quranm◉

Surah Al-An'am transliteration

◉ Súrá · ∞

6:1

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ وَجَعَلَ ٱلظُّلُمَٰتِ وَٱلنُّورَۖ ثُمَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِرَبِّهِمۡ يَعۡدِلُونَ ﴿1﴾

Transliteration: Alhamdu lillahi allathee khalaqa alssamawati waalarda wajaAAala alththulumati waalnnoora thumma allatheena kafaroo birabbihim yaAAdiloona

Translation: Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,Ẹni tí Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó tún dá òkùnkùn àti ìmọ́lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.

6:2

هُوَ ٱلَّذِي خَلَقَكُم مِّن طِينٖ ثُمَّ قَضَىٰٓ أَجَلٗاۖ وَأَجَلٞ مُّسَمًّى عِندَهُۥۖ ثُمَّ أَنتُمۡ تَمۡتَرُونَ ﴿2﴾

Transliteration: Huwa allathee khalaqakum min teenin thumma qada ajalan waajalun musamman AAindahu thumma antum tamtaroona

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó da yín láti inú ẹrẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ó fi gbèdéke àkókó kan sí (ìṣẹ̀mí ayé yín). Àti pé gbèdéke àkókò kan (tún wà fún ayé) lọ́dọ̀ Rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣeyèméjì.

6:3

وَهُوَ ٱللَّهُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَفِي ٱلۡأَرۡضِ يَعۡلَمُ سِرَّكُمۡ وَجَهۡرَكُمۡ وَيَعۡلَمُ مَا تَكۡسِبُونَ ﴿3﴾

Transliteration: Wahuwa Allahu fee alssamawati wafee alardi yaAAlamu sirrakum wajahrakum wayaAAlamu ma taksiboona

Translation: Òun ni Allāhu (Ẹni tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo) nínú àwọn sánmọ̀ àti nínú ilẹ̀. Ó mọ ìkọ̀kọ̀ yín àti gban̄gba yín. Ó sì mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

6:4

وَمَا تَأۡتِيهِم مِّنۡ ءَايَةٖ مِّنۡ ءَايَٰتِ رَبِّهِمۡ إِلَّا كَانُواْ عَنۡهَا مُعۡرِضِينَ ﴿4﴾

Transliteration: Wama tateehim min ayatin min ayati rabbihim illa kanoo AAanha muAArideena

Translation: Kò sí āyah kan (àti àmì kan) tí ó máa dé bá wọn nínú àwọn āyah (àti àmì) Olúwa wọn, àfi kí wọ́n máa gbúnrí kúrò níbẹ̀.

6:5

فَقَدۡ كَذَّبُواْ بِٱلۡحَقِّ لَمَّا جَآءَهُمۡ فَسَوۡفَ يَأۡتِيهِمۡ أَنۢبَـٰٓؤُاْ مَا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ﴿5﴾

Transliteration: Faqad kaththaboo bialhaqqi lamma jaahum fasawfa yateehim anbao ma kanoo bihi yastahzioona

Translation: Wọ́n kúkú pe òdodo ní irọ́ nígbà tí ó dé bá wọn. Nítorí náà, láìpẹ́ àwọn ìró ohun tí wọ́n máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ ń bọ̀ wá bá wọn.

6:6

أَلَمۡ يَرَوۡاْ كَمۡ أَهۡلَكۡنَا مِن قَبۡلِهِم مِّن قَرۡنٖ مَّكَّنَّـٰهُمۡ فِي ٱلۡأَرۡضِ مَا لَمۡ نُمَكِّن لَّكُمۡ وَأَرۡسَلۡنَا ٱلسَّمَآءَ عَلَيۡهِم مِّدۡرَارٗا وَجَعَلۡنَا ٱلۡأَنۡهَٰرَ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهِمۡ فَأَهۡلَكۡنَٰهُم بِذُنُوبِهِمۡ وَأَنشَأۡنَا مِنۢ بَعۡدِهِمۡ قَرۡنًا ءَاخَرِينَ ﴿6﴾

Transliteration: Alam yaraw kam ahlakna min qablihim min qarnin makkannahum fee alardi ma lam numakkin lakum waarsalna alssamaa AAalayhim midraran wajaAAalna alanhara tajree min tahtihim faahlaknahum bithunoobihim waanshana min baAAdihim qarnan akhareena

Translation: Ṣé wọn kò wòye pé ó pọ̀ nínú àwọn ìran tí A ti parẹ́ ṣíwájú wọn? Àwọn tí A fún ní ipò lórí ilẹ̀, (irú) ipò tí A kò fún ẹ̀yin. A sì rọ omi òjò púpọ̀ fún wọn láti sánmọ̀. A sì ṣe àwọn odò tí ń ṣàn sí ìsàlẹ̀ (ilé) wọn. Lẹ́yìn náà, A pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. A sì dá àwọn ìran mìíràn lẹ́yìn wọn.

6:7

وَلَوۡ نَزَّلۡنَا عَلَيۡكَ كِتَٰبٗا فِي قِرۡطَاسٖ فَلَمَسُوهُ بِأَيۡدِيهِمۡ لَقَالَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّا سِحۡرٞ مُّبِينٞ ﴿7﴾

Transliteration: Walaw nazzalna AAalayka kitaban fee qirtasin falamasoohu biaydeehim laqala allatheena kafaroo in hatha illa sihrun mubeenun

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé A sọ tírà kan tí A kọ sínú tákàdá kalẹ̀ fún ọ, kí wọ́n sì fi ọwọ́ ara wọn gbá a mú (báyìí), dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ ìbá wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.”

6:8

وَقَالُواْ لَوۡلَآ أُنزِلَ عَلَيۡهِ مَلَكٞۖ وَلَوۡ أَنزَلۡنَا مَلَكٗا لَّقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ ثُمَّ لَا يُنظَرُونَ ﴿8﴾

Transliteration: Waqaloo lawla onzila AAalayhi malakun walaw anzalna malakan laqudiya alamru thumma la yuntharoona

Translation: Wọ́n sì wí pé: “Nítorí kí ni Wọn kò ṣe sọ mọlāika kan kalẹ̀ fún un?” Tí ó bá jẹ́ pé A sọ mọlāika kan kalẹ̀, ọ̀rọ̀ ìbá ti yanjú. Lẹ́yìn náà, A ò sì níí lọ́ wọn lára mọ́.

6:9

وَلَوۡ جَعَلۡنَٰهُ مَلَكٗا لَّجَعَلۡنَٰهُ رَجُلٗا وَلَلَبَسۡنَا عَلَيۡهِم مَّا يَلۡبِسُونَ ﴿9﴾

Transliteration: Walaw jaAAalnahu malakan lajaAAalnahu rajulan walalabasna AAalayhim ma yalbisoona

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé A ṣe é ní mọlāika ni, Àwa ìbá ṣe é ní ọkùnrin. Àti pé Àwa ìbá tún fi ohun tí wọ́n ń darú mọ́ra wọn lójú rú wọn lójú.1

6:10

وَلَقَدِ ٱسۡتُهۡزِئَ بِرُسُلٖ مِّن قَبۡلِكَ فَحَاقَ بِٱلَّذِينَ سَخِرُواْ مِنۡهُم مَّا كَانُواْ بِهِۦ يَسۡتَهۡزِءُونَ ﴿10﴾

Transliteration: Walaqadi istuhzia birusulin min qablika fahaqa biallatheena sakhiroo minhum ma kanoo bihi yastahzioona

Translation: Wọ́n kúkú ti fi àwọn Òjíṣẹ́ kan ṣe yẹ̀yẹ́ ṣíwájú rẹ! Nítorí náà, ohun tí wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ sì dìyà tó yí àwọn tó ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ po.

6:11

قُلۡ سِيرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ ثُمَّ ٱنظُرُواْ كَيۡفَ كَانَ عَٰقِبَةُ ٱلۡمُكَذِّبِينَ ﴿11﴾

Transliteration: Qul seeroo fee alardi thumma onthuroo kayfa kana AAaqibatu almukaththibeena

Translation: Sọ pé: “Ẹ rin orí ilẹ̀ lọ, lẹ́yìn náà kí ẹ wo báwo ni àtubọ̀tán àwọn tó ń pe òdodo nírọ́ ṣe rí.”

6:12

قُل لِّمَن مَّا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ قُل لِّلَّهِۚ كَتَبَ عَلَىٰ نَفۡسِهِ ٱلرَّحۡمَةَۚ لَيَجۡمَعَنَّكُمۡ إِلَىٰ يَوۡمِ ٱلۡقِيَٰمَةِ لَا رَيۡبَ فِيهِۚ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿12﴾

Transliteration: Qul liman ma fee alssamawati waalardi qul lillahi kataba AAala nafsihi alrrahmata layajmaAAannakum ila yawmi alqiyamati la rayba feehi allatheena khasiroo anfusahum fahum la yuminoona

Translation: Sọ pé: “Ti ta ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?” Sọ pé: “Ti Allāhu ni.” Ó ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí.Dájúdájú Ó máa ko yín jọ ní Ọjọ́ Àjíǹde, kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò níí gbàgbọ́.

6:13

وَلَهُۥ مَا سَكَنَ فِي ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿13﴾

Transliteration: Walahu ma sakana fee allayli waalnnahari wahuwa alssameeAAu alAAaleemu

Translation: TiRẹ̀ ni ohunkóhun tó ń bẹ nínú òru àti ọ̀sán. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

6:14

قُلۡ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَتَّخِذُ وَلِيّٗا فَاطِرِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَهُوَ يُطۡعِمُ وَلَا يُطۡعَمُۗ قُلۡ إِنِّيٓ أُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ أَوَّلَ مَنۡ أَسۡلَمَۖ وَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿14﴾

Transliteration: Qul aghayra Allahi attakhithu waliyyan fatiri alssamawati waalardi wahuwa yutAAimu wala yutAAamu qul innee omirtu an akoona awwala man aslama wala takoonanna mina almushrikeena

Translation: Sọ pé: “Ṣé kí n̄g mú olùrànlọ́wọ́ kan yàtọ̀ sí Allāhu, Ẹlẹ́dàá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀? Òun sì ni Ó ń bọ́ (ẹ̀dá), wọn kì í bọ́ Ọ.” Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n pa mí láṣẹ pé kí n̄g jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tí ó máa ṣe ’Islām (ní àsìkò tèmi).”Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wà nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.

6:15

قُلۡ إِنِّيٓ أَخَافُ إِنۡ عَصَيۡتُ رَبِّي عَذَابَ يَوۡمٍ عَظِيمٖ ﴿15﴾

Transliteration: Qul innee akhafu in AAasaytu rabbee AAathaba yawmin AAatheemin

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú èmi ń páyà ìyà Ọjọ́ Ńlá, tí mo bá fi lè yapa Olúwa mi.”

6:16

مَّن يُصۡرَفۡ عَنۡهُ يَوۡمَئِذٖ فَقَدۡ رَحِمَهُۥۚ وَذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡمُبِينُ ﴿16﴾

Transliteration: Man yusraf AAanhu yawmaithin faqad rahimahu wathalika alfawzu almubeenu

Translation: Ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá darí rẹ̀ kúrò níbi (ìyà) ní Ọjọ́ yẹn, (Allāhu) ti ṣàánú rẹ̀. Ìyẹn sì ni èrèǹjẹ pọ́nńbélé.

6:17

وَإِن يَمۡسَسۡكَ ٱللَّهُ بِضُرّٖ فَلَا كَاشِفَ لَهُۥٓ إِلَّا هُوَۖ وَإِن يَمۡسَسۡكَ بِخَيۡرٖ فَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿17﴾

Transliteration: Wain yamsaska Allahu bidurrin fala kashifa lahu illa huwa wain yamsaska bikhayrin fahuwa AAala kulli shayin qadeerun

Translation: Tí Allāhu bá fi ìnira kan kàn ọ́, kò sí ẹni tí ó lè mú un kúrò àfi Òun náà. Tí Ó bá sì mú oore kan bá ọ, Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.

6:18

وَهُوَ ٱلۡقَاهِرُ فَوۡقَ عِبَادِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ ﴿18﴾

Transliteration: Wahuwa alqahiru fawqa AAibadihi wahuwa alhakeemu alkhabeeru

Translation: Òun sì ni Olùborí tó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀. Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.1

6:19

قُلۡ أَيُّ شَيۡءٍ أَكۡبَرُ شَهَٰدَةٗۖ قُلِ ٱللَّهُۖ شَهِيدُۢ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۚ وَأُوحِيَ إِلَيَّ هَٰذَا ٱلۡقُرۡءَانُ لِأُنذِرَكُم بِهِۦ وَمَنۢ بَلَغَۚ أَئِنَّكُمۡ لَتَشۡهَدُونَ أَنَّ مَعَ ٱللَّهِ ءَالِهَةً أُخۡرَىٰۚ قُل لَّآ أَشۡهَدُۚ قُلۡ إِنَّمَا هُوَ إِلَٰهٞ وَٰحِدٞ وَإِنَّنِي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ ﴿19﴾

Transliteration: Qul ayyu shayin akbaru shahadatan quli Allahu shaheedun baynee wabaynakum waoohiya ilayya hatha alquranu lionthirakum bihi waman balagha ainnakum latashhadoona anna maAAa Allahi alihatan okhra qul la ashhadu qul innama huwa ilahun wahidun wainnanee bareeon mimma tushrikoona

Translation: Sọ pé: “Kí ni ohun tí ó tóbi jùlọ ní ẹ̀rí?” Sọ pé: “Allāhu ni Ẹlẹ́rìí láààrin èmi àti ẹ̀yin.” Ó sì fi ìmísí al-Ƙur’ān yìí ránṣẹ́ sí mi, nítorí kí n̄g lè fi ṣe ìkìlọ̀ fun ẹ̀yin àti ẹnikẹ́ni tí (al-Ƙur’ān) bá dé etí ìgbọ́ rẹ̀.Ṣé dájúdájú ẹ̀yin ń jẹ́rìí pé àwọn ọlọ́hun mìíràn tún wà pẹ̀lú Allāhu ni? Sọ pé: “Èmi kò níí jẹ́rìí bẹ́ẹ̀.” Sọ pé: “Òun nìkan ni Ọlọ́hun Ọ̀kan ṣoṣo tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo. Àti pé dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).”

6:20

ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَعۡرِفُونَهُۥ كَمَا يَعۡرِفُونَ أَبۡنَآءَهُمُۘ ٱلَّذِينَ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ فَهُمۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿20﴾

Transliteration: Allatheena ataynahumu alkitaba yaAArifoonahu kama yaAArifoona abnaahum allatheena khasiroo anfusahum fahum la yuminoona

Translation: Àwọn tí A fún ní Tírà, wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe mọ àwọn ọmọ wọn. Àwọn tó ṣe ẹ̀mí wọn lófò (sínú àìgbàgbọ́), wọn kò sí níí gbàgbọ́.1

6:21

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِهِۦٓۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿21﴾

Transliteration: Waman athlamu mimmani iftara AAala Allahi kathiban aw kaththaba biayatihi innahu la yuflihu alththalimoona

Translation: Ta l’ó sì ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí (ẹni tí) ó pe àwọn āyah Rẹ̀ nírọ́? Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.

6:22

وَيَوۡمَ نَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا ثُمَّ نَقُولُ لِلَّذِينَ أَشۡرَكُوٓاْ أَيۡنَ شُرَكَآؤُكُمُ ٱلَّذِينَ كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ ﴿22﴾

Transliteration: Wayawma nahshuruhum jameeAAan thumma naqoolu lillatheena ashrakoo ayna shurakaokumu allatheena kuntum tazAAumoona

Translation: Àti pé (rántí) Ọjọ́ tí A óò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà A óò sọ fún àwọn tó bá (Allāhu) wá akẹgbẹ́ pé: “Níbo ni àwọn òrìṣà yín wà, àwọn tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ pé wọ́n jẹ́ akẹgbẹ́ Allāhu?”

6:23

ثُمَّ لَمۡ تَكُن فِتۡنَتُهُمۡ إِلَّآ أَن قَالُواْ وَٱللَّهِ رَبِّنَا مَا كُنَّا مُشۡرِكِينَ ﴿23﴾

Transliteration: Thumma lam takun fitnatuhum illa an qaloo waAllahi rabbina ma kunna mushrikeena

Translation: Lẹ́yìn náà, ìfòòró wọn (lórí ìbéèrè náà) kò jẹ́ kiní kan tayọ pé wọ́n á wí pé: “A fi Allāhu Olúwa wa búra, àwa kì í ṣe ọ̀ṣẹbọ.”

6:24

ٱنظُرۡ كَيۡفَ كَذَبُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡۚ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ﴿24﴾

Transliteration: Onthur kayfa kathaboo AAala anfusihim wadalla AAanhum ma kanoo yaftaroona

Translation: Wo bí wọ́n ṣe parọ́ mọ́ra wọn. Ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.1

6:25

وَمِنۡهُم مَّن يَسۡتَمِعُ إِلَيۡكَۖ وَجَعَلۡنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمۡ أَكِنَّةً أَن يَفۡقَهُوهُ وَفِيٓ ءَاذَانِهِمۡ وَقۡرٗاۚ وَإِن يَرَوۡاْ كُلَّ ءَايَةٖ لَّا يُؤۡمِنُواْ بِهَاۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءُوكَ يُجَٰدِلُونَكَ يَقُولُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِنۡ هَٰذَآ إِلَّآ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ﴿25﴾

Transliteration: Waminhum man yastamiAAu ilayka wajaAAalna AAala quloobihim akinnatan an yafqahoohu wafee athanihim waqran wain yaraw kulla ayatin la yuminoo biha hatta itha jaooka yujadiloonaka yaqoolu allatheena kafaroo in hatha illa asateeru alawwaleena

Translation: Ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ní ọ̀dọ̀ rẹ ń bẹ nínú wọn. A sì fi èbìbò bo ọkàn wọn kí wọ́n má baà gbọ́ àgbọ́yé rẹ̀. (A tún fi) èdídí sínú etí wọn. Tí wọ́n bá rí gbogbo āyah (àmì), wọn kò níí gbà á gbọ́ débi pé nígbà tí wọ́n bá wá bá ọ, wọn yó sì máa bá ọ jiyàn; àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ sì máa wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́.”

6:26

وَهُمۡ يَنۡهَوۡنَ عَنۡهُ وَيَنۡـَٔوۡنَ عَنۡهُۖ وَإِن يُهۡلِكُونَ إِلَّآ أَنفُسَهُمۡ وَمَا يَشۡعُرُونَ ﴿26﴾

Transliteration: Wahum yanhawna AAanhu wayanawna AAanhu wain yuhlikoona illa anfusahum wama yashAAuroona

Translation: Àwọn ni wọ́n ń kọ̀ (fún àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -.), àwọn náà sì ń takété sí i. Wọn kò sì kó ìparun bá ẹnikẹ́ni bí kò ṣe ẹ̀mí ara wọn; wọn kò sì fura.

