ́ léèrè nípa àwọn èrò inú Iná.

2:120

وَلَن تَرۡضَىٰ عَنكَ ٱلۡيَهُودُ وَلَا ٱلنَّصَٰرَىٰ حَتَّىٰ تَتَّبِعَ مِلَّتَهُمۡۗ قُلۡ إِنَّ هُدَى ٱللَّهِ هُوَ ٱلۡهُدَىٰۗ وَلَئِنِ ٱتَّبَعۡتَ أَهۡوَآءَهُم بَعۡدَ ٱلَّذِي جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ مَا لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن وَلِيّٖ وَلَا نَصِيرٍ ﴿120﴾

Transliteration: Walan tarda AAanka alyahoodu wala alnnasara hatta tattabiAAa millatahum qul inna huda Allahi huwa alhuda walaini ittabaAAta ahwaahum baAAda allathee jaaka mina alAAilmi ma laka mina Allahi min waliyyin wala naseerin

Translation: Àwọn yẹhudi àti nasọ̄rọ̄ kò níí yọ́nú sí ọ títí o fi máa tẹ̀lé ẹ̀sìn wọn. Sọ pé: “Dájúdajú ìmọ̀nà ti Allāhu ni ìmọ̀nà.” Dájúdajú tí o bá sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn èyí tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀ (’Islām), kò níí sí aláàbò àti alárànṣe kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu.

2:121

ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَتۡلُونَهُۥ حَقَّ تِلَاوَتِهِۦٓ أُوْلَـٰٓئِكَ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۗ وَمَن يَكۡفُرۡ بِهِۦ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ ﴿121﴾

Transliteration: Allatheena ataynahumu alkitaba yatloonahu haqqa tilawatihi olaika yuminoona bihi waman yakfur bihi faolaika humu alkhasiroona

Translation: Àwọn tí A fún ní Tírà (al-Ƙur’ān), wọ́n ń ké e ní kíké ẹ̀tọ́. Àwọn wọ̀nyẹn gbà á gbọ́ ní òdodo. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

2:122

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَنِّي فَضَّلۡتُكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿122﴾

Transliteration: Ya banee israeela othkuroo niAAmatiya allatee anAAamtu AAalaykum waannee faddaltukum AAala alAAalameena

Translation: Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìkẹ́ Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò tiyín).1

2:123

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا تَنفَعُهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿123﴾

Transliteration: Waittaqoo yawman la tajzee nafsun AAan nafsin shayan wala yuqbalu minha AAadlun wala tanfaAAuha shafaAAatun wala hum yunsaroona

Translation: Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. A ò sì níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Ìṣìpẹ̀ kan kò níí wúlò fún un. A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.1

2:124

وَإِذِ ٱبۡتَلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ رَبُّهُۥ بِكَلِمَٰتٖ فَأَتَمَّهُنَّۖ قَالَ إِنِّي جَاعِلُكَ لِلنَّاسِ إِمَامٗاۖ قَالَ وَمِن ذُرِّيَّتِيۖ قَالَ لَا يَنَالُ عَهۡدِي ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿124﴾

Transliteration: Waithi ibtala ibraheema rabbuhu bikalimatin faatammahunna qala innee jaAAiluka lilnnasi imaman qala wamin thurriyyatee qala la yanalu AAahdee alththalimeena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa fi àwọn ọ̀rọ̀ kan dán (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm wò. Ó sì parí wọn ní pípé. (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Èmi yó ṣe ọ́ ní aṣíwájú fún àwọn ènìyàn.” (Ànábì ’Ibrọ̄hīm) sọ pé: “Àti nínú àwọn àrọ́mọdọ́mọ mi.” (Allāhu) sọ pé: “Àdéhùn Mi (láti sọ ẹnì kan di Òjíṣẹ́ tàbí Ànábì) kò níí tẹ àwọn alábòsí lọ́wọ́.”

2:125

وَإِذۡ جَعَلۡنَا ٱلۡبَيۡتَ مَثَابَةٗ لِّلنَّاسِ وَأَمۡنٗا وَٱتَّخِذُواْ مِن مَّقَامِ إِبۡرَٰهِـۧمَ مُصَلّٗىۖ وَعَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ أَن طَهِّرَا بَيۡتِيَ لِلطَّآئِفِينَ وَٱلۡعَٰكِفِينَ وَٱلرُّكَّعِ ٱلسُّجُودِ ﴿125﴾

Transliteration: Waith jaAAalna albayta mathabatan lilnnasi waamnan waittakhithoo min maqami ibraheema musallan waAAahidna ila ibraheema waismaAAeela an tahhira baytiya lilttaifeena waalAAakifeena waalrrukkaAAi alssujoodi

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe Ilé (Kaaba) ní àyè tí àwọn ènìyàn yóò máa wá àti àyè ìfàyàbalẹ̀. Kí ẹ sì mú ibùdúró ’Ibrọ̄hīm ní ibùkírun. A sì pa (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) ’Ismọ̄‘īl láṣẹ pé “Ẹ ṣe Ilé Mi ní mímọ́ fún àwọn olùyípo rẹ̀, àwọn olùkóraró sínú rẹ̀ àti àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún, àwọn olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun).

2:126

وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّ ٱجۡعَلۡ هَٰذَا بَلَدًا ءَامِنٗا وَٱرۡزُقۡ أَهۡلَهُۥ مِنَ ٱلثَّمَرَٰتِ مَنۡ ءَامَنَ مِنۡهُم بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ قَالَ وَمَن كَفَرَ فَأُمَتِّعُهُۥ قَلِيلٗا ثُمَّ أَضۡطَرُّهُۥٓ إِلَىٰ عَذَابِ ٱلنَّارِۖ وَبِئۡسَ ٱلۡمَصِيرُ ﴿126﴾

Transliteration: Waith qala ibraheemu rabbi ijAAal hatha baladan aminan waorzuq ahlahu mina alththamarati man amana minhum biAllahi waalyawmi alakhiri qala waman kafara faomattiAAuhu qaleelan thumma adtarruhu ila AAathabi alnnari wabisa almaseeru

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì pèsè àwọn èso fún àwọn ará ibẹ̀ (ìyẹn) ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn.” (Allāhu) sọ pé: “Àti ẹni tí ó bá ṣàì gbàgbọ́, Èmi yóò fún un ní ìgbádùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, Mo máa taari rẹ̀ sínú ìyà Iná. Ìkángun náà sì burú.”

2:127

وَإِذۡ يَرۡفَعُ إِبۡرَٰهِـۧمُ ٱلۡقَوَاعِدَ مِنَ ٱلۡبَيۡتِ وَإِسۡمَٰعِيلُ رَبَّنَا تَقَبَّلۡ مِنَّآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿127﴾

Transliteration: Waith yarfaAAu ibraheemu alqawaAAida mina albayti waismaAAeelu rabbana taqabbal minna innaka anta alssameeAAu alAAaleemu

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti ’Ismọ̄‘īl gbé àwọn ìpìlẹ̀ Ilé náà dúró. (Wọ́n ṣàdúà pé) “Olúwa wa, gbà á lọ́wọ́ wa, dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:128

رَبَّنَا وَٱجۡعَلۡنَا مُسۡلِمَيۡنِ لَكَ وَمِن ذُرِّيَّتِنَآ أُمَّةٗ مُّسۡلِمَةٗ لَّكَ وَأَرِنَا مَنَاسِكَنَا وَتُبۡ عَلَيۡنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿128﴾

Transliteration: Rabbana waijAAalna muslimayni laka wamin thurriyyatina ommatan muslimatan laka waarina manasikana watub AAalayna innaka anta alttawwabu alrraheemu

Translation: Olúwa wa, ṣe wá ní mùsùlùmí fún Ọ. Kí O sì ṣe nínú àrọ́mọdọ́mọ wa ní ìjọ mùsùlùmí fún Ọ. Fi ìlànà ẹ̀sìn wa hàn wá. Kí O sì gba ìronúpìwàdà wa. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:129

رَبَّنَا وَٱبۡعَثۡ فِيهِمۡ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِكَ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَيُزَكِّيهِمۡۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿129﴾

Transliteration: Rabbana waibAAath feehim rasoolan minhum yatloo AAalayhim ayatika wayuAAallimuhumu alkitaba waalhikmata wayuzakkeehim innaka anta alAAazeezu alhakeemu

Translation: Olúwa wa, gbé dìde nínú wọn Òjíṣẹ́ kan láààrin wọn, (ẹni tí) ó máa ké àwọn āyah Rẹ fún wọn, tí ó máa kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì máa sọ wọ́n di ẹni mímọ́. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”

2:130

وَمَن يَرۡغَبُ عَن مِّلَّةِ إِبۡرَٰهِـۧمَ إِلَّا مَن سَفِهَ نَفۡسَهُۥۚ وَلَقَدِ ٱصۡطَفَيۡنَٰهُ فِي ٱلدُّنۡيَاۖ وَإِنَّهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ لَمِنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ ﴿130﴾

Transliteration: Waman yarghabu AAan millati ibraheema illa man safiha nafsahu walaqadi istafaynahu fee alddunya wainnahu fee alakhirati lamina alssaliheena

Translation: Ta sì ni ó máa kọ ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sílẹ̀ àfi ẹni tí ó bá gọ ẹ̀mí ara rẹ̀. A kúkú ti ṣà á lẹ́ṣà n’ílé ayé. Dájúdájú ó tún wà nínú àwọn ẹni rere ní ọ̀run.

2:131

إِذۡ قَالَ لَهُۥ رَبُّهُۥٓ أَسۡلِمۡۖ قَالَ أَسۡلَمۡتُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿131﴾

Transliteration: Ith qala lahu rabbuhu aslim qala aslamtu lirabbi alAAalameena

Translation: (Ẹ rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ mùsùlùmí.” Ó sọ pé: “Mo jẹ́ mùsùlùmí fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

2:132

وَوَصَّىٰ بِهَآ إِبۡرَٰهِـۧمُ بَنِيهِ وَيَعۡقُوبُ يَٰبَنِيَّ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰ لَكُمُ ٱلدِّينَ فَلَا تَمُوتُنَّ إِلَّا وَأَنتُم مُّسۡلِمُونَ ﴿132﴾

Transliteration: Wawassa biha ibraheemu baneehi wayaAAqoobu ya baniyya inna Allaha istafa lakumu alddeena fala tamootunna illa waantum muslimoona

Translation: (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sì pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀. (Ànábì) Ya‘ƙūb náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Ìkíní kejì sọ pé): “Ẹ̀yin ọmọ mi, dájúdájú Allāhu yan ẹ̀sìn náà fún yín. Nítorí náà, ẹ ò gbọdọ̀ kú àyàfi kí ẹ jẹ́ mùsùlùmí.”

2:133

أَمۡ كُنتُمۡ شُهَدَآءَ إِذۡ حَضَرَ يَعۡقُوبَ ٱلۡمَوۡتُ إِذۡ قَالَ لِبَنِيهِ مَا تَعۡبُدُونَ مِنۢ بَعۡدِيۖ قَالُواْ نَعۡبُدُ إِلَٰهَكَ وَإِلَٰهَ ءَابَآئِكَ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ إِلَٰهٗا وَٰحِدٗا وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ ﴿133﴾

Transliteration: Am kuntum shuhadaa ith hadara yaAAqooba almawtu ith qala libaneehi ma taAAbudoona min baAAdee qaloo naAAbudu ilahaka wailaha abaika ibraheema waismaAAeela waishaqa ilahan wahidan wanahnu lahu muslimoona

Translation: Tàbí ẹ̀yín jẹ́ ẹlẹ́rìí nígbà tí ikú dé bá (Ànábì) Ya‘ƙūb? Nígbà tí ó sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Kí ni ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn (ikú) mi?” Wọ́n sọ pé: “Àwa yó máa jọ́sìn fún Ọlọ́hun rẹ àti Ọlọ́hun àwọn bàbá rẹ, (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl àti ’Ishāƙ, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

2:134

تِلۡكَ أُمَّةٞ قَدۡ خَلَتۡۖ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَلَكُم مَّا كَسَبۡتُمۡۖ وَلَا تُسۡـَٔلُونَ عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿134﴾

Transliteration: Tilka ommatun qad khalat laha ma kasabat walakum ma kasabtum wala tusaloona AAamma kano yaAAmaloona

Translation: Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:135

وَقَالُواْ كُونُواْ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰ تَهۡتَدُواْۗ قُلۡ بَلۡ مِلَّةَ إِبۡرَٰهِـۧمَ حَنِيفٗاۖ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿135﴾

Transliteration: Waqaloo koonoo hoodan aw nasara tahtadoo qul bal millata ibraheema haneefan wama kana mina almushrikeena

Translation: Wọ́n wí pé: “Ẹ jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄ kí ẹ mọ̀nà.” Sọ pé: “Rárá, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm (lẹ̀sìn), ó jẹ́ olùdúró-déédé, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

2:136

قُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱللَّهِ وَمَآ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَمَآ أُنزِلَ إِلَىٰٓ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطِ وَمَآ أُوتِيَ مُوسَىٰ وَعِيسَىٰ وَمَآ أُوتِيَ ٱلنَّبِيُّونَ مِن رَّبِّهِمۡ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّنۡهُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ ﴿136﴾

Transliteration: Qooloo amanna biAllahi wama onzila ilayna wama onzila ila ibraheema waismaAAeela waishaqa wayaAAqooba waalasbati wama ootiya moosa waAAeesa wama ootiya alnnabiyyoona min rabbihim la nufarriqu bayna ahadin minhum wanahnu lahu muslimoona

Translation: Ẹ sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

2:137

فَإِنۡ ءَامَنُواْ بِمِثۡلِ مَآ ءَامَنتُم بِهِۦ فَقَدِ ٱهۡتَدَواْۖ وَّإِن تَوَلَّوۡاْ فَإِنَّمَا هُمۡ فِي شِقَاقٖۖ فَسَيَكۡفِيكَهُمُ ٱللَّهُۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿137﴾

Transliteration: Fain amanoo bimithli ma amantum bihi faqadi ihtadaw wain tawallaw fainnama hum fee shiqaqin fasayakfeekahumu Allahu wahuwa alssameeAAu alAAaleemu

Translation: Nítorí náà, tí wọ́n bá gbàgbọ́ nínú irú ohun tí ẹ gbàgbọ́, wọ́n ti mọ̀nà. Tí wọ́n bá sì gbúnrí, wọ́n ti wà nínú ìyapa (òdodo). Allāhu sì máa tó ọ (níbi aburú) wọn. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:138

صِبۡغَةَ ٱللَّهِ وَمَنۡ أَحۡسَنُ مِنَ ٱللَّهِ صِبۡغَةٗۖ وَنَحۡنُ لَهُۥ عَٰبِدُونَ ﴿138﴾

Transliteration: Sibghata Allahi waman ahsanu mina Allahi sibghatan wanahnu lahu AAabidoona

Translation: (Ẹ dúró ti) aró Allāhu. Ta sì ló dára ju Allāhu lọ ní aró? Àwa sì ni olùjọ́sìn fún Un.1

2:139

قُلۡ أَتُحَآجُّونَنَا فِي ٱللَّهِ وَهُوَ رَبُّنَا وَرَبُّكُمۡ وَلَنَآ أَعۡمَٰلُنَا وَلَكُمۡ أَعۡمَٰلُكُمۡ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُخۡلِصُونَ ﴿139﴾

Transliteration: Qul atuhajjoonana fee Allahi wahuwa rabbuna warabbukum walana aAAmaluna walakum aAAmalukum wanahnu lahu mukhlisoona

Translation: Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò jà wá níyàn nípa Allāhu ni?” Òun sì ni Olúwa wa àti Olúwa yín. Tiwa ni àwọn iṣẹ́ wa. Tiyín sì ni àwọn iṣẹ́ yín. Àwa (mùsùlùmí) sì ni olùṣàfọ̀mọ́-ẹ̀sìn fún Un.

2:140

أَمۡ تَقُولُونَ إِنَّ إِبۡرَٰهِـۧمَ وَإِسۡمَٰعِيلَ وَإِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَ وَٱلۡأَسۡبَاطَ كَانُواْ هُودًا أَوۡ نَصَٰرَىٰۗ قُلۡ ءَأَنتُمۡ أَعۡلَمُ أَمِ ٱللَّهُۗ وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَتَمَ شَهَٰدَةً عِندَهُۥ مِنَ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿140﴾

Transliteration: Am taqooloona inna ibraheema waismaAAeela waishaqa wayaAAqooba waalasbata kanoo hoodan aw nasara qul aantum aAAlamu ami Allahu waman athlamu mimman katama shahadatan AAindahu mina Allahi wama Allahu bighafilin AAamma taAAmaloona

Translation: Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.”Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:141

تِلۡكَ أُمَّةٞ قَدۡ خَلَتۡۖ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَلَكُم مَّا كَسَبۡتُمۡۖ وَلَا تُسۡـَٔلُونَ عَمَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿141﴾

Transliteration: Tilka ommatun qad khalat laha ma kasabat walakum ma kasabtum wala tusaloona AAamma kanoo yaAAmaloona

Translation: Ìjọ kan nìyẹn tí ó ti lọ. Tiwọn ni ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Tiyín ni ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí bi yín léèrè nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:142

سَيَقُولُ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَ ٱلنَّاسِ مَا وَلَّىٰهُمۡ عَن قِبۡلَتِهِمُ ٱلَّتِي كَانُواْ عَلَيۡهَاۚ قُل لِّلَّهِ ٱلۡمَشۡرِقُ وَٱلۡمَغۡرِبُۚ يَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿142﴾

Transliteration: Sayaqoolu alssufahao mina alnnasi ma wallahum AAan qiblatihimu allatee kanoo AAalayha qul lillahi almashriqu waalmaghribu yahdee man yashao ila siratin mustaqeemin

Translation: Àwọn òmùgọ̀ nínú àwọn ènìyàn máa wí pé: “Kí ni ó mú wọn yí kúrò níbi Ƙiblah wọn tí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).”

2:143

وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَٰكُمۡ أُمَّةٗ وَسَطٗا لِّتَكُونُواْ شُهَدَآءَ عَلَى ٱلنَّاسِ وَيَكُونَ ٱلرَّسُولُ عَلَيۡكُمۡ شَهِيدٗاۗ وَمَا جَعَلۡنَا ٱلۡقِبۡلَةَ ٱلَّتِي كُنتَ عَلَيۡهَآ إِلَّا لِنَعۡلَمَ مَن يَتَّبِعُ ٱلرَّسُولَ مِمَّن يَنقَلِبُ عَلَىٰ عَقِبَيۡهِۚ وَإِن كَانَتۡ لَكَبِيرَةً إِلَّا عَلَى ٱلَّذِينَ هَدَى ٱللَّهُۗ وَمَا كَانَ ٱللَّهُ لِيُضِيعَ إِيمَٰنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِٱلنَّاسِ لَرَءُوفٞ رَّحِيمٞ ﴿143﴾

Transliteration: Wakathalika jaAAalnakum ommatan wasatan litakoonoo shuhadaa AAala alnnasi wayakoona alrrasoolu AAalaykum shaheedan wama jaAAalna alqiblata allatee kunta AAalayha illa linaAAlama man yattabiAAu alrrasoola mimman yanqalibu AAala AAaqibayhi wain kanat lakabeeratan illa AAala allatheena hada Allahu wama kana Allahu liyudeeAAa eemanakum inna Allaha bialnnasi laraoofun raheemun

Translation: Báyẹn ni A ṣe yín ní ẹ̀ṣà ìjọ tó lóore jùlọ, nítorí kí ẹ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn àti nítorí kí Òjíṣẹ́ náà lè jẹ́ ẹlẹ́rìí fún yín. A kò sì ṣe Ƙiblah tí o wà lórí rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ibùkọjú-kírun bí kò ṣe pé nítorí kí Á lè ṣe àfihàn ẹni tí ó máa tẹ̀lé Òjíṣẹ́ yàtọ̀ sí ẹni tí ó máa yísẹ̀ padà. Dájúdájú ó lágbára àyàfi fún àwọn tí Allāhu tọ́ sọ́nà. Allāhu kò sì níí fi ìgbàgbọ́ yín ráre. Dájúdájú Allāhu ni Aláàánú, Oníkẹ̀ẹ́ fún àwọn ènìyàn.

