quranm◉

Surah Taha transliteration

◉ Súrá · ∞

20:1

طه ﴿1﴾

Transliteration: Taha

Translation: Tọ̄ hā. (Allāhu ló mọ ohun tí Ó gbàlérò pẹ̀lú àwọn háràfí náà.)1

20:2

مَآ أَنزَلۡنَا عَلَيۡكَ ٱلۡقُرۡءَانَ لِتَشۡقَىٰٓ ﴿2﴾

Transliteration: Ma anzalna AAalayka alqurana litashqa

Translation: A kò sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ fún ọ láti kó wàhálà bá ọ.

20:3

إِلَّا تَذۡكِرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰ ﴿3﴾

Transliteration: Illa tathkiratan liman yakhsha

Translation: Bí kò ṣe pé ó jẹ́ ìrántí fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).

20:4

تَنزِيلٗا مِّمَّنۡ خَلَقَ ٱلۡأَرۡضَ وَٱلسَّمَٰوَٰتِ ٱلۡعُلَى ﴿4﴾

Transliteration: Tanzeelan mimman khalaqa alarda waalssamawati alAAula

Translation: (Ó jẹ́) ìmísí tó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí Ó dá ilẹ̀ àti àwọn sánmọ̀ gíga.

20:5

ٱلرَّحۡمَٰنُ عَلَى ٱلۡعَرۡشِ ٱسۡتَوَىٰ ﴿5﴾

Transliteration: Alrrahmanu AAala alAAarshi istawa

Translation: Àjọkẹ́-ayé gúnwà sórí Ìtẹ́-ọlá.

20:6

لَهُۥ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ وَمَا بَيۡنَهُمَا وَمَا تَحۡتَ ٱلثَّرَىٰ ﴿6﴾

Transliteration: Lahu ma fee alssamawati wama fee alardi wama baynahuma wama tahta alththara

Translation: TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀, ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ àti ohunkóhun tó wà láààrin méjèèjì àti ohunkóhun tó wà lábẹ́ ilẹ̀.

20:7

وَإِن تَجۡهَرۡ بِٱلۡقَوۡلِ فَإِنَّهُۥ يَعۡلَمُ ٱلسِّرَّ وَأَخۡفَى ﴿7﴾

Transliteration: Wain tajhar bialqawli fainnahu yaAAlamu alssirra waakhfa

Translation: Tí o bá sọ ọ̀rọ̀ jáde, dájúdájú (Allāhu) mọ ìkọ̀kọ̀ àti ohun tí ó (tún) pamọ́ jùlọ.

20:8

ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ لَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰ ﴿8﴾

Transliteration: Allahu la ilaha illa huwa lahu alasmao alhusna

Translation: Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. TiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ.

20:9

وَهَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ ﴿9﴾

Transliteration: Wahal ataka hadeethu moosa

Translation: Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā dé ọ̀dọ̀ rẹ?

20:10

إِذۡ رَءَا نَارٗا فَقَالَ لِأَهۡلِهِ ٱمۡكُثُوٓاْ إِنِّيٓ ءَانَسۡتُ نَارٗا لَّعَلِّيٓ ءَاتِيكُم مِّنۡهَا بِقَبَسٍ أَوۡ أَجِدُ عَلَى ٱلنَّارِ هُدٗى ﴿10﴾

Transliteration: Ith raa naran faqala liahlihi omkuthoo innee anastu naran laAAallee ateekum minha biqabasin aw ajidu AAala alnnari hudan

Translation: (Rántí) nígbà tí ó rí iná kan, ó sọ fún àwọn ará ilé rẹ̀ pé: “Ẹ dúró síbí. Dájúdájú èmi rí iná kan. Ó ṣeé ṣe kí n̄g rí ògúnná mú wá fún yín nínú rẹ̀ tàbí kí n̄g rí ojú ọ̀nà kan nítòsí iná náà.”

20:11

فَلَمَّآ أَتَىٰهَا نُودِيَ يَٰمُوسَىٰٓ ﴿11﴾

Transliteration: Falamma ataha noodiya ya moosa

Translation: Nígbà tí ó dé ibẹ̀, A pè é “Mūsā,

20:12

إِنِّيٓ أَنَا۠ رَبُّكَ فَٱخۡلَعۡ نَعۡلَيۡكَ إِنَّكَ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوٗى ﴿12﴾

Transliteration: Innee ana rabbuka faikhlaAA naAAlayka innaka bialwadi almuqaddasi tuwan

Translation: Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀.Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.

20:13

وَأَنَا ٱخۡتَرۡتُكَ فَٱسۡتَمِعۡ لِمَا يُوحَىٰٓ ﴿13﴾

Transliteration: Waana ikhtartuka faistamiAA lima yooha

Translation: Àti pé Èmi ṣà ọ́ lẹ́ṣà. Nítorí náà, fi etí sí ohun tí A máa fi ránṣẹ́ sí ọ nínú ìmísí.

20:14

إِنَّنِيٓ أَنَا ٱللَّهُ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدۡنِي وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ لِذِكۡرِيٓ ﴿14﴾

Transliteration: Innanee ana Allahu la ilaha illa ana faoAAbudnee waaqimi alssalata lithikree

Translation: Dájúdájú Èmi ni Allāhu. Kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi. Nítorí náà, jọ́sìn fún Mi. Kí o sì kírun fún ìrántí Mi.1

20:15

إِنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٌ أَكَادُ أُخۡفِيهَا لِتُجۡزَىٰ كُلُّ نَفۡسِۭ بِمَا تَسۡعَىٰ ﴿15﴾

Transliteration: Inna alssaAAata atiyatun akadu okhfeeha litujza kullu nafsin bima tasAAa

Translation: Dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Ó súnmọ́ kí N̄g ṣàfi hànrẹ̀ (pẹ̀lú àwọn àmì kan. Àkókò náà wà fún) kí Á lè san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san n̄ǹkan tí ó ṣe níṣẹ́.

20:16

فَلَا يَصُدَّنَّكَ عَنۡهَا مَن لَّا يُؤۡمِنُ بِهَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ فَتَرۡدَىٰ ﴿16﴾

Transliteration: Fala yasuddannaka AAanha man la yuminu biha waittabaAAa hawahu fatarda

Translation: Nítorí náà, ẹni tí kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí ó sì tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ṣẹ́rí rẹ kúrò níbẹ̀, kí o má baà parun.

20:17

وَمَا تِلۡكَ بِيَمِينِكَ يَٰمُوسَىٰ ﴿17﴾

Transliteration: Wama tilka biyameenika ya moosa

Translation: Kí ni ìyẹn lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ, Mūsā?”

20:18

قَالَ هِيَ عَصَايَ أَتَوَكَّؤُاْ عَلَيۡهَا وَأَهُشُّ بِهَا عَلَىٰ غَنَمِي وَلِيَ فِيهَا مَـَٔارِبُ أُخۡرَىٰ ﴿18﴾

Transliteration: Qala hiya AAasaya atawakkao AAalayha waahushshu biha AAala ghanamee waliya feeha maaribu okhra

Translation: Ó sọ pé: “Ọ̀pá mi ni. Mò ń fi rọ̀gbọ̀kú. Mo tún ń fi já ewé fún àwọn àgùtàn mi. Mo sì tún ń lò ó fún àwọn bùkátà mìíràn.”

20:19

قَالَ أَلۡقِهَا يَٰمُوسَىٰ ﴿19﴾

Transliteration: Qala alqiha ya moosa

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Jù ú sílẹ̀, Mūsā.”

20:20

فَأَلۡقَىٰهَا فَإِذَا هِيَ حَيَّةٞ تَسۡعَىٰ ﴿20﴾

Transliteration: Faalqaha faitha hiya hayyatun tasAAa

Translation: Nígbà náà, ó jù ú sílẹ̀. Ó sì di ejò tó ń sáré.

20:21

قَالَ خُذۡهَا وَلَا تَخَفۡۖ سَنُعِيدُهَا سِيرَتَهَا ٱلۡأُولَىٰ ﴿21﴾

Transliteration: Qala khuthha wala takhaf sanuAAeeduha seerataha aloola

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Mú un dání, má sì ṣe bẹ̀rù. A máa dá a padà sí ìrísí rẹ̀ àkọ́kọ́.

20:22

وَٱضۡمُمۡ يَدَكَ إِلَىٰ جَنَاحِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٍ ءَايَةً أُخۡرَىٰ ﴿22﴾

Transliteration: Waodmum yadaka ila janahika takhruj baydaa min ghayri sooin ayatan okhra

Translation: Fi ọwọ́ rẹ mọ́ (abẹ́) apá rẹ, ó máa jáde ní funfun, tí kì í ṣe taburú. (Ó tún jẹ́) àmì mìíràn.

20:23

لِنُرِيَكَ مِنۡ ءَايَٰتِنَا ٱلۡكُبۡرَى ﴿23﴾

Transliteration: Linuriyaka min ayatina alkubra

Translation: Kí Á lè fi èyí tó tóbi nínú àwọn àmì Wa hàn ọ́.

20:24

ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ ﴿24﴾

Transliteration: Ithhab ila firAAawna innahu tagha

Translation: Lọ sí ọ̀dọ̀ Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.”

20:25

قَالَ رَبِّ ٱشۡرَحۡ لِي صَدۡرِي ﴿25﴾

Transliteration: Qala rabbi ishrah lee sadree

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, ṣí ọkàn mi payá fún mi.

20:26

وَيَسِّرۡ لِيٓ أَمۡرِي ﴿26﴾

Transliteration: Wayassir lee amree

Translation: Ṣọ̀rọ̀ mi dìrọ̀rùn fún mi.