6:27

وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ وُقِفُواْ عَلَى ٱلنَّارِ فَقَالُواْ يَٰلَيۡتَنَا نُرَدُّ وَلَا نُكَذِّبَ بِـَٔايَٰتِ رَبِّنَا وَنَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿27﴾

Transliteration: Walaw tara ith wuqifoo AAala alnnari faqaloo ya laytana nuraddu wala nukaththiba biayati rabbina wanakoona mina almumineena

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró síbi Iná, wọ́n sì máa wí pé: “Yéè! Kí ó sì jẹ́ pé wọ́n dá wa padà (sílé ayé), àwa kò sì níí pe àwọn āyah Olúwa wa nírọ́ (mọ́), a sì máa wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

6:28

بَلۡ بَدَا لَهُم مَّا كَانُواْ يُخۡفُونَ مِن قَبۡلُۖ وَلَوۡ رُدُّواْ لَعَادُواْ لِمَا نُهُواْ عَنۡهُ وَإِنَّهُمۡ لَكَٰذِبُونَ ﴿28﴾

Transliteration: Bal bada lahum ma kanoo yukhfoona min qablu walaw ruddoo laAAadoo lima nuhoo AAanhu wainnahum lakathiboona

Translation: Kò rí bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń fi pamọ́ láti ẹ̀yìn wá ti hàn sí wọn ni. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n bá dá wọn padà (sílé ayé), wọn yóò kúkú padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Dájúdájú òpùrọ́ mà ni wọ́n.

6:29

وَقَالُوٓاْ إِنۡ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا ٱلدُّنۡيَا وَمَا نَحۡنُ بِمَبۡعُوثِينَ ﴿29﴾

Transliteration: Waqaloo in hiya illa hayatuna alddunya wama nahnu bimabAAootheena

Translation: Wọ́n wí pé: “Kí ni (ó tún ń jẹ́ ìṣẹ̀mí ọ̀run) bí kò ṣe ìṣẹ̀mí wa nílé ayé; Wọn kò sì níí gbé wa dìde (ní ọ̀run).”

6:30

وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذۡ وُقِفُواْ عَلَىٰ رَبِّهِمۡۚ قَالَ أَلَيۡسَ هَٰذَا بِٱلۡحَقِّۚ قَالُواْ بَلَىٰ وَرَبِّنَاۚ قَالَ فَذُوقُواْ ٱلۡعَذَابَ بِمَا كُنتُمۡ تَكۡفُرُونَ ﴿30﴾

Transliteration: Walaw tara ith wuqifoo AAala rabbihim qala alaysa hatha bialhaqqi qaloo bala warabbina qala fathooqoo alAAathaba bima kuntum takfuroona

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé o rí (wọn ni) nígbà tí wọ́n bá dá wọn dúró sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, Ó sì máa sọ pé: “Ṣé èyí kì í ṣe òdodo bí?” Wọ́n á sì wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (òdodo ni), Olúwa wa.” (Allāhu) sọ pé: “Nítorí náà, ẹ tọ́ Ìyà wò nítorí pé ẹ máa ń ṣàì gbàgbọ́.”

6:31

قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِلِقَآءِ ٱللَّهِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَتۡهُمُ ٱلسَّاعَةُ بَغۡتَةٗ قَالُواْ يَٰحَسۡرَتَنَا عَلَىٰ مَا فَرَّطۡنَا فِيهَا وَهُمۡ يَحۡمِلُونَ أَوۡزَارَهُمۡ عَلَىٰ ظُهُورِهِمۡۚ أَلَا سَآءَ مَا يَزِرُونَ ﴿31﴾

Transliteration: Qad khasira allatheena kaththaboo biliqai Allahi hatta itha jaathumu alssaAAatu baghtatan qaloo ya hasratana AAala ma farratna feeha wahum yahmiloona awzarahum AAala thuhoorihim ala saa ma yaziroona

Translation: Dájúdájú àwọn tó pe pípàdé Allāhu (lọ́run) nírọ́ ti ṣòfò débi pé nígbà tí Àkókò náà bá dé bá wọn lójijì, wọ́n á wí pé: “A ká àbámọ̀ lórí ohun tí a fi jáfira.” Wọ́n sì máa ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn sẹ́yìn wọn. Kíyè sí i, ohun tí wọn yóò rù lẹ́ṣẹ̀ sì burú.

6:32

وَمَا ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَآ إِلَّا لَعِبٞ وَلَهۡوٞۖ وَلَلدَّارُ ٱلۡأٓخِرَةُ خَيۡرٞ لِّلَّذِينَ يَتَّقُونَۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿32﴾

Transliteration: Wama alhayatu alddunya illa laAAibun walahwun walalddaru alakhirati khayrun lillatheena yattaqoona afala taAAqiloona

Translation: Ìṣẹ̀mí ayé kò jẹ́ kiní kan bí kò ṣe eré àti ìranù. Ọgbà Ìkẹ́yìn sì lóore jùlọ fún àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu). Ṣé ẹ ò ṣe làákàyè ni?

6:33

قَدۡ نَعۡلَمُ إِنَّهُۥ لَيَحۡزُنُكَ ٱلَّذِي يَقُولُونَۖ فَإِنَّهُمۡ لَا يُكَذِّبُونَكَ وَلَٰكِنَّ ٱلظَّـٰلِمِينَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ ﴿33﴾

Transliteration: Qad naAAlamu innahu layahzunuka allathee yaqooloona fainnahum la yukaththiboonaka walakinna alththalimeena biayati Allahi yajhadoona

Translation: A kúkú ti mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń wí ń bà ọ́ nínú jẹ́. Dájúdájú wọn kò lè pè ọ́ ní òpùrọ́, ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ń tako àwọn āyah Allāhu ni.

6:34

وَلَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ فَصَبَرُواْ عَلَىٰ مَا كُذِّبُواْ وَأُوذُواْ حَتَّىٰٓ أَتَىٰهُمۡ نَصۡرُنَاۚ وَلَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ وَلَقَدۡ جَآءَكَ مِن نَّبَإِيْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ﴿34﴾

Transliteration: Walaqad kuththibat rusulun min qablika fasabaroo AAala ma kuththiboo waoothoo hatta atahum nasruna wala mubaddila likalimati Allahi walaqad jaaka min nabai almursaleena

Translation: Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu.Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ.

6:35

وَإِن كَانَ كَبُرَ عَلَيۡكَ إِعۡرَاضُهُمۡ فَإِنِ ٱسۡتَطَعۡتَ أَن تَبۡتَغِيَ نَفَقٗا فِي ٱلۡأَرۡضِ أَوۡ سُلَّمٗا فِي ٱلسَّمَآءِ فَتَأۡتِيَهُم بِـَٔايَةٖۚ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ لَجَمَعَهُمۡ عَلَى ٱلۡهُدَىٰۚ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡجَٰهِلِينَ ﴿35﴾

Transliteration: Wain kana kabura AAalayka iAAraduhum faini istataAAta an tabtaghiya nafaqan fee alardi aw sullaman fee alssamai fatatiyahum biayatin walaw shaa Allahu lajamaAAahum AAala alhuda fala takoonanna mina aljahileena

Translation: Tí ó bá sì jẹ́ pé gbígbúnrí wọn lágbára lára rẹ, nígbà náà tí o bá lágbára láti wá ihò kan sínú (àjà) ilẹ̀, tàbí àkàbà kan sínú sánmọ̀ (ṣe bẹ́ẹ̀) kí o lè mú àmì kan wá fún wọn. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, dájúdájú ìbá kó wọn jọ papọ̀ sínú ìmọ̀nà(’Islām). Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn aláìmọ̀kan.

6:36

إِنَّمَا يَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ يَسۡمَعُونَۘ وَٱلۡمَوۡتَىٰ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ ثُمَّ إِلَيۡهِ يُرۡجَعُونَ ﴿36﴾

Transliteration: Innama yastajeebu allatheena yasmaAAoona waalmawta yabAAathuhumu Allahu thumma ilayhi yurjaAAoona

Translation: Ọ̀wọ́ ẹni tó ń jẹ́pè ni àwọn tó ń gbọ́rọ̀. (Ní ti) àwọn òkú, Allāhu yó gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí.

6:37

وَقَالُواْ لَوۡلَا نُزِّلَ عَلَيۡهِ ءَايَةٞ مِّن رَّبِّهِۦۚ قُلۡ إِنَّ ٱللَّهَ قَادِرٌ عَلَىٰٓ أَن يُنَزِّلَ ءَايَةٗ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ لَا يَعۡلَمُونَ ﴿37﴾

Transliteration: Waqaloo lawla nuzzila AAalayhi ayatun min rabbihi qul inna Allaha qadirun AAala an yunazzila ayatan walakinna aktharahum la yaAAlamoona

Translation: Wọ́n tún wí pé: “Nítorí kí ni wọn kò ṣe sọ àmì kan kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀?” Sọ pé: “Dájúdájú Allāhu lágbára láti sọ àmì kan kalẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni kò mọ̀.”

6:38

وَمَا مِن دَآبَّةٖ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَلَا طَـٰٓئِرٖ يَطِيرُ بِجَنَاحَيۡهِ إِلَّآ أُمَمٌ أَمۡثَالُكُمۚ مَّا فَرَّطۡنَا فِي ٱلۡكِتَٰبِ مِن شَيۡءٖۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يُحۡشَرُونَ ﴿38﴾

Transliteration: Wama min dabbatin fee alardi wala tairin yateeru bijanahayhi illa omamun amthalukum ma farratna fee alkitabi min shayin thumma ila rabbihim yuhsharoona

Translation: Kò sí ohun abẹ̀mí kan (tó ń rìn) lórí ilẹ̀, tàbí ẹyẹ kan tó ń fò pẹ̀lú apá rẹ̀ méjèèjì bí kò ṣe àwọn ẹ̀dá kan (bí) irú yín. A kò fi kiní kan sílẹ̀ (láì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀) sínú Tírà (ìyẹn, ummul-kitāb). Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni wọn yóò kó wọn jọ sí.

6:39

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا صُمّٞ وَبُكۡمٞ فِي ٱلظُّلُمَٰتِۗ مَن يَشَإِ ٱللَّهُ يُضۡلِلۡهُ وَمَن يَشَأۡ يَجۡعَلۡهُ عَلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿39﴾

Transliteration: Waallatheena kaththaboo biayatina summun wabukmun fee alththulumati man yashai Allahu yudlilhu waman yasha yajAAalhu AAala siratin mustaqeemin

Translation: Àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́, adití àti ayaya tó wà nínú àwọn òkùnkùn ni wọ́n. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa ṣì í lọ́nà. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́, Ó máa fi sójú ọ̀nà tààrà (’Islām).

6:40

قُلۡ أَرَءَيۡتَكُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُ ٱللَّهِ أَوۡ أَتَتۡكُمُ ٱلسَّاعَةُ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ تَدۡعُونَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿40﴾

Transliteration: Qul araaytakum in atakum AAathabu Allahi aw atatkumu alssaAAatu aghayra Allahi tadAAoona in kuntum sadiqeena

Translation: Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín tàbí tí Àkókò náà bá dé ba yín, ṣe n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn Allāhu ni ẹ̀yin máa pè, tí ẹ bá jẹ́ olódodo!”

6:41

بَلۡ إِيَّاهُ تَدۡعُونَ فَيَكۡشِفُ مَا تَدۡعُونَ إِلَيۡهِ إِن شَآءَ وَتَنسَوۡنَ مَا تُشۡرِكُونَ ﴿41﴾

Transliteration: Bal iyyahu tadAAoona fayakshifu ma tadAAoona ilayhi in shaa watansawna ma tushrikoona

Translation: Bẹ́ẹ̀ ni, Òun (nìkan) lẹ máa pè. Ó sì máa mú (ìnira) tí ẹ̀ ń pè É sí kúrò (fún yín) tí Ó bá fẹ́. Ẹ̀yin yó sì gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń fi ṣẹbọ sí I.

6:42

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡبَأۡسَآءِ وَٱلضَّرَّآءِ لَعَلَّهُمۡ يَتَضَرَّعُونَ ﴿42﴾

Transliteration: Walaqad arsalna ila omamin min qablika faakhathnahum bialbasai waalddarrai laAAallahum yatadarraAAoona

Translation: Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi àwọn ìpọ́njú àti àwọn àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).1

6:43

فَلَوۡلَآ إِذۡ جَآءَهُم بَأۡسُنَا تَضَرَّعُواْ وَلَٰكِن قَسَتۡ قُلُوبُهُمۡ وَزَيَّنَ لَهُمُ ٱلشَّيۡطَٰنُ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿43﴾

Transliteration: Falawla ith jaahum basuna tadarraAAoo walakin qasat quloobuhum wazayyana lahumu alshshaytanu ma kanoo yaAAmaloona

Translation: Wọn kò ṣe rawọ́ rasẹ̀ (sí Wa) nígbà tí ìyà Wa dé bá wọn! Ṣùgbọ́n ọkàn wọn le koko. Èṣù sì ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ ní ọ̀ṣọ́ fún wọn.

6:44

فَلَمَّا نَسُواْ مَا ذُكِّرُواْ بِهِۦ فَتَحۡنَا عَلَيۡهِمۡ أَبۡوَٰبَ كُلِّ شَيۡءٍ حَتَّىٰٓ إِذَا فَرِحُواْ بِمَآ أُوتُوٓاْ أَخَذۡنَٰهُم بَغۡتَةٗ فَإِذَا هُم مُّبۡلِسُونَ ﴿44﴾

Transliteration: Falamma nasoo ma thukkiroo bihi fatahna AAalayhim abwaba kulli shayin hatta itha farihoo bima ootoo akhathnahum baghtatan faitha hum mublisoona

Translation: Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbàgbé ohun tí A fi ṣe ìrántí fún wọn, A ṣí àwọn ọ̀nà gbogbo n̄ǹkan sílẹ̀ fún wọn, títí di ìgbà tí wọ́n yọ àyọ̀pọ̀rọ́ sí ohun tí A fún wọn (nínú oore ayé.), A sì mú wọn lójijì. Wọ́n sì di olùsọ̀rètínù.

6:45

فَقُطِعَ دَابِرُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْۚ وَٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿45﴾

Transliteration: FaqutiAAa dabiru alqawmi allatheena thalamoo waalhamdu lillahi rabbi alAAalameena

Translation: Nítorí náà, A pa ìjọ tó ṣàbòsí run pátápátá. Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu nìkan ṣoso, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.1

6:46

قُلۡ أَرَءَيۡتُمۡ إِنۡ أَخَذَ ٱللَّهُ سَمۡعَكُمۡ وَأَبۡصَٰرَكُمۡ وَخَتَمَ عَلَىٰ قُلُوبِكُم مَّنۡ إِلَٰهٌ غَيۡرُ ٱللَّهِ يَأۡتِيكُم بِهِۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ ثُمَّ هُمۡ يَصۡدِفُونَ ﴿46﴾

Transliteration: Qul araaytum in akhatha Allahu samAAakum waabsarakum wakhatama AAala quloobikum man ilahun ghayru Allahi yateekum bihi onthur kayfa nusarrifu alayati thumma hum yasdifoona

Translation: Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí Allāhu bá gba ìgbọ́rọ̀ yín àti ìríran yín, tí Ó sì di ọkàn yín pa, ọlọ́hun wo lẹ́yìn Allāhu ni ó máa mú un wá fún yín? Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sì ń gbúnrí (kúrò níbi òdodo)!

6:47

قُلۡ أَرَءَيۡتَكُمۡ إِنۡ أَتَىٰكُمۡ عَذَابُ ٱللَّهِ بَغۡتَةً أَوۡ جَهۡرَةً هَلۡ يُهۡلَكُ إِلَّا ٱلۡقَوۡمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿47﴾

Transliteration: Qul araaytakum in atakum AAathabu Allahi baghtatan aw jahratan hal yuhlaku illa alqawmu alththalimoona

Translation: Sọ pé: “Ẹ sọ fún mi, tí ìyà Allāhu bá dé ba yín ní òjijì tàbí ní ojúkojú, ṣé wọ́n máa pa ẹnì kan run bí kò ṣe ìjọ alábòsí!”

6:48

وَمَا نُرۡسِلُ ٱلۡمُرۡسَلِينَ إِلَّا مُبَشِّرِينَ وَمُنذِرِينَۖ فَمَنۡ ءَامَنَ وَأَصۡلَحَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ﴿48﴾

Transliteration: Wama nursilu almursaleena illa mubashshireena wamunthireena faman amana waaslaha fala khawfun AAalayhim wala hum yahzanoona

Translation: A kò rán àwọn Òjíṣẹ́ náà níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí wọ́n jẹ́) oníròó ìdùnnú àti olùkìlọ̀. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ ní òdodo, tí ó sì ṣe àtúnṣe (iṣẹ́ rẹ̀), kò níí sí ìbẹ̀rù fún wọn, wọn kò sì níí banújẹ́.

6:49

وَٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا يَمَسُّهُمُ ٱلۡعَذَابُ بِمَا كَانُواْ يَفۡسُقُونَ ﴿49﴾

Transliteration: Waallatheena kaththaboo biayatina yamassuhumu alAAathabu bima kanoo yafsuqoona

Translation: Àwọn tó sì pe àwọn āyah Wa nírọ́, ọwọ́ ìyà yóò tẹ̀ wọ́n nítorí pé wọ́n máa ń ṣèbàjẹ́.

6:50

قُل لَّآ أَقُولُ لَكُمۡ عِندِي خَزَآئِنُ ٱللَّهِ وَلَآ أَعۡلَمُ ٱلۡغَيۡبَ وَلَآ أَقُولُ لَكُمۡ إِنِّي مَلَكٌۖ إِنۡ أَتَّبِعُ إِلَّا مَا يُوحَىٰٓ إِلَيَّۚ قُلۡ هَلۡ يَسۡتَوِي ٱلۡأَعۡمَىٰ وَٱلۡبَصِيرُۚ أَفَلَا تَتَفَكَّرُونَ ﴿50﴾

Transliteration: Qul la aqoolu lakum AAindee khazainu Allahi wala aAAlamu alghayba wala aqoolu lakum innee malakun in attabiAAu illa ma yooha ilayya qul hal yastawee alaAAma waalbaseeru afala tatafakkaroona

Translation: Sọ pé: “Èmi kò sọ fún yín pé àwọn ilé-ọrọ̀ Allāhu wà lọ́dọ̀ mi, èmi kò sì nímọ̀ ìkọ̀kọ̀. Èmi kò sì sọ fún yín pé mọlāika kan ni mí. Èmi kò tẹ̀lé kiní kan àyàfi ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi ní ìmísí.” Sọ pé: “Ǹjẹ́ afọ́jú àti olùríran dọ́gba bí?Ṣé ẹ ò ronú jinlẹ̀ ni?”