2:144

قَدۡ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجۡهِكَ فِي ٱلسَّمَآءِۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبۡلَةٗ تَرۡضَىٰهَاۚ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥۗ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ لَيَعۡلَمُونَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعۡمَلُونَ ﴿144﴾

Transliteration: Qad nara taqalluba wajhika fee alssamai falanuwalliyannaka qiblatan tardaha fawalli wajhaka shatra almasjidi alharami wahaythu ma kuntum fawalloo wujoohakum shatrahu wainna allatheena ootoo alkitaba layaAAlamoona annahu alhaqqu min rabbihim wama Allahu bighafilin AAamma yaAAmaloona

Translation: A kúkú rí yíyí tí ò ń yí ojú rẹ sí sánmọ̀. Nítorí náà, dájúdájú A óò dojú rẹ kọ Ƙiblah kan tí o yọ́nú sí; nítorí náà, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram (ní Mọkkah). Ibikíbi tí ẹ bá tún wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀. Dájúdájú àwọn tí A fún ní Tírà kúkú mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni (àṣẹ Ƙiblah) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:145

وَلَئِنۡ أَتَيۡتَ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡكِتَٰبَ بِكُلِّ ءَايَةٖ مَّا تَبِعُواْ قِبۡلَتَكَۚ وَمَآ أَنتَ بِتَابِعٖ قِبۡلَتَهُمۡۚ وَمَا بَعۡضُهُم بِتَابِعٖ قِبۡلَةَ بَعۡضٖۚ وَلَئِنِ ٱتَّبَعۡتَ أَهۡوَآءَهُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَكَ مِنَ ٱلۡعِلۡمِ إِنَّكَ إِذٗا لَّمِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿145﴾

Transliteration: Walain atayta allatheena ootoo alkitaba bikulli ayatin ma tabiAAoo qiblataka wama anta bitabiAAin qiblatahum wama baAAduhum bitabiAAin qiblata baAAdin walaini ittabaAAta ahwaahum min baAAdi ma jaaka mina alAAilmi innaka ithan lamina alththalimeena

Translation: Dájúdájú tí o bá fún àwọn tí A fún ní Tírà ní gbogbo āyah, wọn kò níí tẹ̀lé Ƙiblah rẹ. Ìwọ náà kò gbọdọ̀ tẹ̀lé Ƙiblah wọn. Apá kan wọn kò sì níí tẹ̀lé Ƙiblah apá kan. Dájúdájú tí o bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú wọn lẹ́yìn ohun tí ó dé bá ọ nínú ìmọ̀, dájúdájú nígbà náà ìwọ wà nínú àwọn alábòsí.

2:146

ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَعۡرِفُونَهُۥ كَمَا يَعۡرِفُونَ أَبۡنَآءَهُمۡۖ وَإِنَّ فَرِيقٗا مِّنۡهُمۡ لَيَكۡتُمُونَ ٱلۡحَقَّ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ ﴿146﴾

Transliteration: Allatheena ataynahumu alkitaba yaAArifoonahu kama yaAArifoona abnaahum wainna fareeqan minhum layaktumoona alhaqqa wahum yaAAlamoona

Translation: Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Dájúdájú àwọn ìjọ kan wà nínú wọn tí wọ́n kúkú ń fi òdodo pamọ́, wọ́n sì mọ̀.

2:147

ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ﴿147﴾

Transliteration: Alhaqqu min rabbika fala takoonanna mina almumtareena

Translation: Òdodo náà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

2:148

وَلِكُلّٖ وِجۡهَةٌ هُوَ مُوَلِّيهَاۖ فَٱسۡتَبِقُواْ ٱلۡخَيۡرَٰتِۚ أَيۡنَ مَا تَكُونُواْ يَأۡتِ بِكُمُ ٱللَّهُ جَمِيعًاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿148﴾

Transliteration: Walikullin wijhatun huwa muwalleeha faistabiqoo alkhayrati ayna ma takoonoo yati bikumu Allahu jameeAAan inna Allaha AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Ìkọ̀ọ̀kan (ìjọ ẹlẹ́sìn) ló ní ibùkọjúsí tó ń kọjú sí. Nítorí náà, ẹ yára gbawájú níbi àwọn iṣẹ́ rere. Ibikíbi tí ẹ bá wà, Allāhu yóò mú gbogbo yín wá (ní Ọjọ́ Àjíǹde). Dájúdájú Alágbára ni Allāhu lórí gbogbo n̄ǹkan.

2:149

وَمِنۡ حَيۡثُ خَرَجۡتَ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۖ وَإِنَّهُۥ لَلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿149﴾

Transliteration: Wamin haythu kharajta fawalli wajhaka shatra almasjidi alharami wainnahu lalhaqqu min rabbika wama Allahu bighafilin AAamma taAAmaloona

Translation: Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram, nítorí pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:150

وَمِنۡ حَيۡثُ خَرَجۡتَ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَيۡكُمۡ حُجَّةٌ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡ فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِي وَلِأُتِمَّ نِعۡمَتِي عَلَيۡكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿150﴾

Transliteration: Wamin haythu kharajta fawalli wajhaka shatra almasjidi alharami wahaythu ma kuntum fawalloo wujoohakum shatrahu lialla yakoona lilnnasi AAalaykum hujjatun illa allatheena thalamoo minhum fala takhshawhum waikhshawnee waliotimma niAAmatee AAalaykum walaAAallakum tahtadoona

Translation: Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀,nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fún yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.

2:151

كَمَآ أَرۡسَلۡنَا فِيكُمۡ رَسُولٗا مِّنكُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِنَا وَيُزَكِّيكُمۡ وَيُعَلِّمُكُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَيُعَلِّمُكُم مَّا لَمۡ تَكُونُواْ تَعۡلَمُونَ ﴿151﴾

Transliteration: Kama arsalna feekum rasoolan minkum yatloo AAalaykum ayatina wayuzakkeekum wayuAAallimukumu alkitaba waalhikmata wayuAAallimukum ma lam takoonoo taAAlamoona

Translation: Gẹ́gẹ́ bí A ṣe rán Òjíṣẹ́ kan si yín láààrin ara yín,tí ó ń ké àwọn āyah Wa fún yín, tí ó ń sọ yín di ẹni mímọ́, tí ó ń kọ yín ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (sunnah), tí ó sì ń kọ yín ní ohun tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀,

2:152

فَٱذۡكُرُونِيٓ أَذۡكُرۡكُمۡ وَٱشۡكُرُواْ لِي وَلَا تَكۡفُرُونِ ﴿152﴾

Transliteration: Faothkuroonee athkurkum waoshkuroo lee wala takfurooni

Translation: nítorí náà, ẹ rántí Mi, Kí N̄g rántí yín.Ẹ dúpẹ́ fún Mi, ẹ má ṣàì moore sí Mi.

2:153

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱسۡتَعِينُواْ بِٱلصَّبۡرِ وَٱلصَّلَوٰةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ ﴿153﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo istaAAeenoo bialssabri waalssalati inna Allaha maAAa alssabireena

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo,ẹ fi sùúrù àti ìrun kíkí tọrọ oore (lọ́dọ̀ Allāhu). Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù.

2:154

وَلَا تَقُولُواْ لِمَن يُقۡتَلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمۡوَٰتُۢۚ بَلۡ أَحۡيَآءٞ وَلَٰكِن لَّا تَشۡعُرُونَ ﴿154﴾

Transliteration: Wala taqooloo liman yuqtalu fee sabeeli Allahi amwatun bal ahyaon walakin la tashAAuroona

Translation: Ẹ má ṣe pe àwọn tí wọ́n ń pa sí ojú-ogun ẹ̀sìn Allāhu ní òkú (ìyà), àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fura.1

2:155

وَلَنَبۡلُوَنَّكُم بِشَيۡءٖ مِّنَ ٱلۡخَوۡفِ وَٱلۡجُوعِ وَنَقۡصٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡوَٰلِ وَٱلۡأَنفُسِ وَٱلثَّمَرَٰتِۗ وَبَشِّرِ ٱلصَّـٰبِرِينَ ﴿155﴾

Transliteration: Walanabluwannakum bishayin mina alkhawfi waaljooAAi wanaqsin mina alamwali waalanfusi waalththamarati wabashshiri alssabireena

Translation: Dájúdájú A ó máa dán-an yín wò pẹ̀lú kiní kan látara ẹ̀rù, ebi, àdínkù nínú àwọn dúkìá, àwọn ẹ̀mí àti àwọn èso. Kí o sì fún àwọn onísùúrù ní ìró ìdùnnú.

2:156

ٱلَّذِينَ إِذَآ أَصَٰبَتۡهُم مُّصِيبَةٞ قَالُوٓاْ إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّآ إِلَيۡهِ رَٰجِعُونَ ﴿156﴾

Transliteration: Allatheena itha asabathum museebatun qaloo inna lillahi wainna ilayhi rajiAAoona

Translation: Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí àdánwò kan bá kàn wọ́n, wọ́n á sọ pé: “Dájúdájú Allāhu l’Ó ni àwa; dájúdájú ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwa yóò padà sí.”

2:157

أُوْلَـٰٓئِكَ عَلَيۡهِمۡ صَلَوَٰتٞ مِّن رَّبِّهِمۡ وَرَحۡمَةٞۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُهۡتَدُونَ ﴿157﴾

Transliteration: Olaika AAalayhim salawatun min rabbihim warahmatun waolaika humu almuhtadoona

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àforíjìn àti ìkẹ́ yó máa bẹ fún láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùmọ̀nà.

2:158

إِنَّ ٱلصَّفَا وَٱلۡمَرۡوَةَ مِن شَعَآئِرِ ٱللَّهِۖ فَمَنۡ حَجَّ ٱلۡبَيۡتَ أَوِ ٱعۡتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِ أَن يَطَّوَّفَ بِهِمَاۚ وَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَإِنَّ ٱللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ ﴿158﴾

Transliteration: Inna alssafa waalmarwata min shaAAairi Allahi faman hajja albayta awi iAAtamara fala junaha AAalayhi an yattawwafa bihima waman tatawwaAAa khayran fainna Allaha shakirun AAaleemun

Translation: Dájúdájú (àpáta) Sọfā àti (àpáta) Mọrwah wà nínú àwọn àríṣàmì fún ẹ̀sìn Allāhu. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ Hajj sí Ilé náà tàbí ó ṣe iṣẹ́ ‘Umrah, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un láti rìn yíká (láààrin àpáta) méjèèjì. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fínnú-fíndọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣegbọrẹ, dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́pẹ́Onímọ̀.

2:159

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡتُمُونَ مَآ أَنزَلۡنَا مِنَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلۡهُدَىٰ مِنۢ بَعۡدِ مَا بَيَّنَّـٰهُ لِلنَّاسِ فِي ٱلۡكِتَٰبِ أُوْلَـٰٓئِكَ يَلۡعَنُهُمُ ٱللَّهُ وَيَلۡعَنُهُمُ ٱللَّـٰعِنُونَ ﴿159﴾

Transliteration: Inna allatheena yaktumoona ma anzalna mina albayyinati waalhuda min baAAdi ma bayyannahu lilnnasi fee alkitabi olaika yalAAanuhumu Allahu wayalAAanuhumu allaAAinoona

Translation: Dájúdájú àwọn tó ń daṣọ bo ohun tí A sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ẹ̀rí tó yanjú àti ìmọ̀nà, lẹ́yìn tí A ti ṣe àlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn sínú Tírà, àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ń ṣẹ́bi lé. Àwọn olùṣẹ́bi sì ń ṣẹ́bi lé wọn.

2:160

إِلَّا ٱلَّذِينَ تَابُواْ وَأَصۡلَحُواْ وَبَيَّنُواْ فَأُوْلَـٰٓئِكَ أَتُوبُ عَلَيۡهِمۡ وَأَنَا ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿160﴾

Transliteration: Illa allatheena taboo waaslahoo wabayyanoo faolaika atoobu AAalayhim waana alttawwabu alrraheemu

Translation: Àyàfi àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n ṣe àtúnṣe, tí wọ́n sì ṣàfi hàn òdodo, nítorí náà, àwọn wọ̀nyẹn ni Mo máa gba ìronúpìwàdà wọn. Èmi sì ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:161

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَمَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٌ أُوْلَـٰٓئِكَ عَلَيۡهِمۡ لَعۡنَةُ ٱللَّهِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ ﴿161﴾

Transliteration: Inna allatheena kafaroo wamatoo wahum kuffarun olaika AAalayhim laAAnatu Allahi waalmalaikati waalnnasi ajmaAAeena

Translation: Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni ègún Allāhu, àti (ègún) àwọn mọlāika àti (ègún) ènìyàn pátápátá ń bẹ lórí wọn.

2:162

خَٰلِدِينَ فِيهَا لَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ ﴿162﴾

Transliteration: Khalideena feeha la yukhaffafu AAanhumu alAAathabu wala hum yuntharoona

Translation: Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. A ò níí ṣe ìyà náà ní fífúyẹ́ fún wọn A ò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).

2:163

وَإِلَٰهُكُمۡ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞۖ لَّآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلرَّحۡمَٰنُ ٱلرَّحِيمُ ﴿163﴾

Transliteration: Wailahukum ilahun wahidun la ilaha illa huwa alrrahmanu alrraheemu

Translation: Ọlọ́hun yín tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo, Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo ni. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Àjọkẹ́-ayé, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:164

إِنَّ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱلۡفُلۡكِ ٱلَّتِي تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِمَا يَنفَعُ ٱلنَّاسَ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن مَّآءٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٖ وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ وَٱلسَّحَابِ ٱلۡمُسَخَّرِ بَيۡنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ﴿164﴾

Transliteration: Inna fee khalqi alssamawati waalardi waikhtilafi allayli waalnnahari waalfulki allatee tajree fee albahri bima yanfaAAu alnnasa wama anzala Allahu mina alssamai min main faahya bihi alarda baAAda mawtiha wabaththa feeha min kulli dabbatin watasreefi alrriyahi waalssahabi almusakhkhari bayna alssamai waalardi laayatin liqawmin yaAAqiloona

Translation: Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn lórí omi pẹ̀lú (ríru) ohun tó ń ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní omi láti sánmọ̀, tí Ó sì ń fi sọ ilẹ̀ di ààyè lẹ́yìn tí ó ti kú, àti (bí) Ó ṣe fọ́n gbogbo ẹranko ká sí orí ilẹ̀, àti ìyípadà atẹ́gùnàti ẹ̀ṣújò tí A tẹ̀ba láààrin sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

2:165

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَتَّخِذُ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَندَادٗا يُحِبُّونَهُمۡ كَحُبِّ ٱللَّهِۖ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَشَدُّ حُبّٗا لِّلَّهِۗ وَلَوۡ يَرَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُوٓاْ إِذۡ يَرَوۡنَ ٱلۡعَذَابَ أَنَّ ٱلۡقُوَّةَ لِلَّهِ جَمِيعٗا وَأَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعَذَابِ ﴿165﴾

Transliteration: Wamina alnnasi man yattakhithu min dooni Allahi andadan yuhibboonahum kahubbi Allahi waallatheena amanoo ashaddu hubban lillahi walaw yara allatheena thalamoo ith yarawna alAAathaba anna alquwwata lillahi jameeAAan waanna Allaha shadeedu alAAathabi

Translation: Ó sì ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ó ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ (tó yẹ kí wọ́n ní sí) Allāhu. Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sì le jùlọ nínú ìfẹ́ sí Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàbòsí lè rí ìgbà tí wọ́n máa rí Ìyà náà ni, (wọn ìbá mọ̀ pé) dájúdájú gbogbo agbára ń jẹ́ ti Allāhu. Àti pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.

2:166

إِذۡ تَبَرَّأَ ٱلَّذِينَ ٱتُّبِعُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُواْ وَرَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَ وَتَقَطَّعَتۡ بِهِمُ ٱلۡأَسۡبَابُ ﴿166﴾

Transliteration: Ith tabarraa allatheena ittubiAAoo mina allatheena ittabaAAoo waraawoo alAAathaba wataqattaAAat bihimu alasbabu

Translation: (Rántí) nígbà tí àwọn tí wọ́n tẹ̀lé (ìyẹn àwọn aṣíwájú kèfèrí) bá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ àwọn tó tẹ̀lé wọn; (nígbà tí) wọ́n bá fojú rí Ìyà, tí ohun tó so wọ́n pọ̀ sì já pátápátá.

2:167

وَقَالَ ٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُواْ لَوۡ أَنَّ لَنَا كَرَّةٗ فَنَتَبَرَّأَ مِنۡهُمۡ كَمَا تَبَرَّءُواْ مِنَّاۗ كَذَٰلِكَ يُرِيهِمُ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡ حَسَرَٰتٍ عَلَيۡهِمۡۖ وَمَا هُم بِخَٰرِجِينَ مِنَ ٱلنَّارِ ﴿167﴾

Transliteration: Waqala allatheena ittabaAAoo law anna lana karratan fanatabarraa minhum kama tabarraoo minna kathalika yureehimu Allahu aAAmalahum hasaratin AAalayhim wama hum bikharijeena mina alnnari

Translation: Àwọn tó tẹ̀lé wọn yó sì wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ìpadàwáyé lè wà fún wa ni, àwa ìbá yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ wa.” Báyẹn ni Allāhu yó ṣe fi àwọn iṣẹ́ wọn hàn wọ́n ní (iṣẹ́) òfò fún wọn. Wọn kò sì níí jáde kúrò nínú Iná.

2:168

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ كُلُواْ مِمَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ حَلَٰلٗا طَيِّبٗا وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٌ ﴿168﴾

Transliteration: Ya ayyuha alnnasu kuloo mimma fee alardi halalan tayyiban wala tattabiAAoo khutuwati alshshaytani innahu lakum AAaduwwun mubeenun

Translation: Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ jẹ nínú ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ (tó jẹ́) ẹ̀tọ́ (àti n̄ǹkan) dáadáa. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

2:169

إِنَّمَا يَأۡمُرُكُم بِٱلسُّوٓءِ وَٱلۡفَحۡشَآءِ وَأَن تَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿169﴾

Transliteration: Innama yamurukum bialssooi waalfahshai waan taqooloo AAala Allahi ma la taAAlamoona

Translation: Ohun tí ó máa pa yín ní àṣẹ rẹ̀ ni (iṣẹ́) aburú, ìbàjẹ́ àti pé kí ẹ máa pa irọ́ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ Allāhu.

2:170

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّبِعُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ بَلۡ نَتَّبِعُ مَآ أَلۡفَيۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَآۚ أَوَلَوۡ كَانَ ءَابَآؤُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ شَيۡـٔٗا وَلَا يَهۡتَدُونَ ﴿170﴾

Transliteration: Waitha qeela lahumu ittabiAAoo ma anzala Allahu qaloo bal nattabiAAu ma alfayna AAalayhi abaana awalaw kana abaohum la yaAAqiloona shayan wala yahtadoona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá, A óò máa tẹ̀lé ohun tí a bá l’ọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” Ṣé pẹ̀lú bí ó ṣe jẹ́ pé àwọn bàbá wọn kò ṣe làákàyè kan kan (nípa ẹ̀sìn), tí wọn kò sì mọ̀nà?

2:171

وَمَثَلُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ كَمَثَلِ ٱلَّذِي يَنۡعِقُ بِمَا لَا يَسۡمَعُ إِلَّا دُعَآءٗ وَنِدَآءٗۚ صُمُّۢ بُكۡمٌ عُمۡيٞ فَهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ ﴿171﴾

Transliteration: Wamathalu allatheena kafaroo kamathali allathee yanAAiqu bima la yasmaAAu illa duAAaan wanidaan summun bukmun AAumyun fahum la yaAAqiloona

Translation: Àpèjúwe àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ dà bí àpèjúwe ẹni tí ó ń kígbe (mọ́ ẹranko) tí kò gbọ́rọ̀ bí kò ṣe ìpè àti igbe (asán). Adití, ayaya, afọ́jú ni wọ́n; wọn kò sì níí ṣe làákàyè.

2:172

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَٱشۡكُرُواْ لِلَّهِ إِن كُنتُمۡ إِيَّاهُ تَعۡبُدُونَ ﴿172﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo kuloo min tayyibati ma razaqnakum waoshkuroo lillahi in kuntum iyyahu taAAbudoona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín, kí ẹ sì dúpẹ́ fún Allāhu tí ó bá jẹ́ pé Òun nìkan ṣoṣo ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.

