quranm◉

Surah Yunus transliteration

◉ Súrá · ∞

10:1

الٓرۚ تِلۡكَ ءَايَٰتُ ٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡحَكِيمِ ﴿1﴾

Transliteration: Aliflamra tilka ayatu alkitabi alhakeemi

Translation: ’Alif Lām Rọ̄. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)Ìwọ̀nyí ni àwọn āyah Tírà tí ó kún fún ọgbọ́n.2

10:2

أَكَانَ لِلنَّاسِ عَجَبًا أَنۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ رَجُلٖ مِّنۡهُمۡ أَنۡ أَنذِرِ ٱلنَّاسَ وَبَشِّرِ ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ أَنَّ لَهُمۡ قَدَمَ صِدۡقٍ عِندَ رَبِّهِمۡۗ قَالَ ٱلۡكَٰفِرُونَ إِنَّ هَٰذَا لَسَٰحِرٞ مُّبِينٌ ﴿2﴾

Transliteration: Akana lilnnasi AAajaban an awhayna ila rajulin minhum an anthiri alnnasa wabashshiri allatheena amanoo anna lahum qadama sidqin AAinda rabbihim qala alkafiroona inna hatha lasahirun mubeenun

Translation: Ṣé ó jẹ́ kàyééfì fún àwọn ènìyàn pé A fi ìmísí ránṣẹ́ sí arákùnrin kan nínú wọn pé: “Ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí o sì fún àwọn tó gbàgbọ́ ní ìró ìdùnnú pé ẹ̀san rere (iṣẹ́ tí wọ́n ṣe) ṣíwájú ti wà ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.”? Àwọn aláìgbàgbọ́ wí pé: “Dájúdájú òpìdán pọ́nńbélé mà ni (Ànábì) yìí.”

10:3

إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۖ مَا مِن شَفِيعٍ إِلَّا مِنۢ بَعۡدِ إِذۡنِهِۦۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡ فَٱعۡبُدُوهُۚ أَفَلَا تَذَكَّرُونَ ﴿3﴾

Transliteration: Inna rabbakumu Allahu allathee khalaqa alssamawati waalarda fee sittati ayyamin thumma istawa AAala alAAarshi yudabbiru alamra ma min shafeeAAin illa min baAAdi ithnihi thalikumu Allahu rabbukum faoAAbudoohu afala tathakkaroona

Translation: Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń ṣètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá). Kò sí olùṣìpẹ̀ kan àfi lẹ́yìn ìyọ̀ǹda Rẹ̀. Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

10:4

إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ جَمِيعٗاۖ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقًّاۚ إِنَّهُۥ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥ لِيَجۡزِيَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ بِٱلۡقِسۡطِۚ وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ ﴿4﴾

Transliteration: Ilayhi marjiAAukum jameeAAan waAAda Allahi haqqan innahu yabdao alkhalqa thumma yuAAeeduhu liyajziya allatheena amanoo waAAamiloo alssalihati bialqisti waallatheena kafaroo lahum sharabun min hameemin waAAathabun aleemun bima kanoo yakfuroona

Translation: Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí gbogbo yín. (Ó jẹ́) àdéhùn Allāhu ní ti òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa da á padà (sọ́dọ̀ Rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi déédé san ẹ̀san fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ rere. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé, wọ́n ṣàì gbàgbọ́.

10:5

هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ ٱلشَّمۡسَ ضِيَآءٗ وَٱلۡقَمَرَ نُورٗا وَقَدَّرَهُۥ مَنَازِلَ لِتَعۡلَمُواْ عَدَدَ ٱلسِّنِينَ وَٱلۡحِسَابَۚ مَا خَلَقَ ٱللَّهُ ذَٰلِكَ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ يُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿5﴾

Transliteration: Huwa allathee jaAAala alshshamsa diyaan waalqamara nooran waqaddarahu manazila litaAAlamoo AAadada alssineena waalhisaba ma khalaqa Allahu thalika illa bialhaqqi yufassilu alayati liqawmin yaAAlamoona

Translation: (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣe òòrùn ní ìtànsán. (Ó ṣe) òṣùpá ní ìmọ́lẹ̀. Ó sì díwọ̀n (ìrísí) rẹ̀ sínú àwọn ibùsọ̀ nítorí kí ẹ lè mọ òǹkà àwọn ọdún àti ìṣírò (ọjọ́). Allāhu kò dá ìyẹn bí kò ṣe pẹ̀lú òdodo. Ó ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó nímọ̀.

10:6

إِنَّ فِي ٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَمَا خَلَقَ ٱللَّهُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَتَّقُونَ ﴿6﴾

Transliteration: Inna fee ikhtilafi allayli waalnnahari wama khalaqa Allahu fee alssamawati waalardi laayatin liqawmin yattaqoona

Translation: Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán àti ohun tí Allāhu dá sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń bẹ̀rù (Allāhu).

10:7

إِنَّ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا وَرَضُواْ بِٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَٱطۡمَأَنُّواْ بِهَا وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِنَا غَٰفِلُونَ ﴿7﴾

Transliteration: Inna allatheena la yarjoona liqaana waradoo bialhayati alddunya waitmaannoo biha waallatheena hum AAan ayatina ghafiloona

Translation: Dájúdájú àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run), tí wọ́n yọ́nú sí ìṣẹ̀mí ayé, tí ọkàn wọn sì balẹ̀ dódó sí (ìṣẹ̀mí ayé yìí) àti àwọn afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa,

10:8

أُوْلَـٰٓئِكَ مَأۡوَىٰهُمُ ٱلنَّارُ بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ﴿8﴾

Transliteration: Olaika mawahumu alnnaru bima kanoo yaksiboona

Translation: àwọn wọ̀nyẹn, ibùgbé wọn ni Iná nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

10:9

إِنَّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ يَهۡدِيهِمۡ رَبُّهُم بِإِيمَٰنِهِمۡۖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمُ ٱلۡأَنۡهَٰرُ فِي جَنَّـٰتِ ٱلنَّعِيمِ ﴿9﴾

Transliteration: Inna allatheena amanoo waAAamiloo alssalihati yahdeehim rabbuhum bieemanihim tajree min tahtihimu alanharu fee jannati alnnaAAeemi

Translation: Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere, Olúwa wọn yóò fi ìgbàgbọ́ òdodo wọn tọ́ wọn sọ́nà.Àwọn odò yó sì máa ṣàn ní ìsàlẹ̀ ọ̀dọ̀ wọn nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra.

10:10

دَعۡوَىٰهُمۡ فِيهَا سُبۡحَٰنَكَ ٱللَّهُمَّ وَتَحِيَّتُهُمۡ فِيهَا سَلَٰمٞۚ وَءَاخِرُ دَعۡوَىٰهُمۡ أَنِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿10﴾

Transliteration: DaAAwahum feeha subhanaka allahumma watahiyyatuhum feeha salamun waakhiru daAAwahum ani alhamdu lillahi rabbi alAAalameena

Translation: Àdúà wọn nínú rẹ̀ ni “mímọ́ ni fún Ọ, Allāhu”. Ìkíni wọn nínú rẹ̀ ni “àlàáfíà”. Ìparí àdúà wọn sì ni pé, “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

10:11

وَلَوۡ يُعَجِّلُ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ ٱلشَّرَّ ٱسۡتِعۡجَالَهُم بِٱلۡخَيۡرِ لَقُضِيَ إِلَيۡهِمۡ أَجَلُهُمۡۖ فَنَذَرُ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ﴿11﴾

Transliteration: Walaw yuAAajjilu Allahu lilnnasi alshsharra istiAAjalahum bialkhayri laqudiya ilayhim ajaluhum fanatharu allatheena la yarjoona liqaana fee tughyanihim yaAAmahoona

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu ń kánjú mú aburú bá àwọn ènìyàn (nípasẹ̀ èpè ẹnu wọn, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe ń) tètè mú oore bá wọn (nípasẹ̀ àdúà), A ìbá ti mú òpin ba ìṣẹ́mí wọn. Nítorí náà, A máa fi àwọn tí kò retí ìpàdé Wa sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.

10:12

وَإِذَا مَسَّ ٱلۡإِنسَٰنَ ٱلضُّرُّ دَعَانَا لِجَنۢبِهِۦٓ أَوۡ قَاعِدًا أَوۡ قَآئِمٗا فَلَمَّا كَشَفۡنَا عَنۡهُ ضُرَّهُۥ مَرَّ كَأَن لَّمۡ يَدۡعُنَآ إِلَىٰ ضُرّٖ مَّسَّهُۥۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلۡمُسۡرِفِينَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿12﴾

Transliteration: Waitha massa alinsana alddurru daAAana lijanbihi aw qaAAidan aw qaiman falamma kashafna AAanhu durrahu marra kaan lam yadAAuna ila durrin massahu kathalika zuyyina lilmusrifeena ma kanoo yaAAmaloona

Translation: Nígbà tí ìnira bá kan ènìyàn, ó máa pè Wá lórí ìdùbúlẹ̀ rẹ̀ tàbí ní ìjókòó tàbí ní ìnàró. Nígbà tí A bá mú ìnira rẹ̀ kúrò fún un, ó máa tẹ̀ síwájú (nínú àìgbàgbọ́) bí ẹni pé kò pè Wá sí ìnira tí ó mú un. Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn alákọyọ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

10:13

وَلَقَدۡ أَهۡلَكۡنَا ٱلۡقُرُونَ مِن قَبۡلِكُمۡ لَمَّا ظَلَمُواْ وَجَآءَتۡهُمۡ رُسُلُهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَمَا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُواْۚ كَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ﴿13﴾

Transliteration: Walaqad ahlakna alquroona min qablikum lamma thalamoo wajaathum rusuluhum bialbayyinati wama kanoo liyuminoo kathalika najzee alqawma almujrimeena

Translation: A kúkú ti pa àwọn ìran kan rẹ́ ṣíwájú yín nígbà tí wọ́n ṣe àbòsí. Àwọn Òjíṣẹ́ wọn mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Wọn kò sì gbàgbọ́. Báyẹn ni A ṣe ń san ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ẹ̀san.