6:51

وَأَنذِرۡ بِهِ ٱلَّذِينَ يَخَافُونَ أَن يُحۡشَرُوٓاْ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ لَيۡسَ لَهُم مِّن دُونِهِۦ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ لَّعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ ﴿51﴾

Transliteration: Waanthir bihi allatheena yakhafoona an yuhsharoo ila rabbihim laysa lahum min doonihi waliyyun wala shafeeAAun laAAallahum yattaqoona

Translation: Fi (al-Ƙur’ān) ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó ń páyà pé wọ́n máa kó àwọn jọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn, kò sì níí sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún wọn lẹ́yìn Rẹ̀.(Kìlọ̀ fún wọn) kí wọ́n lè bẹ̀rù (Allāhu).

6:52

وَلَا تَطۡرُدِ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ مَا عَلَيۡكَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَمَا مِنۡ حِسَابِكَ عَلَيۡهِم مِّن شَيۡءٖ فَتَطۡرُدَهُمۡ فَتَكُونَ مِنَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿52﴾

Transliteration: Wala tatrudi allatheena yadAAoona rabbahum bialghadati waalAAashiyyi yureedoona wajhahu ma AAalayka min hisabihim min shayin wama min hisabika AAalayhim min shayin fatatrudahum fatakoona mina alththalimeena

Translation: Má ṣe lé àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́ dànù; wọ́n ń fẹ́ Ojú rere Rẹ̀ ni. Ìṣirò-iṣẹ́ wọn kò sí ní ọrùn rẹ ní ọ̀nà kan kan. Kò sì sí ìṣirò-iṣẹ́ tìrẹ náà ní ọrùn wọn ní ọ̀nà kan kan. Tí o bá lé wọn dànù, o sì máa wà nínú àwọn alábòsí.1

6:53

وَكَذَٰلِكَ فَتَنَّا بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لِّيَقُولُوٓاْ أَهَـٰٓؤُلَآءِ مَنَّ ٱللَّهُ عَلَيۡهِم مِّنۢ بَيۡنِنَآۗ أَلَيۡسَ ٱللَّهُ بِأَعۡلَمَ بِٱلشَّـٰكِرِينَ ﴿53﴾

Transliteration: Wakathalika fatanna baAAdahum bibaAAdin liyaqooloo ahaolai manna Allahu AAalayhim min baynina alaysa Allahu biaAAlama bialshshakireena

Translation: Báyẹn ni A ṣe fi apá kan wọn ṣe àdánwò fún apá kan nítorí kí (àwọn aláìgbàgbọ́) lè wí pé: “Ṣé àwọn (mùsùlùmí aláìní) wọ̀nyí náà ni Allāhu ṣe ìdẹ̀ra (ìmọ̀nà) fún láààrin wa!?” Ṣé Allāhu kọ́ l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùdúpẹ́ ni?

6:54

وَإِذَا جَآءَكَ ٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِـَٔايَٰتِنَا فَقُلۡ سَلَٰمٌ عَلَيۡكُمۡۖ كَتَبَ رَبُّكُمۡ عَلَىٰ نَفۡسِهِ ٱلرَّحۡمَةَ أَنَّهُۥ مَنۡ عَمِلَ مِنكُمۡ سُوٓءَۢا بِجَهَٰلَةٖ ثُمَّ تَابَ مِنۢ بَعۡدِهِۦ وَأَصۡلَحَ فَأَنَّهُۥ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿54﴾

Transliteration: Waitha jaaka allatheena yuminoona biayatina faqul salamun AAalaykum kataba rabbukum AAala nafsihi alrrahmata annahu man AAamila minkum sooan bijahalatin thumma taba min baAAdihi waaslaha faannahu ghafoorun raheemun

Translation: Nígbà tí àwọn tó gba àwọn āyah Wa gbọ́ bá wá bá ọ, sọ (fún wọn) pé: “Kí àlàáfíà máa ba yín. Olúwa yín ṣe àánú ní ọ̀ran-anyàn léra Rẹ̀ lórí pé, dájúdájú ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá ṣe iṣẹ́ aburú pẹ̀lú àìmọ̀kan, lẹ́yìn náà, tí ó ronú pìwàdà lẹ́yìn rẹ̀, tí ó sì ṣe àtúnṣe, dájúdájú Òun ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”1

6:55

وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلِتَسۡتَبِينَ سَبِيلُ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ﴿55﴾

Transliteration: Wakathalika nufassilu alayati walitastabeena sabeelu almujrimeena

Translation: Báyẹn ni A ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah náà nítorí kí ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fojú hàn kedere.

6:56

قُلۡ إِنِّي نُهِيتُ أَنۡ أَعۡبُدَ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۚ قُل لَّآ أَتَّبِعُ أَهۡوَآءَكُمۡ قَدۡ ضَلَلۡتُ إِذٗا وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُهۡتَدِينَ ﴿56﴾

Transliteration: Qul innee nuheetu an aAAbuda allatheena tadAAoona min dooni Allahi qul la attabiAAu ahwaakum qad dalaltu ithan wama ana mina almuhtadeena

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú Wọ́n kọ̀ fún mi láti jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu.” Sọ pé: “Èmi kò níí tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ nígbà náà, mo ti ṣìnà, èmi kò sì sí nínú àwọn olùmọ̀nà (tí mo bá tẹ̀lé ìfẹ́-inú yín).”

6:57

قُلۡ إِنِّي عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَكَذَّبۡتُم بِهِۦۚ مَا عِندِي مَا تَسۡتَعۡجِلُونَ بِهِۦٓۚ إِنِ ٱلۡحُكۡمُ إِلَّا لِلَّهِۖ يَقُصُّ ٱلۡحَقَّۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلۡفَٰصِلِينَ ﴿57﴾

Transliteration: Qul innee AAala bayyinatin min rabbee wakaththabtum bihi ma AAindee ma tastaAAjiloona bihi ini alhukmu illa lillahi yaqussu alhaqqa wahuwa khayru alfasileena

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú mo wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, ẹ̀yin sì pè é nírọ́. Kò sí ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ní ọ̀dọ̀ mi. Kò sí ìdájọ́ náà (fún ẹnikẹ́ni) àyàfi fún Allāhu, Ẹni tí ń sọ (ìdájọ́) òdodo. Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”1

6:58

قُل لَّوۡ أَنَّ عِندِي مَا تَسۡتَعۡجِلُونَ بِهِۦ لَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُ بَيۡنِي وَبَيۡنَكُمۡۗ وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿58﴾

Transliteration: Qul law anna AAindee ma tastaAAjiloona bihi laqudiya alamru baynee wabaynakum waAllahu aAAlamu bialththalimeena

Translation: Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú ohun tí ẹ̀ ń wá pẹ̀lú ìkánjú ń bẹ ní ọ̀dọ̀ mi ni, Wọn ìbá ti ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà láààrin èmi àti ẹ̀yin. Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn alábòsí.”

6:59

وَعِندَهُۥ مَفَاتِحُ ٱلۡغَيۡبِ لَا يَعۡلَمُهَآ إِلَّا هُوَۚ وَيَعۡلَمُ مَا فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۚ وَمَا تَسۡقُطُ مِن وَرَقَةٍ إِلَّا يَعۡلَمُهَا وَلَا حَبَّةٖ فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡأَرۡضِ وَلَا رَطۡبٖ وَلَا يَابِسٍ إِلَّا فِي كِتَٰبٖ مُّبِينٖ ﴿59﴾

Transliteration: WaAAindahu mafatihu alghaybi la yaAAlamuha illa huwa wayaAAlamu ma fee albarri waalbahri wama tasqutu min waraqatin illa yaAAlamuha wala habbatin fee thulumati alardi wala ratbin wala yabisin illa fee kitabin mubeenin

Translation: Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ sì ni àwọn kọ́kọ́rọ́ ìkọ̀kọ̀ wà. Kò sí ẹni tó nímọ̀ rẹ̀ àfi Òun. Ó nímọ̀ ohun tí ń bẹ nínú ilẹ̀ àti odò. Ewé kan kò sì níí já bọ́ àfi kí Ó nímọ̀ rẹ̀. Kò sì sí kóró èso kan nínú òkùnkùn (inú) ilẹ̀, kò sí ohun tútù tàbí gbígbẹ kan àfi kí ó wà nínú àkọsílẹ̀ tó yanjú.

6:60

وَهُوَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُم بِٱلَّيۡلِ وَيَعۡلَمُ مَا جَرَحۡتُم بِٱلنَّهَارِ ثُمَّ يَبۡعَثُكُمۡ فِيهِ لِيُقۡضَىٰٓ أَجَلٞ مُّسَمّٗىۖ ثُمَّ إِلَيۡهِ مَرۡجِعُكُمۡ ثُمَّ يُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿60﴾

Transliteration: Wahuwa allathee yatawaffakum biallayli wayaAAlamu ma jarahtum bialnnahari thumma yabAAathukum feehi liyuqda ajalun musamman thumma ilayhi marjiAAukum thumma yunabbiokum bima kuntum taAAmaloona

Translation: Òun ni Ẹni tó ń kùn yín ní oorun ní alẹ́.Ó sì nímọ̀ nípa ohun tí ẹ ṣe níṣẹ́ ní ọ̀sán. Lẹ́yìn náà, Ó ń gbe yín dìde (fún ìjẹ-ìmu) ní (ọ̀sán) nítorí kí wọ́n lè parí gbèdéke àkókò kan. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ibùpadàsí yín. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

6:61

وَهُوَ ٱلۡقَاهِرُ فَوۡقَ عِبَادِهِۦۖ وَيُرۡسِلُ عَلَيۡكُمۡ حَفَظَةً حَتَّىٰٓ إِذَا جَآءَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ تَوَفَّتۡهُ رُسُلُنَا وَهُمۡ لَا يُفَرِّطُونَ ﴿61﴾

Transliteration: Wahuwa alqahiru fawqa AAibadihi wayursilu AAalaykum hafathatan hatta itha jaa ahadakumu almawtu tawaffathu rusuluna wahum la yufarritoona

Translation: Òun ni Olùborí tó wà lókè àwọn ẹrú Rẹ̀.Ó sì ń rán àwọn ẹ̀ṣọ́ kan (nínú àwọn mọlāikah) si yín títí di ìgbà tí ikú yóò fi dé bá ẹnì kọ̀ọ̀kan yín. Àwọn Òjíṣẹ́ wa yó sì gba ẹ̀mí rẹ̀, wọn kò sì níí jáfira.

6:62

ثُمَّ رُدُّوٓاْ إِلَى ٱللَّهِ مَوۡلَىٰهُمُ ٱلۡحَقِّۚ أَلَا لَهُ ٱلۡحُكۡمُ وَهُوَ أَسۡرَعُ ٱلۡحَٰسِبِينَ ﴿62﴾

Transliteration: Thumma ruddoo ila Allahi mawlahumu alhaqqi ala lahu alhukmu wahuwa asraAAu alhasibeena

Translation: Lẹ́yìn náà, wọ́n yóò dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ Allāhu Olúwa wọn Òdodo. Kíyè sí i, tiRẹ̀ ni ìdájọ́. Ó sì yára jùlọ nínú àwọn olùṣírò.1

6:63

قُلۡ مَن يُنَجِّيكُم مِّن ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِ تَدۡعُونَهُۥ تَضَرُّعٗا وَخُفۡيَةٗ لَّئِنۡ أَنجَىٰنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّـٰكِرِينَ ﴿63﴾

Transliteration: Qul man yunajjeekum min thulumati albarri waalbahri tadAAoonahu tadarruAAan wakhufyatan lain anjana min hathihi lanakoonanna mina alshshakireena

Translation: Sọ pé: “Ta ni ẹni tó ń gbà yín là nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò, Ẹni tí ẹ̀ ń pè pẹ̀lú ìrawọ́rasẹ̀ àti ní ìkọ̀kọ̀ pé: “Dájúdájú tí Ó bá gbà wá là nínú èyí, dájúdájú àwa yóò wà nínú àwọn olùdúpẹ́ (fún Un)?”

6:64

قُلِ ٱللَّهُ يُنَجِّيكُم مِّنۡهَا وَمِن كُلِّ كَرۡبٖ ثُمَّ أَنتُمۡ تُشۡرِكُونَ ﴿64﴾

Transliteration: Quli Allahu yunajjeekum minha wamin kulli karbin thumma antum tushrikoona

Translation: Sọ pé: “Allāhu l’Ó ń gbà yín là nínú rẹ̀ àti nínú gbogbo ìbànújẹ́. Lẹ́yìn náà, ẹ tún ń ṣẹbọ.”

6:65

قُلۡ هُوَ ٱلۡقَادِرُ عَلَىٰٓ أَن يَبۡعَثَ عَلَيۡكُمۡ عَذَابٗا مِّن فَوۡقِكُمۡ أَوۡ مِن تَحۡتِ أَرۡجُلِكُمۡ أَوۡ يَلۡبِسَكُمۡ شِيَعٗا وَيُذِيقَ بَعۡضَكُم بَأۡسَ بَعۡضٍۗ ٱنظُرۡ كَيۡفَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ لَعَلَّهُمۡ يَفۡقَهُونَ ﴿65﴾

Transliteration: Qul huwa alqadiru AAala an yabAAatha AAalaykum AAathaban min fawqikum aw min tahti arjulikum aw yalbisakum shiyaAAan wayutheeqa baAAdakum basa baAAdin onthur kayfa nusarrifu alayati laAAallahum yafqahoona

Translation: Sọ pé: “Ó lágbára láti fi ìyà ránṣẹ́ si yín láti òkè yín tàbí láti ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ yín, tàbí kí Ó dà yín pọ̀ mọ́ onírúurú ìjọ, nítorí kí Ó lè mu apá kan yín fìnira kan apá kan. Wo bí A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà nítorí kí wọ́n lè gbọ́ àgbọ́yé.”

6:66

وَكَذَّبَ بِهِۦ قَوۡمُكَ وَهُوَ ٱلۡحَقُّۚ قُل لَّسۡتُ عَلَيۡكُم بِوَكِيلٖ ﴿66﴾

Transliteration: Wakaththaba bihi qawmuka wahuwa alhaqqu qul lastu AAalaykum biwakeelin

Translation: Àwọn ènìyàn rẹ pe al-Ƙur’ān nírọ́! (Àmọ́) òdodo ni. Sọ pé: “Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.”

6:67

لِّكُلِّ نَبَإٖ مُّسۡتَقَرّٞۚ وَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ ﴿67﴾

Transliteration: Likulli nabain mustaqarrun wasawfa taAAlamoona

Translation: Gbogbo ìró (àsọtẹ́lẹ̀) l’ó máa wá sí ìmúṣẹ. Láìpẹ́ ẹ máa mọ̀.

6:68

وَإِذَا رَأَيۡتَ ٱلَّذِينَ يَخُوضُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا فَأَعۡرِضۡ عَنۡهُمۡ حَتَّىٰ يَخُوضُواْ فِي حَدِيثٍ غَيۡرِهِۦۚ وَإِمَّا يُنسِيَنَّكَ ٱلشَّيۡطَٰنُ فَلَا تَقۡعُدۡ بَعۡدَ ٱلذِّكۡرَىٰ مَعَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿68﴾

Transliteration: Waitha raayta allatheena yakhoodoona fee ayatina faaAArid AAanhum hatta yakhoodoo fee hadeethin ghayrihi waimma yunsiyannaka alshshaytanu fala taqAAud baAAda alththikra maAAa alqawmi alththalimeena

Translation: Nígbà tí o bá rí àwọn tó ń sọ ìsọkúsọ nípa àwọn āyah Wa, nígbà náà ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn títí wọn yóò fi bọ́ sínú ọ̀rọ̀ mìíràn. Tí Èṣù bá ń mú ọ gbàgbé (tẹ́lẹ̀), ní báyìí lẹ́yìn ìrántí má ṣe jókòó ti ìjọ alábòsí.

6:69

وَمَا عَلَى ٱلَّذِينَ يَتَّقُونَ مِنۡ حِسَابِهِم مِّن شَيۡءٖ وَلَٰكِن ذِكۡرَىٰ لَعَلَّهُمۡ يَتَّقُونَ ﴿69﴾

Transliteration: Wama AAala allatheena yattaqoona min hisabihim min shayin walakin thikra laAAallahum yattaqoona

Translation: Kiní kan nínú ìṣírò-iṣẹ́ wọn kò sí lọ́rùn àwọn tó ń bẹ̀rù (Allāhu), ṣùgbọ́n ìṣítí ni nítorí kí wọ́n lè ṣọ́ra (fún Iná).

6:70

وَذَرِ ٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ دِينَهُمۡ لَعِبٗا وَلَهۡوٗا وَغَرَّتۡهُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَاۚ وَذَكِّرۡ بِهِۦٓ أَن تُبۡسَلَ نَفۡسُۢ بِمَا كَسَبَتۡ لَيۡسَ لَهَا مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٞ وَلَا شَفِيعٞ وَإِن تَعۡدِلۡ كُلَّ عَدۡلٖ لَّا يُؤۡخَذۡ مِنۡهَآۗ أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ أُبۡسِلُواْ بِمَا كَسَبُواْۖ لَهُمۡ شَرَابٞ مِّنۡ حَمِيمٖ وَعَذَابٌ أَلِيمُۢ بِمَا كَانُواْ يَكۡفُرُونَ ﴿70﴾

Transliteration: Wathari allatheena ittakhathoo deenahum laAAiban walahwan wagharrathumu alhayatu alddunya wathakkir bihi an tubsala nafsun bima kasabat laysa laha min dooni Allahi waliyyun wala shafeeAAun wain taAAdil kulla AAadlin la yukhath minha olaika allatheena obsiloo bima kasaboo lahum sharabun min hameemin waAAathabun aleemun bima kanoo yakfuroona

Translation: Pa àwọn tó sọ ẹ̀sìn wọn di eré ṣíṣe àti ìranù tì. Ìṣẹ̀mí ayé sì tàn wọ́n jẹ. Fi al-Ƙur’ān ṣe ìṣítí nítorí kí wọ́n má baà fa ẹ̀mí kalẹ̀ sínú ìparun nípasẹ̀ ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (aburú). Kò sì sí aláàbò tàbí olùṣìpẹ̀ kan fún un lẹ́yìn Allāhu. Tí ó bá sì fi gbogbo ààrọ̀ ṣèràpadà, A ò níí gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí wọ́n fà kalẹ̀ fún ìparun nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Ohun mímu tó gbóná parí àti ìyà ẹlẹ́ta eléro ń bẹ fún wọn nítorí pé wọ́n máa ń ṣàì gbàgbọ́.

