quranm◉

Hizb 17

Range
from 7:117 to 7:188
Surahs covered
Ìtumọ̀
72 Ìtumọ̀

◉

7:117

وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَلۡقِ عَصَاكَۖ فَإِذَا هِيَ تَلۡقَفُ مَا يَأۡفِكُونَ ﴿117﴾

A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā pé: “Ju ọ̀pá rẹ sílẹ̀.” Nígbà náà, ó sì ń gbé ohun tí wọ́n ti pa nírọ́ kalẹ̀ mì kálókáló.

7:118

فَوَقَعَ ٱلۡحَقُّ وَبَطَلَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿118﴾

Nítorí náà, òdodo hàn (ó sì fìdí múlẹ̀). Ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ sì bàjẹ́.

7:119

فَغُلِبُواْ هُنَالِكَ وَٱنقَلَبُواْ صَٰغِرِينَ ﴿119﴾

Nítorí náà, A borí wọn níbẹ̀ yẹn. Wọ́n sì darí wálé ní ẹni yẹpẹrẹ.

7:120

وَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سَٰجِدِينَ ﴿120﴾

Iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

7:121

قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿121﴾

Wọ́n sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa gbogbo ẹ̀dá,

7:122

رَبِّ مُوسَىٰ وَهَٰرُونَ ﴿122﴾

Olúwa (Ànábì) Mūsā àti Hārūn.”

7:123

قَالَ فِرۡعَوۡنُ ءَامَنتُم بِهِۦ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّ هَٰذَا لَمَكۡرٞ مَّكَرۡتُمُوهُ فِي ٱلۡمَدِينَةِ لِتُخۡرِجُواْ مِنۡهَآ أَهۡلَهَاۖ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ﴿123﴾

Fir‘aon wí pé: “Ẹ ti gbà Á gbọ́ ṣíwájú kí n̄g tó yọ̀ǹda fún yín! Dájúdájú èyí ni ète kan tí ẹ dá nínú ìlú nítorí kí ẹ lè kó àwọn ará ìlú jáde kúrò nínú rẹ̀. Nítorí náà, láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

7:124

لَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ ثُمَّ لَأُصَلِّبَنَّكُمۡ أَجۡمَعِينَ ﴿124﴾

Dájúdájú mo máa gé ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Lẹ́yìn náà, dájúdájú mo máa kan gbogbo yín mọ́gi.”

7:125

قَالُوٓاْ إِنَّآ إِلَىٰ رَبِّنَا مُنقَلِبُونَ ﴿125﴾

Wọ́n sọ pé: “Dájúdájú ọ̀dọ̀ Olúwa wa sì ni a máa fàbọ̀ sí.

7:126

وَمَا تَنقِمُ مِنَّآ إِلَّآ أَنۡ ءَامَنَّا بِـَٔايَٰتِ رَبِّنَا لَمَّا جَآءَتۡنَاۚ رَبَّنَآ أَفۡرِغۡ عَلَيۡنَا صَبۡرٗا وَتَوَفَّنَا مُسۡلِمِينَ ﴿126﴾

Àti pé o ò kórira kiní kan lára wa (o ò sì rí àlèébù kan lára wa) bí kò ṣe nítorí pé, a gba àwọn àmì Olúwa wa gbọ́ nígbà tí ó dé bá wa. Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu. Kí O sì pa wá sípò mùsùlùmí.”

7:127

وَقَالَ ٱلۡمَلَأُ مِن قَوۡمِ فِرۡعَوۡنَ أَتَذَرُ مُوسَىٰ وَقَوۡمَهُۥ لِيُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَيَذَرَكَ وَءَالِهَتَكَۚ قَالَ سَنُقَتِّلُ أَبۡنَآءَهُمۡ وَنَسۡتَحۡيِۦ نِسَآءَهُمۡ وَإِنَّا فَوۡقَهُمۡ قَٰهِرُونَ ﴿127﴾

Àwọn ìjòyè nínú ìjọ Fir‘aon wí pé: “Ṣé ìwọ yóò fi Mūsā àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti nítorí kí ó lè pa ìwọ àti àwọn òrìṣà rẹ tì?” (Fir‘aon) wí pé: “A óò máa pa àwọn ọmọkùnrin wọn ni. A ó sì máa dá àwọn ọmọbìnrin wọn sí. Dájúdájú àwa ni alágbára lórí wọn.”

7:128

قَالَ مُوسَىٰ لِقَوۡمِهِ ٱسۡتَعِينُواْ بِٱللَّهِ وَٱصۡبِرُوٓاْۖ إِنَّ ٱلۡأَرۡضَ لِلَّهِ يُورِثُهَا مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۖ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلۡمُتَّقِينَ ﴿128﴾

(Ànábì) Mūsā sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ fi Allāhu wá ìrànlọ́wọ́, kí ẹ sì ṣe sùúrù. Dájúdájú ti Allāhu ni ilẹ̀. Ó sì ń jogún rẹ̀ fún ẹni tó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Ìgbẹ̀yìn (rere) sì wà fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).”

7:129

قَالُوٓاْ أُوذِينَا مِن قَبۡلِ أَن تَأۡتِيَنَا وَمِنۢ بَعۡدِ مَا جِئۡتَنَاۚ قَالَ عَسَىٰ رَبُّكُمۡ أَن يُهۡلِكَ عَدُوَّكُمۡ وَيَسۡتَخۡلِفَكُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ فَيَنظُرَ كَيۡفَ تَعۡمَلُونَ ﴿129﴾

Wọ́n sọ pé: “Wọ́n ni wá lára ṣíwájú kí o tó wá bá wa àti lẹ́yìn tí o dé bá wa.” (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò pa àwọn ọ̀tá yín run. Ó sì máa fi yín rọ́pò (wọn) lórí ilẹ̀. Nígbà náà, (Allāhu) yó sì wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.”

7:130

وَلَقَدۡ أَخَذۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ بِٱلسِّنِينَ وَنَقۡصٖ مِّنَ ٱلثَّمَرَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَذَّكَّرُونَ ﴿130﴾

Dájúdájú A gbá ènìyàn Fir‘aon mú pẹ̀lú ọ̀dá òjò àti àdínkù tó bá àwọn èso nítorí kí wọ́n lè lo ìrántí.

