quranm◉

Ojúewé 123

Range
from 5:90 to 5:95
Surahs covered
Ìtumọ̀
6 Ìtumọ̀

◉

5:90

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِنَّمَا ٱلۡخَمۡرُ وَٱلۡمَيۡسِرُ وَٱلۡأَنصَابُ وَٱلۡأَزۡلَٰمُ رِجۡسٞ مِّنۡ عَمَلِ ٱلشَّيۡطَٰنِ فَٱجۡتَنِبُوهُ لَعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ ﴿90﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú ọtí,tẹ́tẹ́, àwọn òrìṣà àti iṣẹ́ yíyẹ̀wò2, ẹ̀gbin nínú iṣẹ́ Èṣù ni. Nítorí náà, ẹ jìnnà sí i nítorí kí ẹ lè jèrè.

5:91

إِنَّمَا يُرِيدُ ٱلشَّيۡطَٰنُ أَن يُوقِعَ بَيۡنَكُمُ ٱلۡعَدَٰوَةَ وَٱلۡبَغۡضَآءَ فِي ٱلۡخَمۡرِ وَٱلۡمَيۡسِرِ وَيَصُدَّكُمۡ عَن ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَعَنِ ٱلصَّلَوٰةِۖ فَهَلۡ أَنتُم مُّنتَهُونَ ﴿91﴾

Ohun tí Èṣù ń fẹ́ ni pé ó máa dá ọ̀tá àti ìkórira sílẹ̀ láààrin yín níbi ọtí àti tẹ́tẹ́. Ó sì fẹ́ ṣẹ yín lórí kúrò níbi ìrántí Allāhu àti níbi ìrun kíkí. Ṣé ẹ̀yin kò níí jáwọ́ (níbi iṣẹ́ Èṣù) ni?

5:92

وَأَطِيعُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُواْ ٱلرَّسُولَ وَٱحۡذَرُواْۚ فَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّمَا عَلَىٰ رَسُولِنَا ٱلۡبَلَٰغُ ٱلۡمُبِينُ ﴿92﴾

Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu, ẹ tẹ̀lé ti Òjíṣẹ́. Kí ẹ sì ṣọ́ra. Nítorí náà, tí ẹ bá gbúnrí, kí ẹ mọ̀ pé ìkéde (ẹ̀sìn) tó yanjú ni ojúṣe Òjíṣẹ́ Wa.

5:93

لَيۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ جُنَاحٞ فِيمَا طَعِمُوٓاْ إِذَا مَا ٱتَّقَواْ وَّءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ ثُمَّ ٱتَّقَواْ وَّءَامَنُواْ ثُمَّ ٱتَّقَواْ وَّأَحۡسَنُواْۚ وَٱللَّهُ يُحِبُّ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿93﴾

Kò sí ìbáwí fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ rere nípa ohun tí wọ́n jẹ (nínú ouńjẹ ṣíwájú òfin) nígbà tí wọ́n bá ti bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ̀rù Allāhu, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, lẹ́yìn náà, tí wọ́n bẹ́rù Allāhu, tí wọ́n tún ṣiṣẹ́ rere. Allāhu sì fẹ́ràn àwọn olùṣe-rere.1

5:94

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَيَبۡلُوَنَّكُمُ ٱللَّهُ بِشَيۡءٖ مِّنَ ٱلصَّيۡدِ تَنَالُهُۥٓ أَيۡدِيكُمۡ وَرِمَاحُكُمۡ لِيَعۡلَمَ ٱللَّهُ مَن يَخَافُهُۥ بِٱلۡغَيۡبِۚ فَمَنِ ٱعۡتَدَىٰ بَعۡدَ ذَٰلِكَ فَلَهُۥ عَذَابٌ أَلِيمٞ ﴿94﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú Allāhu yóò fi kiní kan dan yín wò níbi ẹran-ìgbẹ́ tí ọwọ́ yín àti ọ̀kọ̀ yín bà (nínú aṣọ hurumi) nítorí kí Allāhu lè ṣàfi hàn ẹni tó ń páyà Rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ ẹnu-ààlà lẹ́yìn ìyẹn, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún un.

5:95

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡتُلُواْ ٱلصَّيۡدَ وَأَنتُمۡ حُرُمٞۚ وَمَن قَتَلَهُۥ مِنكُم مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآءٞ مِّثۡلُ مَا قَتَلَ مِنَ ٱلنَّعَمِ يَحۡكُمُ بِهِۦ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ هَدۡيَۢا بَٰلِغَ ٱلۡكَعۡبَةِ أَوۡ كَفَّـٰرَةٞ طَعَامُ مَسَٰكِينَ أَوۡ عَدۡلُ ذَٰلِكَ صِيَامٗا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمۡرِهِۦۗ عَفَا ٱللَّهُ عَمَّا سَلَفَۚ وَمَنۡ عَادَ فَيَنتَقِمُ ٱللَّهُ مِنۡهُۚ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ ﴿95﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah) Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ẹ̀san rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó máa jẹ́) ẹran ọrẹ tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí kí ó fi ààwẹ̀ dípò ìyẹn, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun tó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ húrùmí tàbí nínú húrùmí), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.