quranm◉

Hizb 42

Range
from 32:11 to 33:50
Surahs covered
Ìtumọ̀
70 Ìtumọ̀

◉

32:11

قُلۡ يَتَوَفَّىٰكُم مَّلَكُ ٱلۡمَوۡتِ ٱلَّذِي وُكِّلَ بِكُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُمۡ تُرۡجَعُونَ ﴿11﴾

Sọ pé: “Mọlāika ikú èyí tí A yàn fún yín máa gba ẹ̀mí yín. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni wọn máa da yín padà sí.”1

32:12

وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلۡمُجۡرِمُونَ نَاكِسُواْ رُءُوسِهِمۡ عِندَ رَبِّهِمۡ رَبَّنَآ أَبۡصَرۡنَا وَسَمِعۡنَا فَٱرۡجِعۡنَا نَعۡمَلۡ صَٰلِحًا إِنَّا مُوقِنُونَ ﴿12﴾

(Ìwọ ìbá rí èèmọ̀) tí ó bá jẹ́ pé o rí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà tí wọ́n bá sorí kọ́ ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, (wọ́n sì máa wí pé): “Olúwa wa, a ti ríran, a sì ti gbọ́ràn (báyìí), nítorí náà, dá wa padà (sí ilé ayé) nítorí kí á lè lọ ṣe iṣẹ́ rere; dájúdájú àwa ni alámọ̀dájú.”

32:13

وَلَوۡ شِئۡنَا لَأٓتَيۡنَا كُلَّ نَفۡسٍ هُدَىٰهَا وَلَٰكِنۡ حَقَّ ٱلۡقَوۡلُ مِنِّي لَأَمۡلَأَنَّ جَهَنَّمَ مِنَ ٱلۡجِنَّةِ وَٱلنَّاسِ أَجۡمَعِينَ ﴿13﴾

Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́ ni, dájúdájú A ìbá fún gbogbo ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ìmọ̀nà rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà ti ṣẹ láti ọ̀dọ̀ Mi (báyìí pé): “Dájúdájú Mo máa mú nínú àwọn àlùjànnú àti ènìyàn ní àpapọ̀ kún inú iná Jahanamọ.”

32:14

فَذُوقُواْ بِمَا نَسِيتُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَآ إِنَّا نَسِينَٰكُمۡۖ وَذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡخُلۡدِ بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿14﴾

Nítorí náà, ẹ tọ́ ìyà wò nítorí pé ẹ ti gbàgbé ìpàdé ọjọ́ yín (òní) yìí. Dájúdájú Àwa náà yóò gbàgbé yín (sínú Iná). Ẹ tọ́ ìyà gbére wò nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.1

32:15

إِنَّمَا يُؤۡمِنُ بِـَٔايَٰتِنَا ٱلَّذِينَ إِذَا ذُكِّرُواْ بِهَا خَرُّواْۤ سُجَّدٗاۤ وَسَبَّحُواْ بِحَمۡدِ رَبِّهِمۡ وَهُمۡ لَا يَسۡتَكۡبِرُونَ۩ ﴿15﴾

Àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa ni àwọn tí ó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá fi ṣe ìṣítí fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀ ní olùforíkanlẹ̀, wọn yó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọn kò sì níí ṣègbéraga.

32:16

تَتَجَافَىٰ جُنُوبُهُمۡ عَنِ ٱلۡمَضَاجِعِ يَدۡعُونَ رَبَّهُمۡ خَوۡفٗا وَطَمَعٗا وَمِمَّا رَزَقۡنَٰهُمۡ يُنفِقُونَ ﴿16﴾

Wọ́n ń gbé ẹ̀gbẹ́ wọn jìnnà sí ibùsùn. Wọ́n sì ń pe Olúwa wọn ní ti ìpáyà àti ìrètí. Wọ́n sì ń ná nínú ohun tí A pèsè fún wọn.

32:17

فَلَا تَعۡلَمُ نَفۡسٞ مَّآ أُخۡفِيَ لَهُم مِّن قُرَّةِ أَعۡيُنٖ جَزَآءَۢ بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿17﴾

Kò sí ẹ̀mí kan tí ó mọ ohun tí A fi pamọ́ fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan ìtutù ojú. (Ó jẹ́) ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

32:18

أَفَمَن كَانَ مُؤۡمِنٗا كَمَن كَانَ فَاسِقٗاۚ لَّا يَسۡتَوُۥنَ ﴿18﴾

Ǹjẹ́ ẹni tó jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo dà bí ẹni tó jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́ bí? Wọn kò dọ́gba.

32:19

أَمَّا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَلَهُمۡ جَنَّـٰتُ ٱلۡمَأۡوَىٰ نُزُلَۢا بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿19﴾

Ní ti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere, àwọn ibùgbé (nínú) Ọ̀gbà Ìdẹ̀ra ń bẹ fún wọn. (Ó jẹ́) ohun tí A pèsè sílẹ̀ (dè wọ́n) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere).

32:20

وَأَمَّا ٱلَّذِينَ فَسَقُواْ فَمَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُۖ كُلَّمَآ أَرَادُوٓاْ أَن يَخۡرُجُواْ مِنۡهَآ أُعِيدُواْ فِيهَا وَقِيلَ لَهُمۡ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلنَّارِ ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ﴿20﴾

Ní ti àwọn tó balẹ̀jẹ́, Iná ni ibùgbé wọn. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá fẹ́ jáde kúrò nínú rẹ̀, A ó sì máa dá wọn padà sínú rẹ̀. A sì máa sọ fún wọn pé: “Ẹ tọ́ ìyà Iná tí ẹ̀ ń pè ní irọ́ wò.”1

32:21

وَلَنُذِيقَنَّهُم مِّنَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَدۡنَىٰ دُونَ ٱلۡعَذَابِ ٱلۡأَكۡبَرِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ﴿21﴾

Dájúdájú A máa fún wọn tọ́ wò nínú ìyà tó kéré jùlọ (nílé ayé) yàtọ̀ sí ìyà tó tóbi jùlọ (lọ́run) nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo ṣíwájú ikú wọn).

