quranm◉

Ojúewé 203

Range
from 9:100 to 9:106
Surahs covered
Ìtumọ̀
7 Ìtumọ̀

◉

9:100

وَٱلسَّـٰبِقُونَ ٱلۡأَوَّلُونَ مِنَ ٱلۡمُهَٰجِرِينَ وَٱلۡأَنصَارِ وَٱلَّذِينَ ٱتَّبَعُوهُم بِإِحۡسَٰنٖ رَّضِيَ ٱللَّهُ عَنۡهُمۡ وَرَضُواْ عَنۡهُ وَأَعَدَّ لَهُمۡ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي تَحۡتَهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَآ أَبَدٗاۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ﴿100﴾

Àwọn aṣíwájú, àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn Muhājirūn àti àwọn ’Ansọ̄r àti àwọn tó fi dáadáa tẹ̀lé wọn, Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Ó tún pa lésè sílẹ̀ dè wọ́n àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra tí odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ títí láéláé. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

9:101

وَمِمَّنۡ حَوۡلَكُم مِّنَ ٱلۡأَعۡرَابِ مُنَٰفِقُونَۖ وَمِنۡ أَهۡلِ ٱلۡمَدِينَةِ مَرَدُواْ عَلَى ٱلنِّفَاقِ لَا تَعۡلَمُهُمۡۖ نَحۡنُ نَعۡلَمُهُمۡۚ سَنُعَذِّبُهُم مَّرَّتَيۡنِ ثُمَّ يُرَدُّونَ إِلَىٰ عَذَابٍ عَظِيمٖ ﴿101﴾

Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí kan ń bẹ nínú àwọn tí ó wà ní àyíká yín nínú àwọn Lárúbáwá oko àti nínú àwọn ará ìlú Mọdīnah, tí wọ́n won̄koko mọ́ ìṣọ̀bẹ-ṣèlú. Ìwọ kò mọ̀ wọ́n, Àwa l’A mọ̀ wọ́n. A óò jẹ wọ́n níyà ní ẹ̀ẹ̀ mejì.Lẹ́yìn náà, A óò dá wọn padà sínú ìyà ńlá.

9:102

وَءَاخَرُونَ ٱعۡتَرَفُواْ بِذُنُوبِهِمۡ خَلَطُواْ عَمَلٗا صَٰلِحٗا وَءَاخَرَ سَيِّئًا عَسَى ٱللَّهُ أَن يَتُوبَ عَلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ ﴿102﴾

Àwọn mìíràn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Wọ́n da iṣẹ́ rere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ mìíràn tó burú. Bóyá Allāhu yóò gba ìronúpìwàdà wọn. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

9:103

خُذۡ مِنۡ أَمۡوَٰلِهِمۡ صَدَقَةٗ تُطَهِّرُهُمۡ وَتُزَكِّيهِم بِهَا وَصَلِّ عَلَيۡهِمۡۖ إِنَّ صَلَوٰتَكَ سَكَنٞ لَّهُمۡۗ وَٱللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ ﴿103﴾

Gba ọrẹ (Zakāh) nínú dúkìá wọn, kí o fi sọ wọ́n di ẹni mímọ́, kí o sì fi ṣe àfọ̀mọ́ fún wọn. Ṣe àdúà fún wọn. Dájúdájú àdúà rẹ ni ìfàyàbalẹ̀ fún wọn. Allāhu sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.1

9:104

أَلَمۡ يَعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ هُوَ يَقۡبَلُ ٱلتَّوۡبَةَ عَنۡ عِبَادِهِۦ وَيَأۡخُذُ ٱلصَّدَقَٰتِ وَأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿104﴾

Ṣé wọn kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu Òun l’Ó ń gba ìronúpìwàdà lọ́wọ́ àwọn ẹrúsìn Rẹ̀, Ó sì ń gba àwọn ọrẹ, àti pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run?

9:105

وَقُلِ ٱعۡمَلُواْ فَسَيَرَى ٱللَّهُ عَمَلَكُمۡ وَرَسُولُهُۥ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَۖ وَسَتُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿105﴾

Sọ pé: “Ẹ ṣiṣẹ́. Allāhu á rí iṣẹ́ yín. Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (máa rí i).Wọ́n sì máa da yín padà sọ́dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀-àti-gban̄gba. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

9:106

وَءَاخَرُونَ مُرۡجَوۡنَ لِأَمۡرِ ٱللَّهِ إِمَّا يُعَذِّبُهُمۡ وَإِمَّا يَتُوبُ عَلَيۡهِمۡۗ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴿106﴾

Wọ́n so ọ̀rọ̀ àwọn yòókù rọ̀ ná títí àṣẹ Allāhu máa fi dé; yálà kí Ó jẹ wọ́n níyà tàbí kí Ó gba ìronúpìwàdà wọn.Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n. 2