حمٓ ﴿1﴾حمٓ
Transliteration: Hameem
Translation: Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1
حمٓ ﴿1﴾حمٓ
Transliteration: Hameem
Translation: Hā mīm. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1
وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ ﴿2﴾وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُبِينِ
Transliteration: Waalkitabi almubeeni
Translation: (Allāhu) fi Tírà tó ń yanjú ọ̀rọ̀ ẹ̀dá búra.
إِنَّا جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴿3﴾إِنَّا جَعَلۡنَٰهُ قُرۡءَٰنًا عَرَبِيّٗا لَّعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ
Transliteration: Inna jaAAalnahu quranan AAarabiyyan laAAallakum taAAqiloona
Translation: Dájúdájú Àwa se é ní al-Ƙur’ān (n̄ǹkan kíké) ní èdè Lárúbáwá nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.
وَإِنَّهُۥ فِيٓ أُمِّ ٱلۡكِتَٰبِ لَدَيۡنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ ﴿4﴾وَإِنَّهُۥ فِيٓ أُمِّ ٱلۡكِتَٰبِ لَدَيۡنَا لَعَلِيٌّ حَكِيمٌ
Transliteration: Wainnahu fee ommi alkitabi ladayna laAAaliyyun hakeemun
Translation: Àti pé dájúdájú nínú Tírà Ìpìlẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ Wa, al-Ƙur’ān mà ga, ó sì kún fún ọgbọ́n.
أَفَنَضۡرِبُ عَنكُمُ ٱلذِّكۡرَ صَفۡحًا أَن كُنتُمۡ قَوۡمٗا مُّسۡرِفِينَ ﴿5﴾أَفَنَضۡرِبُ عَنكُمُ ٱلذِّكۡرَ صَفۡحًا أَن كُنتُمۡ قَوۡمٗا مُّسۡرِفِينَ
Transliteration: Afanadribu AAankumu alththikra safhan an kuntum qawman musrifeena
Translation: Ṣé kí Á ká Tírà Ìrántí (al-Ƙur’ān) kúrò nílẹ̀ fún yín pátápátá (kí Á máa wò yín ní ìran) nítorí pé, ẹ jẹ́ ìjọ alákọyọ?
وَكَمۡ أَرۡسَلۡنَا مِن نَّبِيّٖ فِي ٱلۡأَوَّلِينَ ﴿6﴾وَكَمۡ أَرۡسَلۡنَا مِن نَّبِيّٖ فِي ٱلۡأَوَّلِينَ
Transliteration: Wakam arsalna min nabiyyin fee alawwaleena
Translation: Mélòó mélòó nínú àwọn Ànábì tí A ti rán sí àwọn ẹni àkọ́kọ́.
وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ﴿7﴾وَمَا يَأۡتِيهِم مِّن نَّبِيٍّ إِلَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ
Transliteration: Wama yateehim min nabiyyin illa kanoo bihi yastahzioona
Translation: Kò sí Ànábì kan tí ó wá bá wọn àyàfi kí wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́.
فَأَهۡلَكۡنَآ أَشَدَّ مِنۡهُم بَطۡشٗا وَمَضَىٰ مَثَلُ ٱلۡأَوَّلِينَ ﴿8﴾فَأَهۡلَكۡنَآ أَشَدَّ مِنۡهُم بَطۡشٗا وَمَضَىٰ مَثَلُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Transliteration: Faahlakna ashadda minhum batshan wamada mathalu alawwaleena
Translation: Nítorí náà, A ti pa àwọn tó ní agbára ju àwọn (wọ̀nyí) rẹ́. Àpèjúwe (ìparun) àwọn ẹni àkọ́kọ́ sì ti ṣíwájú.
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿9﴾وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ لَيَقُولُنَّ خَلَقَهُنَّ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡعَلِيمُ
Transliteration: Walain saaltahum man khalaqa alssamawati waalarda layaqoolunna khalaqahunna alAAazeezu alAAaleemu
Translation: Tí o bá kúkú bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Ẹni tó dá wọn ni Alágbára, Onímọ̀;
ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿10﴾ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَجَعَلَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا لَّعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ
Transliteration: Allathee jaAAala lakumu alarda mahdan wajaAAala lakum feeha subulan laAAallakum tahtadoona
Translation: Ẹni tí Ó ṣe ilẹ̀ ní ìtẹ́ fún yín. Ó sì fi àwọn ojú ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín nítorí kí ẹ lè mọ̀nà;
وَٱلَّذِي نَزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءَۢ بِقَدَرٖ فَأَنشَرۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ ﴿11﴾وَٱلَّذِي نَزَّلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءَۢ بِقَدَرٖ فَأَنشَرۡنَا بِهِۦ بَلۡدَةٗ مَّيۡتٗاۚ كَذَٰلِكَ تُخۡرَجُونَ
Transliteration: Waallathee nazzala mina alssamai maan biqadarin faansharna bihi baldatan maytan kathalika tukhrajoona
Translation: Ẹni tí Ó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀ níwọ̀n-níwọ̀n. Ó sì ń fi sọ òkú ilẹ̀ di àyè ilẹ̀. Báyẹn náà ni wọn yóò ṣe mu yín jáde.
وَٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡفُلۡكِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مَا تَرۡكَبُونَ ﴿12﴾وَٱلَّذِي خَلَقَ ٱلۡأَزۡوَٰجَ كُلَّهَا وَجَعَلَ لَكُم مِّنَ ٱلۡفُلۡكِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ مَا تَرۡكَبُونَ
Transliteration: Waallathee khalaqa alazwaja kullaha wajaAAala lakum mina alfulki waalanAAami ma tarkaboona
Translation: Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá gbogbo n̄ǹkan ní oríṣiríṣi.Ó sì ṣe n̄ǹkan tí ẹ̀ ń gùn fún yín láti ara àwọn ọkọ̀ ojú-omi àti àwọn ẹran-ọ̀sìn.
