quranm◉

Ojúewé 196

Range
from 9:55 to 9:61
Surahs covered
Ìtumọ̀
7 Ìtumọ̀

◉

9:55

فَلَا تُعۡجِبۡكَ أَمۡوَٰلُهُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُهُمۡۚ إِنَّمَا يُرِيدُ ٱللَّهُ لِيُعَذِّبَهُم بِهَا فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَتَزۡهَقَ أَنفُسُهُمۡ وَهُمۡ كَٰفِرُونَ ﴿55﴾

Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn jọ ọ́ lójú; Allāhu kàn fẹ́ fi jẹ wọ́n níyà nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) ni. Ẹ̀mí yó sì bọ́ lára wọn, tí wọ́n máa wà nípò aláìgbàgbọ́.

9:56

وَيَحۡلِفُونَ بِٱللَّهِ إِنَّهُمۡ لَمِنكُمۡ وَمَا هُم مِّنكُمۡ وَلَٰكِنَّهُمۡ قَوۡمٞ يَفۡرَقُونَ ﴿56﴾

Wọ́n ń fi Allāhu búra pé dájúdájú àwọn kúkú wà lára yín. Wọn kò sì sí lára yín, ṣùgbọ́n dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ kan tó ń bẹ̀rù.1

9:57

لَوۡ يَجِدُونَ مَلۡجَـًٔا أَوۡ مَغَٰرَٰتٍ أَوۡ مُدَّخَلٗا لَّوَلَّوۡاْ إِلَيۡهِ وَهُمۡ يَجۡمَحُونَ ﴿57﴾

Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n rí ibùsásí kan, tàbí àwọn ihò àpáta kan, tàbí ibùsáwọ̀ kan, wọn ìbá ṣẹ́rí síbẹ̀ ní wéréwéré.

9:58

وَمِنۡهُم مَّن يَلۡمِزُكَ فِي ٱلصَّدَقَٰتِ فَإِنۡ أُعۡطُواْ مِنۡهَا رَضُواْ وَإِن لَّمۡ يُعۡطَوۡاْ مِنۡهَآ إِذَا هُمۡ يَسۡخَطُونَ ﴿58﴾

Ó tún wà nínú wọn, ẹni tí ń bú ọ níbi (pípín) àwọn ọrẹ. Tí A bá fún wọn nínú rẹ̀, wọ́n á yọ́nú (sí i). Tí A ò bá sì fún wọn nínú rẹ̀, nígbà náà ni wọn yóò máa bínú.

9:59

وَلَوۡ أَنَّهُمۡ رَضُواْ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ سَيُؤۡتِينَا ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَرَسُولُهُۥٓ إِنَّآ إِلَى ٱللَّهِ رَٰغِبُونَ ﴿59﴾

Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ) dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí.”

9:60

إِنَّمَا ٱلصَّدَقَٰتُ لِلۡفُقَرَآءِ وَٱلۡمَسَٰكِينِ وَٱلۡعَٰمِلِينَ عَلَيۡهَا وَٱلۡمُؤَلَّفَةِ قُلُوبُهُمۡ وَفِي ٱلرِّقَابِ وَٱلۡغَٰرِمِينَ وَفِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱبۡنِ ٱلسَّبِيلِۖ فَرِيضَةٗ مِّنَ ٱللَّهِۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴿60﴾

Àwọn tí ọrẹ (Zakāh) wà fún ni àwọn aláìní, àwọn mẹ̀kúnnù,àwọn òṣìṣẹ́ Zakāh, àwọn tí ọkàn wọn fẹ́ gba ’Islām (ìyẹn àwọn tí wọ́n fẹ́ fi fa ọkàn wọn mọ́ra sínú ẹ̀sìn), àwọn ẹrú (fún gbígba òmìnira), àwọn onígbèsè, àwọn tó wà lójú ogun (ẹ̀sìn) Allāhu àti onírìn-àjò (tí agara dá). Ọ̀ran-anyàn ni láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

9:61

وَمِنۡهُمُ ٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ ٱلنَّبِيَّ وَيَقُولُونَ هُوَ أُذُنٞۚ قُلۡ أُذُنُ خَيۡرٖ لَّكُمۡ يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَيُؤۡمِنُ لِلۡمُؤۡمِنِينَ وَرَحۡمَةٞ لِّلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنكُمۡۚ وَٱلَّذِينَ يُؤۡذُونَ رَسُولَ ٱللَّهِ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ ﴿61﴾

Àwọn tó ń kó ìnira bá Ànábì wà nínú wọn, tí wọ́n sì ń wí pé: “Elétí-ọfẹ ni.” Sọ pé: “Elétí-ọfẹ rere ni fún yín; ó gbàgbọ́ nínú Allāhu. Ó sì gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbọ́. Ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo nínú yín. Àti pé àwọn tó ń kó ìnira bá Òjíṣẹ́ Allāhu, ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn.”