10:14

ثُمَّ جَعَلۡنَٰكُمۡ خَلَـٰٓئِفَ فِي ٱلۡأَرۡضِ مِنۢ بَعۡدِهِمۡ لِنَنظُرَ كَيۡفَ تَعۡمَلُونَ ﴿14﴾

Transliteration: Thumma jaAAalnakum khalaifa fee alardi min baAAdihim linanthura kayfa taAAmaloona

Translation: Lẹ́yìn náà, A ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀ lẹ́yìn wọn nítorí kí Á lè wo bí ẹ̀yin náà yóò ṣe máa ṣe.

10:15

وَإِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ ءَايَاتُنَا بَيِّنَٰتٖ قَالَ ٱلَّذِينَ لَا يَرۡجُونَ لِقَآءَنَا ٱئۡتِ بِقُرۡءَانٍ غَيۡرِ هَٰذَآ أَوۡ بَدِّلۡهُۚ قُلۡ مَا يَكُونُ لِيٓ أَنۡ أُبَدِّلَهُۥ مِن تِلۡقَآيِٕ نَفۡسِيٓۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۖ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ ﴿15﴾

Transliteration: Waitha tutla AAalayhim ayatuna bayyinatin qala allatheena la yarjoona liqaana iti biquranin ghayri hatha aw baddilhu qul ma yakoonu lee an obaddilahu min tilqai nafsee in attabiAAu illa ma yooha ilayya innee akhafu in AAasaytu rabbee AAathaba yawmin AAatheemin

Translation: Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa tó yanjú fún wọn, àwọn tí kò retí ìpàdé Wa (ní ọ̀run) yóò máa wí pé: “Mú Ƙur’ān kan wá yàtọ̀ sí èyí tàbí kí o yí i padà.” Sọ pé: “Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún mi láti yí i padà láti ọ̀dọ̀ ara mi. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí Wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí. Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ ńlá tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”

10:16

قُل لَّوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا تَلَوۡتُهُۥ عَلَيۡكُمۡ وَلَآ أَدۡرَىٰكُم بِهِۦۖ فَقَدۡ لَبِثۡتُ فِيكُمۡ عُمُرٗا مِّن قَبۡلِهِۦٓۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿16﴾

Transliteration: Qul law shaa Allahu ma talawtuhu AAalaykum wala adrakum bihi faqad labithtu feekum AAumuran min qablihi afala taAAqiloona

Translation: Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni, èmi ìbá tí lè ké al-Ƙur’ān fún yín, àti pé Allāhu ìbá tí fi ìmọ̀ rẹ̀ mọ̀ yín. Mo kúkú ti lo àwọn ọdún kan láààrin yín ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?”

10:17

فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ﴿17﴾

Transliteration: Faman athlamu mimmani iftara AAala Allahi kathiban aw kaththaba biayatihi innahu la yuflihu almujrimoona

Translation: Nítorí náà, ta ló ṣàbòsí ju ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí tó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò níí jèrè.

10:18

وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡ وَيَقُولُونَ هَـٰٓؤُلَآءِ شُفَعَـٰٓؤُنَا عِندَ ٱللَّهِۚ قُلۡ أَتُنَبِّـُٔونَ ٱللَّهَ بِمَا لَا يَعۡلَمُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ﴿18﴾

Transliteration: WayaAAbudoona min dooni Allahi ma la yadurruhum wala yanfaAAuhum wayaqooloona haolai shufaAAaona AAinda Allahi qul atunabbioona Allaha bima la yaAAlamu fee alssamawati wala fee alardi subhanahu wataAAala AAamma yushrikoona

Translation: Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.

10:19

وَمَا كَانَ ٱلنَّاسُ إِلَّآ أُمَّةٗ وَٰحِدَةٗ فَٱخۡتَلَفُواْۚ وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَقُضِيَ بَيۡنَهُمۡ فِيمَا فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ﴿19﴾

Transliteration: Wama kana alnnasu illa ommatan wahidatan faikhtalafoo walawla kalimatun sabaqat min rabbika laqudiya baynahum feema feehi yakhtalifoona

Translation: Kí ni àwọn ènìyàn jẹ́ (ní ìpìlẹ̀) bí kò ṣe ìjọ ẹyọ kan (ìjọ ’Islām). Lẹ́yìn náà ni wọ́n yapa-ẹnu. Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ti ṣíwájú lọ́dọ̀ Olúwa rẹ, Àwa ìbá ti yanjú ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀ láààrin ara wọn.

10:20

وَيَقُولُونَ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ ءَايَةٞ مِّن رَّبِّهِۦۖ فَقُلۡ إِنَّمَا ٱلۡغَيۡبُ لِلَّهِ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ ﴿20﴾

Transliteration: Wayaqooloona lawla onzila AAalayhi ayatun min rabbihi faqul innama alghaybu lillahi faintathiroo innee maAAakum mina almuntathireena

Translation: Wọ́n ń wí pé: “Kí ni kò jẹ́ kí àmì kan sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Nítorí náà, sọ pé: “Ti Allāhu ni ìkọ̀kọ̀. Nítorí náà, ẹ máa retí. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

10:21

وَإِذَآ أَذَقۡنَا ٱلنَّاسَ رَحۡمَةٗ مِّنۢ بَعۡدِ ضَرَّآءَ مَسَّتۡهُمۡ إِذَا لَهُم مَّكۡرٞ فِيٓ ءَايَاتِنَاۚ قُلِ ٱللَّهُ أَسۡرَعُ مَكۡرًاۚ إِنَّ رُسُلَنَا يَكۡتُبُونَ مَا تَمۡكُرُونَ ﴿21﴾

Transliteration: Waitha athaqna alnnasa rahmatan min baAAdi darraa massathum itha lahum makrun fee ayatina quli Allahu asraAAu makran inna rusulana yaktuboona ma tamkuroona

Translation: Nígbà tí A bá fún àwọn ènìyàn ní ìdẹ̀ra kan tọ́wò lẹ́yìn tí ìnira ti fọwọ́ bà wọ́n, nígbà náà ni wọ́n yóò máa dète sí àwọn āyah Wa. Sọ pé: “Allāhu yára jùlọ níbi ète.Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Wa ń ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ẹ̀ ń dá ní ète.”

10:22

هُوَ ٱلَّذِي يُسَيِّرُكُمۡ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا كُنتُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَرَيۡنَ بِهِم بِرِيحٖ طَيِّبَةٖ وَفَرِحُواْ بِهَا جَآءَتۡهَا رِيحٌ عَاصِفٞ وَجَآءَهُمُ ٱلۡمَوۡجُ مِن كُلِّ مَكَانٖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ أُحِيطَ بِهِمۡ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ لَئِنۡ أَنجَيۡتَنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ ﴿22﴾

Transliteration: Huwa allathee yusayyirukum fee albarri waalbahri hatta itha kuntum fee alfulki wajarayna bihim bireehin tayyibatin wafarihoo biha jaatha reehun AAasifun wajaahumu almawju min kulli makanin wathannoo annahum oheeta bihim daAAawoo Allaha mukhliseena lahu alddeena lain anjaytana min hathihi lanakoonanna mina alshshakireena

Translation: (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó ń gbé wọn lọ pẹ̀lú atẹ́gùn tó dára, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un(wọ́n sì máa sọ pé): “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

10:23

فَلَمَّآ أَنجَىٰهُمۡ إِذَا هُمۡ يَبۡغُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ بِغَيۡرِ ٱلۡحَقِّۗ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِنَّمَا بَغۡيُكُمۡ عَلَىٰٓ أَنفُسِكُمۖ مَّتَٰعَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُكُمۡ فَنُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿23﴾

Transliteration: Falamma anjahum itha hum yabghoona fee alardi bighayri alhaqqi ya ayyuha alnnasu innama baghyukum AAala anfusikum mataAAa alhayati alddunya thumma ilayna marjiAAukum fanunabbiokum bima kuntum taAAmaloona

Translation: Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó gbà wọ́n là tán ìgbà náà ni wọ́n tún ń ṣe ìbàjẹ́ kiri lórí ilẹ̀ láì lẹ́tọ̀ọ́. Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú ìbàjẹ́ yín ń bẹ lórí yín. (Ìbàjẹ́ yín sì jẹ́) ìgbádùn ìṣẹ̀mí ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí yín. A sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

10:24

إِنَّمَا مَثَلُ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا كَمَآءٍ أَنزَلۡنَٰهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ فَٱخۡتَلَطَ بِهِۦ نَبَاتُ ٱلۡأَرۡضِ مِمَّا يَأۡكُلُ ٱلنَّاسُ وَٱلۡأَنۡعَٰمُ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَخَذَتِ ٱلۡأَرۡضُ زُخۡرُفَهَا وَٱزَّيَّنَتۡ وَظَنَّ أَهۡلُهَآ أَنَّهُمۡ قَٰدِرُونَ عَلَيۡهَآ أَتَىٰهَآ أَمۡرُنَا لَيۡلًا أَوۡ نَهَارٗا فَجَعَلۡنَٰهَا حَصِيدٗا كَأَن لَّمۡ تَغۡنَ بِٱلۡأَمۡسِۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَتَفَكَّرُونَ ﴿24﴾

Transliteration: Innama mathalu alhayati alddunya kamain anzalnahu mina alssamai faikhtalata bihi nabatu alardi mimma yakulu alnnasu waalanAAamu hatta itha akhathati alardu zukhrufaha waizzayyanat wathanna ahluha annahum qadiroona AAalayha ataha amruna laylan aw naharan fajaAAalnaha haseedan kaan lam taghna bialamsi kathalika nufassilu alayati liqawmin yatafakkaroona

Translation: Àpèjúwe ìṣẹ̀mí ayé dà bí omi kan tí A sọ̀kalẹ̀ láti sánmọ̀, tí àwọn irúgbìn nínú ohun tí ènìyàn àti àwọn ẹran-ọ̀sìn ń jẹ sì gbà á sára, títí di ìgbà tí ilẹ̀ yóò fi lọ́ràá. Ó sì mú ọ̀ṣọ́ (ara) rẹ̀ jáde. Àwọn tó ni ín sì lérò pé àwọn ni alágbára lórí rẹ̀, (nígbà náà ni) àṣẹ Wa dé bá a ní òru tàbí ní ọ̀sán. A sì sọ ọ́ di oko tí wọ́n fà tu dànù bí ẹni pé kò sí níbẹ̀ rárá rí ní àná. Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ aláròjinlẹ̀.

