quranm◉

Hizb 1

Range
from 2:26 to 2:91
Surahs covered
Ìtumọ̀
66 Ìtumọ̀

◉

2:26

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَسۡتَحۡيِۦٓ أَن يَضۡرِبَ مَثَلٗا مَّا بَعُوضَةٗ فَمَا فَوۡقَهَاۚ فَأَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ فَيَعۡلَمُونَ أَنَّهُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّهِمۡۖ وَأَمَّا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَيَقُولُونَ مَاذَآ أَرَادَ ٱللَّهُ بِهَٰذَا مَثَلٗاۘ يُضِلُّ بِهِۦ كَثِيرٗا وَيَهۡدِي بِهِۦ كَثِيرٗاۚ وَمَا يُضِلُّ بِهِۦٓ إِلَّا ٱلۡفَٰسِقِينَ ﴿26﴾

Dájúdájú Allāhu kò níí tijú láti fí ohun kan (tí ó mọ) bí ẹ̀fọn tàbí ohun tí ó jù ú lọ ṣàkàwé ọ̀rọ̀. Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọn yóò mọ̀ pé dájúdájú òdodo ni láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ní ti àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, wọn yóò wí pé: “Kí ni ohun tí Allāhu gbàlérò pẹ̀lú àkàwé yìí?” Allāhu ń fi ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Ó sì ń fi tọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sọ́nà. Kò sì níí fi ṣi ẹnikẹ́ni lọ́nà àyàfi àwọn arúfin.1

2:27

ٱلَّذِينَ يَنقُضُونَ عَهۡدَ ٱللَّهِ مِنۢ بَعۡدِ مِيثَٰقِهِۦ وَيَقۡطَعُونَ مَآ أَمَرَ ٱللَّهُ بِهِۦٓ أَن يُوصَلَ وَيُفۡسِدُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ ﴿27﴾

(Àwọn arúfin náà ni) àwọn tó ń yẹ májẹ̀mu Allāhu lẹ́yìn tí májẹ̀mu náà ti fìdí múlẹ̀, wọ́n tún ń já ohun tí Allāhu pa láṣẹ pé kí wọ́n dàpọ̀, wọ́n sì ń ṣe ìbàjẹ́ lórí ilẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni ẹni òfò.

2:28

كَيۡفَ تَكۡفُرُونَ بِٱللَّهِ وَكُنتُمۡ أَمۡوَٰتٗا فَأَحۡيَٰكُمۡۖ ثُمَّ يُمِيتُكُمۡ ثُمَّ يُحۡيِيكُمۡ ثُمَّ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿28﴾

Báwo ni ẹ ṣe ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu ná! Bẹ́ẹ̀ sì ni òkú ni yín (tẹ́lẹ̀), Ó sì sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di òkú. Lẹ́yìn náà, Ó máa sọ yín di alààyè. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.1

2:29

هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ لَكُم مَّا فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰٓ إِلَى ٱلسَّمَآءِ فَسَوَّىٰهُنَّ سَبۡعَ سَمَٰوَٰتٖۚ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿29﴾

Òun ni Ẹni tí Ó dá ohunkóhun tó wà lórí ilẹ̀ fún yín pátápátá. Lẹ́yìn náà, Ó wà l’ókè sánmọ̀, Ó sì ṣe wọ́n tógún régé sí sánmọ̀ méje. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.1

2:30

وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي جَاعِلٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ خَلِيفَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَجۡعَلُ فِيهَا مَن يُفۡسِدُ فِيهَا وَيَسۡفِكُ ٱلدِّمَآءَ وَنَحۡنُ نُسَبِّحُ بِحَمۡدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَۖ قَالَ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿30﴾

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.”Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Ọ. A óò máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọ sẹ́!” Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

2:31

وَعَلَّمَ ءَادَمَ ٱلۡأَسۡمَآءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمۡ عَلَى ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ فَقَالَ أَنۢبِـُٔونِي بِأَسۡمَآءِ هَـٰٓؤُلَآءِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿31﴾

Allāhu fi gbogbo àwọn orúkọ náà mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ ìwọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

2:32

قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ لَا عِلۡمَ لَنَآ إِلَّا مَا عَلَّمۡتَنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿32﴾

Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

2:33

قَالَ يَـٰٓـَٔادَمُ أَنۢبِئۡهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡۖ فَلَمَّآ أَنۢبَأَهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَأَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ ﴿33﴾

Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”

2:34

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿34﴾

(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.”Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs.2 Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

2:35

وَقُلۡنَا يَـٰٓـَٔادَمُ ٱسۡكُنۡ أَنتَ وَزَوۡجُكَ ٱلۡجَنَّةَ وَكُلَا مِنۡهَا رَغَدًا حَيۡثُ شِئۡتُمَا وَلَا تَقۡرَبَا هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿35﴾

A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”1

2:36

فَأَزَلَّهُمَا ٱلشَّيۡطَٰنُ عَنۡهَا فَأَخۡرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِۖ وَقُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ وَلَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُسۡتَقَرّٞ وَمَتَٰعٌ إِلَىٰ حِينٖ ﴿36﴾

Lẹ́yìn náà, Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: “Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fún yín lórí ilẹ̀ títí di ìgbà kan.”

2:37

فَتَلَقَّىٰٓ ءَادَمُ مِن رَّبِّهِۦ كَلِمَٰتٖ فَتَابَ عَلَيۡهِۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿37﴾

Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:38

قُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ مِنۡهَا جَمِيعٗاۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿38﴾

A sọ pé “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.

2:39

وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَكَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَآ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿39﴾

Àwọn tó bá sì ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n pe àwọn āyah Wa ní irọ́, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.”

2:40

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَوۡفُواْ بِعَهۡدِيٓ أُوفِ بِعَهۡدِكُمۡ وَإِيَّـٰيَ فَٱرۡهَبُونِ ﴿40﴾

Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl,ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo ṣe fún yín. Ẹ mú májẹ̀mu Mi ṣẹ, Mo máa mú (ẹ̀san) májẹ̀mu yín ṣẹ. Èmi nìkan ni kí ẹ sì páyà.

2:41

وَءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلۡتُ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَكُمۡ وَلَا تَكُونُوٓاْ أَوَّلَ كَافِرِۭ بِهِۦۖ وَلَا تَشۡتَرُواْ بِـَٔايَٰتِي ثَمَنٗا قَلِيلٗا وَإِيَّـٰيَ فَٱتَّقُونِ ﴿41﴾

Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Mo sọ̀kalẹ̀, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ẹ má ṣe ta àwọn āyah Mi ní owó pọ́ọ́kú.Èmi nìkan ṣoṣo ni kí ẹ sì bẹ̀rù.

2:42

وَلَا تَلۡبِسُواْ ٱلۡحَقَّ بِٱلۡبَٰطِلِ وَتَكۡتُمُواْ ٱلۡحَقَّ وَأَنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿42﴾

Ẹ má da irọ́ pọ̀ mọ́ òdodo, ẹ sì má fi òdodo pamọ́ nígbà tí ẹ̀yin mọ (òdodo).

2:43

وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱرۡكَعُواْ مَعَ ٱلرَّـٰكِعِينَ ﴿43﴾

Ẹ kírun, ẹ yọ zakāh, kí ẹ sì dáwọ́tẹ orúnkún pẹ̀lú àwọn olùdáwọ́tẹ-orúnkún (lórí ìrun).

2:44

أَتَأۡمُرُونَ ٱلنَّاسَ بِٱلۡبِرِّ وَتَنسَوۡنَ أَنفُسَكُمۡ وَأَنتُمۡ تَتۡلُونَ ٱلۡكِتَٰبَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿44﴾

Ṣé ẹ̀yin yóò máa pa àwọn ènìyàn l’áṣẹ ohun rere, ẹ sì ń gbàgbé ẹ̀mí ara yín, ẹ̀yin sì ń ké Tírà, ṣé ẹ kò ṣe làákàyè ni!

2:45

وَٱسۡتَعِينُواْ بِٱلصَّبۡرِ وَٱلصَّلَوٰةِۚ وَإِنَّهَا لَكَبِيرَةٌ إِلَّا عَلَى ٱلۡخَٰشِعِينَ ﴿45﴾

Ẹ wá oore (Allāhu) pẹ̀lú sùúrùàti ìrun kíkí. Dájúdájú ó lágbára (láti ṣe bẹ́ẹ̀) àyàfi fún àwọn olùpáyà (Allāhu),

2:46

ٱلَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُم مُّلَٰقُواْ رَبِّهِمۡ وَأَنَّهُمۡ إِلَيۡهِ رَٰجِعُونَ ﴿46﴾

(Àwọn olùpáyà Allāhu ni) àwọn tó mọ̀ dájúdájú pé, àwọn yóò pàdé Olúwa wọn, àti pé dájúdájú àwọn yóò padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

2:47

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَتِيَ ٱلَّتِيٓ أَنۡعَمۡتُ عَلَيۡكُمۡ وَأَنِّي فَضَّلۡتُكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿47﴾

Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, ẹ rántí ìdẹ̀ra Mi, èyí tí Mo fi ṣèdẹ̀ra fún yín. Dájúdájú Èmi tún ṣoore àjùlọ fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).

