quranm◉

Ojúewé 6

Range
from 2:30 to 2:37
Surahs covered
Ìtumọ̀
8 Ìtumọ̀

◉

2:30

وَإِذۡ قَالَ رَبُّكَ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ إِنِّي جَاعِلٞ فِي ٱلۡأَرۡضِ خَلِيفَةٗۖ قَالُوٓاْ أَتَجۡعَلُ فِيهَا مَن يُفۡسِدُ فِيهَا وَيَسۡفِكُ ٱلدِّمَآءَ وَنَحۡنُ نُسَبِّحُ بِحَمۡدِكَ وَنُقَدِّسُ لَكَۖ قَالَ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿30﴾

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ fún àwọn mọlāika pé: “Dájúdájú Èmi yóò fi àrólé kan sórí ilẹ̀.”Wọ́n sọ pé: “Ṣé Ìwọ yóò fi ẹni tí ó máa ṣèbàjẹ́ síbẹ̀, tí ó sì máa ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀? Àwa sì ń ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Ọ. A óò máa ṣe àfọ̀mọ́ fún Ọ sẹ́!” Ó sọ pé: “Dájúdájú Èmi mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀.”

2:31

وَعَلَّمَ ءَادَمَ ٱلۡأَسۡمَآءَ كُلَّهَا ثُمَّ عَرَضَهُمۡ عَلَى ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةِ فَقَالَ أَنۢبِـُٔونِي بِأَسۡمَآءِ هَـٰٓؤُلَآءِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿31﴾

Allāhu fi gbogbo àwọn orúkọ náà mọ Ādam. Lẹ́yìn náà, Ó kó wọn síwájú àwọn mọlāika, Ó sì sọ pé: “Ẹ sọ àwọn orúkọ ìwọ̀nyí fún Mi, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

2:32

قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ لَا عِلۡمَ لَنَآ إِلَّا مَا عَلَّمۡتَنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَلِيمُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿32﴾

Wọ́n sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, kò sí ìmọ̀ kan fún wa àyàfi ohun tí O fi mọ̀ wá. Dájúdájú Ìwọ, Ìwọ ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.”

2:33

قَالَ يَـٰٓـَٔادَمُ أَنۢبِئۡهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡۖ فَلَمَّآ أَنۢبَأَهُم بِأَسۡمَآئِهِمۡ قَالَ أَلَمۡ أَقُل لَّكُمۡ إِنِّيٓ أَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَأَعۡلَمُ مَا تُبۡدُونَ وَمَا كُنتُمۡ تَكۡتُمُونَ ﴿33﴾

Ó sọ pé: “Ādam, sọ orúkọ wọn fún wọn.” Nígbà tí ó sọ orúkọ wọn fún wọn tán, Ó sọ pé: “Ṣé Èmi kò sọ fún yín pé dájúdájú Èmi nímọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Mo sì nímọ̀ ohun tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀ àti ohun tí ẹ̀ ń fi pamọ́?”

2:34

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ وَٱسۡتَكۡبَرَ وَكَانَ مِنَ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿34﴾

(Rántí) nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí (Ànábì) Ādam.”Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àyàfi ’Iblīs.2 Ó kọ̀, ó sì ṣe ìgbéraga. Ó sì wà nínú àwọn aláìgbàgbọ́.

2:35

وَقُلۡنَا يَـٰٓـَٔادَمُ ٱسۡكُنۡ أَنتَ وَزَوۡجُكَ ٱلۡجَنَّةَ وَكُلَا مِنۡهَا رَغَدًا حَيۡثُ شِئۡتُمَا وَلَا تَقۡرَبَا هَٰذِهِ ٱلشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿35﴾

A sì sọ pé: “Ādam, ìwọ àti ìyàwó rẹ, ẹ máa gbé nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Kí ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbẹdẹmukẹ ní ibikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ igi yìí, kí ẹ má baà wà nínú àwọn alábòsí.”1

2:36

فَأَزَلَّهُمَا ٱلشَّيۡطَٰنُ عَنۡهَا فَأَخۡرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِۖ وَقُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ وَلَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مُسۡتَقَرّٞ وَمَتَٰعٌ إِلَىٰ حِينٖ ﴿36﴾

Lẹ́yìn náà, Èṣù yẹ àwọn méjèèjì lẹ́sẹ̀ kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ó sì mú wọn jáde kúrò nínú ibi tí wọ́n wà. A sì sọ pé: “Ẹ sọ̀kalẹ̀, ọ̀tá ní apá kan yín jẹ́ fún apá kan. Ibùgbé àti n̄ǹkan ìgbádùn sì ń bẹ fún yín lórí ilẹ̀ títí di ìgbà kan.”

2:37

فَتَلَقَّىٰٓ ءَادَمُ مِن رَّبِّهِۦ كَلِمَٰتٖ فَتَابَ عَلَيۡهِۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿37﴾

Lẹ́yìn náà, (Ànábì) Ādam rí àwọn ọ̀rọ̀ kan gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Ó sì gba ìronúpìwàdà rẹ̀. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.