quranm◉

Surah Al-Hujurat transliteration

◉ Súrá · ∞

49:1

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تُقَدِّمُواْ بَيۡنَ يَدَيِ ٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۖ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿1﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la tuqaddimoo bayna yadayi Allahi warasoolihi waittaqoo Allaha inna Allaha sameeAAun AAaleemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ gbawájú mọ́ Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ lọ́wọ́. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

49:2

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَرۡفَعُوٓاْ أَصۡوَٰتَكُمۡ فَوۡقَ صَوۡتِ ٱلنَّبِيِّ وَلَا تَجۡهَرُواْ لَهُۥ بِٱلۡقَوۡلِ كَجَهۡرِ بَعۡضِكُمۡ لِبَعۡضٍ أَن تَحۡبَطَ أَعۡمَٰلُكُمۡ وَأَنتُمۡ لَا تَشۡعُرُونَ ﴿2﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la tarfaAAoo aswatakum fawqa sawti alnnabiyyi wala tajharoo lahu bialqawli kajahri baAAdikum libaAAdin an tahbata aAAmalukum waantum la tashAAuroona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe gbé ohùn yín ga borí ohùn Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -. Kí ẹ sì má ṣe fi ohùn ariwo bá a sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan yín ṣe ń fi ohùn ariwo bá apá kan sọ̀rọ̀ nítorí kí àwọn iṣẹ́ yín má baà bàjẹ́, ẹ̀yin kò sì níí fura.

49:3

إِنَّ ٱلَّذِينَ يَغُضُّونَ أَصۡوَٰتَهُمۡ عِندَ رَسُولِ ٱللَّهِ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ٱمۡتَحَنَ ٱللَّهُ قُلُوبَهُمۡ لِلتَّقۡوَىٰۚ لَهُم مَّغۡفِرَةٞ وَأَجۡرٌ عَظِيمٌ ﴿3﴾

Transliteration: Inna allatheena yaghuddoona aswatahum AAinda rasooli Allahi olaika allatheena imtahana Allahu quloobahum lilttaqwa lahum maghfiratun waajrun AAatheemun

Translation: Dájúdájú àwọn tó ń rẹ ohùn wọn nílẹ̀ lọ́dọ̀ Òjíṣẹ́ Allāhu, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ti gbìdánwò ọkàn wọn fún ìbẹ̀rù (Rẹ̀). Àforíjìn àti ẹ̀san ńlá wà fún wọn.

49:4

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُنَادُونَكَ مِن وَرَآءِ ٱلۡحُجُرَٰتِ أَكۡثَرُهُمۡ لَا يَعۡقِلُونَ ﴿4﴾

Transliteration: Inna allatheena yunadoonaka min warai alhujurati aktharuhum la yaAAqiloona

Translation: Dájúdájú àwọn tó ń pè ọ́ láti ẹ̀yìn àwọn yàrá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò ṣe làákàyè.

49:5

وَلَوۡ أَنَّهُمۡ صَبَرُواْ حَتَّىٰ تَخۡرُجَ إِلَيۡهِمۡ لَكَانَ خَيۡرٗا لَّهُمۡۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿5﴾

Transliteration: Walaw annahum sabaroo hatta takhruja ilayhim lakana khayran lahum waAllahu ghafoorun raheemun

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n ṣe sùúrù títí o máa fi jáde sí wọn ni, ìbá dára jùlọ fún wọn. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

49:6

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِن جَآءَكُمۡ فَاسِقُۢ بِنَبَإٖ فَتَبَيَّنُوٓاْ أَن تُصِيبُواْ قَوۡمَۢا بِجَهَٰلَةٖ فَتُصۡبِحُواْ عَلَىٰ مَا فَعَلۡتُمۡ نَٰدِمِينَ ﴿6﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo in jaakum fasiqun binabain fatabayyanoo an tuseeboo qawman bijahalatin fatusbihoo AAala ma faAAaltum nadimeena

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, tí arúfin kan bá mú ìró kan wá ba yín, ẹ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láti mọ òdodo (nípa ọ̀rọ̀ náà) nítorí kí ẹ má baà ṣe àwọn ènìyàn kan ní ṣùtá pẹ̀lú àìmọ̀, kí ẹ má baà di olùkábàámọ̀ lórí ohun tí ẹ ṣe.

