quranm◉

Ojúewé 36

Range
from 2:225 to 2:230
Surahs covered
Ìtumọ̀
6 Ìtumọ̀

◉

2:225

لَّا يُؤَاخِذُكُمُ ٱللَّهُ بِٱللَّغۡوِ فِيٓ أَيۡمَٰنِكُمۡ وَلَٰكِن يُؤَاخِذُكُم بِمَا كَسَبَتۡ قُلُوبُكُمۡۗ وَٱللَّهُ غَفُورٌ حَلِيمٞ ﴿225﴾

Allāhu kò níí fi ìbúra yín tí kò ti inú yín wá bi yín, ṣùgbọ́n Ó máa fi ohun tí ó bá ti inú ọkàn yín wá bi yín. Allāhu ni Aláforíjìn, Aláfaradà.

2:226

لِّلَّذِينَ يُؤۡلُونَ مِن نِّسَآئِهِمۡ تَرَبُّصُ أَرۡبَعَةِ أَشۡهُرٖۖ فَإِن فَآءُو فَإِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿226﴾

Ìkóraró fún oṣù mẹ́rin wà fún àwọn tó búra pé àwọn kò níí súnmọ́ obìnrin wọn. Tí wọ́n bá ṣẹ́rí padà (láààrin ìgbà náà), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.1

2:227

وَإِنۡ عَزَمُواْ ٱلطَّلَٰقَ فَإِنَّ ٱللَّهَ سَمِيعٌ عَلِيمٞ ﴿227﴾

Tí wọ́n bá sì pinnu ìkọ̀sílẹ̀, (kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

2:228

وَٱلۡمُطَلَّقَٰتُ يَتَرَبَّصۡنَ بِأَنفُسِهِنَّ ثَلَٰثَةَ قُرُوٓءٖۚ وَلَا يَحِلُّ لَهُنَّ أَن يَكۡتُمۡنَ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِيٓ أَرۡحَامِهِنَّ إِن كُنَّ يُؤۡمِنَّ بِٱللَّهِ وَٱلۡيَوۡمِ ٱلۡأٓخِرِۚ وَبُعُولَتُهُنَّ أَحَقُّ بِرَدِّهِنَّ فِي ذَٰلِكَ إِنۡ أَرَادُوٓاْ إِصۡلَٰحٗاۚ وَلَهُنَّ مِثۡلُ ٱلَّذِي عَلَيۡهِنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ وَلِلرِّجَالِ عَلَيۡهِنَّ دَرَجَةٞۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ ﴿228﴾

Àwọn obìnrin tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ máa kóraró fún héélà mẹ́ta.Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún wọn láti fi ohun tí Allāhu ṣ’ẹ̀dá (rẹ̀) sí inú àpò-ọmọ wọn pamọ́, tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Àwọn ọkọ wọn ní ẹ̀tọ́ sí dídá wọn padà láààrin (àsìkò) yẹn, tí wọ́n bá gbèrò àtúnṣe. Àwọn ìyàwó ní ẹ̀tọ́ l’ọ́dọ̀ ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí àwọn ọkọ wọn ní l’ọ́dọ̀ wọn lọ́nà tó dára. Ipò àjùlọ tún wà fún àwọn ọkùnrin lórí wọn.2 Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

2:229

ٱلطَّلَٰقُ مَرَّتَانِۖ فَإِمۡسَاكُۢ بِمَعۡرُوفٍ أَوۡ تَسۡرِيحُۢ بِإِحۡسَٰنٖۗ وَلَا يَحِلُّ لَكُمۡ أَن تَأۡخُذُواْ مِمَّآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ شَيۡـًٔا إِلَّآ أَن يَخَافَآ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۖ فَإِنۡ خِفۡتُمۡ أَلَّا يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَا فِيمَا ٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ تِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ فَلَا تَعۡتَدُوهَاۚ وَمَن يَتَعَدَّ حُدُودَ ٱللَّهِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿229﴾

Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀).Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

2:230

فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا تَحِلُّ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدُ حَتَّىٰ تَنكِحَ زَوۡجًا غَيۡرَهُۥۗ فَإِن طَلَّقَهَا فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَآ أَن يَتَرَاجَعَآ إِن ظَنَّآ أَن يُقِيمَا حُدُودَ ٱللَّهِۗ وَتِلۡكَ حُدُودُ ٱللَّهِ يُبَيِّنُهَا لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿230﴾

Nítorí náà, tí ọkọ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kẹta), obìnrin náà kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i mọ́ lẹ́yìn náà títí obìnrin náà yóò fi fẹ́ ẹlòmíìràn. Tí ẹni náà bá tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì nígbà náà láti padà sí ọ̀dọ̀ ara wọn, tí àwọn méjèèjì bá ti lérò pé àwọn máa ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀ (fún wọn), tí Ó ń ṣàlàyé rẹ̀ fún ìjọ tó nímọ̀.