10:25

وَٱللَّهُ يَدۡعُوٓاْ إِلَىٰ دَارِ ٱلسَّلَٰمِ وَيَهۡدِي مَن يَشَآءُ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿25﴾

Transliteration: WaAllahu yadAAoo ila dari alssalami wayahdee man yashao ila siratin mustaqeemin

Translation: Allāhu ń pèpè sí ilé Àlàáfíà. Ó sì ń tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà tààrà (’Islām).

10:26

لِّلَّذِينَ أَحۡسَنُواْ ٱلۡحُسۡنَىٰ وَزِيَادَةٞۖ وَلَا يَرۡهَقُ وُجُوهَهُمۡ قَتَرٞ وَلَا ذِلَّةٌۚ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡجَنَّةِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿26﴾

Transliteration: Lillatheena ahsanoo alhusna waziyadatun wala yarhaqu wujoohahum qatarun wala thillatun olaika ashabu aljannati hum feeha khalidoona

Translation: Rere àti àlékún (oore) wà fún àwọn tó ṣe rere. Eruku tàbí ìyẹpẹrẹ kan kò níí bò wọ́n lójú mọ́lẹ̀. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

10:27

وَٱلَّذِينَ كَسَبُواْ ٱلسَّيِّـَٔاتِ جَزَآءُ سَيِّئَةِۭ بِمِثۡلِهَا وَتَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۖ مَّا لَهُم مِّنَ ٱللَّهِ مِنۡ عَاصِمٖۖ كَأَنَّمَآ أُغۡشِيَتۡ وُجُوهُهُمۡ قِطَعٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِ مُظۡلِمًاۚ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿27﴾

Transliteration: Waallatheena kasaboo alssayyiati jazao sayyiatin bimithliha watarhaquhum thillatun ma lahum mina Allahi min AAasimin kaannama oghshiyat wujoohuhum qitaAAan mina allayli muthliman olaika ashabu alnnari hum feeha khalidoona

Translation: Àwọn tó sì ṣ’iṣẹ́ aburú, ẹ̀san aburú bí irú rẹ̀ (ni ẹ̀san wọn). Ìyẹpẹrẹ sì máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Kò sí aláàbò kan fún wọn lọ́dọ̀ Allāhu. (Wọ́n máa dà bí) ẹni pé wọ́n fi apá kan òru tó ṣókùnkùn bò wọ́n lójú pa. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀.

10:28

وَيَوۡمَ نَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ مَكَانَكُمۡ أَنتُمۡ وَشُرَكَآؤُكُمۡۚ فَزَيَّلۡنَا بَيۡنَهُمۡۖ وَقَالَ شُرَكَآؤُهُم مَّا كُنتُمۡ إِيَّانَا تَعۡبُدُونَ ﴿28﴾

Transliteration: Wayawma nahshuruhum jameeAAan thumma naqoolu lillatheena ashrakoo makanakum antum washurakaokum fazayyalna baynahum waqala shurakaohum ma kuntum iyyana taAAbudoona

Translation: Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn tó bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pé: “Ẹ dúró pa sí àyè yín, ẹ̀yin àti àwọn òrìṣà yín.” Nítorí náà, A yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn òrìṣà wọn sì wí pé: “Àwa kọ́ ni ẹ̀ ń jọ́sìn fún.”

10:29

فَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدَۢا بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمۡ إِن كُنَّا عَنۡ عِبَادَتِكُمۡ لَغَٰفِلِينَ ﴿29﴾

Transliteration: Fakafa biAllahi shaheedan baynana wabaynakum in kunna AAan AAibadatikum laghafileena

Translation: Nítorí náà, Allāhu tó ní Ẹlẹ́rìí láààrin àwa àti ẹ̀yin pé àwa jẹ́ aláìmọ̀ nípa ìjọ́sìn yín (tí ẹ̀ ṣe fún wa).”

10:30

هُنَالِكَ تَبۡلُواْ كُلُّ نَفۡسٖ مَّآ أَسۡلَفَتۡۚ وَرُدُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ مَوۡلَىٰهُمُ ٱلۡحَقِّۖ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ﴿30﴾

Transliteration: Hunalika tabloo kullu nafsin ma aslafat waruddoo ila Allahi mawlahumu alhaqqi wadalla AAanhum ma kanoo yaftaroona

Translation: Níbẹ̀ yẹn, ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan máa dá ohun tó ṣe síwájú mọ̀. Wọn yó sì da wọ́n padà sọ́dọ̀ Allāhu Olúwa wọn Òdodo. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.1

10:31

قُلۡ مَن يَرۡزُقُكُم مِّنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ أَمَّن يَمۡلِكُ ٱلسَّمۡعَ وَٱلۡأَبۡصَٰرَ وَمَن يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَيُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتَ مِنَ ٱلۡحَيِّ وَمَن يُدَبِّرُ ٱلۡأَمۡرَۚ فَسَيَقُولُونَ ٱللَّهُۚ فَقُلۡ أَفَلَا تَتَّقُونَ ﴿31﴾

Transliteration: Qul man yarzuqukum mina alssamai waalardi amman yamliku alssamAAa waalabsara waman yukhriju alhayya mina almayyiti wayukhriju almayyita mina alhayyi waman yudabbiru alamra fasayaqooloona Allahu faqul afala tattaqoona

Translation: Sọ pé: “Ta ni Ó ń pèsè fún yín láti inú sánmọ̀ àti ilẹ̀? Ta ni Ó ní ìkápá lórí ìgbọ́rọ̀ àti ìríran? Ta ni Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú, tí Ó tún ń mú òkú jáde láti ara alààyè? Ta sì ni Ó ń ṣe ètò ọ̀rọ̀ (ẹ̀dá)?” Wọn yóò wí pé: “Allāhu” Nígbà náà, sọ pé: “Ṣé ẹ ò níí bẹ̀rù (Rẹ̀) ni?”

10:32

فَذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمُ ٱلۡحَقُّۖ فَمَاذَا بَعۡدَ ٱلۡحَقِّ إِلَّا ٱلضَّلَٰلُۖ فَأَنَّىٰ تُصۡرَفُونَ ﴿32﴾

Transliteration: Fathalikumu Allahu rabbukumu alhaqqu famatha baAAda alhaqqi illa alddalalu faanna tusrafoona

Translation: Ìyẹn ni Allāhu Olúwa yín Òdodo. Kí sì ni ó ń bẹ lẹ́yìn Òdodo bí kò ṣe ìṣìnà? Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?

10:33

كَذَٰلِكَ حَقَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ عَلَى ٱلَّذِينَ فَسَقُوٓاْ أَنَّهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿33﴾

Transliteration: Kathalika haqqat kalimatu rabbika AAala allatheena fasaqoo annahum la yuminoona

Translation: Báyẹn ni ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ṣe wá sí ìmúṣẹ lórí àwọn tó ṣèbàjẹ́ pé dájúdájú wọn kò níí gbàgbọ́.

10:34

قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۚ قُلِ ٱللَّهُ يَبۡدَؤُاْ ٱلۡخَلۡقَ ثُمَّ يُعِيدُهُۥۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ ﴿34﴾

Transliteration: Qul hal min shurakaikum man yabdao alkhalqa thumma yuAAeeduhu quli Allahu yabdao alkhalqa thumma yuAAeeduhu faanna tufakoona

Translation: Sọ pé: “Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tí ó lè pilẹ̀ dídá ẹ̀dá, lẹ́yìn náà, tí ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú)?” Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń pilẹ̀ dídá ẹ̀dá. Lẹ́yìn náà, Ó máa dá a padà (sí ìpìlẹ̀ rẹ̀ lẹ́yìn ikú). Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ́rí yín kúrò níbi òdodo?

10:35

قُلۡ هَلۡ مِن شُرَكَآئِكُم مَّن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّۚ قُلِ ٱللَّهُ يَهۡدِي لِلۡحَقِّۗ أَفَمَن يَهۡدِيٓ إِلَى ٱلۡحَقِّ أَحَقُّ أَن يُتَّبَعَ أَمَّن لَّا يَهِدِّيٓ إِلَّآ أَن يُهۡدَىٰۖ فَمَا لَكُمۡ كَيۡفَ تَحۡكُمُونَ ﴿35﴾

Transliteration: Qul hal min shurakaikum man yahdee ila alhaqqi quli Allahu yahdee lilhaqqi afaman yahdee ila alhaqqi ahaqqu an yuttabaAAa amman la yahiddee illa an yuhda fama lakum kayfa tahkumoona

Translation: Sọ pé: “Ǹjẹ́ ó wà nínú àwọn òrìṣà yín ẹni tó ń fini mọ̀nà síbi òdodo?” Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo. Nígbà náà, ṣé Ẹni t’Ó ń fini mọ̀nà síbi òdodo ló lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí pé kí wọ́n máa tẹ̀lé ni tàbí ẹni tí kò lè dá ọ̀nà mọ̀ fúnra rẹ̀ àfi tí A bá fi mọ̀nà?” Nítorí náà, kí ló ń ṣe yín tí ẹ fi ń dájọ́ báyìí?