49:7

وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ فِيكُمۡ رَسُولَ ٱللَّهِۚ لَوۡ يُطِيعُكُمۡ فِي كَثِيرٖ مِّنَ ٱلۡأَمۡرِ لَعَنِتُّمۡ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ حَبَّبَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡإِيمَٰنَ وَزَيَّنَهُۥ فِي قُلُوبِكُمۡ وَكَرَّهَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكُفۡرَ وَٱلۡفُسُوقَ وَٱلۡعِصۡيَانَۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلرَّـٰشِدُونَ ﴿7﴾

Transliteration: WaiAAlamoo anna feekum rasoola Allahi law yuteeAAukum fee katheerin mina alamri laAAanittum walakinna Allaha habbaba ilaykumu aleemana wazayyanahu fee quloobikum wakarraha ilaykumu alkufra waalfusooqa waalAAisyana olaika humu alrrashidoona

Translation: Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Òjíṣẹ́ Allāhu wà lààrin yín.Tí ó bá jẹ́ pé ó ń tẹ̀lé yín níbi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ (tó ń ṣẹlẹ̀) ni, dájúdájú ẹ̀yin ìbá ti kó ara yín sínú wàhálà. Ṣùgbọ́n Allāhu jẹ́ kí ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìgbàgbọ́ òdodo. Ó ṣe é ní ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ó sì jẹ́ kí ẹ kórira àìgbàgbọ́, ìwà burúkú àti ìyapa àṣẹ. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn olùmọ̀nà.

49:8

فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَنِعۡمَةٗۚ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴿8﴾

Transliteration: Fadlan mina Allahi waniAAmatan waAllahu AAaleemun hakeemun

Translation: (Èyí jẹ́) oore àjùlọ àti ìdẹ̀ra láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

49:9

وَإِن طَآئِفَتَانِ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱقۡتَتَلُواْ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَاۖ فَإِنۢ بَغَتۡ إِحۡدَىٰهُمَا عَلَى ٱلۡأُخۡرَىٰ فَقَٰتِلُواْ ٱلَّتِي تَبۡغِي حَتَّىٰ تَفِيٓءَ إِلَىٰٓ أَمۡرِ ٱللَّهِۚ فَإِن فَآءَتۡ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَهُمَا بِٱلۡعَدۡلِ وَأَقۡسِطُوٓاْۖ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ ﴿9﴾

Transliteration: Wain taifatani mina almumineena iqtataloo faaslihoo baynahuma fain baghat ihdahuma AAala alokhra faqatiloo allatee tabghee hatta tafeea ila amri Allahi fain faat faaslihoo baynahuma bialAAadli waaqsitoo inna Allaha yuhibbu almuqsiteena

Translation: Tí igun méjì nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo bá ń bá ara wọn jà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì. Tí ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì bá sì kọjá ẹnu-ààlà lórí ìkejì, ẹ bá èyí tí ó kọjá ẹnu-ààlà jà títí ó fi máa ṣẹ́rí padà síbi àṣẹ Allāhu. Tí ó bá sì ṣẹ́rí padà, ẹ ṣe àtúnṣe láààrin àwọn méjèèjì pẹ̀lú déédé. Kí ẹ ṣe déédé. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe- déédé.

49:10

إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ إِخۡوَةٞ فَأَصۡلِحُواْ بَيۡنَ أَخَوَيۡكُمۡۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ ﴿10﴾

Transliteration: Innama almuminoona ikhwatun faaslihoo bayna akhawaykum waittaqoo Allaha laAAallakum turhamoona

Translation: Ọmọ ìyá (ẹ̀sìn) ni àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Nítorí náà, ẹ ṣàtúnṣe láààrin àwọn ọmọ ìyá yín méjèèjì. Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu nítorí kí A lè kẹ yín.

