At-Tawbah 9:84وَلَا تُصَلِّ عَلَىٰٓ أَحَدٖ مِّنۡهُم مَّاتَ أَبَدٗا وَلَا تَقُمۡ عَلَىٰ قَبۡرِهِۦٓۖ إِنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَمَاتُواْ وَهُمۡ فَٰسِقُونَ ﴿٨٤﴾
Láéláé, o ò gbọdọ̀ kírun sí ẹnì kan kan lára nínú wọn, tí ó bá kú, o ò sì gbọdọ̀ dúró níbi sàréè rẹ̀, nítorí pé wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n wà nípò òbìlẹ̀jẹ́.
Al-Hajj 22:6ذَٰلِكَ بِأَنَّ ٱللَّهَ هُوَ ٱلۡحَقُّ وَأَنَّهُۥ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَأَنَّهُۥ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿٦﴾
Ìyẹn (rí bẹ́ẹ̀) nítorí pé dájúdájú Allāhu, Òun ni Òdodo. Dájúdájú Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Dájúdájú Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Al-Hajj 22:7وَأَنَّ ٱلسَّاعَةَ ءَاتِيَةٞ لَّا رَيۡبَ فِيهَا وَأَنَّ ٱللَّهَ يَبۡعَثُ مَن فِي ٱلۡقُبُورِ ﴿٧﴾
Àti pé dájúdájú Àkókò náà ń bọ̀. Kò sí iyèméjì nínú rẹ̀. Dájúdájú Allāhu yóò gbé àwọn tó ń bẹ nínú sàréè dìde.
Fatir 35:22وَمَا يَسۡتَوِي ٱلۡأَحۡيَآءُ وَلَا ٱلۡأَمۡوَٰتُۚ إِنَّ ٱللَّهَ يُسۡمِعُ مَن يَشَآءُۖ وَمَآ أَنتَ بِمُسۡمِعٖ مَّن فِي ٱلۡقُبُورِ ﴿٢٢﴾
Àwọn alààyè àti òkú kò dọ́gba. Dájúdájú Allāhu l’Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́ ní ọ̀rọ̀ gbọ́. Ìwọ kò sì lè fún ẹni tí ó wà nínú sàréè ní ọ̀rọ̀ gbọ́.1
Al-Mumtahanah 60:13يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَتَوَلَّوۡاْ قَوۡمًا غَضِبَ ٱللَّهُ عَلَيۡهِمۡ قَدۡ يَئِسُواْ مِنَ ٱلۡأٓخِرَةِ كَمَا يَئِسَ ٱلۡكُفَّارُ مِنۡ أَصۡحَٰبِ ٱلۡقُبُورِ ﴿١٣﴾
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ìjọ kan tí Allāhu ti bínú sí ní ọ̀rẹ́. Dájúdájú wọ́n ti sọ̀rètí nù nípa ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbàgbọ́ tó wà nínú sàréè (ṣe sọ̀rètí nù nípa ìkẹ́).
'Abasa 80:17قُتِلَ ٱلۡإِنسَٰنُ مَآ أَكۡفَرَهُۥ ﴿١٧﴾
Wọ́n ti fi ènìyàn gégùn-ún (nípa) bí ó ṣe jẹ́ aláìmoore jùlọ!
'Abasa 80:18مِنۡ أَيِّ شَيۡءٍ خَلَقَهُۥ ﴿١٨﴾
Kí sì ni Allāhu fi ṣẹ̀dá rẹ̀?
'Abasa 80:19مِن نُّطۡفَةٍ خَلَقَهُۥ فَقَدَّرَهُۥ ﴿١٩﴾
Nínú àtọ̀ l’Ó ti ṣẹ̀dá rẹ̀. Ó sì pèbùbù (ẹ̀yà-ara) rẹ̀.
'Abasa 80:20ثُمَّ ٱلسَّبِيلَ يَسَّرَهُۥ ﴿٢٠﴾
Lẹ́yìn náà, Ó ṣe ọ̀nà àtiwáyé ní ìrọ̀rùn fún un.