6:71

قُلۡ أَنَدۡعُواْ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُنَا وَلَا يَضُرُّنَا وَنُرَدُّ عَلَىٰٓ أَعۡقَابِنَا بَعۡدَ إِذۡ هَدَىٰنَا ٱللَّهُ كَٱلَّذِي ٱسۡتَهۡوَتۡهُ ٱلشَّيَٰطِينُ فِي ٱلۡأَرۡضِ حَيۡرَانَ لَهُۥٓ أَصۡحَٰبٞ يَدۡعُونَهُۥٓ إِلَى ٱلۡهُدَى ٱئۡتِنَاۗ قُلۡ إِنَّ هُدَى ٱللَّهِ هُوَ ٱلۡهُدَىٰۖ وَأُمِرۡنَا لِنُسۡلِمَ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿71﴾

Transliteration: Qul anadAAoo min dooni Allahi ma la yanfaAAuna wala yadurruna wanuraddu AAala aAAqabina baAAda ith hadana Allahu kaallathee istahwathu alshshayateenu fee alardi hayrana lahu ashabun yadAAoonahu ila alhuda itina qul inna huda Allahi huwa alhuda waomirna linuslima lirabbi alAAalameena

Translation: Sọ pé: “Ṣé a óò máa pè lẹ́yìn Allāhu, ohun tí kò lè ṣe wá ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira bá wa; (ṣé) kí wọ́n tún dá wa padà sí ẹsẹ̀-àárọ̀ wa lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti fi ọ̀nà mọ̀ wá (kí á lè dà) bí ẹni tí àwọn èṣù tàn lọ (sínú igbó), ó sì ń dààmú kiri lórí ilẹ̀, ó sì kúkú ní àwọn ọ̀rẹ́ (alábàárìn) kan tí wọ́n ń pè é sí ọ̀nà (ilé) pé, “Máa bọ̀ wá bá wa.” (àmọ́ kò gbọ́ mọ́). Sọ pé: “Dájúdájú ìmọ̀nà ti Allāhu (’Islām), òhun ni ìmọ̀nà. Wọ́n sì pa wá láṣẹ pé kí á gba ẹ̀sìn ’Islām nítorí ti Olúwa gbogbo ẹ̀dá.”

6:72

وَأَنۡ أَقِيمُواْ ٱلصَّلَوٰةَ وَٱتَّقُوهُۚ وَهُوَ ٱلَّذِيٓ إِلَيۡهِ تُحۡشَرُونَ ﴿72﴾

Transliteration: Waan aqeemoo alssalata waittaqoohu wahuwa allathee ilayhi tuhsharoona

Translation: Àti pé kí ẹ kírun, kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu. Òun ni Ẹni tí wọ́n yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

6:73

وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ بِٱلۡحَقِّۖ وَيَوۡمَ يَقُولُ كُن فَيَكُونُۚ قَوۡلُهُ ٱلۡحَقُّۚ وَلَهُ ٱلۡمُلۡكُ يَوۡمَ يُنفَخُ فِي ٱلصُّورِۚ عَٰلِمُ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِۚ وَهُوَ ٱلۡحَكِيمُ ٱلۡخَبِيرُ ﴿73﴾

Transliteration: Wahuwa allathee khalaqa alssamawati waalarda bialhaqqi wayawma yaqoolu kun fayakoonu qawluhu alhaqqu walahu almulku yawma yunfakhu fee alssoori AAalimu alghaybi waalshshahadati wahuwa alhakeemu alkhabeeru

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Àti pé (rántí) ọjọ́ tí (Allāhu máa yí ilẹ̀ àti sánmọ̀ padà sí n̄ǹkan mìíràn) Ó sì máa sọ pé: “Jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì máa jẹ́ bẹ́ẹ̀. Òdodo ni ọ̀rọ̀ Rẹ̀. TiRẹ̀ ni ìjọba ní ọjọ́ tí wọ́n á fọn fèrè oníwo fún àjíǹde. Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba ni. Òun sì ni Ọlọ́gbọ́n, Alámọ̀tán.

6:74

وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ لِأَبِيهِ ءَازَرَ أَتَتَّخِذُ أَصۡنَامًا ءَالِهَةً إِنِّيٓ أَرَىٰكَ وَقَوۡمَكَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ ﴿74﴾

Transliteration: Waith qala ibraheemu liabeehi azara atattakhithu asnaman alihatan innee araka waqawmaka fee dalalin mubeenin

Translation: (Rántí) nígbà tí ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ Āzar (pé): “Ṣé o máa sọ àwọn ère òrìṣà di ọlọ́hun ni? Dájúdájú èmi rí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.”

6:75

وَكَذَٰلِكَ نُرِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ مَلَكُوتَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلِيَكُونَ مِنَ ٱلۡمُوقِنِينَ ﴿75﴾

Transliteration: Wakathalika nuree ibraheema malakoota alssamawati waalardi waliyakoona mina almooqineena

Translation: Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú.

6:76

فَلَمَّا جَنَّ عَلَيۡهِ ٱلَّيۡلُ رَءَا كَوۡكَبٗاۖ قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَآ أُحِبُّ ٱلۡأٓفِلِينَ ﴿76﴾

Transliteration: Falamma janna AAalayhi allaylu raa kawkaban qala hatha rabbee falamma afala qala la ohibbu alafileena

Translation: Nígbà tí òkùnkùn alẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó rí ìràwọ̀ kan, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn (olúwa) tó ń wọ̀ọ̀kùn.”

6:77

فَلَمَّا رَءَا ٱلۡقَمَرَ بَازِغٗا قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَئِن لَّمۡ يَهۡدِنِي رَبِّي لَأَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلضَّآلِّينَ ﴿77﴾

Transliteration: Falamma raa alqamara bazighan qala hatha rabbee falamma afala qala lain lam yahdinee rabbee laakoonanna mina alqawmi alddalleena

Translation: Nígbà tí ó rí òṣùpá tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Dájúdájú tí Olúwa mi kò bá tọ́ mi sọ́nà, dájúdájú mo máa wà nínú àwọn olùṣìnà ènìyàn.”

6:78

فَلَمَّا رَءَا ٱلشَّمۡسَ بَازِغَةٗ قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَآ أَكۡبَرُۖ فَلَمَّآ أَفَلَتۡ قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ ﴿78﴾

Transliteration: Falamma raa alshshamsa bazighatan qala hatha rabbee hatha akbaru falamma afalat qala ya qawmi innee bareeon mimma tushrikoona

Translation: Nígbà tí ó rí òòrùn tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà tó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).1

6:79

إِنِّي وَجَّهۡتُ وَجۡهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ حَنِيفٗاۖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿79﴾

Transliteration: Innee wajjahtu wajhiya lillathee fatara alssamawati waalarda haneefan wama ana mina almushrikeena

Translation: Dájúdájú èmi dojú mi kọ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (mo) dúró déédé (sínú ’Islām fún Un). Èmi kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

6:80

وَحَآجَّهُۥ قَوۡمُهُۥۚ قَالَ أَتُحَـٰٓجُّوٓنِّي فِي ٱللَّهِ وَقَدۡ هَدَىٰنِۚ وَلَآ أَخَافُ مَا تُشۡرِكُونَ بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَشَآءَ رَبِّي شَيۡـٔٗاۚ وَسِعَ رَبِّي كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمًاۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ ﴿80﴾

Transliteration: Wahajjahu qawmuhu qala atuhajjoonnee fee Allahi waqad hadani wala akhafu ma tushrikoona bihi illa an yashaa rabbee shayan wasiAAa rabbee kulla shayin AAilman afala tatathakkaroona

Translation: Àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jà á níyàn. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò jà mí níyàn nípa Allāhu, Ó sì ti fi ọ̀nà mọ̀ mí? Èmi kò sì páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Un, àfi bí Allāhu bá fẹ́ kiní kan (pé kó ṣẹlẹ̀). Olúwa mi fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?

6:81

وَكَيۡفَ أَخَافُ مَآ أَشۡرَكۡتُمۡ وَلَا تَخَافُونَ أَنَّكُمۡ أَشۡرَكۡتُم بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ عَلَيۡكُمۡ سُلۡطَٰنٗاۚ فَأَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ أَحَقُّ بِٱلۡأَمۡنِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿81﴾

Transliteration: Wakayfa akhafu ma ashraktum wala takhafoona annakum ashraktum biAllahi ma lam yunazzil bihi AAalaykum sultanan faayyu alfareeqayni ahaqqu bialamni in kuntum taAAlamoona

Translation: Báwo ni èmi yóò ṣe páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Allāhu, tí ẹ̀yin kò sì páyà pé ẹ̀ ń bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pẹ̀lú ohun tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún yín lórí rẹ̀? Èwo nínú ikọ̀ méjèèjì l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ẹ bá nímọ̀?

6:82

ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَلَمۡ يَلۡبِسُوٓاْ إِيمَٰنَهُم بِظُلۡمٍ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمُ ٱلۡأَمۡنُ وَهُم مُّهۡتَدُونَ ﴿82﴾

Transliteration: Allatheena amanoo walam yalbisoo eemanahum bithulmin olaika lahumu alamnu wahum muhtadoona

Translation: Àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọn kò sì da ìgbàgbọ́ wọn pọ̀ mọ́ àbòsí (ìbọ̀rìṣà), àwọn wọ̀nyẹn ni ìfọ̀kànbalẹ̀ ń bẹ fún. Àwọn sì ni olùmọ̀nà.

6:83

وَتِلۡكَ حُجَّتُنَآ ءَاتَيۡنَٰهَآ إِبۡرَٰهِيمَ عَلَىٰ قَوۡمِهِۦۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٞ ﴿83﴾

Transliteration: Watilka hujjatuna ataynaha ibraheema AAala qawmihi narfaAAu darajatin man nashao inna rabbaka hakeemun AAaleemun

Translation: Ìyẹn ni àwíjàre Wa tí A fún (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm lórí àwọn ènìyàn rẹ̀. À ń ṣe àgbéga ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

6:84

وَوَهَبۡنَا لَهُۥٓ إِسۡحَٰقَ وَيَعۡقُوبَۚ كُلًّا هَدَيۡنَاۚ وَنُوحًا هَدَيۡنَا مِن قَبۡلُۖ وَمِن ذُرِّيَّتِهِۦ دَاوُۥدَ وَسُلَيۡمَٰنَ وَأَيُّوبَ وَيُوسُفَ وَمُوسَىٰ وَهَٰرُونَۚ وَكَذَٰلِكَ نَجۡزِي ٱلۡمُحۡسِنِينَ ﴿84﴾

Transliteration: Wawahabna lahu ishaqa wayaAAqooba kullan hadayna wanoohan hadayna min qablu wamin thurriyyatihi dawooda wasulaymana waayyooba wayoosufa wamoosa waharoona wakathalika najzee almuhsineena

Translation: Ati pé A ta á lọ́rẹ (Ànábì) ’Ishāƙ àti Ya‘ƙūb (tí ó jẹ́ ọmọ ’Ishāƙ). Ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A fi mọ̀nà. A sì fi (Ànábì) Nūh mọ̀nà ṣíwájú. Àti pé nínú àrọ́mọdọ́mọ (Ànábì ’Ibrọ̄hīm tí A fi mọ̀nà ni àwọn Ànábì) Dāwūd, Sulaemọ̄n, ’Ayyūb, Yūsuf, Mūsā àti Hārūn. Báyẹn ni A ṣe ń san àwọn olùṣe-rere ní ẹ̀san (rere).

6:85

وَزَكَرِيَّا وَيَحۡيَىٰ وَعِيسَىٰ وَإِلۡيَاسَۖ كُلّٞ مِّنَ ٱلصَّـٰلِحِينَ ﴿85﴾

Transliteration: Wazakariyya wayahya waAAeesa wailyasa kullun mina alssaliheena

Translation: Àti (Ànábì) Zakariyyā, Yahyā, ‘Īsā àti ’Ilyās; gbogbo wọn wà nínú àwọn ẹni rere.

6:86

وَإِسۡمَٰعِيلَ وَٱلۡيَسَعَ وَيُونُسَ وَلُوطٗاۚ وَكُلّٗا فَضَّلۡنَا عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿86﴾

Transliteration: WaismaAAeela wailyasaAAa wayoonusa walootan wakullan faddalna AAala alAAalameena

Translation: Àti ’Ismọ̄‘īl, al-Yasa‘, Yūnus àti Lūt; ìkọ̀ọ̀kan wọn ni A ṣoore àjùlọ fún lórí àwọn ẹ̀dá (àsìkò wọn).

6:87

وَمِنۡ ءَابَآئِهِمۡ وَذُرِّيَّـٰتِهِمۡ وَإِخۡوَٰنِهِمۡۖ وَٱجۡتَبَيۡنَٰهُمۡ وَهَدَيۡنَٰهُمۡ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ ﴿87﴾

Transliteration: Wamin abaihim wathurriyyatihim waikhwanihim waijtabaynahum wahadaynahum ila siratin mustaqeemin

Translation: Àti pé nínú àwọn bàbá wọn, àrọ́mọdọ́mọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn, A tún ṣà wọ́n lẹ́ṣà. A sì fi wọ́n mọ̀nà tààrà (’Islām).

6:88

ذَٰلِكَ هُدَى ٱللَّهِ يَهۡدِي بِهِۦ مَن يَشَآءُ مِنۡ عِبَادِهِۦۚ وَلَوۡ أَشۡرَكُواْ لَحَبِطَ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿88﴾

Transliteration: Thalika huda Allahi yahdee bihi man yashao min AAibadihi walaw ashrakoo lahabita AAanhum ma kanoo yaAAmaloona

Translation: Ìyẹn ni ìmọ̀nà Allāhu. Ó sì ń fi tọ́ ẹni tí Ó bá fẹ́ sí ọ̀nà nínú àwọn ẹrú Rẹ̀. Tí wọ́n bá fi lè ṣẹbọ ni, dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ (rere) ìbá bàjẹ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

6:89

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحُكۡمَ وَٱلنُّبُوَّةَۚ فَإِن يَكۡفُرۡ بِهَا هَـٰٓؤُلَآءِ فَقَدۡ وَكَّلۡنَا بِهَا قَوۡمٗا لَّيۡسُواْ بِهَا بِكَٰفِرِينَ ﴿89﴾

Transliteration: Olaika allatheena ataynahumu alkitaba waalhukma waalnnubuwwata fain yakfur biha haolai faqad wakkalna biha qawman laysoo biha bikafireena

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí A fún ní Tírà, òye ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah) àti (ipò) Ànábì. Nítorí náà, tí àwọn wọ̀nyí bá ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú A ti gbé e lé àwọn ènìyàn kan lọ́wọ́, tí wọn kò níí ṣàì gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

6:90

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ هَدَى ٱللَّهُۖ فَبِهُدَىٰهُمُ ٱقۡتَدِهۡۗ قُل لَّآ أَسۡـَٔلُكُمۡ عَلَيۡهِ أَجۡرًاۖ إِنۡ هُوَ إِلَّا ذِكۡرَىٰ لِلۡعَٰلَمِينَ ﴿90﴾

Transliteration: Olaika allatheena hada Allahu fabihudahumu iqtadih qul la asalukum AAalayhi ajran in huwa illa thikra lilAAalameena

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu tọ́ sí ọ̀nà. Nítorí náà, ọ̀nà wọn ni kí o tẹ̀lé. Sọ pé: “Èmi kò bi yín ní owó-ọ̀yà kan lórí rẹ̀. Kí sì ni al-Ƙur’ān bí kò ṣe ìrántí fún gbogbo ẹ̀dá.”

6:91

وَمَا قَدَرُواْ ٱللَّهَ حَقَّ قَدۡرِهِۦٓ إِذۡ قَالُواْ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ عَلَىٰ بَشَرٖ مِّن شَيۡءٖۗ قُلۡ مَنۡ أَنزَلَ ٱلۡكِتَٰبَ ٱلَّذِي جَآءَ بِهِۦ مُوسَىٰ نُورٗا وَهُدٗى لِّلنَّاسِۖ تَجۡعَلُونَهُۥ قَرَاطِيسَ تُبۡدُونَهَا وَتُخۡفُونَ كَثِيرٗاۖ وَعُلِّمۡتُم مَّا لَمۡ تَعۡلَمُوٓاْ أَنتُمۡ وَلَآ ءَابَآؤُكُمۡۖ قُلِ ٱللَّهُۖ ثُمَّ ذَرۡهُمۡ فِي خَوۡضِهِمۡ يَلۡعَبُونَ ﴿91﴾

Transliteration: Wama qadaroo Allaha haqqa qadrihi ith qaloo ma anzala Allahu AAala basharin min shayin qul man anzala alkitaba allathee jaa bihi moosa nooran wahudan lilnnasi tajAAaloonahu qarateesa tubdoonaha watukhfoona katheeran waAAullimtum ma lam taAAlamoo antum wala abaokum quli Allahu thumma tharhum fee khawdihim yalAAaboona

Translation: Wọn kò fún Allāhu ní iyì tí ó tọ́ sí I, nígbà tí wọ́n wí pé: “Allāhu kò sọ n̄ǹkan kan kalẹ̀ fún abara kan.” Sọ pé: “Ta ni Ó sọ tírà tí (Ànábì) Mūsā mú wá kalẹ̀, (èyí tó jẹ́) ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ̀nà fún àwọn ènìyàn, èyí tí ẹ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé àjákọ, tí ẹ̀ ń ṣe àfihàn rẹ̀, tí ẹ sì ń fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ rẹ̀ pamọ́, A sì fi ohun tí ẹ ò mọ̀ mọ̀ yín, ẹ̀yin àti àwọn bàbá yín?” Sọ pé: “Allāhu ni.” Lẹ́yìn náà, fi wọ́n sílẹ̀ sínú ìsọkúsọ wọn, kí wọ́n máa ṣeré.

6:92

وَهَٰذَا كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ مُبَارَكٞ مُّصَدِّقُ ٱلَّذِي بَيۡنَ يَدَيۡهِ وَلِتُنذِرَ أُمَّ ٱلۡقُرَىٰ وَمَنۡ حَوۡلَهَاۚ وَٱلَّذِينَ يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ يُؤۡمِنُونَ بِهِۦۖ وَهُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ ﴿92﴾

Transliteration: Wahatha kitabun anzalnahu mubarakun musaddiqu allathee bayna yadayhi walitunthira omma alqura waman hawlaha waallatheena yuminoona bialakhirati yuminoona bihi wahum AAala salatihim yuhafithoona

Translation: Èyí (al-Ƙur’ān) tún ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀; ó ń jẹ́rìí sí èyí tó jẹ́ òdodo nínú èyí tó ṣíwájú rẹ̀ àti pé nítorí kí o lè ṣe ìkìlọ̀ fún ’Ummul-Ƙurọ̄ (ìyẹn, ará ìlú Mọkkah) àti ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní àyíká rẹ̀ (ìyẹn, ará ìlú yòókù). Àwọn tó gbàgbọ́ nínú Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, wọ́n gbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àwọn sì ni wọ́n ń ṣọ́ ìrun wọn.

