quranm◉

Ojúewé 28

Range
from 2:182 to 2:186
Surahs covered
Ìtumọ̀
5 Ìtumọ̀

◉

2:182

فَمَنۡ خَافَ مِن مُّوصٖ جَنَفًا أَوۡ إِثۡمٗا فَأَصۡلَحَ بَيۡنَهُمۡ فَلَآ إِثۡمَ عَلَيۡهِۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿182﴾

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá páyà àìṣe déédé tàbí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó sọ àsọọ́lẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe láààrin (àwọn tí ogún tọ́ sí), nítorí náà, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún un. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

2:183

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ كُتِبَ عَلَيۡكُمُ ٱلصِّيَامُ كَمَا كُتِبَ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿183﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, A ṣe ààwẹ̀ náà ní ọ̀ran-anyàn fún yín, gẹ́gẹ́ bí A ti ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún àwọn tó ṣíwájú yín, nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Allāhu).

2:184

أَيَّامٗا مَّعۡدُودَٰتٖۚ فَمَن كَانَ مِنكُم مَّرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۚ وَعَلَى ٱلَّذِينَ يُطِيقُونَهُۥ فِدۡيَةٞ طَعَامُ مِسۡكِينٖۖ فَمَن تَطَوَّعَ خَيۡرٗا فَهُوَ خَيۡرٞ لَّهُۥۚ وَأَن تَصُومُواْ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿184﴾

(Ẹ gba ààwẹ̀ náà) fún àwọn ọjọ́ tí ó ní òǹkà. (Ṣùgbọ́n) ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá jẹ́ aláìsàn, tàbí ó wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Àti pé ìtánràn (ìyẹn) fífún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ l’ó di dandan fún àwọn tó máa fi ìnira gba ààwẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fínnúfíndọ̀ ṣe (àlékún) iṣẹ́ olóore, ó kúkú lóore jùlọ fún un. Àti pé kí ẹ gba ààwẹ̀ lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.1

2:185

شَهۡرُ رَمَضَانَ ٱلَّذِيٓ أُنزِلَ فِيهِ ٱلۡقُرۡءَانُ هُدٗى لِّلنَّاسِ وَبَيِّنَٰتٖ مِّنَ ٱلۡهُدَىٰ وَٱلۡفُرۡقَانِۚ فَمَن شَهِدَ مِنكُمُ ٱلشَّهۡرَ فَلۡيَصُمۡهُۖ وَمَن كَانَ مَرِيضًا أَوۡ عَلَىٰ سَفَرٖ فَعِدَّةٞ مِّنۡ أَيَّامٍ أُخَرَۗ يُرِيدُ ٱللَّهُ بِكُمُ ٱلۡيُسۡرَ وَلَا يُرِيدُ بِكُمُ ٱلۡعُسۡرَ وَلِتُكۡمِلُواْ ٱلۡعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُواْ ٱللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَىٰكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿185﴾

Oṣù Rọmọdọ̄n èyí tí A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ nínú rẹ̀(tí ó jẹ́) ìmọ̀nà, àwọn àlàyé pọ́nńbélé nípa ìmọ̀nà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà2 fún àwọn ènìyàn; nítorí náà, ẹnikẹ́ni nínú yín tí oṣù náà bá bá láyé (nínú ìlú rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà ara),3 kí ó gba ààwẹ̀ oṣù náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ aláìsàn tàbí tí ó bá wà lórí ìrìn-àjò, (ó máa san) òǹkà ọjọ́ (gbèsè ààwẹ̀ rẹ̀) nínú àwọn ọjọ́ mìíràn. Allāhu fẹ́ ìrọ̀rùn fún yín, kò sì fẹ́ ìnira fún yín. Ẹ parí òǹkà ọjọ́ (ààwẹ̀ náà), kí ẹ sì gbé títóbi fún Allāhu nítorí pé, Ó fi ọ̀nà mọ̀ yín àti nítorí kí ẹ lè dúpẹ́ fún Un.

2:186

وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌۖ أُجِيبُ دَعۡوَةَ ٱلدَّاعِ إِذَا دَعَانِۖ فَلۡيَسۡتَجِيبُواْ لِي وَلۡيُؤۡمِنُواْ بِي لَعَلَّهُمۡ يَرۡشُدُونَ ﴿186﴾

Nígbà tí àwọn ẹrúsìn Mi bá bi ọ́ léèrè nípa Mi, dájúdájú Èmi ni Olùsúnmọ́. Èmi yóò jẹ́pè àdúà aládùúà nígbà tí ó bá pè Mí. Nítorí náà, kí wọ́n jẹ́’pè Mi (nípa ìtẹ̀lé àṣẹ Mi). Kí wọ́n sì gbà Mí gbọ́ nítorí kí wọ́n lè mọ̀nà (gbígbà àdúà).