Al-An'am 6:97وَهُوَ ٱلَّذِي جَعَلَ لَكُمُ ٱلنُّجُومَ لِتَهۡتَدُواْ بِهَا فِي ظُلُمَٰتِ ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۗ قَدۡ فَصَّلۡنَا ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡلَمُونَ ﴿٩٧﴾
Òun ni Ẹni tí Ó fi àwọn ìràwọ̀ ṣe (ìmọ́lẹ̀) fún yín kí ẹ lè fi ríran nínú òkùnkùn ilẹ̀ àti ibúdò. A kúkú ti ṣàlàyé àwọn āyah fún àwọn ènìyàn tó nímọ̀.
Al-A'raf 7:54إِنَّ رَبَّكُمُ ٱللَّهُ ٱلَّذِي خَلَقَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ فِي سِتَّةِ أَيَّامٖ ثُمَّ ٱسۡتَوَىٰ عَلَى ٱلۡعَرۡشِۖ يُغۡشِي ٱلَّيۡلَ ٱلنَّهَارَ يَطۡلُبُهُۥ حَثِيثٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ وَٱلنُّجُومَ مُسَخَّرَٰتِۭ بِأَمۡرِهِۦٓۗ أَلَا لَهُ ٱلۡخَلۡقُ وَٱلۡأَمۡرُۗ تَبَارَكَ ٱللَّهُ رَبُّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿٥٤﴾
Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá.Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
An-Nahl 16:12وَسَخَّرَ لَكُمُ ٱلَّيۡلَ وَٱلنَّهَارَ وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَۖ وَٱلنُّجُومُ مُسَخَّرَٰتُۢ بِأَمۡرِهِۦٓۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ﴿١٢﴾
Ó rọ òru, ọ̀sán, òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún yín pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Dájúdájú àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.
Al-Hajj 22:18أَلَمۡ تَرَ أَنَّ ٱللَّهَ يَسۡجُدُۤ لَهُۥۤ مَن فِي ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ وَٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ وَٱلنُّجُومُ وَٱلۡجِبَالُ وَٱلشَّجَرُ وَٱلدَّوَآبُّ وَكَثِيرٞ مِّنَ ٱلنَّاسِۖ وَكَثِيرٌ حَقَّ عَلَيۡهِ ٱلۡعَذَابُۗ وَمَن يُهِنِ ٱللَّهُ فَمَا لَهُۥ مِن مُّكۡرِمٍۚ إِنَّ ٱللَّهَ يَفۡعَلُ مَا يَشَآءُ۩ ﴿١٨﴾
Ṣé o ò wòye pé dájúdájú Allāhu ni àwọn tó ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti àwọn tó ń bẹ lórí ilẹ̀, àti òòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, àwọn àpáta, àwọn igi, àwọn n̄ǹkan ẹlẹ́mìí àti ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn ènìyàn ń forí kanlẹ̀ fún? Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sì ni ìyà ti kò lé lórí. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fi àbùkù kàn, kò sí ẹnì kan tí ó máa ṣe àpọ́nlé rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́.1
As-Saffat 37:88فَنَظَرَ نَظۡرَةٗ فِي ٱلنُّجُومِ ﴿٨٨﴾
Ó ṣíjú wo àwọn ìràwọ̀ ní wíwò kan.
As-Saffat 37:89فَقَالَ إِنِّي سَقِيمٞ ﴿٨٩﴾
Ó sì sọ pé: “Dájúdájú ó rẹ̀ mí.”
At-Tur 52:48وَٱصۡبِرۡ لِحُكۡمِ رَبِّكَ فَإِنَّكَ بِأَعۡيُنِنَاۖ وَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ حِينَ تَقُومُ ﴿٤٨﴾
Ṣe sùúrù fún ìdájọ́ Olúwa Rẹ, dájúdájú ìwọ wà ní ojútó Wa. Kí ó sì ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ẹyìn fún Olúwa rẹ nígbà tí o bá fẹ́ dìde.1
At-Tur 52:49وَمِنَ ٱلَّيۡلِ فَسَبِّحۡهُ وَإِدۡبَٰرَ ٱلنُّجُومِ ﴿٤٩﴾
Àti pé ní alẹ́ àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá kúrò níta tán ṣàfọ̀mọ́ fún Un.
An-Najm 53:1وَٱلنَّجۡمِ إِذَا هَوَىٰ ﴿١﴾
Allāhu fi gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nínú al-Ƙur’ān alápọ̀n-ọ́nlé nígbà tí ó bá sọ̀kalẹ̀ láti ojú sánmọ̀ búra.1
Ar-Rahman 55:1ٱلرَّحۡمَٰنُ ﴿١﴾
Àjọkẹ́-ayé,
Ar-Rahman 55:2عَلَّمَ ٱلۡقُرۡءَانَ ﴿٢﴾
Ó fi ìmọ̀ al-Ƙur’ān mọ (ẹni tí Ó fẹ́).