6:93

وَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا أَوۡ قَالَ أُوحِيَ إِلَيَّ وَلَمۡ يُوحَ إِلَيۡهِ شَيۡءٞ وَمَن قَالَ سَأُنزِلُ مِثۡلَ مَآ أَنزَلَ ٱللَّهُۗ وَلَوۡ تَرَىٰٓ إِذِ ٱلظَّـٰلِمُونَ فِي غَمَرَٰتِ ٱلۡمَوۡتِ وَٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ بَاسِطُوٓاْ أَيۡدِيهِمۡ أَخۡرِجُوٓاْ أَنفُسَكُمُۖ ٱلۡيَوۡمَ تُجۡزَوۡنَ عَذَابَ ٱلۡهُونِ بِمَا كُنتُمۡ تَقُولُونَ عَلَى ٱللَّهِ غَيۡرَ ٱلۡحَقِّ وَكُنتُمۡ عَنۡ ءَايَٰتِهِۦ تَسۡتَكۡبِرُونَ ﴿93﴾

Transliteration: Waman athlamu mimmani iftara AAala Allahi kathiban aw qala oohiya ilayya walam yooha ilayhi shayon waman qala saonzilu mithla ma anzala Allahu walaw tara ithi alththalimoona fee ghamarati almawti waalmalaikatu basitoo aydeehim akhrijoo anfusakumu alyawma tujzawna AAathaba alhooni bima kuntum taqooloona AAala Allahi ghayra alhaqqi wakuntum AAan ayatihi tastakbiroona

Translation: Ta l’ó ṣàbòsí ju ẹni tí ó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tàbí ẹni tí ó wí pé wọ́n fi ìmísí ránṣẹ́ sí mi - A ò sì fi kiní kan ránṣẹ́ sí i - àti ẹni tí ó wí pé “Èmi náà yóò sọ irú ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀ kalẹ̀.”? Tí ó bá jẹ́ pé ìwọ rí i nígbà tí àwọn alábòsí bá wà nínú ìpọ́kàkà ikú, tí àwọn mọlāika nawọ́ wọn (sí wọn pé) “Ẹ mú ẹ̀mí yín jáde wá. Lónìí ni Wọn yóò san yín ní ẹ̀san àbùkù ìyà nítorí ohun tí ẹ̀ máa ń sọ nípa Allāhu ní àìtọ́. Ẹ sì máa ń ṣe ìgbéraga sí àwọn āyah Rẹ̀.”

6:94

وَلَقَدۡ جِئۡتُمُونَا فُرَٰدَىٰ كَمَا خَلَقۡنَٰكُمۡ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَتَرَكۡتُم مَّا خَوَّلۡنَٰكُمۡ وَرَآءَ ظُهُورِكُمۡۖ وَمَا نَرَىٰ مَعَكُمۡ شُفَعَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ زَعَمۡتُمۡ أَنَّهُمۡ فِيكُمۡ شُرَكَـٰٓؤُاْۚ لَقَد تَّقَطَّعَ بَيۡنَكُمۡ وَضَلَّ عَنكُم مَّا كُنتُمۡ تَزۡعُمُونَ ﴿94﴾

Transliteration: Walaqad jitumoona furada kama khalaqnakum awwala marratin wataraktum ma khawwalnakum waraa thuhoorikum wama nara maAAakum shufaAAaakumu allatheena zaAAamtum annahum feekum shurakao laqad taqattaAAa baynakum wadalla AAankum ma kuntum tazAAumoona

Translation: Dájúdájú ẹ ti wá bá wa ní ìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí A ṣe ṣẹ̀dá yín nígbà àkọ́kọ́. Ẹ sì ti fi ohun tí A fún yín (nínú ọrọ̀ ayé) sílẹ̀ sí ẹ̀yìn yín. A ò mà rí àwọn olùṣìpẹ̀ yín pẹ̀lú yín, àwọn tí ẹ sọ láì ní ẹ̀rí pé dájúdájú láààrin yín àwọn ni akẹgbẹ́ (fún Allāhu). Dájúdájú àṣepọ̀ ààrin yín ti já pátápátá. Àti pé ohun tí ẹ̀ ń sọ nípa wọn (láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́ lórí ìṣìpẹ̀ wọn) sì di òfo mọ yín lọ́wọ́.1

6:95

إِنَّ ٱللَّهَ فَالِقُ ٱلۡحَبِّ وَٱلنَّوَىٰۖ يُخۡرِجُ ٱلۡحَيَّ مِنَ ٱلۡمَيِّتِ وَمُخۡرِجُ ٱلۡمَيِّتِ مِنَ ٱلۡحَيِّۚ ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُۖ فَأَنَّىٰ تُؤۡفَكُونَ ﴿95﴾

Transliteration: Inna Allaha faliqu alhabbi waalnnawa yukhriju alhayya mina almayyiti wamukhriju almayyiti mina alhayyi thalikumu Allahu faanna tufakoona

Translation: Dájúdájú Allāhu l’Ó ń mú kóró èso irúgbìn àti kóró èso dàbínù hù jáde. Ó ń mú alààyè jáde láti ara òkú. Ó sì ń mú òkú jáde láti ara alààyè. Ìyẹn ni Allāhu. Nítorí náà, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣẹ yín lórí kúrò níbi òdodo?

6:96

فَالِقُ ٱلۡإِصۡبَاحِ وَجَعَلَ ٱلَّيۡلَ سَكَنٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ حُسۡبَانٗاۚ ذَٰلِكَ تَقۡدِيرُ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡعَلِيمِ ﴿96﴾

Transliteration: Faliqu alisbahi wajaAAala allayla sakanan waalshshamsa waalqamara husbanan thalika taqdeeru alAAazeezi alAAaleemi

Translation: Ó ń mú ojúmọ́ mọ́. Ó ṣe òru ní ìsinmi. (Ó ń mú) òòrùn àti òṣùpá (rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé). Ìyẹn ni ètò Alágbára, Onímọ̀.

6:97

وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلنُّجُومَ لِتَهۡتَدُواْ بِهَا فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۗ قَدۡ فَصَّلۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿97﴾

Transliteration: Wahuwa allathee jaAAala lakumu alnnujooma litahtadoo biha fee thulumati albarri waalbahri qad fassalna alayati liqawmin yaAAlamoona

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó fi àwọn ìràwọ̀ ṣe (ìmọ́lẹ̀) fún yín kí ẹ lè fi ríran nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn tó nímọ̀.

6:98

وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَكُم مِّن نَّفۡسٖ وَٰحِدَةٖ فَمُسۡتَقَرّٞ وَمُسۡتَوۡدَعٞۗ قَدۡ فَصَّلۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَفۡقَهُونَ ﴿98﴾

Transliteration: Wahuwa allathee anshaakum min nafsin wahidatin famustaqarrun wamustawdaAAun qad fassalna alayati liqawmin yafqahoona

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá yín láti ara ẹ̀mí ẹyọ kan. Nítorí náà, ibùgbé (nílé ayé) àti ibùpadàsí (ní ọ̀run wà fún yín). A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn tó ní àgbọ́yé.

6:99

وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مَآءٗ فَأَخۡرَجۡنَا بِهِۦ نَبَاتَ كُلِّ شَيۡءٖ فَأَخۡرَجۡنَا مِنۡهُ خَضِرٗا نُّخۡرِجُ مِنۡهُ حَبّٗا مُّتَرَاكِبٗا وَمِنَ ٱلنَّخۡلِ مِن طَلۡعِهَا قِنۡوَانٞ دَانِيَةٞ وَجَنَّـٰتٖ مِّنۡ أَعۡنَابٖ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلرُّمَّانَ مُشۡتَبِهٗا وَغَيۡرَ مُتَشَٰبِهٍۗ ٱنظُرُوٓاْ إِلَىٰ ثَمَرِهِۦٓ إِذَآ أَثۡمَرَ وَيَنۡعِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكُمۡ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يُؤۡمِنُونَ ﴿99﴾

Transliteration: Wahuwa allathee anzala mina alssamai maan faakhrajna bihi nabata kulli shayin faakhrajna minhu khadiran nukhriju minhu habban mutarakiban wamina alnnakhli min talAAiha qinwanun daniyatun wajannatin min aAAnabin waalzzaytoona waalrrummana mushtabihan waghayra mutashabihin onthuroo ila thamarihi itha athmara wayanAAihi inna fee thalikum laayatin liqawmin yuminoona

Translation: Òun ni Ẹni tó ń sọ omi kalẹ̀ láti sánmọ̀. A fi mú gbogbo n̄ǹkan ọ̀gbìn jáde. A tún mú ewéko tó ń dán lọ̀gbọ́lọ̀gbọ́ jáde láti inú rẹ̀. A tún ń mú ṣiri èso jáde láti inú rẹ̀. (A sì ń mú jáde) láti ara igi dàbínù, láti ara èso àkọ́yọ rẹ̀, èso tó ṣùjọ mọ́ra wọn tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ wálẹ̀. (À ń ṣe) àwọn ọgbà oko èso àjàrà, èso zaetūn àti èso rummọ̄n (ní àwọn èso tó) jọra àti (àwọn èyí tí) kò jọra. Ẹ wo èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so àti (nígbà tí ó bá) pọ́n. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ onígbàgbọ́ òdodo.

6:100

وَجَعَلُواْ لِلَّهِ شُرَكَآءَ ٱلۡجِنَّ وَخَلَقَهُمۡۖ وَخَرَقُواْ لَهُۥ بَنِينَ وَبَنَٰتِۭ بِغَيۡرِ عِلۡمٖۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يَصِفُونَ ﴿100﴾

Transliteration: WajaAAaloo lillahi shurakaa aljinna wakhalaqahum wakharaqoo lahu baneena wabanatin bighayri AAilmin subhanahu wataAAala AAamma yasifoona

Translation: Wọ́n sì fi àwọn àlùjànnú ṣe akẹgbẹ́ fún Allāhu. Òun sì l’Ó ṣẹ̀dàá wọn! Wọ́n tún parọ́ mọ́ Ọn (pé) Ó bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, láì nímọ̀ kan (nípa rẹ̀). Mímọ́ ni fún Un. Ó sì ga tayọ ohun tí wọ́n ń fi ròyìn (Rẹ̀).

6:101

بَدِيعُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۖ أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُۥ وَلَدٞ وَلَمۡ تَكُن لَّهُۥ صَٰحِبَةٞۖ وَخَلَقَ كُلَّ شَيۡءٖۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿101﴾

Transliteration: BadeeAAu alssamawati waalardi anna yakoonu lahu waladun walam takun lahu sahibatun wakhalaqa kulla shayin wahuwa bikulli shayin AAaleemun

Translation: Olùpilẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni. Báwo ni Ó ṣe ní ọmọ nígbà tí kò ní aya. Ó dá gbogbo n̄ǹkan ni. Òun sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

6:102

ذَٰلِكُمُ ٱللَّهُ رَبُّكُمۡۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ خَٰلِقُ كُلِّ شَيۡءٖ فَٱعۡبُدُوهُۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ وَكِيلٞ ﴿102﴾

Transliteration: Thalikumu Allahu rabbukum la ilaha illa huwa khaliqu kulli shayin faoAAbudoohu wahuwa AAala kulli shayin wakeelun

Translation: Ìyẹn ni Allāhu, Olúwa yín; kò sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun, Ẹlẹ́dàá gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Un. Òun sì ni Olùṣọ́ lórí gbogbo n̄ǹkan.

6:103

لَّا تُدۡرِكُهُ ٱلۡأَبۡصَٰرُ وَهُوَ يُدۡرِكُ ٱلۡأَبۡصَٰرَۖ وَهُوَ ٱللَّطِيفُ ٱلۡخَبِيرُ ﴿103﴾

Transliteration: La tudrikuhu alabsaru wahuwa yudriku alabsara wahuwa allateefu alkhabeeru

Translation: Àwọn ojú (ẹ̀dá) kò lè ká Allāhu. Òun sì ká àwọn ojú. Òun sì ni Aláàánú, Alámọ̀tán.

6:104

قَدۡ جَآءَكُم بَصَآئِرُ مِن رَّبِّكُمۡۖ فَمَنۡ أَبۡصَرَ فَلِنَفۡسِهِۦۖ وَمَنۡ عَمِيَ فَعَلَيۡهَاۚ وَمَآ أَنَا۠ عَلَيۡكُم بِحَفِيظٖ ﴿104﴾

Transliteration: Qad jaakum basairu min rabbikum faman absara falinafsihi waman AAamiya faAAalayha wama ana AAalaykum bihafeethin

Translation: Ìmọ̀ àmọ̀dájú àti ẹ̀rí kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ríran, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fọ́jú, fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni. Èmi kì í ṣe olùṣọ́ lórí yín.

6:105

وَكَذَٰلِكَ نُصَرِّفُ ٱلۡأٓيَٰتِ وَلِيَقُولُواْ دَرَسۡتَ وَلِنُبَيِّنَهُۥ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿105﴾

Transliteration: Wakathalika nusarrifu alayati waliyaqooloo darasta walinubayyinahu liqawmin yaAAlamoona

Translation: Báyẹn ni A ṣe ń mú àwọn āyah wá lóníran-ànran ọ̀nà. - Kí wọ́n máa sọ pé, “O kẹ́kọ̀ọ́ (rẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onítírà ni.” Dípò kí wọ́n wí pé: “Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ fún ọ ni.”- (A mú un wá lóníran-ànran ọ̀nà sẹ́) nítorí kí A lè ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn ènìyàn tó nímọ̀.

6:106

ٱتَّبِعۡ مَآ أُوحِيَ إِلَيۡكَ مِن رَّبِّكَۖ لَآ إِلَٰهَ إِلَّا هُوَۖ وَأَعۡرِضۡ عَنِ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿106﴾

Transliteration: IttabiAA ma oohiya ilayka min rabbika la ilaha illa huwa waaAArid AAani almushrikeena

Translation: Tẹ̀lé ohun tí wọ́n fi rán ọ́ ní ìmísí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Kò sí ẹni tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Òun. Kí o sì ṣẹ́rí kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ṣẹbọ.

6:107

وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَآ أَشۡرَكُواْۗ وَمَا جَعَلۡنَٰكَ عَلَيۡهِمۡ حَفِيظٗاۖ وَمَآ أَنتَ عَلَيۡهِم بِوَكِيلٖ ﴿107﴾

Transliteration: Walaw shaa Allahu ma ashrakoo wama jaAAalnaka AAalayhim hafeethan wama anta AAalayhim biwakeelin

Translation: Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ (ìmọ̀nà fún wọn), wọn ìbá tí ṣẹbọ. A ò sì fi ọ́ ṣe olùṣọ́ lórí wọn. Àti pé ìwọ kọ́ ni alámòjúútó wọn.

6:108

وَلَا تَسُبُّواْ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ فَيَسُبُّواْ ٱللَّهَ عَدۡوَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖۗ كَذَٰلِكَ زَيَّنَّا لِكُلِّ أُمَّةٍ عَمَلَهُمۡ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِم مَّرۡجِعُهُمۡ فَيُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿108﴾

Transliteration: Wala tasubboo allatheena yadAAoona min dooni Allahi fayasubboo Allaha AAadwan bighayri AAilmin kathalika zayyanna likulli ommatin AAamalahum thumma ila rabbihim marjiAAuhum fayunabbiohum bima kanoo yaAAmaloona

Translation: Ẹ má ṣe bú àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kí àwọn (abọ̀rìṣà) má baà bú Allāhu ní ti àbòsí àti àìnímọ̀. Báyẹn ni A ti ṣe iṣẹ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan ní ọ̀ṣọ́ fún wọn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa wọn ni ibùpadàsí wọn. Nítorí náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n máa ń ṣe níṣẹ́.

6:109

وَأَقۡسَمُواْ بِٱللَّهِ جَهۡدَ أَيۡمَٰنِهِمۡ لَئِن جَآءَتۡهُمۡ ءَايَةٞ لَّيُؤۡمِنُنَّ بِهَاۚ قُلۡ إِنَّمَا ٱلۡأٓيَٰتُ عِندَ ٱللَّهِۖ وَمَا يُشۡعِرُكُمۡ أَنَّهَآ إِذَا جَآءَتۡ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿109﴾

Transliteration: Waaqsamoo biAllahi jahda aymanihim lain jaathum ayatun layuminunna biha qul innama alayatu AAinda Allahi wama yushAAirukum annaha itha jaat la yuminoona

Translation: Wọ́n sì fi Allāhu búra tí ìbúra wọn sì lágbára gan-an pé, dájúdájú tí àmì (ìyanu) kan bá dé bá àwọn, àwọn gbọ́dọ̀ gbà á gbọ́. Sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Allāhu nìkan ni àwọn àmì (ìyanu) wà.” Kí sì ni ó máa mu yín fura mọ̀ pé dájúdájú nígbà tí ó bá dé (bá wọn) wọn máa gbà á gbọ́?

6:110

وَنُقَلِّبُ أَفۡـِٔدَتَهُمۡ وَأَبۡصَٰرَهُمۡ كَمَا لَمۡ يُؤۡمِنُواْ بِهِۦٓ أَوَّلَ مَرَّةٖ وَنَذَرُهُمۡ فِي طُغۡيَٰنِهِمۡ يَعۡمَهُونَ ﴿110﴾

Transliteration: Wanuqallibu afidatahum waabsarahum kama lam yuminoo bihi awwala marratin wanatharuhum fee tughyanihim yaAAmahoona

Translation: A máa yí ọkàn wọn àti ojú wọn sódì ni (wọn kò sì níí gbà á gbọ́) gẹ́gẹ́ bí wọn kò ṣe gbàgbọ́ nínú (èyí tó ṣíwájú nínú àwọn àmì ìyanu) nígbà àkọ́kọ́. A ó sì fí wọn sílẹ̀ sínú àgbéré wọn, tí wọn yóò máa pa rìdàrìdà.

6:111

وَلَوۡ أَنَّنَا نَزَّلۡنَآ إِلَيۡهِمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةَ وَكَلَّمَهُمُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَحَشَرۡنَا عَلَيۡهِمۡ كُلَّ شَيۡءٖ قُبُلٗا مَّا كَانُواْ لِيُؤۡمِنُوٓاْ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ وَلَٰكِنَّ أَكۡثَرَهُمۡ يَجۡهَلُونَ ﴿111﴾

Transliteration: Walaw annana nazzalna ilayhimu almalaikata wakallamahumu almawta wahasharna AAalayhim kulla shayin qubulan ma kanoo liyuminoo illa an yashaa Allahu walakinna aktharahum yajhaloona

Translation: Dájúdájú tí A bá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ fún wọn, tí àwọn òkú ń bá wọn sọ̀rọ̀, tí A tún kó gbogbo n̄ǹkan jọ síwájú wọn, wọn kò níí gbàgbọ́ àfi tí Allāhu bá fẹ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni aláìmọ̀kan.

6:112

وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَا لِكُلِّ نَبِيٍّ عَدُوّٗا شَيَٰطِينَ ٱلۡإِنسِ وَٱلۡجِنِّ يُوحِي بَعۡضُهُمۡ إِلَىٰ بَعۡضٖ زُخۡرُفَ ٱلۡقَوۡلِ غُرُورٗاۚ وَلَوۡ شَآءَ رَبُّكَ مَا فَعَلُوهُۖ فَذَرۡهُمۡ وَمَا يَفۡتَرُونَ ﴿112﴾

Transliteration: Wakathalika jaAAalna likulli nabiyyin AAaduwwan shayateena alinsi waaljinni yoohee baAAduhum ila baAAdin zukhrufa alqawli ghurooran walaw shaa rabbuka ma faAAaloohu fatharhum wama yaftaroona

Translation: Báyẹn ni A ti ṣe àwọn èṣù ènìyàn àti èṣù àlùjànnú ní ọ̀tá fún Ànábì kọ̀ọ̀kan; apá kan wọn ń fi ọ̀rọ̀ dídùn (odù irọ́) ránṣẹ́ sí apá kan ní ti ẹ̀tàn. Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa rẹ bá fẹ́ (láti tọ́ wọn sọ́nà ni) wọn ìbá tí ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, fi wọn sílẹ̀ tòhun ti àdápa irọ́ tí wọ́n ń dá.