'Abasa 80:21ثُمَّ أَمَاتَهُۥ فَأَقۡبَرَهُۥ ﴿٢١﴾
Lẹ́yìn náà, Ó máa pa á. Ó sì máa fi sínú sàréè.
'Abasa 80:22ثُمَّ إِذَا شَآءَ أَنشَرَهُۥ ﴿٢٢﴾
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Allāhu bá fẹ́, Ó máa gbé e dìde.
Al-Infitar 82:1إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ﴿١﴾
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1
Al-Infitar 82:2وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ ﴿٢﴾
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
Al-Infitar 82:3وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ ﴿٣﴾
àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
Al-Infitar 82:4وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ ﴿٤﴾
àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
Al-Infitar 82:5عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ ﴿٥﴾
(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
Al-'Adiyat 100:9۞أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ ﴿٩﴾
Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),
Al-'Adiyat 100:10وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ ﴿١٠﴾
tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,
Al-'Adiyat 100:11إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ ﴿١١﴾
dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?
At-Takathur 102:1أَلۡهَىٰكُمُ ٱلتَّكَاثُرُ ﴿١﴾
Wíwá oore ayé ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ fún ìyanràn ṣíṣe ti kó àìrójú fẹ́sìn ba yín
At-Takathur 102:2حَتَّىٰ زُرۡتُمُ ٱلۡمَقَابِرَ ﴿٢﴾
títí ẹ fi wọ inú sàréè.
Ya-Sin 36:51وَنُفِخَ فِي ٱلصُّورِ فَإِذَا هُم مِّنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ إِلَىٰ رَبِّهِمۡ يَنسِلُونَ ﴿٥١﴾
Wọ́n á sì fọn fèrè oníwo fún àjíǹde, nígbà náà ni wọn yóò máa sáré jáde láti inú sàréè wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa wọn.
Ya-Sin 36:52قَالُواْ يَٰوَيۡلَنَا مَنۢ بَعَثَنَا مِن مَّرۡقَدِنَاۜۗ هَٰذَا مَا وَعَدَ ٱلرَّحۡمَٰنُ وَصَدَقَ ٱلۡمُرۡسَلُونَ ﴿٥٢﴾
Wọ́n á wí pé: “Ègbé wa ò! Ta ni ó ta wá jí láti ojú oorun wa?” Èyí ni n̄ǹkan tí Àjọkẹ́-ayé ṣe ní àdéhùn. Àwọn Òjíṣẹ́ sì ti sọ òdodo (nípa rẹ̀).
Ya-Sin 36:53إِن كَانَتۡ إِلَّا صَيۡحَةٗ وَٰحِدَةٗ فَإِذَا هُمۡ جَمِيعٞ لَّدَيۡنَا مُحۡضَرُونَ ﴿٥٣﴾
Kò jẹ́ kiní kan tayọ igbe ẹyọ kan ṣoṣo. Nígbà náà ni (àwọn mọlāika) yóò kó gbogbo wọn wá sí ọ̀dọ̀ Wa.
Al-Qamar 54:7خُشَّعًا أَبۡصَٰرُهُمۡ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ كَأَنَّهُمۡ جَرَادٞ مُّنتَشِرٞ ﴿٧﴾
Ojú wọn máa wálẹ̀ ní ti àbùkù. Wọn yó sì máa jáde láti inú sàréè bí ẹni pé eṣú tí wọ́n fọ́nká síta ni wọ́n.
Al-Ma'arij 70:43يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ ﴿٤٣﴾
Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
Yunus 10:18وَيَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَضُرُّهُمۡ وَلَا يَنفَعُهُمۡ وَيَقُولُونَ هَـٰٓؤُلَآءِ شُفَعَـٰٓؤُنَا عِندَ ٱللَّهِۚ قُلۡ أَتُنَبِّـُٔونَ ٱللَّهَ بِمَا لَا يَعۡلَمُ فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَلَا فِي ٱلۡأَرۡضِۚ سُبۡحَٰنَهُۥ وَتَعَٰلَىٰ عَمَّا يُشۡرِكُونَ ﴿١٨﴾
Wọ́n ń jọ́sìn fún ohun tí kò lè kó ìnira bá wọn, tí kò sì lè ṣe wọ́n ní àǹfààní lẹ́yìn Allāhu. Wọ́n sì ń wí pé: “Àwọn wọ̀nyí ni olùṣìpẹ̀ wa lọ́dọ̀ Allāhu.” Sọ pé: “Ṣé ẹ máa fún Allāhu ní ìró ohun tí kò mọ̀ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ni?” Mímọ́ ni fún Un, Ó ga tayọ n̄ǹkan tí wọ́n ń fi ṣẹbọ sí I.