2:48

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا يُؤۡخَذُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿48﴾

Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.2

2:49

وَإِذۡ نَجَّيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ ﴿49﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

2:50

وَإِذۡ فَرَقۡنَا بِكُمُ ٱلۡبَحۡرَ فَأَنجَيۡنَٰكُمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿50﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami odò sí (ọ̀nà méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) fún yín, A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).

2:51

وَإِذۡ وَٰعَدۡنَا مُوسَىٰٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ ﴿51﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.

2:52

ثُمَّ عَفَوۡنَا عَنكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿52﴾

Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fún yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).

2:53

وَإِذۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡفُرۡقَانَ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿53﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.1

2:54

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِنَّكُمۡ ظَلَمۡتُمۡ أَنفُسَكُم بِٱتِّخَاذِكُمُ ٱلۡعِجۡلَ فَتُوبُوٓاْ إِلَىٰ بَارِئِكُمۡ فَٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ عِندَ بَارِئِكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿54﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn tó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fún yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:55

وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡكُمُ ٱلصَّـٰعِقَةُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿55﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbàgbọ́ nínú rẹ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀.

2:56

ثُمَّ بَعَثۡنَٰكُم مِّنۢ بَعۡدِ مَوۡتِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿56﴾

Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).1

2:57

وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡغَمَامَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴿57﴾

A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnuàti (ohun jíjẹ) salwā2 kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

2:58

وَإِذۡ قُلۡنَا ٱدۡخُلُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ فَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ رَغَدٗا وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا وَقُولُواْ حِطَّةٞ نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطَٰيَٰكُمۡۚ وَسَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿58﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí.Ẹ jẹ nínú ìlú náà níbikíbi tí ẹ bá fẹ́ ní gbẹdẹmukẹ. Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.2 Kí ẹ sì wí pé: “Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.” A óò forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.

2:59

فَبَدَّلَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ قَوۡلًا غَيۡرَ ٱلَّذِي قِيلَ لَهُمۡ فَأَنزَلۡنَا عَلَى ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ ﴿59﴾

Àwọn tó ṣàbòsí yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí ọ̀rọ̀ mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A sọ ìyà kalẹ̀ láti sánmọ̀ lé àwọn tó ṣàbòsí lórí nítorí pé, wọ́n ń rú òfin.

2:60

وَإِذِ ٱسۡتَسۡقَىٰ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ فَقُلۡنَا ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡحَجَرَۖ فَٱنفَجَرَتۡ مِنۡهُ ٱثۡنَتَا عَشۡرَةَ عَيۡنٗاۖ قَدۡ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٖ مَّشۡرَبَهُمۡۖ كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ مِن رِّزۡقِ ٱللَّهِ وَلَا تَعۡثَوۡاْ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُفۡسِدِينَ ﴿60﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā tọrọ omi fún ìjọ rẹ̀. A sì sọ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na òkúta.” Orísun omi méjìlá sì ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti mọ ibùmu wọn. Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu nínú arísìkí Allāhu. Kí ẹ sì má ṣèbàjẹ́ sórí ilẹ̀.