10:36

وَمَا يَتَّبِعُ أَكۡثَرُهُمۡ إِلَّا ظَنًّاۚ إِنَّ ٱلظَّنَّ لَا يُغۡنِي مِنَ ٱلۡحَقِّ شَيۡـًٔاۚ إِنَّ ٱللَّهَ عَلِيمُۢ بِمَا يَفۡعَلُونَ ﴿36﴾

Transliteration: Wama yattabiAAu aktharuhum illa thannan inna alththanna la yughnee mina alhaqqi shayan inna Allaha AAaleemun bima yafAAaloona

Translation: Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò sì rí kiní kan tẹ̀lé bí kò ṣe àròsọ. Dájúdájú àbá dídá kò sì lè rọrọ̀ kiní kan níwájú òdodo. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

10:37

وَمَا كَانَ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ أَن يُفۡتَرَىٰ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِن تَصۡدِيقَ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَتَفۡصِيلَ ٱلۡكِتَٰبِ لَا رَيۡبَ فِيهِ مِن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿37﴾

Transliteration: Wama kana hatha alquranu an yuftara min dooni Allahi walakin tasdeeqa allathee bayna yadayhi watafseela alkitabi la rayba feehi min rabbi alAAalameena

Translation: Al-Ƙur’ān yìí kì í ṣe n̄ǹkan tí ó ṣe é dáhun (láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíìràn) lẹ́yìn Allāhu, ṣùgbọ́n ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀, ó ń ṣe àlàyé (àwọn) Tírà náà. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. (Ó wá) láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

10:38

أَمۡ يَقُولُونَ ٱفۡتَرَىٰهُۖ قُلۡ فَأۡتُواْ بِسُورَةٖ مِّثۡلِهِۦ وَٱدۡعُواْ مَنِ ٱسۡتَطَعۡتُم مِّن دُونِ ٱللَّهِ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿38﴾

Transliteration: Am yaqooloona iftarahu qul fatoo bisooratin mithlihi waodAAoo mani istataAAtum min dooni Allahi in kuntum sadiqeena

Translation: Tàbí wọ́n ń wí pé: “Ó hun ún ni? Sọ pé: “Ẹ mú sūrah kan bí irú rẹ̀ wá. Kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè pè lẹ́yìn Allāhu, tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

10:39

بَلۡ كَذَّبُواْ بِمَا لَمۡ يُحِيطُواْ بِعِلۡمِهِۦ وَلَمَّا يَأۡتِهِمۡ تَأۡوِيلُهُۥۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿39﴾

Transliteration: Bal kaththaboo bima lam yuheetoo biAAilmihi walamma yatihim taweeluhu kathalika kaththaba allatheena min qablihim faonthur kayfa kana AAaqibatu alththalimeena

Translation: Kò rí bẹ́è, wọ́n pe ohun tí wọn kò ní ìmọ̀ rẹ̀ nírọ́ ni. Àti pé ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò tí ì dé bá wọn (ni wọ́n fi pè é nírọ́). Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe pe (ọ̀rọ̀ Allāhu) nírọ́. Nítorí náà, wo bí àtubọ̀tán àwọn alábòsí ṣe rí.

10:40

وَمِنۡهُم مَّن يُؤۡمِنُ بِهِۦ وَمِنۡهُم مَّن لَّا يُؤۡمِنُ بِهِۦۚ وَرَبُّكَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴿40﴾

Transliteration: Waminhum man yuminu bihi waminhum man la yuminu bihi warabbuka aAAlamu bialmufsideena

Translation: Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbà á gbọ́ ní òdodo. Ó tún ń bẹ́ nínú wọn ẹni tí kò gbà á gbọ́. Olúwa rẹ sì ni Onímọ̀-jùlọ nípa àwọn òbìlẹ̀jẹ́.

10:41

وَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل لِّي عَمَلِي وَلَكُمۡ عَمَلُكُمۡۖ أَنتُم بَرِيٓـُٔونَ مِمَّآ أَعۡمَلُ وَأَنَا۠ بَرِيٓءٞ مِّمَّا تَعۡمَلُونَ ﴿41﴾

Transliteration: Wain kaththabooka faqul lee AAamalee walakum AAamalukum antum bareeoona mimma aAAmalu waana bareeon mimma taAAmaloona

Translation: Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ pé: “Tèmi ni iṣẹ́ mi. Tiyín ni iṣẹ́ yín. Ẹ̀yin yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí mò ń ṣe níṣẹ́. Èmi náà sì yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

10:42

وَمِنۡهُم مَّن يَسۡتَمِعُونَ إِلَيۡكَۚ أَفَأَنتَ تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ وَلَوۡ كَانُواْ لَا يَعۡقِلُونَ ﴿42﴾

Transliteration: Waminhum man yastamiAAoona ilayka afaanta tusmiAAu alssumma walaw kanoo la yaAAqiloona

Translation: Ó sì wà nínú wọn, àwọn tó ń tẹ́tí sí ọ. Ṣé ìwọ lo máa mú adití gbọ́rọ̀ ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe làákàyè?1

10:43

وَمِنۡهُم مَّن يَنظُرُ إِلَيۡكَۚ أَفَأَنتَ تَهۡدِي ٱلۡعُمۡيَ وَلَوۡ كَانُواْ لَا يُبۡصِرُونَ ﴿43﴾

Transliteration: Waminhum man yanthuru ilayka afaanta tahdee alAAumya walaw kanoo la yubsiroona

Translation: Ó tún ń bẹ nínú wọn ẹni tó ń wò ọ́. Ṣé ìwọ lo máa fi afọ́jú mọ̀nà ni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ríran?

10:44

إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَظۡلِمُ ٱلنَّاسَ شَيۡـٔٗا وَلَٰكِنَّ ٱلنَّاسَ أَنفُسَهُمۡ يَظۡلِمُونَ ﴿44﴾

Transliteration: Inna Allaha la yathlimu alnnasa shayan walakinna alnnasa anfusahum yathlimoona

Translation: Dájúdájú Allāhu kò níí fí kiní kan ṣàbòsí sí ènìyàn. Ṣùgbọ́n ènìyàn ń ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn.

10:45

وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ كَأَن لَّمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا سَاعَةٗ مِّنَ ٱلنَّهَارِ يَتَعَارَفُونَ بَيۡنَهُمۡۚ قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱللَّهِ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ ﴿45﴾

Transliteration: Wayawma yahshuruhum kaan lam yalbathoo illa saAAatan mina alnnahari yataAAarafoona baynahum qad khasira allatheena kaththaboo biliqai Allahi wama kanoo muhtadeena

Translation: Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó wọn jọ àfi bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé ju àkókò kan nínú ọ̀sán. Wọn yó sì dára wọn mọ̀. Dájúdájú àwọn tó pe ìpàdé Allāhu nírọ́ ti ṣòfò; wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.

10:46

وَإِمَّا نُرِيَنَّكَ بَعۡضَ ٱلَّذِي نَعِدُهُمۡ أَوۡ نَتَوَفَّيَنَّكَ فَإِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ ثُمَّ ٱللَّهُ شَهِيدٌ عَلَىٰ مَا يَفۡعَلُونَ ﴿46﴾

Transliteration: Waimma nuriyannaka baAAda allathee naAAiduhum aw natawaffayannaka failayna marjiAAuhum thumma Allahu shaheedun AAala ma yafAAaloona

Translation: Ó ṣeé ṣe kí A fi apá kan èyí tí A ṣe ní ìlérí fún wọn hàn ọ́ tàbí kí A ti gba ẹ̀mí rẹ (ṣíwájú àsìkò náà), ọ̀dọ̀ Wa kúkú ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, Allāhu ni Arínú-róde ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

10:47

وَلِكُلِّ أُمَّةٖ رَّسُولٞۖ فَإِذَا جَآءَ رَسُولُهُمۡ قُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ﴿47﴾

Transliteration: Walikulli ommatin rasoolun faitha jaa rasooluhum qudiya baynahum bialqisti wahum la yuthlamoona

Translation: Òjíṣẹ́ ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan.Nítorí náà, nígbà tí Òjíṣẹ́ wọn bá dé, A óò ṣèdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

10:48

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡوَعۡدُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿48﴾

Transliteration: Wayaqooloona mata hatha alwaAAdu in kuntum sadiqeena

Translation: Wọ́n ń wí pé: “Ìgbà wo ni àdéhùn yìí yóò ṣẹ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

10:49

قُل لَّآ أَمۡلِكُ لِنَفۡسِي ضَرّٗا وَلَا نَفۡعًا إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۗ لِكُلِّ أُمَّةٍ أَجَلٌۚ إِذَا جَآءَ أَجَلُهُمۡ فَلَا يَسۡتَـٔۡخِرُونَ سَاعَةٗ وَلَا يَسۡتَقۡدِمُونَ ﴿49﴾

Transliteration: Qul la amliku linafsee darran wala nafAAan illa ma shaa Allahu likulli ommatin ajalun itha jaa ajaluhum fala yastakhiroona saAAatan wala yastaqdimoona

Translation: Sọ pé: “Èmi kò ní ìkápá ìnira tàbí oore kan fún ẹ̀mí ara mi àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́. Gbèdéke àkókò ti wà fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí àkókò wọn bá dé, wọn kò níí lè sún un ṣíwájú di àkókò kan, wọn kò sì níí lè fà á sẹ́yìn.”1

10:50

قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُهُۥ بَيَٰتًا أَوۡ نَهَارٗا مَّاذَا يَسۡتَعۡجِلُ مِنۡهُ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ﴿50﴾

Transliteration: Qul araaytum in atakum AAathabuhu bayatan aw naharan matha yastaAAjilu minhu almujrimoona

Translation: Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Rẹ̀ bá dé ba yín ní òru tàbí ní ọ̀sán? Èwo nínú rẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú?”

10:51

أَثُمَّ إِذَا مَا وَقَعَ ءَامَنتُم بِهِۦٓۚ ءَآلۡـَٰٔنَ وَقَدۡ كُنتُم بِهِۦ تَسۡتَعۡجِلُونَ ﴿51﴾

Transliteration: Athumma itha ma waqaAAa amantum bihi alana waqad kuntum bihi tastaAAjiloona

Translation: Ṣé lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ tán ni ẹ máa gbà á gbọ́? Ṣé nísinsìn yìí (ni ẹ óò gbà á gbọ́), tí ẹ sì kúkú ti ń wá a pẹ̀lú ìkánjú?

10:52

ثُمَّ قِيلَ لِلَّذِينَ ظَلَمُواْ ذُوقُواْ عَذَابَ ٱلۡخُلۡدِ هَلۡ تُجۡزَوۡنَ إِلَّا بِمَا كُنتُمۡ تَكۡسِبُونَ ﴿52﴾

Transliteration: Thumma qeela lillatheena thalamoo thooqoo AAathaba alkhuldi hal tujzawna illa bima kuntum taksiboona

Translation: Lẹ́yìn náà, A óò sọ fún àwọn tó ṣàbòsí pé: “Ẹ tọ́ ìyà gbére wò.” Ṣé A óò san yín ní ẹ̀san kan bí kò ṣe ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́?

