quranm◉

Surah Al-Mumtahanah transliteration

◉ Súrá · ∞

60:1

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَّخِذُواْ عَدُوِّي وَعَدُوَّكُمۡ أَوۡلِيَآءَ تُلۡقُونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَقَدۡ كَفَرُواْ بِمَا جَآءَكُم مِّنَ ٱلۡحَقِّ يُخۡرِجُونَ ٱلرَّسُولَ وَإِيَّاكُمۡ أَن تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ رَبِّكُمۡ إِن كُنتُمۡ خَرَجۡتُمۡ جِهَٰدٗا فِي سَبِيلِي وَٱبۡتِغَآءَ مَرۡضَاتِيۚ تُسِرُّونَ إِلَيۡهِم بِٱلۡمَوَدَّةِ وَأَنَا۠ أَعۡلَمُ بِمَآ أَخۡفَيۡتُمۡ وَمَآ أَعۡلَنتُمۡۚ وَمَن يَفۡعَلۡهُ مِنكُمۡ فَقَدۡ ضَلَّ سَوَآءَ ٱلسَّبِيلِ ﴿1﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la tattakhithoo AAaduwwee waAAaduwwakum awliyaa tulqoona ilayhim bialmawaddati waqad kafaroo bima jaakum mina alhaqqi yukhrijoona alrrasoola waiyyakum an tuminoo biAllahi rabbikum in kuntum kharajtum jihadan fee sabeelee waibtighaa mardatee tusirroona ilayhim bialmawaddati waana aAAlamu bima akhfaytum wama aAAlantum waman yafAAalhu minkum faqad dalla sawaa alssabeeli

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun nítorí ẹ̀sìn Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.

60:2

إِن يَثۡقَفُوكُمۡ يَكُونُواْ لَكُمۡ أَعۡدَآءٗ وَيَبۡسُطُوٓاْ إِلَيۡكُمۡ أَيۡدِيَهُمۡ وَأَلۡسِنَتَهُم بِٱلسُّوٓءِ وَوَدُّواْ لَوۡ تَكۡفُرُونَ ﴿2﴾

Transliteration: In yathqafookum yakoonoo lakam aAAdaan wayabsutoo ilaykum aydiyahum waalsinatahum bialssooi wawaddoo law takfuroona

Translation: Tí ọwọ́ wọn bá bà yín, wọ́n máa di ọ̀tá fún yín. Wọn yó sì fi ọwọ́ wọn àti ahọ́n wọn nawọ́ aburú si yín. Wọ́n sì máa fẹ́ kí ó jẹ́ pé ẹ di aláìgbàgbọ́.

60:3

لَن تَنفَعَكُمۡ أَرۡحَامُكُمۡ وَلَآ أَوۡلَٰدُكُمۡۚ يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِ يَفۡصِلُ بَيۡنَكُمۡۚ وَٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ﴿3﴾

Transliteration: Lan tanfaAAakum arhamukum wala awladukum yawma alqiyamati yafsilu baynakum waAllahu bima taAAmaloona baseerun

Translation: Àwọn ẹbí yín àti àwọn ọmọ yín kò lè ṣe yín ní àǹfààní; ní Ọjọ́ Àjíǹde ni Allāhu máa ṣèpínyà láààrin yín. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.

60:4

قَدۡ كَانَتۡ لَكُمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ فِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ وَٱلَّذِينَ مَعَهُۥٓ إِذۡ قَالُواْ لِقَوۡمِهِمۡ إِنَّا بُرَءَـٰٓؤُاْ مِنكُمۡ وَمِمَّا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ كَفَرۡنَا بِكُمۡ وَبَدَا بَيۡنَنَا وَبَيۡنَكُمُ ٱلۡعَدَٰوَةُ وَٱلۡبَغۡضَآءُ أَبَدًا حَتَّىٰ تُؤۡمِنُواْ بِٱللَّهِ وَحۡدَهُۥٓ إِلَّا قَوۡلَ إِبۡرَٰهِيمَ لِأَبِيهِ لَأَسۡتَغۡفِرَنَّ لَكَ وَمَآ أَمۡلِكُ لَكَ مِنَ ٱللَّهِ مِن شَيۡءٖۖ رَّبَّنَا عَلَيۡكَ تَوَكَّلۡنَا وَإِلَيۡكَ أَنَبۡنَا وَإِلَيۡكَ ٱلۡمَصِيرُ ﴿4﴾