Al-A'raf 7:194إِنَّ ٱلَّذِينَ تَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ عِبَادٌ أَمۡثَالُكُمۡۖ فَٱدۡعُوهُمۡ فَلۡيَسۡتَجِيبُواْ لَكُمۡ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿١٩٤﴾
Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń pè lẹ́yìn Allāhu, ẹrú bí irú yin ni wọ́n. Nítorí náà, ẹ pè wọ́n wò, kí wọ́n da yín lóhùn tí ẹ bá jẹ́ olódodo.
Yunus 10:104قُلۡ يَـٰٓأَيُّهَا ٱلنَّاسُ إِن كُنتُمۡ فِي شَكّٖ مِّن دِينِي فَلَآ أَعۡبُدُ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلَٰكِنۡ أَعۡبُدُ ٱللَّهَ ٱلَّذِي يَتَوَفَّىٰكُمۡۖ وَأُمِرۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿١٠٤﴾
Sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, tí ẹ bá wà nínú iyèméjì nípa ẹ̀sìn mi. Nígbà náà, èmi kò níí jọ́sìn fún àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu. Ṣùgbọ́n èmi yóò máa jọ́sìn fún Allāhu, Ẹni tí Ó máa gba ẹ̀mí yín. Wọ́n sì pa mí ní àṣẹ pé kí n̄g wà nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.
Ibrahim 14:35وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِيمُ رَبِّ ٱجۡعَلۡ هَٰذَا ٱلۡبَلَدَ ءَامِنٗا وَٱجۡنُبۡنِي وَبَنِيَّ أَن نَّعۡبُدَ ٱلۡأَصۡنَامَ ﴿٣٥﴾
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, ṣe ìlú yìí ní ìlú ìfàyàbalẹ̀. Kí O sì mú èmi àti àwọn ọmọ mi jìnnà sí jíjọ́sìn fún àwọn òrìṣà.
Al-Kahf 18:102أَفَحَسِبَ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَن يَتَّخِذُواْ عِبَادِي مِن دُونِيٓ أَوۡلِيَآءَۚ إِنَّآ أَعۡتَدۡنَا جَهَنَّمَ لِلۡكَٰفِرِينَ نُزُلٗا ﴿١٠٢﴾
Ṣé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lérò pé àwọn yóò mú àwọn ẹrúsìn Mi ní alátìlẹ́yìn lẹ́yìn Mi ni? Dájúdájú Àwa pèsè iná Jahanamọ sílẹ̀ ní ibùdésí fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Al-Anbya 21:66قَالَ أَفَتَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ مَا لَا يَنفَعُكُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَا يَضُرُّكُمۡ ﴿٦٦﴾
Ó sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin yóò máa jọ́sìn fún n̄ǹkan tí kò lè ṣe yín ní àǹfààní, tí kò sì lè kó ìnira ba yín lẹ́yìn Allāhu?
Al-Anbya 21:67أُفّٖ لَّكُمۡ وَلِمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِۚ أَفَلَا تَعۡقِلُونَ ﴿٦٧﴾
Ṣíọ̀ ẹ̀yin àti n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, ṣé ẹ̀yin kò níí ṣe làákàyè ni?"
Ash-Shu'ara 26:69وَٱتۡلُ عَلَيۡهِمۡ نَبَأَ إِبۡرَٰهِيمَ ﴿٦٩﴾
Ka ìròyìn (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm fún wọn.