7:131

فَإِذَا جَآءَتۡهُمُ ٱلۡحَسَنَةُ قَالُواْ لَنَا هَٰذِهِۦۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَطَّيَّرُواْ بِمُوسَىٰ وَمَن مَّعَهُۥٓۗ أَلَآ إِنَّمَا طَـٰٓئِرُهُمۡ عِندَ ٱللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿131﴾

Nígbà tí ohun rere bá dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Tiwa ni èyí.” Tí aburú kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á ṣàfitì aburú náà sọ́dọ̀ (Ànábì) Mūsā àti ẹni tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Kíyè sí i, àmì aburú wọn kúkú wà (nínú kádàrá wọn) lọ́dọ̀ Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò nímọ̀.

7:132

وَقَالُواْ مَهۡمَا تَأۡتِنَا بِهِۦ مِنۡ ءَايَةٖ لِّتَسۡحَرَنَا بِهَا فَمَا نَحۡنُ لَكَ بِمُؤۡمِنِينَ ﴿132﴾

Wọ́n sì wí pé: “Ohunkóhun tí o bá mú wá fún wa ní àmì láti fi pidán fún wa, àwa kò níí gbà ọ́ gbọ́.”

7:133

فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلطُّوفَانَ وَٱلۡجَرَادَ وَٱلۡقُمَّلَ وَٱلضَّفَادِعَ وَٱلدَّمَ ءَايَٰتٖ مُّفَصَّلَٰتٖ فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ ﴿133﴾

Nítorí náà, A sì fi ẹ̀kún omi, àwọn eṣú, àwọn kòkòrò iná, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àti ẹ̀jẹ̀ ránṣẹ́ sí wọn ní àwọn àmì tí ń tẹ̀léra wọn tó fojú hàn. Ńṣe ni wọ́n tún ṣègbéraga; wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

7:134

وَلَمَّا وَقَعَ عَلَيۡهِمُ ٱلرِّجۡزُ قَالُواْ يَٰمُوسَى ٱدۡعُ لَنَا رَبَّكَ بِمَا عَهِدَ عِندَكَۖ لَئِن كَشَفۡتَ عَنَّا ٱلرِّجۡزَ لَنُؤۡمِنَنَّ لَكَ وَلَنُرۡسِلَنَّ مَعَكَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ﴿134﴾

Nígbà tí ìyà sọ̀kalẹ̀ lé wọn lórí, wọ́n wí pé: “Mūsā, pe Olúwa rẹ fún wa nítorí àdéhùn tí Ó ṣe fún ọ. Dájúdájú tí o bá fi lè gbé ìyà náà kúrò fún wa (pẹ̀lú àdúà rẹ), dájúdájú a máa gbà ọ́ gbọ́, dájúdájú a sì máa jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá ọ lọ.”

7:135

فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُمُ ٱلرِّجۡزَ إِلَىٰٓ أَجَلٍ هُم بَٰلِغُوهُ إِذَا هُمۡ يَنكُثُونَ ﴿135﴾

Nígbà tí A bá gbé ìyà náà kúrò fún wọn fún àkókò kan tí wọn yóò lò (nínú ìṣẹ̀mí wọn), nígbà náà ni wọ́n tún ń yẹ àdéhùn.

7:136

فَٱنتَقَمۡنَا مِنۡهُمۡ فَأَغۡرَقۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡيَمِّ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ ﴿136﴾

Nítorí náà, A gbẹ̀san lára wọn, A sì tẹ̀ wọ́n rì sínú agbami odò nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́. Wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.

7:137

وَأَوۡرَثۡنَا ٱلۡقَوۡمَ ٱلَّذِينَ كَانُواْ يُسۡتَضۡعَفُونَ مَشَٰرِقَ ٱلۡأَرۡضِ وَمَغَٰرِبَهَا ٱلَّتِي بَٰرَكۡنَا فِيهَاۖ وَتَمَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ ٱلۡحُسۡنَىٰ عَلَىٰ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ بِمَا صَبَرُواْۖ وَدَمَّرۡنَا مَا كَانَ يَصۡنَعُ فِرۡعَوۡنُ وَقَوۡمُهُۥ وَمَا كَانُواْ يَعۡرِشُونَ ﴿137﴾

A sì jogún àwọn ibùyọ òòrùn lórí ilẹ̀ ayé àti ibùwọ̀ òòrùn rẹ̀, tí A fi ìbùnkún sí, fún àwọn ènìyàn tí wọ́n kà sí ọ̀lẹ. Ọ̀rọ̀ Olúwa Rẹ tó dára sì ṣẹ lórí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl nítorí pé, wọ́n ṣe sùúrù. A sì pa ohun tí Fir‘aon àti ìjọ rẹ̀ ń ṣe níṣẹ́ àti ohun tí wọ́n ń kọ́ nílé run.

7:138

وَجَٰوَزۡنَا بِبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱلۡبَحۡرَ فَأَتَوۡاْ عَلَىٰ قَوۡمٖ يَعۡكُفُونَ عَلَىٰٓ أَصۡنَامٖ لَّهُمۡۚ قَالُواْ يَٰمُوسَى ٱجۡعَل لَّنَآ إِلَٰهٗا كَمَا لَهُمۡ ءَالِهَةٞۚ قَالَ إِنَّكُمۡ قَوۡمٞ تَجۡهَلُونَ ﴿138﴾

A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄‘īl la agbami òkun kọjá. Nígbà náà, wọ́n kọjá lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn kan tí wọ́n dúró ti àwọn òrìṣà wọn. Wọ́n sì wí pé: “Mūsā, ṣe òrìṣà kan fún wa, gẹ́gẹ́ bí àwọn (wọ̀nyí) ṣe ní àwọn òrìṣà kan.” (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Dájúdájú ẹ̀yin ni ìjọ aláìmọ̀kan.1

7:139

إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ مُتَبَّرٞ مَّا هُمۡ فِيهِ وَبَٰطِلٞ مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿139﴾

Dájúdájú àwọn wọ̀nyí, ohun tí wọ́n ń ṣe (yìí) máa parun. Ohun tí wọ́n ń ṣe sì máa di òfo.”