2:173

إِنَّمَا حَرَّمَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَيۡتَةَ وَٱلدَّمَ وَلَحۡمَ ٱلۡخِنزِيرِ وَمَآ أُهِلَّ بِهِۦ لِغَيۡرِ ٱللَّهِۖ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ ﴿173﴾

Transliteration: Innama harrama AAalaykumu almaytata waalddama walahma alkhinzeeri wama ohilla bihi lighayri Allahi famani idturra ghayra baghin wala AAadin fala ithma AAalayhi inna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Ohun tí (Allāhu) ṣe ní èèwọ̀ fún yín ni òkúǹbete ẹ̀jẹ̀2, ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun tí wọ́n pe orúkọ mìíràn lé lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Ṣùgbọ́n ẹni tí ìnira (ebi) bá mú (jẹ ẹran èèwọ̀), tí kì í ṣe ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.3

2:174

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡتُمُونَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَيَشۡتَرُونَ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلًا أُوْلَـٰٓئِكَ مَا يَأۡكُلُونَ فِي بُطُونِهِمۡ إِلَّا ٱلنَّارَ وَلَا يُكَلِّمُهُمُ ٱللَّهُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وَلَا يُزَكِّيهِمۡ وَلَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٌ ﴿174﴾

Transliteration: Inna allatheena yaktumoona ma anzala Allahu mina alkitabi wayashtaroona bihi thamanan qaleelan olaika ma yakuloona fee butoonihim illa alnnara wala yukallimuhumu Allahu yawma alqiyamati wala yuzakkeehim walahum AAathabun aleemun

Translation: Dájúdájú àwọn tó ń daṣọ bo ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ nínú Tírà, tí wọ́n sì ń tà á ní owó pọ́ọ́kú, àwọn wọ̀nyẹn kò jẹ kiní kan sí inú wọn bí kò ṣe Iná. Allāhu kò sì níí bá wọn sọ̀rọ̀ (ìdùnnú) ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sì níí fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún wọn.

2:175

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلضَّلَٰلَةَ بِٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡعَذَابَ بِٱلۡمَغۡفِرَةِۚ فَمَآ أَصۡبَرَهُمۡ عَلَى ٱلنَّارِ ﴿175﴾

Transliteration: Olaika allatheena ishtarawoo alddalalata bialhuda waalAAathaba bialmaghfirati fama asbarahum AAala alnnari

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó fi ìmọ̀nà ra ìṣìnà, (wọ́n tún fi) àforíjìn ra ìyà.Ṣé wọn sì lè ṣèfaradà fún Iná! (Àbí kí ló kì wọ́n láyà láti ṣe iṣẹ́ Iná!)

2:176

ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ نَزَّلَ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّۗ وَإِنَّ ٱلَّذِينَ ٱخۡتَلَفُواْ فِي ٱلۡكِتَٰبِ لَفِي شِقَاقِۭ بَعِيدٖ ﴿176﴾

Transliteration: Thalika bianna Allaha nazzala alkitaba bialhaqqi wainna allatheena ikhtalafoo fee alkitabi lafee shiqaqin baAAeedin

Translation: Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé dájúdájú Allāhu sọ Tírà (al-Ƙur’ān) kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Dájúdájú àwọn tó sì yapa Tírà náà kúkú ti wà nínú ìyapà tó jìnnà (sí òdodo).

2:177

لَّيۡسَ ٱلۡبِرَّ أَن تُوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ قِبَلَ ٱلۡمَشۡرِقِ وَٱلۡمَغۡرِبِ وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ وَٱلۡكِتَٰبِ وَٱلنَّبِيِّـۧنَ وَءَاتَى ٱلۡمَالَ عَلَىٰ حُبِّهِۦ ذَوِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينَ وَٱبۡنَ ٱلسَّبِيلِ وَٱلسَّآئِلِينَ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَأَقَامَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَى ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلۡمُوفُونَ بِعَهۡدِهِمۡ إِذَا عَٰهَدُواْۖ وَٱلصَّـٰبِرِينَ فِي ٱلۡبَأۡسَآءِ وَٱلضَّرَّآءِ وَحِينَ ٱلۡبَأۡسِۗ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ صَدَقُواْۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُتَّقُونَ ﴿177﴾

Transliteration: Laysa albirra an tuwalloo wujoohakum qibala almashriqi waalmaghribi walakinna albirra man amana biAllahi waalyawmi alakhiri waalmalaikati waalkitabi waalnnabiyyeena waata almala AAala hubbihi thawee alqurba waalyatama waalmasakeena waibna alssabeeli waalssaileena wafee alrriqabi waaqama alssalata waata alzzakata waalmoofoona biAAahdihim itha AAahadoo waalssabireena fee albasai waalddarrai waheena albasi olaika allatheena sadaqoo waolaika humu almuttaqoona

Translation: Kì í ṣe ohun rere ni pé, kí ẹ kọjú sí agbègbè ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn,àmọ́ (olùṣe) rere ni ẹnikẹ́ni tó bá gbàgbọ́ nínú Allāhu, Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, àwọn mọlāika, Tírà (al-Ƙur’ān), àti àwọn Ànábì. Tòhun ti ìfẹ́ tí olùṣe-rere ní sí dúkìá, ó tún ń fi dúkìá náà tọrẹ fún àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù, onírìn-àjò (tí agara dá), àwọn atọrọjẹ àti fún ìtúsílẹ̀ ẹrú l’óko ẹrú. (Ẹni rere) yó máa kírun, yó sì máa yọ Zakāh. (Ẹni rere ni) àwọn tó ń mú àdéhùn wọn ṣẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe àdéhùn. (Wọ́n jẹ́) onísùúrù lásìkò ìpọ́njú, lásìkò àìlera àti l’ójú ogun ẹ̀sìn. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tó ṣe (iṣẹ́) òdodo. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn sì ni olùbẹ̀rù (Allāhu).

2:178

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِصَاصُ فِي ٱلۡقَتۡلَىۖ ٱلۡحُرُّ بِٱلۡحُرِّ وَٱلۡعَبۡدُ بِٱلۡعَبۡدِ وَٱلۡأُنثَىٰ بِٱلۡأُنثَىٰۚ فَمَنۡ عُفِيَ لَهُۥ مِنۡ أَخِيهِ شَيۡءٞ فَٱتِّبَاعُۢ بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَأَدَآءٌ إِلَيۡهِ بِإِحۡسَٰنٖۗ ذَٰلِكَ تَخۡفِيفٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَرَحۡمَةٞۗ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ بَعۡدَ ذَٰلِكَ فَلَهُۥ عَذَابٌ أَلِيمٞ ﴿178﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo kutiba AAalaykumu alqisasu fee alqatla alhurru bialhurri waalAAabdu bialAAabdi waalontha bialontha faman AAufiya lahu min akheehi shayon faittibaAAun bialmaAAroofi waadaon ilayhi biihsanin thalika takhfeefun min rabbikum warahmatun famani iAAtada baAAda thalika falahu AAathabun aleemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ẹ̀san gbígbà níbi ìpànìyàn ní ọ̀ran-anyàn fún yín. Olómìnira fún olómìnira, ẹrú fún ẹrú, obìnrin fún obìnrin. Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ṣàmójú kúrò kiní kan fún láti ọ̀dọ̀ arákùnrin rẹ̀ (ìyẹn ni pé, ti aláṣẹ ẹni tí wọ́n pa bá gbà láti gba owó ẹ̀mí dípò fífi ẹ̀mí apànìyàn dí ẹ̀mí ẹni tí wọ́n pa, kí ẹni tí ó gba owó ẹ̀mí dípò ẹ̀mí) ṣe dáadáa tẹ̀lé (owó tí ó gbà, ìyẹn ni pé, kí ó fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba owó ẹ̀mí náà. Àti pé kí ẹni tí ó máa san owó ẹ̀mí) san ań fún un ní ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni ìgbéfúyẹ́ àti àánú láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà (òfin) lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.

2:179

وَلَكُمۡ فِي ٱلۡقِصَاصِ حَيَوٰةٞ يَـٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿179﴾

Transliteration: Walakum fee alqisasi hayatun ya olee alalbabi laAAallakum tattaqoona

Translation: Ìsẹ̀mí wà fún yín nínú (òfin) ìgbẹ̀san, ẹ̀yin onílàákáyè, kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).

2:180

كُتِبَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ إِن تَرَكَ خَيۡرًا ٱلۡوَصِيَّةُ لِلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَ بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُتَّقِينَ ﴿180﴾

Transliteration: Kutiba AAalaykum itha hadara ahadakumu almawtu in taraka khayran alwasiyyatu lilwalidayni waalaqrabeena bialmaAAroofi haqqan AAala almuttaqeena

Translation: A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún yín, nígbà tí (àwọn àmì) ikúbá dé bá ẹnì kan nínú yín, tí ó sì máa fi dúkìá sílẹ̀, pé kí ó sọ àsọọ́lẹ̀2 ní ọ̀nà tó dára fún àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí. (Èyí jẹ́) ojúṣe fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

2:181

فَمَنۢ بَدَّلَهُۥ بَعۡدَ مَا سَمِعَهُۥ فَإِنَّمَآ إِثۡمُهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ يُبَدِّلُونَهُۥٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿181﴾

Transliteration: Faman baddalahu baAAdama samiAAahu fainnama ithmuhu AAala allatheena yubaddiloonahu inna Allaha sameeAAun AAaleemun

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá yí i padà lẹ́yìn tí ó ti gbọ́ ọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yó sì wà lọ́rùn àwọn tó ń yí i padà. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:182

فَمَنۡ خَافَ مِن مُّوصٖ جَنَفًا أَوۡ إِثۡمٗا فَأَصۡلَحَ بَيۡنَهُمۡ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿182﴾

Transliteration: Faman khafa min moosin janafan aw ithman faaslaha baynahum fala ithma AAalayhi inna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá páyà àìṣe déédé tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó sọ àsọọ́lẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe láààrin (àwọn tí ogún tọ́ sí), nítorí náà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:183

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿183﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo kutiba AAalaykumu alssiyamu kama kutiba AAala allatheena min qablikum laAAallakum tattaqoona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fún yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).

2:184

أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۚ وَعَلَى ٱلَّذِينَ يُطِيقُونَهُۥ فِدۡيَةٞ طَعَامُ مِسۡكِينٖۖ فَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥۚ وَأَن تَصُومُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿184﴾

Transliteration: Ayyaman maAAdoodatin faman kana minkum mareedan aw AAala safarin faAAiddatun min ayyamin okhara waAAala allatheena yuteeqoonahu fidyatun taAAamu miskeenin faman tatawwaAAa khayran fahuwa khayrun lahu waan tasoomoo khayrun lakum in kuntum taAAlamoona

Translation: (Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn tó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.1

2:185

شَهۡرُ رَمَضَانَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ فِيهِ ٱلۡقُرۡءَانُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡفُرۡقَانِۚ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ ٱلشَّهۡرَ فَلۡيَصُمۡهُۖ وَمَن كَانَ مَرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۗ يُرِيدُ ٱللَّهُ بِكُمُ ٱلۡيُسۡرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ ٱلۡعُسۡرَ وَلِتُكۡمِلُواْ ٱلۡعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿185﴾

Transliteration: Shahru ramadana allathee onzila feehi alquranu hudan lilnnasi wabayyinatin mina alhuda waalfurqani faman shahida minkumu alshshahra falyasumhu waman kana mareedan aw AAala safarin faAAiddatun min ayyamin okhara yureedu Allahu bikumu alyusra wala yureedu bikumu alAAusra walitukmiloo alAAiddata walitukabbiroo Allaha AAala ma hadakum walaAAallakum tashkuroona

Translation: Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀(tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà2 fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú yín tí oṣù náà bá bá láyé (nínú ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ara),3 kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fún yín, kò sì fẹ́ ìnira fún yín. Ẹ parí òǹkà ọjọ́ (ààwẹ̀ náà), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un.

2:186

وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌۖ أُجِيبُ دَعۡوَةَ ٱلدَّاعِ إِذَا دَعَانِۖ فَلۡيَسۡتَجِيبُواْ لِي وَلۡيُؤۡمِنُواْ بِي لَعَلَّهُمۡ يَرۡشُدُونَ ﴿186﴾

Transliteration: Waitha saalaka AAibadee AAannee fainnee qareebun ojeebu daAAwata alddaAAi itha daAAani falyastajeeboo lee walyuminoo bee laAAallahum yarshudoona

Translation: Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ́ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Nítorí náà, kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà).

2:187

أُحِلَّ لَكُمۡ لَيۡلَةَ ٱلصِّيَامِ ٱلرَّفَثُ إِلَىٰ نِسَآئِكُمۡۚ هُنَّ لِبَاسٞ لَّكُمۡ وَأَنتُمۡ لِبَاسٞ لَّهُنَّۗ عَلِمَ ٱللَّهُ أَنَّكُمۡ كُنتُمۡ تَخۡتَانُونَ أَنفُسَكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡ وَعَفَا عَنكُمۡۖ فَٱلۡـَٰٔنَ بَٰشِرُوهُنَّ وَٱبۡتَغُواْ مَا كَتَبَ ٱللَّهُ لَكُمۡۚ وَكُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ حَتَّىٰ يَتَبَيَّنَ لَكُمُ ٱلۡخَيۡطُ ٱلۡأَبۡيَضُ مِنَ ٱلۡخَيۡطِ ٱلۡأَسۡوَدِ مِنَ ٱلۡفَجۡرِۖ ثُمَّ أَتِمُّواْ ٱلصِّيَامَ إِلَى ٱلَّيۡلِۚ وَلَا تُبَٰشِرُوهُنَّ وَأَنتُمۡ عَٰكِفُونَ فِي ٱلۡمَسَٰجِدِۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَقۡرَبُوهَاۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ ءَايَٰتِهِۦ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ ﴿187﴾

Transliteration: Ohilla lakum laylata alssiyami alrrafathu ila nisaikum hunna libasun lakum waantum libasun lahunna AAalima Allahu annakum kuntum takhtanoona anfusakum fataba AAalaykum waAAafa AAankum faalana bashiroohunna waibtaghoo ma kataba Allahu lakum wakuloo waishraboo hatta yatabayyana lakumu alkhaytu alabyadu mina alkhayti alaswadi mina alfajri thumma atimmoo alssiyama ila allayli wala tubashiroohunna waantum AAakifoona fee almasajidi tilka hudoodu Allahi fala taqrabooha kathalika yubayyinu Allahu ayatihi lilnnasi laAAallahum yattaqoona

Translation: Wọ́n ṣe alẹ́ ààwẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín láti súnmọ́ àwọn ìyàwó yín; àwọn ni aṣọ yín, ẹ̀yin sì ni aṣọ wọn. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀ ń tan ara yín jẹ (nípa àìfẹ́ sun oorun ìfẹ́ ní alẹ́ ààwẹ̀). Ó ti gba ìronúpìwàdà yín, Ó sì ṣe àmójúkúrò fún yín. Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ́ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ óò fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) nípasẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ òdodo. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́ (nígbà tí òòrùn bá wọ̀). Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn nígbà tí ẹ bá ń kóra ró nínú àwọn mọ́sálásí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin tí) Allāhu (gbékalẹ̀), ẹ má ṣe súnmọ́ ọn (ẹ má ṣe kọlu àwọn òfin náà). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Rẹ̀).

2:188

وَلَا تَأۡكُلُوٓاْ أَمۡوَٰلَكُم بَيۡنَكُم بِٱلۡبَٰطِلِ وَتُدۡلُواْ بِهَآ إِلَى ٱلۡحُكَّامِ لِتَأۡكُلُواْ فَرِيقٗا مِّنۡ أَمۡوَٰلِ ٱلنَّاسِ بِٱلۡإِثۡمِ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿188﴾

Transliteration: Wala takuloo amwalakum baynakum bialbatili watudloo biha ila alhukkami litakuloo fareeqan min amwali alnnasi bialithmi waantum taAAlamoona

Translation: Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ fi èrú jẹ dúkìá yín láààrin ara yín. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ gbé dúkìá lọ bá àwọn adájọ́ (ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀) nítorí kí ẹ lè fi ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ìpín kan nínú dúkìá àwọn ènìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ (pé ìjà àbòsí lẹ̀ ń jà).

2:189

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡأَهِلَّةِۖ قُلۡ هِيَ مَوَٰقِيتُ لِلنَّاسِ وَٱلۡحَجِّۗ وَلَيۡسَ ٱلۡبِرُّ بِأَن تَأۡتُواْ ٱلۡبُيُوتَ مِن ظُهُورِهَا وَلَٰكِنَّ ٱلۡبِرَّ مَنِ ٱتَّقَىٰۗ وَأۡتُواْ ٱلۡبُيُوتَ مِنۡ أَبۡوَٰبِهَاۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ ﴿189﴾

Transliteration: Yasaloonaka AAani alahillati qul hiya mawaqeetu lilnnasi waalhajji walaysa albirru bian tatoo albuyoota min thuhooriha walakinna albirra mani ittaqa watoo albuyoota min abwabiha waittaqoo Allaha laAAallakum tuflihoona

Translation: Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ìlétéṣù. Sọ pé: “Òhun ni (òǹkà) àkókò fún àwọn ènìyàn àti (òǹkà àkókò fún) iṣẹ́ Hajj. Kì í ṣe iṣẹ́ rere (fún yín) láti gba ẹ̀yìn-ìnkùlé wọnú ilé, ṣùgbọ́n (olùṣe) rere ni ẹni tí ó bá bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà wọnú ilé. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí ẹ lè jèrè.

2:190

وَقَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ٱلَّذِينَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ وَلَا تَعۡتَدُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُعۡتَدِينَ ﴿190﴾

Transliteration: Waqatiloo fee sabeeli Allahi allatheena yuqatiloonakum wala taAAtadoo inna Allaha la yuhibbu almuAAtadeena

Translation: Fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, ẹ pa àwọn tó ń jà yín lógun. Kí ẹ sì má ṣe tayọ ẹnu-ààlà.Dájúdájú Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.

2:191

وَٱقۡتُلُوهُمۡ حَيۡثُ ثَقِفۡتُمُوهُمۡ وَأَخۡرِجُوهُم مِّنۡ حَيۡثُ أَخۡرَجُوكُمۡۚ وَٱلۡفِتۡنَةُ أَشَدُّ مِنَ ٱلۡقَتۡلِۚ وَلَا تُقَٰتِلُوهُمۡ عِندَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ حَتَّىٰ يُقَٰتِلُوكُمۡ فِيهِۖ فَإِن قَٰتَلُوكُمۡ فَٱقۡتُلُوهُمۡۗ كَذَٰلِكَ جَزَآءُ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿191﴾

Transliteration: Waoqtuloohum haythu thaqiftumoohum waakhrijoohum min haythu akhrajookum waalfitnatu ashaddu mina alqatli wala tuqatiloohum AAinda almasjidi alharami hatta yuqatilookum feehi fain qatalookum faoqtuloohum kathalika jazao alkafireena

Translation: Ẹ pa wọ́n níbikíbi tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n. Kí ẹ sì lé wọn jáde kúrò níbi tí wọ́n ti le yín jáde. Ìfòòró le ju pípa lọ. Ẹ má ṣe bá wọn jagun ní Mọ́sálásí Haram àfi ìgbà tí wọ́n bá ń ba yín jà nínú rẹ̀. Nítorí náà, tí wọ́n bá jà yín lógun, ẹ jà wọ́n lógun. Báyẹn ni ẹ̀san àwọn aláìgbàgbọ́.

2:192

فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿192﴾

Transliteration: Faini intahaw fainna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Tí wọ́n bá sì jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:193

وَقَٰتِلُوهُمۡ حَتَّىٰ لَا تَكُونَ فِتۡنَةٞ وَيَكُونَ ٱلدِّينُ لِلَّهِۖ فَإِنِ ٱنتَهَوۡاْ فَلَا عُدۡوَٰنَ إِلَّا عَلَى ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿193﴾

Transliteration: Waqatiloohum hatta la takoona fitnatun wayakoona alddeenu lillahi faini intahaw fala AAudwana illa AAala alththalimeena

Translation: Ẹ gbógun tì wọ́n títí kò fi níí sí ìfòòró (ìbọ̀rìṣà) mọ́. Ẹ̀sìn ’Islām yó sì wà (ní òmìnira) fún Allāhu. Nítorí náà, tí wọ́n bá jáwọ́ (nínú ìbọ̀rìṣà), kò sí ogun mọ́ àyàfi lórí àwọn alábòsí.

2:194

ٱلشَّهۡرُ ٱلۡحَرَامُ بِٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡحُرُمَٰتُ قِصَاصٞۚ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡ فَٱعۡتَدُواْ عَلَيۡهِ بِمِثۡلِ مَا ٱعۡتَدَىٰ عَلَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُتَّقِينَ ﴿194﴾

Transliteration: Alshshahru alharamu bialshshahri alharami waalhurumatu qisasun famani iAAtada AAalaykum faiAAtadoo AAalayhi bimithli ma iAAtada AAalaykum waittaqoo Allaha waiAAlamoo anna Allaha maAAa almuttaqeena

Translation: Oṣù ọ̀wọ̀ fún oṣù ọ̀wọ̀. Àwọn n̄ǹkan ọ̀wọ̀ sì ní (òfin) ìgbẹ̀san.Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà si yín, ẹ gb’ẹ̀san ìtayọ ẹnu-ààlà lára rẹ̀ pẹ̀lú irú ohun tí ó fi tayọ ẹnu-ààlà si yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn olùbẹ̀rù (Rẹ̀).