Ash-Shu'ara 26:70إِذۡ قَالَ لِأَبِيهِ وَقَوۡمِهِۦ مَا تَعۡبُدُونَ ﴿٧٠﴾
Nígbà tí ó sọ fún bàbá rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pé: “Kí ni n̄ǹkan tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún ná?”
Ash-Shu'ara 26:71قَالُواْ نَعۡبُدُ أَصۡنَامٗا فَنَظَلُّ لَهَا عَٰكِفِينَ ﴿٧١﴾
Wọ́n wí pé: “À ń jọ́sìn fún àwọn ère òrìṣà kan ni. A ò sì níí yé takú tì wọ́n lọ́rùn.”
Al-'Ankabut 29:17إِنَّمَا تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ أَوۡثَٰنٗا وَتَخۡلُقُونَ إِفۡكًاۚ إِنَّ ٱلَّذِينَ تَعۡبُدُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَمۡلِكُونَ لَكُمۡ رِزۡقٗا فَٱبۡتَغُواْ عِندَ ٱللَّهِ ٱلرِّزۡقَ وَٱعۡبُدُوهُ وَٱشۡكُرُواْ لَهُۥٓۖ إِلَيۡهِ تُرۡجَعُونَ ﴿١٧﴾
Ẹ kàn ń jọ́sìn fún àwọn òrìṣà lẹ́yìn Allāhu. Ẹ sì ń dá àdápa irọ́. Dájúdájú àwọn tí ẹ̀ ń jọ́sìn fún lẹ́yìn Allāhu, wọn kò ní ìkápá arísìkí kan fún yín. Ẹ wá arísìkí sí ọ̀dọ̀ Allāhu. Kí ẹ jọ́sìn fún Un. Kí ẹ sì dúpẹ́ fún Un. Ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò da yín padà sí.
Saba 34:40وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا ثُمَّ يَقُولُ لِلۡمَلَـٰٓئِكَةِ أَهَـٰٓؤُلَآءِ إِيَّاكُمۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ ﴿٤٠﴾
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, lẹ́yìn náà Ó máa sọ fún àwọn mọlāika pé: “Ṣé ẹ̀yin ni wọ́n ń jọ́sìn fún?”
Saba 34:41قَالُواْ سُبۡحَٰنَكَ أَنتَ وَلِيُّنَا مِن دُونِهِمۖ بَلۡ كَانُواْ يَعۡبُدُونَ ٱلۡجِنَّۖ أَكۡثَرُهُم بِهِم مُّؤۡمِنُونَ ﴿٤١﴾
Wọ́n á sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ! Ìwọ ni Aláàbò wa, kì í ṣe àwọn. Rárá (wọn kò jọ́sìn fún wa). Àwọn àlùjànnú ni wọ́n ń jọ́sìn fún; ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn ni wọ́n gbàgbọ́ nínú àwọn àlùjànnú.
Az-Zumar 39:3أَلَا لِلَّهِ ٱلدِّينُ ٱلۡخَالِصُۚ وَٱلَّذِينَ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَ مَا نَعۡبُدُهُمۡ إِلَّا لِيُقَرِّبُونَآ إِلَى ٱللَّهِ زُلۡفَىٰٓ إِنَّ ٱللَّهَ يَحۡكُمُ بَيۡنَهُمۡ فِي مَا هُمۡ فِيهِ يَخۡتَلِفُونَۗ إِنَّ ٱللَّهَ لَا يَهۡدِي مَنۡ هُوَ كَٰذِبٞ كَفَّارٞ ﴿٣﴾
Gbọ́! Ti Allāhu ni ẹ̀sìn mímọ́.Àwọn tí wọ́n sì mú àwọn aláfẹ̀yìntì kan yàtọ̀ sí Allāhu, (wọ́n wí pé): “A kò jọ́sìn fún wọn bí kò ṣe pé, nítorí kí wọ́n lè mú wa súnmọ́ Allāhu pẹ́kípẹ́kí ni.” Dájúdájú Allāhu l’Ó máa dájọ́ láààrin wọn nípa ohun tí wọ́n ń yapa-ẹnu nípa rẹ̀ (ìyẹn, ẹ̀sìn ’Islām). Dájúdájú Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ẹni tí ó jẹ́ òpùrọ́, aláìgbàgbọ́.