7:140

قَالَ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَبۡغِيكُمۡ إِلَٰهٗا وَهُوَ فَضَّلَكُمۡ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿140﴾

(Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ṣé kí èmi tún ba yín wá ọlọ́hun kan tí ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu ni? Òun l’Ó sì ṣe àjùlọ oore fún yín lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò yín).

7:141

وَإِذۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ ءَالِ فِرۡعَوۡنَ يَسُومُونَكُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ يُقَتِّلُونَ أَبۡنَآءَكُمۡ وَيَسۡتَحۡيُونَ نِسَآءَكُمۡۚ وَفِي ذَٰلِكُم بَلَآءٞ مِّن رَّبِّكُمۡ عَظِيمٞ ﴿141﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A là yín lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Fir‘aon tí wọ́n ń fi ìyà burúkú jẹ yín, wọ́n ń pa àwọn ọmọkùnrin yín tààrà, wọ́n sì ń dá àwọn ọmọbìnrin yín sí. Àdánwò ńlá wà nínú ìyẹn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín.”

7:142

وَوَٰعَدۡنَا مُوسَىٰ ثَلَٰثِينَ لَيۡلَةٗ وَأَتۡمَمۡنَٰهَا بِعَشۡرٖ فَتَمَّ مِيقَٰتُ رَبِّهِۦٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗۚ وَقَالَ مُوسَىٰ لِأَخِيهِ هَٰرُونَ ٱخۡلُفۡنِي فِي قَوۡمِي وَأَصۡلِحۡ وَلَا تَتَّبِعۡ سَبِيلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴿142﴾

Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀(dá fún un fún ìbánisọ̀rọ̀) pé ní òru ogójì.(Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀ Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”

7:143

وَلَمَّا جَآءَ مُوسَىٰ لِمِيقَٰتِنَا وَكَلَّمَهُۥ رَبُّهُۥ قَالَ رَبِّ أَرِنِيٓ أَنظُرۡ إِلَيۡكَۚ قَالَ لَن تَرَىٰنِي وَلَٰكِنِ ٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡجَبَلِ فَإِنِ ٱسۡتَقَرَّ مَكَانَهُۥ فَسَوۡفَ تَرَىٰنِيۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُۥ لِلۡجَبَلِ جَعَلَهُۥ دَكّٗا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقٗاۚ فَلَمَّآ أَفَاقَ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿143﴾

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un (fún ìbánisọ̀rọ̀ náà), Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀.(Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó jí, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi.)2

7:144

قَالَ يَٰمُوسَىٰٓ إِنِّي ٱصۡطَفَيۡتُكَ عَلَى ٱلنَّاسِ بِرِسَٰلَٰتِي وَبِكَلَٰمِي فَخُذۡ مَآ ءَاتَيۡتُكَ وَكُن مِّنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ ﴿144﴾

(Allāhu) sọ pé: “Mūsā, dájúdájú Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà lórí àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ Mi àti ọ̀rọ̀ Mi.Nítorí náà, gbá ohun tí Mo fún ọ mú. Kí o sì wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

7:145

وَكَتَبۡنَا لَهُۥ فِي ٱلۡأَلۡوَاحِ مِن كُلِّ شَيۡءٖ مَّوۡعِظَةٗ وَتَفۡصِيلٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ فَخُذۡهَا بِقُوَّةٖ وَأۡمُرۡ قَوۡمَكَ يَأۡخُذُواْ بِأَحۡسَنِهَاۚ سَأُوْرِيكُمۡ دَارَ ٱلۡفَٰسِقِينَ ﴿145﴾

A sì kọ gbogbo n̄ǹkan fún un sínú àwọn wàláà. (Ó jẹ́) wáàsí àti àlàyé ọ̀rọ̀ fún gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣàmúlò rẹ̀ dáradára. Kí o sì pa ìjọ rẹ láṣẹ pé kí wọ́n ṣàmúlò n̄ǹkan dáadáa tó ń bẹ nínú rẹ̀. Èmi yóò fi ilé àwọn arúfin hàn yín.1

7:146

سَأَصۡرِفُ عَنۡ ءَايَٰتِيَ ٱلَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّ وَإِن يَرَوۡاْ كُلَّ ءَايَةٖ لَّا يُؤۡمِنُواْ بِهَا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلرُّشۡدِ لَا يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗا وَإِن يَرَوۡاْ سَبِيلَ ٱلۡغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلٗاۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَكَانُواْ عَنۡهَا غَٰفِلِينَ ﴿146﴾

Èmi yóò ṣẹ́rí àwọn tó ń ṣègbéraga lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́ kúrò níbi àwọn āyahMi; tí wọ́n bá rí gbogbo āyah, wọn kò níí gbà á gbọ́. Tí wọ́n bá rí ọ̀nà ìmọ̀nà, wọn kò níí mú un ní ọ̀nà. Tí wọ́n bá sì rí ọ̀nà ìṣìnà, wọn yóò mú un ní ọ̀nà. Ìyẹn nítorí pé, wọ́n pe àwọn āyah Wa nírọ́; wọ́n sì jẹ́ afọ́núfọ́ra nípa rẹ̀.

7:147

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَلِقَآءِ ٱلۡأٓخِرَةِ حَبِطَتۡ أَعۡمَٰلُهُمۡۚ هَلۡ يُجۡزَوۡنَ إِلَّا مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿147﴾

Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa àti ìpàdé Ọjọ́ Ìkẹ́yìn ní irọ́, àwọn iṣẹ́ wọn ti bàjẹ́. Ṣé A óò san wọ́n ní ẹ̀san kan ni bí kò ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́?

7:148

وَٱتَّخَذَ قَوۡمُ مُوسَىٰ مِنۢ بَعۡدِهِۦ مِنۡ حُلِيِّهِمۡ عِجۡلٗا جَسَدٗا لَّهُۥ خُوَارٌۚ أَلَمۡ يَرَوۡاْ أَنَّهُۥ لَا يُكَلِّمُهُمۡ وَلَا يَهۡدِيهِمۡ سَبِيلًاۘ ٱتَّخَذُوهُ وَكَانُواْ ظَٰلِمِينَ ﴿148﴾

Àwọn ènìyàn (Ànábì) Mūsā, lẹ́yìn rẹ̀ (nígbà tí ó fi lọ bá Allāhu sọ̀rọ̀), wọ́n mú nínú ọ̀ṣọ́ wọn (láti fi ṣe) ère ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi, ó sì ń dún (bíi màálù). Ṣé wọn kò wòye sí i pé dájúdájú kò lè bá wọn sọ̀rọ̀ ni, kò sì lè fi ọ̀nà mọ̀ wọ́n? Wọ́n sì sọ ọ́ di àkúnlẹ̀bọ. Wọ́n sì jẹ́ alábòsí.