2:195

وَأَنفِقُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَلَا تُلۡقُواْ بِأَيۡدِيكُمۡ إِلَى ٱلتَّهۡلُكَةِ وَأَحۡسِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿195﴾

Transliteration: Waanfiqoo fee sabeeli Allahi wala tulqoo biaydeekum ila alttahlukati waahsinoo inna Allaha yuhibbu almuhsineena

Translation: Ẹ náwó fún ogun ẹ̀sìn Allāhu. Kí ẹ sì má ṣe fi ọwọ́ ara yín fa ìparun (nípa sísá fún ogun ẹ̀sìn). Ẹ ṣe rere. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùṣe-rere.

2:196

وَأَتِمُّواْ ٱلۡحَجَّ وَٱلۡعُمۡرَةَ لِلَّهِۚ فَإِنۡ أُحۡصِرۡتُمۡ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۖ وَلَا تَحۡلِقُواْ رُءُوسَكُمۡ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡهَدۡيُ مَحِلَّهُۥۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ بِهِۦٓ أَذٗى مِّن رَّأۡسِهِۦ فَفِدۡيَةٞ مِّن صِيَامٍ أَوۡ صَدَقَةٍ أَوۡ نُسُكٖۚ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَمَن تَمَتَّعَ بِٱلۡعُمۡرَةِ إِلَى ٱلۡحَجِّ فَمَا ٱسۡتَيۡسَرَ مِنَ ٱلۡهَدۡيِۚ فَمَن لَّمۡ يَجِدۡ فَصِيَامُ ثَلَٰثَةِ أَيَّامٖ فِي ٱلۡحَجِّ وَسَبۡعَةٍ إِذَا رَجَعۡتُمۡۗ تِلۡكَ عَشَرَةٞ كَامِلَةٞۗ ذَٰلِكَ لِمَن لَّمۡ يَكُنۡ أَهۡلُهُۥ حَاضِرِي ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ ﴿196﴾

Transliteration: Waatimmoo alhajja waalAAumrata lillahi fain ohsirtum fama istaysara mina alhadyi wala tahliqoo ruoosakum hatta yablugha alhadyu mahillahu faman kana minkum mareedan aw bihi athan min rasihi fafidyatun min siyamin aw sadaqatin aw nusukin faitha amintum faman tamattaAAa bialAAumrati ila alhajji fama istaysara mina alhadyi faman lam yajid fasiyamu thalathati ayyamin fee alhajji wasabAAatin itha rajaAAtum tilka AAasharatun kamilatun thalika liman lam yakun ahluhu hadiree almasjidi alharami waittaqoo Allaha waiAAlamoo anna Allaha shadeedu alAAiqabi

Translation: Ẹ ṣe àṣepé iṣẹ́ Hajj àti ‘Umrah fún Allāhu. Tí wọ́n bá sì se yín mọ́ ojú ọ̀nà, ẹ fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ fá irun orí yín títí di ìgbà tí ẹran ọrẹ náà yó fi dé àyè rẹ̀. Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí ìnira kan ń bẹ ní orí rẹ̀, ó máa fi ààwẹ̀ tàbí sàráà tàbí ẹran pípa ṣe ìtánràn (fún kíkánjú fá irun orí). Nígbà tí ẹ bá fọkànbalẹ̀ (nínú ewu), ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ‘Umrah àti Hajj nínú oṣù iṣẹ́ Hajj, ó máa fi èyí tí ó bá rọrùn nínú ẹran ṣe ọrẹ. Ẹni tí kò bá rí (ẹran ọrẹ), kí ó gba ààwẹ̀ ọjọ́ mẹ́ta nínú (iṣẹ́) hajj, méje nígbà tí ẹ bá darí wálé. Ìyẹn ni (ààwẹ̀) mẹ́wàá tó pé. Ìyẹn wà fún ẹni tí kò sí ẹbí rẹ̀ ní Mọ́sálásí Haram. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.

2:197

ٱلۡحَجُّ أَشۡهُرٞ مَّعۡلُومَٰتٞۚ فَمَن فَرَضَ فِيهِنَّ ٱلۡحَجَّ فَلَا رَفَثَ وَلَا فُسُوقَ وَلَا جِدَالَ فِي ٱلۡحَجِّۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يَعۡلَمۡهُ ٱللَّهُۗ وَتَزَوَّدُواْ فَإِنَّ خَيۡرَ ٱلزَّادِ ٱلتَّقۡوَىٰۖ وَٱتَّقُونِ يَـٰٓأُوْلِي ٱلۡأَلۡبَٰبِ ﴿197﴾

Transliteration: Alhajju ashhurun maAAloomatun faman farada feehinna alhajja fala rafatha wala fusooqa wala jidala fee alhajji wama tafAAaloo min khayrin yaAAlamhu Allahu watazawwadoo fainna khayra alzzadi alttaqwa waittaqooni ya olee alalbabi

Translation: Hajj ṣíṣe (wà) nínú àwọn oṣù tí wọ́n ti mọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe é ní ọ̀ran-anyàn lórí ara rẹ̀ láti ṣe Hajj nínú àwọn oṣù náà, kò gbọdọ̀ sí oorun ìfẹ́, rírú òfin àti àríyànjiyàn nínú iṣẹ́ Hajj. Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe ní rere, Allāhu mọ̀ ọ́n. Ẹ mú èsè ìrìn-àjò lọ́wọ́. Dájúdájú èsè ìrìn-àjò tó lóore jùlọ ni ìṣọ́ra (níbi èsè ẹlòmíìràn àti agbe ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ Hajj). Ẹ bẹ̀rù Mi, ẹ̀yin onílàákàyè.

2:198

لَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَن تَبۡتَغُواْ فَضۡلٗا مِّن رَّبِّكُمۡۚ فَإِذَآ أَفَضۡتُم مِّنۡ عَرَفَٰتٖ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ عِندَ ٱلۡمَشۡعَرِ ٱلۡحَرَامِۖ وَٱذۡكُرُوهُ كَمَا هَدَىٰكُمۡ وَإِن كُنتُم مِّن قَبۡلِهِۦ لَمِنَ ٱلضَّآلِّينَ ﴿198﴾

Transliteration: Laysa AAalaykum junahun an tabtaghoo fadlan min rabbikum faitha afadtum min AAarafatin faothkuroo Allaha AAinda almashAAari alharami waothkuroohu kama hadakum wain kuntum min qablihi lamina alddalleena

Translation: Kò sí ìbáwí fún yín (níbi òwò ṣíṣe l’ásìkò iṣẹ́ hajj) pé kí ẹ wá oore kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá ń darí bọ̀ láti ‘Arafah, ẹ ṣe ìrántí Allāhu ní àyè alápọ̀n-ọ́nlé (Muzdalifah). Ẹ ṣe ìrántí Rẹ̀ nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ẹ wà nínú àwọn olùṣìnà.

2:199

ثُمَّ أَفِيضُواْ مِنۡ حَيۡثُ أَفَاضَ ٱلنَّاسُ وَٱسۡتَغۡفِرُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿199﴾

Transliteration: Thumma afeedoo min haythu afada alnnasu waistaghfiroo Allaha inna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Lẹ́yìn náà, ẹ dà kúrò láti ibi tí àwọn ènìyàn ti dà kúrò (ìyẹn ní ‘Arafah), kí ẹ sì tọrọ àforíjìn Allāhu. Dájúdájú, Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:200

فَإِذَا قَضَيۡتُم مَّنَٰسِكَكُمۡ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَذِكۡرِكُمۡ ءَابَآءَكُمۡ أَوۡ أَشَدَّ ذِكۡرٗاۗ فَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا وَمَا لَهُۥ فِي ٱلۡأٓخِرَةِ مِنۡ خَلَٰقٖ ﴿200﴾

Transliteration: Faitha qadaytum manasikakum faothkuroo Allaha kathikrikum abaakum aw ashadda thikran famina alnnasi man yaqoolu rabbana atina fee alddunya wama lahu fee alakhirati min khalaqin

Translation: Nígbà tí ẹ bá parí ìjọ́sìn (Hajj) yín, ẹ ṣèrántí Allāhu gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń ṣèrántí àwọn baba ńlá yín. Tàbí kí ìrántí náà lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń wí pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ayé.” Kò sì níí sí ìpín oore kan fún un ní ọ̀run.

2:201

وَمِنۡهُم مَّن يَقُولُ رَبَّنَآ ءَاتِنَا فِي ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ حَسَنَةٗ وَقِنَا عَذَابَ ٱلنَّارِ ﴿201﴾

Transliteration: Waminhum man yaqoolu rabbana atina fee alddunya hasanatan wafee alakhirati hasanatan waqina AAathaba alnnari

Translation: Ó sì ń bẹ nínú wọn, ẹni tó ń sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná.”

2:202

أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ نَصِيبٞ مِّمَّا كَسَبُواْۚ وَٱللَّهُ سَرِيعُ ٱلۡحِسَابِ ﴿202﴾

Transliteration: Olaika lahum naseebun mimma kasaboo waAllahu sareeAAu alhisabi

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn, tiwọn ni ìpín oore nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu sì ni Olùyára níbi ìṣírò-iṣẹ́.

2:203

وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ فِيٓ أَيَّامٖ مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن تَعَجَّلَ فِي يَوۡمَيۡنِ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِ وَمَن تَأَخَّرَ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۖ لِمَنِ ٱتَّقَىٰۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُمۡ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ ﴿203﴾

Transliteration: Waothkuroo Allaha fee ayyamin maAAdoodatin faman taAAajjala fee yawmayni fala ithma AAalayhi waman taakhkhara fala ithma AAalayhi limani ittaqa waittaqoo Allaha waiAAlamoo annakum ilayhi tuhsharoona

Translation: Ẹ ṣèrántí Allāhu láààrin àwọn ọjọ́ tó ní òǹkà. Nítorí náà, ẹni tí ó bá kánjú (ṣe é) fún ọjọ́ méjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Ẹni tí ó bá kẹ́yìn (tí ó dúró di ọjọ́ kẹta), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un fún ẹni tí ó bá ṣọ́ra (fún ìwà ẹ̀ṣẹ̀). Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.1

2:204

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يُعۡجِبُكَ قَوۡلُهُۥ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَيُشۡهِدُ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا فِي قَلۡبِهِۦ وَهُوَ أَلَدُّ ٱلۡخِصَامِ ﴿204﴾

Transliteration: Wamina alnnasi man yuAAjibuka qawluhu fee alhayati alddunya wayushhidu Allaha AAala ma fee qalbihi wahuwa aladdu alkhisami

Translation: Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tí ọ̀rọ̀ (ẹnu) rẹ̀ yó máa ṣe ọ́ ní kàyéfì nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí, tí yó sì máa fi Allāhu jẹ́rìí sí ohun tí ń bẹ nínú ọkàn rẹ̀ (pé kò sí ìjà mọ́), oníjà tó le jùlọ sì ni.

2:205

وَإِذَا تَوَلَّىٰ سَعَىٰ فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيُفۡسِدَ فِيهَا وَيُهۡلِكَ ٱلۡحَرۡثَ وَٱلنَّسۡلَۚ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ ٱلۡفَسَادَ ﴿205﴾

Transliteration: Waitha tawalla saAAa fee alardi liyufsida feeha wayuhlika alhartha waalnnasla waAllahu la yuhibbu alfasada

Translation: Nígbà tí ó bá sì yísẹ̀ padà, ó máa ṣiṣẹ́ káàkiri lórí ilẹ̀ nítorí kí ó lè ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀, kí ó sì lè pa n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn run. Allāhu kò sì fẹ́ràn ìbàjẹ́.

2:206

وَإِذَا قِيلَ لَهُ ٱتَّقِ ٱللَّهَ أَخَذَتۡهُ ٱلۡعِزَّةُ بِٱلۡإِثۡمِۚ فَحَسۡبُهُۥ جَهَنَّمُۖ وَلَبِئۡسَ ٱلۡمِهَادُ ﴿206﴾

Transliteration: Waitha qeela lahu ittaqi Allaha akhathathu alAAizzatu bialithmi fahasbuhu jahannamu walabisa almihadu

Translation: Àti pé nígbà tí wọ́n bá sọ fún un pé: “Bẹ̀rù Allāhu.” Ìgbéraga sì máa mú un dẹ́ṣẹ̀. Nítorí náà, iná Jahanamọ yóò tó o (ní ẹ̀san). Ibùgbé náà sì burú.

2:207

وَمِنَ ٱلنَّاسِ مَن يَشۡرِي نَفۡسَهُ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ رَءُوفُۢ بِٱلۡعِبَادِ ﴿207﴾

Transliteration: Wamina alnnasi man yashree nafsahu ibtighaa mardati Allahi waAllahu raoofun bialAAibadi

Translation: Ó ń bẹ nínú àwọn ènìyàn, ẹni tó ń ta ẹ̀mí ara rẹ̀ (ìyẹn, olùjagun-ẹ̀sìn) láti wá ìyọ́nú Allāhu. Allāhu sì ni Aláàánú fún àwọn ẹrúsìn (Rẹ̀).

2:208

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱدۡخُلُواْ فِي ٱلسِّلۡمِ كَآفَّةٗ وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ ﴿208﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo odkhuloo fee alssilmi kaffatan wala tattabiAAoo khutuwati alshshaytani innahu lakum AAaduwwun mubeenun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ kó s’ínú ẹ̀sìn ’Islām pátápátá. Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ tẹ̀lé ojú-ẹsẹ̀ Èṣù. Dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

2:209

فَإِن زَلَلۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡكُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ ﴿209﴾

Transliteration: Fain zalaltum min baAAdi ma jaatkumu albayyinatu faiAAlamoo anna Allaha AAazeezun hakeemun

Translation: Nítorí náà, tí ẹsẹ̀ yín bá yẹ̀ (kúrò nínú ’Islām) lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé ba yín, kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

2:210

هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن يَأۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ فِي ظُلَلٖ مِّنَ ٱلۡغَمَامِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ ﴿210﴾

Transliteration: Hal yanthuroona illa an yatiyahumu Allahu fee thulalin mina alghamami waalmalaikatu waqudiya alamru waila Allahi turjaAAu alomooru

Translation: Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe pé kí Allāhu wá bá wọn nínú ibòji ẹ̀ṣújò funfun,àwọn mọlāika náà (sì máa wá, nígbà náà), A ó sì yanjú ọ̀rọ̀ (ìṣírò iṣẹ́ ẹ̀dá)! Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

2:211

سَلۡ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ كَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُم مِّنۡ ءَايَةِۭ بَيِّنَةٖۗ وَمَن يُبَدِّلۡ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُ فَإِنَّ ٱللَّهَ شَدِيدُ ٱلۡعِقَابِ ﴿211﴾

Transliteration: Sal banee israeela kam ataynahum min ayatin bayyinatin waman yubaddil niAAmata Allahi min baAAdi ma jaathu fainna Allaha shadeedu alAAiqabi

Translation: Bi àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl léèrè pé: “Mélòó ni A ti fún wọn nínú āyah tó yanjú (àmọ́ tí wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀)?” Ẹnikẹ́ni tí ó bá (fi àìgbàgbọ́) jìrọ̀ ìdẹ̀ra Allāhu lẹ́yìn tí ó dé bá a, dájúdájú Allāhu le (níbi) ìyà.

2:212

زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَيَسۡخَرُونَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۘ وَٱلَّذِينَ ٱتَّقَوۡاْ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ وَٱللَّهُ يَرۡزُقُ مَن يَشَآءُ بِغَيۡرِ حِسَابٖ ﴿212﴾

Transliteration: Zuyyina lillatheena kafaroo alhayatu alddunya wayaskharoona mina allatheena amanoo waallatheena ittaqaw fawqahum yawma alqiyamati waAllahu yarzuqu man yashao bighayri hisabin

Translation: Wọ́n ṣe ìṣẹ̀mí ayé ní ọ̀ṣọ́ (ẹ̀tàn) fún àwọn aláìgbàgbọ́. (Tí ayé bá sì yẹ wọ́n tán,) wọn yó máa fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo ṣe yẹ̀yẹ́. Àwọn tó sì bẹ̀rù Allāhu máa wà l’ókè wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde. Àti pé Allāhu ń pèsè ìjẹ-ìmu àti ìgbádùn fún ẹni tí Ó bá fẹ́ láì níí ní ìṣírò.1

2:213

كَانَ ٱلنَّاسُ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ فَبَعَثَ ٱللَّهُ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَ وَأَنزَلَ مَعَهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ بِٱلۡحَقِّ لِيَحۡكُمَ بَيۡنَ ٱلنَّاسِ فِيمَا ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِۚ وَمَا ٱخۡتَلَفَ فِيهِ إِلَّا ٱلَّذِينَ أُوتُوهُ مِنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ بَغۡيَۢا بَيۡنَهُمۡۖ فَهَدَى ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لِمَا ٱخۡتَلَفُواْ فِيهِ مِنَ ٱلۡحَقِّ بِإِذۡنِهِۦۗ وَٱللَّهُ يَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٍ ﴿213﴾

Transliteration: Kana alnnasu ommatan wahidatan fabaAAatha Allahu alnnabiyyeena mubashshireena wamunthireena waanzala maAAahumu alkitaba bialhaqqi liyahkuma bayna alnnasi feema ikhtalafoo feehi wama ikhtalafa feehi illa allatheena ootoohu min baAAdi ma jaathumu albayyinatu baghyan baynahum fahada Allahu allatheena amanoo lima ikhtalafoo feehi mina alhaqqi biithnihi waAllahu yahdee man yashao ila siratin mustaqeemin

Translation: Àwọn ènìyàn jẹ́ ìjọ kan ṣoṣo (ẹlẹ́sìn ’Islām bẹ̀rẹ̀ lórí Ànábì Ādam - kí ọlà Allāhu máa bá a -). Lẹ́yìn náà, Allāhu gbé àwọn Ànábì dìde, tí wọ́n ń jẹ́ oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún wọn pẹ̀lú òdodo nítorí kí Ó lè fi ṣe ìdájọ́ láààrin àwọn ènìyàn nípa ohun tí wọ́n yapa-ẹnu lórí rẹ̀. Kò sì sí ẹni tó yapa-ẹnu (lórí ’Islām) àfi àwọn tí A fún ní Tírà, lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú dé bá wọn ní ti ìlara láààrin ara wọn (sí àwọn Ànábì - kí ọlà Allāhu máa bá wọn -). Nítorí náà, Allāhu tọ́ àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo sọ́nà pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ nípa ohun tí (àwọn onílara)yapa-ẹnu lórí rẹ̀ nípa òdodo (’Islām). Allāhu yó máa tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà.2

2:214

أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تَدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ وَلَمَّا يَأۡتِكُم مَّثَلُ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِكُمۖ مَّسَّتۡهُمُ ٱلۡبَأۡسَآءُ وَٱلضَّرَّآءُ وَزُلۡزِلُواْ حَتَّىٰ يَقُولَ ٱلرَّسُولُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ مَتَىٰ نَصۡرُ ٱللَّهِۗ أَلَآ إِنَّ نَصۡرَ ٱللَّهِ قَرِيبٞ ﴿214﴾

Transliteration: Am hasibtum an tadkhuloo aljannata walamma yatikum mathalu allatheena khalaw min qablikum massathumu albasao waalddarrao wazulziloo hatta yaqoola alrrasoolu waallatheena amanoo maAAahu mata nasru Allahi ala inna nasra Allahi qareebun

Translation: Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí irúfẹ́ (àdánwò) tó kan àwọn tó ti lọ ṣíwájú yín kò ì kàn yín? Ìpọ́njú àti àìlera mú wọn. Wọ́n sì rí àmìwò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Òjíṣẹ́ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ fi sọ pé: “Ìgbà wo ni àrànṣe Allāhu máa dé sẹ́?” Kíyè sí i! Dájúdájú àrànṣe Allāhu súnmọ́.

2:215

يَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَۖ قُلۡ مَآ أَنفَقۡتُم مِّنۡ خَيۡرٖ فَلِلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۗ وَمَا تَفۡعَلُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٞ ﴿215﴾

Transliteration: Yasaloonaka matha yunfiqoona qul ma anfaqtum min khayrin falilwalidayni waalaqrabeena waalyatama waalmasakeeni waibni alssabeeli wama tafAAaloo min khayrin fainna Allaha bihi AAaleemun

Translation: Wọ́n ń bí ọ léèrè pé kí ni àwọn yó máa náwó sí. Sọ pé: “Ohun tí ẹ bá ná nínú ohun rere, kí ó máa jẹ́ ti àwọn òbí méjèèjì, àwọn ẹbí, àwọn ọmọ òrukàn, àwọn mẹ̀kúnnù àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ohunkóhun tí ẹ bá ṣe nínú ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.”

