quranm◉

Ojúewé 8

Range
from 2:49 to 2:57
Surahs covered
Ìtumọ̀
9 Ìtumọ̀

◉

2:49

وَإِذۡ نَجَّيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُذَبِّحُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ ﴿49﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon, tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, tí wọ́n ń dúńbú àwọn ọmọkùnrin yín, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí àwọn obìnrin yín ṣẹ̀mí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn fún yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.

2:50

وَإِذۡ فَرَقۡنَا بِكُمُ ٱلۡبَحۡرَ فَأَنجَيۡنَٰكُمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿50﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami odò sí (ọ̀nà méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀) fún yín, A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).

2:51

وَإِذۡ وَٰعَدۡنَا مُوسَىٰٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗ ثُمَّ ٱتَّخَذۡتُمُ ٱلۡعِجۡلَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَنتُمۡ ظَٰلِمُونَ ﴿51﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A ṣe àdéhùn ogójì òru fún (Ànábì) Mūsā. Lẹ́yìn náà, ẹ tún bọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù lẹ́yìn rẹ̀. Alábòsí sì ni yín.

2:52

ثُمَّ عَفَوۡنَا عَنكُم مِّنۢ بَعۡدِ ذَٰلِكَ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿52﴾

Lẹ́yìn náà, A mójú kúrò fún yín lẹ́yìn ìyẹn nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).

2:53

وَإِذۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡفُرۡقَانَ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿53﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.1

2:54

وَإِذۡ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِنَّكُمۡ ظَلَمۡتُمۡ أَنفُسَكُم بِٱتِّخَاذِكُمُ ٱلۡعِجۡلَ فَتُوبُوٓاْ إِلَىٰ بَارِئِكُمۡ فَٱقۡتُلُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ عِندَ بَارِئِكُمۡ فَتَابَ عَلَيۡكُمۡۚ إِنَّهُۥ هُوَ ٱلتَّوَّابُ ٱلرَّحِيمُ ﴿54﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí (Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, dájúdájú ẹ̀yin ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara yín nípa sísọ ọ̀bọrọgidi ọmọ màálù di òrìṣà. Nítorí náà, ẹ ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín, kí àwọn tí kò bọ màálù pa àwọn tó bọ ọ́ láààrin yín. Ìyẹn l’óore jùlọ fún yín ní ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá yín. Ó sì máa gba ìronúpìwàdà yín. Dájúdájú Allāhu, Òun ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:55

وَإِذۡ قُلۡتُمۡ يَٰمُوسَىٰ لَن نُّؤۡمِنَ لَكَ حَتَّىٰ نَرَى ٱللَّهَ جَهۡرَةٗ فَأَخَذَتۡكُمُ ٱلصَّـٰعِقَةُ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ﴿55﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí ẹ wí pé: “Mūsā, a ò níí gbàgbọ́ nínú rẹ àfi kí á rí Allāhu ní ojúkojú.” Nítorí náà, iná láti ojú sánmọ̀ gba yín mú, ẹ sì ń wò bọ̀ọ̀.

2:56

ثُمَّ بَعَثۡنَٰكُم مِّنۢ بَعۡدِ مَوۡتِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿56﴾

Lẹ́yìn náà, A ji yín dìde lẹ́yìn ikú yín, nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ (fún Allāhu).1

2:57

وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡغَمَامَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴿57﴾

A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún yín. A sì tún sọ (ohun mímu) mọnnuàti (ohun jíjẹ) salwā2 kalẹ̀ fún yín. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣàbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.