6:113

وَلِتَصۡغَىٰٓ إِلَيۡهِ أَفۡـِٔدَةُ ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ وَلِيَرۡضَوۡهُ وَلِيَقۡتَرِفُواْ مَا هُم مُّقۡتَرِفُونَ ﴿113﴾

Transliteration: Walitasgha ilayhi afidatu allatheena la yuminoona bialakhirati waliyardawhu waliyaqtarifoo ma hum muqtarifoona

Translation: Kí àwọn ọkàn àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́ máa tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí (odù irọ́ Èṣù), kí wọ́n yọ́nú sí i, kí wọ́n sì máa dá ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀ ǹ só.

6:114

أَفَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَبۡتَغِي حَكَمٗا وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ إِلَيۡكُمُ ٱلۡكِتَٰبَ مُفَصَّلٗاۚ وَٱلَّذِينَ ءَاتَيۡنَٰهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ يَعۡلَمُونَ أَنَّهُۥ مُنَزَّلٞ مِّن رَّبِّكَ بِٱلۡحَقِّۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمُمۡتَرِينَ ﴿114﴾

Transliteration: Afaghayra Allahi abtaghee hakaman wahuwa allathee anzala ilaykumu alkitaba mufassalan waallatheena ataynahumu alkitaba yaAAlamoona annahu munazzalun min rabbika bialhaqqi fala takoonanna mina almumtareena

Translation: Ṣé n̄ǹkan mìíràn ni kí n̄g wá ní olùdájọ́ lẹ́yìn Allāhu ni? Òun sì ni Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún yín tí wọ́n fi ṣàlàyé ìdájọ́.Àwọn tí A sì fún ní tírà mọ̀ pé, dájúdájú wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ. Nítorí náà, o ò gbọdọ̀ wà lára àwọn oníyèméjì.

6:115

وَتَمَّتۡ كَلِمَتُ رَبِّكَ صِدۡقٗا وَعَدۡلٗاۚ لَّا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِهِۦۚ وَهُوَ ٱلسَّمِيعُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿115﴾

Transliteration: Watammat kalimatu rabbika sidqan waAAadlan la mubaddila likalimatihi wahuwa alssameeAAu alAAaleemu

Translation: Ọ̀rọ̀ Olúwa rẹ pé ní òdodo àti ní déédé. Kò sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Òun sì ni Olùgbọ́, Onímọ̀.

6:116

وَإِن تُطِعۡ أَكۡثَرَ مَن فِي ٱلۡأَرۡضِ يُضِلُّوكَ عَن سَبِيلِ ٱللَّهِۚ إِن يَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ هُمۡ إِلَّا يَخۡرُصُونَ ﴿116﴾

Transliteration: Wain tutiAA akthara man fee alardi yudillooka AAan sabeeli Allahi in yattabiAAoona illa alththanna wain hum illa yakhrusoona

Translation: Tí o bá tẹ̀lé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀, wọ́n máa ṣì ọ́ lọ́nà kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Wọn kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Kí sì ni wọn (ń ṣe) bí kò ṣe pé wọ́n ń parọ́.

6:117

إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ مَن يَضِلُّ عَن سَبِيلِهِۦۖ وَهُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُهۡتَدِينَ ﴿117﴾

Transliteration: Inna rabbaka huwa aAAlamu man yadillu AAan sabeelihi wahuwa aAAlamu bialmuhtadeena

Translation: Dájúdájú Olúwa rẹ, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa ẹni tó ṣìnà lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Àti pé, Òun l’Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùmọ̀nà.

6:118

فَكُلُواْ مِمَّا ذُكِرَ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ إِن كُنتُم بِـَٔايَٰتِهِۦ مُؤۡمِنِينَ ﴿118﴾

Transliteration: Fakuloo mimma thukira ismu Allahi AAalayhi in kuntum biayatihi mumineena

Translation: Nítorí náà, ẹ jẹ nínú ohun tí wọ́n bá fi orúkọ Allāhu pa, tí ẹ bá gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Rẹ̀.

6:119

وَمَا لَكُمۡ أَلَّا تَأۡكُلُواْ مِمَّا ذُكِرَ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَقَدۡ فَصَّلَ لَكُم مَّا حَرَّمَ عَلَيۡكُمۡ إِلَّا مَا ٱضۡطُرِرۡتُمۡ إِلَيۡهِۗ وَإِنَّ كَثِيرٗا لَّيُضِلُّونَ بِأَهۡوَآئِهِم بِغَيۡرِ عِلۡمٍۚ إِنَّ رَبَّكَ هُوَ أَعۡلَمُ بِٱلۡمُعۡتَدِينَ ﴿119﴾

Transliteration: Wama lakum alla takuloo mimma thukira ismu Allahi AAalayhi waqad fassala lakum ma harrama AAalaykum illa ma idturirtum ilayhi wainna katheeran layudilloona biahwaihim bighayri AAilmin inna rabbaka huwa aAAlamu bialmuAAtadeena

Translation: Kí ni ó máa kọ̀ fún yín láti jẹ nínú ohun tí wọ́n fi orúkọ Allāhu pa! Ó kúkú ti ṣàlàyé fún yín ohun tí Ó ṣe ní èèwọ̀ fún yín àyàfi èyí tí wọ́n bá fi ìnira tì yín débẹ̀. Dájúdájú ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ni wọ́n ń fi ìfẹ́-inú wọn pẹ̀lú àìnímọ̀ (wọn) ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà. Dájúdájú Olúwa rẹ, Ó nímọ̀ jùlọ nípa àwọn olùtayọ ẹnu-ààlà.

6:120

وَذَرُواْ ظَٰهِرَ ٱلۡإِثۡمِ وَبَاطِنَهُۥٓۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ يَكۡسِبُونَ ٱلۡإِثۡمَ سَيُجۡزَوۡنَ بِمَا كَانُواْ يَقۡتَرِفُونَ ﴿120﴾

Transliteration: Watharoo thahira alithmi wabatinahu inna allatheena yaksiboona alithma sayujzawna bima kanoo yaqtarifoona

Translation: Ẹ fi èyí tó hàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti èyí tó pamọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀. Dájúdájú àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, A óò san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá lẹ́ṣẹ̀.

6:121

وَلَا تَأۡكُلُواْ مِمَّا لَمۡ يُذۡكَرِ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَإِنَّهُۥ لَفِسۡقٞۗ وَإِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِهِمۡ لِيُجَٰدِلُوكُمۡۖ وَإِنۡ أَطَعۡتُمُوهُمۡ إِنَّكُمۡ لَمُشۡرِكُونَ ﴿121﴾

Transliteration: Wala takuloo mimma lam yuthkari ismu Allahi AAalayhi wainnahu lafisqun wainna alshshayateena layoohoona ila awliyaihim liyujadilookum wain ataAAtumoohum innakum lamushrikoona

Translation: Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa.Dájúdájú ìbàjẹ́ ni. Àti pé dájúdájú àwọn èṣù, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.

6:122

أَوَمَن كَانَ مَيۡتٗا فَأَحۡيَيۡنَٰهُ وَجَعَلۡنَا لَهُۥ نُورٗا يَمۡشِي بِهِۦ فِي ٱلنَّاسِ كَمَن مَّثَلُهُۥ فِي ٱلظُّلُمَٰتِ لَيۡسَ بِخَارِجٖ مِّنۡهَاۚ كَذَٰلِكَ زُيِّنَ لِلۡكَٰفِرِينَ مَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿122﴾

Transliteration: Awa man kana maytan faahyaynahu wajaAAalna lahu nooran yamshee bihi fee alnnasi kaman mathaluhu fee alththulumati laysa bikharijin minha kathalika zuyyina lilkafireena ma kanoo yaAAmaloona

Translation: Ǹjẹ́ ẹni tí (àfiwé rẹ̀) jẹ́ òkú (ìyẹn, aláìgbàgbọ́), tí A sọ di alààyè (nípa pé ó gba ’Islām), tí A sì fún un ní ìmọ́lẹ̀ (ìyẹn, ìmọ̀ ẹ̀sìn), tí ó sì ń lò ó láààrin àwọn ènìyàn, (ǹjẹ́) ó dà bí ẹni tí àfiwé tirẹ̀ jẹ́ (ẹni tí) ń bẹ nínú àwọn òkùnkùn (àìgbàgbọ́), tí kò sì jáde kúrò nínú rẹ̀? Báyẹn ni wọ́n ṣe ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn aláìgbàgbọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

6:123

وَكَذَٰلِكَ جَعَلۡنَا فِي كُلِّ قَرۡيَةٍ أَكَٰبِرَ مُجۡرِمِيهَا لِيَمۡكُرُواْ فِيهَاۖ وَمَا يَمۡكُرُونَ إِلَّا بِأَنفُسِهِمۡ وَمَا يَشۡعُرُونَ ﴿123﴾

Transliteration: Wakathalika jaAAalna fee kulli qaryatin akabira mujrimeeha liyamkuroo feeha wama yamkuroona illa bianfusihim wama yashAAuroona

Translation: Báyẹn ni A ṣe sọ àwọn ọ̀tọ̀kùlúkan di ọ̀daràn ìlú nínú ìlú kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n lè máa dète níbẹ̀. Wọn kò sì dète sí ẹnikẹ́ni bí kò ṣe sí ara wọn, wọn kò sì fura.

6:124

وَإِذَا جَآءَتۡهُمۡ ءَايَةٞ قَالُواْ لَن نُّؤۡمِنَ حَتَّىٰ نُؤۡتَىٰ مِثۡلَ مَآ أُوتِيَ رُسُلُ ٱللَّهِۘ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ حَيۡثُ يَجۡعَلُ رِسَالَتَهُۥۗ سَيُصِيبُ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ صَغَارٌ عِندَ ٱللَّهِ وَعَذَابٞ شَدِيدُۢ بِمَا كَانُواْ يَمۡكُرُونَ ﴿124﴾

Transliteration: Waitha jaathum ayatun qaloo lan numina hatta nuta mithla ma ootiya rusulu Allahi Allahu aAAlamu haythu yajAAalu risalatahu sayuseebu allatheena ajramoo sagharun AAinda Allahi waAAathabun shadeedun bima kanoo yamkuroona

Translation: Nígbà tí āyah kan bá sì dé bá wọn, wọ́n á wí pé: “Àwa kò níí gbà á gbọ́ títí di ìgbà tí wọ́n bá tó fún àwa náà ní irú ohun tí wọ́n fún àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu.” Allāhu ló nímọ̀ jùlọ nípa ibi tí Ó ń fí iṣẹ́-rírán Rẹ̀ sí.Láìpẹ́ ìyẹpẹrẹ àti ìyà líle láti ọ̀dọ̀ Allāhu yóò dé bá àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n ń dá léte.

6:125

فَمَن يُرِدِ ٱللَّهُ أَن يَهۡدِيَهُۥ يَشۡرَحۡ صَدۡرَهُۥ لِلۡإِسۡلَٰمِۖ وَمَن يُرِدۡ أَن يُضِلَّهُۥ يَجۡعَلۡ صَدۡرَهُۥ ضَيِّقًا حَرَجٗا كَأَنَّمَا يَصَّعَّدُ فِي ٱلسَّمَآءِۚ كَذَٰلِكَ يَجۡعَلُ ٱللَّهُ ٱلرِّجۡسَ عَلَى ٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ ﴿125﴾

Transliteration: Faman yuridi Allahu an yahdiyahu yashrah sadrahu lilislami waman yurid an yudillahu yajAAal sadrahu dayyiqan harajan kaannama yassaAAAAadu fee alssamai kathalika yajAAalu Allahu alrrijsa AAala allatheena la yuminoona

Translation: Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fọ̀nà mọ̀, Ó máa ṣí igbá-àyà rẹ̀ payá fún ’Islām. Ẹnikẹ́ni tí Ó bá sì fẹ́ ṣì lọ́nà, Ó máa fún igbá-àyà rẹ̀ pa gádígádí bí ẹni pé ó la ìgùnkè lọ sínú sánmọ̀ bọra rẹ̀ lọ́rùn. Báyẹn ni Allāhu ṣe ṣe ìyà fún àwọn tí kò gbàgbọ́.

6:126

وَهَٰذَا صِرَٰطُ رَبِّكَ مُسۡتَقِيمٗاۗ قَدۡ فَصَّلۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَذَّكَّرُونَ ﴿126﴾

Transliteration: Wahatha siratu rabbika mustaqeeman qad fassalna alayati liqawmin yaththakkaroona

Translation: Èyí ni ojú ọ̀nà Olúwa rẹ (tó jẹ́) ọ̀nà tààrà. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń lo ìrántí.

6:127

لَهُمۡ دَارُ ٱلسَّلَٰمِ عِندَ رَبِّهِمۡۖ وَهُوَ وَلِيُّهُم بِمَا كَانُواْ يَعۡمَلُونَ ﴿127﴾

Transliteration: Lahum daru alssalami AAinda rabbihim wahuwa waliyyuhum bima kanoo yaAAmaloona

Translation: Ilé àlàáfíà ń bẹ fun wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Òun sì ni Alátìlẹ́yìn wọn nípa ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

6:128

وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا يَٰمَعۡشَرَ ٱلۡجِنِّ قَدِ ٱسۡتَكۡثَرۡتُم مِّنَ ٱلۡإِنسِۖ وَقَالَ أَوۡلِيَآؤُهُم مِّنَ ٱلۡإِنسِ رَبَّنَا ٱسۡتَمۡتَعَ بَعۡضُنَا بِبَعۡضٖ وَبَلَغۡنَآ أَجَلَنَا ٱلَّذِيٓ أَجَّلۡتَ لَنَاۚ قَالَ ٱلنَّارُ مَثۡوَىٰكُمۡ خَٰلِدِينَ فِيهَآ إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٞ ﴿128﴾

Transliteration: Wayawma yahshuruhum jameeAAan ya maAAshara aljinni qadi istakthartum mina alinsi waqala awliyaohum mina alinsi rabbana istamtaAAa baAAduna bibaAAdin wabalaghna ajalana allathee ajjalta lana qala alnnaru mathwakum khalideena feeha illa ma shaa Allahu inna rabbaka hakeemun AAaleemun

Translation: (Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́ Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

6:129

وَكَذَٰلِكَ نُوَلِّي بَعۡضَ ٱلظَّـٰلِمِينَ بَعۡضَۢا بِمَا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ﴿129﴾

Transliteration: Wakathalika nuwallee baAAda alththalimeena baAAdan bima kanoo yaksiboona

Translation: Báyẹn ni A ṣe fi apá kan àwọn alábòsí ṣọ̀rẹ́ apá kan (wọn) nítorí ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

6:130

يَٰمَعۡشَرَ ٱلۡجِنِّ وَٱلۡإِنسِ أَلَمۡ يَأۡتِكُمۡ رُسُلٞ مِّنكُمۡ يَقُصُّونَ عَلَيۡكُمۡ ءَايَٰتِي وَيُنذِرُونَكُمۡ لِقَآءَ يَوۡمِكُمۡ هَٰذَاۚ قَالُواْ شَهِدۡنَا عَلَىٰٓ أَنفُسِنَاۖ وَغَرَّتۡهُمُ ٱلۡحَيَوٰةُ ٱلدُّنۡيَا وَشَهِدُواْ عَلَىٰٓ أَنفُسِهِمۡ أَنَّهُمۡ كَانُواْ كَٰفِرِينَ ﴿130﴾

Transliteration: Ya maAAshara aljinni waalinsi alam yatikum rusulun minkum yaqussoona AAalaykum ayatee wayunthiroonakum liqaa yawmikum hatha qaloo shahidna AAala anfusina wagharrathumu alhayatu alddunya washahidoo AAala anfusihim annahum kanoo kafireena

Translation: Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú àti ènìyàn, ṣé àwọn Òjíṣẹ́ kan láààrin yín kò wá ba yín, tí wọ́n ń ké àwọn āyah Mi fún yín, tí wọ́n sì ń fi ìpàdé yín Òní yìí ṣèkìlọ̀ fún yín? Wọ́n wí pé: “A jẹ́rìí léra wa lórí (pé wọ́n wá).” Ìṣẹ́mí ayé tàn wọ́n jẹ. Wọ́n sì jẹ́rìí léra wọn lórí pé dájúdájú àwọn jẹ́ aláìgbàgbọ́.

6:131

ذَٰلِكَ أَن لَّمۡ يَكُن رَّبُّكَ مُهۡلِكَ ٱلۡقُرَىٰ بِظُلۡمٖ وَأَهۡلُهَا غَٰفِلُونَ ﴿131﴾

Transliteration: Thalika an lam yakun rabbuka muhlika alqura bithulmin waahluha ghafiloona

Translation: Ìyẹn nítorí pé, Olúwa rẹ kò níí pa àwọn ìlú run nípasẹ̀ àbòsí (ọwọ́ wọn), lásìkò tí àwọn ara ìlú náà jẹ́ aláìmọ̀ (títí Òjíṣẹ́ yóò fi dé bá wọn).

6:132

وَلِكُلّٖ دَرَجَٰتٞ مِّمَّا عَمِلُواْۚ وَمَا رَبُّكَ بِغَٰفِلٍ عَمَّا يَعۡمَلُونَ ﴿132﴾

Transliteration: Walikullin darajatun mimma AAamiloo wama rabbuka bighafilin AAamma yaAAmaloona

Translation: Àwọn ipò (ìkẹ́ àti ipò ìyà) ń bẹ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ohun tí wọ́n bá ṣe níṣẹ́. Olúwa rẹ kì í ṣe onígbàgbé nípa n̄ǹkan tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

6:133

وَرَبُّكَ ٱلۡغَنِيُّ ذُو ٱلرَّحۡمَةِۚ إِن يَشَأۡ يُذۡهِبۡكُمۡ وَيَسۡتَخۡلِفۡ مِنۢ بَعۡدِكُم مَّا يَشَآءُ كَمَآ أَنشَأَكُم مِّن ذُرِّيَّةِ قَوۡمٍ ءَاخَرِينَ ﴿133﴾

Transliteration: Warabbuka alghaniyyu thoo alrrahmati in yasha yuthhibkum wayastakhlif min baAAdikum ma yashao kama anshaakum min thurriyyati qawmin akhareena

Translation: Olúwa rẹ ni Ọlọ́rọ̀, Aláàánú. Tí Ó bá fẹ́, Ó máa ko yín kúrò (lórí ilẹ̀). Ó sì máa fi ohun tí Ó bá fẹ́ rọ́pò (yín) lẹ́yìn (ìparun) yín gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe mu yín jáde lẹ́yìn (ìparun) àrọ́mọdọ́mọ àwọn ìjọ mìíràn.