7:149

وَلَمَّا سُقِطَ فِيٓ أَيۡدِيهِمۡ وَرَأَوۡاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ ضَلُّواْ قَالُواْ لَئِن لَّمۡ يَرۡحَمۡنَا رَبُّنَا وَيَغۡفِرۡ لَنَا لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿149﴾

Nígbà tí ó di àbámọ̀ mọ́ wọn lọ́wọ́ tán, wọ́n rí i pé àwọn ti ṣìnà, wọ́n wí pé: “Tí Olúwa wa kò bá ṣàánú wa, kí Ó sì foríjìn wá, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn ẹni òfò.”

7:150

وَلَمَّا رَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗا قَالَ بِئۡسَمَا خَلَفۡتُمُونِي مِنۢ بَعۡدِيٓۖ أَعَجِلۡتُمۡ أَمۡرَ رَبِّكُمۡۖ وَأَلۡقَى ٱلۡأَلۡوَاحَ وَأَخَذَ بِرَأۡسِ أَخِيهِ يَجُرُّهُۥٓ إِلَيۡهِۚ قَالَ ٱبۡنَ أُمَّ إِنَّ ٱلۡقَوۡمَ ٱسۡتَضۡعَفُونِي وَكَادُواْ يَقۡتُلُونَنِي فَلَا تُشۡمِتۡ بِيَ ٱلۡأَعۡدَآءَ وَلَا تَجۡعَلۡنِي مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿150﴾

Nígbà tí (Ànábì) Mūsā sì padà sí ọ̀dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́, ó sọ pé: “Ohun tí ẹ fi rólé dè mí lẹ́yìn mi burú. Ṣé ẹ ti kánjú pa àṣẹ Olúwa yín tì ni?” Ó sì ju àwọn wàláà sílẹ̀, ó gbá orí arákùnrin rẹ̀ mú, ó sì ń wọ́ ọ mọ́ra. (Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi ò, dájúdájú àwọn ènìyàn ni wọ́n fojú kéré mi, wọ́n sì fẹ́ẹ̀ pa mí. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá yọ̀ mí. Má sì ṣe mú mi mọ́ ìjọ alábòsí.”

7:151

قَالَ رَبِّ ٱغۡفِرۡ لِي وَلِأَخِي وَأَدۡخِلۡنَا فِي رَحۡمَتِكَۖ وَأَنتَ أَرۡحَمُ ٱلرَّـٰحِمِينَ ﴿151﴾

(Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, foríjin èmi àti arákùnrin mi. Kí O sì fi wá sínú ìkẹ́ Rẹ. Ìwọ sì ni Aláàánú-jùlọ nínú àwọn aláàánú.”

7:152

إِنَّ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ ٱلۡعِجۡلَ سَيَنَالُهُمۡ غَضَبٞ مِّن رَّبِّهِمۡ وَذِلَّةٞ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُفۡتَرِينَ ﴿152﴾

Dájúdájú àwọn tó sọ (ère) ọmọ màálù di àkúnlẹ̀bọ, ìbínú láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn àti ìyẹpẹrẹ yóò bá wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé yìí. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn aládapa irọ́ ní ẹ̀san.

7:153

وَٱلَّذِينَ عَمِلُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ ثُمَّ تَابُواْ مِنۢ بَعۡدِهَا وَءَامَنُوٓاْ إِنَّ رَبَّكَ مِنۢ بَعۡدِهَا لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿153﴾

Àwọn tó sì ṣe àwọn iṣẹ́ aburú, lẹ́yìn náà tí wọ́n ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí wọ́n sì gbàgbọ́ ní òdodo, dájúdájú lẹ́yìn èyí Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

7:154

وَلَمَّا سَكَتَ عَن مُّوسَى ٱلۡغَضَبُ أَخَذَ ٱلۡأَلۡوَاحَۖ وَفِي نُسۡخَتِهَا هُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّلَّذِينَ هُمۡ لِرَبِّهِمۡ يَرۡهَبُونَ ﴿154﴾

Nígbà tí ìbínú (Ànábì) Mūsā sì wálẹ̀, ó mú àwọn wàláà náà. Ìmọ̀nà àti àánú ń bẹ nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún àwọn tó ń bẹ̀rù Olúwa wọn.

7:155

وَٱخۡتَارَ مُوسَىٰ قَوۡمَهُۥ سَبۡعِينَ رَجُلٗا لِّمِيقَٰتِنَاۖ فَلَمَّآ أَخَذَتۡهُمُ ٱلرَّجۡفَةُ قَالَ رَبِّ لَوۡ شِئۡتَ أَهۡلَكۡتَهُم مِّن قَبۡلُ وَإِيَّـٰيَۖ أَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلسُّفَهَآءُ مِنَّآۖ إِنۡ هِيَ إِلَّا فِتۡنَتُكَ تُضِلُّ بِهَا مَن تَشَآءُ وَتَهۡدِي مَن تَشَآءُۖ أَنتَ وَلِيُّنَا فَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَاۖ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡغَٰفِرِينَ ﴿155﴾

(Ànábì) Mūsā sì yan àádọ́rin ọkùnrin nínú ìjọ rẹ̀ fún àkókò tí A fún un (láti wá tọrọ àforíjìn fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ibi àpáta Sīnā’), ohùn igbe líle tó mi ilẹ̀ tìtì sì gbá wọn mú, ó sọ pé: “Olúwa mi, tí O bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ ìbá ti pa àwọn àti èmi rẹ́ ṣíwájú (kí á tó wá síbí); ṣé Ìwọ yóò pa wá rẹ́ nítorí ohun tí àwọn òmùgọ̀ nínú wa ṣe ni? Kí ni ohun (tí wọ́n ṣe) bí kò ṣe àdánwò Rẹ; Ò ń fi ṣi ẹni tí O bá fẹ́ lọ́nà, O sì ń tọ́ ẹni tí O bá fẹ́ sọ́nà. Ìwọ ni Aláàbò wa. Nítorí náà, foríjìn wá, kí O sì kẹ́ wa. Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn aláforíjìn.