20:27

وَٱحۡلُلۡ عُقۡدَةٗ مِّن لِّسَانِي ﴿27﴾

Transliteration: Waohlul AAuqdatan min lisanee

Translation: Tú kókó orí ahọ́n mi

20:28

يَفۡقَهُواْ قَوۡلِي ﴿28﴾

Transliteration: Yafqahoo qawlee

Translation: kí wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé.

20:29

وَٱجۡعَل لِّي وَزِيرٗا مِّنۡ أَهۡلِي ﴿29﴾

Transliteration: WaijAAal lee wazeeran min ahlee

Translation: Àti pé fún mi ní amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú àwọn ará ilé mi,

20:30

هَٰرُونَ أَخِي ﴿30﴾

Transliteration: Haroona akhee

Translation: Hārūn, arákùnrin mi ni.

20:31

ٱشۡدُدۡ بِهِۦٓ أَزۡرِي ﴿31﴾

Transliteration: Oshdud bihi azree

Translation: Fi kún mi lọ́wọ́.

20:32

وَأَشۡرِكۡهُ فِيٓ أَمۡرِي ﴿32﴾

Transliteration: Waashrikhu fee amree

Translation: Fi ṣakẹgbẹ́ mi nínú iṣẹ́ mi

20:33

كَيۡ نُسَبِّحَكَ كَثِيرٗا ﴿33﴾

Transliteration: Kay nusabbihaka katheeran

Translation: torí kí á lè ṣàfọ̀mọ́ (orúkọ) Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀,

20:34

وَنَذۡكُرَكَ كَثِيرًا ﴿34﴾

Transliteration: Wanathkuraka katheeran

Translation: kí á tún lè ṣèrántí Rẹ ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.

20:35

إِنَّكَ كُنتَ بِنَا بَصِيرٗا ﴿35﴾

Transliteration: Innaka kunta bina baseeran

Translation: Dájúdájú Ìwọ ń rí wa.”

20:36

قَالَ قَدۡ أُوتِيتَ سُؤۡلَكَ يَٰمُوسَىٰ ﴿36﴾

Transliteration: Qala qad ooteeta sulaka ya moosa

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú A ti fún ọ ní ìbéèrè rẹ, Mūsā.

20:37

وَلَقَدۡ مَنَنَّا عَلَيۡكَ مَرَّةً أُخۡرَىٰٓ ﴿37﴾

Transliteration: Walaqad mananna AAalayka marratan okhra

Translation: Àti pé dájúdájú A ti ṣe oore fún ọ nígbà kan rí.

20:38

إِذۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰٓ أُمِّكَ مَا يُوحَىٰٓ ﴿38﴾

Transliteration: Ith awhayna ila ommika ma yooha

Translation: (Rántí) nígbà tí A ṣípayá ohun tí A ṣípayá fún ìyá rẹ

20:39

أَنِ ٱقۡذِفِيهِ فِي ٱلتَّابُوتِ فَٱقۡذِفِيهِ فِي ٱلۡيَمِّ فَلۡيُلۡقِهِ ٱلۡيَمُّ بِٱلسَّاحِلِ يَأۡخُذۡهُ عَدُوّٞ لِّي وَعَدُوّٞ لَّهُۥۚ وَأَلۡقَيۡتُ عَلَيۡكَ مَحَبَّةٗ مِّنِّي وَلِتُصۡنَعَ عَلَىٰ عَيۡنِيٓ ﴿39﴾

Transliteration: Ani iqthifeehi fee alttabooti faiqthifeehi fee alyammi falyulqihi alyammu bialssahili yakhuthhu AAaduwwun lee waAAaduwwun lahu waalqaytu AAalayka mahabbatan minnee walitusnaAAa AAala AAaynee

Translation: pé: “Ju Mūsā sínú àpótí. Kí o sì gbé e jù sínú odò. Odò yó sì gbé e jù sí etí odò. Ọ̀tá Mi àti ọ̀tá rẹ̀ sì máa gbé e.” Mo sì da ìfẹ́ láti ọ̀dọ̀ Mi bò ọ́ nítorí kí wọ́n lè tọ́jú rẹ lójú Mi.”

20:40

إِذۡ تَمۡشِيٓ أُخۡتُكَ فَتَقُولُ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ مَن يَكۡفُلُهُۥۖ فَرَجَعۡنَٰكَ إِلَىٰٓ أُمِّكَ كَيۡ تَقَرَّ عَيۡنُهَا وَلَا تَحۡزَنَۚ وَقَتَلۡتَ نَفۡسٗا فَنَجَّيۡنَٰكَ مِنَ ٱلۡغَمِّ وَفَتَنَّـٰكَ فُتُونٗاۚ فَلَبِثۡتَ سِنِينَ فِيٓ أَهۡلِ مَدۡيَنَ ثُمَّ جِئۡتَ عَلَىٰ قَدَرٖ يَٰمُوسَىٰ ﴿40﴾

Transliteration: Ith tamshee okhtuka fataqoolu hal adullukum AAala man yakfuluhu farajaAAnaka ila ommika kay taqarra AAaynuha wala tahzana waqatalta nafsan fanajjaynaka mina alghammi wafatannaka futoonan falabithta sineena fee ahli madyana thumma jita AAala qadarin ya moosa

Translation: (Rántí) nígbà tí arábìnrin rẹ ń rìn lọ, ó sì ń sọ pé: “Ṣé kí n̄g júwe yín sí ẹni tí ó máa gbà á tọ́?” A sì dá ọ padà sọ́dọ̀ ìyá rẹ nítorí kí ó lè ní ìtutù ojú, àti pé kí ò má baà banújẹ́. Àti pé o pa ẹ̀mí ẹnì kan. A sì mú ọ kúrò nínú ìbànújẹ́. A tún mú àwọn àdánwò kan bá ọ. O tún lo àwọn ọdún kan lọ́dọ̀ àwọn ará Mọdyan. Lẹ́yìn náà, o dé (ní àkókò) tí ó ti wà nínú kádàrá, Mūsā.

20:41

وَٱصۡطَنَعۡتُكَ لِنَفۡسِي ﴿41﴾

Transliteration: WaistanaAAtuka linafsee

Translation: Mo sì ṣà ọ́ lẹ́ṣà fún (iṣẹ́) Mi.

20:42

ٱذۡهَبۡ أَنتَ وَأَخُوكَ بِـَٔايَٰتِي وَلَا تَنِيَا فِي ذِكۡرِي ﴿42﴾

Transliteration: Ithhab anta waakhooka biayatee wala taniya fee thikree

Translation: Lọ, ìwọ àti arákùnrin rẹ pẹ̀lú àwọn àmì (iṣẹ́ ìyanu) Mi. Kí ẹ sì má ṣe kọ́lẹ níbi ìrántí Mi.

20:43

ٱذۡهَبَآ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ ﴿43﴾

Transliteration: Ithhaba ila firAAawna innahu tagha

Translation: Ẹ lọ bá Fir‘aon. Dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.

20:44

فَقُولَا لَهُۥ قَوۡلٗا لَّيِّنٗا لَّعَلَّهُۥ يَتَذَكَّرُ أَوۡ يَخۡشَىٰ ﴿44﴾

Transliteration: Faqoola lahu qawlan layyinan laAAallahu yatathakkaru aw yakhsha

Translation: Ẹ sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀lẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kí ó lo ìṣítí tàbí kí ó páyà (Mi).”

20:45

قَالَا رَبَّنَآ إِنَّنَا نَخَافُ أَن يَفۡرُطَ عَلَيۡنَآ أَوۡ أَن يَطۡغَىٰ ﴿45﴾

Transliteration: Qala rabbana innana nakhafu an yafruta AAalayna aw an yatgha

Translation: Àwọn méjèèjì sọ pé: “Olúwa wa, dájúdájú àwa ń páyà pé ó má yára jẹ wá níyà tàbí pé ó má tayọ ẹnu-ààlà.”

20:46

قَالَ لَا تَخَافَآۖ إِنَّنِي مَعَكُمَآ أَسۡمَعُ وَأَرَىٰ ﴿46﴾

Transliteration: Qala la takhafa innanee maAAakuma asmaAAu waara

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Ẹ má ṣe páyà. Dájúdájú Èmi wà pẹ̀lú ẹ̀yin méjèèjì; Mò ń gbọ (yín), Mo sì ń ri (yín).”1

20:47

فَأۡتِيَاهُ فَقُولَآ إِنَّا رَسُولَا رَبِّكَ فَأَرۡسِلۡ مَعَنَا بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ وَلَا تُعَذِّبۡهُمۡۖ قَدۡ جِئۡنَٰكَ بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّكَۖ وَٱلسَّلَٰمُ عَلَىٰ مَنِ ٱتَّبَعَ ٱلۡهُدَىٰٓ ﴿47﴾

Transliteration: Fatiyahu faqoola inna rasoola rabbika faarsil maAAana banee israeela wala tuAAaththibhum qad jinaka biayatin min rabbika waalssalamu AAala mani ittabaAAa alhuda

Translation: Nítorí náà, ẹ lọ bá a, kí ẹ sọ fún un pé: “Dájúdájú Òjíṣẹ́ Olúwa rẹ ni àwa méjèèjì. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl máa bá wa lọ. Má ṣe fìyà jẹ wọ́n. Dájúdájú a ti mú àmì kan wá bá ọ láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kí àlàáfíà sì máa bá ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà náà.