2:61

وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نَّصۡبِرَ عَلَىٰ طَعَامٖ وَٰحِدٖ فَٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُخۡرِجۡ لَنَا مِمَّا تُنۢبِتُ ٱلۡأَرۡضُ مِنۢ بَقۡلِهَا وَقِثَّآئِهَا وَفُومِهَا وَعَدَسِهَا وَبَصَلِهَاۖ قَالَ أَتَسۡتَبۡدِلُونَ ٱلَّذِي هُوَ أَدۡنَىٰ بِٱلَّذِي هُوَ خَيۡرٌۚ ٱهۡبِطُواْ مِصۡرٗا فَإِنَّ لَكُم مَّا سَأَلۡتُمۡۗ وَضُرِبَتۡ عَلَيۡهِمُ ٱلذِّلَّةُ وَٱلۡمَسۡكَنَةُ وَبَآءُو بِغَضَبٖ مِّنَ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَانُواْ يَكۡفُرُونَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَيَقۡتُلُونَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكَ بِمَا عَصَواْ وَّكَانُواْ يَعۡتَدُونَ ﴿61﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí ṣe ìfaradà lórí oúnjẹ ẹyọ kan. Nítorí náà, pe Olúwa rẹ fún wa. Kí Ó mú jáde fún wa nínú ohun tí ilẹ̀ ń hù jáde ní ewébẹ̀ rẹ̀ àti kùkúḿbà rẹ̀ àti fūmu rẹ̀ (wíìtì àti àlùbọ́sà áyù) àti ọkàbàbà rẹ̀ àti àlùbọ́sà rẹ̀.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò fi èyí tó yẹpẹrẹ pààrọ̀ èyí tí ó dára jùlọ ni? Ẹ sọ̀kalẹ̀ sínú ìlú (mìíràn). Dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń bèèrè fún ń bẹ (níbẹ̀) fún yín.” A sì mú ìyẹpẹrẹ àti òṣì bá wọn. Wọ́n sì padà wálé pẹ̀lú ìbínú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Allāhu, wọ́n sì ń pa àwọn Ànábì láì lẹ́tọ̀ọ́. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n yapa (àṣẹ Allāhu), wọ́n sì ń tayọ ẹnu-ààlà.

2:62

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَٱلَّذِينَ هَادُواْ وَٱلنَّصَٰرَىٰ وَٱلصَّـٰبِـِٔينَ مَنۡ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا فَلَهُمۡ أَجۡرُهُمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ وَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿62﴾

Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn yẹhudi àti àwọn nasọ̄rọ̄ àti àwọn sọ̄bi’u; ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, ẹ̀san wọn ń bẹ fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Kò sí ìbẹ̀rù fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.1

2:63

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ وَرَفَعۡنَا فَوۡقَكُمُ ٱلطُّورَ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿63﴾

Ẹ rántí nígbà tí A gba àdéhùn yín, A sì gbé àpáta wá sókè orí yín, (A sì sọ pé): “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáradára, kí ẹ sì rántí ohun tó wà nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).

2:64

ثُمَّ تَوَلَّيۡتُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَۖ فَلَوۡلَا فَضۡلُ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ وَرَحۡمَتُهُۥ لَكُنتُم مِّنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿64﴾

Lẹ́yìn náà, ẹ pẹ̀yìndà lẹ́yìn ìyẹn. Tí kì í bá ṣe oore àjùlọ Allāhu àti àánú Rẹ̀ lórí yín, ẹ̀yin ìbá wà nínú ẹni òfò.

2:65

وَلَقَدۡ عَلِمۡتُمُ ٱلَّذِينَ ٱعۡتَدَوۡاْ مِنكُمۡ فِي ٱلسَّبۡتِ فَقُلۡنَا لَهُمۡ كُونُواْ قِرَدَةً خَٰسِـِٔينَ ﴿65﴾

Dájúdájú ẹ mọ àwọn tó kọjá ẹnu-ààlà nínú yín nípa ọjọ́ Sabt. A sì sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni-ìgbéjìnnà sí ìkẹ́ (ẹni àbùkù ẹni yẹpẹrẹ).”

2:66

فَجَعَلۡنَٰهَا نَكَٰلٗا لِّمَا بَيۡنَ يَدَيۡهَا وَمَا خَلۡفَهَا وَمَوۡعِظَةٗ لِّلۡمُتَّقِينَ ﴿66﴾

A sì ṣe é ní ìyà (àríkọ́gbọ́n) fún ẹni tó ṣojú rẹ̀ àti ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. (Ó tún jẹ́) wáàsí (ìṣítí) fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

2:67

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَأۡمُرُكُمۡ أَن تَذۡبَحُواْ بَقَرَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَتَّخِذُنَا هُزُوٗاۖ قَالَ أَعُوذُ بِٱللَّهِ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ ﴿67﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Dájúdájú Allāhu ń pa yín ní àṣẹ pé kí ẹ pa abo màálù kan.” Wọ́n wí pé: “Ṣé ò ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ ni!” Ó sọ pé: “Mò ń sádi Allāhu kúrò níbi kí n̄g jẹ́ ara àwọn òpè.”