Transliteration: Qad kanat lakum oswatun hasanatun fee ibraheema waallatheena maAAahu ith qaloo liqawmihim inna buraao minkum wamimma taAAbudoona min dooni Allahi kafarna bikum wabada baynana wabaynakumu alAAadawatu waalbaghdao abadan hatta tuminoo biAllahi wahdahu illa qawla ibraheema liabeehi laastaghfiranna laka wama amliku laka mina Allahi min shayin rabbana AAalayka tawakkalna wailayka anabna wailayka almaseeru

Translation: Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún ìjọ wọn pé: "Dájúdájú àwa yọwọ́-yọsẹ̀ kúrò nínú ọ̀rọ̀ yín àti ohun tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. A takò yín. Ọ̀tá àti ìkórira sì ti hàn láààrin wa títí láéláé àyàfi ìgbà tí ẹ bá tó gbàgbọ́ nínú Allāhu nìkan ṣoṣo. - Àfi ọ̀rọ̀ tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Dájúdájú mo máa tọrọ àforíjìn fún ọ, èmi kò sì ní ìkápá kiní kan fún ọ lọ́dọ̀ Allāhu. - Olúwa wa, Ìwọ l’a gbáralé. Ọ̀dọ̀ Rẹ l’a ṣẹ́rí padà sí (nípa ìronúpìwàdà). Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.

60:5

رَبَّنَا لَا تَجۡعَلۡنَا فِتۡنَةٗ لِّلَّذِينَ كَفَرُواْ وَٱغۡفِرۡ لَنَا رَبَّنَآۖ إِنَّكَ أَنتَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿5﴾

Transliteration: Rabbana la tajAAalna fitnatan lillatheena kafaroo waighfir lana rabbana innaka anta alAAazeezu alhakeemu

Translation: Olúwa wa, má ṣe wá ní àdánwò fún àwọn tó ṣàì gbàgbọ́.Foríjìn wá, Olúwa wa. Dájúdájú Ìwọ ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”

60:6

لَقَدۡ كَانَ لَكُمۡ فِيهِمۡ أُسۡوَةٌ حَسَنَةٞ لِّمَن كَانَ يَرۡجُواْ ٱللَّهَ وَٱلۡيَوۡمَ ٱلۡأٓخِرَۚ وَمَن يَتَوَلَّ فَإِنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡغَنِيُّ ٱلۡحَمِيدُ ﴿6﴾

Transliteration: Laqad kana lakum feehim oswatun hasanatun liman kana yarjoo Allaha waalyawma alakhira waman yatawalla fainna Allaha huwa alghanniyyu alhameedu

Translation: Dájúdájú àwòkọ́ṣe rere ti wà fún yín ní ara wọn fún ẹni tó ń retí (ẹ̀sán) Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbúnrí, dájúdájú Allāhu, Òun ni Ọlọ́rọ̀, Ẹlẹ́yìn.

60:7

عَسَى ٱللَّهُ أَن يَجۡعَلَ بَيۡنَكُمۡ وَبَيۡنَ ٱلَّذِينَ عَادَيۡتُم مِّنۡهُم مَّوَدَّةٗۚ وَٱللَّهُ قَدِيرٞۚ وَٱللَّهُ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿7﴾

Transliteration: AAasa Allahu an yajAAala baynakum wabayna allatheena AAadaytum minhum mawaddatan waAllahu qadeerun waAllahu ghafoorun raheemun

Translation: Ó lè jẹ́ pé Allāhu yóò fi ìfẹ́ sí ààrin ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ mú ní ọ̀tá nínú wọn (ìyẹn, nígbà tí wọ́n bá di mùsùlùmí). Allāhu ni Alágbára. Allāhu sì ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

60:8

لَّا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ لَمۡ يُقَٰتِلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَلَمۡ يُخۡرِجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ أَن تَبَرُّوهُمۡ وَتُقۡسِطُوٓاْ إِلَيۡهِمۡۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُحِبُّ ٱلۡمُقۡسِطِينَ ﴿8﴾

Transliteration: La yanhakumu Allahu AAani allatheena lam yuqatilookum fee alddeeni walam yukhrijookum min diyarikum an tabarroohum watuqsitoo ilayhim inna Allaha yuhibbu almuqsiteena

Translation: Allāhu kò kọ̀ fún yín nípa àwọn tí kò gbé ogun tì yín nípa ẹ̀sìn, tí wọn kò sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, pé kí ẹ ṣe dáadáa sí wọn, kí ẹ sì ṣe déédé sí wọn. Dájúdájú Allāhu fẹ́ràn àwọn olùṣe-déédé.