7:156

وَٱكۡتُبۡ لَنَا فِي هَٰذِهِ ٱلدُّنۡيَا حَسَنَةٗ وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِ إِنَّا هُدۡنَآ إِلَيۡكَۚ قَالَ عَذَابِيٓ أُصِيبُ بِهِۦ مَنۡ أَشَآءُۖ وَرَحۡمَتِي وَسِعَتۡ كُلَّ شَيۡءٖۚ فَسَأَكۡتُبُهَا لِلَّذِينَ يَتَّقُونَ وَيُؤۡتُونَ ٱلزَّكَوٰةَ وَٱلَّذِينَ هُم بِـَٔايَٰتِنَا يُؤۡمِنُونَ ﴿156﴾

Kí O sì kọ àkọsílẹ̀ rere fún wa ní ayé yìí àti ní ọ̀run. Dájúdájú àwa ṣẹ́rí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìyà Mi, Mo ń fi jẹ ẹni tí Mo bá fẹ́. Àti pé ìkẹ́ Mi gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Èmi yó sì kọ (ìkẹ́ Mi) mọ́ àwọn tó ń bẹ̀rù (Mi), tí wọ́n sì ń yọ Zakāh àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú àwọn āyah Wa.”

7:157

ٱلَّذِينَ يَتَّبِعُونَ ٱلرَّسُولَ ٱلنَّبِيَّ ٱلۡأُمِّيَّ ٱلَّذِي يَجِدُونَهُۥ مَكۡتُوبًا عِندَهُمۡ فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِ وَٱلۡإِنجِيلِ يَأۡمُرُهُم بِٱلۡمَعۡرُوفِ وَيَنۡهَىٰهُمۡ عَنِ ٱلۡمُنكَرِ وَيُحِلُّ لَهُمُ ٱلطَّيِّبَٰتِ وَيُحَرِّمُ عَلَيۡهِمُ ٱلۡخَبَـٰٓئِثَ وَيَضَعُ عَنۡهُمۡ إِصۡرَهُمۡ وَٱلۡأَغۡلَٰلَ ٱلَّتِي كَانَتۡ عَلَيۡهِمۡۚ فَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ بِهِۦ وَعَزَّرُوهُ وَنَصَرُوهُ وَٱتَّبَعُواْ ٱلنُّورَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ مَعَهُۥٓ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡمُفۡلِحُونَ ﴿157﴾

Àwọn tó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa ní èèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn tó wúwo) àti àjàgà tó ń bẹ lọ́rùn wọnkúrò fún wọn; àwọn tó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè.

7:158

قُلۡ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنِّي رَسُولُ ٱللَّهِ إِلَيۡكُمۡ جَمِيعًا ٱلَّذِي لَهُۥ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُۖ فَـَٔامِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِ ٱلنَّبِيِّ ٱلۡأُمِّيِّ ٱلَّذِي يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ وَكَلِمَٰتِهِۦ وَٱتَّبِعُوهُ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ﴿158﴾

Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Allāhu sí gbogbo yín pátápátá. (Allāhu) Ẹni tó ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Nítorí náà, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ẹ tẹ̀lé e nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.”

7:159

وَمِن قَوۡمِ مُوسَىٰٓ أُمَّةٞ يَهۡدُونَ بِٱلۡحَقِّ وَبِهِۦ يَعۡدِلُونَ ﴿159﴾

Ó wà nínú ìjọ (Ànábì) Mūsā, ìjọ kan tó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà. Wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.1

7:160

وَقَطَّعۡنَٰهُمُ ٱثۡنَتَيۡ عَشۡرَةَ أَسۡبَاطًا أُمَمٗاۚ وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ إِذِ ٱسۡتَسۡقَىٰهُ قَوۡمُهُۥٓ أَنِ ٱضۡرِب بِّعَصَاكَ ٱلۡحَجَرَۖ فَٱنۢبَجَسَتۡ مِنۡهُ ٱثۡنَتَا عَشۡرَةَ عَيۡنٗاۖ قَدۡ عَلِمَ كُلُّ أُنَاسٖ مَّشۡرَبَهُمۡۚ وَظَلَّلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلۡغَمَٰمَ وَأَنزَلۡنَا عَلَيۡهِمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰۖ كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡۚ وَمَا ظَلَمُونَا وَلَٰكِن كَانُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴿160﴾

A sì pín wọn sí igun méjìlá (igun kọ̀ọ̀kan sì ní) ìran àti ìjọ. A sì fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā, nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ wá omi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Fi ọ̀pá rẹ na àpáta.” (Ó ṣe bẹ́ẹ̀) orísun omi méjìlá sì ṣẹ́yọ lára rẹ̀. Àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan sì ti dá ibùmu wọn mọ̀. A tún fi ẹ̀ṣújò ṣe ibòji fún wọn. A sọ (ohun mímu) mọ́nnùàti (ohun jíjẹ) salwā2 kalẹ̀ fun wọ́n. Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pèsè fún yín. Wọn kò sì ṣe àbòsí sí Wa, ṣùgbọ́n ẹ̀mí ara wọn ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

7:161

وَإِذۡ قِيلَ لَهُمُ ٱسۡكُنُواْ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةَ وَكُلُواْ مِنۡهَا حَيۡثُ شِئۡتُمۡ وَقُولُواْ حِطَّةٞ وَٱدۡخُلُواْ ٱلۡبَابَ سُجَّدٗا نَّغۡفِرۡ لَكُمۡ خَطِيٓـَٰٔتِكُمۡۚ سَنَزِيدُ ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿161﴾

(Ẹ rántí) nígbà tí A sọ fún wọn pé: “Ẹ wọ inú ìlú yìí. Ẹ máa jẹ nínú rẹ̀ níbikíbi tí ẹ bá fẹ́. Kí ẹ sì sọ pé: ‘Ha ẹ̀ṣẹ̀ wa dànù.’ Ẹ gba ẹnu-ọ̀nà (ìlú) náà wọlé ní ìtẹríba.A máa forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. A ó sì ṣe àlékún (ẹ̀san rere) fún àwọn olùṣe-rere.”