6:134

إِنَّ مَا تُوعَدُونَ لَأٓتٖۖ وَمَآ أَنتُم بِمُعۡجِزِينَ ﴿134﴾

Transliteration: Inna ma tooAAadoona laatin wama antum bimuAAjizeena

Translation: Dájúdájú ohun tí À ń ṣe ní àdéhùn fún yín, ó kúkú ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀; ẹ̀yin kò sì lè dá Allāhu lágara.1

6:135

قُلۡ يَٰقَوۡمِ ٱعۡمَلُواْ عَلَىٰ مَكَانَتِكُمۡ إِنِّي عَامِلٞۖ فَسَوۡفَ تَعۡلَمُونَ مَن تَكُونُ لَهُۥ عَٰقِبَةُ ٱلدَّارِۚ إِنَّهُۥ لَا يُفۡلِحُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿135﴾

Transliteration: Qul ya qawmi iAAmaloo AAala makanatikum innee AAamilun fasawfa taAAlamoona man takoonu lahu AAaqibatu alddari innahu la yuflihu alththalimoona

Translation: Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ ṣisẹ́ ní àyè yín. Dájúdájú èmi náà ń ṣiṣẹ́.Láìpẹ́ ẹ̀ máa mọ ẹni tí Ilé Ìkángun-rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) yóò jẹ́ tirẹ̀. Dájúdájú àwọn alábòsí kò níí jèrè.”

6:136

وَجَعَلُواْ لِلَّهِ مِمَّا ذَرَأَ مِنَ ٱلۡحَرۡثِ وَٱلۡأَنۡعَٰمِ نَصِيبٗا فَقَالُواْ هَٰذَا لِلَّهِ بِزَعۡمِهِمۡ وَهَٰذَا لِشُرَكَآئِنَاۖ فَمَا كَانَ لِشُرَكَآئِهِمۡ فَلَا يَصِلُ إِلَى ٱللَّهِۖ وَمَا كَانَ لِلَّهِ فَهُوَ يَصِلُ إِلَىٰ شُرَكَآئِهِمۡۗ سَآءَ مَا يَحۡكُمُونَ ﴿136﴾

Transliteration: WajaAAaloo lillahi mimma tharaa mina alharthi waalanAAami naseeban faqaloo hatha lillahi bizaAAmihim wahatha lishurakaina fama kana lishurakaihim fala yasilu ila Allahi wama kana lillahi fahuwa yasilu ila shurakaihim saa ma yahkumoona

Translation: Wọ́n sì fi ìpín kan fún Allāhu nínú ohun tí Ó dá nínú n̄ǹkan oko àti ẹran-ọ̀sìn; wọ́n wí pé: “Èyí ni ti Allāhu - pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́, - èyí sì ni ti àwọn òrìṣà wa.” Nítorí náà, ohun tí ó bá jẹ́ ti àwọn òrìṣà kò níí dàpọ̀ mọ́ ti Allāhu. Ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Allāhu, ó ń dàpọ̀ mọ́ ti àwọn òrìṣà wọn; ohun tí wọ́n ń dá lẹ́jọ́ burú.

6:137

وَكَذَٰلِكَ زَيَّنَ لِكَثِيرٖ مِّنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ قَتۡلَ أَوۡلَٰدِهِمۡ شُرَكَآؤُهُمۡ لِيُرۡدُوهُمۡ وَلِيَلۡبِسُواْ عَلَيۡهِمۡ دِينَهُمۡۖ وَلَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَا فَعَلُوهُۖ فَذَرۡهُمۡ وَمَا يَفۡتَرُونَ ﴿137﴾

Transliteration: Wakathalika zayyana likatheerin mina almushrikeena qatla awladihim shurakaohum liyurdoohum waliyalbisoo AAalayhim deenahum walaw shaa Allahu ma faAAaloohu fatharhum wama yaftaroona

Translation: Báyẹn ni àwọn òrìṣà wọn ṣe pípa àwọn ọmọ wọn ní ọ̀ṣọ́ fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ nítorí kí wọ́n lè pa wọ́n run àti nítorí kí wọ́n lè d’ojú ẹ̀sìn wọn rú mọ́ wọn lọ́wọ́. Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí ṣe (bẹ́ẹ̀). Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ tòhun ti ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.

6:138

وَقَالُواْ هَٰذِهِۦٓ أَنۡعَٰمٞ وَحَرۡثٌ حِجۡرٞ لَّا يَطۡعَمُهَآ إِلَّا مَن نَّشَآءُ بِزَعۡمِهِمۡ وَأَنۡعَٰمٌ حُرِّمَتۡ ظُهُورُهَا وَأَنۡعَٰمٞ لَّا يَذۡكُرُونَ ٱسۡمَ ٱللَّهِ عَلَيۡهَا ٱفۡتِرَآءً عَلَيۡهِۚ سَيَجۡزِيهِم بِمَا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ﴿138﴾

Transliteration: Waqaloo hathihi anAAamun waharthun hijrun la yatAAamuha illa man nashao bizaAAmihim waanAAamun hurrimat thuhooruha waanAAamun la yathkuroona isma Allahi AAalayha iftiraan AAalayhi sayajzeehim bima kanoo yaftaroona

Translation: Wọ́n tún wí pé: “Èèwọ̀ ni àwọn ẹran-ọ̀sìn àti n̄ǹkan oko wọ̀nyí. Ẹnì kan kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ àfi ẹni tí a bá fẹ́, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọn láì ní ẹ̀rí lọ́wọ́.” - Àwọn ẹran-ọ̀sìn kan tún ń bẹ tí wọ́n ṣe ẹ̀yìn wọn ní èèwọ̀ (fún gígùn àti ẹrù rírù), àwọn ẹran kan tún ń bẹ tí wọn kì í fi orúkọ Allāhu pa. (Wọ́n fi àwọn n̄ǹkan wọ̀nyí) dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu ni. Ó sì máa san wọ́n ní ẹ̀san ohun tí wọ́n ń dá ní àdápa irọ́.

6:139

وَقَالُواْ مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ ٱلۡأَنۡعَٰمِ خَالِصَةٞ لِّذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِنَاۖ وَإِن يَكُن مَّيۡتَةٗ فَهُمۡ فِيهِ شُرَكَآءُۚ سَيَجۡزِيهِمۡ وَصۡفَهُمۡۚ إِنَّهُۥ حَكِيمٌ عَلِيمٞ ﴿139﴾

Transliteration: Waqaloo ma fee butooni hathihi alanAAami khalisatun lithukoorina wamuharramun AAala azwajina wain yakun maytatan fahum feehi shurakao sayajzeehim wasfahum innahu hakeemun AAaleemun

Translation: Wọ́n tún wí pé: “Ohun tí ń bẹ nínú ikùn àwọn ẹran-ọ̀sìn wọ̀nyí jẹ́ ti àwọn ọkùnrin wa nìkan, ó sì jẹ́ èèwọ̀ fún àwọn obìnrin wa.” Tí ó bá sì jẹ́ òkú ọmọ-ẹran, akẹgbẹ́ sì ni wọn nínú (ìpín) rẹ̀.(Allāhu) yóò san wọ́n ní ẹ̀san irọ́ (ẹnu) wọn. Dájúdájú Òun ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

6:140

قَدۡ خَسِرَ ٱلَّذِينَ قَتَلُوٓاْ أَوۡلَٰدَهُمۡ سَفَهَۢا بِغَيۡرِ عِلۡمٖ وَحَرَّمُواْ مَا رَزَقَهُمُ ٱللَّهُ ٱفۡتِرَآءً عَلَى ٱللَّهِۚ قَدۡ ضَلُّواْ وَمَا كَانُواْ مُهۡتَدِينَ ﴿140﴾

Transliteration: Qad khasira allatheena qataloo awladahum safahan bighayri AAilmin waharramoo ma razaqahumu Allahu iftiraan AAala Allahi qad dalloo wama kanoo muhtadeena

Translation: Àwọn tó fi agọ̀ àti àìmọ̀ pa àwọn ọmọ wọn kúkú ti ṣòfò; wọ́n tún ṣe ohun tí Allāhu pa lésè fún wọn ní èèwọ̀, ní ti dídá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu. Wọ́n kúkú ti ṣìnà, wọn kò sì jẹ́ olùmọ̀nà.

6:141

وَهُوَ ٱلَّذِيٓ أَنشَأَ جَنَّـٰتٖ مَّعۡرُوشَٰتٖ وَغَيۡرَ مَعۡرُوشَٰتٖ وَٱلنَّخۡلَ وَٱلزَّرۡعَ مُخۡتَلِفًا أُكُلُهُۥ وَٱلزَّيۡتُونَ وَٱلرُّمَّانَ مُتَشَٰبِهٗا وَغَيۡرَ مُتَشَٰبِهٖۚ كُلُواْ مِن ثَمَرِهِۦٓ إِذَآ أَثۡمَرَ وَءَاتُواْ حَقَّهُۥ يَوۡمَ حَصَادِهِۦۖ وَلَا تُسۡرِفُوٓاْۚ إِنَّهُۥ لَا يُحِبُّ ٱلۡمُسۡرِفِينَ ﴿141﴾

Transliteration: Wahuwa allathee anshaa jannatin maAArooshatin waghayra maAArooshatin waalnnakhla waalzzarAAa mukhtalifan okuluhu waalzzaytoona waalrrummana mutashabihan waghayra mutashabihin kuloo min thamarihi itha athmara waatoo haqqahu yawma hasadihi wala tusrifoo innahu la yuhibbu almusrifeena

Translation: (Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn (n̄ǹkan) ọgbà oko èyí tí ẹ̀ ń fọwọ́ ara yín gbìn àti èyí tó ń lalẹ̀ hù àti dàbínù àti irúgbìn tí (adùn) jíjẹ rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àti èso zaetūn àti èso rummọ̄n tó jọra wọn àti èyí tí kò jọra wọn. Ẹ jẹ nínú èso rẹ̀ nígbà tí ó bá so, kí ẹ sì yọ Zakāh rẹ̀ ní ọjọ́ ìkórè rẹ̀. Kí ẹ sì má yàpà. Dájúdájú (Allāhu) kò nífẹ̀ẹ́ àwọn àpà.

6:142

وَمِنَ ٱلۡأَنۡعَٰمِ حَمُولَةٗ وَفَرۡشٗاۚ كُلُواْ مِمَّا رَزَقَكُمُ ٱللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُواْ خُطُوَٰتِ ٱلشَّيۡطَٰنِۚ إِنَّهُۥ لَكُمۡ عَدُوّٞ مُّبِينٞ ﴿142﴾

Transliteration: Wamina alanAAami hamoolatan wafarshan kuloo mimma razaqakumu Allahu wala tattabiAAoo khutuwati alshshaytani innahu lakum AAaduwwun mubeenun

Translation: Ó sì ń bẹ nínú àwọn ẹran-ọ̀sìn, èyí tó lè ru ẹrù àti èyí tí kò lè ru ẹrù. Ẹ jẹ nínú ohun tí Allāhu pa lésè fún yín. Kí ẹ sì má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú-ẹsẹ̀ Èṣù;dájúdájú òun ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún yín.

6:143

ثَمَٰنِيَةَ أَزۡوَٰجٖۖ مِّنَ ٱلضَّأۡنِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡمَعۡزِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ نَبِّـُٔونِي بِعِلۡمٍ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿143﴾

Transliteration: Thamaniyata azwajin mina alddani ithnayni wamina almaAAzi ithnayni qul alththakarayni harrama ami alonthayayni amma ishtamalat AAalayhi arhamu alonthayayni nabbioonee biAAilmin in kuntum sadiqeena

Translation: (Allāhu dá ẹran) mẹ́jọ ní takọ- tabo; méjì nínú àgùtàn (takọ-tabo), méjì nínú ewúrẹ́ (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Ẹ fún mi ní ìró pẹ̀lú ìmọ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

6:144

وَمِنَ ٱلۡإِبِلِ ٱثۡنَيۡنِ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ ٱثۡنَيۡنِۗ قُلۡ ءَآلذَّكَرَيۡنِ حَرَّمَ أَمِ ٱلۡأُنثَيَيۡنِ أَمَّا ٱشۡتَمَلَتۡ عَلَيۡهِ أَرۡحَامُ ٱلۡأُنثَيَيۡنِۖ أَمۡ كُنتُمۡ شُهَدَآءَ إِذۡ وَصَّىٰكُمُ ٱللَّهُ بِهَٰذَاۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّنِ ٱفۡتَرَىٰ عَلَى ٱللَّهِ كَذِبٗا لِّيُضِلَّ ٱلنَّاسَ بِغَيۡرِ عِلۡمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿144﴾

Transliteration: Wamina alibili ithnayni wamina albaqari ithnayni qul alththakarayni harrama ami alonthayayni amma ishtamalat AAalayhi arhamu alonthayayni am kuntum shuhadaa ith wassakumu Allahu bihatha faman athlamu mimmani iftara AAala Allahi kathiban liyudilla alnnasa bighayri AAilmin inna Allaha la yahdee alqawma alththalimeena

Translation: Méjì nínú ràkúnmí (takọ-tabo) àti méjì nínú màálù (takọ-tabo). Sọ pé: “Ṣé àwọn akọ méjèèjì ni Allāhu ṣe ní èèwọ̀ ni tàbí abo méjèèjì, tàbí ohun tí ń bẹ nínú àpò-ìbímọ àwọn abo ẹran méjèèjì. Tàbí ṣé ẹ̀yin wà níbẹ̀ nígbà tí Allāhu pa yín láṣẹ èyí ni?” Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí tó tún tayọ ẹni tó dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu láti lè ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà pẹ̀lú àìnímọ̀. Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

6:145

قُل لَّآ أَجِدُ فِي مَآ أُوحِيَ إِلَيَّ مُحَرَّمًا عَلَىٰ طَاعِمٖ يَطۡعَمُهُۥٓ إِلَّآ أَن يَكُونَ مَيۡتَةً أَوۡ دَمٗا مَّسۡفُوحًا أَوۡ لَحۡمَ خِنزِيرٖ فَإِنَّهُۥ رِجۡسٌ أَوۡ فِسۡقًا أُهِلَّ لِغَيۡرِ ٱللَّهِ بِهِۦۚ فَمَنِ ٱضۡطُرَّ غَيۡرَ بَاغٖ وَلَا عَادٖ فَإِنَّ رَبَّكَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿145﴾

Transliteration: Qul la ajidu fee ma oohiya ilayya muharraman AAala taAAimin yatAAamuhu illa an yakoona maytatan aw daman masfoohan aw lahma khinzeerin fainnahu rijsun aw fisqan ohilla lighayri Allahi bihi famani idturra ghayra baghin wala AAadin fainna rabbaka ghafoorun raheemun

Translation: Sọ pé: “Èmi kò rí nínú ohun tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi tí wọ́n ṣe ní èèwọ̀ fún ẹni tí ó ń jẹ ẹ́ àfi ohun tí ó bá jẹ́ ẹran òkúǹbete tàbí ẹ̀jẹ̀ tí ó tú jáde lára ẹran (yálà nípasẹ̀ dídúńbú, gígún tàbí títalọ́fà) tàbí ẹran ẹlẹ́dẹ̀ nítorí pé dájúdájú ẹ̀gbin ni, tàbí ẹran ìyapa (àṣẹ Allāhu) tí wọ́n pa pẹ̀lú pípe orúkọ mìíràn lé e lórí yàtọ̀ sí (orúkọ) Allāhu. Nítorí náà, ẹni tí ìnira (ebi) bá mú, yàtọ̀ sí ẹni tó ń wá èèwọ̀ kiri àti olùtayọ-ẹnu-ààlà,2 dájúdájú Olúwa rẹ ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.3

6:146

وَعَلَى ٱلَّذِينَ هَادُواْ حَرَّمۡنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٖۖ وَمِنَ ٱلۡبَقَرِ وَٱلۡغَنَمِ حَرَّمۡنَا عَلَيۡهِمۡ شُحُومَهُمَآ إِلَّا مَا حَمَلَتۡ ظُهُورُهُمَآ أَوِ ٱلۡحَوَايَآ أَوۡ مَا ٱخۡتَلَطَ بِعَظۡمٖۚ ذَٰلِكَ جَزَيۡنَٰهُم بِبَغۡيِهِمۡۖ وَإِنَّا لَصَٰدِقُونَ ﴿146﴾

Transliteration: WaAAala allatheena hadoo harramna kulla thee thufurin wamina albaqari waalghanami harramna AAalayhim shuhoomahuma illa ma hamalat thuhooruhuma awi alhawaya aw ma ikhtalata biAAathmin thalika jazaynahum bibaghyihim wainna lasadiqoona

Translation: A ṣe é ní èèwọ̀ fún àwọn tó di yẹhudi gbogbo ẹran tó ní èékánná tàbí pátákò tó ṣùpọ̀ mọ́ra wọn. Nínú ẹran màálù àti àgùtàn, A tún ṣe ọ̀rá àwọn méjèèjì ní èèwọ̀ fún wọn àfi èyí tí ó bá lẹ̀mọ́ ẹ̀yìn wọn tàbí ìfun tàbí èyí tí ó bá yípọ̀ mọ́ eegun. Ìyẹn ni A fi san wọ́n ní ẹ̀san nítorí àbòsí ọwọ́ wọn. Dájúdájú Àwa sì ni Olódodo.

6:147

فَإِن كَذَّبُوكَ فَقُل رَّبُّكُمۡ ذُو رَحۡمَةٖ وَٰسِعَةٖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُهُۥ عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ﴿147﴾

Transliteration: Fain kaththabooka faqul rabbukum thoo rahmatin wasiAAatin wala yuraddu basuhu AAani alqawmi almujrimeena

Translation: Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, sọ nígbà náà pé: “Olúwa yín ni Oníkẹ̀ẹ́ tó gbòòrò. Kò sì sí ẹni tó lè gbé ìyà Rẹ̀ kúrò lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.”

6:148

سَيَقُولُ ٱلَّذِينَ أَشۡرَكُواْ لَوۡ شَآءَ ٱللَّهُ مَآ أَشۡرَكۡنَا وَلَآ ءَابَآؤُنَا وَلَا حَرَّمۡنَا مِن شَيۡءٖۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِهِمۡ حَتَّىٰ ذَاقُواْ بَأۡسَنَاۗ قُلۡ هَلۡ عِندَكُم مِّنۡ عِلۡمٖ فَتُخۡرِجُوهُ لَنَآۖ إِن تَتَّبِعُونَ إِلَّا ٱلظَّنَّ وَإِنۡ أَنتُمۡ إِلَّا تَخۡرُصُونَ ﴿148﴾

Transliteration: Sayaqoolu allatheena ashrakoo law shaa Allahu ma ashrakna wala abaona wala harramna min shayin kathalika kaththaba allatheena min qablihim hatta thaqoo basana qul hal AAindakum min AAilmin fatukhrijoohu lana in tattabiAAoona illa alththanna wain antum illa takhrusoona

Translation: Àwọn tó ń ṣẹbọ yóò wí pé: “Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́ ni àwa àti àwọn bàbá wa ìbá tí ṣẹbọ, àti pé àwa ìbá tí ṣe n̄ǹkan kan ní èèwọ̀.” Báyẹn ni àwọn tó ṣíwájú wọn ṣe pe ọ̀rọ̀ Allāhu nírọ́ títí wọ́n fi tọ́ ìyà Wa wò. Sọ pé: “Ǹjẹ́ ìmọ̀ kan ń bẹ ní ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ mú un jáde fún wa?” Ẹ̀yin kò tẹ̀lé kiní kan bí kò ṣe àbá dídá. Kí sì ni ẹ̀ ń sọ bí kò ṣe pé ẹ̀ ń parọ́.