32:22

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن ذُكِّرَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦ ثُمَّ أَعۡرَضَ عَنۡهَآۚ إِنَّا مِنَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ مُنتَقِمُونَ ﴿22﴾

Àti pé ta l’ó ṣe àbòsí tó tayọ ẹni tí wọn fi àwọn āyah Wa ṣe ìṣítí fún, lẹ́yìn náà, tí ó gbúnrí kúrò níbẹ̀? Dájúdájú Àwa máa gbẹ̀san lára àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.

32:23

وَلَقَدۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ فَلَا تَكُن فِي مِرۡيَةٖ مِّن لِّقَآئِهِۦۖ وَجَعَلۡنَٰهُ هُدٗى لِّبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ﴿23﴾

Dájúdájú A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa bí ó ṣe pàdé rẹ̀ (ìyẹn, nínú ìrìn-àjò òru àti gígun sánmọ̀).A sì ṣe Tírà A sì ṣe Tírà náà ní ìmọ̀nà fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.

32:24

وَجَعَلۡنَا مِنۡهُمۡ أَئِمَّةٗ يَهۡدُونَ بِأَمۡرِنَا لَمَّا صَبَرُواْۖ وَكَانُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يُوقِنُونَ ﴿24﴾

Àti pé A ṣe àwọn kan nínú wọn ní Imām (aṣíwájú) tí wọ́n ń fi àṣẹ Wa (ohun tí A pa wọ́n ní àṣẹ rẹ̀ nínú at-Taorāh) tọ́ àwọn ènìyàn wọn sí ọ̀nà òdodo. (A ṣe wọ́n bẹ́ẹ̀) nígbà tí wọ́n ṣe sùúrù, tí wọ́n sì ní àmọ̀dájú nípa àwọn āyah Wa.

32:25

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ يَفۡصِلُ بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ﴿25﴾

Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó máa ṣe ìdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

32:26

أَوَلَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٍۚ أَفَلَا يَسۡمَعُونَ ﴿26﴾

Ṣé kò fojú hàn sí wọn pé, mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn. Àwọn náà sì ń rìn kọjá nínú àwọn ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn. Nítorí náà, ṣé wọn kò níí tẹ́tí gbọ́rọ̀ (òdodo ni)?

32:27

أَوَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّا نَسُوقُ ٱلۡمَآءَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡجُرُزِ فَنُخۡرِجُ بِهِۦ زَرۡعٗا تَأۡكُلُ مِنۡهُ أَنۡعَٰمُهُمۡ وَأَنفُسُهُمۡۚ أَفَلَا يُبۡصِرُونَ ﴿27﴾

Tàbí wọn kò rí i pé dájúdájú Àwa l’À ń wa omi òjò lọ sórí ilẹ̀ gbígbẹ, tí A sì ń fi mú irúgbìn jáde? Àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn àti àwọn náà sì ń jẹ nínú rẹ̀. Nítorí náà, ṣé wọn kò ríran ni?

32:28

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡفَتۡحُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿28﴾

Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

32:29

قُلۡ يَوۡمَ ٱلۡفَتۡحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِيمَٰنُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ ﴿29﴾

Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”1

32:30

فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ وَٱنتَظِرۡ إِنَّهُم مُّنتَظِرُونَ ﴿30﴾

Nítorí náà, ṣẹ́rí kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí o sì máa retí (Ọjọ́ Ìdájọ́). Dájúdájú àwọn náà ń retí (rẹ̀).

33:1

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ ٱتَّقِ ٱللَّهَ وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ عَلِيمًا حَكِيمٗا ﴿1﴾

Ìwọ Ànábì, bẹ̀rù Allāhu. Má sì tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣẹ̀lu mùsùlùmí. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

33:2

وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرٗا ﴿2﴾

Tẹ̀lé ohun tí A ń mú wá fún ọ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

33:3

وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا ﴿3﴾

Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣọ́.

33:4

مَّا جَعَلَ ٱللَّهُ لِرَجُلٖ مِّن قَلۡبَيۡنِ فِي جَوۡفِهِۦۚ وَمَا جَعَلَ أَزۡوَٰجَكُمُ ٱلَّـٰٓـِٔي تُظَٰهِرُونَ مِنۡهُنَّ أُمَّهَٰتِكُمۡۚ وَمَا جَعَلَ أَدۡعِيَآءَكُمۡ أَبۡنَآءَكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ قَوۡلُكُم بِأَفۡوَٰهِكُمۡۖ وَٱللَّهُ يَقُولُ ٱلۡحَقَّ وَهُوَ يَهۡدِي ٱلسَّبِيلَ ﴿4﴾

Allāhu kò fún ènìyàn kan ní ọkàn méjì nínú ikùn rẹ̀. (Allāhu) kò sì sọ àwọn ìyàwó yín, tí ẹ̀ ń fi ẹ̀yìn wọn wé ẹ̀yìn ìyá yín, di ìyá yín. Àti pé (Allāhu) kò sọ àwọn ọmọ-ọlọ́mọ tí ẹ̀ ń pè ní ọmọ yín di ọmọ yín. Ìyẹn ni ọ̀rọ̀ ẹnu yín. Allāhu ń sọ òdodo. Àti pé Òun l’Ó ń fi (ẹ̀dá) mọ̀nà.