Ar-Rahman 55:3خَلَقَ ٱلۡإِنسَٰنَ ﴿٣﴾
Ó ṣẹ̀dá ènìyàn.
Ar-Rahman 55:4عَلَّمَهُ ٱلۡبَيَانَ ﴿٤﴾
Ó sì fi àlàyé (ọ̀rọ̀ sísọ) mọ̀ ọ́n.
Ar-Rahman 55:5ٱلشَّمۡسُ وَٱلۡقَمَرُ بِحُسۡبَانٖ ﴿٥﴾
Òòrùn àti òṣùpá (ń rìn) fún ìṣírò (ọjọ́ ayé).
Ar-Rahman 55:6وَٱلنَّجۡمُ وَٱلشَّجَرُ يَسۡجُدَانِ ﴿٦﴾
Àwọn ìtàkùn ilẹ̀ àti igi ń forí kanlẹ̀ (fún Allāhu).
Al-Waqi'ah 56:75۞فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَوَٰقِعِ ٱلنُّجُومِ ﴿٧٥﴾
Nítorí náà, Mò ń fi àwọn àyè tí ìkọ̀ọ̀kan gbólóhùn al-Ƙur’ān wà nínú sánmọ̀ búra.1
Al-Waqi'ah 56:76وَإِنَّهُۥ لَقَسَمٞ لَّوۡ تَعۡلَمُونَ عَظِيمٌ ﴿٧٦﴾
Dájúdájú ìbúra ńlá ni, tí ẹ bá mọ̀.
Al-Mursalat 77:7إِنَّمَا تُوعَدُونَ لَوَٰقِعٞ ﴿٧﴾
Dájúdájú ohun tí A ṣe ní àdéhùn fún yín kúkú máa ṣẹlẹ̀.
Al-Mursalat 77:8فَإِذَا ٱلنُّجُومُ طُمِسَتۡ ﴿٨﴾
Nítorí náà, nígbà tí wọ́n bá pa (ìmọ́lẹ̀) ìràwọ̀ rẹ́,
Al-Mursalat 77:9وَإِذَا ٱلسَّمَآءُ فُرِجَتۡ ﴿٩﴾
àti nígbà tí wọ́n bá ṣí sánmọ̀ sílẹ̀ gbagada,
Al-Mursalat 77:10وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ نُسِفَتۡ ﴿١٠﴾
àti nígbà tí wọ́n bá ku àwọn àpáta dànù,
At-Takwir 81:1إِذَا ٱلشَّمۡسُ كُوِّرَتۡ ﴿١﴾
Nígbà tí wọ́n bá ká òòrùn kóróbójó dànù,
At-Takwir 81:2وَإِذَا ٱلنُّجُومُ ٱنكَدَرَتۡ ﴿٢﴾
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
At-Takwir 81:3وَإِذَا ٱلۡجِبَالُ سُيِّرَتۡ ﴿٣﴾
àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn àpáta rìn (kúrò ní àyè wọn, tí wọ́n kù wọ́n dànù),
At-Takwir 81:4وَإِذَا ٱلۡعِشَارُ عُطِّلَتۡ ﴿٤﴾
àti nígbà tí wọ́n bá pa àwọn ràkúnmí aboyún tì,
At-Takwir 81:5وَإِذَا ٱلۡوُحُوشُ حُشِرَتۡ ﴿٥﴾
àti nígbà tí wọ́n bá ko àwọn ẹranko jọ,
At-Takwir 81:6وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ سُجِّرَتۡ ﴿٦﴾
àti nígbà tí wọ́n bá mú àwọn agbami odò gbiná,
At-Takwir 81:7وَإِذَا ٱلنُّفُوسُ زُوِّجَتۡ ﴿٧﴾
àti nígbà tí wọ́n bá so àwọn ẹ̀mí pọ̀ mọ́ra wọn, (ẹni rere pẹ̀lú ẹni rere, ẹni ibi pẹ̀lú ẹni ibi)
At-Tariq 86:1وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ ﴿١﴾
(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
At-Tariq 86:2وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ ﴿٢﴾
Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
At-Tariq 86:3ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ ﴿٣﴾
Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
At-Tariq 86:4إِن كُلُّ نَفۡسٖ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظٞ ﴿٤﴾
Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
An-Nur 24:35۞ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشۡكَوٰةٖ فِيهَا مِصۡبَاحٌۖ ٱلۡمِصۡبَاحُ فِي زُجَاجَةٍۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوۡكَبٞ دُرِّيّٞ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٖ مُّبَٰرَكَةٖ زَيۡتُونَةٖ لَّا شَرۡقِيَّةٖ وَلَا غَرۡبِيَّةٖ يَكَادُ زَيۡتُهَا يُضِيٓءُ وَلَوۡ لَمۡ تَمۡسَسۡهُ نَارٞۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٖۚ يَهۡدِي ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَ لِلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ﴿٣٥﴾
Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan tó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn, tí kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn (nìkan mọ).Epo rẹ̀ fẹ́rẹ̀ tànmọ́lẹ̀, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni.2 Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
As-Saffat 37:6إِنَّا زَيَّنَّا ٱلسَّمَآءَ ٱلدُّنۡيَا بِزِينَةٍ ٱلۡكَوَاكِبِ ﴿٦﴾
Dájúdájú Àwa fi àwọn ìràwọ̀ ṣe sánmọ̀ ilé ayé ní ọ̀ṣọ́
Al-An'am 6:75وَكَذَٰلِكَ نُرِيٓ إِبۡرَٰهِيمَ مَلَكُوتَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَلِيَكُونَ مِنَ ٱلۡمُوقِنِينَ ﴿٧٥﴾
Báyẹn ni wọ́n ṣe fi (àwọn àmì) ìjọba Allahu tí ń bẹ nínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ han (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm nítorí kí ó lè wà nínú àwọn alámọ̀dájú.
Al-An'am 6:76فَلَمَّا جَنَّ عَلَيۡهِ ٱلَّيۡلُ رَءَا كَوۡكَبٗاۖ قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَآ أُحِبُّ ٱلۡأٓفِلِينَ ﴿٧٦﴾
Nígbà tí òkùnkùn alẹ́ bò ó mọ́lẹ̀, ó rí ìràwọ̀ kan, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Èmi kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn (olúwa) tó ń wọ̀ọ̀kùn.”
Al-An'am 6:77فَلَمَّا رَءَا ٱلۡقَمَرَ بَازِغٗا قَالَ هَٰذَا رَبِّيۖ فَلَمَّآ أَفَلَ قَالَ لَئِن لَّمۡ يَهۡدِنِي رَبِّي لَأَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡقَوۡمِ ٱلضَّآلِّينَ ﴿٧٧﴾
Nígbà tí ó rí òṣùpá tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi.” Nígbà tí ó wọ̀, ó sọ pé: “Dájúdájú tí Olúwa mi kò bá tọ́ mi sọ́nà, dájúdájú mo máa wà nínú àwọn olùṣìnà ènìyàn.”
Al-An'am 6:78فَلَمَّا رَءَا ٱلشَّمۡسَ بَازِغَةٗ قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَآ أَكۡبَرُۖ فَلَمَّآ أَفَلَتۡ قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ ﴿٧٨﴾
Nígbà tí ó rí òòrùn tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà tó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).1
Al-An'am 6:79إِنِّي وَجَّهۡتُ وَجۡهِيَ لِلَّذِي فَطَرَ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضَ حَنِيفٗاۖ وَمَآ أَنَا۠ مِنَ ٱلۡمُشۡرِكِينَ ﴿٧٩﴾
Dájúdájú èmi dojú mi kọ Ẹni tí Ó pilẹ̀ ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, (mo) dúró déédé (sínú ’Islām fún Un). Èmi kò sì sí nínú àwọn ọ̀ṣẹbọ.”
Al-An'am 6:80وَحَآجَّهُۥ قَوۡمُهُۥۚ قَالَ أَتُحَـٰٓجُّوٓنِّي فِي ٱللَّهِ وَقَدۡ هَدَىٰنِۚ وَلَآ أَخَافُ مَا تُشۡرِكُونَ بِهِۦٓ إِلَّآ أَن يَشَآءَ رَبِّي شَيۡـٔٗاۚ وَسِعَ رَبِّي كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمًاۚ أَفَلَا تَتَذَكَّرُونَ ﴿٨٠﴾
Àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jà á níyàn. Ó sọ pé: "Ṣé ẹ̀yin yóò jà mí níyàn nípa Allāhu, Ó sì ti fi ọ̀nà mọ̀ mí? Èmi kò sì páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Un, àfi bí Allāhu bá fẹ́ kiní kan (pé kó ṣẹlẹ̀). Olúwa mi fi ìmọ̀ gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan. Nítorí náà, ṣé ẹ ò níí lo ìrántí ni?