2:216

كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِتَالُ وَهُوَ كُرۡهٞ لَّكُمۡۖ وَعَسَىٰٓ أَن تَكۡرَهُواْ شَيۡـٔٗا وَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَعَسَىٰٓ أَن تُحِبُّواْ شَيۡـٔٗا وَهُوَ شَرّٞ لَّكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ ﴿216﴾

Transliteration: Kutiba AAalaykumu alqitalu wahuwa kurhun lakum waAAasa an takrahoo shayan wahuwa khayrun lakum waAAasa an tuhibboo shayan wahuwa sharrun lakum waAllahu yaAAlamu waantum la taAAlamoona

Translation: A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí, ohun ìkórira sì ni fún yín. Ó sì lè jẹ́ pé ẹ kórira kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ oore fún yín. Ó sì tún lè jẹ́ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí kiní kan, kí ohun náà sì jẹ́ aburú fún yín. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.

2:217

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلشَّهۡرِ ٱلۡحَرَامِ قِتَالٖ فِيهِۖ قُلۡ قِتَالٞ فِيهِ كَبِيرٞۚ وَصَدٌّ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِ وَكُفۡرُۢ بِهِۦ وَٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَإِخۡرَاجُ أَهۡلِهِۦ مِنۡهُ أَكۡبَرُ عِندَ ٱللَّهِۚ وَٱلۡفِتۡنَةُ أَكۡبَرُ مِنَ ٱلۡقَتۡلِۗ وَلَا يَزَالُونَ يُقَٰتِلُونَكُمۡ حَتَّىٰ يَرُدُّوكُمۡ عَن دِينِكُمۡ إِنِ ٱسۡتَطَٰعُواْۚ وَمَن يَرۡتَدِدۡ مِنكُمۡ عَن دِينِهِۦ فَيَمُتۡ وَهُوَ كَافِرٞ فَأُوْلَـٰٓئِكَ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡ فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۖ وَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿217﴾

Transliteration: Yasaloonaka AAani alshshahri alharami qitalin feehi qul qitalun feehi kabeerun wasaddun AAan sabeeli Allahi wakufrun bihi waalmasjidi alharami waikhraju ahlihi minhu akbaru AAinda Allahi waalfitnatu akbaru mina alqatli wala yazaloona yuqatiloonakum hatta yaruddookum AAan deenikum ini istataAAoo waman yartadid minkum AAan deenihi fayamut wahuwa kafirun faolaika habitat aAAmaluhum fee alddunya waalakhirati waolaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ogun jíjà nínú oṣù ọ̀wọ̀. Sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni ogun jíjà nínú rẹ̀. Àti pé ṣíṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò l’ójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ṣíṣe àìgbàgbọ́ nínú Allāhu, dídí àwọn mùsùlùmí lọ́wọ́ láti wọ inú Mọ́sálásí Haram àti lílé àwọn mùsùlùmí jáde kúrò nínú rẹ̀, (ìwọ̀nyí) tún tóbi jùlọ ní ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu.” Ìfòòró tóbi ju ìpànìyàn. Wọn kò ní yéé gbógun tì yín títí wọn yó fi ṣẹ́ yín lórí kúrò nínú ẹ̀sìn yín, tí wọ́n bá lágbára (ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀). Ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣẹ́rí kúrò nínú ẹ̀sìn rẹ̀, tí ó sì kú sí ipò kèfèrí, nítorí náà àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́ ní ayé àti ní ọ̀run. Àwọn wọ̀nyẹn sì ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:218

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَاجَرُواْ وَجَٰهَدُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أُوْلَـٰٓئِكَ يَرۡجُونَ رَحۡمَتَ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿218﴾

Transliteration: Inna allatheena amanoo waallatheena hajaroo wajahadoo fee sabeeli Allahi olaika yarjoona rahmata Allahi waAllahu ghafoorun raheemun

Translation: Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tó gbé ìlú (wọn) jù sílẹ̀ àti àwọn tó jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ń retí ìkẹ́ Allāhu. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:219

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡخَمۡرِ وَٱلۡمَيۡسِرِۖ قُلۡ فِيهِمَآ إِثۡمٞ كَبِيرٞ وَمَنَٰفِعُ لِلنَّاسِ وَإِثۡمُهُمَآ أَكۡبَرُ مِن نَّفۡعِهِمَاۗ وَيَسۡـَٔلُونَكَ مَاذَا يُنفِقُونَۖ قُلِ ٱلۡعَفۡوَۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَتَفَكَّرُونَ ﴿219﴾

Transliteration: Yasaloonaka AAani alkhamri waalmaysiri qul feehima ithmun kabeerun wamanafiAAu lilnnasi waithmuhuma akbaru min nafAAihima wayasaloonaka matha yunfiqoona quli alAAafwa kathalika yubayyinu Allahu lakumu alayati laAAallakum tatafakkaroona

Translation: Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa ọtí àti tẹ́tẹ́. Sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ tó tóbi àti àwọn àǹfààní kan wà nínú méjèèjì fún àwọn ènìyàn. Ẹ̀ṣẹ̀ méjèèjì sì tóbi ju àǹfààní wọn.”Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè pé kí ni àwọn yó máa ná ní sàráà. Sọ pé: “Ohun tí ó bá ṣẹ́kù lẹ́yìn tí ẹ bá ti gbọ́ bùkátà inú ilé tán (ni kí ẹ ṣe sàráà).” Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀

2:220

فِي ٱلدُّنۡيَا وَٱلۡأٓخِرَةِۗ وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡيَتَٰمَىٰۖ قُلۡ إِصۡلَاحٞ لَّهُمۡ خَيۡرٞۖ وَإِن تُخَالِطُوهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ ٱلۡمُفۡسِدَ مِنَ ٱلۡمُصۡلِحِۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَأَعۡنَتَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ﴿220﴾

Transliteration: Fee alddunya waalakhirati wayasaloonaka AAani alyatama qul islahun lahum khayrun wain tukhalitoohum faikhwanukum waAllahu yaAAlamu almufsida mina almuslihi walaw shaa Allahu laaAAnatakum inna Allaha AAazeezun hakeemun

Translation: nípa ayé àti ọ̀run. Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn ọmọ òrukàn. Sọ pé: “Ṣíṣe àtúnṣe dúkìá wọn (láì níí dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín) l’ó dára jùlọ. Tí ẹ bá sì dà á pọ̀ mọ́ dúkìá yín, ọmọ ìyá yín (nínú ẹ̀sìn) kúkú ni wọ́n. Allāhu sì mọ òbìlẹ̀jẹ́ yàtọ̀ sí alátùn-únṣe. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (kí ẹ ya dúkìá wọn sí ọ̀tọ̀ nìkan ni) ìbá kó ìnira ba yín. Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”

2:221

وَلَا تَنكِحُواْ ٱلۡمُشۡرِكَٰتِ حَتَّىٰ يُؤۡمِنَّۚ وَلَأَمَةٞ مُّؤۡمِنَةٌ خَيۡرٞ مِّن مُّشۡرِكَةٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَتۡكُمۡۗ وَلَا تُنكِحُواْ ٱلۡمُشۡرِكِينَ حَتَّىٰ يُؤۡمِنُواْۚ وَلَعَبۡدٞ مُّؤۡمِنٌ خَيۡرٞ مِّن مُّشۡرِكٖ وَلَوۡ أَعۡجَبَكُمۡۗ أُوْلَـٰٓئِكَ يَدۡعُونَ إِلَى ٱلنَّارِۖ وَٱللَّهُ يَدۡعُوٓاْ إِلَى ٱلۡجَنَّةِ وَٱلۡمَغۡفِرَةِ بِإِذۡنِهِۦۖ وَيُبَيِّنُ ءَايَٰتِهِۦ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمۡ يَتَذَكَّرُونَ ﴿221﴾

Transliteration: Wala tankihoo almushrikati hatta yuminna walaamatun muminatun khayrun min mushrikatin walaw aAAjabatkum wala tunkihoo almushrikeena hatta yuminoo walaAAabdun muminun khayrun min mushrikin walaw aAAjabakum olaika yadAAoona ila alnnari waAllahu yadAAoo ila aljannati waalmaghfirati biithnihi wayubayyinu ayatihi lilnnasi laAAallahum yatathakkaroona

Translation: Ẹ má fi àwọn abọ̀rìṣà lóbìnrin ṣaya títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Dájúdájú ẹrúbìnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lóbìnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lóbìnrin jọ yín lójú.Ẹ má sì fi onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin fún àwọn abọ̀rìṣà lọ́kùnrin títí wọn yó fi gbàgbọ́ ní òdodo. Ẹrúkùnrin onígbàgbọ́ òdodo lóore ju abọ̀rìṣà lọ́kùnrin, kódà kí abọ̀rìṣà lọ́kùnrin jọ yín lójú. Àwọn (abọ̀rìṣà) wọ̀nyẹn ń pèpè sínú Iná. Allāhu sì ń pèpè sínú Ọgbà Ìdẹ̀ra àti àforíjìn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ó sì ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

2:222

وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡمَحِيضِۖ قُلۡ هُوَ أَذٗى فَٱعۡتَزِلُواْ ٱلنِّسَآءَ فِي ٱلۡمَحِيضِ وَلَا تَقۡرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطۡهُرۡنَۖ فَإِذَا تَطَهَّرۡنَ فَأۡتُوهُنَّ مِنۡ حَيۡثُ أَمَرَكُمُ ٱللَّهُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلتَّوَّـٰبِينَ وَيُحِبُّ ٱلۡمُتَطَهِّرِينَ ﴿222﴾

Transliteration: Wayasaloonaka AAani almaheedi qul huwa athan faiAAtaziloo alnnisaa fee almaheedi wala taqraboohunna hatta yathurna faitha tatahharna fatoohunna min haythu amarakumu Allahu inna Allaha yuhibbu alttawwabeena wayuhibbu almutatahhireena

Translation: Wọ́n sì ń bi ọ́ léèrè nípa n̄ǹkan oṣù (obìnrin). Sọ pé: “Ìnirani (sísúnmọ́ wọn lásìkò náà). Nítorí náà, ẹ yẹra fún àwọn obìnrin l’ásìkò n̄ǹkan oṣù. Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn (fún oorun ìfẹ́) títí wọn yó fi ṣe ìmọ́ra. Tí wọ́n bá sì ti ṣe ìmọ́ra, ẹ súnmọ́ wọn ní àyè tí Allāhu pa láṣẹ fún yín. Dájúdájú Allāhu nífẹ̀ẹ́ àwọn olùronú-pìwàdà. Ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn olùmọ́ra.”2

2:223

نِسَآؤُكُمۡ حَرۡثٞ لَّكُمۡ فَأۡتُواْ حَرۡثَكُمۡ أَنَّىٰ شِئۡتُمۡۖ وَقَدِّمُواْ لِأَنفُسِكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّكُم مُّلَٰقُوهُۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿223﴾

Transliteration: Nisaokum harthun lakum fatoo harthakum anna shitum waqaddimoo lianfusikum waittaqoo Allaha waiAAlamoo annakum mulaqoohu wabashshiri almumineena

Translation: Oko yín ni àwọn obìnrin yín (ìyẹn àwọn ìyàwó yín). Ẹ lọ s’ínú oko yín bí ẹ bá ṣe fẹ́, kí ẹ sì ti (iṣẹ́ rere) ṣíwájú fún ẹ̀mí ara yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ mọ̀ pé dájúdájú ẹ máa pàdé Rẹ̀. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.

2:224

وَلَا تَجۡعَلُواْ ٱللَّهَ عُرۡضَةٗ لِّأَيۡمَٰنِكُمۡ أَن تَبَرُّواْ وَتَتَّقُواْ وَتُصۡلِحُواْ بَيۡنَ ٱلنَّاسِۚ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿224﴾

Transliteration: Wala tajAAaloo Allaha AAurdatan liaymanikum an tabarroo watattaqoo watuslihoo bayna alnnasi waAllahu sameeAAun AAaleemun

Translation: Ẹ má ṣe fi Allāhu ṣe ìkẹ́wọ́ fún ìbúra yín pé ẹ kò níí ṣe rere, ẹ kò níí ṣọ́ra (níbi ìwà ẹ̀ṣẹ̀), ẹ kò sì níí ṣe àtúnṣe láààrin àwọn ènìyàn. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:225

لَّا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا كَسَبَتۡ قُلُوبُكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٞ ﴿225﴾

Transliteration: La yuakhithukumu Allahu biallaghwi fee aymanikum walakin yuakhithukum bima kasabat quloobukum waAllahu ghafoorun haleemun

Translation: Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá ti inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.

2:226

لِّلَّذِينَ يُؤۡلُونَ مِن نِّسَآئِهِمۡ تَرَبُّصُ أَرۡبَعَةِ أَشۡهُرٖۖ فَإِن فَآءُو فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿226﴾

Transliteration: Lillatheena yuloona min nisaihim tarabbusu arbaAAati ashhurin fain faoo fainna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Ìkóraró fún oṣù mẹ́rin wà fún àwọn tó búra pé àwọn kò níí súnmọ́ obìnrin wọn. Tí wọ́n bá ṣẹ́rí padà (láààrin ìgbà náà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.1

2:227

وَإِنۡ عَزَمُواْ ٱلطَّلَٰقَ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿227﴾

Transliteration: Wain AAazamoo alttalaqa fainna Allaha sameeAAun AAaleemun

Translation: Tí wọ́n bá sì pinnu ìkọ̀sílẹ̀, (kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:228

وَٱلۡمُطَلَّقَٰتُ يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ ثَلَٰثَةَ قُرُوٓءٖۚ وَلَا يَحِلُّ لَهُنَّ أَن يَكۡتُمۡنَ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِيٓ أَرۡحَامِهِنَّ إِن كُنَّ يُؤۡمِنَّ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَبُعُولَتُهُنَّ أَحَقُّ بِرَدِّهِنَّ فِي ذَٰلِكَ إِنۡ أَرَادُوٓاْ إِصۡلَٰحٗاۚ وَلَهُنَّ مِثۡلُ ٱلَّذِي عَلَيۡهِنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيۡهِنَّ دَرَجَةٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ ﴿228﴾

Transliteration: Waalmutallaqatu yatarabbasna bianfusihinna thalathata qurooin wala yahillu lahunna an yaktumna ma khalaqa Allahu fee arhamihinna in kunna yuminna biAllahi waalyawmi alakhiri wabuAAoolatuhunna ahaqqu biraddihinna fee thalika in aradoo islahan walahunna mithlu allathee AAalayhinna bialmaAAroofi walilrrijali AAalayhinna darajatun waAllahu AAazeezun hakeemun

Translation: Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóraró fún héélà mẹ́ta.Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti fi ohun tí Allāhu ṣ’ẹ̀dá (rẹ̀) sí inú àpò-ọmọ wọn pamọ́, tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àwọn ọkọ wọn ní ẹ̀tọ́ sí dídá wọn padà láààrin (àsìkò) yẹn, tí wọ́n bá gbèrò àtúnṣe. Àwọn ìyàwó ní ẹ̀tọ́ l’ọ́dọ̀ ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí àwọn ọkọ wọn ní l’ọ́dọ̀ wọn lọ́nà tó dára. Ipò àjùlọ tún wà fún àwọn ọkùnrin lórí wọn.2 Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

2:229

ٱلطَّلَٰقُ مَرَّتَانِۖ فَإِمۡسَاكُۢ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ تَسۡرِيحُۢ بِإِحۡسَٰنٖۗ وَلَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَأۡخُذُواْ مِمَّآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ شَيۡـًٔا إِلَّآ أَن يَخَافَآ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَا فِيمَا ٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَعۡتَدُوهَاۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿229﴾

Transliteration: Alttalaqu marratani faimsakun bimaAAroofin aw tasreehun biihsanin wala yahillu lakum an takhuthoo mimma ataytumoohunna shayan illa an yakhafa alla yuqeema hudooda Allahi fain khiftum alla yuqeema hudooda Allahi fala junaha AAalayhima feema iftadat bihi tilka hudoodu Allahi fala taAAtadooha waman yataAAadda hudooda Allahi faolaika humu alththalimoona

Translation: Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀).Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

2:230

فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا تَحِلُّ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدُ حَتَّىٰ تَنكِحَ زَوۡجًا غَيۡرَهُۥۗ فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يَتَرَاجَعَآ إِن ظَنَّآ أَن يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۗ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ يُبَيِّنُهَا لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿230﴾

Transliteration: Fain tallaqaha fala tahillu lahu min baAAdu hatta tankiha zawjan ghayrahu fain tallaqaha fala junaha AAalayhima an yatarajaAAa in thanna an yuqeema hudooda Allahi watilka hudoodu Allahi yubayyinuha liqawmin yaAAlamoona

Translation: Nítorí náà, tí ọkọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kẹta), obìnrin náà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i mọ́ lẹ́yìn náà títí obìnrin náà yóò fi fẹ́ ẹlòmíìràn. Tí ẹni náà bá tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì nígbà náà láti padà sí ọ̀dọ̀ ara wọn, tí àwọn méjèèjì bá ti lérò pé àwọn máa ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ (fún wọn), tí Ó ń ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ tó nímọ̀.

2:231

وَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمۡسِكُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ سَرِّحُوهُنَّ بِمَعۡرُوفٖۚ وَلَا تُمۡسِكُوهُنَّ ضِرَارٗا لِّتَعۡتَدُواْۚ وَمَن يَفۡعَلۡ ذَٰلِكَ فَقَدۡ ظَلَمَ نَفۡسَهُۥۚ وَلَا تَتَّخِذُوٓاْ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ هُزُوٗاۚ وَٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَمَآ أَنزَلَ عَلَيۡكُم مِّنَ ٱلۡكِتَٰبِ وَٱلۡحِكۡمَةِ يَعِظُكُم بِهِۦۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿231﴾

Transliteration: Waitha tallaqtumu alnnisaa fabalaghna ajalahunna faamsikoohunna bimaAAroofin aw sarrihoohunna bimaAAroofin wala tumsikoohunna diraran litaAAtadoo waman yafAAal thalika faqad thalama nafsahu wala tattakhithoo ayati Allahi huzuwan waothkuroo niAAmata Allahi AAalaykum wama anzala AAalaykum mina alkitabi waalhikmati yaAAithukum bihi waittaqoo Allaha waiAAlamoo anna Allaha bikulli shayin AAaleemun

Translation: Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí àsìkò (opó) wọn súnmọ́ kó parí, ẹ lè mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ (ní ìparí opó wọn) pẹ̀lú dáadáa. Ẹ má ṣe mú wọn mọ́ra ní ọ̀nà ìnira láti lè tayọ ẹnu-ààlà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìyẹn, ó kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹ má ṣe sọ àwọn āyah Allāhu di n̄ǹkan yẹ̀yẹ́. Ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín àti ohun tí Ó sọ̀kalẹ̀ fún yín nínú Tírà àti òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -, tí Ó ń fi ṣe ìṣítí fún yín. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

2:232

وَإِذَا طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ فَبَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا تَعۡضُلُوهُنَّ أَن يَنكِحۡنَ أَزۡوَٰجَهُنَّ إِذَا تَرَٰضَوۡاْ بَيۡنَهُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ ذَٰلِكَ يُوعَظُ بِهِۦ مَن كَانَ مِنكُمۡ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۗ ذَٰلِكُمۡ أَزۡكَىٰ لَكُمۡ وَأَطۡهَرُۚ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ وَأَنتُمۡ لَا تَعۡلَمُونَ ﴿232﴾

Transliteration: Waitha tallaqtumu alnnisaa fabalaghna ajalahunna fala taAAduloohunna an yankihna azwajahunna itha taradaw baynahum bialmaAAroofi thalika yooAAathu bihi man kana minkum yuminu biAllahi waalyawmi alakhiri thalikum azka lakum waatharu waAllahu yaAAlamu waantum la taAAlamoona

Translation: Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.1

2:233

وَٱلۡوَٰلِدَٰتُ يُرۡضِعۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ حَوۡلَيۡنِ كَامِلَيۡنِۖ لِمَنۡ أَرَادَ أَن يُتِمَّ ٱلرَّضَاعَةَۚ وَعَلَى ٱلۡمَوۡلُودِ لَهُۥ رِزۡقُهُنَّ وَكِسۡوَتُهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ لَا تُكَلَّفُ نَفۡسٌ إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَا تُضَآرَّ وَٰلِدَةُۢ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوۡلُودٞ لَّهُۥ بِوَلَدِهِۦۚ وَعَلَى ٱلۡوَارِثِ مِثۡلُ ذَٰلِكَۗ فَإِنۡ أَرَادَا فِصَالًا عَن تَرَاضٖ مِّنۡهُمَا وَتَشَاوُرٖ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَاۗ وَإِنۡ أَرَدتُّمۡ أَن تَسۡتَرۡضِعُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا سَلَّمۡتُم مَّآ ءَاتَيۡتُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ﴿233﴾