20:48

إِنَّا قَدۡ أُوحِيَ إِلَيۡنَآ أَنَّ ٱلۡعَذَابَ عَلَىٰ مَن كَذَّبَ وَتَوَلَّىٰ ﴿48﴾

Transliteration: Inna qad oohiya ilayna anna alAAathaba AAala man kaththaba watawalla

Translation: Dájúdájú wọ́n ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí wa pé, dájúdájú ìyà ń bẹ fún ẹni tí ó bá pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.”

20:49

قَالَ فَمَن رَّبُّكُمَا يَٰمُوسَىٰ ﴿49﴾

Transliteration: Qala faman rabbukuma ya moosa

Translation: (Fir‘aon) wí pé: “Ta ni Olúwa ẹ̀yin méjèèjì, Mūsā?”

20:50

قَالَ رَبُّنَا ٱلَّذِيٓ أَعۡطَىٰ كُلَّ شَيۡءٍ خَلۡقَهُۥ ثُمَّ هَدَىٰ ﴿50﴾

Transliteration: Qala rabbuna allathee aAAta kulla shayin khalqahu thumma hada

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa wa ni Ẹni tí Ó fún gbogbo n̄ǹkan ní ìṣẹ̀dá rẹ̀.Lẹ́yìn náà, Ó tọ́ ọ sí ọ̀nà.”

20:51

قَالَ فَمَا بَالُ ٱلۡقُرُونِ ٱلۡأُولَىٰ ﴿51﴾

Transliteration: Qala fama balu alqurooni aloola

Translation: (Fir‘aon) wí pé: “Kí ló mú àwọn ìran àkọ́kọ́ (tí wọn kò fi mọ̀nà)?”

20:52

قَالَ عِلۡمُهَا عِندَ رَبِّي فِي كِتَٰبٖۖ لَّا يَضِلُّ رَبِّي وَلَا يَنسَى ﴿52﴾

Transliteration: Qala AAilmuha AAinda rabbee fee kitabin la yadillu rabbee wala yansa

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ìmọ̀ rẹ̀ wà nínú tírà kan lọ́dọ̀ Olúwa mi. Olúwa mi kò níí ṣàṣìṣe. Kò sì níí gbàgbé.

20:53

ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلۡأَرۡضَ مَهۡدٗا وَسَلَكَ لَكُمۡ فِيهَا سُبُلٗا وَأَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّن نَّبَاتٖ شَتَّىٰ ﴿53﴾

Transliteration: Allathee jaAAala lakumu alarda mahdan wasalaka lakum feeha subulan waanzala mina alssamai maan faakhrajna bihi azwajan min nabatin shatta

Translation: (Òun ni) Ẹni tí Ó tẹ́ ilẹ̀ ní pẹrẹsẹ fún yín. Ó sì la àwọn ọ̀nà sínú rẹ̀ fún yín. Ó sì sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A sì fi mú oríṣiríṣi jáde nínú àwọn irúgbìn ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

20:54

كُلُواْ وَٱرۡعَوۡاْ أَنۡعَٰمَكُمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ ﴿54﴾

Transliteration: Kuloo wairAAaw anAAamakum inna fee thalika laayatin liolee alnnuha

Translation: Ẹ jẹ, kí ẹ sì fi bọ́ àwọn ẹran-ọ̀sìn yín. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn onílàákàyè.

20:55

مِنۡهَا خَلَقۡنَٰكُمۡ وَفِيهَا نُعِيدُكُمۡ وَمِنۡهَا نُخۡرِجُكُمۡ تَارَةً أُخۡرَىٰ ﴿55﴾

Transliteration: Minha khalaqnakum wafeeha nuAAeedukum waminha nukhrijukum taratan okhra

Translation: Láti ara erùpẹ̀ ni A ti da yín. Inú rẹ̀ sì ni A óò da yín padà sí. Láti inú rẹ̀ sì ni A óò ti mu yín jáde padà nígbà mìíràn.”

20:56

وَلَقَدۡ أَرَيۡنَٰهُ ءَايَٰتِنَا كُلَّهَا فَكَذَّبَ وَأَبَىٰ ﴿56﴾

Transliteration: Walaqad araynahu ayatina kullaha fakaththaba waaba

Translation: Dájúdájú A ti fi àwọn àmì Wa hàn án, gbogbo rẹ̀. Àmọ́ ó pè é ní irọ́. Ó sì kọ̀ jálẹ̀.

20:57

قَالَ أَجِئۡتَنَا لِتُخۡرِجَنَا مِنۡ أَرۡضِنَا بِسِحۡرِكَ يَٰمُوسَىٰ ﴿57﴾

Transliteration: Qala ajitana litukhrijana min ardina bisihrika ya moosa

Translation: Ó wí pé: “Ṣé o wá bá wa nítorí kí o lè mú wa jáde kúrò lórí ilẹ̀ wa pẹ̀lú idán rẹ ni, Mūsā?

20:58

فَلَنَأۡتِيَنَّكَ بِسِحۡرٖ مِّثۡلِهِۦ فَٱجۡعَلۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكَ مَوۡعِدٗا لَّا نُخۡلِفُهُۥ نَحۡنُ وَلَآ أَنتَ مَكَانٗا سُوٗى ﴿58﴾

Transliteration: Falanatiyannaka bisihrin mithlihi faijAAal baynana wabaynaka mawAAidan la nukhlifuhu nahnu wala anta makanan suwan

Translation: Dájúdájú a máa mú idán irú rẹ̀ wá bá ọ. Nítorí náà, mú àyè àdéhùn ìpàdé láààrin àwa àti ìwọ, tí àwa àti ìwọ kò sì níí yapa rẹ̀, (kí ó jẹ́) àyè kan tí kò níí fì sọ́dọ̀ igun méjèèjì.”

20:59

قَالَ مَوۡعِدُكُمۡ يَوۡمُ ٱلزِّينَةِ وَأَن يُحۡشَرَ ٱلنَّاسُ ضُحٗى ﴿59﴾

Transliteration: Qala mawAAidukum yawmu alzzeenati waan yuhshara alnnasu duhan

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Àkókò ìpàdé yín ni ọjọ́ Ọ̀ṣọ́ (ìyẹn, ọjọ́ ọdún). Kí wọ́n sì kó àwọn ènìyàn jọ ní ìyálẹ̀ta.”

20:60

فَتَوَلَّىٰ فِرۡعَوۡنُ فَجَمَعَ كَيۡدَهُۥ ثُمَّ أَتَىٰ ﴿60﴾

Transliteration: Fatawalla firAAawnu fajamaAAa kaydahu thumma ata

Translation: Fir‘aon pẹ̀yìndà. Ó sì sa ète rẹ̀ jọ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, ó dé (síbẹ̀).

20:61

قَالَ لَهُم مُّوسَىٰ وَيۡلَكُمۡ لَا تَفۡتَرُواْ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا فَيُسۡحِتَكُم بِعَذَابٖۖ وَقَدۡ خَابَ مَنِ ٱفۡتَرَىٰ ﴿61﴾

Transliteration: Qala lahum moosa waylakum la taftaroo AAala Allahi kathiban fayushitakum biAAathabin waqad khaba mani iftara

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Ègbé yín ò! Ẹ má ṣe dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu nítorí kí Ó má baà fi ìyà pa yín rẹ́. Àti pé dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá dá àdápa irọ́ (mọ́ Allāhu) ti pòfo.”

20:62

فَتَنَٰزَعُوٓاْ أَمۡرَهُم بَيۡنَهُمۡ وَأَسَرُّواْ ٱلنَّجۡوَىٰ ﴿62﴾

Transliteration: FatanazaAAoo amrahum baynahum waasarroo alnnajwa

Translation: Wọ́n fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ láààrin ara wọn. Wọ́n sì tẹ̀ sọ̀rọ̀.

20:63

قَالُوٓاْ إِنۡ هَٰذَٰنِ لَسَٰحِرَٰنِ يُرِيدَانِ أَن يُخۡرِجَاكُم مِّنۡ أَرۡضِكُم بِسِحۡرِهِمَا وَيَذۡهَبَا بِطَرِيقَتِكُمُ ٱلۡمُثۡلَىٰ ﴿63﴾

Transliteration: Qaloo in hathani lasahirani yureedani an yukhrijakum min ardikum bisihrihima wayathhaba bitareeqatikumu almuthla

Translation: Wọ́n wí pé: “Dájúdájú àwọn méjèèjì yìí, òpìdán ni wọ́n o. Wọ́n fẹ́ mu yín jáde kúrò lórí ilẹ̀ yín pẹ̀lú idán wọn ni. Wọ́n sì (fẹ́) gba ojú ọ̀nà yín tó dára jùlọ mọ yín lọ́wọ́.

20:64

فَأَجۡمِعُواْ كَيۡدَكُمۡ ثُمَّ ٱئۡتُواْ صَفّٗاۚ وَقَدۡ أَفۡلَحَ ٱلۡيَوۡمَ مَنِ ٱسۡتَعۡلَىٰ ﴿64﴾

Transliteration: FaajmiAAoo kaydakum thumma itoo saffan waqad aflaha alyawma mani istaAAla

Translation: Nítorí náà, ẹ kó ète yín jọ papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, kí ẹ tò wá ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Dájúdájú ẹni tí ó bá borí ní òní ti jèrè.”

20:65

قَالُواْ يَٰمُوسَىٰٓ إِمَّآ أَن تُلۡقِيَ وَإِمَّآ أَن نَّكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَلۡقَىٰ ﴿65﴾

Transliteration: Qaloo ya moosa imma an tulqiya waimma an nakoona awwala man alqa

Translation: (Àwọn òpìdán) wí pé: “Mūsā, ìwọ ni o máa kọ́kọ́ ju (ọ̀pá sílẹ̀ ni) tàbí àwa ni a óò kọ́kọ́ jù ú sílẹ̀.”