33:5

ٱدۡعُوهُمۡ لِأٓبَآئِهِمۡ هُوَ أَقۡسَطُ عِندَ ٱللَّهِۚ فَإِن لَّمۡ تَعۡلَمُوٓاْ ءَابَآءَهُمۡ فَإِخۡوَٰنُكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَمَوَٰلِيكُمۡۚ وَلَيۡسَ عَلَيۡكُمۡ جُنَاحٞ فِيمَآ أَخۡطَأۡتُم بِهِۦ وَلَٰكِن مَّا تَعَمَّدَتۡ قُلُوبُكُمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمًا ﴿5﴾

Ẹ pè wọ́n pẹ̀lú orúkọ bàbá wọn. Òhun l’ó ṣe déédé jùlọ lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n tí ẹ kò bá mọ (orúkọ) bàbá wọn, ọmọ ìyá yín nínú ẹ̀sìn àti ẹrú yín kúkú ni wọ́n.Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín níbi ohun tí ẹ ti ṣàṣìṣe, ṣùgbọ́n (ẹ̀ṣẹ̀ wà níbi) ohun tí ọkàn yín mọ̀ọ́mọ̀ ṣe. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

33:6

ٱلنَّبِيُّ أَوۡلَىٰ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ مِنۡ أَنفُسِهِمۡۖ وَأَزۡوَٰجُهُۥٓ أُمَّهَٰتُهُمۡۗ وَأُوْلُواْ ٱلۡأَرۡحَامِ بَعۡضُهُمۡ أَوۡلَىٰ بِبَعۡضٖ فِي كِتَٰبِ ٱللَّهِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُهَٰجِرِينَ إِلَّآ أَن تَفۡعَلُوٓاْ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِكُم مَّعۡرُوفٗاۚ كَانَ ذَٰلِكَ فِي ٱلۡكِتَٰبِ مَسۡطُورٗا ﴿6﴾

Ànábì ní ẹ̀tọ́ sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo ju ẹ̀mí ara wọn lọ (nípa ìfẹ́ rẹ̀ àti ìdájọ́ rẹ̀).Àwọn aya rẹ̀ sì ni ìyá wọn. Nínú Tírà Allāhu, àwọn ẹbí, apá kan wọn ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ ju apá kan lọ. (Àwọn ẹbí tún ní ẹ̀tọ́ sí ogún jíjẹ) ju àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn tó kúrò nínú ìlú Mọkkah fún ààbò ẹ̀sìn, àfi tí ẹ bá máa ṣe dáadáa kan sí àwọn ọ̀rẹ́ yín (wọ̀nyí ni ogún lè fi kàn wọ́n pẹ̀lú àsọọ́lẹ̀).2 Ìyẹn wà nínú Tírà (Laohul-Mahfūṭḥ) ní àkọsílẹ̀.

33:7

وَإِذۡ أَخَذۡنَا مِنَ ٱلنَّبِيِّـۧنَ مِيثَٰقَهُمۡ وَمِنكَ وَمِن نُّوحٖ وَإِبۡرَٰهِيمَ وَمُوسَىٰ وَعِيسَى ٱبۡنِ مَرۡيَمَۖ وَأَخَذۡنَا مِنۡهُم مِّيثَٰقًا غَلِيظٗا ﴿7﴾

(Rántí) nígbà tí A gba àdéhùn ní ọwọ́ àwọn Ànábì àti ní ọwọ́ rẹ, àti ní ọwọ́ (Ànábì) Nūh, ’Ibrọ̄hīm, Mūsā àti ‘Īsā ọmọ Mọryam. A gba àdéhùn ní ọwọ́ wọn ní àdéhùn tó nípọn

33:8

لِّيَسۡـَٔلَ ٱلصَّـٰدِقِينَ عَن صِدۡقِهِمۡۚ وَأَعَدَّ لِلۡكَٰفِرِينَ عَذَابًا أَلِيمٗا ﴿8﴾

nítorí kí (Allāhu) lè bèèrè (òdodo) àwọn olódodo nípa òdodo wọn. Ó sì pèsè ìyà ẹlẹ́ta-eléro sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

33:9

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَآءَتۡكُمۡ جُنُودٞ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا وَجُنُودٗا لَّمۡ تَرَوۡهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا ﴿9﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ kò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.1

33:10

إِذۡ جَآءُوكُم مِّن فَوۡقِكُمۡ وَمِنۡ أَسۡفَلَ مِنكُمۡ وَإِذۡ زَاغَتِ ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَبَلَغَتِ ٱلۡقُلُوبُ ٱلۡحَنَاجِرَ وَتَظُنُّونَ بِٱللَّهِ ٱلظُّنُونَا۠ ﴿10﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí wọ́n dé ba yín láti òkè yín àti ìsàlẹ̀ yín, àti nígbà tí àwọn ojú yẹ̀ (sọ́tùn-ún sósì), tí àwọn ọkàn sí dé ọ̀nà-ọ̀fun (ní ti ìpáyà). Ẹ sì ń ro àwọn èrò kan nípa Allāhu.

33:11

هُنَالِكَ ٱبۡتُلِيَ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ وَزُلۡزِلُواْ زِلۡزَالٗا شَدِيدٗا ﴿11﴾

Níbẹ̀ yẹn ni wọ́n ti fi àdánwò kan àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọ́n sì milẹ̀ mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ ní ìmìtìtì líle.

33:12

وَإِذۡ يَقُولُ ٱلۡمُنَٰفِقُونَ وَٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ مَّا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ إِلَّا غُرُورٗا ﴿12﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí àti àwọn tí àìsàn wà nínú ọkàn wọn ń wí pé: “Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kò ṣe àdéhùn kan fún wa bí kò ṣe ẹ̀tàn.”