Transliteration: Waalwalidatu yurdiAAna awladahunna hawlayni kamilayni liman arada an yutimma alrradaAAata waAAala almawloodi lahu rizquhunna wakiswatuhunna bialmaAAroofi la tukallafu nafsun illa wusAAaha la tudarra walidatun biwaladiha wala mawloodun lahu biwaladihi waAAala alwarithi mithlu thalika fain arada fisalan AAan taradin minhuma watashawurin fala junaha AAalayhima wain aradtum an tastardiAAoo awladakum fala junaha AAalaykum itha sallamtum ma ataytum bialmaAAroofi waittaqoo Allaha waiAAlamoo anna Allaha bima taAAmaloona baseerun

Translation: Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà tó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún.Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà tó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:234

وَٱلَّذِينَ يُتَوَفَّوۡنَ مِنكُمۡ وَيَذَرُونَ أَزۡوَٰجٗا يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ أَرۡبَعَةَ أَشۡهُرٖ وَعَشۡرٗاۖ فَإِذَا بَلَغۡنَ أَجَلَهُنَّ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا فَعَلۡنَ فِيٓ أَنفُسِهِنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ ﴿234﴾

Transliteration: Waallatheena yutawaffawna minkum wayatharoona azwajan yatarabbasna bianfusihinna arbaAAata ashhurin waAAashran faitha balaghna ajalahunna fala junaha AAalaykum feema faAAalna fee anfusihinna bialmaAAroofi waAllahu bima taAAmaloona khabeerun

Translation: Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sílẹ̀, àwọn ìyàwó wọn yóò kóraró fún oṣù mẹ́rin àti ọjọ́ mẹ́wàá. Nígbà tí wọ́n bá sì parí àsìkò (opó) wọn, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí wọ́n bá ṣe fúnra wọn (láti ní ọkọ mìíràn) ní ọ̀nà tó dára. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:235

وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِيمَا عَرَّضۡتُم بِهِۦ مِنۡ خِطۡبَةِ ٱلنِّسَآءِ أَوۡ أَكۡنَنتُمۡ فِيٓ أَنفُسِكُمۡۚ عَلِمَ ٱللَّهُ أَنَّكُمۡ سَتَذۡكُرُونَهُنَّ وَلَٰكِن لَّا تُوَاعِدُوهُنَّ سِرًّا إِلَّآ أَن تَقُولُواْ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗاۚ وَلَا تَعۡزِمُواْ عُقۡدَةَ ٱلنِّكَاحِ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ ٱلۡكِتَٰبُ أَجَلَهُۥۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ فَٱحۡذَرُوهُۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ غَفُورٌ حَلِيمٞ ﴿235﴾

Transliteration: Wala junaha AAalaykum feema AAarradtum bihi min khitbati alnnisai aw aknantum fee anfusikum AAalima Allahu annakum satathkuroonahunna walakin la tuwaAAidoohunna sirran illa an taqooloo qawlan maAAroofan wala taAAzimoo AAuqdata alnnikahi hatta yablugha alkitabu ajalahu waiAAlamoo anna Allaha yaAAlamu ma fee anfusikum faihtharoohu waiAAlamoo anna Allaha ghafoorun haleemun

Translation: Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí ẹ pẹ́sọ nínú ìbánisọ̀rọ̀ ìfẹ́ tàbí tí ẹ fi pamọ́ sínú ẹ̀mí yín. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀yin ọkùnrin yó máa rántí wọn, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn ní ìkọ̀kọ̀, àyàfi pé kí ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ dáadáa. Ẹ má ṣe pinnu títa kókó yìgì títí àsìkò (opó) máa fi parí. Ẹ mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí ń bẹ nínú ẹ̀mí yín, nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Rẹ̀. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.

2:236

لَّا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِن طَلَّقۡتُمُ ٱلنِّسَآءَ مَا لَمۡ تَمَسُّوهُنَّ أَوۡ تَفۡرِضُواْ لَهُنَّ فَرِيضَةٗۚ وَمَتِّعُوهُنَّ عَلَى ٱلۡمُوسِعِ قَدَرُهُۥ وَعَلَى ٱلۡمُقۡتِرِ قَدَرُهُۥ مَتَٰعَۢا بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿236﴾

Transliteration: La junaha AAalaykum in tallaqtumu alnnisaa ma lam tamassoohunna aw tafridoo lahunna fareedatan wamattiAAoohunna AAala almoosiAAi qadaruhu waAAala almuqtiri qadaruhu mataAAan bialmaAAroofi haqqan AAala almuhsineena

Translation: Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín, tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, láì tí ì súnmọ́ wọn tàbí láì tí ì sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn ní pàtó. Kí ẹ sì fún wọn ní ẹ̀bùn (ìkọ̀sílẹ̀); kí olùgbòòrò (nínú arísìkí) fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀, kí tálíkà sì fi ìwọ̀n (agbára) rẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀nà tó dára. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùṣe-rere.

2:237

وَإِن طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ وَقَدۡ فَرَضۡتُمۡ لَهُنَّ فَرِيضَةٗ فَنِصۡفُ مَا فَرَضۡتُمۡ إِلَّآ أَن يَعۡفُونَ أَوۡ يَعۡفُوَاْ ٱلَّذِي بِيَدِهِۦ عُقۡدَةُ ٱلنِّكَاحِۚ وَأَن تَعۡفُوٓاْ أَقۡرَبُ لِلتَّقۡوَىٰۚ وَلَا تَنسَوُاْ ٱلۡفَضۡلَ بَيۡنَكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ ﴿237﴾

Transliteration: Wain tallaqtumoohunna min qabli an tamassoohunna waqad faradtum lahunna fareedatan fanisfu ma faradtum illa an yaAAfoona aw yaAAfuwa allathee biyadihi AAuqdatu alnnikahi waan taAAfoo aqrabu lilttaqwa wala tansawoo alfadla baynakum inna Allaha bima taAAmaloona baseerun

Translation: Tí ẹ bá sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó súnmọ́ wọn, tí ẹ sì ti sọ òdíwọ̀n sọ̀daàkí kan fún wọn, ìlàjì ohun tí ẹ ti ṣòdíwọ̀n rẹ̀ ní sọ̀daàkí (ni kí ẹ fún wọn), àfi tí àwọn obìnrin náà bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀) tàbí tí ẹni tí ìtakókó yìgì ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀bá ṣàmójú kúrò (níbi gbogbo rẹ̀). Kí ẹ ṣàmójú kúrò ló súnmọ́ ìbẹ̀rù Allāhu jùlọ. Ẹ má ṣe gbàgbé oore àjùlọ ààrin yín. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:238

حَٰفِظُواْ عَلَى ٱلصَّلَوَٰتِ وَٱلصَّلَوٰةِ ٱلۡوُسۡطَىٰ وَقُومُواْ لِلَّهِ قَٰنِتِينَ ﴿238﴾

Transliteration: Hafithoo AAala alssalawati waalssalati alwusta waqoomoo lillahi qaniteena

Translation: Ẹ ṣọ́ àwọn ìrun (wákàtí márààrún) àti (ní pàápàá jùlọ) ìrun ààrin. Kí ẹ sì dúró kírun fún Allāhu láì níí sọ̀rọ̀ (tó jẹmọ́ tayé lórí ìrun).

2:239

فَإِنۡ خِفۡتُمۡ فَرِجَالًا أَوۡ رُكۡبَانٗاۖ فَإِذَآ أَمِنتُمۡ فَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَمَا عَلَّمَكُم مَّا لَمۡ تَكُونُواْ تَعۡلَمُونَ ﴿239﴾

Transliteration: Fain khiftum farijalan aw rukbanan faitha amintum faothkuroo Allaha kama AAallamakum ma lam takoonoo taAAlamoona

Translation: Ṣùgbọ́n tí ẹ bá ń bẹ̀rù (ọ̀tá l’ójú ogun ẹ̀sìn), ẹ kírun yín lórí ìrìn (ẹsẹ̀) tàbí lórí n̄ǹkan ìgùn. Nígbà tí ọkàn yín bá balẹ̀, ẹ rántí Allāhu (ẹ kírun) gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe fi ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀ (tẹ́lẹ̀) mọ̀ yín.

2:240

وَٱلَّذِينَ يُتَوَفَّوۡنَ مِنكُمۡ وَيَذَرُونَ أَزۡوَٰجٗا وَصِيَّةٗ لِّأَزۡوَٰجِهِم مَّتَٰعًا إِلَى ٱلۡحَوۡلِ غَيۡرَ إِخۡرَاجٖۚ فَإِنۡ خَرَجۡنَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ فِي مَا فَعَلۡنَ فِيٓ أَنفُسِهِنَّ مِن مَّعۡرُوفٖۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ﴿240﴾

Transliteration: Waallatheena yutawaffawna minkum wayatharoona azwajan wasiyyatan liazwajihim mataAAan ila alhawli ghayra ikhrajin fain kharajna fala junaha AAalaykum fee ma faAAalna fee anfusihinna min maAAroofin waAllahu AAazeezun hakeemun

Translation: Àwọn tí wọ́n kú nínú yín, tí wọ́n sì fi àwọn ìyàwó sáyé lọ, kí wọ́n sọ àsọọ́lẹ̀ ìjẹ-ìmu ọdún kan fún àwọn ìyàwó wọn, láì sì níí lé wọn jáde kúrò nínú ilé wọn. Tí wọ́n bá sì jáde (fúnra wọn lẹ́yìn ìjáde opó), kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín nípa ohun tí wọ́n bá fi’ra wọn ṣe ní dáadáa (láti ní ọkọ mìíràn). Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

2:241

وَلِلۡمُطَلَّقَٰتِ مَتَٰعُۢ بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُتَّقِينَ ﴿241﴾

Transliteration: Walilmutallaqati mataAAun bialmaAAroofi haqqan AAala almuttaqeena

Translation: N̄ǹkan ìgbádùn ní ọ̀nà tó dára tún máa wà fún àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀sílẹ̀. Ojúṣe l’ó jẹ́ fún àwọn olùbẹ̀rù Allāhu.

2:242

كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴿242﴾

Transliteration: Kathalika yubayyinu Allahu lakum ayatihi laAAallakum taAAqiloona

Translation: Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

2:243

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِينَ خَرَجُواْ مِن دِيَٰرِهِمۡ وَهُمۡ أُلُوفٌ حَذَرَ ٱلۡمَوۡتِ فَقَالَ لَهُمُ ٱللَّهُ مُوتُواْ ثُمَّ أَحۡيَٰهُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَشۡكُرُونَ ﴿243﴾

Transliteration: Alam tara ila allatheena kharajoo min diyarihim wahum oloofun hathara almawti faqala lahumu Allahu mootoo thumma ahyahum inna Allaha lathoo fadlin AAala alnnasi walakinna akthara alnnasi la yashkuroona

Translation: Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tó jáde láti inú ilé wọn lẹ́gbẹẹgbẹ̀rún nítorí ìbẹ̀rù ikú! Allāhu sì sọ fún wọn pé: “Ẹ kú.” Lẹ́yìn náà, Ó sọ wọ́n di alààyè. Dájúdájú Allāhu ni Olóore-àjùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn kò dúpẹ́ (fún Un).1

2:244

وَقَٰتِلُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿244﴾

Transliteration: Waqatiloo fee sabeeli Allahi waiAAlamoo anna Allaha sameeAAun AAaleemun

Translation: Ẹ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu, kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:245

مَّن ذَا ٱلَّذِي يُقۡرِضُ ٱللَّهَ قَرۡضًا حَسَنٗا فَيُضَٰعِفَهُۥ لَهُۥٓ أَضۡعَافٗا كَثِيرَةٗۚ وَٱللَّهُ يَقۡبِضُ وَيَبۡصُۜطُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿245﴾

Transliteration: Man tha allathee yuqridu Allaha qardan hasanan fayudaAAifahu lahu adAAafan katheeratan waAllahu yaqbidu wayabsutu wailayhi turjaAAoona

Translation: Ta ni ẹni tí ó máa yá Allāhu ní dúkìá tó dára, kí Allāhu sì ṣe àdìpèlé (ẹ̀san) fún un ní àdìpèlé púpọ̀? Allāhu ń ká ọrọ̀ nílẹ̀, Ó sì ń tẹ́ ẹ sílẹ̀. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

2:246

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلۡمَلَإِ مِنۢ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ مِنۢ بَعۡدِ مُوسَىٰٓ إِذۡ قَالُواْ لِنَبِيّٖ لَّهُمُ ٱبۡعَثۡ لَنَا مَلِكٗا نُّقَٰتِلۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۖ قَالَ هَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡقِتَالُ أَلَّا تُقَٰتِلُواْۖ قَالُواْ وَمَا لَنَآ أَلَّا نُقَٰتِلَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَقَدۡ أُخۡرِجۡنَا مِن دِيَٰرِنَا وَأَبۡنَآئِنَاۖ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيۡهِمُ ٱلۡقِتَالُ تَوَلَّوۡاْ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿246﴾

Transliteration: Alam tara ila almalai min banee israeela min baAAdi moosa ith qaloo linabiyyin lahumu ibAAath lana malikan nuqatil fee sabeeli Allahi qala hal AAasaytum in kutiba AAalaykumu alqitalu alla tuqatiloo qaloo wama lana alla nuqatila fee sabeeli Allahi waqad okhrijna min diyarina waabnaina falamma kutiba AAalayhimu alqitalu tawallaw illa qaleelan minhum waAllahu AAaleemun bialththalimeena

Translation: Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn aṣíwájú nínú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl, lẹ́yìn (ìgbà Ànábì) Mūsā? Nígbà tí wọ́n sọ fún Ànábì tiwọn pé: “Yan ọba kan fún wa, kí á lọ jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu.” Ó sọ pé: “Ṣebí ó ṣeé ṣe pé tí wọ́n bá ṣe ogun jíjà ní ọ̀ran-anyàn le yín lórí tán, ẹ ò kúkú níí jagun?” Wọ́n wí pé: “Kí ni ó máa dí wa lọ́wọ́ láti jagun fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu? Wọ́n kúkú ti lé àwa àti àwọn ọmọ wa jáde kúrò nínú ilé wa!” Àmọ́ nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí tán, wọ́n pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú wọn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.

2:247

وَقَالَ لَهُمۡ نَبِيُّهُمۡ إِنَّ ٱللَّهَ قَدۡ بَعَثَ لَكُمۡ طَالُوتَ مَلِكٗاۚ قَالُوٓاْ أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ ٱلۡمُلۡكُ عَلَيۡنَا وَنَحۡنُ أَحَقُّ بِٱلۡمُلۡكِ مِنۡهُ وَلَمۡ يُؤۡتَ سَعَةٗ مِّنَ ٱلۡمَالِۚ قَالَ إِنَّ ٱللَّهَ ٱصۡطَفَىٰهُ عَلَيۡكُمۡ وَزَادَهُۥ بَسۡطَةٗ فِي ٱلۡعِلۡمِ وَٱلۡجِسۡمِۖ وَٱللَّهُ يُؤۡتِي مُلۡكَهُۥ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ ﴿247﴾

Transliteration: Waqala lahum nabiyyuhum inna Allaha qad baAAatha lakum taloota malikan qaloo anna yakoonu lahu almulku AAalayna wanahnu ahaqqu bialmulki minhu walam yuta saAAatan mina almali qala inna Allaha istafahu AAalaykum wazadahu bastatan fee alAAilmi waaljismi waAllahu yutee mulkahu man yashao waAllahu wasiAAun AAaleemun

Translation: Ànábì wọn sọ fún wọn pé: “Dájúdájú Allāhu ti gbé Tọ̄lūt dìde fún yín ní ọba.” Wọ́n wí pé: “Báwo ni ó ṣe lè jẹ ọba lé wa lórí nígbà tí ó jẹ́ pé àwa ní ẹ̀tọ́ sí ipò ọba jù ú lọ? Wọn kò sì fún un ní owó púpọ̀?” Ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ṣà á lẹ́ṣà le yín lórí. Ó sì fún un ní àlékún púpọ̀ nínú ìmọ̀ àti okun ara. Allāhu ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ìjọba Rẹ̀. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.”

2:248

وَقَالَ لَهُمۡ نَبِيُّهُمۡ إِنَّ ءَايَةَ مُلۡكِهِۦٓ أَن يَأۡتِيَكُمُ ٱلتَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَبَقِيَّةٞ مِّمَّا تَرَكَ ءَالُ مُوسَىٰ وَءَالُ هَٰرُونَ تَحۡمِلُهُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَةٗ لَّكُمۡ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ ﴿248﴾

Transliteration: Waqala lahum nabiyyuhum inna ayata mulkihi an yatiyakumu alttabootu feehi sakeenatun min rabbikum wabaqiyyatun mimma taraka alu moosa waalu haroona tahmiluhu almalaikatu inna fee thalika laayatan lakum in kuntum mumineena

Translation: Ànábì wọn tún sọ fún wọn pé: “Dájúdájú àmì ìjọba rẹ̀ ni pé, àpótí yóò wá ba yín. N̄ǹkan ìfàyàbalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín àti ohun tó ṣẹ́kù nínú ohun tí àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā àti ènìyàn (Ànábì) Hārūn fi sílẹ̀ ń bẹ nínú àpótí náà. Àwọn mọlāika máa rù ú wá (ba yín). Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún yín, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.”

2:249

فَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِٱلۡجُنُودِ قَالَ إِنَّ ٱللَّهَ مُبۡتَلِيكُم بِنَهَرٖ فَمَن شَرِبَ مِنۡهُ فَلَيۡسَ مِنِّي وَمَن لَّمۡ يَطۡعَمۡهُ فَإِنَّهُۥ مِنِّيٓ إِلَّا مَنِ ٱغۡتَرَفَ غُرۡفَةَۢ بِيَدِهِۦۚ فَشَرِبُواْ مِنۡهُ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنۡهُمۡۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُۥ هُوَ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ قَالُواْ لَا طَاقَةَ لَنَا ٱلۡيَوۡمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِۦۚ قَالَ ٱلَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَٰقُواْ ٱللَّهِ كَم مِّن فِئَةٖ قَلِيلَةٍ غَلَبَتۡ فِئَةٗ كَثِيرَةَۢ بِإِذۡنِ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ مَعَ ٱلصَّـٰبِرِينَ ﴿249﴾

Transliteration: Falamma fasala talootu bialjunoodi qala inna Allaha mubtaleekum binaharin faman shariba minhu falaysa minnee waman lam yatAAamhu fainnahu minnee illa mani ightarafa ghurfatan biyadihi fashariboo minhu illa qaleelan minhum falamma jawazahu huwa waallatheena amanoo maAAahu qaloo la taqata lana alyawma bijaloota wajunoodihi qala allatheena yathunnoona annahum mulaqoo Allahi kam min fiatin qaleelatin ghalabat fiatan katheeratan biithni Allahi waAllahu maAAa alssabireena

Translation: Nígbà tí Tọ̄lūt jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sọ pé: “Dájúdájú Allāhu máa fi odò kan dan yín wò. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú rẹ̀, kì í ṣe ẹni mi. Ẹni tí kò bá tọ́ ọ wò dájúdájú òun ni ẹni mi, àyàfi ẹni tí ó bá bu ìwọ̀n ẹ̀kúnwọ́ rẹ̀ kan mu.” (Ṣùgbọ́n) wọ́n mu nínú rẹ̀ àfi díẹ̀ nínú wọn. Nígbà tí òun àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ sọdá odò náà, wọ́n sọ pé: “Kò sí agbára kan fún wa lónìí tí a lè fi k’ojú Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀.” Àwọn tó mọ̀ pé dájúdájú àwọn máa pàdé Allāhu, wọ́n sọ pé: “Mélòó mélòó nínú àwọn ìjọ (ogun) kékeré tó ti ṣẹ́gun ìjọ (ogun) púpọ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onísùúrù.”

