quranm◉

Surah Al-Jumu'ah transliteration

◉ Súrá · ∞

62:1

يُسَبِّحُ لِلَّهِ مَا فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَا فِي ٱلۡأَرۡضِ ٱلۡمَلِكِ ٱلۡقُدُّوسِ ٱلۡعَزِيزِ ٱلۡحَكِيمِ ﴿1﴾

Transliteration: Yusabbihu lillahi ma fee alssamawati wama fee alardi almaliki alquddoosi alAAazeezi alhakeemi

Translation: Ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀ ń ṣe àfọ̀mọ́ fún Allāhu, Ọba ẹ̀dá, Ẹni-Mímọ́ jùlọ, Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

62:2

هُوَ ٱلَّذِي بَعَثَ فِي ٱلۡأُمِّيِّـۧنَ رَسُولٗا مِّنۡهُمۡ يَتۡلُواْ عَلَيۡهِمۡ ءَايَٰتِهِۦ وَيُزَكِّيهِمۡ وَيُعَلِّمُهُمُ ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَإِن كَانُواْ مِن قَبۡلُ لَفِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ ﴿2﴾

Transliteration: Huwa allathee baAAatha fee alommiyyeena rasoolan minhum yatloo AAalayhim ayatihi wayuzakkeehim wayuAAallimuhumu alkitaba waalhikmata wain kanoo min qablu lafee dalalin mubeenin

Translation: Òun ni Ẹni tí Ó gbé Òjíṣẹ́ kan dìde láààrin àwọn aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà (àwọn aláìnítírà), tí ó ń ké àwọn āyah Rẹ̀ fún wọn. Ó ń fọ̀ wọ́n mọ́ (nínú ẹ̀ṣẹ̀). Ó sì ń kọ́ wọn ní Tírà àti ọgbọ́n ìjìnlẹ̀ (ìyẹn, sunnah), bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n ti wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.

62:3

وَءَاخَرِينَ مِنۡهُمۡ لَمَّا يَلۡحَقُواْ بِهِمۡۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿3﴾

Transliteration: Waakhareena minhum lamma yalhaqoo bihim wahuwa alAAazeezu alhakeemu

Translation: (Iṣẹ́ jíjẹ́ rẹ̀ tún wà fún) àwọn mìíràn tí wọ́n máa wà nínú àwọn (ọmọlẹ́yìn rẹ̀), àmọ́ tí wọn kò ì pàdé wọn. (Allāhu) Òun ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

62:4

ذَٰلِكَ فَضۡلُ ٱللَّهِ يُؤۡتِيهِ مَن يَشَآءُۚ وَٱللَّهُ ذُو ٱلۡفَضۡلِ ٱلۡعَظِيمِ ﴿4﴾

Transliteration: Thalika fadlu Allahi yuteehi man yashao waAllahu thoo alfadli alAAatheemi

Translation: Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olóore-àjùlọ ńlá.

62:5

مَثَلُ ٱلَّذِينَ حُمِّلُواْ ٱلتَّوۡرَىٰةَ ثُمَّ لَمۡ يَحۡمِلُوهَا كَمَثَلِ ٱلۡحِمَارِ يَحۡمِلُ أَسۡفَارَۢاۚ بِئۡسَ مَثَلُ ٱلۡقَوۡمِ ٱلَّذِينَ كَذَّبُواْ بِـَٔايَٰتِ ٱللَّهِۚ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿5﴾

Transliteration: Mathalu allatheena hummiloo alttawrata thumma lam yahmilooha kamathali alhimari yahmilu asfaran bisa mathalu alqawmi allatheena kaththaboo biayati Allahi waAllahu la yahdee alqawma alththalimeena

Translation: Àpèjúwe ìjọ tí A la at-Taorāh bọ̀ lọ́rùn, lẹ́yìn náà tí wọn kò lò ó, ó dà bí àpèjúwe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ru ẹrù àwọn tírà ńlá ńlá. Aburú ni àpèjúwe àwọn tó pe àwọn āyah Allāhu ní irọ́. Allāhu kò sì níí fi ọ̀nà mọ ìjọ alábòsí.

62:6

قُلۡ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ هَادُوٓاْ إِن زَعَمۡتُمۡ أَنَّكُمۡ أَوۡلِيَآءُ لِلَّهِ مِن دُونِ ٱلنَّاسِ فَتَمَنَّوُاْ ٱلۡمَوۡتَ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿6﴾

Transliteration: Qul ya ayyuha allatheena hadoo in zaAAamtum annakum awliyao lillahi min dooni alnnasi fatamannawoo almawta in kuntum sadiqeena

Translation: Sọ pé: “Ẹ̀yin yẹhudi, tí ẹ bá lérò pé dájúdájú ẹ̀yin ni ọ̀rẹ́ Allāhu dípò àwọn ènìyàn (yòókù), ẹ tọrọ ikú nígbà náà tí ẹ bá jẹ́ olódodo.”