33:13

وَإِذۡ قَالَت طَّآئِفَةٞ مِّنۡهُمۡ يَـٰٓأَهۡلَ يَثۡرِبَ لَا مُقَامَ لَكُمۡ فَٱرۡجِعُواْۚ وَيَسۡتَـٔۡذِنُ فَرِيقٞ مِّنۡهُمُ ٱلنَّبِيَّ يَقُولُونَ إِنَّ بُيُوتَنَا عَوۡرَةٞ وَمَا هِيَ بِعَوۡرَةٍۖ إِن يُرِيدُونَ إِلَّا فِرَارٗا ﴿13﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí igun kan nínú wọn wí pé: “Ẹ̀yin ará Yẹthrib,kò sí àyè (ìṣẹ́gun) fún yín, nítorí náà, ẹ ṣẹ́rí padà (lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́).” Apá kan nínú wọn sì ń tọrọ ìyọ̀ǹda lọ́wọ́ Ànábì, wọ́n ń wí pé: “Dájúdájú ilé wa dá páropáro ni.” (Ilé wọn) kò sì dá páropáro. Wọn kò sì gbèrò ohun kan tayọ síságun.

33:14

وَلَوۡ دُخِلَتۡ عَلَيۡهِم مِّنۡ أَقۡطَارِهَا ثُمَّ سُئِلُواْ ٱلۡفِتۡنَةَ لَأٓتَوۡهَا وَمَا تَلَبَّثُواْ بِهَآ إِلَّا يَسِيرٗا ﴿14﴾

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé (ọmọ ogun oníjọ) wọlé tọ̀ wọ́n wá láti àwọn ìloro ìlú (Mọdīnah), lẹ́yìn náà, kí wọ́n pe (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) sínú ẹbọ ṣíṣe, wọn ìbá ṣẹbọ. Wọn kò sì níí gbé nínú ìlú mọ́ tayọ ìgbà díẹ̀ (tí wọn yóò fi parẹ́).

33:15

وَلَقَدۡ كَانُواْ عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ مِن قَبۡلُ لَا يُوَلُّونَ ٱلۡأَدۡبَٰرَۚ وَكَانَ عَهۡدُ ٱللَّهِ مَسۡـُٔولٗا ﴿15﴾

Dájúdájú wọ́n ti bá Allāhu ṣe àdéhùn ṣíwájú pé àwọn kò níí pẹ̀yìndà (láti ságun). Àdéhùn Allāhu sì jẹ́ ohun tí wọ́n máa bèèrè (lọ́wọ́ wọn).

33:16

قُل لَّن يَنفَعَكُمُ ٱلۡفِرَارُ إِن فَرَرۡتُم مِّنَ ٱلۡمَوۡتِ أَوِ ٱلۡقَتۡلِ وَإِذٗا لَّا تُمَتَّعُونَ إِلَّا قَلِيلٗا ﴿16﴾

Sọ pé: “Síságun yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí ẹ bá sá fún ikú tàbí pípa (sí ojú ogun ẹ̀sìn. Tí ẹ bá sì ságun) nígbà náà, A kò níí fún yín ní ìgbádùn ayé bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.

33:17

قُلۡ مَن ذَا ٱلَّذِي يَعۡصِمُكُم مِّنَ ٱللَّهِ إِنۡ أَرَادَ بِكُمۡ سُوٓءًا أَوۡ أَرَادَ بِكُمۡ رَحۡمَةٗۚ وَلَا يَجِدُونَ لَهُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا ﴿17﴾

Sọ pé: “Ta ni ẹni tí ó lè dá ààbò bò yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá fẹ́ fi aburú kàn yín tàbí tí Ó bá fẹ́ kẹ yín?” Wọn kò sì lè rí aláàbò tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.

33:18

قَدۡ يَعۡلَمُ ٱللَّهُ ٱلۡمُعَوِّقِينَ مِنكُمۡ وَٱلۡقَآئِلِينَ لِإِخۡوَٰنِهِمۡ هَلُمَّ إِلَيۡنَاۖ وَلَا يَأۡتُونَ ٱلۡبَأۡسَ إِلَّا قَلِيلًا ﴿18﴾

Dájúdájú Allāhu ti mọ àwọn tó ń fa ènìyàn sẹ́yìn nínú yín àti àwọn tó ń wí fún àwọn arakùnrin wọn pé: “Ẹ máa bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wa.” Wọn kò sì níí lọ sí ojú ogun ẹ̀sìn àfi (ogun) díẹ̀.

33:19

أَشِحَّةً عَلَيۡكُمۡۖ فَإِذَا جَآءَ ٱلۡخَوۡفُ رَأَيۡتَهُمۡ يَنظُرُونَ إِلَيۡكَ تَدُورُ أَعۡيُنُهُمۡ كَٱلَّذِي يُغۡشَىٰ عَلَيۡهِ مِنَ ٱلۡمَوۡتِۖ فَإِذَا ذَهَبَ ٱلۡخَوۡفُ سَلَقُوكُم بِأَلۡسِنَةٍ حِدَادٍ أَشِحَّةً عَلَى ٱلۡخَيۡرِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ لَمۡ يُؤۡمِنُواْ فَأَحۡبَطَ ٱللَّهُ أَعۡمَٰلَهُمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا ﴿19﴾

Wọ́n ní ahun si yín (láti ṣe ìrànlọ́wọ́). Nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá dé, o máa rí wọn tí wọn yóò máa wò ọ́. Ojú wọn yó sì máa yí kiri ràkọ̀ràkọ̀ (ní ti ìbẹ̀rù) bí ẹni tí ikú kì mọ́lẹ̀ láti pa, ṣùgbọ́n nígbà tí ìbẹ̀rù (ogun) bá lọ, (tí ìkógun bá dé), wọn yóò máa fi àwọn ahọ́n kan tó mú bérébéré ba yín sọ̀rọ̀ ní ti ṣíṣe ọ̀kánjúà sí oore náà. Àwọn wọ̀nyẹn kò gbàgbọ́ ní òdodo. Nítorí náà, Allāhu ba àwọn iṣẹ́ wọn jẹ́. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.