10:53

وَيَسۡتَنۢبِـُٔونَكَ أَحَقٌّ هُوَۖ قُلۡ إِي وَرَبِّيٓ إِنَّهُۥ لَحَقّٞۖ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ ﴿53﴾

Transliteration: Wayastanbioonaka ahaqqun huwa qul ee warabbee innahu lahaqqun wama antum bimuAAjizeena

Translation: Wọ́n sì ń bèèrè fún ìró rẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “ṣé òdodo ni?” Sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Mo fi Olúwa mi búra. Dájúdájú òdodo ni. Ẹ̀yin kò sì níí mórí bọ́.”

10:54

وَلَوۡ أَنَّ لِكُلِّ نَفۡسٖ ظَلَمَتۡ مَا فِي ٱلۡأَرۡضِ لَٱفۡتَدَتۡ بِهِۦۗ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّدَامَةَ لَمَّا رَأَوُاْ ٱلۡعَذَابَۖ وَقُضِيَ بَيۡنَهُم بِٱلۡقِسۡطِ وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ﴿54﴾

Transliteration: Walaw anna likulli nafsin thalamat ma fee alardi laiftadat bihi waasarroo alnnadamata lamma raawoo alAAathaba waqudiya baynahum bialqisti wahum la yuthlamoona

Translation: Àti pé tí ó bá jẹ́ pé gbogbo n̄ǹkan tí ń bẹ lórí ilẹ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan tó ṣàbòsí, ìbá fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi ìyà). Wọn yóò fi igbe àbámọ̀ pamọ́ nígbà tí wọ́n bá rí Ìyà. A ó ṣe ìdájọ́ láààrin wọn pẹ̀lú déédé; Wọn kò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

10:55

أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۗ أَلَآ إِنَّ وَعۡدَ ٱللَّهِ حَقّٞ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿55﴾

Transliteration: Ala inna lillahi ma fee alssamawati waalardi ala inna waAAda Allahi haqqun walakinna aktharahum la yaAAlamoona

Translation: Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Gbọ́! Dájúdájú àdéhùn Allāhu ni òdodo, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò nímọ̀.

10:56

هُوَ يُحۡيِۦ وَيُمِيتُ وَإِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿56﴾

Transliteration: Huwa yuhyee wayumeetu wailayhi turjaAAoona

Translation: Ó ń sọ ẹ̀dá di alààyè. Ó sì ń sọ ẹ̀dá di òkú. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni wọn yóò da yín padà sí.

10:57

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَتۡكُم مَّوۡعِظَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَشِفَآءٞ لِّمَا فِي ٱلصُّدُورِ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿57﴾

Transliteration: Ya ayyuha alnnasu qad jaatkum mawAAithatun min rabbikum washifaon lima fee alssudoori wahudan warahmatun lilmumineena

Translation: Èyin ènìyàn, ìṣítí kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ti dé ba yín. Ìwòsàn ni fún n̄ǹkan tó wà nínú àwọn igbá-àyà ẹ̀dá. Ìmọ̀nà àti ìkẹ́ ni fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

10:58

قُلۡ بِفَضۡلِ ٱللَّهِ وَبِرَحۡمَتِهِۦ فَبِذَٰلِكَ فَلۡيَفۡرَحُواْ هُوَ خَيۡرٞ مِّمَّا يَجۡمَعُونَ ﴿58﴾

Transliteration: Qul bifadli Allahi wabirahmatihi fabithalika falyafrahoo huwa khayrun mimma yajmaAAoona

Translation: Sọ pé: “Pẹ̀lú oore àjùlọ Allāhu (ìyẹn, al-Ƙur’ān) àti àánú Rẹ̀ (ìyẹn, ’Islām), nítorí ìyẹn ni kí wọ́n máa fi dunnú; ó sì lóore ju ohun tí àwọn (aláìgbàgbọ́) ń kó jọ (nínú oore ayé).”

10:59

قُلۡ أَرَءَيۡتُم مَّآ أَنزَلَ ٱللَّهُ لَكُم مِّن رِّزۡقٖ فَجَعَلۡتُم مِّنۡهُ حَرَامٗا وَحَلَٰلٗا قُلۡ ءَآللَّهُ أَذِنَ لَكُمۡۖ أَمۡ عَلَى ٱللَّهِ تَفۡتَرُونَ ﴿59﴾

Transliteration: Qul araaytum ma anzala Allahu lakum min rizqin fajaAAaltum minhu haraman wahalalan qul allahu athina lakum am AAala Allahi taftaroona

Translation: Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi nípa àwọn n̄ǹkan tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ fún yín nínú arísìkí, tí ẹ̀yin fúnra yín ṣe àwọn kan ní èèwọ̀ àti ẹ̀tọ́.” Sọ pé, “Ṣé Allāhu l’Ó yọ̀ǹda fún yín (láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni) tàbí ẹ̀ ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu?”

10:60

وَمَا ظَنُّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلنَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَشۡكُرُونَ ﴿60﴾

Transliteration: Wama thannu allatheena yaftaroona AAala Allahi alkathiba yawma alqiyamati inna Allaha lathoo fadlin AAala alnnasi walakinna aktharahum la yashkuroona

Translation: Kí ni èrò-ọkàn àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ní Ọjọ́ Àjíǹde ná? Dájúdájú Allāhu ni Ọlọ́lá-jùlọ lórí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kì í dúpẹ́ (fún Un).

10:61

وَمَا تَكُونُ فِي شَأۡنٖ وَمَا تَتۡلُواْ مِنۡهُ مِن قُرۡءَانٖ وَلَا تَعۡمَلُونَ مِنۡ عَمَلٍ إِلَّا كُنَّا عَلَيۡكُمۡ شُهُودًا إِذۡ تُفِيضُونَ فِيهِۚ وَمَا يَعۡزُبُ عَن رَّبِّكَ مِن مِّثۡقَالِ ذَرَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا فِي ٱلسَّمَآءِ وَلَآ أَصۡغَرَ مِن ذَٰلِكَ وَلَآ أَكۡبَرَ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٍ ﴿61﴾

Transliteration: Wama takoonu fee shanin wama tatloo minhu min quranin wala taAAmaloona min AAamalin illa kunna AAalaykum shuhoodan ith tufeedoona feehi wama yaAAzubu AAan rabbika min mithqali tharratin fee alardi wala fee alssamai wala asghara min thalika wala akbara illa fee kitabin mubeenun

Translation: Ìwọ kò níí wà nínú ìṣe kan, ìwọ kò sì níí ké (āyah kan) nínú al-Ƙur’ān, ẹ̀yin kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi kí Àwa jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí yín nígbà tí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é. Kiní kan kò pamọ́ fún Olúwa rẹ; ohun tí ó mọ ní òdíwọ̀n ọmọ iná-igún nínú ilẹ̀ àti nínú sánmọ̀, èyí tí ó kéré sí ìyẹn àti èyí tí ó tóbi jù ú lọ àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.

10:62

أَلَآ إِنَّ أَوۡلِيَآءَ ٱللَّهِ لَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿62﴾

Transliteration: Ala inna awliyaa Allahi la khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: Gbọ́, dájúdájú àwọn ọ̀rẹ́ Allāhu, kò níí sí ìbẹ̀rù (ìyà ọ̀run) fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́ (lórí oore ayé).1

10:63

ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَكَانُواْ يَتَّقُونَ ﴿63﴾

Transliteration: Allatheena amanoo wakanoo yattaqoona

Translation: (Àwọn ni) àwọn tó gbàgbọ́ lódodo, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù (Allāhu).

10:64

لَهُمُ ٱلۡبُشۡرَىٰ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَفِي ٱلۡأٓخِرَةِۚ لَا تَبۡدِيلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ ذَٰلِكَ هُوَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ﴿64﴾

Transliteration: Lahumu albushra fee alhayati alddunya wafee alakhirati la tabdeela likalimati Allahi thalika huwa alfawzu alAAatheemu

Translation: Ti wọn ni ìró ìdùnnú nínú ìṣẹ̀mí ayé (yìí) àti ní Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Kò sí ìyípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu.Ìyẹn, òhun ni èrèǹjẹ ńlá.

10:65

وَلَا يَحۡزُنكَ قَوۡلُهُمۡۘ إِنَّ ٱلۡعِزَّةَ لِلَّهِ جَمِيعًاۚ هُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿65﴾

Transliteration: Wala yahzunka qawluhum inna alAAizzata lillahi jameeAAan huwa alssameeAAu alAAaleemu

Translation: Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ (ẹnu) wọn bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú gbogbo agbára pátápátá ń jẹ́ ti Allāhu. Òun ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

10:66

أَلَآ إِنَّ لِلَّهِ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِۗ وَمَا يَتَّبِعُ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ شُرَكَآءَۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ ﴿66﴾

Transliteration: Ala inna lillahi man fee alssamawati waman fee alardi wama yattabiAAu allatheena yadAAoona min dooni Allahi shurakaa in yattabiAAoona illa alththanna wain hum illa yakhrusoona

Translation: Gbọ́, dájúdájú ti Allāhu ni ẹnikẹ́ni tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ẹnikẹ́ni tó ń bẹ lórí ilẹ̀. Àwọn tó ń pe àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu kò (rí) akẹgbẹ́ Allāhu tẹ̀lé (torí pé, kò sí akẹgbẹ́ fún Allāhu níbìkan kan) Wọn kò tẹ̀lé (kiní kan) bí kò ṣe àbá dídá.Wọn kò sì ṣe kiní kan bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.

10:67

هُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ لِتَسۡكُنُواْ فِيهِ وَٱلنَّهَارَ مُبۡصِرًاۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَسۡمَعُونَ ﴿67﴾

Transliteration: Huwa allathee jaAAala lakumu allayla litaskunoo feehi waalnnahara mubsiran inna fee thalika laayatin liqawmin yasmaAAoona

Translation: Òun ni Ẹni t’Ó ṣe òru fún yín nítorí kí ẹ lè sinmi nínú rẹ̀. (Ó ṣe) ọ̀sán ní (àsìkò) ìríran (láti rìn káàkiri). Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ń gbọ́rọ̀ (òdodo).