60:9

إِنَّمَا يَنۡهَىٰكُمُ ٱللَّهُ عَنِ ٱلَّذِينَ قَٰتَلُوكُمۡ فِي ٱلدِّينِ وَأَخۡرَجُوكُم مِّن دِيَٰرِكُمۡ وَظَٰهَرُواْ عَلَىٰٓ إِخۡرَاجِكُمۡ أَن تَوَلَّوۡهُمۡۚ وَمَن يَتَوَلَّهُمۡ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلظَّـٰلِمُونَ ﴿9﴾

Transliteration: Innama yanhakumu Allahu AAani allatheena qatalookum fee alddeeni waakhrajookum min diyarikum wathaharoo AAala ikhrajikum an tawallawhum waman yatawallahum faolaika humu alththalimoona

Translation: Ohun tí Allāhu kọ̀ fún yín nípa àwọn tó gbógun tì yín nínú ẹ̀sìn, tí wọ́n sì lè yín jáde kúrò nínú ìlú yín, tí wọ́n tún ṣe ìrànlọ́wọ́ (fún àwọn ọ̀tá yín) láti le yín jáde, ni pé (Ó kọ̀ fún yín) láti mú wọn ní ọ̀rẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú wọn ní ọ̀rẹ́, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí.

60:10

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا جَآءَكُمُ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ مُهَٰجِرَٰتٖ فَٱمۡتَحِنُوهُنَّۖ ٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِإِيمَٰنِهِنَّۖ فَإِنۡ عَلِمۡتُمُوهُنَّ مُؤۡمِنَٰتٖ فَلَا تَرۡجِعُوهُنَّ إِلَى ٱلۡكُفَّارِۖ لَا هُنَّ حِلّٞ لَّهُمۡ وَلَا هُمۡ يَحِلُّونَ لَهُنَّۖ وَءَاتُوهُم مَّآ أَنفَقُواْۚ وَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ أَن تَنكِحُوهُنَّ إِذَآ ءَاتَيۡتُمُوهُنَّ أُجُورَهُنَّۚ وَلَا تُمۡسِكُواْ بِعِصَمِ ٱلۡكَوَافِرِ وَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقۡتُمۡ وَلۡيَسۡـَٔلُواْ مَآ أَنفَقُواْۚ ذَٰلِكُمۡ حُكۡمُ ٱللَّهِ يَحۡكُمُ بَيۡنَكُمۡۖ وَٱللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٞ ﴿10﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo itha jaakumu almuminatu muhajiratin faimtahinoohunna Allahu aAAlamu bieemanihinna fain AAalimtumoohunna muminatin fala tarjiAAoohunna ila alkuffari la hunna hillun lahum wala hum yahilloona lahunna waatoohum ma anfaqoo wala junaha AAalaykum an tankihoohunna itha ataytumoohunna ojoorahunna wala tumsikoo biAAisami alkawafiri waisaloo ma anfaqtum walyasaloo ma anfaqoo thalikum hukmu Allahi yahkumu baynakum waAllahu AAaleemun hakeemun

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá ba yín, tí wọ́n gbé ìlú àwọn aláìgbàgbọ́ jù sílẹ̀ fún ààbò ẹ̀sìn wọn, ẹ ṣe ìdánwò fún wọn. Allāhu nímọ̀ jùlọ nípa ìgbàgbọ́ wọn. Nítorí náà, tí ẹ bá mọ̀ wọ́n sí onígbàgbọ́ òdodo, ẹ má ṣe dá wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin kò lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn. Àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin kò sì lẹ́tọ̀ọ́ sí wọn.Ẹ fún (àwọn aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin) ní owó tí wọ́n ná (ní owó-orí obìnrin náà). Kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀yin náà pé kí ẹ fẹ́ wọn nígbà tí ẹ bá ti fún (àwọn obìnrin wọ̀nyí) ní owó-orí wọn. Ẹ má ṣe fi owó-orí àwọn obìnrin yín tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mú wọn mọ́lẹ̀ (gẹ́gẹ́ bí ìyàwó yín láì jẹ́ pé wọ́n gba ’Islām pẹ̀lú yín).2 Ẹ bèèrè ohun tí ẹ ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin tí wọ́n sá lọ bá). Kí àwọn (aláìgbàgbọ́ lọ́kùnrin náà) bèèrè ohun tí àwọn náà ná (ní owó-orí wọn lọ́wọ́ ẹ̀yin tí onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin sá wá bá). Ìyẹn ni ìdájọ́ Allāhu. Ó sì ń dájọ́ láààrin yín. Allāhu sì ni Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