33:20

يَحۡسَبُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ لَمۡ يَذۡهَبُواْۖ وَإِن يَأۡتِ ٱلۡأَحۡزَابُ يَوَدُّواْ لَوۡ أَنَّهُم بَادُونَ فِي ٱلۡأَعۡرَابِ يَسۡـَٔلُونَ عَنۡ أَنۢبَآئِكُمۡۖ وَلَوۡ كَانُواْ فِيكُم مَّا قَٰتَلُوٓاْ إِلَّا قَلِيلٗا ﴿20﴾

Wọ́n ń lérò pé àwọn ọmọ ogun oníjọ kò tí ì lọ, (wọ́n sì ti túká). Tí àwọn ọmọ ogun oníjọ bá (sì padà) dé, dájúdájú (àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí) yóò fẹ́ kí àwọn ti wà ní oko láààrin àwọn Lárúbáwá oko, kí wọ́n máa bèèrè nípa àwọn ìró yín (pé ṣé ẹ ti kú tán tàbí ẹ sì wà láyé). Tí ó bá sì jẹ́ pé wọ́n wà láààrin yín, wọn kò níí jagun bí kò ṣe fún ìgbà díẹ̀.

33:21

لَّقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِي رَسُولِ ٱللَّهِ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَ وَذَكَرَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا ﴿21﴾

Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere wà fún yín lára Òjíṣẹ́ Allāhu fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ń retí (ẹ̀san) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, tí ó sì rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (ìgbà).

33:22

وَلَمَّا رَءَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلۡأَحۡزَابَ قَالُواْ هَٰذَا مَا وَعَدَنَا ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَصَدَقَ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥۚ وَمَا زَادَهُمۡ إِلَّآ إِيمَٰنٗا وَتَسۡلِيمٗا ﴿22﴾

Nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo rí àwọn ọmọ ogun oníjọ, wọ́n sọ pé: “Èyí ni ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ṣe ní àdéhùn fún wa.Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ ti sọ òdodo ọ̀rọ̀.” (Rírí wọn) kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe (àlékún) ìgbàgbọ́ òdodo àti ìjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀ (fún àṣẹ Allāhu).

33:23

مِّنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ رِجَالٞ صَدَقُواْ مَا عَٰهَدُواْ ٱللَّهَ عَلَيۡهِۖ فَمِنۡهُم مَّن قَضَىٰ نَحۡبَهُۥ وَمِنۡهُم مَّن يَنتَظِرُۖ وَمَا بَدَّلُواْ تَبۡدِيلٗا ﴿23﴾

Ó wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n jẹ́ olódodo nípa àdéhùn tí wọ́n bá Allāhu ṣe; ó wà nínú wọn ẹni tí ó pé àdéhùn rẹ̀ (tó sì kú sójú ogun ẹ̀sìn), ó sì wà nínú wọn ẹni tó ń retí (ikú tirẹ̀). Wọn kò sì yí (àdéhùn) padà rárá.

33:24

لِّيَجۡزِيَ ٱللَّهُ ٱلصَّـٰدِقِينَ بِصِدۡقِهِمۡ وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ إِن شَآءَ أَوۡ يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ غَفُورٗا رَّحِيمٗا ﴿24﴾

(Ìwọ̀nyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè fi (òdodo) àwọn olódodo san wọ́n ní ẹ̀san òdodo wọn, àti nítorí kí Ó lè jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí ní ìyà tí Ó bá fẹ́ tàbí nítorí kí Ó lè gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu, Ó ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

33:25

وَرَدَّ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِغَيۡظِهِمۡ لَمۡ يَنَالُواْ خَيۡرٗاۚ وَكَفَى ٱللَّهُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلۡقِتَالَۚ وَكَانَ ٱللَّهُ قَوِيًّا عَزِيزٗا ﴿25﴾

Allāhu sì dá àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ padà tòhun ti ìbínú wọn; ọwọ́ wọn kò sì tẹ oore kan. Allāhu sì tó àwọn onígbàgbọ́ òdodo níbi ogun náà. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Olùborí.

33:26

وَأَنزَلَ ٱلَّذِينَ ظَٰهَرُوهُم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن صَيَاصِيهِمۡ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَ فَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ وَتَأۡسِرُونَ فَرِيقٗا ﴿26﴾

(Allāhu) sì mú àwọn tó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn onítírà sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú.1

33:27

وَأَوۡرَثَكُمۡ أَرۡضَهُمۡ وَدِيَٰرَهُمۡ وَأَمۡوَٰلَهُمۡ وَأَرۡضٗا لَّمۡ تَطَـُٔوهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٗا ﴿27﴾

(Allāhu) sì jogún ilẹ̀ wọn, ilé wọn, dúkìá wọn àti ilẹ̀ tí ẹ kò tẹ̀ rí fún yín. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

33:28

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ قُل لِّأَزۡوَٰجِكَ إِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا وَزِينَتَهَا فَتَعَالَيۡنَ أُمَتِّعۡكُنَّ وَأُسَرِّحۡكُنَّ سَرَاحٗا جَمِيلٗا ﴿28﴾

Ìwọ Ànábì, sọ fún àwọn ìyàwó rẹ pé: “Tí ẹ bá fẹ́ ìṣẹ̀mí ayé yìí àti ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ẹ wá níbí kí n̄g fún yín ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀,kí n̄g sì fi yín sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ tó rẹwà.