10:68

قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗاۗ سُبۡحَٰنَهُۥۖ هُوَ ٱلۡغَنِيُّۖ لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ إِنۡ عِندَكُم مِّن سُلۡطَٰنِۭ بِهَٰذَآۚ أَتَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ مَا لَا تَعۡلَمُونَ ﴿68﴾

Transliteration: Qaloo ittakhatha Allahu waladan subhanahu huwa alghaniyyu lahu ma fee alssamawati wama fee alardi in AAindakum min sultanin bihatha ataqooloona AAala Allahi ma la taAAlamoona

Translation: Wọ́n wí pé: “Allāhu sọ ẹnì kan di ọmọ.” - Mímọ́ ni fún Un. Òun ní Ọlọ́rọ̀.TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. - Kò sí ẹ̀rí kan lọ́dọ̀ yín lórí èyí. Ṣé ẹ̀yin yóò máa ṣe àfitì ọ̀rọ̀ tí ẹ ò nímọ̀ rẹ̀ sọ́dọ̀ Allāhu ni?

10:69

قُلۡ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَفۡتَرُونَ عَلَى ٱللَّهِ ٱلۡكَذِبَ لَا يُفۡلِحُونَ ﴿69﴾

Transliteration: Qul inna allatheena yaftaroona AAala Allahi alkathiba la yuflihoona

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú àwọn tó ń dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu, wọn kò níí jèrè.”

10:70

مَتَٰعٞ فِي ٱلدُّنۡيَا ثُمَّ إِلَيۡنَا مَرۡجِعُهُمۡ ثُمَّ نُذِيقُهُمُ ٱلۡعَذَابَ ٱلشَّدِيدَ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ ﴿70﴾

Transliteration: MataAAun fee alddunya thumma ilayna marjiAAuhum thumma nutheequhumu alAAathaba alshshadeeda bima kanoo yakfuroona

Translation: Ìgbádùn bín-íntín (lè wà fún wọn) nílé ayé. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Lẹ́yìn náà, A óò fún wọn ní ìyà líle tọ́ wò nítorí pé wọ́n ń ṣàì gbàgbọ́.

10:71

وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ نُوحٍ إِذۡ قَالَ لِقَوۡمِهِۦ يَٰقَوۡمِ إِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكُم مَّقَامِي وَتَذۡكِيرِي بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَعَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡتُ فَأَجۡمِعُوٓاْ أَمۡرَكُمۡ وَشُرَكَآءَكُمۡ ثُمَّ لَا يَكُنۡ أَمۡرُكُمۡ عَلَيۡكُمۡ غُمَّةٗ ثُمَّ ٱقۡضُوٓاْ إِلَيَّ وَلَا تُنظِرُونِ ﴿71﴾

Transliteration: Waotlu AAalayhim nabaa noohin ith qala liqawmihi ya qawmi in kana kabura AAalaykum maqamee watathkeeree biayati Allahi faAAala Allahi tawakkaltu faajmiAAoo amrakum washurakaakum thumma la yakun amrukum AAalaykum ghummatan thumma iqdoo ilayya wala tunthirooni

Translation: Ka ìròyìn (Ànábì) Nūh fún wọn. Nígbà tí ó sọ fún ìjọ rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ó bá jẹ́ pé ìdúró mi (pẹ̀lú yín) àti bí mo ṣe ń fi àwọn āyah Allāhu ṣe ìṣítí fún yín bá lágbára lára yín, nígbà náà Allāhu ni mo gbáralé. Nítorí náà, ẹ pa ìmọ̀ràn yín pọ̀, (kí ẹ sì ké pe) àwọn òrìṣà yín. Lẹ́yìn náà, kí ìpinnu ọ̀rọ̀ yín má ṣe wà ní bòńkẹ́lẹ́ láààrin yín. Lẹ́yìn náà, kí ẹ yanjú ọ̀rọ̀ mi. Kí ẹ sì má ṣe lọ́ mi lára mọ́.

10:72

فَإِن تَوَلَّيۡتُمۡ فَمَا سَأَلۡتُكُم مِّنۡ أَجۡرٍۖ إِنۡ أَجۡرِيَ إِلَّا عَلَى ٱللَّهِۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ﴿72﴾

Transliteration: Fain tawallaytum fama saaltukum min ajrin in ajriya illa AAala Allahi waomirtu an akoona mina almuslimeena

Translation: Tí ẹ bá sì kọ̀yìn (sí ìrántí), èmi kò kúkú tọrọ owó-ọ̀yà kan lọ́wọ́ yín. Kò sí ẹ̀san kan fún mi (níbì kan) bí kò ṣe lọ́dọ̀ Allāhu. Wọ́n sì ti pa mí láṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn mùsùlùmí.”

10:73

فَكَذَّبُوهُ فَنَجَّيۡنَٰهُ وَمَن مَّعَهُۥ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَعَلۡنَٰهُمۡ خَلَـٰٓئِفَ وَأَغۡرَقۡنَا ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَاۖ فَٱنظُرۡ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُنذَرِينَ ﴿73﴾

Transliteration: Fakaththaboohu fanajjaynahu waman maAAahu fee alfulki wajaAAalnahum khalaifa waaghraqna allatheena kaththaboo biayatina faonthur kayfa kana AAaqibatu almunthareena

Translation: Nígbà náà, wọ́n pè é ní òpùrọ́. Nítorí náà, A gbà á là, òun àti àwọn tó ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àrólé (lórí ilẹ̀). A sì tẹ àwọn tó pe āyah Wa nírọ́ rì sínú agbami. Nítorí náà, wo bí ìkángun àwọn ẹni-akìlọ̀-fún ṣe rí.

10:74

ثُمَّ بَعَثۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِۦ رُسُلًا إِلَىٰ قَوۡمِهِمۡ فَجَآءُوهُم بِٱلۡبَيِّنَٰتِ فَمَا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُواْ بِمَا كَذَّبُواْ بِهِۦ مِن قَبۡلُۚ كَذَٰلِكَ نَطۡبَعُ عَلَىٰ قُلُوبِ ٱلۡمُعۡتَدِينَ ﴿74﴾

Transliteration: Thumma baAAathna min baAAdihi rusulan ila qawmihim fajaoohum bialbayyinati fama kanoo liyuminoo bima kaththaboo bihi min qablu kathalika natbaAAu AAala quloobi almuAAtadeena

Translation: Lẹ́yìn náà, A gbé àwọn Òjíṣẹ́ kan dìde sí àwọn ìjọ wọn. Wọ́n sì mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn náà kò kúkú gbàgbọ́ nínú ohun tí (ijọ́ Ànábì Nūh) pè nírọ́ ṣíwájú (wọn, ìyẹn ni pé, irú kan-ùn ni wọ́n).Báyẹn ni A ṣe ń fi èdídí bo ọkàn àwọn alákọyọ.

10:75

ثُمَّ بَعَثۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِم مُّوسَىٰ وَهَٰرُونَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦ بِـَٔايَٰتِنَا فَٱسۡتَكۡبَرُواْ وَكَانُواْ قَوۡمٗا مُّجۡرِمِينَ ﴿75﴾

Transliteration: Thumma baAAathna min baAAdihim moosa waharoona ila firAAawna wamalaihi biayatina faistakbaroo wakanoo qawman mujrimeena

Translation: Lẹ́yìn náà, lẹ́yìn wọn A fi àwọn àmì Wa rán (Ànábì) Mūsā àti Hārūn níṣẹ́ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà náà, wọ́n ṣègbéraga. Wọ́n sì jẹ́ ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

10:76

فَلَمَّا جَآءَهُمُ ٱلۡحَقُّ مِنۡ عِندِنَا قَالُوٓاْ إِنَّ هَٰذَا لَسِحۡرٞ مُّبِينٞ ﴿76﴾

Transliteration: Falamma jaahumu alhaqqu min AAindina qaloo inna hatha lasihrun mubeenun

Translation: Nígbà tí òdodo dé bá wọn láti ọ̀dọ̀ Wa, wọ́n wí pé: “Dájúdájú èyí ni idán pọ́nńbélé.”

10:77

قَالَ مُوسَىٰٓ أَتَقُولُونَ لِلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَكُمۡۖ أَسِحۡرٌ هَٰذَا وَلَا يُفۡلِحُ ٱلسَّـٰحِرُونَ ﴿77﴾

Transliteration: Qala moosa ataqooloona lilhaqqi lamma jaakum asihrun hatha wala yuflihu alssahiroona

Translation: (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ṣé n̄ǹkan tí ẹ̀yin yóò máa wí nípa òdodo nìyẹn nígbà tí ó dé ba yín? Ṣé idán sì ni èyí! Àwọn òpìdán kò sì níí jèrè.”

10:78

قَالُوٓاْ أَجِئۡتَنَا لِتَلۡفِتَنَا عَمَّا وَجَدۡنَا عَلَيۡهِ ءَابَآءَنَا وَتَكُونَ لَكُمَا ٱلۡكِبۡرِيَآءُ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا نَحۡنُ لَكُمَا بِمُؤۡمِنِينَ ﴿78﴾

Transliteration: Qaloo ajitana litalfitana AAamma wajadna AAalayhi abaana watakoona lakuma alkibriyao fee alardi wama nahnu lakuma bimumineena

Translation: Wọ́n wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè ṣẹ́rí wa kúrò níbi ohun tí a bá àwọn bàbá wa lórí rẹ̀ (nínú ìbọ̀rìṣà) àti nítorí kí títóbi sì lè jẹ́ tẹ̀yin méjèèjì lórí ilẹ̀? Àwa kò sì níí gba ẹ̀yin méjèèjì gbọ́.”

10:79

وَقَالَ فِرۡعَوۡنُ ٱئۡتُونِي بِكُلِّ سَٰحِرٍ عَلِيمٖ ﴿79﴾

Transliteration: Waqala firAAawnu itoonee bikulli sahirin AAaleemin

Translation: Fir‘aon wí pé: “Ẹ lọ mú gbogbo àwọn onímọ̀ nípa idán pípa wá fún mi.”