2:250

وَلَمَّا بَرَزُواْ لِجَالُوتَ وَجُنُودِهِۦ قَالُواْ رَبَّنَآ أَفۡرِغۡ عَلَيۡنَا صَبۡرٗا وَثَبِّتۡ أَقۡدَامَنَا وَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿250﴾

Transliteration: Walamma barazoo lijaloota wajunoodihi qaloo rabbana afrigh AAalayna sabran wathabbit aqdamana waonsurna AAala alqawmi alkafireena

Translation: Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”

2:251

فَهَزَمُوهُم بِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَقَتَلَ دَاوُۥدُ جَالُوتَ وَءَاتَىٰهُ ٱللَّهُ ٱلۡمُلۡكَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَعَلَّمَهُۥ مِمَّا يَشَآءُۗ وَلَوۡلَا دَفۡعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لَّفَسَدَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ ذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿251﴾

Transliteration: Fahazamoohum biithni Allahi waqatala dawoodu jaloota waatahu Allahu almulka waalhikmata waAAallamahu mimma yashao walawla dafAAu Allahi alnnasa baAAdahum bibaAAdin lafasadati alardu walakinna Allaha thoo fadlin AAala alAAalameena

Translation: Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá.

2:252

تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱللَّهِ نَتۡلُوهَا عَلَيۡكَ بِٱلۡحَقِّۚ وَإِنَّكَ لَمِنَ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ﴿252﴾

Transliteration: Tilka ayatu Allahi natlooha AAalayka bialhaqqi wainnaka lamina almursaleena

Translation: Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Allāhu, tí À ń ké e fún ọ pẹ̀lú òdodo. Àti pé dájúdájú ìwọ wà lára àwọn Òjíṣẹ́.

2:253

تِلۡكَ ٱلرُّسُلُ فَضَّلۡنَا بَعۡضَهُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۘ مِّنۡهُم مَّن كَلَّمَ ٱللَّهُۖ وَرَفَعَ بَعۡضَهُمۡ دَرَجَٰتٖۚ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلَ ٱلَّذِينَ مِنۢ بَعۡدِهِم مِّنۢ بَعۡدِ مَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡبَيِّنَٰتُ وَلَٰكِنِ ٱخۡتَلَفُواْ فَمِنۡهُم مَّنۡ ءَامَنَ وَمِنۡهُم مَّن كَفَرَۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا ٱقۡتَتَلُواْ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يُرِيدُ ﴿253﴾

Transliteration: Tilka alrrusulu faddalna baAAdahum AAala baAAdin minhum man kallama Allahu warafaAAa baAAdahum darajatin waatayna AAeesa ibna maryama albayyinati waayyadnahu biroohi alqudusi walaw shaa Allahu ma iqtatala allatheena min baAAdihim min baAAdi ma jaathumu albayyinatu walakini ikhtalafoo faminhum man amana waminhum man kafara walaw shaa Allahu ma iqtataloo walakinna Allaha yafAAalu ma yureedu

Translation: Àwọn Òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn, A ṣoore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan. Ó ń bẹ nínú wọn, ẹni tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (tààrà). Ó sì ṣe àgbéga àwọn ipò fún apá kan wọn. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn tó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasọ̄rọ̄).Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.

2:254

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنفِقُواْ مِمَّا رَزَقۡنَٰكُم مِّن قَبۡلِ أَن يَأۡتِيَ يَوۡمٞ لَّا بَيۡعٞ فِيهِ وَلَا خُلَّةٞ وَلَا شَفَٰعَةٞۗ وَٱلۡكَٰفِرُونَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿254﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo anfiqoo mimma razaqnakum min qabli an yatiya yawmun la bayAAun feehi wala khullatun wala shafaAAatun waalkafiroona humu alththalimoona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú ohun tí A ṣe ní arísìkí fún yín ṣíwájú kí ọjọ́ kan tó dé. Kò níí sí títà-rírà kan nínú rẹ̀. Kò níí sí olólùfẹ́ kan, kò sì níí sí ìṣìpẹ̀ kan (fún àwọn aláìgbàgbọ́). Àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn sì ni alábòsí.1

2:255

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ٱلۡحَيُّ ٱلۡقَيُّومُۚ لَا تَأۡخُذُهُۥ سِنَةٞ وَلَا نَوۡمٞۚ لَّهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ مَن ذَا ٱلَّذِي يَشۡفَعُ عِندَهُۥٓ إِلَّا بِإِذۡنِهِۦۚ يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡۖ وَلَا يُحِيطُونَ بِشَيۡءٖ مِّنۡ عِلۡمِهِۦٓ إِلَّا بِمَا شَآءَۚ وَسِعَ كُرۡسِيُّهُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَۖ وَلَا يَـُٔودُهُۥ حِفۡظُهُمَاۚ وَهُوَ ٱلۡعَلِيُّ ٱلۡعَظِيمُ ﴿255﴾

Transliteration: Allahu la ilaha illa huwa alhayyu alqayyoomu la takhuthuhu sinatun wala nawmun lahu ma fee alssamawati wama fee alardi man tha allathee yashfaAAu AAindahu illa biithnihi yaAAlamu ma bayna aydeehim wama khalfahum wala yuheetoona bishayin min AAilmihi illa bima shaa wasiAAa kursiyyuhu alssamawati waalarda wala yaooduhu hifthuhuma wahuwa alAAaliyyu alAAatheemu

Translation: Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Òògbé kì í ta Á. Àti pé oorun kì í kùn Ún. TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Ta ni ẹni tí ó máa ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Rẹ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀?Ó mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ lẹ́yìn wọn. Wọn kò sì ní ìmọ̀ àmọ̀tán nípa kiní kan nínú ìmọ̀ Rẹ̀ àfi ohun tí Ó bá fẹ́ (fi mọ̀ wọ́n). Àga Rẹ̀ gbààyè ju àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀.2 Ṣíṣọ́ sánmọ̀ àti ilẹ̀ kò sì dá A lágara. Allāhu ga, Ó tóbi.3

2:256

لَآ إِكۡرَاهَ فِي ٱلدِّينِۖ قَد تَّبَيَّنَ ٱلرُّشۡدُ مِنَ ٱلۡغَيِّۚ فَمَن يَكۡفُرۡ بِٱلطَّـٰغُوتِ وَيُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ فَقَدِ ٱسۡتَمۡسَكَ بِٱلۡعُرۡوَةِ ٱلۡوُثۡقَىٰ لَا ٱنفِصَامَ لَهَاۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ ﴿256﴾

Transliteration: La ikraha fee alddeeni qad tabayyana alrrushdu mina alghayyi faman yakfur bialttaghooti wayumin biAllahi faqadi istamsaka bialAAurwati alwuthqa la infisama laha waAllahu sameeAAun AAaleemun

Translation: Kò sí ìjẹnípá nínú ẹ̀sìn. Ìmọ̀nà ti fojú hàn kúrò nínú ìṣìnà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lòdì sí àwọn òrìṣà, tí ó sì ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu, ó kúkú ti dìmọ́ okùn tó fọkàn balẹ̀ jùlọ, tí kò níí já. Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:257

ٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُخۡرِجُهُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَوۡلِيَآؤُهُمُ ٱلطَّـٰغُوتُ يُخۡرِجُونَهُم مِّنَ ٱلنُّورِ إِلَى ٱلظُّلُمَٰتِۗ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿257﴾

Transliteration: Allahu waliyyu allatheena amanoo yukhrijuhum mina alththulumati ila alnnoori waallatheena kafaroo awliyaohumu alttaghootu yukhrijoonahum mina alnnoori ila alththulumati olaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Allāhu ni Alárànṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:258

أَلَمۡ تَرَ إِلَى ٱلَّذِي حَآجَّ إِبۡرَٰهِـۧمَ فِي رَبِّهِۦٓ أَنۡ ءَاتَىٰهُ ٱللَّهُ ٱلۡمُلۡكَ إِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّيَ ٱلَّذِي يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ قَالَ أَنَا۠ أُحۡيِۦ وَأُمِيتُۖ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ فَإِنَّ ٱللَّهَ يَأۡتِي بِٱلشَّمۡسِ مِنَ ٱلۡمَشۡرِقِ فَأۡتِ بِهَا مِنَ ٱلۡمَغۡرِبِ فَبُهِتَ ٱلَّذِي كَفَرَۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿258﴾

Transliteration: Alam tara ila allathee hajja ibraheema fee rabbihi an atahu Allahu almulka ith qala ibraheemu rabbiya allathee yuhyee wayumeetu qala ana ohyee waomeetu qala ibraheemu fainna Allaha yatee bialshshamsi mina almashriqi fati biha mina almaghribi fabuhita allathee kafara waAllahu la yahdee alqawma alththalimeena

Translation: Ṣé ìwọ kò wòye sí ẹni tó bá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm jiyàn nípa Olúwa rẹ̀, nítorí pé Allāhu fún un ní ìjọba? Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi ni Ẹni tí ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” Ó wí pé: “Èmi náà ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Mo sì ń sọ ẹ̀dá di òkú.” (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Dájúdájú Allāhu ń mú òòrùn wá láti ibùyọ. Mú un wa nígbà náà láti ibùwọ̀.” Wọ́n sì pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ lẹ́nu. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

2:259

أَوۡ كَٱلَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرۡيَةٖ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحۡيِۦ هَٰذِهِ ٱللَّهُ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۖ فَأَمَاتَهُ ٱللَّهُ مِاْئَةَ عَامٖ ثُمَّ بَعَثَهُۥۖ قَالَ كَمۡ لَبِثۡتَۖ قَالَ لَبِثۡتُ يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۖ قَالَ بَل لَّبِثۡتَ مِاْئَةَ عَامٖ فَٱنظُرۡ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمۡ يَتَسَنَّهۡۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجۡعَلَكَ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِۖ وَٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡعِظَامِ كَيۡفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكۡسُوهَا لَحۡمٗاۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥ قَالَ أَعۡلَمُ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿259﴾

Transliteration: Aw kaallathee marra AAala qaryatin wahiya khawiyatun AAala AAurooshiha qala anna yuhyee hathihi Allahu baAAda mawtiha faamatahu Allahu miata AAamin thumma baAAathahu qala kam labithta qala labithtu yawman aw baAAda yawmin qala bal labithta miata AAamin faonthur ila taAAamika washarabika lam yatasannah waonthur ila himarika walinajAAalaka ayatan lilnnasi waonthur ila alAAithami kayfa nunshizuha thumma naksooha lahman falamma tabayyana lahu qala aAAlamu anna Allaha AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí (àwọn ilé ibẹ̀) ti dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o ti wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn (ni ìwọ̀nyí jẹ́). Wo eegun (ràkúnmí náà), wo bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”1

2:260

وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّ أَرِنِي كَيۡفَ تُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ قَالَ أَوَلَمۡ تُؤۡمِنۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِن لِّيَطۡمَئِنَّ قَلۡبِيۖ قَالَ فَخُذۡ أَرۡبَعَةٗ مِّنَ ٱلطَّيۡرِ فَصُرۡهُنَّ إِلَيۡكَ ثُمَّ ٱجۡعَلۡ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٖ مِّنۡهُنَّ جُزۡءٗا ثُمَّ ٱدۡعُهُنَّ يَأۡتِينَكَ سَعۡيٗاۚ وَٱعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ﴿260﴾

Transliteration: Waith qala ibraheemu rabbi arinee kayfa tuhyee almawta qala awalam tumin qala bala walakin liyatmainna qalbee qala fakhuth arbaAAatan mina alttayri fasurhunna ilayka thumma ijAAal AAala kulli jabalin minhunna juzan thumma odAAuhunna yateenaka saAAyan waiAAlam anna Allaha AAazeezun hakeemun

Translation: Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè.” (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (mo gbàgbọ́), ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: “Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”

2:261

مَّثَلُ ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ كَمَثَلِ حَبَّةٍ أَنۢبَتَتۡ سَبۡعَ سَنَابِلَ فِي كُلِّ سُنۢبُلَةٖ مِّاْئَةُ حَبَّةٖۗ وَٱللَّهُ يُضَٰعِفُ لِمَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٌ ﴿261﴾

Transliteration: Mathalu allatheena yunfiqoona amwalahum fee sabeeli Allahi kamathali habbatin anbatat sabAAa sanabila fee kulli sunbulatin miatu habbatin waAllahu yudaAAifu liman yashao waAllahu wasiAAun AAaleemun

Translation: Àpèjúwe àwọn tó ń ná dúkìá wọn fún ẹ̀sìn Allāhu dà bí àpèjúwe kóró èso kan tí ó hu ṣiri méje jáde, tí ọgọ́rùn-ún kóró sì wà lára ṣiri kọ̀ọ̀kan. Allāhu yó ṣe àdìpèlé fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.

2:262

ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ ثُمَّ لَا يُتۡبِعُونَ مَآ أَنفَقُواْ مَنّٗا وَلَآ أَذٗى لَّهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿262﴾

Transliteration: Allatheena yunfiqoona amwalahum fee sabeeli Allahi thumma la yutbiAAoona ma anfaqoo mannan wala athan lahum ajruhum AAinda rabbihim wala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Àwọn tó ń ná dúkìá wọn fún ẹ̀sìn Allāhu, tí wọn kò sì fi ìrègún àti ìpalára tẹ̀lé ohun tí wọ́n ná, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn lọ́dọ̀ Olúwa wọn. Ìbẹ̀rù kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

2:263

قَوۡلٞ مَّعۡرُوفٞ وَمَغۡفِرَةٌ خَيۡرٞ مِّن صَدَقَةٖ يَتۡبَعُهَآ أَذٗىۗ وَٱللَّهُ غَنِيٌّ حَلِيمٞ ﴿263﴾

Transliteration: Qawlun maAAroofun wamaghfiratun khayrun min sadaqatin yatbaAAuha athan waAllahu ghaniyyun haleemun

Translation: Ọ̀rọ̀ rere àti àforíjìn lóore ju sàráà tí ìpalára tẹ̀lé. Allāhu sì ni Ọlọ́rọ̀, Aláfaradà.

2:264

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُبۡطِلُواْ صَدَقَٰتِكُم بِٱلۡمَنِّ وَٱلۡأَذَىٰ كَٱلَّذِي يُنفِقُ مَالَهُۥ رِئَآءَ ٱلنَّاسِ وَلَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۖ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ صَفۡوَانٍ عَلَيۡهِ تُرَابٞ فَأَصَابَهُۥ وَابِلٞ فَتَرَكَهُۥ صَلۡدٗاۖ لَّا يَقۡدِرُونَ عَلَىٰ شَيۡءٖ مِّمَّا كَسَبُواْۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿264﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la tubtiloo sadaqatikum bialmanni waalatha kaallathee yunfiqu malahu riaa alnnasi wala yuminu biAllahi waalyawmi alakhiri famathaluhu kamathali safwanin AAalayhi turabun faasabahu wabilun fatarakahu saldan la yaqdiroona AAala shayin mimma kasaboo waAllahu la yahdee alqawma alkafireena

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe fi ìrègún àti ìpalára ba àwọn sàráà yín jẹ́, bí ẹni tí ó ń ná dúkìá rẹ̀ pẹ̀lú ṣekárími, kò sì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àpèjúwe rẹ̀ dà bí àpèjúwe àpáta kan tí erùpẹ̀ ń bẹ lórí rẹ̀. Òjò ńlá rọ̀ sí i, ó sì kó erùpẹ̀ kúrò lórí rẹ̀ pátápátá. Wọn kò ní agbára lórí kiní kan nínú ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ aláìgbàgbọ́.

2:265

وَمَثَلُ ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُمُ ٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِ ٱللَّهِ وَتَثۡبِيتٗا مِّنۡ أَنفُسِهِمۡ كَمَثَلِ جَنَّةِۭ بِرَبۡوَةٍ أَصَابَهَا وَابِلٞ فَـَٔاتَتۡ أُكُلَهَا ضِعۡفَيۡنِ فَإِن لَّمۡ يُصِبۡهَا وَابِلٞ فَطَلّٞۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ ﴿265﴾

Transliteration: Wamathalu allatheena yunfiqoona amwalahumu ibtighaa mardati Allahi watathbeetan min anfusihim kamathali jannatin birabwatin asabaha wabilun faatat okulaha diAAfayni fain lam yusibha wabilun fatallun waAllahu bima taAAmaloona baseerun

Translation: Àpèjúwe àwọn tó ń ná dúkìá wọn láti wá ìyọ́nú Allāhu àti (nítorí pé) ó rinlẹ̀ nínú ẹ̀mí wọn (pé ẹ̀san rere ń bẹ fún àwọn lórí rẹ̀ lọ́dọ̀ Allāhu), ó dà bí àpèjúwe ọgbà oko tó wà lórí ilẹ̀ gíga kan, tí òjò ńlá rọ̀ sí, tí àwọn èso rẹ̀ sì yọ jáde ní ìlọ́po méjì. Tí òjò ńlá kò bá sì rọ̀ sí i, ìrì ń ṣẹ̀ sí i. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.

2:266

أَيَوَدُّ أَحَدُكُمۡ أَن تَكُونَ لَهُۥ جَنَّةٞ مِّن نَّخِيلٖ وَأَعۡنَابٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ لَهُۥ فِيهَا مِن كُلِّ ٱلثَّمَرَٰتِ وَأَصَابَهُ ٱلۡكِبَرُ وَلَهُۥ ذُرِّيَّةٞ ضُعَفَآءُ فَأَصَابَهَآ إِعۡصَارٞ فِيهِ نَارٞ فَٱحۡتَرَقَتۡۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ ٱللَّهُ لَكُمُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَتَفَكَّرُونَ ﴿266﴾

Transliteration: Ayawaddu ahadukum an takoona lahu jannatun min nakheelin waaAAnabin tajree min tahtiha alanharu lahu feeha min kulli alththamarati waasabahu alkibaru walahu thurriyyatun duAAafao faasabaha iAAsarun feehi narun faihtaraqat kathalika yubayyinu Allahu lakumu alayati laAAallakum tatafakkaroona

Translation: Ǹjẹ́ ẹnì kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí kí òun ní ọgbà oko dàbínù àti àjàrà, tí àwọn odò ń ṣàn ní abẹ́ rẹ̀, tí oríṣiríṣi èso tún wà fún un nínú rẹ̀, kí ogbó dé bá a, ó sì ní àwọn ọmọ wẹẹrẹ tí kò lágbara (iṣẹ́ oko ṣíṣe), kí atẹ́gùn líle tí iná ń bẹ nínú rẹ̀ kọlu oko náà, kí ó sì jóná? Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah náà fún yín nítorí kí ẹ lè ronú jinlẹ̀.

2:267

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنفِقُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا كَسَبۡتُمۡ وَمِمَّآ أَخۡرَجۡنَا لَكُم مِّنَ ٱلۡأَرۡضِۖ وَلَا تَيَمَّمُواْ ٱلۡخَبِيثَ مِنۡهُ تُنفِقُونَ وَلَسۡتُم بِـَٔاخِذِيهِ إِلَّآ أَن تُغۡمِضُواْ فِيهِۚ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ غَنِيٌّ حَمِيدٌ ﴿267﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo anfiqoo min tayyibati ma kasabtum wamimma akhrajna lakum mina alardi wala tayammamoo alkhabeetha minhu tunfiqoona walastum biakhitheehi illa an tughmidoo feehi waiAAlamoo anna Allaha ghaniyyun hameedun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ ná nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí ẹ ṣe níṣẹ́ àti nínú àwọn n̄ǹkan tí A mú jáde fún yín láti inú ilẹ̀. Ẹ má ṣe gbèrò láti ná nínú èyí tí kò dára. Ẹ̀yin náà kò níí gbà á àfi kí ẹ dijú gbà á. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.1

2:268

ٱلشَّيۡطَٰنُ يَعِدُكُمُ ٱلۡفَقۡرَ وَيَأۡمُرُكُم بِٱلۡفَحۡشَآءِۖ وَٱللَّهُ يَعِدُكُم مَّغۡفِرَةٗ مِّنۡهُ وَفَضۡلٗاۗ وَٱللَّهُ وَٰسِعٌ عَلِيمٞ ﴿268﴾

Transliteration: Alshshaytanu yaAAidukumu alfaqra wayamurukum bialfahshai waAllahu yaAAidukum maghfiratan minhu wafadlan waAllahu wasiAAun AAaleemun

Translation: Èṣù ń fi òṣì dẹ́rù bà yín, ó sì ń pa yín ní àṣẹ ìbàjẹ́ ṣíṣe. Allāhu sì ń ṣe àdéhùn àforíjìn àti oore àjùlọ láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ fún yín. Allāhu ní Oníbúọlá, Onímọ̀.

2:269

يُؤۡتِي ٱلۡحِكۡمَةَ مَن يَشَآءُۚ وَمَن يُؤۡتَ ٱلۡحِكۡمَةَ فَقَدۡ أُوتِيَ خَيۡرٗا كَثِيرٗاۗ وَمَا يَذَّكَّرُ إِلَّآ أُوْلُواْ ٱلۡأَلۡبَٰبِ ﴿269﴾

Transliteration: Yutee alhikmata man yashao waman yuta alhikmata faqad ootiya khayran katheeran wama yaththakkaru illa oloo alalbabi

Translation: Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní òye ìjìnlẹ̀. Ẹni tí A bá sì fún ní òye ìjìnlẹ̀ A kúkú ti fún un ní oore púpọ̀. Ẹnì kan kò níí lo ìrántí àfi àwọn onílàákàyè.