7:162

فَبَدَّلَ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡ قَوۡلًا غَيۡرَ ٱلَّذِي قِيلَ لَهُمۡ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِجۡزٗا مِّنَ ٱلسَّمَآءِ بِمَا كَانُواْ يَظۡلِمُونَ ﴿162﴾

Àwọn tó ṣàbòsí yí ọ̀rọ̀ náà padà (sí n̄ǹkan mìíràn) yàtọ̀ sí èyí tí A sọ fún wọn. Nítorí náà, A fi ìyà ránsẹ́ sí wọn láti sánmọ̀ nítorí pé wọ́n ń ṣe àbòsí.

7:163

وَسۡـَٔلۡهُمۡ عَنِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلَّتِي كَانَتۡ حَاضِرَةَ ٱلۡبَحۡرِ إِذۡ يَعۡدُونَ فِي ٱلسَّبۡتِ إِذۡ تَأۡتِيهِمۡ حِيتَانُهُمۡ يَوۡمَ سَبۡتِهِمۡ شُرَّعٗا وَيَوۡمَ لَا يَسۡبِتُونَ لَا تَأۡتِيهِمۡۚ كَذَٰلِكَ نَبۡلُوهُم بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ ﴿163﴾

Bi wọ́n léèrè nípa ìlú tó wà ní ẹ̀bádò, nígbà tí wọ́n kọjá ẹnu-ààlà nípa ọjọ́ Sabt, nígbà tí ẹja wọn ń wá bá wọn ní ọjọ́ Sabt wọn, wọ́n sì máa léfòó sí ojú odò, ọjọ́ tí kì í bá sì ṣe ọjọ́ Sabt wọn, wọn kò níí wá bá wọn. Báyẹn ni A ṣe ń dán wọn wò nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.1

7:164

وَإِذۡ قَالَتۡ أُمَّةٞ مِّنۡهُمۡ لِمَ تَعِظُونَ قَوۡمًا ٱللَّهُ مُهۡلِكُهُمۡ أَوۡ مُعَذِّبُهُمۡ عَذَابٗا شَدِيدٗاۖ قَالُواْ مَعۡذِرَةً إِلَىٰ رَبِّكُمۡ وَلَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ ﴿164﴾

(Rántí) nígbà tí ìjọ kan nínú wọn wí pé: “Nítorí kí ni ẹ fí ń ṣe wáàsí fún ìjọ kan tí Allāhu máa parẹ́ tàbí tí Ó máa jẹ ní ìyà tó lágbára?” Wọ́n sọ pé: “(Kí ó lè jẹ́) àwáwí lọ́dọ̀ Olúwa yín àti nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu) ni.”

7:165

فَلَمَّا نَسُواْ مَا ذُكِّرُواْ بِهِۦٓ أَنجَيۡنَا ٱلَّذِينَ يَنۡهَوۡنَ عَنِ ٱلسُّوٓءِ وَأَخَذۡنَا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ بِعَذَابِۭ بَـِٔيسِۭ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ ﴿165﴾

Nígbà tí wọ́n sì gbàgbé ohun tí wọ́n fi ṣèrántí fún wọn, A gba àwọn tó ń kọ aburú là. A sì fi ìyà tó le jẹ àwọn tó ṣàbòsí nítorí pé wọ́n jẹ́ òbìlẹ̀jẹ́.

7:166

فَلَمَّا عَتَوۡاْ عَن مَّا نُهُواْ عَنۡهُ قُلۡنَا لَهُمۡ كُونُواْ قِرَدَةً خَٰسِـِٔينَ ﴿166﴾

Nígbà tí wọ́n tayọ ẹnu-ààlà níbi ohun tí A kọ̀ fún wọn, A sọ fún wọn pé: “Ẹ di ọ̀bọ, ẹni ìgbéjìnnà sí ìkẹ́.”

7:167

وَإِذۡ تَأَذَّنَ رَبُّكَ لَيَبۡعَثَنَّ عَلَيۡهِمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ مَن يَسُومُهُمۡ سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِۗ إِنَّ رَبَّكَ لَسَرِيعُ ٱلۡعِقَابِ وَإِنَّهُۥ لَغَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿167﴾

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ sọ ọ́ di mímọ̀ (fún wọn) pé dájúdájú Òun yóò gbé ẹni tí ó máa fi ìyà burúkú jẹ wọ́n dìde sí wọn títí di Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

7:168

وَقَطَّعۡنَٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ أُمَمٗاۖ مِّنۡهُمُ ٱلصَّـٰلِحُونَ وَمِنۡهُمۡ دُونَ ذَٰلِكَۖ وَبَلَوۡنَٰهُم بِٱلۡحَسَنَٰتِ وَٱلسَّيِّـَٔاتِ لَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ﴿168﴾

A dá wọn kékekèle sí orí ilẹ̀ ní ìjọ-ìjọ; àwọn ẹni rere wà nínú wọn, àwọn mìíràn tún wà nínú wọn. A sì fi àwọn ohun rere àti ohun burúkú dán wọn wò kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).

7:169

فَخَلَفَ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ خَلۡفٞ وَرِثُواْ ٱلۡكِتَٰبَ يَأۡخُذُونَ عَرَضَ هَٰذَا ٱلۡأَدۡنَىٰ وَيَقُولُونَ سَيُغۡفَرُ لَنَا وَإِن يَأۡتِهِمۡ عَرَضٞ مِّثۡلُهُۥ يَأۡخُذُوهُۚ أَلَمۡ يُؤۡخَذۡ عَلَيۡهِم مِّيثَٰقُ ٱلۡكِتَٰبِ أَن لَّا يَقُولُواْ عَلَى ٱللَّهِ إِلَّا ٱلۡحَقَّ وَدَرَسُواْ مَا فِيهِۗ وَٱلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يَتَّقُونَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿169﴾

Àwọn àrólé kan sì rólé lẹ́yìn wọn; wọ́n jogún Tírà (Taorāt àti ’Injīl), wọ́n sì ń gba (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) dúkìá ilé ayé yìí (láti kọ ìkọkúkọ sínú rẹ̀), wọ́n sì ń wí pé: “Wọn yóò foríjìn wá.” Tí (àbẹ̀tẹ́lẹ̀) dúkìá irú rẹ̀ bá tún wá bá wọn, wọ́n máa gbà á. Ṣé A kò ti bá wọn ṣe àdéhùn nínú Tírà pé, wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àfitì ọ̀rọ̀ kan sọ́dọ̀ Allāhu àfi òdodo? Wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí ń bẹ nínú rẹ̀! Ilé ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò níí ṣe làákàyè ni?