لِتَسۡتَوُۥاْ عَلَىٰ ظُهُورِهِۦ ثُمَّ تَذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ رَبِّكُمۡ إِذَا ٱسۡتَوَيۡتُمۡ عَلَيۡهِ وَتَقُولُواْ سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَنَا هَٰذَا وَمَا كُنَّا لَهُۥ مُقۡرِنِينَ ﴿13﴾لِتَسۡتَوُۥاْ عَلَىٰ ظُهُورِهِۦ ثُمَّ تَذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ رَبِّكُمۡ إِذَا ٱسۡتَوَيۡتُمۡ عَلَيۡهِ وَتَقُولُواْ سُبۡحَٰنَ ٱلَّذِي سَخَّرَ لَنَا هَٰذَا وَمَا كُنَّا لَهُۥ مُقۡرِنِينَ
Transliteration: Litastawoo AAala thuhoorihi thumma tathkuroo niAAmata rabbikum itha istawaytum AAalayhi wataqooloo subhana allathee sakhkhara lana hatha wama kunna lahu muqrineena
Translation: Nítorí kí ẹ lè jókòó dáadáa sẹ́yìn rẹ̀, lẹ́yìn náà kí ẹ lè ṣe ìrántí ìdẹ̀ra Olúwa yín nígbà tí ẹ bá jókòó dáadáa tán sórí rẹ̀, kí ẹ sì sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ẹni tí Ó rọ èyí fún wa, kì í ṣe pé a jẹ́ alágbára lórí rẹ̀.
وَإِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ ﴿14﴾وَإِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا لَمُنقَلِبُونَ
Transliteration: Wainna ila rabbina lamunqaliboona
Translation: Àti pé dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa ni àwa yóò padà sí.”
وَجَعَلُواْ لَهُۥ مِنۡ عِبَادِهِۦ جُزۡءًاۚ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٞ مُّبِينٌ ﴿15﴾وَجَعَلُواْ لَهُۥ مِنۡ عِبَادِهِۦ جُزۡءًاۚ إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لَكَفُورٞ مُّبِينٌ
Transliteration: WajaAAaloo lahu min AAibadihi juzan inna alinsana lakafoorun mubeenun
Translation: Wọ́n fi ìpín kan nínú àwọn ẹrúsìn (Allāhu) tì sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ (ní ti ọmọ bíbí). Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore pọ́nńbélé.
أَمِ ٱتَّخَذَ مِمَّا يَخۡلُقُ بَنَاتٖ وَأَصۡفَىٰكُم بِٱلۡبَنِينَ ﴿16﴾أَمِ ٱتَّخَذَ مِمَّا يَخۡلُقُ بَنَاتٖ وَأَصۡفَىٰكُم بِٱلۡبَنِينَ
Transliteration: Ami ittakhatha mimma yakhluqu banatin waasfakum bialbaneena
Translation: Tàbí (ẹ̀yin ń wí pé): “Ó mú nínú n̄ǹkan tí Ó dá ní ọmọbìnrin (fúnra Rẹ̀). Ó sì fi àwọn ọmọkùnrin ṣa ẹ̀yin lẹ́ṣà.”
وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحۡمَٰنِ مَثَلٗا ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٌ ﴿17﴾وَإِذَا بُشِّرَ أَحَدُهُم بِمَا ضَرَبَ لِلرَّحۡمَٰنِ مَثَلٗا ظَلَّ وَجۡهُهُۥ مُسۡوَدّٗا وَهُوَ كَظِيمٌ
Transliteration: Waitha bushshira ahaduhum bima daraba lilrrahmani mathalan thalla wajhuhu muswaddan wahuwa katheemun
Translation: Nígbà tí wọ́n bá fún ẹnì kan nínú wọn ní ìró ìdùnnú ohun tí ó fi ṣe àpẹ̀ẹrẹ fún Àjọkẹ́-ayé, ojú rẹ̀ máa dúdú wá (pé òun bí ọmọbìnrin).Ó sì máa kún fún ìbànújẹ́.
أَوَمَن يُنَشَّؤُاْ فِي ٱلۡحِلۡيَةِ وَهُوَ فِي ٱلۡخِصَامِ غَيۡرُ مُبِينٖ ﴿18﴾أَوَمَن يُنَشَّؤُاْ فِي ٱلۡحِلۡيَةِ وَهُوَ فِي ٱلۡخِصَامِ غَيۡرُ مُبِينٖ
Transliteration: Awaman yunashshao fee alhilyati wahuwa fee alkhisami ghayru mubeenin
Translation: Ṣé ẹni tí wọ́n ń tọ́ nínú ọ̀ṣọ́ (tí ó ń to ọ̀ṣọ́ mọ́ra), tí kò sì lè bọ́ sí gban̄gba níbi ìjà (ni ẹ̀ ń pè ní ọmọ Àjọkẹ́-ayé)!?
وَجَعَلُواْ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ ٱلَّذِينَ هُمۡ عِبَٰدُ ٱلرَّحۡمَٰنِ إِنَٰثًاۚ أَشَهِدُواْ خَلۡقَهُمۡۚ سَتُكۡتَبُ شَهَٰدَتُهُمۡ وَيُسۡـَٔلُونَ ﴿19﴾وَجَعَلُواْ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ ٱلَّذِينَ هُمۡ عِبَٰدُ ٱلرَّحۡمَٰنِ إِنَٰثًاۚ أَشَهِدُواْ خَلۡقَهُمۡۚ سَتُكۡتَبُ شَهَٰدَتُهُمۡ وَيُسۡـَٔلُونَ
Transliteration: WajaAAaloo almalaikata allatheena hum AAibadu alrrahmani inathan ashahidoo khalqahum satuktabu shahadatuhum wayusaloona
Translation: Àwọn mọlāika, àwọn tó jẹ́ ẹrúsìn Àjọkẹ́-ayé, wọ́n tún sọ wọ́n di ọmọbìnrin! Ṣé wọ́n fojú rí ìṣẹ̀dá wọn ni? Wọ́n máa ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n fojú rí. Wọ́n sì máa bi wọ́n léèrè (nípa rẹ̀).
وَقَالُواْ لَوۡ شَآءَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَا عَبَدۡنَٰهُمۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ ﴿20﴾وَقَالُواْ لَوۡ شَآءَ ٱلرَّحۡمَٰنُ مَا عَبَدۡنَٰهُمۗ مَّا لَهُم بِذَٰلِكَ مِنۡ عِلۡمٍۖ إِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ
Transliteration: Waqaloo law shaa alrrahmanu ma AAabadnahum ma lahum bithalika min AAilmin in hum illa yakhrusoona
Translation: Wọ́n tún wí pé: “Tí Àjọkẹ́-ayé bá fẹ́, àwa ìbá tí jọ́sìn fún wọn.” Kò sí ìmọ̀ kan fún wọn nípa ìyẹn. Wọn kò sì jẹ́ kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.
أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا مِّن قَبۡلِهِۦ فَهُم بِهِۦ مُسۡتَمۡسِكُونَ ﴿21﴾أَمۡ ءَاتَيۡنَٰهُمۡ كِتَٰبٗا مِّن قَبۡلِهِۦ فَهُم بِهِۦ مُسۡتَمۡسِكُونَ
Transliteration: Am ataynahum kitaban min qablihi fahum bihi mustamsikoona
Translation: Tàbí A ti fún wọn ní Tírà kan ṣíwájú al-Ƙur’ān, tí wọ́n ń lò ní ẹ̀rí?