10:80

فَلَمَّا جَآءَ ٱلسَّحَرَةُ قَالَ لَهُم مُّوسَىٰٓ أَلۡقُواْ مَآ أَنتُم مُّلۡقُونَ ﴿80﴾

Transliteration: Falamma jaa alssaharatu qala lahum moosa alqoo ma antum mulqoona

Translation: Nígbà tí àwọn òpìdán dé, (Ànábì) Mūsā sọ fún wọn pé: “Ẹ ju ohun tí ẹ fẹ́ jù sílẹ̀.”

10:81

فَلَمَّآ أَلۡقَوۡاْ قَالَ مُوسَىٰ مَا جِئۡتُم بِهِ ٱلسِّحۡرُۖ إِنَّ ٱللَّهَ سَيُبۡطِلُهُۥٓ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يُصۡلِحُ عَمَلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴿81﴾

Transliteration: Falamma alqaw qala moosa ma jitum bihi alssihru inna Allaha sayubtiluhu inna Allaha la yuslihu AAamala almufsideena

Translation: Nígbà tí wọ́n jù ú sílẹ̀, (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Idán ni ohun tí ẹ mú wá. Dájúdájú Allāhu sì máa bà á jẹ́. Dájúdájú Allāhu kò sì níí ṣàtúnṣe iṣẹ́ àwọn òbìlẹ̀jẹ́.

10:82

وَيُحِقُّ ٱللَّهُ ٱلۡحَقَّ بِكَلِمَٰتِهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُجۡرِمُونَ ﴿82﴾

Transliteration: Wayuhiqqu Allahu alhaqqa bikalimatihi walaw kariha almujrimoona

Translation: Allāhu sì máa mú òdodo ṣẹ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ìbáà kórira rẹ̀.

10:83

فَمَآ ءَامَنَ لِمُوسَىٰٓ إِلَّا ذُرِّيَّةٞ مِّن قَوۡمِهِۦ عَلَىٰ خَوۡفٖ مِّن فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِمۡ أَن يَفۡتِنَهُمۡۚ وَإِنَّ فِرۡعَوۡنَ لَعَالٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَإِنَّهُۥ لَمِنَ ٱلۡمُسۡرِفِينَ ﴿83﴾

Transliteration: Fama amana limoosa illa thurriyyatun min qawmihi AAala khawfin min firAAawna wamalaihim an yaftinahum wainna firAAawna laAAalin fee alardi wainnahu lamina almusrifeena

Translation: Nítorí náà, kò sí ẹni tó gba (Ànábì) Mūsā gbọ́ àfi àwọn àrọ́mọdọ́mọ kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo (wọn) sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè wọn pé ó máa fòòró àwọn. Dájúdájú Fir‘aon kúkú ṣègbéraga lórí ilẹ̀. Àti pé, dájúdájú ó wà nínú àwọn alákọyọ.

10:84

وَقَالَ مُوسَىٰ يَٰقَوۡمِ إِن كُنتُمۡ ءَامَنتُم بِٱللَّهِ فَعَلَيۡهِ تَوَكَّلُوٓاْ إِن كُنتُم مُّسۡلِمِينَ ﴿84﴾

Transliteration: Waqala moosa ya qawmi in kuntum amantum biAllahi faAAalayhi tawakkaloo in kuntum muslimeena

Translation: (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí ẹ bá jẹ́ ẹni tó gbàgbọ́ nínú Allāhu, Òun náà ni kí ẹ gbáralé tí ẹ bá jẹ́ mùsùlùmí.”

10:85

فَقَالُواْ عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡنَا رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةٗ لِّلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿85﴾

Transliteration: Faqaloo AAala Allahi tawakkalna rabbana la tajAAalna fitnatan lilqawmi alththalimeena

Translation: Nítorí náà, wọ́n sọ pé: “Allāhu la gbáralé. Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwòfún ìjọ alábòsí.

10:86

وَنَجِّنَا بِرَحۡمَتِكَ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿86﴾

Transliteration: Wanajjina birahmatika mina alqawmi alkafireena

Translation: Kí Ó sì fi àánú Rẹ gbà wá là lọ́wọ́ ìjọ aláìgbàgbọ́.”

10:87

وَأَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰ وَأَخِيهِ أَن تَبَوَّءَا لِقَوۡمِكُمَا بِمِصۡرَ بُيُوتٗا وَٱجۡعَلُواْ بُيُوتَكُمۡ قِبۡلَةٗ وَأَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿87﴾

Transliteration: Waawhayna ila moosa waakheehi an tabawwaa liqawmikuma bimisra buyootan waijAAaloo buyootakum qiblatan waaqeemoo alssalata wabashshiri almumineena

Translation: A sì ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā àti arákùnrin rẹ̀ pé: “Kí ẹ̀yin méjèèjì mú àwọn ibùgbé fún àwọn ènìyàn yín sí ìlú Misrọ. Kí ẹ sì sọ ibùgbé yín di ibùkírun.Kí ẹ sì máa kírun. Àti pé, fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.”

10:88

وَقَالَ مُوسَىٰ رَبَّنَآ إِنَّكَ ءَاتَيۡتَ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَأَهُۥ زِينَةٗ وَأَمۡوَٰلٗا فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا رَبَّنَا لِيُضِلُّواْ عَن سَبِيلِكَۖ رَبَّنَا ٱطۡمِسۡ عَلَىٰٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ وَٱشۡدُدۡ عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ فَلَا يُؤۡمِنُواْ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ﴿88﴾

Transliteration: Waqala moosa rabbana innaka atayta firAAawna wamalaahu zeenatan waamwalan fee alhayati alddunya rabbana liyudilloo AAan sabeelika rabbana itmis AAala amwalihim waoshdud AAala quloobihim fala yuminoo hatta yarawoo alAAathaba alaleema

Translation: (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú Ìwọ l’O fún Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀ ní ọ̀ṣọ́ àti dúkìá nínú ìṣẹ̀mí ayé. Olúwa wa, (O fún wọn) torí kí wọ́n lè ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ.Olúwa wa, pa dúkìá wọn rẹ́, kí O sì mú ọkàn wọn le, kí wọ́n má gbàgbọ́ mọ́ títí wọn fi máa rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.”

10:89

قَالَ قَدۡ أُجِيبَت دَّعۡوَتُكُمَا فَٱسۡتَقِيمَا وَلَا تَتَّبِعَآنِّ سَبِيلَ ٱلَّذِينَ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿89﴾

Transliteration: Qala qad ojeebat daAAwatukuma faistaqeema wala tattabiAAanni sabeela allatheena la yaAAlamoona

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Mo ti gba àdúà ẹ̀yin méjèèjì. Nítorí náà, kí ẹ̀yin méjèèjì dúró ṣinṣin. Ẹ má ṣe tẹ̀lé ojú ọ̀nà àwọn tí kò nímọ̀.”

10:90

وَجَٰوَزۡنَا بِبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ ٱلۡبَحۡرَ فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ وَجُنُودُهُۥ بَغۡيٗا وَعَدۡوًاۖ حَتَّىٰٓ إِذَآ أَدۡرَكَهُ ٱلۡغَرَقُ قَالَ ءَامَنتُ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا ٱلَّذِيٓ ءَامَنَتۡ بِهِۦ بَنُوٓاْ إِسۡرَـٰٓءِيلَ وَأَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ﴿90﴾

Transliteration: Wajawazna bibanee israeela albahra faatbaAAahum firAAawnu wajunooduhu baghyan waAAadwan hatta itha adrakahu algharaqu qala amantu annahu la ilaha illa allathee amanat bihi banoo israeela waana mina almuslimeena

Translation: A mú àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl la agbami òkun já. Fir‘aon àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì gbá tọ̀ wọ́n lẹ́yìn, ní ti ìlara àti ìtayọ ẹnu-ààlà, títí ìtẹ̀rì sínú agbami òkun fi bá a. Ó sì wí pé: “Mo gbàgbọ́ pé dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ẹni tí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl gbàgbọ́. Mo sì wà nínú àwọn mùsùlùmí.”1

10:91

ءَآلۡـَٰٔنَ وَقَدۡ عَصَيۡتَ قَبۡلُ وَكُنتَ مِنَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ﴿91﴾

Transliteration: Alana waqad AAasayta qablu wakunta mina almufsideena

Translation: Ṣé nísinsìn yìí, tí ìwọ ti yapa ṣíwájú, tí o sì wà nínú àwọn òbìlẹ̀jẹ́?

10:92

فَٱلۡيَوۡمَ نُنَجِّيكَ بِبَدَنِكَ لِتَكُونَ لِمَنۡ خَلۡفَكَ ءَايَةٗۚ وَإِنَّ كَثِيرٗا مِّنَ ٱلنَّاسِ عَنۡ ءَايَٰتِنَا لَغَٰفِلُونَ ﴿92﴾

Transliteration: Faalyawma nunajjeeka bibadanika litakoona liman khalfaka ayatan wainna katheeran mina alnnasi AAan ayatina laghafiloona

Translation: Nítorí náà, ní òní ni A óò gbé òkú rẹ jáde sí orí ilẹ̀ téńté nítorí kí o lè jẹ́ àmì (fèyíkọ́gbọ́n) fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn mà ni afọ́nú-fọ́ra nípa àwọn āyah Wa.

10:93

وَلَقَدۡ بَوَّأۡنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ مُبَوَّأَ صِدۡقٖ وَرَزَقۡنَٰهُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ فَمَا ٱخۡتَلَفُواْ حَتَّىٰ جَآءَهُمُ ٱلۡعِلۡمُۚ إِنَّ رَبَّكَ يَقۡضِي بَيۡنَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ فِيمَا كَانُواْ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَ ﴿93﴾

Transliteration: Walaqad bawwana banee israeela mubawwaa sidqin warazaqnahum mina alttayyibati fama ikhtalafoo hatta jaahumu alAAilmu inna rabbaka yaqdee baynahum yawma alqiyamati feema kanoo feehi yakhtalifoona

Translation: A kúkú ṣe ibùgbé fún àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl ní ibùgbé dáadáa. A sì pèsè fún wọn nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa. Nígbà náà, wọn kò yapa-ẹnu (lórí ’Islām) títí ìmọ̀ fi dé bá wọn.Dájúdájú Olúwa rẹ yóò ṣèdájọ́ láààrin wọn ní Ọjọ́ Àjíǹde nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu lórí rẹ̀.