20:66

قَالَ بَلۡ أَلۡقُواْۖ فَإِذَا حِبَالُهُمۡ وَعِصِيُّهُمۡ يُخَيَّلُ إِلَيۡهِ مِن سِحۡرِهِمۡ أَنَّهَا تَسۡعَىٰ ﴿66﴾

Transliteration: Qala bal alqoo faitha hibaluhum waAAisiyyuhum yukhayyalu ilayhi min sihrihim annaha tasAAa

Translation: (Mūsā) sọ pé: “Ẹ ju (tiyín) sílẹ̀ (ná).” Nígbà náà ni àwọn okùn wọn àti ọ̀pá wọn bá ń yíra padà lójú rẹ̀ nípasẹ̀ idán wọn, bí ẹni pé dájúdájú wọ́n ń sáré.

20:67

فَأَوۡجَسَ فِي نَفۡسِهِۦ خِيفَةٗ مُّوسَىٰ ﴿67﴾

Transliteration: Faawjasa fee nafsihi kheefatan moosa

Translation: Ìbẹ̀rù wọn sì mú (Ànábì) Mūsā.1

20:68

قُلۡنَا لَا تَخَفۡ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡأَعۡلَىٰ ﴿68﴾

Transliteration: Qulna la takhaf innaka anta alaAAla

Translation: A sọ pé: “Má ṣe páyà. Dájúdájú ìwọ, ìwọ lo máa lékè.

20:69

وَأَلۡقِ مَا فِي يَمِينِكَ تَلۡقَفۡ مَا صَنَعُوٓاْۖ إِنَّمَا صَنَعُواْ كَيۡدُ سَٰحِرٖۖ وَلَا يُفۡلِحُ ٱلسَّاحِرُ حَيۡثُ أَتَىٰ ﴿69﴾

Transliteration: Waalqi ma fee yameenika talqaf ma sanaAAoo innama sanaAAoo kaydu sahirin wala yuflihu alssahiru haythu ata

Translation: Ju ohun tí ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ sílẹ̀. Ó sì máa gbé ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mì káló. Dájúdájú ohun tí wọ́n ṣe kalẹ̀, ète òpìdán ni. Òpìdán kò sì níí jèrè ní ibikíbi tí ó bá dé.”

20:70

فَأُلۡقِيَ ٱلسَّحَرَةُ سُجَّدٗا قَالُوٓاْ ءَامَنَّا بِرَبِّ هَٰرُونَ وَمُوسَىٰ ﴿70﴾

Transliteration: Faolqiya alssaharatu sujjadan qaloo amanna birabbi haroona wamoosa

Translation: Nítorí náà, iṣẹ́ ìyanu (Ànábì Mūsā) mú àwọn òpìdán wó lulẹ̀, tí wọ́n forí kanlẹ̀ (fún Allāhu). Wọ́n wí pé: “A gbàgbọ́ nínú Olúwa Hārūn àti Mūsā.”

20:71

قَالَ ءَامَنتُمۡ لَهُۥ قَبۡلَ أَنۡ ءَاذَنَ لَكُمۡۖ إِنَّهُۥ لَكَبِيرُكُمُ ٱلَّذِي عَلَّمَكُمُ ٱلسِّحۡرَۖ فَلَأُقَطِّعَنَّ أَيۡدِيَكُمۡ وَأَرۡجُلَكُم مِّنۡ خِلَٰفٖ وَلَأُصَلِّبَنَّكُمۡ فِي جُذُوعِ ٱلنَّخۡلِ وَلَتَعۡلَمُنَّ أَيُّنَآ أَشَدُّ عَذَابٗا وَأَبۡقَىٰ ﴿71﴾

Transliteration: Qala amantum lahu qabla an athana lakum innahu lakabeerukumu allathee AAallamakumu alssihra falaoqattiAAanna aydiyakum waarjulakum min khilafin walaosallibannakum fee juthooAAi alnnakhli walataAAlamunna ayyuna ashaddu AAathaban waabqa

Translation: (Fir‘aon) wí pé: “Ṣé ẹ ti gbàfà fún un ṣíwájú kí èmi tó yọ̀ǹda fún yín? Dájúdájú òun ni àgbà yín tí ó kọ yín ní idán pípa. Nítorí náà, dájúdájú mo máa gé àwọn ọwọ́ yín àti ẹsẹ̀ yín ní ìpasípayọ. Dájúdájú mo tún máa kàn yín mọ́ àwọn igi dàbínù. Dájúdájú ẹ̀yin yóò mọ èwo nínú wa ni ìyà (rẹ̀) yóò le jùlọ, tí ó sì máa pẹ́ jùlọ.”

20:72

قَالُواْ لَن نُّؤۡثِرَكَ عَلَىٰ مَا جَآءَنَا مِنَ ٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلَّذِي فَطَرَنَاۖ فَٱقۡضِ مَآ أَنتَ قَاضٍۖ إِنَّمَا تَقۡضِي هَٰذِهِ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَآ ﴿72﴾

Transliteration: Qaloo lan nuthiraka AAala ma jaana mina albayyinati waallathee fatarana faiqdi ma anta qadin innama taqdee hathihi alhayata alddunya

Translation: (Àwọn òpìdán) sọ pé: “Àwa kò níí gbọ́lá fún ọ lórí ohun tí ó dé bá wa nínú àwọn ẹ̀rí tó dájú, (a kò sì níí gbọ́lá fún ọ lórí) Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá wa. Nítorí náà, dá ohun tí ó bá fẹ́ dá ní ẹjọ́. Ilé ayé yìí nìkan ni o ti lè dájọ́.

20:73

إِنَّآ ءَامَنَّا بِرَبِّنَا لِيَغۡفِرَ لَنَا خَطَٰيَٰنَا وَمَآ أَكۡرَهۡتَنَا عَلَيۡهِ مِنَ ٱلسِّحۡرِۗ وَٱللَّهُ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰٓ ﴿73﴾

Transliteration: Inna amanna birabbina liyaghfira lana khatayana wama akrahtana AAalayhi mina alssihri waAllahu khayrun waabqa

Translation: Dájúdájú àwa gbàgbọ́ nínú Olúwa wa nítorí kí Ó lè ṣe àforíjìn àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún wa àti ohun tí o jẹ wá nípá ṣe nínú idán pípa. Allāhu lóore jùlọ, Ó sì máa wà títí láéláé.

20:74

إِنَّهُۥ مَن يَأۡتِ رَبَّهُۥ مُجۡرِمٗا فَإِنَّ لَهُۥ جَهَنَّمَ لَا يَمُوتُ فِيهَا وَلَا يَحۡيَىٰ ﴿74﴾

Transliteration: Innahu man yati rabbahu mujriman fainna lahu jahannama la yamootu feeha wala yahya

Translation: Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá wá bá Olúwa rẹ̀ ní (ipò) ẹlẹ́ṣẹ̀, dájúdájú iná Jahanamọ ti wà fún un. Kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí wà lààyè.

20:75

وَمَن يَأۡتِهِۦ مُؤۡمِنٗا قَدۡ عَمِلَ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ فَأُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلدَّرَجَٰتُ ٱلۡعُلَىٰ ﴿75﴾

Transliteration: Waman yatihi muminan qad AAamila alssalihati faolaika lahumu alddarajatu alAAula

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá bá A (ní ipò) onígbàgbọ́ òdodo, tí ó sì ti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn ipò gíga ń bẹ fún.

20:76

جَنَّـٰتُ عَدۡنٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَاۚ وَذَٰلِكَ جَزَآءُ مَن تَزَكَّىٰ ﴿76﴾

Transliteration: Jannatu AAadnin tajree min tahtiha alanharu khalideena feeha wathalika jazao man tazakka

Translation: (Ohun ni) àwọn Ọgbà ìdẹ̀ra gbére tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Ìyẹn sì ni ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàfọ̀mọ́ (iṣẹ́ rẹ̀).”

20:77

وَلَقَدۡ أَوۡحَيۡنَآ إِلَىٰ مُوسَىٰٓ أَنۡ أَسۡرِ بِعِبَادِي فَٱضۡرِبۡ لَهُمۡ طَرِيقٗا فِي ٱلۡبَحۡرِ يَبَسٗا لَّا تَخَٰفُ دَرَكٗا وَلَا تَخۡشَىٰ ﴿77﴾

Transliteration: Walaqad awhayna ila moosa an asri biAAibadee faidrib lahum tareeqan fee albahri yabasan la takhafu darakan wala takhsha

Translation: Àti pé dájúdájú A ti fi ìmísí ránṣẹ́ sí (Ànábì) Mūsā báyìí pé: “Mú àwọn ẹrúsìn Mi rìn ní òru. Fi (ọ̀pá rẹ) na omi fún wọn (kí ó di) ojú ọ̀nà gbígbẹ nínú omi òkun. Má ṣe bẹ̀rù àlébá, má sì ṣe páyà (ìtẹ̀rì sínú omi òkun).”

20:78

فَأَتۡبَعَهُمۡ فِرۡعَوۡنُ بِجُنُودِهِۦ فَغَشِيَهُم مِّنَ ٱلۡيَمِّ مَا غَشِيَهُمۡ ﴿78﴾

Transliteration: FaatbaAAahum firAAawnu bijunoodihi faghashiyahum mina alyammi ma ghashiyahum

Translation: Fir‘aon sì tẹ̀lé wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ohun tí ó bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru nínú odò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ dáru.