بَلۡ قَالُوٓاْ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّهۡتَدُونَ ﴿22﴾بَلۡ قَالُوٓاْ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّهۡتَدُونَ
Transliteration: Bal qaloo inna wajadna abaana AAala ommatin wainna AAala atharihim muhtadoona
Translation: Rárá. Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùmọ̀nà lórí orípa wọn.”1
وَكَذَٰلِكَ مَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي قَرۡيَةٖ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتۡرَفُوهَآ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّقۡتَدُونَ ﴿23﴾وَكَذَٰلِكَ مَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ فِي قَرۡيَةٖ مِّن نَّذِيرٍ إِلَّا قَالَ مُتۡرَفُوهَآ إِنَّا وَجَدۡنَآ ءَابَآءَنَا عَلَىٰٓ أُمَّةٖ وَإِنَّا عَلَىٰٓ ءَاثَٰرِهِم مُّقۡتَدُونَ
Transliteration: Wakathalika ma arsalna min qablika fee qaryatin min natheerin illa qala mutrafooha inna wajadna abaana AAala ommatin wainna AAala atharihim muqtadoona
Translation: Bákan náà, Àwa kò rán olùkìlọ̀ kan sí ìlú kan ṣíwájú rẹ, àyàfi kí àwọn onígbẹdẹmukẹ ìlú náà wí pé: “Dájúdájú àwa bá àwọn bàbá wa lórí ẹ̀sìn kan. Dájúdájú àwa sì ni olùtẹ̀lé wọn lórí orípa wọn.”
قَٰلَ أَوَلَوۡ جِئۡتُكُم بِأَهۡدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمۡ عَلَيۡهِ ءَابَآءَكُمۡۖ قَالُوٓاْ إِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ ﴿24﴾۞قَٰلَ أَوَلَوۡ جِئۡتُكُم بِأَهۡدَىٰ مِمَّا وَجَدتُّمۡ عَلَيۡهِ ءَابَآءَكُمۡۖ قَالُوٓاْ إِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ
Transliteration: Qala awalaw jitukum biahda mimma wajadtum AAalayhi abaakum qaloo inna bima orsiltum bihi kafiroona
Translation: (Olùkìlọ̀) sì sọ pé: “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú wá fún yín ohun tí ó jẹ́ ìmọ̀nà jùlọ sí ohun tí ẹ bá àwọn bàbá yín lórí rẹ̀?” Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”
فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ﴿25﴾فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ
Transliteration: Faintaqamna minhum faonthur kayfa kana AAaqibatu almukaththibeena
Translation: Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn. Wo bí ìkángun àwọn tó pe òdodo ní irọ́ ti rí!
وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦٓ إِنَّنِي بَرَآءٞ مِّمَّا تَعۡبُدُونَ ﴿26﴾وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦٓ إِنَّنِي بَرَآءٞ مِّمَّا تَعۡبُدُونَ
Transliteration: Waith qala ibraheemu liabeehi waqawmihi innanee baraon mimma taAAbudoona
Translation: (Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ kúrò nínú ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún.
إِلَّا ٱلَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُۥ سَيَهۡدِينِ ﴿27﴾إِلَّا ٱلَّذِي فَطَرَنِي فَإِنَّهُۥ سَيَهۡدِينِ
Transliteration: Illa allathee fataranee fainnahu sayahdeeni
Translation: Àfi Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá mi. Dájúdájú Òun l’Ó máa fi ọ̀nà tààrà mọ̀ mí.”
وَجَعَلَهَا كَلِمَةَۢ بَاقِيَةٗ فِي عَقِبِهِۦ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ﴿28﴾وَجَعَلَهَا كَلِمَةَۢ بَاقِيَةٗ فِي عَقِبِهِۦ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Transliteration: WajaAAalaha kalimatan baqiyatan fee AAaqibihi laAAallahum yarjiAAoona
Translation: Allāhu sì ṣe é ní ọ̀rọ̀ kan tó máa wà títí láéláé láààrin àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).1
بَلۡ مَتَّعۡتُ هَـٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ وَرَسُولٞ مُّبِينٞ ﴿29﴾بَلۡ مَتَّعۡتُ هَـٰٓؤُلَآءِ وَءَابَآءَهُمۡ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ وَرَسُولٞ مُّبِينٞ
Transliteration: Bal mattaAAtu haolai waabaahum hatta jaahumu alhaqqu warasoolun mubeenun
Translation: Ṣùgbọ́n Mo fún àwọn wọ̀nyí àti àwọn bàbá wọn ní ìgbádùn ayé títí òdodo àti Òjíṣẹ́ pọ́nńbélé fi dé bá wọn.
وَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ وَإِنَّا بِهِۦ كَٰفِرُونَ ﴿30﴾وَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ قَالُواْ هَٰذَا سِحۡرٞ وَإِنَّا بِهِۦ كَٰفِرُونَ
Transliteration: Walamma jaahumu alhaqqu qaloo hatha sihrun wainna bihi kafiroona
Translation: Nígbà tí òdodo dé bá wọn, wọ́n wí pé: “Idán ni èyí; dájúdájú àwa kò sì níí gbà á gbọ́.”
وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنَ ٱلۡقَرۡيَتَيۡنِ عَظِيمٍ ﴿31﴾وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ عَلَىٰ رَجُلٖ مِّنَ ٱلۡقَرۡيَتَيۡنِ عَظِيمٍ
Transliteration: Waqaloo lawla nuzzila hatha alquranu AAala rajulin mina alqaryatayni AAatheemun
Translation: Wọ́n tún wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí Wọ́n sọ al-Ƙur’ān yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin ńlá kan nínú àwọn ìlú méjèèjì?”