33:29

وَإِن كُنتُنَّ تُرِدۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ وَٱلدَّارَ ٱلۡأٓخِرَةَ فَإِنَّ ٱللَّهَ أَعَدَّ لِلۡمُحۡسِنَٰتِ مِنكُنَّ أَجۡرًا عَظِيمٗا ﴿29﴾

Tí ẹ bá sì fẹ́ ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti ilé Ìkẹ́yìn, dájúdájú Allāhu ti pèsè ẹ̀san ńlá sílẹ̀ de àwọn olùṣe-rere lóbìnrin nínú yín.”

33:30

يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ مَن يَأۡتِ مِنكُنَّ بِفَٰحِشَةٖ مُّبَيِّنَةٖ يُضَٰعَفۡ لَهَا ٱلۡعَذَابُ ضِعۡفَيۡنِۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عَلَى ٱللَّهِ يَسِيرٗا ﴿30﴾

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn, A máa di àdìpèlé ìyà ìlọ́po méjì fún un. Ìyẹn sì ń jẹ́ ìrọ̀rùn fún Allāhu.

33:31

وَمَن يَقۡنُتۡ مِنكُنَّ لِلَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتَعۡمَلۡ صَٰلِحٗا نُّؤۡتِهَآ أَجۡرَهَا مَرَّتَيۡنِ وَأَعۡتَدۡنَا لَهَا رِزۡقٗا كَرِيمٗا ﴿31﴾

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń tẹ̀lé ti Allāhu àti ti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nínú yín, tí ó sì ń ṣe iṣẹ́ rere, A máa fún un ní ẹ̀san ìlọ́po méjì. A sì ti pèsè ìjẹ-ìmu alápọ̀n-ọ́nlé sílẹ̀ dè é.”

33:32

يَٰنِسَآءَ ٱلنَّبِيِّ لَسۡتُنَّ كَأَحَدٖ مِّنَ ٱلنِّسَآءِ إِنِ ٱتَّقَيۡتُنَّۚ فَلَا تَخۡضَعۡنَ بِٱلۡقَوۡلِ فَيَطۡمَعَ ٱلَّذِي فِي قَلۡبِهِۦ مَرَضٞ وَقُلۡنَ قَوۡلٗا مَّعۡرُوفٗا ﴿32﴾

Ẹ̀yin ìyàwó Ànábì, ẹ kò dà bí ẹnì kan kan nínú àwọn obìnrin, tí ẹ bá ti bẹ̀rù (Allāhu). Ẹ má ṣe dínhùn (sí àwọn ọkùnrin létí) nítorí kí ẹni tí àrùn wà nínú ọkàn rẹ̀ má baá jẹ̀rankàn. Kí ẹ sì máa sọ ọ̀rọ̀ tó dára.

33:33

وَقَرۡنَ فِي بُيُوتِكُنَّ وَلَا تَبَرَّجۡنَ تَبَرُّجَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ ٱلۡأُولَىٰۖ وَأَقِمۡنَ ٱلصَّلَوٰةَ وَءَاتِينَ ٱلزَّكَوٰةَ وَأَطِعۡنَ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥٓۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُذۡهِبَ عَنكُمُ ٱلرِّجۡسَ أَهۡلَ ٱلۡبَيۡتِ وَيُطَهِّرَكُمۡ تَطۡهِيرٗا ﴿33﴾

Ẹ fìdí mọ́lé yín. Ẹ má ṣe fi ara àti ọ̀ṣọ́ hàn níta gẹ́gẹ́ bí ti ìfara-fọ̀ṣọ́-hàn ìgbà àìmọ̀kan àkọ́kọ́ (ìyẹn, ṣíwájú kí ẹ tó di mùsùlùmí). Ẹ kírun. Ẹ yọ Zakāh. Kí ẹ sì tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu kàn ń gbèrò láti mú ẹ̀gbin kúrò lára yín, ẹ̀yin ará ilé (Ànábì). Àti pé Ó (kàn ń gbèrò láti) fọ̀ yín mọ́ tónítóní ni.

33:34

وَٱذۡكُرۡنَ مَا يُتۡلَىٰ فِي بُيُوتِكُنَّ مِنۡ ءَايَٰتِ ٱللَّهِ وَٱلۡحِكۡمَةِۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ لَطِيفًا خَبِيرًا ﴿34﴾

Ẹ rántí ohun tí wọ́n ń ké nínú ilé yín nínú àwọn āyah Allāhu àti ìjìnlẹ̀ òye (ìyẹn, sunnah Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -). Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Aláàánú, Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀.1

33:35

إِنَّ ٱلۡمُسۡلِمِينَ وَٱلۡمُسۡلِمَٰتِ وَٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ وَٱلۡقَٰنِتِينَ وَٱلۡقَٰنِتَٰتِ وَٱلصَّـٰدِقِينَ وَٱلصَّـٰدِقَٰتِ وَٱلصَّـٰبِرِينَ وَٱلصَّـٰبِرَٰتِ وَٱلۡخَٰشِعِينَ وَٱلۡخَٰشِعَٰتِ وَٱلۡمُتَصَدِّقِينَ وَٱلۡمُتَصَدِّقَٰتِ وَٱلصَّـٰٓئِمِينَ وَٱلصَّـٰٓئِمَٰتِ وَٱلۡحَٰفِظِينَ فُرُوجَهُمۡ وَٱلۡحَٰفِظَٰتِ وَٱلذَّـٰكِرِينَ ٱللَّهَ كَثِيرٗا وَٱلذَّـٰكِرَٰتِ أَعَدَّ ٱللَّهُ لَهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمٗا ﴿35﴾