2:68

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا فَارِضٞ وَلَا بِكۡرٌ عَوَانُۢ بَيۡنَ ذَٰلِكَۖ فَٱفۡعَلُواْ مَا تُؤۡمَرُونَ ﴿68﴾

Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ ògbólógbòó, kò sì níí jẹ́ gódógbó. Ọdún rẹ̀ máa wà láààrin (méjèèjì) yẹn. Nítorí náà, ẹ ṣe ohun tí wọ́n ń pa yín láṣẹ.”

2:69

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا لَوۡنُهَاۚ قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ صَفۡرَآءُ فَاقِعٞ لَّوۡنُهَا تَسُرُّ ٱلنَّـٰظِرِينَ ﴿69﴾

Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí àwọ̀ rẹ̀ bá jẹ́ fún wa.” Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù, aláwọ̀ omi-ọsàn ni. Àwọ̀ rẹ̀ sì máa mọ́ fónífóní, tí ó máa dùn-ún wò lójú àwọn olùwòran.

2:70

قَالُواْ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّن لَّنَا مَا هِيَ إِنَّ ٱلۡبَقَرَ تَشَٰبَهَ عَلَيۡنَا وَإِنَّآ إِن شَآءَ ٱللَّهُ لَمُهۡتَدُونَ ﴿70﴾

Wọ́n wí pé: “Pe Olúwa rẹ fún wa, kí Ó ṣàlàyé irú èyí tí ó bá jẹ́ fún wa sẹ́.” Dájúdájú àwọn abo màálù jọra wọn lójú wa. Àti pé dájúdájú, tí Allāhu bá fẹ́, àwa máa mọ̀nà (tí a ó gbà rí i.)”

2:71

قَالَ إِنَّهُۥ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٞ لَّا ذَلُولٞ تُثِيرُ ٱلۡأَرۡضَ وَلَا تَسۡقِي ٱلۡحَرۡثَ مُسَلَّمَةٞ لَّا شِيَةَ فِيهَاۚ قَالُواْ ٱلۡـَٰٔنَ جِئۡتَ بِٱلۡحَقِّۚ فَذَبَحُوهَا وَمَا كَادُواْ يَفۡعَلُونَ ﴿71﴾

Ó sọ pé: “Dájúdájú Ó ń sọ pé abo màálù ni. Kò níí jẹ́ màálù yẹpẹrẹ tí ó ń kọ ebè sórí ilẹ̀ (tó ń ro oko) àti èyí tí ó ń fomi wọ́n oko. Ó máa ní àlàáfíà, kò sì níí ní àbàwọ́n kan lára.” Wọ́n wí pé: “Nísinsìn yìí lo mú òdodo wá.” Wọ́n sì pa màálù náà. Wọ́n fẹ́ẹ̀ má ṣe é mọ́.

2:72

وَإِذۡ قَتَلۡتُمۡ نَفۡسٗا فَٱدَّـٰرَ ٰٔتُمۡ فِيهَاۖ وَٱللَّهُ مُخۡرِجٞ مَّا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ ﴿72﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ pa ẹnì kan, ẹ sì ń tì í síra yín. Allāhu yó sì ṣàfi hàn ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́.

2:73

فَقُلۡنَا ٱضۡرِبُوهُ بِبَعۡضِهَاۚ كَذَٰلِكَ يُحۡيِ ٱللَّهُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَيُرِيكُمۡ ءَايَٰتِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴿73﴾

Nítorí náà, A sọ pé: “Ẹ fi burè kan (lára màálù) lu (òkú náà).”Báyẹn ni Allāhu ṣe ń sọ òkú di alààyè. Ó sì ń fi àwọn àmì Rẹ̀ hàn yín, nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

2:74

ثُمَّ قَسَتۡ قُلُوبُكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ فَهِيَ كَٱلۡحِجَارَةِ أَوۡ أَشَدُّ قَسۡوَةٗۚ وَإِنَّ مِنَ ٱلۡحِجَارَةِ لَمَا يَتَفَجَّرُ مِنۡهُ ٱلۡأَنۡهَٰرُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَشَّقَّقُ فَيَخۡرُجُ مِنۡهُ ٱلۡمَآءُۚ وَإِنَّ مِنۡهَا لَمَا يَهۡبِطُ مِنۡ خَشۡيَةِ ٱللَّهِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿74﴾