20:79

وَأَضَلَّ فِرۡعَوۡنُ قَوۡمَهُۥ وَمَا هَدَىٰ ﴿79﴾

Transliteration: Waadalla firAAawnu qawmahu wama hada

Translation: Fir‘aon ṣi àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́nà; òun (náà) kò sì mọ̀nà.

20:80

يَٰبَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ قَدۡ أَنجَيۡنَٰكُم مِّنۡ عَدُوِّكُمۡ وَوَٰعَدۡنَٰكُمۡ جَانِبَ ٱلطُّورِ ٱلۡأَيۡمَنَ وَنَزَّلۡنَا عَلَيۡكُمُ ٱلۡمَنَّ وَٱلسَّلۡوَىٰ ﴿80﴾

Transliteration: Ya banee israeela qad anjaynakum min AAaduwwikum wawaAAadnakum janiba alttoori alaymana wanazzalna AAalaykumu almanna waalssalwa

Translation: Ẹ̀yin ọmọ ’Isrọ̄’īl, dájúdájú A ti gbà yín là lọ́wọ́ ọ̀tá yín. A sì ṣe àdéhùn fún yín (pé kí Ànábì Mūsā wá, kí Á bá a sọ̀rọ̀ tààrà) ní ẹ̀gbẹ́ àpáta ní ọwọ́ ọ̀tún(Ànábì Mūsā láààrin àpáta àti àfonífojì2 ní ìwọ̀ òòrùn3). A sì sọ ohun mímu mọnu àti ohun jíjẹ salwā kalẹ̀ fún yín.4

20:81

كُلُواْ مِن طَيِّبَٰتِ مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ وَلَا تَطۡغَوۡاْ فِيهِ فَيَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبِيۖ وَمَن يَحۡلِلۡ عَلَيۡهِ غَضَبِي فَقَدۡ هَوَىٰ ﴿81﴾

Transliteration: Kuloo min tayyibati ma razaqnakum wala tatghaw feehi fayahilla AAalaykum ghadabee waman yahlil AAalayhi ghadabee faqad hawa

Translation: Ẹ jẹ nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa tí A pa lésè fún yín. Ẹ má sì kọjá ẹnu ààlà nínú rẹ̀ nítorí kí ìbínú Mi má baà kò le yín lórí. Ẹnikẹ́ni tí ìbínú Mi bá sì kò lé lórí, dájúdájú ó ti jábọ́ (sínú ìparun).

20:82

وَإِنِّي لَغَفَّارٞ لِّمَن تَابَ وَءَامَنَ وَعَمِلَ صَٰلِحٗا ثُمَّ ٱهۡتَدَىٰ ﴿82﴾

Transliteration: Wainnee laghaffarun liman taba waamana waAAamila salihan thumma ihtada

Translation: Dájúdájú Èmi ni Aláforíjìn fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ronú pìwàdà, tí ó gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe iṣẹ́ rere, lẹ́yìn náà tí ó tún tẹ̀lé ìmọ̀nà.

20:83

وَمَآ أَعۡجَلَكَ عَن قَوۡمِكَ يَٰمُوسَىٰ ﴿83﴾

Transliteration: Wama aAAjalaka AAan qawmika ya moosa

Translation: Kí ni ó mú ọ kánjú ya àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀, Mūsā?

20:84

قَالَ هُمۡ أُوْلَآءِ عَلَىٰٓ أَثَرِي وَعَجِلۡتُ إِلَيۡكَ رَبِّ لِتَرۡضَىٰ ﴿84﴾

Transliteration: Qala hum olai AAala atharee waAAajiltu ilayka rabbi litarda

Translation: Ó sọ pé: “Àwọn nìwọ̀nyí tí wọ́n ń tọ orípa mi bọ̀ (lẹ́yìn mi). Èmi sì kánjú wá sọ́dọ̀ Rẹ nítorí kí O lè yọ́nú sí mi ni, Olúwa mi.”

20:85

قَالَ فَإِنَّا قَدۡ فَتَنَّا قَوۡمَكَ مِنۢ بَعۡدِكَ وَأَضَلَّهُمُ ٱلسَّامِرِيُّ ﴿85﴾

Transliteration: Qala fainna qad fatanna qawmaka min baAAdika waadallahumu alssamiriyyu

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Dájúdájú Àwa ti dán ìjọ rẹ wò lẹ́yìn rẹ. Àti pé Sāmiriy ṣì wọ́n lọ́nà.”

20:86

فَرَجَعَ مُوسَىٰٓ إِلَىٰ قَوۡمِهِۦ غَضۡبَٰنَ أَسِفٗاۚ قَالَ يَٰقَوۡمِ أَلَمۡ يَعِدۡكُمۡ رَبُّكُمۡ وَعۡدًا حَسَنًاۚ أَفَطَالَ عَلَيۡكُمُ ٱلۡعَهۡدُ أَمۡ أَرَدتُّمۡ أَن يَحِلَّ عَلَيۡكُمۡ غَضَبٞ مِّن رَّبِّكُمۡ فَأَخۡلَفۡتُم مَّوۡعِدِي ﴿86﴾

Transliteration: FarajaAAa moosa ila qawmihi ghadbana asifan qala ya qawmi alam yaAAidkum rabbukum waAAdan hasanan afatala AAalaykumu alAAahdu am aradtum an yahilla AAalaykum ghadabun min rabbikum faakhlaftum mawAAidee

Translation: (Ànábì) Mūsā sì padà sọ́dọ̀ ìjọ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú àti ìbànújẹ́. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ṣé Olúwa yín kò ti ba yín ṣe àdéhùn dáadáa ni? Ṣé àdéhùn ti pẹ́ jù lójú yín ni tàbí ẹ fẹ́ kí ìbínú kò le yín lórí láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ẹ fi yapa àdéhùn mi?”

20:87

قَالُواْ مَآ أَخۡلَفۡنَا مَوۡعِدَكَ بِمَلۡكِنَا وَلَٰكِنَّا حُمِّلۡنَآ أَوۡزَارٗا مِّن زِينَةِ ٱلۡقَوۡمِ فَقَذَفۡنَٰهَا فَكَذَٰلِكَ أَلۡقَى ٱلسَّامِرِيُّ ﴿87﴾

Transliteration: Qaloo ma akhlafna mawAAidaka bimalkina walakinna hummilna awzaran min zeenati alqawmi faqathafnaha fakathalika alqa alssamiriyyu

Translation: Wọ́n wí pé: “Àwa kò fínnúfíndọ̀ yapa àdéhùn fúnra wa, ṣùgbọ́n wọ́n di ẹrù ọ̀ṣọ́ àwọn ènìyàn (Misrọ) rù wá lọ́rùn. A sì jù ú sínú iná (pẹ̀lú àṣẹ Sāmiriyy). Báyẹn náà sì ni Sāmiriyy ṣe ju tirẹ̀.”

20:88

فَأَخۡرَجَ لَهُمۡ عِجۡلٗا جَسَدٗا لَّهُۥ خُوَارٞ فَقَالُواْ هَٰذَآ إِلَٰهُكُمۡ وَإِلَٰهُ مُوسَىٰ فَنَسِيَ ﴿88﴾

Transliteration: Faakhraja lahum AAijlan jasadan lahu khuwarun faqaloo hatha ilahukum wailahu moosa fanasiya

Translation: Ó sì (fi mọ) ọmọ màálù ọ̀bọrọgidi kan jáde fún wọn, tó ń dún (bíi màálù). Wọ́n sì wí pé: “Èyí ni ọlọ́hun yín àti ọlọ́hun Mūsā. Àmọ́ ó ti gbàgbé (rẹ̀).”

20:89

أَفَلَا يَرَوۡنَ أَلَّا يَرۡجِعُ إِلَيۡهِمۡ قَوۡلٗا وَلَا يَمۡلِكُ لَهُمۡ ضَرّٗا وَلَا نَفۡعٗا ﴿89﴾

Transliteration: Afala yarawna alla yarjiAAu ilayhim qawlan wala yamliku lahum darran wala nafAAan

Translation: Ṣé wọn kò rí i pé kò lè dá èsì ọ̀rọ̀ kan padà fún wọn ni, kò sì ní agbára láti kó ìnira tàbí àǹfààní kan bá wọn!

20:90

وَلَقَدۡ قَالَ لَهُمۡ هَٰرُونُ مِن قَبۡلُ يَٰقَوۡمِ إِنَّمَا فُتِنتُم بِهِۦۖ وَإِنَّ رَبَّكُمُ ٱلرَّحۡمَٰنُ فَٱتَّبِعُونِي وَأَطِيعُوٓاْ أَمۡرِي ﴿90﴾

Transliteration: Walaqad qala lahum haroonu min qablu ya qawmi innama futintum bihi wainna rabbakumu alrrahmanu faittabiAAoonee waateeAAoo amree

Translation: Àti pé dájúdájú Hārūn ti sọ fún wọn ṣíwájú pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, wọ́n kàn fi ṣe àdánwò fún yín ni. Dájúdájú Olúwa yín ni Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé mi. Kí ẹ sì tẹ̀lé àṣẹ mi.”

20:91

قَالُواْ لَن نَّبۡرَحَ عَلَيۡهِ عَٰكِفِينَ حَتَّىٰ يَرۡجِعَ إِلَيۡنَا مُوسَىٰ ﴿91﴾

Transliteration: Qaloo lan nabraha AAalayhi AAakifeena hatta yarjiAAa ilayna moosa

Translation: Wọ́n wí pé: “A ò níí yé dúró sọ́dọ̀ rẹ̀ tí a óò máa jọ́sìn fún un títí (Ànábì) Mūsā yóò fi padà sọ́dọ̀ wa.”

20:92

قَالَ يَٰهَٰرُونُ مَا مَنَعَكَ إِذۡ رَأَيۡتَهُمۡ ضَلُّوٓاْ ﴿92﴾

Transliteration: Qala ya haroonu ma manaAAaka ith raaytahum dalloo

Translation: (Ànábì) Mūsā sọ pé: “Hārūn, kí ni ó kọ̀ fún ọ nígbà tí o rí wọn tí wọ́n ṣìnà

20:93

أَلَّا تَتَّبِعَنِۖ أَفَعَصَيۡتَ أَمۡرِي ﴿93﴾

Transliteration: Alla tattabiAAani afaAAasayta amree

Translation: láti tọ̀ mí wá? Ṣé o yapa àṣẹ mi ni?”

20:94

قَالَ يَبۡنَؤُمَّ لَا تَأۡخُذۡ بِلِحۡيَتِي وَلَا بِرَأۡسِيٓۖ إِنِّي خَشِيتُ أَن تَقُولَ فَرَّقۡتَ بَيۡنَ بَنِيٓ إِسۡرَـٰٓءِيلَ وَلَمۡ تَرۡقُبۡ قَوۡلِي ﴿94﴾

Transliteration: Qala ya bna omma la takhuth bilihyatee wala birasee innee khasheetu an taqoola farraqta bayna banee israeela walam tarqub qawlee

Translation: (Ànábì Hārūn) sọ pé: “Ọmọ ìyá mi, má ṣe fi irungbọ̀n mi mú mi, (má ṣe fi irun) orí mi mú mi. Dájúdájú èmi páyà pé ó máa sọ pé: 'O dá òpínyà sílẹ̀ láààrin àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl. O ò sì ṣọ́ ọ̀rọ̀ mi.'“

20:95

قَالَ فَمَا خَطۡبُكَ يَٰسَٰمِرِيُّ ﴿95﴾

Transliteration: Qala fama khatbuka ya samiriyyu

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Kí ni ọ̀rọ̀ tìrẹ ti jẹ́, Sāmiriyy?”

20:96

قَالَ بَصُرۡتُ بِمَا لَمۡ يَبۡصُرُواْ بِهِۦ فَقَبَضۡتُ قَبۡضَةٗ مِّنۡ أَثَرِ ٱلرَّسُولِ فَنَبَذۡتُهَا وَكَذَٰلِكَ سَوَّلَتۡ لِي نَفۡسِي ﴿96﴾

Transliteration: Qala basurtu bima lam yabsuroo bihi faqabadtu qabdatan min athari alrrasooli fanabathtuha wakathalika sawwalat lee nafsee

Translation: (Sāmiriyy) wí pé: “Mo rí ohun tí wọn kò rí. Mo sì bu ẹ̀kúnwọ́ kan níbi (erùpẹ̀) ojú ẹsẹ̀ (ẹṣin) Òjíṣẹ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl). Mo sì dà á sílẹ̀ (láti fi mọ ère). Báyẹn ni ẹ̀mí mi ṣe (aburú) ní ọ̀ṣọ́ fún mi.”

20:97

قَالَ فَٱذۡهَبۡ فَإِنَّ لَكَ فِي ٱلۡحَيَوٰةِ أَن تَقُولَ لَا مِسَاسَۖ وَإِنَّ لَكَ مَوۡعِدٗا لَّن تُخۡلَفَهُۥۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰٓ إِلَٰهِكَ ٱلَّذِي ظَلۡتَ عَلَيۡهِ عَاكِفٗاۖ لَّنُحَرِّقَنَّهُۥ ثُمَّ لَنَنسِفَنَّهُۥ فِي ٱلۡيَمِّ نَسۡفًا ﴿97﴾

Transliteration: Qala faithhab fainna laka fee alhayati an taqoola la misasa wainna laka mawAAidan lan tukhlafahu waonthur ila ilahika allathee thalta AAalayhi AAakifan lanuharriqannahu thumma lanansifannahu fee alyammi nasfan

Translation: (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Nítorí náà, máa lọ. Dájúdájú (ìjìyà) rẹ nílé ayé yìí ni kí o máa wí pé, “Má fi ara kàn mí”. Àti pé dájúdájú ọjọ́ ìyà kan ń bẹ fún ọ tí wọn kò níí gbé fò ọ́. Kí o sì wo ọlọ́hun rẹ, èyí tí o takú tì lọ́rùn tí ò ń bọ, dájúdájú a máa dáná sun ún. Lẹ́yìn náà, dájúdájú a máa ku eérú rẹ̀ dànù pátápátá sínú odò.

20:98

إِنَّمَآ إِلَٰهُكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۚ وَسِعَ كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمٗا ﴿98﴾

Transliteration: Innama ilahukumu Allahu allathee la ilaha illa huwa wasiAAa kulla shayin AAilman

Translation: Ọlọ́hun yín ni Allāhu nìkan, ẹni tí kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Ó fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan.

20:99

كَذَٰلِكَ نَقُصُّ عَلَيۡكَ مِنۡ أَنۢبَآءِ مَا قَدۡ سَبَقَۚ وَقَدۡ ءَاتَيۡنَٰكَ مِن لَّدُنَّا ذِكۡرٗا ﴿99﴾

Transliteration: Kathalika naqussu AAalayka min anbai ma qad sabaqa waqad ataynaka min ladunna thikran

Translation: Báyẹn ni A ṣe ń sọ ìtàn fún ọ nínú àwọn ìró tí ó ti ṣíwájú. Láti ọ̀dọ̀ Wa sì ni A kúkú ti fún ọ ní ìrántí (ìyẹn, al-Ƙur’ān).

20:100

مَّنۡ أَعۡرَضَ عَنۡهُ فَإِنَّهُۥ يَحۡمِلُ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ وِزۡرًا ﴿100﴾

Transliteration: Man aAArada AAanhu fainnahu yahmilu yawma alqiyamati wizran

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí kúrò níbẹ̀, dájúdájú ó máa ru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde.

20:101

خَٰلِدِينَ فِيهِۖ وَسَآءَ لَهُمۡ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ حِمۡلٗا ﴿101﴾

Transliteration: Khalideena feehi wasaa lahum yawma alqiyamati himlan

Translation: Olùṣegbére ni wọ́n nínú (ìyà) rẹ̀. (Ẹrù ẹ̀ṣẹ̀) sì burú fún wọn láti rù ní Ọjọ́ Àjíǹde.

20:102

يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِۚ وَنَحۡشُرُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ يَوۡمَئِذٖ زُرۡقٗا ﴿102﴾

Transliteration: Yawma yunfakhu fee alssoori wanahshuru almujrimeena yawmaithin zurqan

Translation: Ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. A sí máa kó àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jọ ní ọjọ́ yẹn, tí ojú wọn yó sì dúdú batakun.

20:103

يَتَخَٰفَتُونَ بَيۡنَهُمۡ إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا عَشۡرٗا ﴿103﴾

Transliteration: Yatakhafatoona baynahum in labithtum illa AAashran

Translation: Wọn yó sì máa sọ̀rọ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ láààrin ara wọn pé: “Ẹ̀yin kò gbé ilé ayé tayọ (ọjọ́) mẹ́wàá.”

20:104

نَّحۡنُ أَعۡلَمُ بِمَا يَقُولُونَ إِذۡ يَقُولُ أَمۡثَلُهُمۡ طَرِيقَةً إِن لَّبِثۡتُمۡ إِلَّا يَوۡمٗا ﴿104﴾

Transliteration: Nahnu aAAlamu bima yaqooloona ith yaqoolu amthaluhum tareeqatan in labithtum illa yawman

Translation: Àwa nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí wọ́n ń wí nígbà tí ẹni tí ọpọlọ rẹ̀ pé jùlọ nínú wọn wí pé: “Ẹ kò gbé ilé ayé tayọ ọjọ́ kan.”

20:105

وَيَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلۡجِبَالِ فَقُلۡ يَنسِفُهَا رَبِّي نَسۡفٗا ﴿105﴾

Transliteration: Wayasaloonaka AAani aljibali faqul yansifuha rabbee nasfan

Translation: Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa àwọn àpáta. Sọ pé: “Olúwa mi yóò kù wọ́n dànù pátápátá.

20:106

فَيَذَرُهَا قَاعٗا صَفۡصَفٗا ﴿106﴾

Transliteration: Fayatharuha qaAAan safsafan

Translation: Nígbà náà, Ó máa fi wọ́n sílẹ̀ ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ gban̄sasa.

20:107

لَّا تَرَىٰ فِيهَا عِوَجٗا وَلَآ أَمۡتٗا ﴿107﴾

Transliteration: La tara feeha AAiwajan wala amtan

Translation: O ò sì níí rí ọ̀gbun tàbí gelemọ kan nínú rẹ̀.

20:108

يَوۡمَئِذٖ يَتَّبِعُونَ ٱلدَّاعِيَ لَا عِوَجَ لَهُۥۖ وَخَشَعَتِ ٱلۡأَصۡوَاتُ لِلرَّحۡمَٰنِ فَلَا تَسۡمَعُ إِلَّا هَمۡسٗا ﴿108﴾

Transliteration: Yawmaithin yattabiAAoona alddaAAiya la AAiwaja lahu wakhashaAAati alaswatu lilrrahmani fala tasmaAAu illa hamsan

Translation: Ní ọjọ́ yẹn, àwọn ènìyàn yóò tẹ̀lé olùpèpè náà, kò níí sí yíyà kúrò lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ohùn yó sì palọ́lọ́ fún Àjọkẹ́-ayé. Nítorí náà, o ò níí gbọ́ ohùn kan bí kò ṣe gìrìgìrì ẹsẹ̀.

20:109

يَوۡمَئِذٖ لَّا تَنفَعُ ٱلشَّفَٰعَةُ إِلَّا مَنۡ أَذِنَ لَهُ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَرَضِيَ لَهُۥ قَوۡلٗا ﴿109﴾

Transliteration: Yawmaithin la tanfaAAu alshshafaAAatu illa man athina lahu alrrahmanu waradiya lahu qawlan

Translation: Ní ọjọ́ yẹn, ìṣìpẹ̀ kò níí ṣe àǹfààní àfi ẹni tí Àjọkẹ́-ayé bá yọ̀ǹda fún, tí Ó sì yọ́nú sí ọ̀rọ̀ fún un.1

20:110

يَعۡلَمُ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيهِمۡ وَمَا خَلۡفَهُمۡ وَلَا يُحِيطُونَ بِهِۦ عِلۡمٗا ﴿110﴾

Transliteration: YaAAlamu ma bayna aydeehim wama khalfahum wala yuheetoona bihi AAilman

Translation: (Allāhu) mọ ohun tí ń bẹ níwájú wọn àti ohun tí ń bẹ ní ẹ̀yìn wọn. Àwọn kò sì fi ìmọ̀ rọkiri ká Rẹ̀.

20:111

وَعَنَتِ ٱلۡوُجُوهُ لِلۡحَيِّ ٱلۡقَيُّومِۖ وَقَدۡ خَابَ مَنۡ حَمَلَ ظُلۡمٗا ﴿111﴾

Transliteration: WaAAanati alwujoohu lilhayyi alqayyoomi waqad khaba man hamala thulman

Translation: Àwọn ojú yó sì wólẹ̀ fún Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá. Dájúdájú ẹnikẹ́ni tí ó bá di àbòsí mẹ́rù ti pòfo.

20:112

وَمَن يَعۡمَلۡ مِنَ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ وَهُوَ مُؤۡمِنٞ فَلَا يَخَافُ ظُلۡمٗا وَلَا هَضۡمٗا ﴿112﴾

Transliteration: Waman yaAAmal mina alssalihati wahuwa muminun fala yakhafu thulman wala hadman

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nínú àwọn iṣẹ́ rere, tí ó sì jẹ́ onígbàgbọ́ òdodo, kí ó má ṣe páyà àbòsí tàbí ìrẹ́jẹ kan (láti ọ̀dọ̀ Allāhu).

20:113

وَكَذَٰلِكَ أَنزَلۡنَٰهُ قُرۡءَانًا عَرَبِيّٗا وَصَرَّفۡنَا فِيهِ مِنَ ٱلۡوَعِيدِ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ أَوۡ يُحۡدِثُ لَهُمۡ ذِكۡرٗا ﴿113﴾

Transliteration: Wakathalika anzalnahu quranan AAarabiyyan wasarrafna feehi mina alwaAAeedi laAAallahum yattaqoona aw yuhdithu lahum thikran

Translation: Báyẹn ni A ṣe sọ (ìrántí) kalẹ̀ ní ohun kíké pẹ̀lú èdè Lárúbáwá. A sì ṣe àlàyé oníran-ànran ìlérí sínú rẹ̀ nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún ìyà) tàbí nítorí kí ó lè jẹ́ ìrántí fún wọn.

20:114

فَتَعَٰلَى ٱللَّهُ ٱلۡمَلِكُ ٱلۡحَقُّۗ وَلَا تَعۡجَلۡ بِٱلۡقُرۡءَانِ مِن قَبۡلِ أَن يُقۡضَىٰٓ إِلَيۡكَ وَحۡيُهُۥۖ وَقُل رَّبِّ زِدۡنِي عِلۡمٗا ﴿114﴾

Transliteration: FataAAala Allahu almaliku alhaqqu wala taAAjal bialqurani min qabli an yuqda ilayka wahyuhu waqul rabbi zidnee AAilman

Translation: Nítorí náà, Allāhu Ọba Òdodo ga jùlọ. Má ṣe kánjú pẹ̀lú al-Ƙur’ān ṣíwájú kí wọ́n tó parí ìmísí rẹ̀ fún ọ. Kí o sì sọ pé: “Olúwa mi, ṣàlékún ìmọ̀ fún mi.”

20:115

وَلَقَدۡ عَهِدۡنَآ إِلَىٰٓ ءَادَمَ مِن قَبۡلُ فَنَسِيَ وَلَمۡ نَجِدۡ لَهُۥ عَزۡمٗا ﴿115﴾

Transliteration: Walaqad AAahidna ila adama min qablu fanasiya walam najid lahu AAazman

Translation: Dájúdájú A ṣe àdéhùn fún (Ànábì) Ādam ṣíwájú. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé. A kò sì bá a pẹ̀lú ìpinnu ọkàn.

20:116

وَإِذۡ قُلۡنَا لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ ٱسۡجُدُواْ لِأٓدَمَ فَسَجَدُوٓاْ إِلَّآ إِبۡلِيسَ أَبَىٰ ﴿116﴾

Transliteration: Waith qulna lilmalaikati osjudoo liadama fasajadoo illa ibleesa aba

Translation: Nígbà tí A sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ẹ forí kanlẹ̀ kí Ādam. Wọ́n sì forí kanlẹ̀ kí i àfi ’Iblīs, (tí) ó kọ̀.”

20:117

فَقُلۡنَا يَـٰٓـَٔادَمُ إِنَّ هَٰذَا عَدُوّٞ لَّكَ وَلِزَوۡجِكَ فَلَا يُخۡرِجَنَّكُمَا مِنَ ٱلۡجَنَّةِ فَتَشۡقَىٰٓ ﴿117﴾

Transliteration: Faqulna ya adamu inna hatha AAaduwwun laka walizawjika fala yukhrijannakuma mina aljannati fatashqa

Translation: Nítorí náà, A sọ pé: “Ādam, dájúdájú èyí ni ọ̀tá fún ìwọ àti ìyàwó rẹ. Nítorí náà, kò gbọdọ̀ mú ẹ̀yin méjèèjì jáde kúrò nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra nítorí kí o má baà máa dààmú (fún ìjẹ-ìmu).

20:118

إِنَّ لَكَ أَلَّا تَجُوعَ فِيهَا وَلَا تَعۡرَىٰ ﴿118﴾

Transliteration: Inna laka alla tajooAAa feeha wala taAAra

Translation: Dájúdájú ebi kò níí pa ọ́, o ò sì níí rìn hòhò nínú rẹ̀.

20:119

وَأَنَّكَ لَا تَظۡمَؤُاْ فِيهَا وَلَا تَضۡحَىٰ ﴿119﴾

Transliteration: Waannaka la tathmao feeha wala tadha

Translation: Àti pé dájúdájú òǹgbẹ kò níí gbẹ ọ́ nínú rẹ̀, òòrùn kò sì níí pa ọ́.”

20:120

فَوَسۡوَسَ إِلَيۡهِ ٱلشَّيۡطَٰنُ قَالَ يَـٰٓـَٔادَمُ هَلۡ أَدُلُّكَ عَلَىٰ شَجَرَةِ ٱلۡخُلۡدِ وَمُلۡكٖ لَّا يَبۡلَىٰ ﴿120﴾

Transliteration: Fawaswasa ilayhi alshshaytanu qala ya adamu hal adulluka AAala shajarati alkhuldi wamulkin la yabla

Translation: Ṣùgbọ́n Èṣù kó ròyíròyí bá a; ó wí pé: “Ādam, ǹjẹ́ mo lè júwe rẹ sí igi gbére àti ìjọba tí kò níí tán?”

20:121

فَأَكَلَا مِنۡهَا فَبَدَتۡ لَهُمَا سَوۡءَٰتُهُمَا وَطَفِقَا يَخۡصِفَانِ عَلَيۡهِمَا مِن وَرَقِ ٱلۡجَنَّةِۚ وَعَصَىٰٓ ءَادَمُ رَبَّهُۥ فَغَوَىٰ ﴿121﴾

Transliteration: Faakala minha fabadat lahuma sawatuhuma watafiqa yakhsifani AAalayhima min waraqi aljannati waAAasa adamu rabbahu faghawa

Translation: Nítorí náà, àwọn méjèèjì jẹ nínú (èso) rẹ̀. Ìhòhò àwọn méjèèjì sì hàn síra wọn; àwọn méjèèjì sì bẹ̀rẹ̀ sí da ewé Ọgbà Ìdẹ̀ra bo ara wọn. Ādam yapa àṣẹ Olúwa rẹ̀. Ó sì ṣìnà.

20:122

ثُمَّ ٱجۡتَبَٰهُ رَبُّهُۥ فَتَابَ عَلَيۡهِ وَهَدَىٰ ﴿122﴾

Transliteration: Thumma ijtabahu rabbuhu fataba AAalayhi wahada

Translation: Lẹ́yìn náà, Olúwa rẹ̀ ṣà á lẹ́ṣà; Ó gba ìronúpìwàdà rẹ̀, Ó sì tọ́ ọ sí ọ̀nà.

20:123

قَالَ ٱهۡبِطَا مِنۡهَا جَمِيعَۢاۖ بَعۡضُكُمۡ لِبَعۡضٍ عَدُوّٞۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَنِ ٱتَّبَعَ هُدَايَ فَلَا يَضِلُّ وَلَا يَشۡقَىٰ ﴿123﴾

Transliteration: Qala ihbita minha jameeAAan baAAdukum libaAAdin AAaduwwun faimma yatiyannakum minnee hudan famani ittabaAAa hudaya fala yadillu wala yashqa

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Ẹ̀yin méjèèjì, ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ pátápátá. Apá kan yín sì jẹ́ ọ̀tá sí apá kan - ẹ̀yin àti Èṣù. Nígbà tí ìmọ̀nà bá sì dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, kò níí ṣìnà, kò sì níí ṣorí burúkú.

20:124

وَمَنۡ أَعۡرَضَ عَن ذِكۡرِي فَإِنَّ لَهُۥ مَعِيشَةٗ ضَنكٗا وَنَحۡشُرُهُۥ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ أَعۡمَىٰ ﴿124﴾

Transliteration: Waman aAArada AAan thikree fainna lahu maAAeeshatan dankan wanahshuruhu yawma alqiyamati aAAman

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ́rí kúrò níbi ìrántí Mi, dájúdájú ìṣẹ̀mí ìnira máa wà fún un. A sì máa gbé e dìde ní afọ́jú ní Ọjọ́ Àjíǹde.”

20:125

قَالَ رَبِّ لِمَ حَشَرۡتَنِيٓ أَعۡمَىٰ وَقَدۡ كُنتُ بَصِيرٗا ﴿125﴾

Transliteration: Qala rabbi lima hashartanee aAAma waqad kuntu baseeran

Translation: (Ó) máa wí pé: “Olúwa mi, nítorí kí ni O fi gbé mi dìde ní afọ́jú? Mo ti jẹ́ olùríran tẹ́lẹ̀!”

20:126

قَالَ كَذَٰلِكَ أَتَتۡكَ ءَايَٰتُنَا فَنَسِيتَهَاۖ وَكَذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمَ تُنسَىٰ ﴿126﴾

Transliteration: Qala kathalika atatka ayatuna fanaseetaha wakathalika alyawma tunsa

Translation: (Allāhu) sọ pé: “Báyẹn ni àwọn āyah Wa ṣe dé bá ọ, o sì gbàgbé rẹ̀ (o pa á tì). Ní òní, báyẹn ni wọ́n ṣe máa gbàgbé ìwọ náà (sínú Iná).

20:127

وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي مَنۡ أَسۡرَفَ وَلَمۡ يُؤۡمِنۢ بِـَٔايَٰتِ رَبِّهِۦۚ وَلَعَذَابُ ٱلۡأٓخِرَةِ أَشَدُّ وَأَبۡقَىٰٓ ﴿127﴾

Transliteration: Wakathalika najzee man asrafa walam yumin biayati rabbihi walaAAathabu alakhirati ashaddu waabqa

Translation: Àti pé báyẹn ni A ṣe ń san ẹ̀san fún ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àṣejù, tí kò sì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Olúwa rẹ̀. Dájúdájú ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn le jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.”

20:128

أَفَلَمۡ يَهۡدِ لَهُمۡ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا قَبۡلَهُم مِّنَ ٱلۡقُرُونِ يَمۡشُونَ فِي مَسَٰكِنِهِمۡۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّأُوْلِي ٱلنُّهَىٰ ﴿128﴾

Transliteration: Afalam yahdi lahum kam ahlakna qablahum mina alqurooni yamshoona fee masakinihim inna fee thalika laayatin liolee alnnuha

Translation: Ṣé kò hàn sí wọn pé mélòó mélòó nínú àwọn ìran tí A ti parun ṣíwájú wọn, tí (àwọn wọ̀nyí náà) sì ń rìn kọjá ní ibùgbé wọn! Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún àwọn olóye.

20:129

وَلَوۡلَا كَلِمَةٞ سَبَقَتۡ مِن رَّبِّكَ لَكَانَ لِزَامٗا وَأَجَلٞ مُّسَمّٗى ﴿129﴾

Transliteration: Walawla kalimatun sabaqat min rabbika lakana lizaman waajalun musamman

Translation: Tí kò bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ kan tó ṣíwájú àti gbèdéke àkókò kan lọ́dọ̀ Olúwa rẹ (ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn) ìbá ti di dandan.

20:130

فَٱصۡبِرۡ عَلَىٰ مَا يَقُولُونَ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ قَبۡلَ طُلُوعِ ٱلشَّمۡسِ وَقَبۡلَ غُرُوبِهَاۖ وَمِنۡ ءَانَآيِٕ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡ وَأَطۡرَافَ ٱلنَّهَارِ لَعَلَّكَ تَرۡضَىٰ ﴿130﴾

Transliteration: Faisbir AAala ma yaqooloona wasabbih bihamdi rabbika qabla tulooAAi alshshamsi waqabla ghuroobiha wamin anai allayli fasabbih waatrafa alnnahari laAAallaka tarda

Translation: Nítorí náà, ṣe sùúrù lórí ohun tí wọ́n ń wí, kí o sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa Rẹ ṣíwájú yíyọ òòrùn àti ṣíwájú wíwọ̀ rẹ̀. Ṣe àfọ̀mọ́ (fún Allāhu) ní àwọn àsìkò alẹ́ àti ní àwọn abala ọ̀sán nítorí kí (Á lè san ọ́ ní ẹ̀san rere tí) ó máa yọ́nú sí.

20:131

وَلَا تَمُدَّنَّ عَيۡنَيۡكَ إِلَىٰ مَا مَتَّعۡنَا بِهِۦٓ أَزۡوَٰجٗا مِّنۡهُمۡ زَهۡرَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَا لِنَفۡتِنَهُمۡ فِيهِۚ وَرِزۡقُ رَبِّكَ خَيۡرٞ وَأَبۡقَىٰ ﴿131﴾

Transliteration: Wala tamuddanna AAaynayka ila ma mattaAAna bihi azwajan minhum zahrata alhayati alddunya linaftinahum feehi warizqu rabbika khayrun waabqa

Translation: Má ṣe fẹjú rẹ sí ohun tí A fi ṣe ìgbádùn tó jẹ́ òdòdó ìṣẹ̀mí ilé ayé fún àwọn ìran-ìran kan nínú wọn. (A fún wọn) nítorí kí Á lè fi ṣe àdánwò fún wọn ni. Arísìkí Olúwa rẹ lóore jùlọ. Ó sì máa wà títí láéláé.

20:132

وَأۡمُرۡ أَهۡلَكَ بِٱلصَّلَوٰةِ وَٱصۡطَبِرۡ عَلَيۡهَاۖ لَا نَسۡـَٔلُكَ رِزۡقٗاۖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكَۗ وَٱلۡعَٰقِبَةُ لِلتَّقۡوَىٰ ﴿132﴾

Transliteration: Wamur ahlaka bialssalati waistabir AAalayha la nasaluka rizqan nahnu narzuquka waalAAaqibatu lilttaqwa

Translation: Pa ará ilé rẹ láṣẹ ìrun kíkí, kí o sì ṣe sùúrù lórí rẹ̀. A ò níí bèèrè èsè kan lọ́wọ́ rẹ; Àwa l’À ń pèsè fún ọ. Ìgbẹ̀yìn rere sì wà fún ìbẹ̀rù (Allāhu).

20:133

وَقَالُواْ لَوۡلَا يَأۡتِينَا بِـَٔايَةٖ مِّن رَّبِّهِۦٓۚ أَوَلَمۡ تَأۡتِهِم بَيِّنَةُ مَا فِي ٱلصُّحُفِ ٱلۡأُولَىٰ ﴿133﴾

Transliteration: Waqaloo lawla yateena biayatin min rabbihi awalam tatihim bayyinatu ma fee alssuhufi aloola

Translation: Wọ́n wí pé: “Nítorí kí ni kò fi mú àmì kan wá fún wa láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Ṣé ẹ̀rí tó yanjú tó wà nínú àwọn tákàdá àkọ́kọ́ kò dé bá wọn ni?

20:134

وَلَوۡ أَنَّآ أَهۡلَكۡنَٰهُم بِعَذَابٖ مِّن قَبۡلِهِۦ لَقَالُواْ رَبَّنَا لَوۡلَآ أَرۡسَلۡتَ إِلَيۡنَا رَسُولٗا فَنَتَّبِعَ ءَايَٰتِكَ مِن قَبۡلِ أَن نَّذِلَّ وَنَخۡزَىٰ ﴿134﴾

Transliteration: Walaw anna ahlaknahum biAAathabin min qablihi laqaloo rabbana lawla arsalta ilayna rasoolan fanattabiAAa ayatika min qabli an nathilla wanakhza

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú A ti fi ìyà kan pa wọ́n run ṣíwájú rẹ̀ ni, wọn ìbá wí pé: “Olúwa wa nítorí kí ni O ò ṣe rán Òjíṣẹ́ kan sí wa, àwa ìbá tẹ̀lé àwọn āyah Rẹ ṣíwájú kí á tó yẹpẹrẹ, (kí á sì tó) kàbùkù.”

20:135

قُلۡ كُلّٞ مُّتَرَبِّصٞ فَتَرَبَّصُواْۖ فَسَتَعۡلَمُونَ مَنۡ أَصۡحَٰبُ ٱلصِّرَٰطِ ٱلسَّوِيِّ وَمَنِ ٱهۡتَدَىٰ ﴿135﴾

Transliteration: Qul kullun mutarabbisun fatarabbasoo fasataAAlamoona man ashabu alssirati alssawiyyi wamani ihtada

Translation: Sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni olùretí (ìkángun).” Nítorí náà, ẹ máa retí (rẹ̀). Ẹ máa mọ ta ni èrò ọ̀nà tààrà àti ẹni tó mọ̀nà.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download