Dájúdájú àwọn mùsùlùmí lọ́kùnrin àti mùsùlùmí lóbìnrin, àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ Allāhu lóbìnrin, àwọn olódodo lọ́kùnrin àti àwọn olódodo lóbìnrin, àwọn onísùúrù lọ́kùnrin àti àwọn onísùúrù lóbìnrin, àwọn olùtẹríba fún Allāhu lọ́kùnrin àti àwọn olùtẹríba fún Allāhu lóbìnrin, àwọn olùtọrẹ lọ́kùnrin àti àwọn olùtọrẹ lóbìnrin, àwọn aláàwẹ̀ lọ́kùnrin àti àwọn aláàwẹ̀ lóbìnrin, àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lọ́kùnrin àti àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn lóbìnrin, àwọn olùrántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́kùnrin àti àwọn olùrántí Allāhu (ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀) lóbìnrin; Allāhu ti pèsè àforíjìn àti ẹ̀san ńlá sílẹ̀ dè wọ́n.

33:36

وَمَا كَانَ لِمُؤۡمِنٖ وَلَا مُؤۡمِنَةٍ إِذَا قَضَى ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥٓ أَمۡرًا أَن يَكُونَ لَهُمُ ٱلۡخِيَرَةُ مِنۡ أَمۡرِهِمۡۗ وَمَن يَعۡصِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ فَقَدۡ ضَلَّ ضَلَٰلٗا مُّبِينٗا ﴿36﴾

Kò tọ́ fún onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, nígbà tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ bá ti parí ọ̀rọ̀ kan, láti ní ẹ̀ṣà (ọ̀rọ̀ mìíràn) fún ọ̀rọ̀ ara wọn. Àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá yapa (àṣẹ) Allāhu àti (àṣẹ) Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú ó ti ṣìnà ní ìṣìnà pọ́nńbélé.

33:37

وَإِذۡ تَقُولُ لِلَّذِيٓ أَنۡعَمَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِ وَأَنۡعَمۡتَ عَلَيۡهِ أَمۡسِكۡ عَلَيۡكَ زَوۡجَكَ وَٱتَّقِ ٱللَّهَ وَتُخۡفِي فِي نَفۡسِكَ مَا ٱللَّهُ مُبۡدِيهِ وَتَخۡشَى ٱلنَّاسَ وَٱللَّهُ أَحَقُّ أَن تَخۡشَىٰهُۖ فَلَمَّا قَضَىٰ زَيۡدٞ مِّنۡهَا وَطَرٗا زَوَّجۡنَٰكَهَا لِكَيۡ لَا يَكُونَ عَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ حَرَجٞ فِيٓ أَزۡوَٰجِ أَدۡعِيَآئِهِمۡ إِذَا قَضَوۡاْ مِنۡهُنَّ وَطَرٗاۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ مَفۡعُولٗا ﴿37﴾

(Rántí) nígbà tí ò ń sọ fún ẹni tí Allāhu ṣèdẹ̀ra fún, tí ìwọ náà ṣèdẹ̀ra fúnpé: “Mú ìyàwó rẹ dání, kí o sì bẹ̀rù Allāhu.” O sì ń fi pamọ́ sínú ẹ̀mí rẹ ohun tí Allāhu yó ṣàfi hàn rẹ̀. Àti pé ò ń páyà àwọn ènìyàn. Allāhu l’Ó sì lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ pé kí o páyà Rẹ̀. Nígbà tí Zaed ti parí bùkátà rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ (tí ó sì ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀), A ti ṣe é ní ìyàwó fún ọ nítorí kí ó má baà jẹ́ láìfí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo láti fẹ́ ìyàwó ọmọ-ọlọ́mọ tí wọ́n ń pè ní ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá ti parí bùkátà wọn lọ́dọ̀ wọn (tí wọ́n sì ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀). Àṣẹ Allāhu sì gbọ́dọ̀ ṣẹ.2

33:38

مَّا كَانَ عَلَى ٱلنَّبِيِّ مِنۡ حَرَجٖ فِيمَا فَرَضَ ٱللَّهُ لَهُۥۖ سُنَّةَ ٱللَّهِ فِي ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلُۚ وَكَانَ أَمۡرُ ٱللَّهِ قَدَرٗا مَّقۡدُورًا ﴿38﴾

Kò sí láìfí fún Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - nípa ohun tí Allāhu ṣe ní ẹ̀tọ́ fún un. (Ó jẹ́) ìlànà Allāhu lórí àwọn tó ti lọ ṣíwájú. Àti pé àṣẹ Allāhu jẹ́ àkọọ́lẹ̀ kan tó gbọ́dọ̀ ṣẹ.

33:39

ٱلَّذِينَ يُبَلِّغُونَ رِسَٰلَٰتِ ٱللَّهِ وَيَخۡشَوۡنَهُۥ وَلَا يَخۡشَوۡنَ أَحَدًا إِلَّا ٱللَّهَۗ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ حَسِيبٗا ﴿39﴾

(Kọ́ṣe àwọn tó ti lọ ṣíwájú nínú àwọn Òjíṣẹ́) àwọn tó ń jẹ́ iṣẹ́ Allāhu, tí wọ́n ń páyà Rẹ̀, tí wọn kò sì páyà ẹnì kan àyàfi Allāhu. Allāhu sì tó ní Olùṣírò.