أَهُمۡ يَقۡسِمُونَ رَحۡمَتَ رَبِّكَۚ نَحۡنُ قَسَمۡنَا بَيۡنَهُم مَّعِيشَتَهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَرَفَعۡنَا بَعۡضَهُمۡ فَوۡقَ بَعۡضٖ دَرَجَٰتٖ لِّيَتَّخِذَ بَعۡضُهُم بَعۡضٗا سُخۡرِيّٗاۗ وَرَحۡمَتُ رَبِّكَ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ ﴿32﴾أَهُمۡ يَقۡسِمُونَ رَحۡمَتَ رَبِّكَۚ نَحۡنُ قَسَمۡنَا بَيۡنَهُم مَّعِيشَتَهُمۡ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَرَفَعۡنَا بَعۡضَهُمۡ فَوۡقَ بَعۡضٖ دَرَجَٰتٖ لِّيَتَّخِذَ بَعۡضُهُم بَعۡضٗا سُخۡرِيّٗاۗ وَرَحۡمَتُ رَبِّكَ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ
Transliteration: Ahum yaqsimoona rahmata rabbika nahnu qasamna baynahum maAAeeshatahum fee alhayati alddunya warafaAAna baAAdahum fawqa baAAdin darajatin liyattakhitha baAAduhum baAAdan sukhriyyan warahmatu rabbika khayrun mimma yajmaAAoona
Translation: Ṣé àwọn ni wọn máa pín ìkẹ́ Olúwa rẹ ni? Àwa l’A pín n̄ǹkan ìṣẹ̀mí wọn fún wọn nínú ìgbésí ayé. A sì fi àwọn ipò gíga gbé apá kan wọn ga ju apá kan lọ nítorí kí apá kan wọn lè máa ṣiṣẹ́ fún apá kan. Ìkẹ́ Olúwa rẹ sì lóore jùlọ sí ohun tí wọ́n ń kó jọ.
وَلَوۡلَآ أَن يَكُونَ ٱلنَّاسُ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ لَّجَعَلۡنَا لِمَن يَكۡفُرُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ لِبُيُوتِهِمۡ سُقُفٗا مِّن فِضَّةٖ وَمَعَارِجَ عَلَيۡهَا يَظۡهَرُونَ ﴿33﴾وَلَوۡلَآ أَن يَكُونَ ٱلنَّاسُ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ لَّجَعَلۡنَا لِمَن يَكۡفُرُ بِٱلرَّحۡمَٰنِ لِبُيُوتِهِمۡ سُقُفٗا مِّن فِضَّةٖ وَمَعَارِجَ عَلَيۡهَا يَظۡهَرُونَ
Transliteration: Walawla an yakoona alnnasu ommatan wahidatan lajaAAalna liman yakfuru bialrrahmani libuyootihim suqufan min fiddatin wamaAAarija AAalayha yathharoona
Translation: Tí kò bá jẹ́ pé àwọn ènìyàn máa di ìjọ kan ṣoṣo (tí gbogbo wọn máa di kèfèrí nítorí ọrọ̀ ayé), A ìbá ṣe àwọn òrùlé àti àwọn àkàbà tí wọn yóò fi máa gùnkè nínú ilé ní fàdákà fún ẹni tó ń ṣàì gbàgbọ́ nínú Àjọkẹ́-ayé.
وَلِبُيُوتِهِمۡ أَبۡوَٰبٗا وَسُرُرًا عَلَيۡهَا يَتَّكِـُٔونَ ﴿34﴾وَلِبُيُوتِهِمۡ أَبۡوَٰبٗا وَسُرُرًا عَلَيۡهَا يَتَّكِـُٔونَ
Transliteration: Walibuyootihim abwaban wasururan AAalayha yattakioona
Translation: (A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)
وَزُخۡرُفٗاۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُتَّقِينَ ﴿35﴾وَزُخۡرُفٗاۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُتَّقِينَ
Transliteration: Wazukhrufan wain kullu thalika lamma mataAAu alhayati alddunya waalakhiratu AAinda rabbika lilmuttaqeena
Translation: àti góòlù.Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
وَمَن يَعۡشُ عَن ذِكۡرِ ٱلرَّحۡمَٰنِ نُقَيِّضۡ لَهُۥ شَيۡطَٰنٗا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٞ ﴿36﴾وَمَن يَعۡشُ عَن ذِكۡرِ ٱلرَّحۡمَٰنِ نُقَيِّضۡ لَهُۥ شَيۡطَٰنٗا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٞ
Transliteration: Waman yaAAshu AAan thikri alrrahmani nuqayyid lahu shaytanan fahuwa lahu qareenun
Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀.
وَإِنَّهُمۡ لَيَصُدُّونَهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُم مُّهۡتَدُونَ ﴿37﴾وَإِنَّهُمۡ لَيَصُدُّونَهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُم مُّهۡتَدُونَ
Transliteration: Wainnahum layasuddoonahum AAani alssabeeli wayahsaboona annahum muhtadoona
Translation: Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.
حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَٰلَيۡتَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَ بُعۡدَ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرِينُ ﴿38﴾حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَٰلَيۡتَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَ بُعۡدَ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرِينُ
Transliteration: Hatta itha jaana qala ya layta baynee wabaynaka buAAda almashriqayni fabisa alqareenu
Translation: Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: “Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni.
وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ إِذ ظَّلَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ ﴿39﴾وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ إِذ ظَّلَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ
Transliteration: Walan yanfaAAakumu alyawma ith thalamtum annakum fee alAAathabi mushtarikoona
Translation: (Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni ẹ dìjọ máa kẹ́gbẹ́ nínú ìyà.
أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ أَوۡ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ ﴿40﴾أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ أَوۡ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ
Transliteration: Afaanta tusmiAAu alssumma aw tahdee alAAumya waman kana fee dalalin mubeenin
Translation: Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé?1
فَإِمَّا نَذۡهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنۡهُم مُّنتَقِمُونَ ﴿41﴾فَإِمَّا نَذۡهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنۡهُم مُّنتَقِمُونَ
Transliteration: Faimma nathhabanna bika fainna minhum muntaqimoona
Translation: Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn.
أَوۡ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِي وَعَدۡنَٰهُمۡ فَإِنَّا عَلَيۡهِم مُّقۡتَدِرُونَ ﴿42﴾أَوۡ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِي وَعَدۡنَٰهُمۡ فَإِنَّا عَلَيۡهِم مُّقۡتَدِرُونَ
Transliteration: Aw nuriyannaka allathee waAAadnahum fainna AAalayhim muqtadiroona
Translation: Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn.
فَٱسۡتَمۡسِكۡ بِٱلَّذِيٓ أُوحِيَ إِلَيۡكَۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿43﴾فَٱسۡتَمۡسِكۡ بِٱلَّذِيٓ أُوحِيَ إِلَيۡكَۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ
Transliteration: Faistamsik biallathee oohiya ilayka innaka AAala siratin mustaqeemin
Translation: Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām).
وَإِنَّهُۥ لَذِكۡرٞ لَّكَ وَلِقَوۡمِكَۖ وَسَوۡفَ تُسۡـَٔلُونَ ﴿44﴾وَإِنَّهُۥ لَذِكۡرٞ لَّكَ وَلِقَوۡمِكَۖ وَسَوۡفَ تُسۡـَٔلُونَ
Transliteration: Wainnahu lathikrun laka waliqawmika wasawfa tusaloona
Translation: Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀).
وَسۡـَٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةٗ يُعۡبَدُونَ ﴿45﴾وَسۡـَٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةٗ يُعۡبَدُونَ
Transliteration: Waisal man arsalna min qablika min rusulina ajaAAalna min dooni alrrahmani alihatan yuAAbadoona
Translation: Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): “Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?”1
وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَقَالَ إِنِّي رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿46﴾وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَقَالَ إِنِّي رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Transliteration: Walaqad arsalna moosa biayatina ila firAAawna wamalaihi faqala innee rasoolu rabbi alAAalameena
Translation: A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”
فَلَمَّا جَآءَهُم بِـَٔايَٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَضۡحَكُونَ ﴿47﴾فَلَمَّا جَآءَهُم بِـَٔايَٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَضۡحَكُونَ
Transliteration: Falamma jaahum biayatina itha hum minha yadhakoona
Translation: Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà.
وَمَا نُرِيهِم مِّنۡ ءَايَةٍ إِلَّا هِيَ أَكۡبَرُ مِنۡ أُخۡتِهَاۖ وَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ﴿48﴾وَمَا نُرِيهِم مِّنۡ ءَايَةٍ إِلَّا هِيَ أَكۡبَرُ مِنۡ أُخۡتِهَاۖ وَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡعَذَابِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ
Transliteration: Wama nureehim min ayatin illa hiya akbaru min okhtiha waakhathnahum bialAAathabi laAAallahum yarjiAAoona
Translation: A kò níí fi àmì kan hàn wọ́n àyàfi kí ó tóbi ju irú rẹ̀ (tó ṣíwájú). A sì fi ìyà jẹ wọ́n nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).
وَقَالُواْ يَـٰٓأَيُّهَ ٱلسَّاحِرُ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهۡتَدُونَ ﴿49﴾وَقَالُواْ يَـٰٓأَيُّهَ ٱلسَّاحِرُ ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَ إِنَّنَا لَمُهۡتَدُونَ
Transliteration: Waqaloo ya ayyuha alsahiru odAAu lana rabbaka bima AAahida AAindaka innana lamuhtadoona
Translation: Wọ́n sì wí pé: “Ìwọ òpìdán, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe pẹ̀lú rẹ. Dájúdájú àwa máa tẹ̀lé ìmọ̀nà Rẹ̀.”
فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ ﴿50﴾فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلۡعَذَابَ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ
Transliteration: Falamma kashafna AAanhumu alAAathaba itha hum yankuthoona
Translation: Ṣùgbọ́n nígbà tí A bá mú ìyà kúrò fún wọn, nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.
وَنَادَىٰ فِرۡعَوۡنُ فِي قَوۡمِهِۦ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَيۡسَ لِي مُلۡكُ مِصۡرَ وَهَٰذِهِ ٱلۡأَنۡهَٰرُ تَجۡرِي مِن تَحۡتِيٓۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ ﴿51﴾وَنَادَىٰ فِرۡعَوۡنُ فِي قَوۡمِهِۦ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَيۡسَ لِي مُلۡكُ مِصۡرَ وَهَٰذِهِ ٱلۡأَنۡهَٰرُ تَجۡرِي مِن تَحۡتِيٓۚ أَفَلَا تُبۡصِرُونَ
Transliteration: Wanada firAAawnu fee qawmihi qala ya qawmi alaysa lee mulku misra wahathihi alanharu tajree min tahtee afala tubsiroona
Translation: Fir‘aon sì pèpè láààrin àwọn ènìyàn rẹ̀, ó wí pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ṣé tèmi kọ́ ni ìjọba Misrọ àti àwọn odò wọ̀nyí tó ń ṣàn nísàlẹ̀ (ọ̀dọ̀) mi? Ṣé ẹ kò ríran ni?
أَمۡ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي هُوَ مَهِينٞ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ ﴿52﴾أَمۡ أَنَا۠ خَيۡرٞ مِّنۡ هَٰذَا ٱلَّذِي هُوَ مَهِينٞ وَلَا يَكَادُ يُبِينُ
Transliteration: Am ana khayrun min hatha allathee huwa maheenun wala yakadu yubeenu
Translation: Tàbí ṣé èmi kò lóore ju èyí tí ó jẹ́ ọ̀lẹ ẹni yẹpẹrẹ, tí ó fẹ́ẹ̀ má lè dá ọ̀rọ̀ sọ yanjú?
فَلَوۡلَآ أُلۡقِيَ عَلَيۡهِ أَسۡوِرَةٞ مِّن ذَهَبٍ أَوۡ جَآءَ مَعَهُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ مُقۡتَرِنِينَ ﴿53﴾فَلَوۡلَآ أُلۡقِيَ عَلَيۡهِ أَسۡوِرَةٞ مِّن ذَهَبٍ أَوۡ جَآءَ مَعَهُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ مُقۡتَرِنِينَ
Transliteration: Falawla olqiya AAalayhi aswiratun min thahabin aw jaa maAAahu almalaikatu muqtarineena
Translation: Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n fún un ní àwọn ẹ̀gbà-ọwọ́ góòlù tàbí (kí ni kò jẹ́ kí) àwọn mọlāika wá pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n jẹ́ alábàárìn (tí wọn yóò máa jẹ́rìí rẹ̀)?”
فَٱسۡتَخَفَّ قَوۡمَهُۥ فَأَطَاعُوهُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ ﴿54﴾فَٱسۡتَخَفَّ قَوۡمَهُۥ فَأَطَاعُوهُۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ
Transliteration: Faistakhaffa qawmahu faataAAoohu innahum kanoo qawman fasiqeena
Translation: Nítorí náà, ó sọ àwọn ènìyàn rẹ̀ di òpè. Wọ́n sì tẹ̀lé e. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.
فَلَمَّآ ءَاسَفُونَا ٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ ﴿55﴾فَلَمَّآ ءَاسَفُونَا ٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ أَجۡمَعِينَ
Transliteration: Falamma asafoona intaqamna minhum faaghraqnahum ajmaAAeena
Translation: Nígbà tí wọ́n wá ìbínú Wa, A gba ẹ̀san (ìyà) lára wọn. Nítorí náà, A tẹ gbogbo wọn rì (sínú agbami odò).