6:149

قُلۡ فَلِلَّهِ ٱلۡحُجَّةُ ٱلۡبَٰلِغَةُۖ فَلَوۡ شَآءَ لَهَدَىٰكُمۡ أَجۡمَعِينَ ﴿149﴾

Transliteration: Qul falillahi alhujjatu albalighatu falaw shaa lahadakum ajmaAAeena

Translation: Sọ pé: “Ti Allāhu ni ẹ̀rí tó dópin. Nítorí náà, tí Ó bá fẹ́ ni, ìbá fi gbogbo yín mọ̀nà pátápátá.”

6:150

قُلۡ هَلُمَّ شُهَدَآءَكُمُ ٱلَّذِينَ يَشۡهَدُونَ أَنَّ ٱللَّهَ حَرَّمَ هَٰذَاۖ فَإِن شَهِدُواْ فَلَا تَشۡهَدۡ مَعَهُمۡۚ وَلَا تَتَّبِعۡ أَهۡوَآءَ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِنَا وَٱلَّذِينَ لَا يُؤۡمِنُونَ بِٱلۡأٓخِرَةِ وَهُم بِرَبِّهِمۡ يَعۡدِلُونَ ﴿150﴾

Transliteration: Qul halumma shuhadaakumu allatheena yashhadoona anna Allaha harrama hatha fain shahidoo fala tashhad maAAahum wala tattabiAA ahwaa allatheena kaththaboo biayatina waallatheena la yuminoona bialakhirati wahum birabbihim yaAAdiloona

Translation: Sọ pé: “Ẹ mú àwọn ẹlẹ́rìí yín jáde, àwọn tó máa jẹ́rìí pé dájúdájú Allāhu l’ó ṣe èyí ní èèwọ̀.” Tí wọ́n bá jẹ́rìí (irọ́), ìwọ má ṣe bá wọn jẹ́rìí (sí i). Má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú àwọn tó pe àwọn āyah Wa nírọ́ àti àwọn tí kò gba Ọjọ́ Ìkẹ́yìn gbọ́. Àwọn sì ni wọ́n ń bá Olúwa wọn wá akẹgbẹ́.

6:151

قُلۡ تَعَالَوۡاْ أَتۡلُ مَا حَرَّمَ رَبُّكُمۡ عَلَيۡكُمۡۖ أَلَّا تُشۡرِكُواْ بِهِۦ شَيۡـٔٗاۖ وَبِٱلۡوَٰلِدَيۡنِ إِحۡسَٰنٗاۖ وَلَا تَقۡتُلُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُم مِّنۡ إِمۡلَٰقٖ نَّحۡنُ نَرۡزُقُكُمۡ وَإِيَّاهُمۡۖ وَلَا تَقۡرَبُواْ ٱلۡفَوَٰحِشَ مَا ظَهَرَ مِنۡهَا وَمَا بَطَنَۖ وَلَا تَقۡتُلُواْ ٱلنَّفۡسَ ٱلَّتِي حَرَّمَ ٱللَّهُ إِلَّا بِٱلۡحَقِّۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَعۡقِلُونَ ﴿151﴾

Transliteration: Qul taAAalaw atlu ma harrama rabbukum AAalaykum alla tushrikoo bihi shayan wabialwalidayni ihsanan wala taqtuloo awladakum min imlaqin nahnu narzuqukum waiyyahum wala taqraboo alfawahisha ma thahara minha wama batana wala taqtuloo alnnafsa allatee harrama Allahu illa bialhaqqi thalikum wassakum bihi laAAallakum taAAqiloona

Translation: Sọ pé: “Ẹ wá kí n̄g ka ohun tí Olúwa yín ṣe ní èèwọ̀ fún yín pé; kí ẹ má ṣe fí n̄ǹkan kan ṣẹbọ sí I, (kí ẹ sì ṣe) dáadáa sí àwọn òbí (yín) méjèèjì, kí ẹ sì má ṣe pa àwọn ọmọ yín nítorí (ìbẹ̀rù) òṣì, - Àwa ni À ń pèsè fun ẹ̀yin àti àwọn - kí ẹ sì má ṣe súnmọ́ àwọn ìwà ìbájẹ́ - èyí tó hàn nínú rẹ̀ àti èyí tó pamọ́, - àti pé kí ẹ sì má ṣe pa ẹ̀mí (ènìyàn) tí Allāhu ṣe ní èèwọ̀ àyàfi ní ọ̀nà ẹ̀tọ́. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè ṣe làákàyè.

6:152

وَلَا تَقۡرَبُواْ مَالَ ٱلۡيَتِيمِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ حَتَّىٰ يَبۡلُغَ أَشُدَّهُۥۚ وَأَوۡفُواْ ٱلۡكَيۡلَ وَٱلۡمِيزَانَ بِٱلۡقِسۡطِۖ لَا نُكَلِّفُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۖ وَإِذَا قُلۡتُمۡ فَٱعۡدِلُواْ وَلَوۡ كَانَ ذَا قُرۡبَىٰۖ وَبِعَهۡدِ ٱللَّهِ أَوۡفُواْۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَذَكَّرُونَ ﴿152﴾

Transliteration: Wala taqraboo mala alyateemi illa biallatee hiya ahsanu hatta yablugha ashuddahu waawfoo alkayla waalmeezana bialqisti la nukallifu nafsan illa wusAAaha waitha qultum faiAAdiloo walaw kana tha qurba wabiAAahdi Allahi awfoo thalikum wassakum bihi laAAallakum tathakkaroona

Translation: Ẹ má ṣe súnmọ́ dúkìá ọmọ òrukàn àyàfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ títí ó fi máa dàgbà dáadáa. Ẹ wọn kóńgò àti òṣùwọ̀n kún ní dọ́gban̄n̄dọ́gba.A kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àyàfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Tí ẹ bá sọ̀rọ̀, ẹ ṣe déédé, ìbáà jẹ́ ìbátan. Kí ẹ sì pé àdéhùn Allāhu. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè lo ìrántí.

6:153

وَأَنَّ هَٰذَا صِرَٰطِي مُسۡتَقِيمٗا فَٱتَّبِعُوهُۖ وَلَا تَتَّبِعُواْ ٱلسُّبُلَ فَتَفَرَّقَ بِكُمۡ عَن سَبِيلِهِۦۚ ذَٰلِكُمۡ وَصَّىٰكُم بِهِۦ لَعَلَّكُمۡ تَتَّقُونَ ﴿153﴾

Transliteration: Waanna hatha siratee mustaqeeman faittabiAAoohu wala tattabiAAoo alssubula fatafarraqa bikum AAan sabeelihi thalikum wassakum bihi laAAallakum tattaqoona

Translation: Àti pé dájúdájú èyí ni ọ̀nà Mi (tí ó jẹ́ ọ̀nà) tààrà. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Ẹ má ṣe tẹ̀lé àwọn ojú ọ̀nà (mìíràn) nítorí kí ó má baà mu yín yapa ojú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Rẹ̀. Ìyẹn l’Ó pa láṣẹ fún yín nítorí kí ẹ lè bẹ̀rù (Rẹ̀).”

6:154

ثُمَّ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ تَمَامًا عَلَى ٱلَّذِيٓ أَحۡسَنَ وَتَفۡصِيلٗا لِّكُلِّ شَيۡءٖ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٗ لَّعَلَّهُم بِلِقَآءِ رَبِّهِمۡ يُؤۡمِنُونَ ﴿154﴾

Transliteration: Thumma atayna moosa alkitaba tamaman AAala allathee ahsana watafseelan likulli shayin wahudan warahmatan laAAallahum biliqai rabbihim yuminoona

Translation: Lẹ́yìn náà, A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà ní pípé pérépéré fún ẹni tí ó máa ṣe dáadáa. (Ó jẹ́) àlàyé fún gbogbo n̄ǹkan. (Ó tún jẹ́) ìmọ̀nà àti ìkẹ́ nítorí kí wọ́n lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìpàdé Olúwa wọn.

6:155

وَهَٰذَا كِتَٰبٌ أَنزَلۡنَٰهُ مُبَارَكٞ فَٱتَّبِعُوهُ وَٱتَّقُواْ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ ﴿155﴾

Transliteration: Wahatha kitabun anzalnahu mubarakun faittabiAAoohu waittaqoo laAAallakum turhamoona

Translation: Èyí ni Tírà ìbùkún tí A sọ̀kalẹ̀. Nítorí náà, ẹ tẹ̀lé e. Kí ẹ sì bẹ̀rù (Allāhu) nítorí kí A lè kẹ yín.

6:156

أَن تَقُولُوٓاْ إِنَّمَآ أُنزِلَ ٱلۡكِتَٰبُ عَلَىٰ طَآئِفَتَيۡنِ مِن قَبۡلِنَا وَإِن كُنَّا عَن دِرَاسَتِهِمۡ لَغَٰفِلِينَ ﴿156﴾

Transliteration: An taqooloo innama onzila alkitabu AAala taifatayni min qablina wain kunna AAan dirasatihim laghafileena

Translation: Nítorí kí ẹ má ṣe wí pé: “Ọ̀wọ́ ìjọ méjì tí ó ṣíwájú wa ni wọ́n sọ Tírà kalẹ̀ fún. A sì jẹ́ aláìnímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ wọn.”

6:157

أَوۡ تَقُولُواْ لَوۡ أَنَّآ أُنزِلَ عَلَيۡنَا ٱلۡكِتَٰبُ لَكُنَّآ أَهۡدَىٰ مِنۡهُمۡۚ فَقَدۡ جَآءَكُم بَيِّنَةٞ مِّن رَّبِّكُمۡ وَهُدٗى وَرَحۡمَةٞۚ فَمَنۡ أَظۡلَمُ مِمَّن كَذَّبَ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِ وَصَدَفَ عَنۡهَاۗ سَنَجۡزِي ٱلَّذِينَ يَصۡدِفُونَ عَنۡ ءَايَٰتِنَا سُوٓءَ ٱلۡعَذَابِ بِمَا كَانُواْ يَصۡدِفُونَ ﴿157﴾

Transliteration: Aw taqooloo law anna onzila AAalayna alkitabu lakunna ahda minhum faqad jaakum bayyinatun min rabbikum wahudan warahmatun faman athlamu mimman kaththaba biayati Allahi wasadafa AAanha sanajzee allatheena yasdifoona AAan ayatina sooa alAAathabi bima kanoo yasdifoona

Translation: Tàbí kí ẹ má baà wí pé: “Dájúdájú wọn ìbá sọ Tírà kalẹ̀ fún wa ni, àwa ìbá mọ̀nà jù wọ́n lọ.” Ẹ̀rí tó yanjú, ìmọ̀nà àti ìkẹ́ kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín. Nítorí náà, ta ni ó ṣe àbòsí ju ẹni tó pe àwọn āyah Allāhu nírọ́, tó tún gbúnrí kúrò níbẹ̀? A máa san àwọn tó ń gbúnrí kúrò níbi àwọn āyah Wa ní (ẹ̀san) ìyà burúkú nítorí pé wọ́n ń gbúnrí(kúrò níbẹ̀).

6:158

هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن تَأۡتِيَهُمُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ أَوۡ يَأۡتِيَ رَبُّكَ أَوۡ يَأۡتِيَ بَعۡضُ ءَايَٰتِ رَبِّكَۗ يَوۡمَ يَأۡتِي بَعۡضُ ءَايَٰتِ رَبِّكَ لَا يَنفَعُ نَفۡسًا إِيمَٰنُهَا لَمۡ تَكُنۡ ءَامَنَتۡ مِن قَبۡلُ أَوۡ كَسَبَتۡ فِيٓ إِيمَٰنِهَا خَيۡرٗاۗ قُلِ ٱنتَظِرُوٓاْ إِنَّا مُنتَظِرُونَ ﴿158﴾

Transliteration: Hal yanthuroona illa an tatiyahumu almalaikatu aw yatiya rabbuka aw yatiya baAAdu ayati rabbika yawma yatee baAAdu ayati rabbika la yanfaAAu nafsan eemanuha lam takun amanat min qablu aw kasabat fee eemaniha khayran quli intathiroo inna muntathiroona

Translation: Ṣé wọ́n ń retí n̄ǹkan (mìíràn) bí kò ṣe pé kí àwọn mọlāika wá bá wọn tàbí kí Olúwa rẹ wá bá wọn tàbí kí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ wá bá wọn? Ní ọjọ́ tí apá kan àwọn àmì Olúwa rẹ bá wá bá wọn, ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà). Sọ pé: “Ẹ máa retí, dájúdájú Àwa náà ń retí (Ọjọ́ náà).

6:159

إِنَّ ٱلَّذِينَ فَرَّقُواْ دِينَهُمۡ وَكَانُواْ شِيَعٗا لَّسۡتَ مِنۡهُمۡ فِي شَيۡءٍۚ إِنَّمَآ أَمۡرُهُمۡ إِلَى ٱللَّهِ ثُمَّ يُنَبِّئُهُم بِمَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ ﴿159﴾

Transliteration: Inna allatheena farraqoo deenahum wakanoo shiyaAAan lasta minhum fee shayin innama amruhum ila Allahi thumma yunabbiohum bima kanoo yafAAaloona

Translation: Dájúdájú àwọn tó ya ẹ̀sìn wọn sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì di ìjọ-ìjọ, ìwọ kò ní n̄ǹkan kan ṣepọ̀ pẹ̀lú wọn. Ọ̀rọ̀ wọn sì ń bẹ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́.

6:160

مَن جَآءَ بِٱلۡحَسَنَةِ فَلَهُۥ عَشۡرُ أَمۡثَالِهَاۖ وَمَن جَآءَ بِٱلسَّيِّئَةِ فَلَا يُجۡزَىٰٓ إِلَّا مِثۡلَهَا وَهُمۡ لَا يُظۡلَمُونَ ﴿160﴾

Transliteration: Man jaa bialhasanati falahu AAashru amthaliha waman jaa bialssayyiati fala yujza illa mithlaha wahum la yuthlamoona

Translation: Ẹnikẹ́ni tó bá mú iṣẹ́ dáadáa wá, (ẹ̀san) mẹ́wàá irú rẹ̀ l’ó máa wà fún un. Ẹnikẹ́ni tó bá sì mú iṣẹ́ aburú wa, A ò níí san án ní ẹ̀san àyàfi irú rẹ̀. A ò sì níí ṣàbòsí sí wọn.

6:161

قُلۡ إِنَّنِي هَدَىٰنِي رَبِّيٓ إِلَىٰ صِرَٰطٖ مُّسۡتَقِيمٖ دِينٗا قِيَمٗا مِّلَّةَ إِبۡرَٰهِيمَ حَنِيفٗاۚ وَمَا كَانَ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿161﴾

Transliteration: Qul innanee hadanee rabbee ila siratin mustaqeemin deenan qiyaman millata ibraheema haneefan wama kana mina almushrikeena

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú Olúwa mi ti fi ọ̀nà tààrà (’Islām) mọ̀ mí, ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀, ẹ̀sìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn, kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”

6:162

قُلۡ إِنَّ صَلَاتِي وَنُسُكِي وَمَحۡيَايَ وَمَمَاتِي لِلَّهِ رَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿162﴾

Transliteration: Qul inna salatee wanusukee wamahyaya wamamatee lillahi rabbi alAAalameena

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú ìrun mi, ẹran(pípa) mi, ìṣẹ̀mí ayé mi àti ikú mi ń jẹ́ ti Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.

6:163

لَا شَرِيكَ لَهُۥۖ وَبِذَٰلِكَ أُمِرۡتُ وَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡمُسۡلِمِينَ ﴿163﴾

Transliteration: La shareeka lahu wabithalika omirtu waana awwalu almuslimeena

Translation: Kò sí akẹgbẹ́ fún Un. Ìyẹn ni wọ́n pa láṣẹ fún mi. Èmi sì ni ẹni-àkọ́kọ́ àwọn mùsùlùmí (ní àsìkò tèmi).”1

6:164

قُلۡ أَغَيۡرَ ٱللَّهِ أَبۡغِي رَبّٗا وَهُوَ رَبُّ كُلِّ شَيۡءٖۚ وَلَا تَكۡسِبُ كُلُّ نَفۡسٍ إِلَّا عَلَيۡهَاۚ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٞ وِزۡرَ أُخۡرَىٰۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّكُم مَّرۡجِعُكُمۡ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ فِيهِ تَخۡتَلِفُونَ ﴿164﴾

Transliteration: Qul aghayra Allahi abghee rabban wahuwa rabbu kulli shayin wala taksibu kullu nafsin illa AAalayha wala taziru waziratun wizra okhra thumma ila rabbikum marjiAAukum fayunabbiokum bima kuntum feehi takhtalifoona

Translation: Sọ pé: “Ṣé èmi yóò tún wá olúwa kan yàtọ̀ sí Allāhu ni, nígbà tí ó jẹ́ pé Òun ni Olúwa gbogbo n̄ǹkan. Ẹ̀mí kan kò sì níí ṣe iṣẹ́ kan àfi fún ẹ̀mí ara rẹ̀. Ẹlẹ́rù-ẹ̀ṣẹ̀ kan kò sì níí ru ẹ̀ṣẹ̀ ẹlòmíìràn. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Olúwa yín ni ibùpadàsí yín. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń yapa ẹnu sí.”

6:165

وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَكُمۡ خَلَـٰٓئِفَ ٱلۡأَرۡضِ وَرَفَعَ بَعۡضَكُمۡ فَوۡقَ بَعۡضٖ دَرَجَٰتٖ لِّيَبۡلُوَكُمۡ فِي مَآ ءَاتَىٰكُمۡۗ إِنَّ رَبَّكَ سَرِيعُ ٱلۡعِقَابِ وَإِنَّهُۥ لَغَفُورٞ رَّحِيمُۢ ﴿165﴾

Transliteration: Wahuwa allathee jaAAalakum khalaifa alardi warafaAAa baAAdakum fawqa baAAdin darajatin liyabluwakum fee ma atakum inna rabbaka sareeAAu alAAiqabi wainnahu laghafoorun raheemun

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó ṣe yín ní àrólé lórí ilẹ̀. Ó sì fi àwọn ipò gbe yín ga ju ara yín lọ nítorí kí Ó lè dan yín wò nínú ohun tí Ó fún yín. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Olùyára níbi ìyà. Dájúdájú Òun sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.”

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download