33:40

مَّا كَانَ مُحَمَّدٌ أَبَآ أَحَدٖ مِّن رِّجَالِكُمۡ وَلَٰكِن رَّسُولَ ٱللَّهِ وَخَاتَمَ ٱلنَّبِيِّـۧنَۗ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا ﴿40﴾

(Ànábì) Muhammad kì í ṣe bàbá ẹnì kan kan nínú àwọn ọkùnrin yín, ṣùgbọ́n (ó jẹ́) Òjíṣẹ́ Allāhu àti òpin àwọn Ànábì.Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

33:41

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ ذِكۡرٗا كَثِيرٗا ﴿41﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí Allāhu ní ìrántí púpọ̀.

33:42

وَسَبِّحُوهُ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلًا ﴿42﴾

Ẹ ṣàfọ̀mọ́ fún Allāhu ní àárọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

33:43

هُوَ ٱلَّذِي يُصَلِّي عَلَيۡكُمۡ وَمَلَـٰٓئِكَتُهُۥ لِيُخۡرِجَكُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۚ وَكَانَ بِٱلۡمُؤۡمِنِينَ رَحِيمٗا ﴿43﴾

(Allāhu) Òun ni Ẹni tó ń kẹ yín, àwọn mọlāika Rẹ̀ (sì ń tọrọ àforíjìn fún yín), nítorí kí Allāhu lè mu yín kúrò láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àti pé Ó ń jẹ́ Àṣàkẹ́-ọ̀run fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

33:44

تَحِيَّتُهُمۡ يَوۡمَ يَلۡقَوۡنَهُۥ سَلَٰمٞۚ وَأَعَدَّ لَهُمۡ أَجۡرٗا كَرِيمٗا ﴿44﴾

Ìkíni wọn ní ọjọ́ tí wọn yóò pàdé Rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ó sì ti pèsè ẹ̀san alápọ̀n-ọ́nlẹ́ sílẹ̀ dè wọ́n.

33:45

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ شَٰهِدٗا وَمُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا ﴿45﴾

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú, olùkìlọ̀,

33:46

وَدَاعِيًا إِلَى ٱللَّهِ بِإِذۡنِهِۦ وَسِرَاجٗا مُّنِيرٗا ﴿46﴾

olùpèpè sí ọ̀dọ̀ Allāhu pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Rẹ̀ àti àtùpà ìmọ́lẹ̀.

33:47

وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ بِأَنَّ لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ فَضۡلٗا كَبِيرٗا ﴿47﴾

Fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú oore àjùlọ ńlá wà fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu.

33:48

وَلَا تُطِعِ ٱلۡكَٰفِرِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَدَعۡ أَذَىٰهُمۡ وَتَوَكَّلۡ عَلَى ٱللَّهِۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَكِيلٗا ﴿48﴾

Má ṣe tẹ̀lé àwọn aláìgbàgbọ́ àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí. Fi bí wọ́n ṣe ń kó ìnira bá ọ sílẹ̀. Kí o sì gbáralé Allāhu. Allāhu sì ń tó ní Alámòjúútó.

33:49

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نَكَحۡتُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ ثُمَّ طَلَّقۡتُمُوهُنَّ مِن قَبۡلِ أَن تَمَسُّوهُنَّ فَمَا لَكُمۡ عَلَيۡهِنَّ مِنۡ عِدَّةٖ تَعۡتَدُّونَهَاۖ فَمَتِّعُوهُنَّ وَسَرِّحُوهُنَّ سَرَاحٗا جَمِيلٗا ﴿49﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin,lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fún yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ tó rẹwà.

33:50

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِنَّآ أَحۡلَلۡنَا لَكَ أَزۡوَٰجَكَ ٱلَّـٰتِيٓ ءَاتَيۡتَ أُجُورَهُنَّ وَمَا مَلَكَتۡ يَمِينُكَ مِمَّآ أَفَآءَ ٱللَّهُ عَلَيۡكَ وَبَنَاتِ عَمِّكَ وَبَنَاتِ عَمَّـٰتِكَ وَبَنَاتِ خَالِكَ وَبَنَاتِ خَٰلَٰتِكَ ٱلَّـٰتِي هَاجَرۡنَ مَعَكَ وَٱمۡرَأَةٗ مُّؤۡمِنَةً إِن وَهَبَتۡ نَفۡسَهَا لِلنَّبِيِّ إِنۡ أَرَادَ ٱلنَّبِيُّ أَن يَسۡتَنكِحَهَا خَالِصَةٗ لَّكَ مِن دُونِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَۗ قَدۡ عَلِمۡنَا مَا فَرَضۡنَا عَلَيۡهِمۡ فِيٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ وَمَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ لِكَيۡلَا يَكُونَ عَلَيۡكَ حَرَجٞۗ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا ﴿50﴾

Ìwọ Ànábì, dájúdájú Àwa ṣe é ní ẹ̀tọ́ fún ọ àwọn ìyàwó rẹ̀, tí o fún ní owó-orí wọn, àti àwọn ẹrú rẹ nínú àwọn tí Allāhu fí ṣe ìkógun fún ọ àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin bàbá rẹ àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin bàbá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arákùnrin ìyá rẹ, àti àwọn ọmọbìnrin arábìnrin ìyá rẹ, àwọn tó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ìlú Mọdīnah pẹ̀lú rẹ, àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin, tí ó bá fi ara rẹ̀ tọrẹ fún Ànábì, tí Ànábì náà sì fẹ́ fi ṣe ìyàwó. Ìwọ nìkan ni (èyí) wà fún, kò sí fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin. A ti mọ ohun tí A ṣe ní ẹ̀tọ́ fún wọn nípa àwọn ìyàwó wọn àti àwọn ẹrú wọn.(Èyí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí ó má baà sí láìfí fún ọ. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.