فَجَعَلۡنَٰهُمۡ سَلَفٗا وَمَثَلٗا لِّلۡأٓخِرِينَ ﴿56﴾فَجَعَلۡنَٰهُمۡ سَلَفٗا وَمَثَلٗا لِّلۡأٓخِرِينَ
Transliteration: FajaAAalnahum salafan wamathalan lilakhireena
Translation: A sì ṣe wọ́n ní ìjọ aṣíwájú (nínú ìparun) àti àpẹ̀ẹrẹ (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn ẹni ìkẹ́yìn.
وَلَمَّا ضُرِبَ ٱبۡنُ مَرۡيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوۡمُكَ مِنۡهُ يَصِدُّونَ ﴿57﴾۞وَلَمَّا ضُرِبَ ٱبۡنُ مَرۡيَمَ مَثَلًا إِذَا قَوۡمُكَ مِنۡهُ يَصِدُّونَ
Transliteration: Walamma duriba ibnu maryama mathalan itha qawmuka minhu yasiddoona
Translation: Nígbà tí àwọn ọ̀ṣẹbọ fi ọmọ Mọryam ṣe àpẹ̀ẹrẹ (fún òrìṣà wọn), nígbà náà ni àwọn ènìyàn rẹ bá ń fi (àpẹ̀ẹrẹ náà) rẹ́rìn-ín.
وَقَالُوٓاْ ءَأَٰلِهَتُنَا خَيۡرٌ أَمۡ هُوَۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلَۢاۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ خَصِمُونَ ﴿58﴾وَقَالُوٓاْ ءَأَٰلِهَتُنَا خَيۡرٌ أَمۡ هُوَۚ مَا ضَرَبُوهُ لَكَ إِلَّا جَدَلَۢاۚ بَلۡ هُمۡ قَوۡمٌ خَصِمُونَ
Transliteration: Waqaloo aalihatuna khayrun am huwa ma daraboohu laka illa jadalan bal hum qawmun khasimoona
Translation: Wọ́n sì wí pé: “Ṣé àwọn òrìṣà wa l’ó lóore jùlọ ni tàbí òun? Wọn kò wulẹ̀ fi ṣàpẹ̀ẹrẹ fún ọ bí kò ṣe (fún) àtakò. Àní sẹ́, ìjọ oníyànjíjà ni wọ́n.
إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ﴿59﴾إِنۡ هُوَ إِلَّا عَبۡدٌ أَنۡعَمۡنَا عَلَيۡهِ وَجَعَلۡنَٰهُ مَثَلٗا لِّبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ
Transliteration: In huwa illa AAabdun anAAamna AAalayhi wajaAAalnahu mathalan libanee israeela
Translation: Kí ni òun bí kò ṣe ẹrúsìn kan tí A ṣe ìdẹ̀ra fún. A sì ṣe é ní àpẹ̀ẹrẹ rere fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl.1
وَلَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَا مِنكُم مَّلَـٰٓئِكَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَخۡلُفُونَ ﴿60﴾وَلَوۡ نَشَآءُ لَجَعَلۡنَا مِنكُم مَّلَـٰٓئِكَةٗ فِي ٱلۡأَرۡضِ يَخۡلُفُونَ
Transliteration: Walaw nashao lajaAAalna minkum malaikatan fee alardi yakhlufoona
Translation: Tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, A ìbá máa fi àwọn mọlāika rọ́pò yín lórí ilẹ̀.
وَإِنَّهُۥ لَعِلۡمٞ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمۡتَرُنَّ بِهَا وَٱتَّبِعُونِۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ ﴿61﴾وَإِنَّهُۥ لَعِلۡمٞ لِّلسَّاعَةِ فَلَا تَمۡتَرُنَّ بِهَا وَٱتَّبِعُونِۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Transliteration: Wainnahu laAAilmun lilssaAAati fala tamtarunna biha waittabiAAooni hatha siratun mustaqeemun
Translation: Dájúdájú òun ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣeyèméjì lórí rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà.1
وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ ﴿62﴾وَلَا يَصُدَّنَّكُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُۖ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ
Transliteration: Wala yasuddannakumu alshshaytanu innahu lakum AAaduwwun mubeenun
Translation: Ẹ má ṣe jẹ́ kí Èṣù ṣẹ yín lórí (kúrò lójú ọ̀nà tààrà náà); dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.
وَلَمَّا جَآءَ عِيسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالَ قَدۡ جِئۡتُكُم بِٱلۡحِكۡمَةِ وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي تَخۡتَلِفُونَ فِيهِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ ﴿63﴾وَلَمَّا جَآءَ عِيسَىٰ بِٱلۡبَيِّنَٰتِ قَالَ قَدۡ جِئۡتُكُم بِٱلۡحِكۡمَةِ وَلِأُبَيِّنَ لَكُم بَعۡضَ ٱلَّذِي تَخۡتَلِفُونَ فِيهِۖ فَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَأَطِيعُونِ
Transliteration: Walamma jaa AAeesa bialbayyinati qala qad jitukum bialhikmati waliobayyina lakum baAAda allathee takhtalifoona feehi faittaqoo Allaha waateeAAooni
Translation: Nígbà tí (Ànábì) ‘Īsā dé pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ó sọ pé: “Dájúdájú mo dé wá ba yín pẹ̀lú ọgbọ́n ìjìnlẹ̀. (Mo sì dé) nítorí kí n̄g lè ṣe àlàyé apá kan èyí tí ẹ̀ ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀ fún yín. Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù Allāhu, kí ẹ sì tẹ̀lé mi.
إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ ﴿64﴾إِنَّ ٱللَّهَ هُوَ رَبِّي وَرَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ هَٰذَا صِرَٰطٞ مُّسۡتَقِيمٞ
Transliteration: Inna Allaha huwa rabbee warabbukum faoAAbudoohu hatha siratun mustaqeemun
Translation: Dájúdájú Allāhu ni Olúwa mi àti Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Èyí ni ọ̀nà tààrà.”
فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ عَذَابِ يَوۡمٍ أَلِيمٍ ﴿65﴾فَٱخۡتَلَفَ ٱلۡأَحۡزَابُ مِنۢ بَيۡنِهِمۡۖ فَوَيۡلٞ لِّلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡ عَذَابِ يَوۡمٍ أَلِيمٍ
Transliteration: Faikhtalafa alahzabu min baynihim fawaylun lillatheena thalamoo min AAathabi yawmin aleemin
Translation: Àwọn ìjọ (rẹ̀) sì yapa (ẹ̀sìn ’Islām) láààrin ara wọn. Nítorí náà, ègbé ni fún àwọn tó ṣàbòsí ní ọjọ́ ìyà ẹlẹ́ta-eléro.
هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ ﴿66﴾هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا ٱلسَّاعَةَ أَن تَأۡتِيَهُم بَغۡتَةٗ وَهُمۡ لَا يَشۡعُرُونَ
Transliteration: Hal yanthuroona illa alssaAAata an tatiyahum baghtatan wahum la yashAAuroona
Translation: Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe Àkókò náà; tí ó máa dé bá wọn ní òjijì; wọn kò sì níí fura?
ٱلۡأَخِلَّآءُ يَوۡمَئِذِۭ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوٌّ إِلَّا ٱلۡمُتَّقِينَ ﴿67﴾ٱلۡأَخِلَّآءُ يَوۡمَئِذِۭ بَعۡضُهُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوٌّ إِلَّا ٱلۡمُتَّقِينَ
Transliteration: Alakhillao yawmaithin baAAduhum libaAAdin AAaduwwun illa almuttaqeena
Translation: Àwọn ọ̀rẹ́ àyò ní ọjọ́ yẹn, apá kan wọn yóò jẹ́ ọ̀tá fún apá kan àyàfi àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
يَٰعِبَادِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَآ أَنتُمۡ تَحۡزَنُونَ ﴿68﴾يَٰعِبَادِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡكُمُ ٱلۡيَوۡمَ وَلَآ أَنتُمۡ تَحۡزَنُونَ
Transliteration: Ya AAibadi la khawfun AAalaykumu alyawma wala antum tahzanoona
Translation: Ẹ̀yin ẹrúsìn Mi, kò sí ìbẹ̀rù fún yín ní òní. Ẹ̀yin kò sì níí banújẹ́.
ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ مُسۡلِمِينَ ﴿69﴾ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ مُسۡلِمِينَ
Transliteration: Allatheena amanoo biayatina wakanoo muslimeena
Translation: (Àwọn ni) àwọn tó gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, tí wọ́n sì jẹ́ mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀ fún Allāhu).
ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ أَنتُمۡ وَأَزۡوَٰجُكُمۡ تُحۡبَرُونَ ﴿70﴾ٱدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ أَنتُمۡ وَأَزۡوَٰجُكُمۡ تُحۡبَرُونَ
Transliteration: Odkhuloo aljannata antum waazwajukum tuhbaroona
Translation: Ẹ wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra, ẹ̀yin àti àwọn ìyàwó yín; kí wọ́n máa dun yín nínú.
يُطَافُ عَلَيۡهِم بِصِحَافٖ مِّن ذَهَبٖ وَأَكۡوَابٖۖ وَفِيهَا مَا تَشۡتَهِيهِ ٱلۡأَنفُسُ وَتَلَذُّ ٱلۡأَعۡيُنُۖ وَأَنتُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿71﴾يُطَافُ عَلَيۡهِم بِصِحَافٖ مِّن ذَهَبٖ وَأَكۡوَابٖۖ وَفِيهَا مَا تَشۡتَهِيهِ ٱلۡأَنفُسُ وَتَلَذُّ ٱلۡأَعۡيُنُۖ وَأَنتُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ
Transliteration: Yutafu AAalayhim bisihafin min thahabin waakwabin wafeeha ma tashtaheehi alanfusu watalaththu alaAAyunu waantum feeha khalidoona
Translation: Wọn yóò máa gbé àwọn àwo góòlù àti àwọn ife ìmumi káà kiri ọ̀dọ̀ wọn. Ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́ àti (ohun tí) ojú yóò máa dúnnú sí wà nínú rẹ̀. Olùṣegbére sì ni yín nínú rẹ̀.
وَتِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِيٓ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿72﴾وَتِلۡكَ ٱلۡجَنَّةُ ٱلَّتِيٓ أُورِثۡتُمُوهَا بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ
Transliteration: Watilka aljannatu allatee oorithtumooha bima kuntum taAAmaloona
Translation: Ìyẹn ni Ọgbà Ìdẹ̀ra tí A jogún rẹ̀ fún yín nítorí ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
لَكُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ كَثِيرَةٞ مِّنۡهَا تَأۡكُلُونَ ﴿73﴾لَكُمۡ فِيهَا فَٰكِهَةٞ كَثِيرَةٞ مِّنۡهَا تَأۡكُلُونَ
Transliteration: Lakum feeha fakihatun katheeratun minha takuloona
Translation: Èso púpọ̀ wà fún yín nínú rẹ̀. Ẹ̀yin yó sì máa jẹ nínú rẹ̀.
إِنَّ ٱلۡمُجۡرِمِينَ فِي عَذَابِ جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ ﴿74﴾إِنَّ ٱلۡمُجۡرِمِينَ فِي عَذَابِ جَهَنَّمَ خَٰلِدُونَ
Transliteration: Inna almujrimeena fee AAathabi jahannama khalidoona
Translation: Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni olùṣegbére nínú ìyà iná Jahanamọ.
لَا يُفَتَّرُ عَنۡهُمۡ وَهُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ ﴿75﴾لَا يُفَتَّرُ عَنۡهُمۡ وَهُمۡ فِيهِ مُبۡلِسُونَ
Transliteration: La yufattaru AAanhum wahum feehi mublisoona
Translation: A kò níí gbé e fúyẹ́ fún wọn. Wọn yó sì sọ̀rètí nù nínú Iná.
وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُواْ هُمُ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿76﴾وَمَا ظَلَمۡنَٰهُمۡ وَلَٰكِن كَانُواْ هُمُ ٱلظَّـٰلِمِينَ
Transliteration: Wama thalamnahum walakin kanoo humu alththalimeena
Translation: A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n àwọn ni wọ́n jẹ́ alábòsí.
وَنَادَوۡاْ يَٰمَٰلِكُ لِيَقۡضِ عَلَيۡنَا رَبُّكَۖ قَالَ إِنَّكُم مَّـٰكِثُونَ ﴿77﴾وَنَادَوۡاْ يَٰمَٰلِكُ لِيَقۡضِ عَلَيۡنَا رَبُّكَۖ قَالَ إِنَّكُم مَّـٰكِثُونَ
Transliteration: Wanadaw ya maliku liyaqdi AAalayna rabbuka qala innakum makithoona
Translation: Wọn yóò pe (mọlāika kan) pé: “Mọ̄lik (ẹ̀ṣọ́ Iná), jẹ́ kí Olúwa rẹ pa wá ráúráú.” (Mọ̄lik) yóò sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin yóò máa gbé inú rẹ̀ ni.”