10:94

فَإِن كُنتَ فِي شَكّٖ مِّمَّآ أَنزَلۡنَآ إِلَيۡكَ فَسۡـَٔلِ ٱلَّذِينَ يَقۡرَءُونَ ٱلۡكِتَٰبَ مِن قَبۡلِكَۚ لَقَدۡ جَآءَكَ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكَ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ﴿94﴾

Transliteration: Fain kunta fee shakkin mimma anzalnna ilayka faisali allatheena yaqraoona alkitaba min qablika laqad jaaka alhaqqu min rabbika fala takoonanna mina almumtareena

Translation: Tí o bá wà nínú iyèméjì nípa n̄ǹkan tí A sọ̀kalẹ̀ fún ọ (pé orúkọ rẹ àti àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ wà nínú at-Taorāt àti al-’Injīl), bi àwọn tó ń ka Tírà ṣíwájú rẹ léèrè wò.Dájúdájú òdodo ti dé bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

10:95

وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ فَتَكُونَ مِنَ ٱلۡخَٰسِرِينَ ﴿95﴾

Transliteration: Wala takoonanna mina allatheena kaththaboo biayati Allahi fatakoona mina alkhasireena

Translation: O ò gbọdọ̀ wà lára àwọn tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, nítorí kí o má baà wà lára àwọn ẹni òfò.

10:96

إِنَّ ٱلَّذِينَ حَقَّتۡ عَلَيۡهِمۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿96﴾

Transliteration: Inna allatheena haqqat AAalayhim kalimatu rabbika la yuminoona

Translation: Dájúdájú àwọn tí ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ ti kò lé lórí, wọn kò níí gbàgbọ́,

10:97

وَلَوۡ جَآءَتۡهُمۡ كُلُّ ءَايَةٍ حَتَّىٰ يَرَوُاْ ٱلۡعَذَابَ ٱلۡأَلِيمَ ﴿97﴾

Transliteration: Walaw jaathum kullu ayatin hatta yarawoo alAAathaba alaleema

Translation: gbogbo āyah ìbáà dé bá wọn, títí wọ́n máa fi rí ìyà ẹlẹ́ta-eléro.1

10:98

فَلَوۡلَا كَانَتۡ قَرۡيَةٌ ءَامَنَتۡ فَنَفَعَهَآ إِيمَٰنُهَآ إِلَّا قَوۡمَ يُونُسَ لَمَّآ ءَامَنُواْ كَشَفۡنَا عَنۡهُمۡ عَذَابَ ٱلۡخِزۡيِ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا وَمَتَّعۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ حِينٖ ﴿98﴾

Transliteration: Falawla kanat qaryatun amanat fanafaAAaha eemanuha illa qawma yoonusa lamma amanoo kashafna AAanhum AAathaba alkhizyi fee alhayati alddunya wamattaAAnahum ila heenin

Translation: Kí ó sì jẹ́ pé ìlú kàn gbàgbọ́ (lásìkò ìsọ̀kalẹ̀ ìyà), kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ sì ṣe é ní àǹfààní (kò kúkú sí) àfi ìjọ (Ànábì) Yūnus (nítorí pé), nígbà tí wọ́n gbàgbọ́, A mú àbùkù ìyà kúrò fún wọn nínú ìṣẹ̀mí ayé. A sì jẹ́ kí wọ́n jẹ ìgbádùn ayé fún ìgbà díẹ̀.

10:99

وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ لَأٓمَنَ مَن فِي ٱلۡأَرۡضِ كُلُّهُمۡ جَمِيعًاۚ أَفَأَنتَ تُكۡرِهُ ٱلنَّاسَ حَتَّىٰ يَكُونُواْ مُؤۡمِنِينَ ﴿99﴾

Transliteration: Walaw shaa rabbuka laamana man fee alardi kulluhum jameeAAan afaanta tukrihu alnnasa hatta yakoonoo mumineena

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́, gbogbo àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ pátápátá ìbá gbàgbọ́. Nítorí náà, ṣé ìwọ lo máa jẹ àwọn ènìyàn nípá títí wọn yóò fi di onígbàgbọ́ òdodo ni?

10:100

وَمَا كَانَ لِنَفۡسٍ أَن تُؤۡمِنَ إِلَّا بِإِذۡنِ ٱللَّهِۚ وَيَجۡعَلُ ٱلرِّجۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يَعۡقِلُونَ ﴿100﴾

Transliteration: Wama kana linafsin an tumina illa biithni Allahi wayajAAalu alrrijsa AAala allatheena la yaAAqiloona

Translation: Ẹ̀mí kan kò lè gbàgbọ́ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì máa fi ìyà jẹ àwọn tí kò ṣe làákàyè.1

10:101

قُلِ ٱنظُرُواْ مَاذَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَمَا تُغۡنِي ٱلۡأٓيَٰتُ وَٱلنُّذُرُ عَن قَوۡمٖ لَّا يُؤۡمِنُونَ ﴿101﴾

Transliteration: Quli onthuroo matha fee alssamawati waalardi wama tughnee alayatu waalnnuthuru AAan qawmin la yuminoona

Translation: Sọ pé: “Ẹ wòye sí n̄ǹkan tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àwọn āyah àti ìkìlọ̀ kò sì níí rọ ìjọ aláìgbàgbọ́ lọ́rọ̀.”

10:102

فَهَلۡ يَنتَظِرُونَ إِلَّا مِثۡلَ أَيَّامِ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِهِمۡۚ قُلۡ فَٱنتَظِرُوٓاْ إِنِّي مَعَكُم مِّنَ ٱلۡمُنتَظِرِينَ ﴿102﴾

Transliteration: Fahal yantathiroona illa mithla ayyami allatheena khalaw min qablihim qul faintathiroo innee maAAakum mina almuntathireena

Translation: Nítorí náà, ṣé wọ́n tún ń retí (n̄ǹkan mìíràn) ni bí kò ṣe (ìparun) irú ti ọjọ́ àwọn tó ré kọjá lọ ṣíwájú wọn. Sọ pé: “Ẹ máa retí nígbà náà. Dájúdájú èmi náà wà pẹ̀lú yín nínú àwọn olùretí.”

10:103

ثُمَّ نُنَجِّي رُسُلَنَا وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْۚ كَذَٰلِكَ حَقًّا عَلَيۡنَا نُنجِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿103﴾

Transliteration: Thumma nunajjee rusulana waallatheena amanoo kathalika haqqan AAalayna nunjee almumineena

Translation: Lẹ́yìn náà, A óò gba àwọn Òjíṣẹ́ Wa àti àwọn tó gbàgbọ́ lódodo là. Báyẹn ní ó ṣe jẹ́ ojúṣe Wa láti gba àwọn onígbàgbọ́ òdodo là.

10:104

قُلۡ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي شَكّٖ مِّن دِينِي فَلَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِنۡ أَعۡبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُمۡۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿104﴾

Transliteration: Qul ya ayyuha alnnasu in kuntum fee shakkin min deenee fala aAAbudu allatheena taAAbudoona min dooni Allahi walakin aAAbudu Allaha allathee yatawaffakum waomirtu an akoona mina almumineena

Translation: Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

10:105

وَأَنۡ أَقِمۡ وَجۡهَكَ لِلدِّينِ حَنِيفٗا وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿105﴾

Transliteration: Waan aqim wajhaka lilddeeni haneefan wala takoonanna mina almushrikeena

Translation: (Wọ́n tún pa mí láṣẹ pé): “Dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn.Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

10:106

وَلَا تَدۡعُ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَۖ فَإِن فَعَلۡتَ فَإِنَّكَ إِذٗا مِّنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿106﴾

Transliteration: Wala tadAAu min dooni Allahi ma la yanfaAAuka wala yadurruka fain faAAalta fainnaka ithan mina alththalimeena

Translation: Àti pé má ṣe pè lẹ́yìn Allāhu n̄ǹkan tí kò lè ṣe ọ́ ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá ọ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà, dájúdájú ìwọ ti wà nínú àwọn alábòsí.”

10:107

وَإِن يَمۡسَسۡكَ ٱللَّهُ بِضُرّٖ فَلَا كَاشِفَ لَهُۥٓ إِلَّا هُوَۖ وَإِن يُرِدۡكَ بِخَيۡرٖ فَلَا رَآدَّ لِفَضۡلِهِۦۚ يُصِيبُ بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡغَفُورُ ٱلرَّحِيمُ ﴿107﴾

Transliteration: Wain yamsaska Allahu bidurrin fala kashifa lahu illa huwa wain yuridka bikhayrin fala radda lifadlihi yuseebu bihi man yashao min AAibadihi wahuwa alghafooru alrraheemu

Translation: Tí Allāhu bá mú ìnira bá ọ, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun. Tí Ó bá sì gbèrò oore kan pẹ̀lú rẹ, kò sí ẹni tí ó lè dá oore Rẹ̀ padà. Ó ń ṣoore fún ẹni tí Ó bá fẹ́ nínú àwọn ẹrúsìn Rẹ̀. Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

10:108

قُلۡ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ قَدۡ جَآءَكُمُ ٱلۡحَقُّ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهۡتَدِي لِنَفۡسِهِۦۖ وَمَن ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيۡهَاۖ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِوَكِيلٖ ﴿108﴾

Transliteration: Qul ya ayyuha alnnasu qad jaakumu alhaqqu min rabbikum famani ihtada fainnama yahtadee linafsihi waman dalla fainnama yadillu AAalayha wama ana AAalaykum biwakeelin

Translation: Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, dájúdájú òdodo ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀nà, ó mọ̀nà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣìnà, ó ṣìnà fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Èmi sì kọ́ ni olùṣọ́ fún yín.”

10:109

وَٱتَّبِعۡ مَا يُوحَىٰٓ إِلَيۡكَ وَٱصۡبِرۡ حَتَّىٰ يَحۡكُمَ ٱللَّهُۚ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡحَٰكِمِينَ ﴿109﴾

Transliteration: WaittabiAA ma yooha ilayka waisbir hatta yahkuma Allahu wahuwa khayru alhakimeena

Translation: Tẹ̀lé ohun tí A fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí. Kí o sì ṣe sùúrù títí Allāhu yóò fi ṣèdájọ́. Òun sì lóore julọ nínú àwọn olùdájọ́.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download