An-Naml 27:80إِنَّكَ لَا تُسۡمِعُ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَلَا تُسۡمِعُ ٱلصُّمَّ ٱلدُّعَآءَ إِذَا وَلَّوۡاْ مُدۡبِرِينَ ﴿٨٠﴾
Dájúdájú ìwọ kọ́ l’o máa mú àwọn òkú gbọ́rọ̀. O ò sì níí mú àwọn adití gbọ́ ìpè nígbà tí wọ́n bá kẹ̀yìn sí ọ, tí wọ́n ń lọ.
Ash-Shuraa 42:9أَمِ ٱتَّخَذُواْ مِن دُونِهِۦٓ أَوۡلِيَآءَۖ فَٱللَّهُ هُوَ ٱلۡوَلِيُّ وَهُوَ يُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿٩﴾
Ṣé wọ́n mú àwọn aláàbò kan lẹ́yìn Rẹ̀ ni? Allāhu, Òun sì ni Aláàbò. Òun l’Ó ń sọ àwọn òkú di alààyè. Òun sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.
Al-Mursalat 77:25أَلَمۡ نَجۡعَلِ ٱلۡأَرۡضَ كِفَاتًا ﴿٢٥﴾
Ǹjẹ́ Àwa kò ṣe ilẹ̀ ní ohun tó ń kó ẹ̀dá jọ mọ́ra wọn;
Al-Mursalat 77:26أَحۡيَآءٗ وَأَمۡوَٰتٗا ﴿٢٦﴾
(ìyẹn) àwọn alààyè àti àwọn òkú?
Al-Baqarah 2:259أَوۡ كَٱلَّذِي مَرَّ عَلَىٰ قَرۡيَةٖ وَهِيَ خَاوِيَةٌ عَلَىٰ عُرُوشِهَا قَالَ أَنَّىٰ يُحۡيِۦ هَٰذِهِ ٱللَّهُ بَعۡدَ مَوۡتِهَاۖ فَأَمَاتَهُ ٱللَّهُ مِاْئَةَ عَامٖ ثُمَّ بَعَثَهُۥۖ قَالَ كَمۡ لَبِثۡتَۖ قَالَ لَبِثۡتُ يَوۡمًا أَوۡ بَعۡضَ يَوۡمٖۖ قَالَ بَل لَّبِثۡتَ مِاْئَةَ عَامٖ فَٱنظُرۡ إِلَىٰ طَعَامِكَ وَشَرَابِكَ لَمۡ يَتَسَنَّهۡۖ وَٱنظُرۡ إِلَىٰ حِمَارِكَ وَلِنَجۡعَلَكَ ءَايَةٗ لِّلنَّاسِۖ وَٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡعِظَامِ كَيۡفَ نُنشِزُهَا ثُمَّ نَكۡسُوهَا لَحۡمٗاۚ فَلَمَّا تَبَيَّنَ لَهُۥ قَالَ أَعۡلَمُ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٞ ﴿٢٥٩﴾
Tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kọjá nínú ìlú kan nígbà tí (àwọn ilé ibẹ̀) ti dàwó lulẹ̀ tòrùlé-tòrùlé wọn. Ó sọ pé: “Báwo ni Allāhu yó ṣe sọ èyí di alààyè lẹ́yìn ikú rẹ̀!” Allāhu sì sọ ọ́ di òkú fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Lẹ́yìn náà, Ó gbé e dìde. Ó sọ pé: “Ìgbà wo ni o ti wà níbí?” Ó sọ pé: “Mo wà níbí fún ọjọ́ kan tàbí ìlàjì ọjọ́.” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, o ti wà níbí fún ọgọ́rùn-ún ọdún. Wo oúnjẹ rẹ àti omi rẹ, kò yí padà. Tún wo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ, kí Á lè fi ọ́ ṣe àmì kan fún àwọn ènìyàn (ni ìwọ̀nyí jẹ́). Wo eegun (ràkúnmí náà), wo bí A ó ṣe tò wọ́n papọ̀ mọ́ra wọn. Lẹ́yìn náà, (wo) bí A ó ṣe da ẹran bò ó lára. Nígbà tí ó fojú hàn sí i kedere (bẹ́ẹ̀), ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan.”1