Lẹ́yìn náà, ọkàn yín le lẹ́yìn ìyẹn. Ó sì dà bí òkúta tàbí líle tó lágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ.Dájúdájú ó ń bẹ nínú àwọn òkúta tí àwọn odò ń ṣàn jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó máa sán kànkàn. Omi sì máa jáde láti inú rẹ̀. Dájúdájú ó tún ń bẹ nínú wọn tí ó ń wó lulẹ̀ gbì fún ìpáyà Allāhu. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:75

أَفَتَطۡمَعُونَ أَن يُؤۡمِنُواْ لَكُمۡ وَقَدۡ كَانَ فَرِيقٞ مِّنۡهُمۡ يَسۡمَعُونَ كَلَٰمَ ٱللَّهِ ثُمَّ يُحَرِّفُونَهُۥ مِنۢ بَعۡدِ مَا عَقَلُوهُ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ ﴿75﴾

Ṣé ẹ̀ ń rankàn pé wọn yóò gbà yín gbọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé igun kan nínú wọn kúkú ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, wọ́n á yí i padà sódì lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ọ yé; wọ́n sì mọ̀.

2:76

وَإِذَا لَقُواْ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ قَالُوٓاْ ءَامَنَّا وَإِذَا خَلَا بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ قَالُوٓاْ أَتُحَدِّثُونَهُم بِمَا فَتَحَ ٱللَّهُ عَلَيۡكُمۡ لِيُحَآجُّوكُم بِهِۦ عِندَ رَبِّكُمۡۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿76﴾

Nígbà tí wọ́n bá sì pàdé àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́.” Nígbà tí ó bá sì ku apá kan wọn ku apá kan, wọ́n á wí pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Allāhu ti ṣípayá rẹ̀ fún yín, kí wọ́n lè fi jà yín níyàn ní ọ̀dọ̀ Olúwa yín? Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni!”

2:77

أَوَلَا يَعۡلَمُونَ أَنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ مَا يُسِرُّونَ وَمَا يُعۡلِنُونَ ﴿77﴾

Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu mọ ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ àti ohun tí wọ́n ń ṣàfi hàn rẹ̀?

2:78

وَمِنۡهُمۡ أُمِّيُّونَ لَا يَعۡلَمُونَ ٱلۡكِتَٰبَ إِلَّآ أَمَانِيَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَظُنُّونَ ﴿78﴾

Àti pé ó wà nínú wọn, àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, tí wọn kò nímọ̀ nípa Tírà àfi àwọn irọ́. Kí ni wọ́n (ń sọ) bí kò ṣe pé wọ́n ń dá àbá (àròsọ).

2:79

فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ يَكۡتُبُونَ ٱلۡكِتَٰبَ بِأَيۡدِيهِمۡ ثُمَّ يَقُولُونَ هَٰذَا مِنۡ عِندِ ٱللَّهِ لِيَشۡتَرُواْ بِهِۦ ثَمَنٗا قَلِيلٗاۖ فَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا كَتَبَتۡ أَيۡدِيهِمۡ وَوَيۡلٞ لَّهُم مِّمَّا يَكۡسِبُونَ ﴿79﴾

Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ń fi ọwọ́ ara wọn kọ tírà, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Nítorí kí wọ́n lè tà á ní owó pọ́ọ́kú. Ègbé ni fún wọn sẹ́ nípa ohun tí ọwọ́ wọn kọ. Ègbé sì ni fún wọn pẹ̀lú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

2:80

وَقَالُواْ لَن تَمَسَّنَا ٱلنَّارُ إِلَّآ أَيَّامٗا مَّعۡدُودَةٗۚ قُلۡ أَتَّخَذۡتُمۡ عِندَ ٱللَّهِ عَهۡدٗا فَلَن يُخۡلِفَ ٱللَّهُ عَهۡدَهُۥٓۖ أَمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿80﴾

Wọ́n sì wí pé: “Iná kò lè fọwọ́ bà wá tayọ ọjọ́ tó lóǹkà.” Sọ pé: “Ṣé ẹ ti rí àdéhùn kan gbà lọ́dọ̀ Allāhu ni?”Allāhu kò sì níí yapa àdéhùn Rẹ̀. Àbí ṣé ẹ̀yin yóò máa pa irọ́ ohun tí ẹ kò nímọ̀ nípa rẹ̀ mọ́ Allāhu ni?