لَقَدۡ جِئۡنَٰكُم بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَكُمۡ لِلۡحَقِّ كَٰرِهُونَ ﴿78﴾لَقَدۡ جِئۡنَٰكُم بِٱلۡحَقِّ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَكُمۡ لِلۡحَقِّ كَٰرِهُونَ
Transliteration: Laqad jinakum bialhaqqi walakinna aktharakum lilhaqqi karihoona
Translation: Dájúdájú A ti mú òdodo wá ba yín, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ yin kórira òdodo.
أَمۡ أَبۡرَمُوٓاْ أَمۡرٗا فَإِنَّا مُبۡرِمُونَ ﴿79﴾أَمۡ أَبۡرَمُوٓاْ أَمۡرٗا فَإِنَّا مُبۡرِمُونَ
Transliteration: Am abramoo amran fainna mubrimoona
Translation: Tàbí àwọn (aláìgbàgbọ́) ti pinnu ọ̀rọ̀ kan ni? Dájúdájú Àwa náà ń pinnu ọ̀rọ̀.
أَمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّا لَا نَسۡمَعُ سِرَّهُمۡ وَنَجۡوَىٰهُمۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا لَدَيۡهِمۡ يَكۡتُبُونَ ﴿80﴾أَمۡ يَحۡسَبُونَ أَنَّا لَا نَسۡمَعُ سِرَّهُمۡ وَنَجۡوَىٰهُمۚ بَلَىٰ وَرُسُلُنَا لَدَيۡهِمۡ يَكۡتُبُونَ
Transliteration: Am yahsaboona anna la nasmaAAu sirrahum wanajwahum bala warusuluna ladayhim yaktuboona
Translation: Tàbí wọ́n ń lérò pé Àwa kò gbọ́ ọ̀rọ̀ àṣírí wọn àti ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ wọn? Bẹ́ẹ̀ ni (À ń gbọ́ ọ); àwọn Òjíṣẹ́ Wa wà ní ọ̀dọ̀ wọn, tí wọ́n ń ṣe àkọsílẹ̀ (ọ̀rọ̀ wọn).
قُلۡ إِن كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٞ فَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡعَٰبِدِينَ ﴿81﴾قُلۡ إِن كَانَ لِلرَّحۡمَٰنِ وَلَدٞ فَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡعَٰبِدِينَ
Transliteration: Qul in kana lilrrahmani waladun faana awwalu alAAabideena
Translation: Sọ pé: “Kò sí ọmọ kan fún Àjọké ayé. Nítorí náà, èmi ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn olùjọ́sìn (fún Allāhu ní àsìkò tèmi).1
سُبۡحَٰنَ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَرۡشِ عَمَّا يَصِفُونَ ﴿82﴾سُبۡحَٰنَ رَبِّ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ رَبِّ ٱلۡعَرۡشِ عَمَّا يَصِفُونَ
Transliteration: Subhana rabbi alssamawati waalardi rabbi alAAarshi AAamma yasifoona
Translation: Mímọ́ ni fún Olúwa àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, Olúwa Ìtẹ́-ọlá tayọ irọ́ tí wọ́n ń pa (mọ́ Ọn).
فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ ﴿83﴾فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ
Transliteration: Fatharhum yakhoodoo wayalAAaboo hatta yulaqoo yawmahumu allathee yooAAadoona
Translation: Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré wọn lọ títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn, tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
وَهُوَ ٱلَّذِي فِي ٱلسَّمَآءِ إِلَٰهٞ وَفِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَٰهٞۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿84﴾وَهُوَ ٱلَّذِي فِي ٱلسَّمَآءِ إِلَٰهٞ وَفِي ٱلۡأَرۡضِ إِلَٰهٞۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡعَلِيمُ
Transliteration: Wahuwa allathee fee alssamai ilahun wafee alardi ilahun wahuwa alhakeemu alAAaleemu
Translation: (Allāhu) Òun ni Ọlọ́hun tí wọ́n ń jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo nínú sánmọ̀. Òun náà sì ni Ọlọ́hun tí wọ́n gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lórí ilẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.
وَتَبَارَكَ ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿85﴾وَتَبَارَكَ ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَعِندَهُۥ عِلۡمُ ٱلسَّاعَةِ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ
Transliteration: Watabaraka allathee lahu mulku alssamawati waalardi wama baynahuma waAAindahu AAilmu alssaAAati wailayhi turjaAAoona
Translation: Ìbùkún ni fún Ẹni tí Ó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọ́n máa da yín padà sí.
وَلَا يَمۡلِكُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ ﴿86﴾وَلَا يَمۡلِكُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِهِ ٱلشَّفَٰعَةَ إِلَّا مَن شَهِدَ بِٱلۡحَقِّ وَهُمۡ يَعۡلَمُونَ
Transliteration: Wala yamliku allatheena yadAAoona min doonihi alshshafaAAata illa man shahida bialhaqqi wahum yaAAlamoona
Translation: Àwọn tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Rẹ̀, wọn kò ní ìkápá ìṣìpẹ̀ àyàfi ẹni tí ó bá jẹ́rìí sí òdodo (kalmọtuṣ-ṣahaadah), tí wọ́n sì nímọ̀ (rẹ̀).1
وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ ﴿87﴾وَلَئِن سَأَلۡتَهُم مَّنۡ خَلَقَهُمۡ لَيَقُولُنَّ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ يُؤۡفَكُونَ
Transliteration: Walain saaltahum man khalaqahum layaqoolunna Allahu faanna yufakoona
Translation: Àti pé tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá wọn?”, dájúdájú wọn á wí pé: “Allāhu ni.” Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí wọn kúrò níbi òdodo?
وَقِيلِهِۦ يَٰرَبِّ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٞ لَّا يُؤۡمِنُونَ ﴿88﴾وَقِيلِهِۦ يَٰرَبِّ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ قَوۡمٞ لَّا يُؤۡمِنُونَ
Transliteration: Waqeelihi yarabbi inna haolai qawmun la yuminoona
Translation: Ọ̀rọ̀ (tí Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ń sọ fún Allāhu ni pé): “Olúwa Mi, dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni ìjọ tí kò gbàgbọ́.”
فَٱصۡفَحۡ عَنۡهُمۡ وَقُلۡ سَلَٰمٞۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ ﴿89﴾فَٱصۡفَحۡ عَنۡهُمۡ وَقُلۡ سَلَٰمٞۚ فَسَوۡفَ يَعۡلَمُونَ
Transliteration: Faisfah AAanhum waqul salamun fasawfa yaAAlamoona
Translation: Nítorí náà, ṣàmójú kúrò fún wọn, kí ó sì sọ pé: “Àlàáfíà!” Láìpẹ́ wọ́n máa mọ̀.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download