quranm◉

Ojúewé 492

Range
from 43:34 to 43:47
Surahs covered
Ìtumọ̀
14 Ìtumọ̀

◉

43:34

وَلِبُيُوتِهِمۡ أَبۡوَٰبٗا وَسُرُرًا عَلَيۡهَا يَتَّكِـُٔونَ ﴿34﴾

(A ìbá tún ṣe) àwọn ẹnu ọ̀nà ilé wọn àti àwọn ibùsùn tí wọn yóò máa rọ̀gbọ̀kú lé lórí (ní fàdákà)

43:35

وَزُخۡرُفٗاۚ وَإِن كُلُّ ذَٰلِكَ لَمَّا مَتَٰعُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۚ وَٱلۡأٓخِرَةُ عِندَ رَبِّكَ لِلۡمُتَّقِينَ ﴿35﴾

àti góòlù.Gbogbo n̄ǹkan wọ̀nyí kò jẹ́ n̄ǹkan kan bí kò ṣe ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé lásán. (Ọgbà Ìdẹ̀ra) Ọ̀run sì wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

43:36

وَمَن يَعۡشُ عَن ذِكۡرِ ٱلرَّحۡمَٰنِ نُقَيِّضۡ لَهُۥ شَيۡطَٰنٗا فَهُوَ لَهُۥ قَرِينٞ ﴿36﴾

Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbi ìrántí Àjọké-ayé, A máa yan èṣù kan fún un. Òun sì ni alábàárìn rẹ̀.

43:37

وَإِنَّهُمۡ لَيَصُدُّونَهُمۡ عَنِ ٱلسَّبِيلِ وَيَحۡسَبُونَ أَنَّهُم مُّهۡتَدُونَ ﴿37﴾

Dájúdájú àwọn èṣù náà yóò máa ṣẹ́rí wọn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn Allāhu). Wọn yó sì máa lérò pé dájúdájú àwọn ni olùmọ̀nà.

43:38

حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَنَا قَالَ يَٰلَيۡتَ بَيۡنِي وَبَيۡنَكَ بُعۡدَ ٱلۡمَشۡرِقَيۡنِ فَبِئۡسَ ٱلۡقَرِينُ ﴿38﴾

Títí di ìgbà tí ó fi máa wá bá Wa, ó sì máa wí pé: “Háà! Kí ó sì jẹ́ pé (ìtakété bí) ìtakété ibùyọ-òòrùn àti ibùwọ̀ rẹ̀ sì wà láààrin èmi àti ìwọ (èṣù alábàárìn yìí, ìbá dára); alábàárìn burúkú sì ni.

43:39

وَلَن يَنفَعَكُمُ ٱلۡيَوۡمَ إِذ ظَّلَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ فِي ٱلۡعَذَابِ مُشۡتَرِكُونَ ﴿39﴾

(Àbámọ̀ yín) kò níí ṣe yín ní àǹfààní ní Òní nígbà tí ẹ ti ṣàbòsí. (Àti pé) dájúdájú ẹ̀yin (àti òrìṣà yín) ni ẹ dìjọ máa kẹ́gbẹ́ nínú ìyà.

43:40

أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ أَوۡ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَمَن كَانَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ ﴿40﴾

Ṣé ìwọ l’o máa fún àwọn adití ní ọ̀rọ̀ gbọ́ tàbí o máa fún àwọn afọ́jú ní ìmọ̀nà àti ẹni tí ó wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé?1

43:41

فَإِمَّا نَذۡهَبَنَّ بِكَ فَإِنَّا مِنۡهُم مُّنتَقِمُونَ ﴿41﴾

Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Á ti mú ọ kúrò (lórí ilẹ̀ ayé ṣíwájú àsìkò ìyà wọn), dájúdájú Àwa yóò gbẹ̀san (ìyà) lára wọn.

43:42

أَوۡ نُرِيَنَّكَ ٱلَّذِي وَعَدۡنَٰهُمۡ فَإِنَّا عَلَيۡهِم مُّقۡتَدِرُونَ ﴿42﴾

Tàbí kí Á fi ohun tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́, dájúdájú Àwa jẹ́ Alágbára lórí wọn.

43:43

فَٱسۡتَمۡسِكۡ بِٱلَّذِيٓ أُوحِيَ إِلَيۡكَۖ إِنَّكَ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿43﴾

Nítorí náà, di ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ mú ṣinṣin. Dájúdájú ìwọ wà lójú ọ̀nà tààrà (’Islām).

43:44

وَإِنَّهُۥ لَذِكۡرٞ لَّكَ وَلِقَوۡمِكَۖ وَسَوۡفَ تُسۡـَٔلُونَ ﴿44﴾

Dájúdájú al-Ƙur’ān ni tírà ìrántí fún ìwọ àti ìjọ rẹ. Láìpẹ́ wọ́n máa bi yín léèrè (nípa rẹ̀).

43:45

وَسۡـَٔلۡ مَنۡ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رُّسُلِنَآ أَجَعَلۡنَا مِن دُونِ ٱلرَّحۡمَٰنِ ءَالِهَةٗ يُعۡبَدُونَ ﴿45﴾

Bèèrè wò lọ́wọ́ àwọn tí A rán níṣẹ́ ṣíwájú rẹ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Wa (pé): “Ǹjẹ́ A sọ àwọn kan di ọlọ́hun tí wọn yóò máa jọ́sìn fún lẹ́yìn Àjọkẹ́-ayé bí?”1

43:46

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَا مُوسَىٰ بِـَٔايَٰتِنَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ فَقَالَ إِنِّي رَسُولُ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿46﴾

A kúkú fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Ó sì sọ pé: “Dájúdájú èmi ni Òjíṣẹ́ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

43:47

فَلَمَّا جَآءَهُم بِـَٔايَٰتِنَآ إِذَا هُم مِّنۡهَا يَضۡحَكُونَ ﴿47﴾

Ṣùgbọ́n nígbà tí ó mú àwọn àmì Wa wá bá wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi àwọn àmì náà rẹ́rìn-ín nígbà náà.