60:11

وَإِن فَاتَكُمۡ شَيۡءٞ مِّنۡ أَزۡوَٰجِكُمۡ إِلَى ٱلۡكُفَّارِ فَعَاقَبۡتُمۡ فَـَٔاتُواْ ٱلَّذِينَ ذَهَبَتۡ أَزۡوَٰجُهُم مِّثۡلَ مَآ أَنفَقُواْۚ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ ٱلَّذِيٓ أَنتُم بِهِۦ مُؤۡمِنُونَ ﴿11﴾

Transliteration: Wain fatakum shayon min azwajikum ila alkuffari faAAaqabtum faatoo allatheena thahabat azwajuhum mithla ma anfaqoo waittaqoo Allaha allathee antum bihi muminoona

Translation: Tí kiní kan láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó yín bá bọ́ mọ yín lọ́wọ́ sí ọ̀dọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, tí ẹ sì kórè ogun, ẹ fún àwọn tí ìyàwó wọn sá lọ ní irú òdiwọ̀n ohun tí wọ́n ná (ní owó-orí). Kí ẹ sì bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Rẹ̀.

60:12

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّبِيُّ إِذَا جَآءَكَ ٱلۡمُؤۡمِنَٰتُ يُبَايِعۡنَكَ عَلَىٰٓ أَن لَّا يُشۡرِكۡنَ بِٱللَّهِ شَيۡـٔٗا وَلَا يَسۡرِقۡنَ وَلَا يَزۡنِينَ وَلَا يَقۡتُلۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ وَلَا يَأۡتِينَ بِبُهۡتَٰنٖ يَفۡتَرِينَهُۥ بَيۡنَ أَيۡدِيهِنَّ وَأَرۡجُلِهِنَّ وَلَا يَعۡصِينَكَ فِي مَعۡرُوفٖ فَبَايِعۡهُنَّ وَٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُنَّ ٱللَّهَۚ إِنَّ ٱللَّهَ غَفُورٞ رَّحِيمٞ ﴿12﴾

Transliteration: Ya ayyuha alnnabiyyu itha jaaka almuminatu yubayiAAnaka AAala an la yushrikna biAllahi shayan wala yasriqna wala yazneena wala yaqtulna awladahunna wala yateena bibuhtanin yaftareenahu bayna aydeehinna waarjulihinna wala yaAAseenaka fee maAAroofin fabayiAAhunna waistaghfir lahunna Allaha inna Allaha ghafoorun raheemun

Translation: Ìwọ Ànábì, nígbà tí àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin bá wá bá ọ, tí wọ́n ń ṣe àdéhùn fún ọ pé àwọn kò níí fi kiní kan ṣẹbọ sí Allāhu, àwọn kò níí jalè, àwọn kò níí ṣe sìná, àwọn kò níí pa ọmọ wọn, àwọn kò níí mú àdápa irọ́ wá, àdápa irọ́ tí wọ́n ń mú wá láààrin ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn (ìyẹn ni gbígbé oyún olóyún fún ọkọ wọn), àwọn kò sì níí yapa rẹ níbi n̄ǹkan dáadáa, nígbà náà bá wọn ṣe àdéhùn, kí ó sì bá wọn tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Allāhu. Dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.

60:13

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ قَدۡ يَئِسُواْ مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِ كَمَا يَئِسَ ٱلۡكُفَّارُ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡقُبُورِ ﴿13﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo la tatawallaw qawman ghadiba Allahu AAalayhim qad yaisoo mina alakhirati kama yaisa alkuffaru min ashabi alquboori

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́).

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download