2:270

وَمَآ أَنفَقۡتُم مِّن نَّفَقَةٍ أَوۡ نَذَرۡتُم مِّن نَّذۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُهُۥۗ وَمَا لِلظَّـٰلِمِينَ مِنۡ أَنصَارٍ ﴿270﴾

Transliteration: Wama anfaqtum min nafaqatin aw nathartum min nathrin fainna Allaha yaAAlamuhu wama lilththalimeena min ansarin

Translation: Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ìnáwó tàbí (ohunkóhun) tí ẹ bá jẹ́ ní ẹ̀jẹ́, dájúdájú Allāhu mọ̀ ọ́n. Kò sì níí sí olùrànlọ́wọ́ kan fún àwọn alábòsí.

2:271

إِن تُبۡدُواْ ٱلصَّدَقَٰتِ فَنِعِمَّا هِيَۖ وَإِن تُخۡفُوهَا وَتُؤۡتُوهَا ٱلۡفُقَرَآءَ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۚ وَيُكَفِّرُ عَنكُم مِّن سَيِّـَٔاتِكُمۡۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٞ ﴿271﴾

Transliteration: In tubdoo alssadaqati faniAAimma hiya wain tukhfooha watutooha alfuqaraa fahuwa khayrun lakum wayukaffiru AAankum min sayyiatikum waAllahu bima taAAmaloona khabeerun

Translation: Tí ẹ bá ṣàfi hàn àwọn sàráà, ó kúkú dára. Tí ẹ bá sì fi pamọ́, tí ẹ lọ́ fún àwọn aláìní, ó sì dára jùlọ fún yín. Allāhu sì máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fún yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:272

لَّيۡسَ عَلَيۡكَ هُدَىٰهُمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ يَهۡدِي مَن يَشَآءُۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَلِأَنفُسِكُمۡۚ وَمَا تُنفِقُونَ إِلَّا ٱبۡتِغَآءَ وَجۡهِ ٱللَّهِۚ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ يُوَفَّ إِلَيۡكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تُظۡلَمُونَ ﴿272﴾

Transliteration: Laysa AAalayka hudahum walakinna Allaha yahdee man yashao wama tunfiqoo min khayrin falianfusikum wama tunfiqoona illa ibtighaa wajhi Allahi wama tunfiqoo min khayrin yuwaffa ilaykum waantum la tuthlamoona

Translation: Ìmọ̀nà wọn kò sí lọ́rùn rẹ, ṣùgbọ́n Allāhu ń fi ẹni tí Ó bá fẹ́ mọ̀nà. Ohunkóhun tí ẹ bá ń ná ní ohun rere, fún ẹ̀mí ara yín ni. Ẹ ò sì gbọ́dọ̀ náwó àfi láti fi wá ojú rere Allāhu. Ohunkóhun tí ẹ bá sì ná ní ohun rere, A ó san yín ní ẹ̀san (rẹ̀) ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí si yín.

2:273

لِلۡفُقَرَآءِ ٱلَّذِينَ أُحۡصِرُواْ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ لَا يَسۡتَطِيعُونَ ضَرۡبٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ يَحۡسَبُهُمُ ٱلۡجَاهِلُ أَغۡنِيَآءَ مِنَ ٱلتَّعَفُّفِ تَعۡرِفُهُم بِسِيمَٰهُمۡ لَا يَسۡـَٔلُونَ ٱلنَّاسَ إِلۡحَافٗاۗ وَمَا تُنفِقُواْ مِنۡ خَيۡرٖ فَإِنَّ ٱللَّهَ بِهِۦ عَلِيمٌ ﴿273﴾

Transliteration: Lilfuqarai allatheena ohsiroo fee sabeeli Allahi la yastateeAAoona darban fee alardi yahsabuhumu aljahilu aghniyaa mina alttaAAaffufi taAArifuhum biseemahum la yasaloona alnnasa ilhafan wama tunfiqoo min khayrin fainna Allaha bihi AAaleemun

Translation: (Ẹ tọrẹ) fún àwọn aláìní tí wọ́n sé (ara wọn mọ́nú mọ́sálásí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nítorí kí wọ́n lè máa jagun) fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Wọn kò sì lágbára lílọ-bíbọ̀ lórí ilẹ̀ (fún òkòwò ṣíṣe). Ẹni tí kò mọ̀ wọ́n máa kà wọ́n kún ọlọ́rọ̀ látara àìṣagbe. O máa mọ̀ wọ́n pẹ̀lú àmì wọn. Wọn kò níí tọrọ n̄ǹkan lọ́wọ́ ènìyàn lemọ́lemọ́.Ohunkóhun tí ẹ bá ná ní ohun rere, dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa rẹ̀.

2:274

ٱلَّذِينَ يُنفِقُونَ أَمۡوَٰلَهُم بِٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ سِرّٗا وَعَلَانِيَةٗ فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿274﴾

Transliteration: Allatheena yunfiqoona amwalahum biallayli waalnnahari sirran waAAalaniyatan falahum ajruhum AAinda rabbihim wala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Àwọn tó ń ná dúkìá wọn ní òru àti ní ọ̀sán, ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gban̄gba, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

2:275

ٱلَّذِينَ يَأۡكُلُونَ ٱلرِّبَوٰاْ لَا يَقُومُونَ إِلَّا كَمَا يَقُومُ ٱلَّذِي يَتَخَبَّطُهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ مِنَ ٱلۡمَسِّۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡبَيۡعُ مِثۡلُ ٱلرِّبَوٰاْۗ وَأَحَلَّ ٱللَّهُ ٱلۡبَيۡعَ وَحَرَّمَ ٱلرِّبَوٰاْۚ فَمَن جَآءَهُۥ مَوۡعِظَةٞ مِّن رَّبِّهِۦ فَٱنتَهَىٰ فَلَهُۥ مَا سَلَفَ وَأَمۡرُهُۥٓ إِلَى ٱللَّهِۖ وَمَنۡ عَادَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿275﴾

Transliteration: Allatheena yakuloona alrriba la yaqoomoona illa kama yaqoomu allathee yatakhabbatuhu alshshaytanu mina almassi thalika biannahum qaloo innama albayAAu mithlu alrriba waahalla Allahu albayAAa waharrama alrriba faman jaahu mawAAithatun min rabbihi faintaha falahu ma salafa waamruhu ila Allahi waman AAada faolaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Àwọn tó ń jẹ èlé kò níí dìde (nínú sàréè) àfi bí ẹni tí Èṣù fọwọ́ bà tí ń ta gẹ̀ẹ́gẹ̀ẹ́ yó ṣe dìde. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n wí pé: “Òwò ṣíṣe dà bí òwò èlé.” Allāhu sì ṣe òwò ṣíṣe ní ẹ̀tọ́, Ó sì ṣe òwò èlé ní èèwọ̀. Ẹnikẹ́ni tí wáàsí bá dé bá láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀, tí ó sì jáwọ́, tirẹ̀ ni èyí tó ṣíwájú, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì di ọ̀dọ̀ Allāhu. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì padà (síbi òwò èlé), àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:276

يَمۡحَقُ ٱللَّهُ ٱلرِّبَوٰاْ وَيُرۡبِي ٱلصَّدَقَٰتِۗ وَٱللَّهُ لَا يُحِبُّ كُلَّ كَفَّارٍ أَثِيمٍ ﴿276﴾

Transliteration: Yamhaqu Allahu alrriba wayurbee alssadaqati waAllahu la yuhibbu kulla kaffarin atheemin

Translation: Allāhu máa run òwò èlé. Ó sì máa bù sí àwọn ọrẹ. Allāhu kò nífẹ̀ẹ́ gbogbo aláìgbàgbọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀.

2:277

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتَوُاْ ٱلزَّكَوٰةَ لَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿277﴾

Transliteration: Inna allatheena amanoo waAAamiloo alssalihati waaqamoo alssalata waatawoo alzzakata lahum ajruhum AAinda rabbihim wala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere, tí wọ́n kírun, tí wọ́n sì yọ Zakāh, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìpáyà fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

2:278

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَذَرُواْ مَا بَقِيَ مِنَ ٱلرِّبَوٰٓاْ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ ﴿278﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo ittaqoo Allaha watharoo ma baqiya mina alrriba in kuntum mumineena

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì fi ohun tó ṣẹ́kù nínú èlé sílẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo.

2:279

فَإِن لَّمۡ تَفۡعَلُواْ فَأۡذَنُواْ بِحَرۡبٖ مِّنَ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۖ وَإِن تُبۡتُمۡ فَلَكُمۡ رُءُوسُ أَمۡوَٰلِكُمۡ لَا تَظۡلِمُونَ وَلَا تُظۡلَمُونَ ﴿279﴾

Transliteration: Fain lam tafAAaloo fathanoo biharbin mina Allahi warasoolihi wain tubtum falakum ruoosu amwalikum la tathlimoona wala tuthlamoona

Translation: Tí ẹ kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ lọ mọ̀ pé ogun kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (ń bọ̀ wá bá yín). Tí ẹ bá sì ronú pìwàdà, tiyín ni ojú-owó yín. Ẹ kò níí ṣàbòsí (sí wọn). Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí yín.

2:280

وَإِن كَانَ ذُو عُسۡرَةٖ فَنَظِرَةٌ إِلَىٰ مَيۡسَرَةٖۚ وَأَن تَصَدَّقُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿280﴾

Transliteration: Wain kana thoo AAusratin fanathiratun ila maysaratin waan tasaddaqoo khayrun lakum in kuntum taAAlamoona

Translation: Tí (onígbèsè) bá jẹ́ ẹni tí ara ń ni, ẹ wò ó níran títí di àsìkò ìdẹ̀ra. Àti pé kí ẹ fị ṣe sàráà (fún un) lóore jùlọ fún yín, tí ẹ bá mọ̀.

2:281

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا تُرۡجَعُونَ فِيهِ إِلَى ٱللَّهِۖ ثُمَّ تُوَفَّىٰ كُلُّ نَفۡسٖ مَّا كَسَبَتۡ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ﴿281﴾

Transliteration: Waittaqoo yawman turjaAAoona feehi ila Allahi thumma tuwaffa kullu nafsin ma kasabat wahum la yuthlamoona

Translation: Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí wọ́n máa da yín padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ (nípa) ohun tí ó ṣe níṣẹ́. Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

2:282

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا تَدَايَنتُم بِدَيۡنٍ إِلَىٰٓ أَجَلٖ مُّسَمّٗى فَٱكۡتُبُوهُۚ وَلۡيَكۡتُب بَّيۡنَكُمۡ كَاتِبُۢ بِٱلۡعَدۡلِۚ وَلَا يَأۡبَ كَاتِبٌ أَن يَكۡتُبَ كَمَا عَلَّمَهُ ٱللَّهُۚ فَلۡيَكۡتُبۡ وَلۡيُمۡلِلِ ٱلَّذِي عَلَيۡهِ ٱلۡحَقُّ وَلۡيَتَّقِ ٱللَّهَ رَبَّهُۥ وَلَا يَبۡخَسۡ مِنۡهُ شَيۡـٔٗاۚ فَإِن كَانَ ٱلَّذِي عَلَيۡهِ ٱلۡحَقُّ سَفِيهًا أَوۡ ضَعِيفًا أَوۡ لَا يَسۡتَطِيعُ أَن يُمِلَّ هُوَ فَلۡيُمۡلِلۡ وَلِيُّهُۥ بِٱلۡعَدۡلِۚ وَٱسۡتَشۡهِدُواْ شَهِيدَيۡنِ مِن رِّجَالِكُمۡۖ فَإِن لَّمۡ يَكُونَا رَجُلَيۡنِ فَرَجُلٞ وَٱمۡرَأَتَانِ مِمَّن تَرۡضَوۡنَ مِنَ ٱلشُّهَدَآءِ أَن تَضِلَّ إِحۡدَىٰهُمَا فَتُذَكِّرَ إِحۡدَىٰهُمَا ٱلۡأُخۡرَىٰۚ وَلَا يَأۡبَ ٱلشُّهَدَآءُ إِذَا مَا دُعُواْۚ وَلَا تَسۡـَٔمُوٓاْ أَن تَكۡتُبُوهُ صَغِيرًا أَوۡ كَبِيرًا إِلَىٰٓ أَجَلِهِۦۚ ذَٰلِكُمۡ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِ وَأَقۡوَمُ لِلشَّهَٰدَةِ وَأَدۡنَىٰٓ أَلَّا تَرۡتَابُوٓاْ إِلَّآ أَن تَكُونَ تِجَٰرَةً حَاضِرَةٗ تُدِيرُونَهَا بَيۡنَكُمۡ فَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٌ أَلَّا تَكۡتُبُوهَاۗ وَأَشۡهِدُوٓاْ إِذَا تَبَايَعۡتُمۡۚ وَلَا يُضَآرَّ كَاتِبٞ وَلَا شَهِيدٞۚ وَإِن تَفۡعَلُواْ فَإِنَّهُۥ فُسُوقُۢ بِكُمۡۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۖ وَيُعَلِّمُكُمُ ٱللَّهُۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿282﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo itha tadayantum bidaynin ila ajalin musamman faoktuboohu walyaktub baynakum katibun bialAAadli wala yaba katibun an yaktuba kama AAallamahu Allahu falyaktub walyumlili allathee AAalayhi alhaqqu walyattaqi Allaha rabbahu wala yabkhas minhu shayan fain kana allathee AAalayhi alhaqqu safeehan aw daAAeefan aw la yastateeAAu an yumilla huwa falyumlil waliyyuhu bialAAadli waistashhidoo shaheedayni min rijalikum fain lam yakoona rajulayni farajulun waimraatani mimman tardawna mina alshshuhadai an tadilla ihdahuma fatuthakkira ihdahuma alokhra wala yaba alshshuhadao itha ma duAAoo wala tasamoo an taktuboohu sagheeran aw kabeeran ila ajalihi thalikum aqsatu AAinda Allahi waaqwamu lilshshahadati waadna alla tartaboo illa an takoona tijaratan hadiratan tudeeroonaha baynakum falaysa AAalaykum junahun alla taktubooha waashhidoo itha tabayaAAtum wala yudarra katibun wala shaheedun wain tafAAaloo fainnahu fusooqun bikum waittaqoo Allaha wayuAAallimukumu Allahu waAllahu bikulli shayin AAaleemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà ní àwìn fún gbèdéke àkókò kan, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Kí akọ̀wé ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ láààrin yín ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí akọ̀wé má ṣe kọ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Allāhu ṣe fi mọ̀ ọ́n. Nítorí náà. kí ó ṣe àkọsílẹ̀. Kí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ pè é fún un. Kí ó bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Kò má ṣe dín kiní kan kù nínú rẹ̀. Tí ẹni tí ẹ̀tọ́ wà lọ́rùn rẹ̀ bá jẹ́ aláìlóye tàbí aláìsàn, tàbí kò lè pè é (fúnra rẹ̀), kí alámòjúútó rẹ̀ bá a pè é ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Kí ẹ pe ẹlẹ́rìí méjì nínú àwọn ọkùnrin yín láti jẹ́rìí sí i. Tí kò bá sí ọkùnrin méjì, kí ẹ wá ọkùnrin kan àti obìnrin méjì nínú àwọn ẹlẹ́rìí tí ẹ yọ́nú sí; nítorí pé tí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin méjèèjì bá gbàgbé, ọ̀kan yó sì rán ìkejì létí. Kí àwọn ẹlẹ́rìí má ṣe kọ̀ tí wọ́n bá pè wọ́n (láti jẹ́rìí). Ẹ má ṣe káàárẹ̀ láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, ó kéré ni tàbí ó tóbi, títí di àsìkò ìsangbèsè rẹ̀. Ìyẹn ni déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu. Ó sì gbé ìjẹ́rìí dúró jùlọ. Ó tún fi súnmọ́ jùlọ pé ẹ̀yin kò fi níí ṣeyèméjì. Àfi tí ó bá jẹ́ kátà-kárà ojú ẹsẹ̀ tí ẹ̀ ń ṣe ní àtọwọ́dọ́wọ́ láààrin ara yín, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín tí ẹ kò bá ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ẹ wá ẹlẹ́rìí sẹ́ nígbà tí ẹ bá ń ṣe kátà-kárà (ọjà àwìn). Wọn kò sì gbọ́dọ̀ kó ìnira bá akọ̀wé àti ẹlẹ́rìí. Tí ẹ bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, dájúdájú ìbàjẹ́ l’ẹ ṣe. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Allāhu yó sì máa fi ìmọ̀ mọ̀ yín. Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

2:283

وَإِن كُنتُمۡ عَلَىٰ سَفَرٖ وَلَمۡ تَجِدُواْ كَاتِبٗا فَرِهَٰنٞ مَّقۡبُوضَةٞۖ فَإِنۡ أَمِنَ بَعۡضُكُم بَعۡضٗا فَلۡيُؤَدِّ ٱلَّذِي ٱؤۡتُمِنَ أَمَٰنَتَهُۥ وَلۡيَتَّقِ ٱللَّهَ رَبَّهُۥۗ وَلَا تَكۡتُمُواْ ٱلشَّهَٰدَةَۚ وَمَن يَكۡتُمۡهَا فَإِنَّهُۥٓ ءَاثِمٞ قَلۡبُهُۥۗ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ عَلِيمٞ ﴿283﴾

Transliteration: Wain kuntum AAala safarin walam tajidoo katiban farihanun maqboodatun fain amina baAAdukum baAAdan falyuaddi allathee itumina amanatahu walyattaqi Allaha rabbahu wala taktumoo alshshahadata waman yaktumha fainnahu athimun qalbuhu waAllahu bima taAAmaloona AAaleemun

Translation: Àti pé tí ẹ bá wà lórí ìrìn-àjò, tí ẹ̀yin kò sì rí akọ̀wé, ẹ gba ohun ìdógò. (Ṣùgbọ́n) tí apá kan yín bá fi ọkàn tán apá kan, kí ẹni tí wọ́n fi ọkàn tán dá ohun tí wọ́n fi ọkàn tán an lé lórí padà, kí ó sì bẹ̀rù Allāhu, Olúwa rẹ̀. Ẹ má ṣe fi ẹ̀rí pamọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi pamọ́, dájúdájú ọkàn rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe.

2:284

لِّلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَإِن تُبۡدُواْ مَا فِيٓ أَنفُسِكُمۡ أَوۡ تُخۡفُوهُ يُحَاسِبۡكُم بِهِ ٱللَّهُۖ فَيَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۗ وَٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ ﴿284﴾

Transliteration: Lillahi ma fee alssamawati wama fee alardi wain tubdoo ma fee anfusikum aw tukhfoohu yuhasibkum bihi Allahu fayaghfiru liman yashao wayuAAaththibu man yashao waAllahu AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun tó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fún yín Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

2:285

ءَامَنَ ٱلرَّسُولُ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مِن رَّبِّهِۦ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَۚ كُلٌّ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَمَلَـٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّن رُّسُلِهِۦۚ وَقَالُواْ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَاۖ غُفۡرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيۡكَ ٱلۡمَصِيرُ ﴿285﴾

Transliteration: Amana alrrasoolu bima onzila ilayhi min rabbihi waalmuminoona kullun amana biAllahi wamalaikatihi wakutubihi warusulihi la nufarriqu bayna ahadin min rusulihi waqaloo samiAAna waataAAna ghufranaka rabbana wailayka almaseeru

Translation: Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀.A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”

2:286

لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَعَلَيۡهَا مَا ٱكۡتَسَبَتۡۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذۡنَآ إِن نَّسِينَآ أَوۡ أَخۡطَأۡنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تَحۡمِلۡ عَلَيۡنَآ إِصۡرٗا كَمَا حَمَلۡتَهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلۡنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِۦۖ وَٱعۡفُ عَنَّا وَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَآۚ أَنتَ مَوۡلَىٰنَا فَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿286﴾

Transliteration: La yukallifu Allahu nafsan illa wusAAaha laha ma kasabat waAAalayha ma iktasabat rabbana la tuakhithna in naseena aw akhtana rabbana wala tahmil AAalayna isran kama hamaltahu AAala allatheena min qablina rabbana wala tuhammilna ma la taqata lana bihi waoAAfu AAanna waighfir lana wairhamna anta mawlana faonsurna AAala alqawmi alkafireena

Translation: Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù tó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn tó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download