62:7

وَلَا يَتَمَنَّوۡنَهُۥٓ أَبَدَۢا بِمَا قَدَّمَتۡ أَيۡدِيهِمۡۚ وَٱللَّهُ عَلِيمُۢ بِٱلظَّـٰلِمِينَ ﴿7﴾

Transliteration: Wala yatamannawnahu abadan bima qaddamat aydeehim waAllahu AAaleemun bialththalimeena

Translation: Wọn kò níí tọrọ rẹ̀ láéláé nítorí ohun tí ọwọ́ wọn ti tì ṣíwájú. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa àwọn alábòsí.

62:8

قُلۡ إِنَّ ٱلۡمَوۡتَ ٱلَّذِي تَفِرُّونَ مِنۡهُ فَإِنَّهُۥ مُلَٰقِيكُمۡۖ ثُمَّ تُرَدُّونَ إِلَىٰ عَٰلِمِ ٱلۡغَيۡبِ وَٱلشَّهَٰدَةِ فَيُنَبِّئُكُم بِمَا كُنتُمۡ تَعۡمَلُونَ ﴿8﴾

Transliteration: Qul inna almawta allathee tafirroona minhu fainnahu mulaqeekum thumma turaddoona ila AAalimi alghaybi waalshshahadati fayunabbiokum bima kuntum taAAmaloona

Translation: Sọ pé: “Dájúdájú ikú tí ẹ̀ ń sá fún, dájúdájú ó máa pàdé yín. Lẹ́yìn náà, wọn yóò da yín padà sí ọ̀dọ̀ Onímọ̀-ìkọ̀kọ̀ àti gban̄gba. Ó sì máa fún yín ní ìró ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.”

62:9

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُوٓاْ إِذَا نُودِيَ لِلصَّلَوٰةِ مِن يَوۡمِ ٱلۡجُمُعَةِ فَٱسۡعَوۡاْ إِلَىٰ ذِكۡرِ ٱللَّهِ وَذَرُواْ ٱلۡبَيۡعَۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿9﴾

Transliteration: Ya ayyuha allatheena amanoo itha noodiya lilssalati min yawmi aljumuAAati faisAAaw ila thikri Allahi watharoo albayAAa thalikum khayrun lakum in kuntum taAAlamoona

Translation: Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá pe ìrun ní ọjọ́ Jum‘ah, ẹ yára lọ síbi ìrántí Allāhu, kí ẹ sì pa kátà-kárà tì. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.

62:10

فَإِذَا قُضِيَتِ ٱلصَّلَوٰةُ فَٱنتَشِرُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱبۡتَغُواْ مِن فَضۡلِ ٱللَّهِ وَٱذۡكُرُواْ ٱللَّهَ كَثِيرٗا لَّعَلَّكُمۡ تُفۡلِحُونَ ﴿10﴾

Transliteration: Faitha qudiyati alssalatu faintashiroo fee alardi waibtaghoo min fadli Allahi waothkuroo Allaha katheeran laAAallakum tuflihoona

Translation: Nígbà tí wọ́n bá sì parí ìrun, ẹ túká sí orí ilẹ̀, kí ẹ sì máa wa nínú oore Allāhu. Ẹ rántí Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè.

62:11

وَإِذَا رَأَوۡاْ تِجَٰرَةً أَوۡ لَهۡوًا ٱنفَضُّوٓاْ إِلَيۡهَا وَتَرَكُوكَ قَآئِمٗاۚ قُلۡ مَا عِندَ ٱللَّهِ خَيۡرٞ مِّنَ ٱللَّهۡوِ وَمِنَ ٱلتِّجَٰرَةِۚ وَٱللَّهُ خَيۡرُ ٱلرَّـٰزِقِينَ ﴿11﴾

Transliteration: Waitha raaw tijaratan aw lahwan infaddoo ilayha watarakooka qaiman qul ma AAinda Allahi khayrun mina allahwi wamina alttijarati waAllahu khayru alrraziqeena

Translation: Nígbà tí wọ́n bá rí ọjà kan tàbí ìranù kan, wọn yóò dà lọ síbẹ̀. Wọn yó sì fi ọ́ sílẹ̀ lórí ìdúró. Sọ pé: “N̄ǹkan tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Allāhu l’óore ju ìranù àti ọjà. Allāhu sì l’óore jùlọ nínú àwọn olùpèsè.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download