Al-An'am 6:81وَكَيۡفَ أَخَافُ مَآ أَشۡرَكۡتُمۡ وَلَا تَخَافُونَ أَنَّكُمۡ أَشۡرَكۡتُم بِٱللَّهِ مَا لَمۡ يُنَزِّلۡ بِهِۦ عَلَيۡكُمۡ سُلۡطَٰنٗاۚ فَأَيُّ ٱلۡفَرِيقَيۡنِ أَحَقُّ بِٱلۡأَمۡنِۖ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿٨١﴾
Báwo ni èmi yóò ṣe páyà (àwọn òrìṣà) tí ẹ sọ di akẹgbẹ́ fún Allāhu, tí ẹ̀yin kò sì páyà pé ẹ̀ ń bá Allāhu wá akẹgbẹ́ pẹ̀lú ohun tí kò sọ ẹ̀rí kan kalẹ̀ fún yín lórí rẹ̀? Èwo nínú ikọ̀ méjèèjì l’ó lẹ́tọ̀ọ́ jùlọ sí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ẹ bá nímọ̀?
Yusuf 12:4إِذۡ قَالَ يُوسُفُ لِأَبِيهِ يَـٰٓأَبَتِ إِنِّي رَأَيۡتُ أَحَدَ عَشَرَ كَوۡكَبٗا وَٱلشَّمۡسَ وَٱلۡقَمَرَ رَأَيۡتُهُمۡ لِي سَٰجِدِينَ ﴿٤﴾
(Rántí) nígbà tí (Ànábì) Yūsuf sọ fún bàbá rẹ̀ pé: “Bàbá mi, dájúdájú èmi (lálàá) rí àwọn ìràwọ̀ mọ́kànlá, òòrùn àti òṣùpá. Mo rí wọn tí wọ́n forí kanlẹ̀ fún mi.”
Yusuf 12:5قَالَ يَٰبُنَيَّ لَا تَقۡصُصۡ رُءۡيَاكَ عَلَىٰٓ إِخۡوَتِكَ فَيَكِيدُواْ لَكَ كَيۡدًاۖ إِنَّ ٱلشَّيۡطَٰنَ لِلۡإِنسَٰنِ عَدُوّٞ مُّبِينٞ ﴿٥﴾
Ó sọ pé: “Ọmọ mi, má ṣe rọ́ àlá rẹ fún àwọn ọbàkan rẹ kí wọ́n má baà déte sí ọ. Dájúdájú Èṣù ni ọ̀tá pọ́nńbélé fún ènìyàn.
Al-Infitar 82:1إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ﴿١﴾
Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1
Al-Infitar 82:2وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ ﴿٢﴾
àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
Al-Infitar 82:3وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ ﴿٣﴾
àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
Al-Infitar 82:4وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ ﴿٤﴾
àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
Al-Infitar 82:5عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ ﴿٥﴾
(nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
An-Nisa 4:78أَيۡنَمَا تَكُونُواْ يُدۡرِككُّمُ ٱلۡمَوۡتُ وَلَوۡ كُنتُمۡ فِي بُرُوجٖ مُّشَيَّدَةٖۗ وَإِن تُصِبۡهُمۡ حَسَنَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ وَإِن تُصِبۡهُمۡ سَيِّئَةٞ يَقُولُواْ هَٰذِهِۦ مِنۡ عِندِكَۚ قُلۡ كُلّٞ مِّنۡ عِندِ ٱللَّهِۖ فَمَالِ هَـٰٓؤُلَآءِ ٱلۡقَوۡمِ لَا يَكَادُونَ يَفۡقَهُونَ حَدِيثٗا ﴿٧٨﴾
Ibikíbi tí ẹ bá wà, ikú yóò pàdé yín, ẹ̀yin ìbáà wà nínú odi ilé orí òkè ilé gíga fíofío. Tí oore (ìkógun) kan bá tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Tí aburú (ìfọ́gun) kan bá sì ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n á wí pé: “Èyí wá láti ọ̀dọ̀ rẹ.” Sọ pé: “Gbogbo rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Allāhu.” Kí ló ń ṣe àwọn ènìyàn wọ̀nyí ná, tí wọn kò fẹ́ẹ̀ gbọ́ àgbọ́yé ọ̀rọ̀ kan.
Al-Hijr 15:16وَلَقَدۡ جَعَلۡنَا فِي ٱلسَّمَآءِ بُرُوجٗا وَزَيَّنَّـٰهَا لِلنَّـٰظِرِينَ ﴿١٦﴾
A kúkú fi àwọn ibùsọ̀ ìràwọ̀ sínú sánmọ̀ (ayé). A ṣe é ní ọ̀ṣọ́ fún àwọn olùwòran.