2:81

بَلَىٰۚ مَن كَسَبَ سَيِّئَةٗ وَأَحَٰطَتۡ بِهِۦ خَطِيٓـَٔتُهُۥ فَأُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿81﴾

Rárá (Iná kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí); ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ ibi kan, tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tún yí i ká, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:82

وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿82﴾

Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

2:83

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ لَا تَعۡبُدُونَ إِلَّا ٱللَّهَ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَانٗا وَذِي ٱلۡقُرۡبَىٰ وَٱلۡيَتَٰمَىٰ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَقُولُواْ لِلنَّاسِ حُسۡنٗا وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتُواْ ٱلزَّكَوٰةَ ثُمَّ تَوَلَّيۡتُمۡ إِلَّا قَلِيلٗا مِّنكُمۡ وَأَنتُم مُّعۡرِضُونَ ﴿83﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl pé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ọlọ́hun kan àyàfi Allāhu. Kí ẹ sì ṣe dáadáa sí àwọn òbí méjèèjì, ìbátan, àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn mẹ̀kúnnù.Ẹ bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ rere. Ẹ kírun, kí ẹ sì yọ Zakāh. Lẹ́yìn náà lẹ pẹ̀yìn dà àfi díẹ̀ nínú yín. Ẹ̀yin sì ń gbúnrí (kúrò níbi àdéhùn).

2:84

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِيثَٰقَكُمۡ لَا تَسۡفِكُونَ دِمَآءَكُمۡ وَلَا تُخۡرِجُونَ أَنفُسَكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ ثُمَّ أَقۡرَرۡتُمۡ وَأَنتُمۡ تَشۡهَدُونَ ﴿84﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A gba àdéhùn lọ́wọ́ yínpé, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ta ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ léra yín jáde kúrò nínú ilé yín. Lẹ́yìn náà, ẹ fi rinlẹ̀, ẹ sì ń jẹ́rìí sí i.

2:85

ثُمَّ أَنتُمۡ هَـٰٓؤُلَآءِ تَقۡتُلُونَ أَنفُسَكُمۡ وَتُخۡرِجُونَ فَرِيقٗا مِّنكُم مِّن دِيَٰرِهِمۡ تَظَٰهَرُونَ عَلَيۡهِم بِٱلۡإِثۡمِ وَٱلۡعُدۡوَٰنِ وَإِن يَأۡتُوكُمۡ أُسَٰرَىٰ تُفَٰدُوهُمۡ وَهُوَ مُحَرَّمٌ عَلَيۡكُمۡ إِخۡرَاجُهُمۡۚ أَفَتُؤۡمِنُونَ بِبَعۡضِ ٱلۡكِتَٰبِ وَتَكۡفُرُونَ بِبَعۡضٖۚ فَمَا جَزَآءُ مَن يَفۡعَلُ ذَٰلِكَ مِنكُمۡ إِلَّا خِزۡيٞ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَيَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يُرَدُّونَ إِلَىٰٓ أَشَدِّ ٱلۡعَذَابِۗ وَمَا ٱللَّهُ بِغَٰفِلٍ عَمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿85﴾

Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin wọ̀nyí lẹ̀ ń pa ara yín. Ẹ tún ń lé apá kan nínú yín jáde kúrò nínú ilé wọn. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àti àbòsí ṣèrànwọ́ (fún àwọn ọ̀tá) lórí wọn. Tí wọ́n bá sì wá ba yín (tí wọ́n ti di) ẹrú, ẹ̀yin ń rà wọ́n (láti fi’ra yín ṣẹrú). Èèwọ̀ sì fẹ̀ẹ̀kan ni fún yín láti lé wọn jáde. Ṣé ẹ̀yin yóò gba apá kan Tírà gbọ́, ẹ sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú apá kan? Nítorí náà, kí ni ẹ̀san fún ẹni tó ṣè yẹn nínú yín bí kò ṣe àbùkù nínú ìṣẹ̀mí ayé. Ní ọjọ́ Àjíǹde, wọ́n sì máa dá wọn padà sínú ìyà tó le jùlọ. Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

2:86

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱشۡتَرَوُاْ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا بِٱلۡأٓخِرَةِۖ فَلَا يُخَفَّفُ عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابُ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿86﴾

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fi ọ̀run ra ìṣẹ̀mí ayé.Nítorí náà, A ò níí ṣe ìyà ní fífúyẹ́ fún wọn, A ò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