49:11

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا يَسۡخَرۡ قَوۡمٞ مِّن قَوۡمٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُونُواْ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَلَا نِسَآءٞ مِّن نِّسَآءٍ عَسَىٰٓ أَن يَكُنَّ خَيۡرٗا مِّنۡهُنَّۖ وَلَا تَلۡمِزُوٓاْ أَنفُسَكُمۡ وَلَا تَنَابَزُواْ بِٱلۡأَلۡقَٰبِۖ بِئۡسَ ٱلِٱسۡمُ ٱلۡفُسُوقُ بَعۡدَ ٱلۡإِيمَٰنِۚ وَمَن لَّمۡ يَتُبۡ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿11﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la yaskhar qawmun min qawmin AAasa an yakoonoo khayran minhum wala nisaon min nisain AAasa an yakunna khayran minhunna wala talmizoo anfusakum wala tanabazoo bialalqabi bisa alismu alfusooqu baAAda aleemani waman lam yatub faolaika humu alththalimoona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, àwọn ènìyàn kan kò gbọ́dọ̀ fi àwọn ènìyàn kan ṣe yẹ̀yẹ́. Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Àwọn obìnrin kan (kò sì gbọ́dọ̀ fi) àwọn obìnrin kan (ṣe yẹ̀yẹ́). Ó lè jẹ́ pé àwọn (tí wọ́n sọ di oníyẹ̀yẹ́) dára ju àwọn (tó ń ṣe yẹ̀yẹ́). Ẹ má ṣe búra yín. Ẹ má pe’ra yín ní ìnagijẹ burúkú. Orúkọ burúkú (tí kò bá òfin ẹ̀sìn mu) burú lẹ́yìn ìgbàgbọ́ òdodo. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ronú pìwàdà, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

49:12

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱجۡتَنِبُواْ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلظَّنِّ إِنَّ بَعۡضَ ٱلظَّنِّ إِثۡمٞۖ وَلَا تَجَسَّسُواْ وَلَا يَغۡتَب بَّعۡضُكُم بَعۡضًاۚ أَيُحِبُّ أَحَدُكُمۡ أَن يَأۡكُلَ لَحۡمَ أَخِيهِ مَيۡتٗا فَكَرِهۡتُمُوهُۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ تَوَّابٞ رَّحِيمٞ ﴿12﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo ijtaniboo katheeran mina alththanni inna baAAda alththanni ithmun wala tajassasoo wala yaghtab baAAdukum baAAdan ayuhibbu ahadukum an yakula lahma akheehi maytan fakarihtumoohu waittaqoo Allaha inna Allaha tawwabun raheemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ jìnnà sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àbá dídá. Dájúdájú ẹ̀ṣẹ̀ ni apá kan àbá dídá. Ẹ má ṣe tọpinpin ara yín. Kí apá kan yín má ṣe sọ̀rọ̀ apá kan lẹ́yìn. Ṣé ọ̀kan nínú yín nífẹ̀ẹ́ sí láti jẹ ẹran-ara ọmọ ìyá rẹ̀ ní òkú? Ẹ sì kórira rẹ̀. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

49:13

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّا خَلَقۡنَٰكُم مِّن ذَكَرٖ وَأُنثَىٰ وَجَعَلۡنَٰكُمۡ شُعُوبٗا وَقَبَآئِلَ لِتَعَارَفُوٓاْۚ إِنَّ أَكۡرَمَكُمۡ عِندَ ٱللَّهِ أَتۡقَىٰكُمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٞ ﴿13﴾

Transliteration: Ya ayyuha alnnasu inna khalaqnakum min thakarin waontha wajaAAalnakum shuAAooban waqabaila litaAAarafoo inna akramakum AAinda Allahi atqakum inna Allaha AAaleemun khabeerun

Translation: Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá yín láti ara ọkùnrin àti obìnrin. A sì ṣe yín ní orílẹ̀-èdè orílẹ̀-èdè àti ìran-ìran nítorí kí ẹ lè dára yín mọ̀. Dájúdájú alápọ̀n-ọ́nlé jùlọ nínú yín lọ́dọ̀ Allāhu ni ẹni tó bẹ̀rù (Rẹ̀) jùlọ. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.

49:14

قَالَتِ ٱلۡأَعۡرَابُ ءَامَنَّاۖ قُل لَّمۡ تُؤۡمِنُواْ وَلَٰكِن قُولُوٓاْ أَسۡلَمۡنَا وَلَمَّا يَدۡخُلِ ٱلۡإِيمَٰنُ فِي قُلُوبِكُمۡۖ وَإِن تُطِيعُواْ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ لَا يَلِتۡكُم مِّنۡ أَعۡمَٰلِكُمۡ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٌ ﴿14﴾

Transliteration: Qalati alaAArabu amanna qul lam tuminoo walakin qooloo aslamna walamma yadkhuli aleemanu fee quloobikum wain tuteeAAoo Allaha warasoolahu la yalitkum min aAAmalikum shayan inna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Àwọn Lárúbáwá oko sọ pé: “A gbàgbọ́ ní òdodo.” Sọ pé: “Ẹ̀yin kò gbàgbọ́ ní òdodo.” Ṣùgbọ́n ẹ sọ pé: “A gba ’Islām.” níwọ̀n ìgbà tí ìgbàgbọ́ òdodo kò tí ì wọ’nú ọkàn yín. Tí ẹ bá tẹ̀lé (àṣẹ) Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) kò níí dín kiní kan kù fún yín nínú (ẹ̀san) àwọn iṣẹ́ yín. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

49:15

إِنَّمَا ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ ثُمَّ لَمۡ يَرۡتَابُواْ وَجَٰهَدُواْ بِأَمۡوَٰلِهِمۡ وَأَنفُسِهِمۡ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلصَّـٰدِقُونَ ﴿15﴾

Transliteration: Innama almuminoona allatheena amanoo biAllahi warasoolihi thumma lam yartaboo wajahadoo biamwalihim waanfusihim fee sabeeli Allahi olaika humu alssadiqoona

Translation: Àwọn onígbàgbọ́ òdodo ni àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà tí wọn kò ṣeyèméjì, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun fún ẹ̀sìn Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olódodo.

49:16

قُلۡ أَتُعَلِّمُونَ ٱللَّهَ بِدِينِكُمۡ وَٱللَّهُ يَعۡلَمُ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿16﴾

Transliteration: Qul atuAAallimoona Allaha bideenikum waAllahu yaAAlamu ma fee alssamawati wama fee alardi waAllahu bikulli shayin AAaleemun

Translation: Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa sọ nípa ẹ̀sìn yín fún Allāhu ni (pé ìgbàgbọ́ òdodo ti wà nínú ọkàn yín)?” Allāhu sì mọ ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

49:17

يَمُنُّونَ عَلَيۡكَ أَنۡ أَسۡلَمُواْۖ قُل لَّا تَمُنُّواْ عَلَيَّ إِسۡلَٰمَكُمۖ بَلِ ٱللَّهُ يَمُنُّ عَلَيۡكُمۡ أَنۡ هَدَىٰكُمۡ لِلۡإِيمَٰنِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿17﴾

Transliteration: Yamunnoona AAalayka an aslamoo qul la tamunnoo AAalayya islamakum bali Allahu yamunnu AAalaykum an hadakum lileemani in kuntum sadiqeena

Translation: Wọ́n ń ṣèrègún lórí rẹ pé àwọn gba ’Islām. Sọ pé: “Ẹ má fi ’Islām yín ṣèrègún lórí mi. Bí kò ṣe pé Allāhu l’Ó máa ṣèrègún lórí yín pé Ó fi yín mọ̀nà síbi ìgbàgbọ́ òdodo tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

49:18

إِنَّ ٱللَّهَ يَعۡلَمُ غَيۡبَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَٱللَّهُ بَصِيرُۢ بِمَا تَعۡمَلُونَ ﴿18﴾

Transliteration: Inna Allaha yaAAlamu ghayba alssamawati waalardi waAllahu baseerun bima taAAmaloona

Translation: Dájúdájú Allāhu mọ ìkọ̀kọ̀ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àti pé Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download