7:170

وَٱلَّذِينَ يُمَسِّكُونَ بِٱلۡكِتَٰبِ وَأَقَامُواْ ٱلصَّلَوٰةَ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجۡرَ ٱلۡمُصۡلِحِينَ ﴿170﴾

Àwọn tó sì ń mú Tírà lò dáradára, tí wọ́n ń kírun, dájúdájú Àwa kò níí fi ẹ̀san àwọn tó ń ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ wọn) ráre.1

7:171

وَإِذۡ نَتَقۡنَا ٱلۡجَبَلَ فَوۡقَهُمۡ كَأَنَّهُۥ ظُلَّةٞ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُۥ وَاقِعُۢ بِهِمۡ خُذُواْ مَآ ءَاتَيۡنَٰكُم بِقُوَّةٖ وَٱذۡكُرُواْ مَا فِيهِ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿171﴾

(Rántí) nígbà tí A gbé àpáta ga sókè orí wọn, ó sì dà bí ibòji. Wọ́n sì lérò pé ó máa wó lu àwọn mọ́lẹ̀, (A sì sọ fún wọn pé): “Ẹ gbá ohun tí A fún yín mú dáadáa, kí ẹ sì máa rántí ohun tó ń bẹ nínú rẹ̀, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).”

7:172

وَإِذۡ أَخَذَ رَبُّكَ مِنۢ بَنِيٓ ءَادَمَ مِن ظُهُورِهِمۡ ذُرِّيَّتَهُمۡ وَأَشۡهَدَهُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَلَسۡتُ بِرَبِّكُمۡۖ قَالُواْ بَلَىٰ شَهِدۡنَآۚ أَن تَقُولُواْ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ إِنَّا كُنَّا عَنۡ هَٰذَا غَٰفِلِينَ ﴿172﴾

(Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ gba àdéhùn lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ādam nínú àrọ́mọdọ́mọ wọn tó fà jáde láti (ìbàdí ní) ẹ̀yìn (bàbá ńlá) wọn, Ó sì fi wọ́n ṣe ẹlẹ́rìí lórí ara wọn pé: “Ṣé Èmi kọ́ ni Olúwa yín ni?” Wọ́n sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni – (Ìwọ ni Olúwa wa) - a jẹ́rìí sí i.” Nítorí kí ẹ má baà sọ ní Ọjọ́ Àjíǹdé pé: “Dájúdájú àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa èyí.”

7:173

أَوۡ تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أَشۡرَكَ ءَابَآؤُنَا مِن قَبۡلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةٗ مِّنۢ بَعۡدِهِمۡۖ أَفَتُهۡلِكُنَا بِمَا فَعَلَ ٱلۡمُبۡطِلُونَ ﴿173﴾

Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Àwọn bàbá wa ló kúkú bá Allāhu wá akẹgbẹ́ ṣíwájú (wa), àwa sì jẹ́ àrọ́mọdọ́mọ lẹ́yìn wọn (ni a fi wò wọ́n kọ́ṣe pẹ̀lú àìmọ̀kan). Ṣé Ìwọ yóò pa wá run nítorí ohun tí àwọn tó ń ba iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn jẹ́ṣe ni?”

7:174

وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلَعَلَّهُمۡ يَرۡجِعُونَ ﴿174﴾

Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Wa, nítorí kí wọ́n lè ṣẹ́rí padà (síbi òdodo).

7:175

وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ ٱلَّذِيٓ ءَاتَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا فَٱنسَلَخَ مِنۡهَا فَأَتۡبَعَهُ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَكَانَ مِنَ ٱلۡغَاوِينَ ﴿175﴾

Ka ìròyìn ẹni tí A fún ní àwọn āyah Wa fún wọn, tí ó yọra rẹ̀ sílẹ̀ níbi àwọn āyah náà.Nítorí náà, Èṣù tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó sì wà nínú àwọn olùṣìnà.

7:176

وَلَوۡ شِئۡنَا لَرَفَعۡنَٰهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُۥٓ أَخۡلَدَ إِلَى ٱلۡأَرۡضِ وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُۚ فَمَثَلُهُۥ كَمَثَلِ ٱلۡكَلۡبِ إِن تَحۡمِلۡ عَلَيۡهِ يَلۡهَثۡ أَوۡ تَتۡرُكۡهُ يَلۡهَثۚ ذَّـٰلِكَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۚ فَٱقۡصُصِ ٱلۡقَصَصَ لَعَلَّهُمۡ يَتَفَكَّرُونَ ﴿176﴾

Àti pé tí ó bá jẹ́ pé A bá fẹ́, Àwa ìbá fi (ìmọ̀ nípa àwọn āyah Wa) ṣàgbéga fún un. Ṣùgbọ́n ó wayé mọ́yà. Ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀. Nítorí náà, àfiwé rẹ̀ dà bí ajá. Tí o bá lé e síwájú, ó máa yọ ahọ́n síta. Tí o bá sì fi sílẹ̀, ó tún máa yọ ahọ́n síta. Ìyẹn ni àfiwé ìjọ tó pe àwọn āyah Wa nírọ́. Sọ ìtàn náà fún wọn nítorí kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀.

7:177

سَآءَ مَثَلًا ٱلۡقَوۡمُ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَأَنفُسَهُمۡ كَانُواْ يَظۡلِمُونَ ﴿177﴾

Ìjọ tí ó pe àwọn āyah Wa nírọ́, wọ́n burú ní àfiwé. Ara wọn sì ni wọ́n ń ṣàbòsí sí.