2:87

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَقَفَّيۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ بِٱلرُّسُلِۖ وَءَاتَيۡنَا عِيسَى ٱبۡنَ مَرۡيَمَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَأَيَّدۡنَٰهُ بِرُوحِ ٱلۡقُدُسِۗ أَفَكُلَّمَا جَآءَكُمۡ رَسُولُۢ بِمَا لَا تَهۡوَىٰٓ أَنفُسُكُمُ ٱسۡتَكۡبَرۡتُمۡ فَفَرِيقٗا كَذَّبۡتُمۡ وَفَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ ﴿87﴾

Dájúdájú A ti fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. A sì mú àwọn Òjíṣẹ́ wá ní tẹ̀léǹtẹ̀lé lẹ́yìn rẹ̀. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú.A sì fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, Mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Ṣé gbogbo ìgbà tí Òjíṣẹ́ kan bá wá ba yín pẹ̀lú ohun tí ọkàn yín kò fẹ́ ni ẹ ó máa ṣègbéraga? Ẹ sì pe apá kan (àwọn Ànábì) ní òpùrọ́, ẹ sì ń pa apá kan!

2:88

وَقَالُواْ قُلُوبُنَا غُلۡفُۢۚ بَل لَّعَنَهُمُ ٱللَّهُ بِكُفۡرِهِمۡ فَقَلِيلٗا مَّا يُؤۡمِنُونَ ﴿88﴾

Wọ́n sì wí pé: “Èbìbò bò wá lọ́kàn.” Kò sì rí bẹ́ẹ̀. Allāhu ti ṣẹ́bi lé wọn ni, nítorí àìgbàgbọ́ wọn. Ṣebí díẹ̀ ni wọ́n ń gbàgbọ́.

2:89

وَلَمَّا جَآءَهُمۡ كِتَٰبٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِ مُصَدِّقٞ لِّمَا مَعَهُمۡ وَكَانُواْ مِن قَبۡلُ يَسۡتَفۡتِحُونَ عَلَى ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فَلَمَّا جَآءَهُم مَّا عَرَفُواْ كَفَرُواْ بِهِۦۚ فَلَعۡنَةُ ٱللَّهِ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿89﴾

Nígbà tí Tírà kan sì dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Allāhu, tí ó ń fi ìdí òdodo múlẹ̀ nípa ohun tí ó wà pẹ̀lú wọn (ìyẹn tírà Taorāt), bẹ́ẹ̀ sì ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti ń tọrọ ìṣẹ́gun lórí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, àmọ́ nígbà tí ohun tí wọ́n nímọ̀ nípa rẹ̀ dé bá wọn, wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ibi dandan Allāhu kí ó máa bá àwọn aláìgbàgbọ́.1

2:90

بِئۡسَمَا ٱشۡتَرَوۡاْ بِهِۦٓ أَنفُسَهُمۡ أَن يَكۡفُرُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ بَغۡيًا أَن يُنَزِّلَ ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ عَلَىٰ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ فَبَآءُو بِغَضَبٍ عَلَىٰ غَضَبٖۚ وَلِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابٞ مُّهِينٞ ﴿90﴾

Aburú ni ohun tí wọ́n rà fún ẹ̀mí ara wọn nípa bí wọ́n ṣe ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀, ní ti ìlara pé Allāhu ń sọ (Tírà) kalẹ̀ nínú oore àjùlọ Rẹ̀ fún ẹni tí Ó fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Wọ́n sì padà pẹ̀lú ìbínú (mìíràn) lórí ìbínú (Allāhu tí ó ti wà lórí wọn tẹ́lẹ̀). Ìyà tí í yẹpẹrẹ (ẹ̀dá) sì ń bẹ fún àwọn aláìgbàgbọ́.

2:91

وَإِذَا قِيلَ لَهُمۡ ءَامِنُواْ بِمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ قَالُواْ نُؤۡمِنُ بِمَآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا وَيَكۡفُرُونَ بِمَا وَرَآءَهُۥ وَهُوَ ٱلۡحَقُّ مُصَدِّقٗا لِّمَا مَعَهُمۡۗ قُلۡ فَلِمَ تَقۡتُلُونَ أَنۢبِيَآءَ ٱللَّهِ مِن قَبۡلُ إِن كُنتُم مُّؤۡمِنِينَ ﴿91﴾

Nígbà tí wọ́n bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa.” Wọ́n sì ń ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tó wà lẹ́yìn rẹ̀, òhun sì ni òdodo, tí ó ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wà pẹ̀lú wọn. Sọ pé: “Nítorí kí ni ẹ fi ń pa àwọn Ànábì Allāhu tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo?