quranm◉

Surah Al-Fath transliteration

◉ Súrá · ∞

48:1

إِنَّا فَتَحۡنَا لَكَ فَتۡحٗا مُّبِينٗا ﴿1﴾

Transliteration: Inna fatahna laka fathan mubeenan

Translation: Dájúdájú Àwa ṣẹ́gun fún ọ ní ìṣẹ́gun tó fojú hàn

48:2

لِّيَغۡفِرَ لَكَ ٱللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِن ذَنۢبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَيَهۡدِيَكَ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا ﴿2﴾

Transliteration: Liyaghfira laka Allahu ma taqaddama min thanbika wama taakhkhara wayutimma niAAmatahu AAalayka wayahdiyaka siratan mustaqeeman

Translation: nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀),àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām),

48:3

وَيَنصُرَكَ ٱللَّهُ نَصۡرًا عَزِيزًا ﴿3﴾

Transliteration: Wayansuraka Allahu nasran AAazeezan

Translation: àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe tó lágbára.

48:4

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ لِيَزۡدَادُوٓاْ إِيمَٰنٗا مَّعَ إِيمَٰنِهِمۡۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا ﴿4﴾

Transliteration: Huwa allathee anzala alssakeenata fee quloobi almumineena liyazdadoo eemanan maAAa eemanihim walillahi junoodu alssamawati waalardi wakana Allahu AAaleeman hakeeman

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

48:5

لِّيُدۡخِلَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَٱلۡمُؤۡمِنَٰتِ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ خَٰلِدِينَ فِيهَا وَيُكَفِّرَ عَنۡهُمۡ سَيِّـَٔاتِهِمۡۚ وَكَانَ ذَٰلِكَ عِندَ ٱللَّهِ فَوۡزًا عَظِيمٗا ﴿5﴾

Transliteration: Liyudkhila almumineena waalmuminati jannatin tajree min tahtiha alanharu khalideena feeha wayukaffira AAanhum sayyiatihim wakana thalika AAinda Allahi fawzan AAatheeman

Translation: (Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún wọn) nítorí kí Ó lè mú àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́kùnrin àti onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ, olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀, àti nítorí kí Ó lè pa àwọn àṣìṣe wọn rẹ́. Ìyẹn sì jẹ́ èrèǹjẹ ńlá ní ọ̀dọ̀ Allāhu.

48:6

وَيُعَذِّبَ ٱلۡمُنَٰفِقِينَ وَٱلۡمُنَٰفِقَٰتِ وَٱلۡمُشۡرِكِينَ وَٱلۡمُشۡرِكَٰتِ ٱلظَّآنِّينَ بِٱللَّهِ ظَنَّ ٱلسَّوۡءِۚ عَلَيۡهِمۡ دَآئِرَةُ ٱلسَّوۡءِۖ وَغَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ وَلَعَنَهُمۡ وَأَعَدَّ لَهُمۡ جَهَنَّمَۖ وَسَآءَتۡ مَصِيرٗا ﴿6﴾

Transliteration: WayuAAaththiba almunafiqeena waalmunafiqati waalmushrikeena waalmushrikati alththanneena biAllahi thanna alssawi AAalayhim dairatu alssawi waghadiba Allahu AAalayhim walaAAanahum waaAAadda lahum jahannama wasaat maseeran

Translation: Àti nítorí kí Ó lè fìyà jẹ àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lóbìnrin, pẹ̀lú àwọn ọ̀ṣẹbọ lọ́kùnrin àti àwọn ọ̀ṣẹbọ lóbìnrin, àwọn eléròkérò nípa Allāhu ní ti èrò aburú. Àpadàsí aburú ń bẹ fún wọn. Allāhu ti bínú sí wọn. Ó ti ṣẹ́bi lé wọn. Ó sì ti pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ dè wọ́n. Ó sì burú ní ìkángun.

48:7

وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا ﴿7﴾

Transliteration: Walillahi junoodu alssamawati waalardi wakana Allahu AAazeezan hakeeman

Translation: Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

48:8

إِنَّآ أَرۡسَلۡنَٰكَ شَٰهِدٗا وَمُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا ﴿8﴾

Transliteration: Inna arsalnaka shahidan wamubashshiran wanatheeran

Translation: Dájúdájú Àwa rán ọ níṣẹ́ (pé kí o jẹ́) olùjẹ́rìí, oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀

48:9

لِّتُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتُعَزِّرُوهُ وَتُوَقِّرُوهُۚ وَتُسَبِّحُوهُ بُكۡرَةٗ وَأَصِيلًا ﴿9﴾

Transliteration: Lituminoo biAllahi warasoolihi watuAAazziroohu watuwaqqiroohu watusabbihoohu bukratan waaseelan

Translation: nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àti (nítorí kí) ẹ lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún (Òjíṣẹ́ náà) àti nítorí kí ẹ lè pàtàkì rẹ̀, àti nítorí kí ẹ lè ṣàfọ̀mọ́ fún (Allāhu) ní òwúrọ̀ àti ní ìrọ̀lẹ́.

48:10

إِنَّ ٱلَّذِينَ يُبَايِعُونَكَ إِنَّمَا يُبَايِعُونَ ٱللَّهَ يَدُ ٱللَّهِ فَوۡقَ أَيۡدِيهِمۡۚ فَمَن نَّكَثَ فَإِنَّمَا يَنكُثُ عَلَىٰ نَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ أَوۡفَىٰ بِمَا عَٰهَدَ عَلَيۡهُ ٱللَّهَ فَسَيُؤۡتِيهِ أَجۡرًا عَظِيمٗا ﴿10﴾

Transliteration: Inna allatheena yubayiAAoonaka innama yubayiAAoona Allaha yadu Allahi fawqa aydeehim faman nakatha fainnama yankuthu AAala nafsihi waman awfa bima AAahada AAalayhu Allaha fasayuteehi ajran AAatheeman

Translation: Dájúdájú àwọn tó ń ṣàdéhùn fún ọ (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun), dájúdájú Allāhu ni wọ́n ń ṣàdéhùn fún. Ọwọ́ Allāhu wà lókè ọwọ́ wọn.Ẹnikẹ́ni tí ó bá tú àdéhùn rẹ̀, ó tú u fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì mú àdéhùn tó ṣe fún Allāhu ṣẹ, (Allāhu) yóò fún un ní ẹ̀san ńlá.

48:11

سَيَقُولُ لَكَ ٱلۡمُخَلَّفُونَ مِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ شَغَلَتۡنَآ أَمۡوَٰلُنَا وَأَهۡلُونَا فَٱسۡتَغۡفِرۡ لَنَاۚ يَقُولُونَ بِأَلۡسِنَتِهِم مَّا لَيۡسَ فِي قُلُوبِهِمۡۚ قُلۡ فَمَن يَمۡلِكُ لَكُم مِّنَ ٱللَّهِ شَيۡـًٔا إِنۡ أَرَادَ بِكُمۡ ضَرًّا أَوۡ أَرَادَ بِكُمۡ نَفۡعَۢاۚ بَلۡ كَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ خَبِيرَۢا ﴿11﴾

Transliteration: Sayaqoolu laka almukhallafoona mina alaAArabi shaghalatna amwaluna waahloona faistaghfir lana yaqooloona bialsinatihim ma laysa fee quloobihim qul faman yamliku lakum mina Allahi shayan in arada bikum darran aw arada bikum nafAAan bal kana Allahu bima taAAmaloona khabeeran

Translation: Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn nínú àwọn Lárúbáwá oko yóò máa wí fún ọ pé: “Àwọn dúkìá wa àti àwọn ará ilé wa l’ó kó àìrójú bá wa. Nítorí náà, tọrọ àforíjìn fún wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn wí ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Sọ pé: “Ta ni ó ní ìkápá kiní kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá gbèrò (láti fi) ìnira kàn yín tàbí tí Ó bá gbèrò àǹfààní kan fún yín? Rárá (kò sí). Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

48:12

بَلۡ ظَنَنتُمۡ أَن لَّن يَنقَلِبَ ٱلرَّسُولُ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَ إِلَىٰٓ أَهۡلِيهِمۡ أَبَدٗا وَزُيِّنَ ذَٰلِكَ فِي قُلُوبِكُمۡ وَظَنَنتُمۡ ظَنَّ ٱلسَّوۡءِ وَكُنتُمۡ قَوۡمَۢا بُورٗا ﴿12﴾

Transliteration: Bal thanantum an lan yanqaliba alrrasoolu waalmuminoona ila ahleehim abadan wazuyyina thalika fee quloobikum wathanantum thanna alssawi wakuntum qawman booran

Translation: Rárá (kì í ṣe iṣẹ́ kan l’ó di yín lọ́wọ́ láti lọ jagun, àmọ́) ẹ ti lérò pé Òjíṣẹ́ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò níí padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn mọ́ láéláé. Wọ́n ṣe ìyẹn ni ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ẹ sì ro èrò aburú. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ìparun.

48:13

وَمَن لَّمۡ يُؤۡمِنۢ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ فَإِنَّآ أَعۡتَدۡنَا لِلۡكَٰفِرِينَ سَعِيرٗا ﴿13﴾

Transliteration: Waman lam yumin biAllahi warasoolihi fainna aAAtadna lilkafireena saAAeeran

Translation: Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Àwa ti pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́.

48:14

وَلِلَّهِ مُلۡكُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ يَغۡفِرُ لِمَن يَشَآءُ وَيُعَذِّبُ مَن يَشَآءُۚ وَكَانَ ٱللَّهُ غَفُورٗا رَّحِيمٗا ﴿14﴾

Transliteration: Walillahi mulku alssamawati waalardi yaghfiru liman yashao wayuAAaththibu man yashao wakana Allahu ghafooran raheeman

Translation: Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà.Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

48:15

سَيَقُولُ ٱلۡمُخَلَّفُونَ إِذَا ٱنطَلَقۡتُمۡ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأۡخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعۡكُمۡۖ يُرِيدُونَ أَن يُبَدِّلُواْ كَلَٰمَ ٱللَّهِۚ قُل لَّن تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمۡ قَالَ ٱللَّهُ مِن قَبۡلُۖ فَسَيَقُولُونَ بَلۡ تَحۡسُدُونَنَاۚ بَلۡ كَانُواْ لَا يَفۡقَهُونَ إِلَّا قَلِيلٗا ﴿15﴾

Transliteration: Sayaqoolu almukhallafoona itha intalaqtum ila maghanima litakhuthooha tharoona nattabiAAkum yureedoona an yubaddiloo kalama Allahi qul lan tattabiAAoona kathalikum qala Allahu min qablu fasayaqooloona bal tahsudoonana bal kanoo la yafqahoona illa qaleelan

Translation: Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni.(Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”2 Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.

48:16

قُل لِّلۡمُخَلَّفِينَ مِنَ ٱلۡأَعۡرَابِ سَتُدۡعَوۡنَ إِلَىٰ قَوۡمٍ أُوْلِي بَأۡسٖ شَدِيدٖ تُقَٰتِلُونَهُمۡ أَوۡ يُسۡلِمُونَۖ فَإِن تُطِيعُواْ يُؤۡتِكُمُ ٱللَّهُ أَجۡرًا حَسَنٗاۖ وَإِن تَتَوَلَّوۡاْ كَمَا تَوَلَّيۡتُم مِّن قَبۡلُ يُعَذِّبۡكُمۡ عَذَابًا أَلِيمٗا ﴿16﴾

Transliteration: Qul lilmukhallafeena mina alaAArabi satudAAawna ila qawmin olee basin shadeedin tuqatiloonahum aw yuslimoona fain tuteeAAoo yutikumu Allahu ajran hasanan wain tatawallaw kama tawallaytum min qablu yuAAaththibkum AAathaban aleeman

Translation: Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: “Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà gan-an. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fún yín ní ẹ̀san tó dára. Tí ẹ̀yin bá sì pẹ̀yìndà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe pẹ̀yìndà ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín.1

48:17

لَّيۡسَ عَلَى ٱلۡأَعۡمَىٰ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡأَعۡرَجِ حَرَجٞ وَلَا عَلَى ٱلۡمَرِيضِ حَرَجٞۗ وَمَن يُطِعِ ٱللَّهَ وَرَسُولَهُۥ يُدۡخِلۡهُ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُۖ وَمَن يَتَوَلَّ يُعَذِّبۡهُ عَذَابًا أَلِيمٗا ﴿17﴾

Transliteration: Laysa AAala alaAAma harajun wala AAala alaAAraji harajun wala AAala almareedi harajun waman yutiAAi Allaha warasoolahu yudkhilhu jannatin tajree min tahtiha alanharu waman yatawalla yuAAaththibhu AAathaban aleeman

Translation: Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn (tí wọn kò bá lọ sójú ogun). Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìndà, Ó máa jẹ ẹ́ ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

48:18

لَّقَدۡ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ يُبَايِعُونَكَ تَحۡتَ ٱلشَّجَرَةِ فَعَلِمَ مَا فِي قُلُوبِهِمۡ فَأَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ عَلَيۡهِمۡ وَأَثَٰبَهُمۡ فَتۡحٗا قَرِيبٗا ﴿18﴾

Transliteration: Laqad radiya Allahu AAani almumineena ith yubayiAAoonaka tahta alshshajarati faAAalima ma fee quloobihim faanzala alsakeenata AAalayhim waathabahum fathan qareeban

Translation: Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun Hudaebiyyah). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (ìyẹn ogun Hudaebiyyah)

48:19

وَمَغَانِمَ كَثِيرَةٗ يَأۡخُذُونَهَاۗ وَكَانَ ٱللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمٗا ﴿19﴾

Transliteration: Wamaghanima katheeratan yakhuthoonaha wakana Allahu AAazeezan hakeeman

Translation: àti àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí wọn yóò rí kó. Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

48:20

وَعَدَكُمُ ٱللَّهُ مَغَانِمَ كَثِيرَةٗ تَأۡخُذُونَهَا فَعَجَّلَ لَكُمۡ هَٰذِهِۦ وَكَفَّ أَيۡدِيَ ٱلنَّاسِ عَنكُمۡ وَلِتَكُونَ ءَايَةٗ لِّلۡمُؤۡمِنِينَ وَيَهۡدِيَكُمۡ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا ﴿20﴾

Transliteration: WaAAadakumu Allahu maghanima katheeratan takhuthoonaha faAAajjala lakum hathihi wakaffa aydiya alnnasi AAankum walitakoona ayatan lilmumineena wayahdiyakum siratan mustaqeeman

Translation: Àti pé Allāhu ṣàdéhùn àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí ẹ̀yin yóò rí kó fún yín. Ó sì tètè mú èyí wá fún yín. Ó tún kó àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ró fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ àmì kan fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ yín rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).

48:21

وَأُخۡرَىٰ لَمۡ تَقۡدِرُواْ عَلَيۡهَا قَدۡ أَحَاطَ ٱللَّهُ بِهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٗا ﴿21﴾

Transliteration: Waokhra lam taqdiroo AAalayha qad ahata Allahu biha wakana Allahu AAala kulli shayin qadeeran

Translation: Àti òmíràn tí ẹ kò lágbára lórí rẹ̀, (àmọ́ tí) Allāhu ti rọkiriká rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

48:22

وَلَوۡ قَٰتَلَكُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ لَوَلَّوُاْ ٱلۡأَدۡبَٰرَ ثُمَّ لَا يَجِدُونَ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا ﴿22﴾

Transliteration: Walaw qatalakumu allatheena kafaroo lawallawoo aladbara thumma la yajidoona waliyyan wala naseeran

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ gbógun dìde si yín ni, wọn ìbá pẹ̀yìndà (láti ságun fún yín). Lẹ́yìn náà, wọn kò níí rí aláàbò tàbí alárànṣe kan.

48:23

سُنَّةَ ٱللَّهِ ٱلَّتِي قَدۡ خَلَتۡ مِن قَبۡلُۖ وَلَن تَجِدَ لِسُنَّةِ ٱللَّهِ تَبۡدِيلٗا ﴿23﴾

Transliteration: Sunnata Allahi allatee qad khalat min qablu walan tajida lisunnati Allahi tabdeelan

Translation: Ìṣe Allāhu, èyí tó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀).

48:24

وَهُوَ ٱلَّذِي كَفَّ أَيۡدِيَهُمۡ عَنكُمۡ وَأَيۡدِيَكُمۡ عَنۡهُم بِبَطۡنِ مَكَّةَ مِنۢ بَعۡدِ أَنۡ أَظۡفَرَكُمۡ عَلَيۡهِمۡۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا ﴿24﴾

Transliteration: Wahuwa allathee kaffa aydiyahum AAankum waaydiyakum AAanhum bibatni makkata min baAAdi an athfarakum AAalayhim wakana Allahu bima taAAmaloona baseeran

Translation: Òun sì ni Ẹni tí Ó kó wọn lọ́wọ́ ró fún yín. Ó sì kó ẹ̀yin náà lọ́wọ́ ró fún wọn nínú ìlú Mọkkah lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti fi yín borí wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

48:25

هُمُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَصَدُّوكُمۡ عَنِ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِ وَٱلۡهَدۡيَ مَعۡكُوفًا أَن يَبۡلُغَ مَحِلَّهُۥۚ وَلَوۡلَا رِجَالٞ مُّؤۡمِنُونَ وَنِسَآءٞ مُّؤۡمِنَٰتٞ لَّمۡ تَعۡلَمُوهُمۡ أَن تَطَـُٔوهُمۡ فَتُصِيبَكُم مِّنۡهُم مَّعَرَّةُۢ بِغَيۡرِ عِلۡمٖۖ لِّيُدۡخِلَ ٱللَّهُ فِي رَحۡمَتِهِۦ مَن يَشَآءُۚ لَوۡ تَزَيَّلُواْ لَعَذَّبۡنَا ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ مِنۡهُمۡ عَذَابًا أَلِيمًا ﴿25﴾

Transliteration: Humu allatheena kafaroo wasaddookum AAani almasjidi alharami waalhadya maAAkoofan an yablugha mahillahu walawla rijalun muminoona wanisaon muminatun lam taAAlamoohum an tataoohum fatuseebakum minhum maAAarratun bighayri AAilmin liyudkhila Allahu fee rahmatihi man yashao law tazayyaloo laAAaththabna allatheena kafaroo minhum AAathaban aleeman

Translation: Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

48:26

إِذۡ جَعَلَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلۡحَمِيَّةَ حَمِيَّةَ ٱلۡجَٰهِلِيَّةِ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَىٰ رَسُولِهِۦ وَعَلَى ٱلۡمُؤۡمِنِينَ وَأَلۡزَمَهُمۡ كَلِمَةَ ٱلتَّقۡوَىٰ وَكَانُوٓاْ أَحَقَّ بِهَا وَأَهۡلَهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا ﴿26﴾

Transliteration: Ith jaAAala allatheena kafaroo fee quloobihimu alhamiyyata hamiyyata aljahiliyyati faanzala Allahu sakeenatahu AAala rasoolihi waAAala almumineena waalzamahum kalimata alttaqwa wakanoo ahaqqa biha waahlaha wakana Allahu bikulli shayin AAaleeman

Translation: (Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kó ìgbónára sínú ọkàn wọn ní ìgbónára ti ìgbà àìmọ̀kan, Allāhu sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù (Rẹ̀) wà pẹ̀lú wọn; Wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí i jùlọ, àwọn ni wọ́n sì ni ín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

48:27

لَّقَدۡ صَدَقَ ٱللَّهُ رَسُولَهُ ٱلرُّءۡيَا بِٱلۡحَقِّۖ لَتَدۡخُلُنَّ ٱلۡمَسۡجِدَ ٱلۡحَرَامَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ مُحَلِّقِينَ رُءُوسَكُمۡ وَمُقَصِّرِينَ لَا تَخَافُونَۖ فَعَلِمَ مَا لَمۡ تَعۡلَمُواْ فَجَعَلَ مِن دُونِ ذَٰلِكَ فَتۡحٗا قَرِيبًا ﴿27﴾

Transliteration: Laqad sadaqa Allahu rasoolahu alrruya bialhaqqi latadkhulunna almasjida alharama in shaa Allahu amineena muhalliqeena ruoosakum wamuqassireena la takhafoona faAAalima ma lam taAAlamoo fajaAAala min dooni thalika fathan qareeban

Translation: Dájúdájú Allāhu ti sọ àlá Òjíṣẹ́ Rẹ̀ di òdodo pé - tí Allāhu bá fẹ́ - dájúdájú ẹ̀yin yóò wọ inú Mọ́sálásí Haram ní ẹni ìfàyàbalẹ̀, ní ẹni tí ó máa fá irun orí yín, tí ẹ sì máa gé irun (orí yín mọ́lẹ̀), tí kò níí sí ìpáyà fún yín. Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ó tún ṣe ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (fún yín).

48:28

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلۡهُدَىٰ وَدِينِ ٱلۡحَقِّ لِيُظۡهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ شَهِيدٗا ﴿28﴾

Transliteration: Huwa allathee arsala rasoolahu bialhuda wadeeni alhaqqi liyuthhirahu AAala alddeeni kullihi wakafa biAllahi shaheedan

Translation: (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá. Allāhu sì tó ní Ẹlẹ́rìí.

48:29

مُّحَمَّدٞ رَّسُولُ ٱللَّهِۚ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ أَشِدَّآءُ عَلَى ٱلۡكُفَّارِ رُحَمَآءُ بَيۡنَهُمۡۖ تَرَىٰهُمۡ رُكَّعٗا سُجَّدٗا يَبۡتَغُونَ فَضۡلٗا مِّنَ ٱللَّهِ وَرِضۡوَٰنٗاۖ سِيمَاهُمۡ فِي وُجُوهِهِم مِّنۡ أَثَرِ ٱلسُّجُودِۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمۡ فِي ٱلتَّوۡرَىٰةِۚ وَمَثَلُهُمۡ فِي ٱلۡإِنجِيلِ كَزَرۡعٍ أَخۡرَجَ شَطۡـَٔهُۥ فَـَٔازَرَهُۥ فَٱسۡتَغۡلَظَ فَٱسۡتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِۦ يُعۡجِبُ ٱلزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ ٱلۡكُفَّارَۗ وَعَدَ ٱللَّهُ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَعَمِلُواْ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ مِنۡهُم مَّغۡفِرَةٗ وَأَجۡرًا عَظِيمَۢا ﴿29﴾

Transliteration: Muhammadun rasoolu Allahi waallatheena maAAahu ashiddao AAala alkuffari ruhamao baynahum tarahum rukkaAAan sujjadan yabtaghoona fadlan mina Allahi waridwanan seemahum fee wujoohihim min athari alssujoodi thalika mathaluhum fee alttawrati wamathaluhum fee alinjeeli kazarAAin akhraja shatahu faazarahu faistaghlatha faistawa AAala sooqihi yuAAjibu alzzurraAAa liyagheetha bihimu alkuffara waAAada Allahu allatheena amanoo waAAamiloo alssalihati minhum maghfiratan waajran AAatheeman

Translation: Muhammad ni Òjíṣẹ́ Allāhu. Àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́, aláàánú sì ni wọ́n láààrin ara wọn. O máa rí wọn ní olùdáwọ́tẹ-orúnkún àti olùforíkanlẹ̀ (lórí ìrun), tí wọ́n ń wá oore àjùlọ àti ìyọ́nú láti ọ̀dọ̀ Allāhu. Àmì wọn wà ní ojú wọn níbi orípa ìforíkanlẹ̀. Ìyẹn ni àpèjúwe wọn nínú Taorāh àti àpèjúwe wọn nínú ’Injīl, (wọ́n dà) gẹ́gẹ́ bí irúgbìn kan tó yọ ẹ̀ka rẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, ó fún un lágbára, ó nípọn, ó sì dúró gbagidi lórí igi rẹ̀. Ó sì ń jọ àwọn àgbẹ̀ lójú. (Allāhu fi àyè gba Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - àti àwọn Sọhābah rẹ̀) nítorí kí Ó lè fi wọ́n ṣe ohun ìbínú fún àwọn aláìgbàgbọ́. Allāhu ṣàdéhùn àforíjìn àti ẹ̀san ńlá fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere nínú wọn.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download