7:178

مَن يَهۡدِ ٱللَّهُ فَهُوَ ٱلۡمُهۡتَدِيۖ وَمَن يُضۡلِلۡ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡخَٰسِرُونَ ﴿178﴾

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi mọ̀nà (’Islām), òun ni olùmọ̀nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì ṣì lọ́nà, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni ẹni òfò.

7:179

وَلَقَدۡ ذَرَأۡنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِۖ لَهُمۡ قُلُوبٞ لَّا يَفۡقَهُونَ بِهَا وَلَهُمۡ أَعۡيُنٞ لَّا يُبۡصِرُونَ بِهَا وَلَهُمۡ ءَاذَانٞ لَّا يَسۡمَعُونَ بِهَآۚ أُوْلَـٰٓئِكَ كَٱلۡأَنۡعَٰمِ بَلۡ هُمۡ أَضَلُّۚ أُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡغَٰفِلُونَ ﴿179﴾

Dájúdájú A ti dá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn àti àlùjànnú fún iná Jahanamọ (nítorí pé) wọ́n ní ọkàn, wọn kò sì fi gbọ́ àgbọ́yé; wọ́n ní ojú, wọn kò sì fi ríran; wọ́n ní etí, wọn kò sì fi gbọ́ràn. Àwọn wọ̀nyẹn dà bí ẹran-ọ̀sìn. Wọ́n wulẹ̀ sọnù jùlọ. Àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni afọ́nú-fọ́ra.

7:180

وَلِلَّهِ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ فَٱدۡعُوهُ بِهَاۖ وَذَرُواْ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ أَسۡمَـٰٓئِهِۦۚ سَيُجۡزَوۡنَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿180﴾

Ti Allāhu ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Nítorí náà, ẹ fi pè É. Kí ẹ sì pa àwọn tó ń darí àwọn orúkọ Rẹ̀ kọ ọ̀nà òdì tì.A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

7:181

وَمِمَّنۡ خَلَقۡنَآ أُمَّةٞ يَهۡدُونَ بِٱلۡحَقِّ وَبِهِۦ يَعۡدِلُونَ ﴿181﴾

Ó wà nínú àwọn tí A dá, ìjọ kan tó ń fi òdodo tọ́ (àwọn ènìyàn) sọ́nà, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

7:182

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا سَنَسۡتَدۡرِجُهُم مِّنۡ حَيۡثُ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿182﴾

Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, A óò máa dẹ wọ́n lẹ́kẹ láti jẹ wọ́n níyà ní àyè tí wọn kò níí mọ̀.

7:183

وَأُمۡلِي لَهُمۡۚ إِنَّ كَيۡدِي مَتِينٌ ﴿183﴾

Èmi yóò lọ́ wọn lára. Dájúdájú ète Mi lágbára.1

7:184

أَوَلَمۡ يَتَفَكَّرُواْۗ مَا بِصَاحِبِهِم مِّن جِنَّةٍۚ إِنۡ هُوَ إِلَّا نَذِيرٞ مُّبِينٌ ﴿184﴾

Ṣé wọn kò ronú jinlẹ̀ ni? Kò sí wèrè kan kan lára ẹni wọn (Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a -. Ta sì ni bí kò ṣe olùkìlọ̀ pọ́nńbélé.

7:185

أَوَلَمۡ يَنظُرُواْ فِي مَلَكُوتِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ مِن شَيۡءٖ وَأَنۡ عَسَىٰٓ أَن يَكُونَ قَدِ ٱقۡتَرَبَ أَجَلُهُمۡۖ فَبِأَيِّ حَدِيثِۭ بَعۡدَهُۥ يُؤۡمِنُونَ ﴿185﴾

Ṣé wọn kò wo ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú gbogbo n̄ǹkan tí Allāhu dá? Àmọ́ sá ó lè jẹ́ pé Àkókò ikú wọn ti súnmọ́. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ wo ni wọn yóò gbàgbọ́ lẹ́yìn rẹ̀?1

7:186

مَن يُضۡلِلِ ٱللَّهُ فَلَا هَادِيَ لَهُۥۚ وَيَذَرُهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ﴿186﴾

Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá ṣì lọ́nà kò lè sí afinimọ̀nà kan fún un. (Allāhu) yó sì fi wọ́n sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.

7:187

يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَاۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ رَبِّيۖ لَا يُجَلِّيهَا لِوَقۡتِهَآ إِلَّا هُوَۚ ثَقُلَتۡ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ لَا تَأۡتِيكُمۡ إِلَّا بَغۡتَةٗۗ يَسۡـَٔلُونَكَ كَأَنَّكَ حَفِيٌّ عَنۡهَاۖ قُلۡ إِنَّمَا عِلۡمُهَا عِندَ ٱللَّهِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَ ٱلنَّاسِ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿187﴾

Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé ìgbà wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà. Kò sí ẹni tó lè ṣàfi hàn Àkókò rẹ̀ àfi Òun. Ó ṣòro (láti mọ̀) fún àwọn ará sánmọ̀ àti ará ilẹ̀. Kò níí dé ba yín àfi lójijì.” Wọ́n tún ń bi ọ́ léèrè bí ẹni pé ìwọ nímọ̀ nípa rẹ̀. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Olúwa mi nìkan ni ìmọ̀ rẹ̀ wà, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni kò mọ̀.”

7:188

قُل لَّآ أَمۡلِكُ لِنَفۡسِي نَفۡعٗا وَلَا ضَرًّا إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ وَلَوۡ كُنتُ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ لَٱسۡتَكۡثَرۡتُ مِنَ ٱلۡخَيۡرِ وَمَا مَسَّنِيَ ٱلسُّوٓءُۚ إِنۡ أَنَا۠ إِلَّا نَذِيرٞ وَبَشِيرٞ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ ﴿188﴾

Sọ pé: “Èmi kò ní agbára àǹfààní tàbí ìnira kan tí mo lè fi kan ara mi àyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Tí ó bá jẹ́ pé mo ní ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ ni, èmi ìbá ti kó ohun púpọ̀ jọ nínú oore ayé (sí ọ̀dọ̀ mi) àti pé aburú ayé ìbá tí kàn mí. Ta ni èmi bí kò ṣe olùkìlọ̀ àti oníròó ìdùnnú fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.”