Al-Baqarah 2:260وَإِذۡ قَالَ إِبۡرَٰهِـۧمُ رَبِّ أَرِنِي كَيۡفَ تُحۡيِ ٱلۡمَوۡتَىٰۖ قَالَ أَوَلَمۡ تُؤۡمِنۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِن لِّيَطۡمَئِنَّ قَلۡبِيۖ قَالَ فَخُذۡ أَرۡبَعَةٗ مِّنَ ٱلطَّيۡرِ فَصُرۡهُنَّ إِلَيۡكَ ثُمَّ ٱجۡعَلۡ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٖ مِّنۡهُنَّ جُزۡءٗا ثُمَّ ٱدۡعُهُنَّ يَأۡتِينَكَ سَعۡيٗاۚ وَٱعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٞ ﴿٢٦٠﴾
Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè.” (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (mo gbàgbọ́), ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: “Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”
Al-An'am 6:36۞إِنَّمَا يَسۡتَجِيبُ ٱلَّذِينَ يَسۡمَعُونَۘ وَٱلۡمَوۡتَىٰ يَبۡعَثُهُمُ ٱللَّهُ ثُمَّ إِلَيۡهِ يُرۡجَعُونَ ﴿٣٦﴾
Ọ̀wọ́ ẹni tó ń jẹ́pè ni àwọn tó ń gbọ́rọ̀. (Ní ti) àwọn òkú, Allāhu yó gbé wọn dìde. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni wọn yóò dá wọn padà sí.
An-Nahl 16:20وَٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ مِن دُونِ ٱللَّهِ لَا يَخۡلُقُونَ شَيۡـٔٗا وَهُمۡ يُخۡلَقُونَ ﴿٢٠﴾
Àwọn (òrìṣà) tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu; wọn kò lè dá kiní kan. Allāhu l’Ó sì ṣẹ̀dá wọn.
Al-Baqarah 2:257ٱللَّهُ وَلِيُّ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يُخۡرِجُهُم مِّنَ ٱلظُّلُمَٰتِ إِلَى ٱلنُّورِۖ وَٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ أَوۡلِيَآؤُهُمُ ٱلطَّـٰغُوتُ يُخۡرِجُونَهُم مِّنَ ٱلنُّورِ إِلَى ٱلظُّلُمَٰتِۗ أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلنَّارِۖ هُمۡ فِيهَا خَٰلِدُونَ ﴿٢٥٧﴾
Allāhu ni Alárànṣe àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo. Ó ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀. Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́, àwọn òrìṣà ni aláfẹ̀yìntì wọn. Àwọn òrìṣà ń mú wọn jáde kúrò nínú ìmọ́lẹ̀ wá sínú àwọn òkùnkùn. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Al-An'am 6:121وَلَا تَأۡكُلُواْ مِمَّا لَمۡ يُذۡكَرِ ٱسۡمُ ٱللَّهِ عَلَيۡهِ وَإِنَّهُۥ لَفِسۡقٞۗ وَإِنَّ ٱلشَّيَٰطِينَ لَيُوحُونَ إِلَىٰٓ أَوۡلِيَآئِهِمۡ لِيُجَٰدِلُوكُمۡۖ وَإِنۡ أَطَعۡتُمُوهُمۡ إِنَّكُمۡ لَمُشۡرِكُونَ ﴿١٢١﴾
Ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ jẹ nínú ohun tí wọn kò fi orúkọ Allāhu pa.Dájúdájú ìbàjẹ́ ni. Àti pé dájúdájú àwọn èṣù, wọn yóò máa fi ọ̀rọ̀ irọ́ ránṣẹ́ sí àwọn ẹni wọn, nítorí kí wọ́n lè takò yín. Tí ẹ bá fi lè tẹ̀lé wọn, dájúdájú ẹ ti di ọ̀ṣẹbọ.