quranm◉

Ojúewé 293

Range
from 17:105 to 18:4
Surahs covered
Ìtumọ̀
11 Ìtumọ̀

◉

17:105

وَبِٱلۡحَقِّ أَنزَلۡنَٰهُ وَبِٱلۡحَقِّ نَزَلَۗ وَمَآ أَرۡسَلۡنَٰكَ إِلَّا مُبَشِّرٗا وَنَذِيرٗا ﴿105﴾

A sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. Ó sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú òdodo. A kò sì rán ọ níṣẹ́ bí kò ṣe pé (kí o jẹ́) oníròó-ìdùnnú àti olùkìlọ̀.1

17:106

وَقُرۡءَانٗا فَرَقۡنَٰهُ لِتَقۡرَأَهُۥ عَلَى ٱلنَّاسِ عَلَىٰ مُكۡثٖ وَنَزَّلۡنَٰهُ تَنزِيلٗا ﴿106﴾

Àti pé al-Ƙur’ān, A ṣàlàyé rẹ̀ (fún ọ) nítorí kí o lè ké e fún àwọn ènìyàn pẹ̀lú pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. A sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ díẹ̀ díẹ̀.1

17:107

قُلۡ ءَامِنُواْ بِهِۦٓ أَوۡ لَا تُؤۡمِنُوٓاْۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ أُوتُواْ ٱلۡعِلۡمَ مِن قَبۡلِهِۦٓ إِذَا يُتۡلَىٰ عَلَيۡهِمۡ يَخِرُّونَۤ لِلۡأَذۡقَانِۤ سُجَّدٗاۤ ﴿107﴾

Sọ pé: “Ẹ gbàgbọ́ nínú al-Ƙur’ān gbọ́ tàbí ẹ kò gbàgbọ́ nínú rẹ̀, dájúdájú àwọn tí A fún ní ìmọ̀ ṣíwájú (ìsọ̀kalẹ̀) rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ń ké e fún wọn, wọn yóò dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).

17:108

وَيَقُولُونَ سُبۡحَٰنَ رَبِّنَآ إِن كَانَ وَعۡدُ رَبِّنَا لَمَفۡعُولٗا ﴿108﴾

Wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́ ni fún Olúwa wa. Dájúdájú àdéhùn Olúwa wa máa wá sí ìmúṣẹ ni.”

17:109

وَيَخِرُّونَ لِلۡأَذۡقَانِ يَبۡكُونَ وَيَزِيدُهُمۡ خُشُوعٗا۩ ﴿109﴾

Wọ́n ń dojú bolẹ̀, tí wọ́n yóò máa sunkún (fún Allāhu. Al-Ƙur’ān) sì ń ṣàlékún ìtẹríba fún wọn.

17:110

قُلِ ٱدۡعُواْ ٱللَّهَ أَوِ ٱدۡعُواْ ٱلرَّحۡمَٰنَۖ أَيّٗا مَّا تَدۡعُواْ فَلَهُ ٱلۡأَسۡمَآءُ ٱلۡحُسۡنَىٰۚ وَلَا تَجۡهَرۡ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتۡ بِهَا وَٱبۡتَغِ بَيۡنَ ذَٰلِكَ سَبِيلٗا ﴿110﴾

Sọ pé: “Ẹ pe Allāhu tàbí ẹ pe ar-Rahmọ̄n (Àjọkẹ́-ayé).”Èyíkéyìí tí ẹ bá fi pè É (nínú rẹ̀), ṣebí tiRẹ̀ ni àwọn orúkọ tó dára jùlọ. Má ṣe kígbe lórí ìrun (àti àdúà) rẹ. Má sì ṣe wà ní ìdákẹ́ rọ́rọ́. Wá ọ̀nà sáààrin méjèèjì yẹn.

17:111

وَقُلِ ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِي لَمۡ يَتَّخِذۡ وَلَدٗا وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ شَرِيكٞ فِي ٱلۡمُلۡكِ وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ وَلِيّٞ مِّنَ ٱلذُّلِّۖ وَكَبِّرۡهُ تَكۡبِيرَۢا ﴿111﴾

Kí o sì sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu,Ẹni tí kò fi ẹnì kan ṣe ọmọ. Kò sì ní akẹgbẹ́ nínú ìjọba. Kò sì ní ọ̀rẹ́ kan torí àìlágbára.”2 Gbé títóbi fún Un gan-an.

18:1

ٱلۡحَمۡدُ لِلَّهِ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ عَلَىٰ عَبۡدِهِ ٱلۡكِتَٰبَ وَلَمۡ يَجۡعَل لَّهُۥ عِوَجَاۜ ﴿1﴾

Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, Ẹni tí Ó sọ Tírà kalẹ̀ fún ẹrúsìn Rẹ̀. Kò sì dojú ọ̀rọ̀ kan rú nínú rẹ̀.

18:2

قَيِّمٗا لِّيُنذِرَ بَأۡسٗا شَدِيدٗا مِّن لَّدُنۡهُ وَيُبَشِّرَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ٱلَّذِينَ يَعۡمَلُونَ ٱلصَّـٰلِحَٰتِ أَنَّ لَهُمۡ أَجۡرًا حَسَنٗا ﴿2﴾

(Ó ṣe é ni tírà) tó dúró déédénítorí kí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) lè fi ṣe ìkìlọ̀ ìyà líle láti ọ̀dọ̀ (Allāhu) àti nítorí kí ó lè fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo, àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ rere ní ìró ìdùnnú pé dájúdájú ẹ̀san rere ń bẹ fún wọn (nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra);

18:3

مَّـٰكِثِينَ فِيهِ أَبَدٗا ﴿3﴾

Wọn yóò máa gbé nínú rẹ̀ lọ títí láéláé.

18:4

وَيُنذِرَ ٱلَّذِينَ قَالُواْ ٱتَّخَذَ ٱللَّهُ وَلَدٗا ﴿4﴾

Àti nítorí kí ó lè ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó wí pé: “Allāhu mú ẹnì kan ní ọmọ.”