quranm◉

Àwọn kókó · yo

72 Àyá · Àwọn kókó · yo

Al-Ma'idah 5:52

فَتَرَى ٱلَّذِينَ فِي قُلُوبِهِم مَّرَضٞ يُسَٰرِعُونَ فِيهِمۡ يَقُولُونَ نَخۡشَىٰٓ أَن تُصِيبَنَا دَآئِرَةٞۚ فَعَسَى ٱللَّهُ أَن يَأۡتِيَ بِٱلۡفَتۡحِ أَوۡ أَمۡرٖ مِّنۡ عِندِهِۦ فَيُصۡبِحُواْ عَلَىٰ مَآ أَسَرُّواْ فِيٓ أَنفُسِهِمۡ نَٰدِمِينَ ﴿٥٢﴾

Nítorí náà, o máa rí àwọn tí àárẹ̀ wà nínú ọkàn wọn, tí wọn yóò máa yára lọ sáààrin wọn. Wọn yóò máa wí pé: “À ń bẹ̀rù pé kí àpadàsí ìgbà má baà kàn wá ni.” Ó súnmọ́ kí Allāhu mú ìṣẹ́gun tàbí àṣẹ kan wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Wọn yó sì di alábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n fi pamọ́ sínú ọkàn wọn.

Al-A'raf 7:89

قَدِ ٱفۡتَرَيۡنَا عَلَى ٱللَّهِ كَذِبًا إِنۡ عُدۡنَا فِي مِلَّتِكُم بَعۡدَ إِذۡ نَجَّىٰنَا ٱللَّهُ مِنۡهَاۚ وَمَا يَكُونُ لَنَآ أَن نَّعُودَ فِيهَآ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُ رَبُّنَاۚ وَسِعَ رَبُّنَا كُلَّ شَيۡءٍ عِلۡمًاۚ عَلَى ٱللَّهِ تَوَكَّلۡنَاۚ رَبَّنَا ٱفۡتَحۡ بَيۡنَنَا وَبَيۡنَ قَوۡمِنَا بِٱلۡحَقِّ وَأَنتَ خَيۡرُ ٱلۡفَٰتِحِينَ ﴿٨٩﴾

Dájúdájú a ti dá àdápa irọ́ mọ́ Allāhu tí a bá fi lè padà sínú ẹ̀sìn yín lẹ́yìn ìgbà tí Allāhu ti yọ wá kúrò nínú rẹ̀. Àti pé kò lẹ́tọ̀ọ́ fún wa láti padà sínú rẹ̀ àfi tí Allāhu Olúwa wa bá fẹ́. Olúwa wa gbòòrò tayọ gbogbo n̄ǹkan pẹ̀lú ìmọ̀. Allāhu l’a gbáralé. Olúwa wa, ṣe ìdájọ́ láààrin àwa àti ìjọ wa pẹ̀lú òdodo, Ìwọ sì lóore jùlọ nínú àwọn olùdájọ́.”

Al-Anfal 8:19

إِن تَسۡتَفۡتِحُواْ فَقَدۡ جَآءَكُمُ ٱلۡفَتۡحُۖ وَإِن تَنتَهُواْ فَهُوَ خَيۡرٞ لَّكُمۡۖ وَإِن تَعُودُواْ نَعُدۡ وَلَن تُغۡنِيَ عَنكُمۡ فِئَتُكُمۡ شَيۡـٔٗا وَلَوۡ كَثُرَتۡ وَأَنَّ ٱللَّهَ مَعَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿١٩﴾

Tí ẹ̀yin (aláìgbàgbọ́) bá ń wá ìdájọ́, dájúdájú ìdájọ́ ti kò le yín lórí. Tí ẹ bá jáwọ́ (níbi ogun), ó sì dára jùlọ fún yín. Tí ẹ bá tún padà (síbi ogun), A máa padà (ran àwọn onígbàgbọ́ òdodo lọ́wọ́); àkójọ yín kò sì níí rọ̀ yín lọ́rọ̀ kan kan, ìbáà pọ̀. Dájúdájú Allāhu ń bẹ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.

Ash-Shu'ara 26:116

قَالُواْ لَئِن لَّمۡ تَنتَهِ يَٰنُوحُ لَتَكُونَنَّ مِنَ ٱلۡمَرۡجُومِينَ ﴿١١٦﴾

Wọ́n wí pé: “Dájúdájú tí ìwọ Nūh kò bá jáwọ́ (nibí ìpèpè rẹ) dájúdájú o máa wà nínú àwọn tí a máa jù lókò.”

Ash-Shu'ara 26:117

قَالَ رَبِّ إِنَّ قَوۡمِي كَذَّبُونِ ﴿١١٧﴾

Ó sọ pé: “Olúwa mi, dájúdájú àwọn ènìyàn mi ti pè mí ní òpùrọ́.

Ash-Shu'ara 26:118

فَٱفۡتَحۡ بَيۡنِي وَبَيۡنَهُمۡ فَتۡحٗا وَنَجِّنِي وَمَن مَّعِيَ مِنَ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿١١٨﴾

Nítorí náà, ṣèdájọ́ tààrà láààrin èmi àti àwọn. Kí o sì la èmi àti àwọn tó wà pẹ̀lú mi nínú àwọn onígbàgbọ́ òdodo.”

As-Sajdah 32:28

وَيَقُولُونَ مَتَىٰ هَٰذَا ٱلۡفَتۡحُ إِن كُنتُمۡ صَٰدِقِينَ ﴿٢٨﴾

Wọ́n sì ń wí pé: “Ìgbà wo ni Ìdájọ́ yìí máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ bá jẹ́ olódodo?”

As-Sajdah 32:29

قُلۡ يَوۡمَ ٱلۡفَتۡحِ لَا يَنفَعُ ٱلَّذِينَ كَفَرُوٓاْ إِيمَٰنُهُمۡ وَلَا هُمۡ يُنظَرُونَ ﴿٢٩﴾

Sọ pé: “Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, ìgbàgbọ́ tí àwọn ọ̀ṣẹbọ máa fẹ́ ní nígbà tí wọ́n bá fojú rí ìyà Iná kò níí ṣe wọ́n ní àǹfààní. A kò sì níí fún wọn ní ìsinmi (nínú Iná).”1

Saba 34:26

قُلۡ يَجۡمَعُ بَيۡنَنَا رَبُّنَا ثُمَّ يَفۡتَحُ بَيۡنَنَا بِٱلۡحَقِّ وَهُوَ ٱلۡفَتَّاحُ ٱلۡعَلِيمُ ﴿٢٦﴾

Sọ pé: “Olúwa wa yóò kó wa jọ papọ̀. Lẹ́yìn náà, Ó máa fi òdodo ṣèdájọ́ láààrin wa. Òun sì ni Onídàájọ́, Onímọ̀.”

Fatir 35:2

مَّا يَفۡتَحِ ٱللَّهُ لِلنَّاسِ مِن رَّحۡمَةٖ فَلَا مُمۡسِكَ لَهَاۖ وَمَا يُمۡسِكۡ فَلَا مُرۡسِلَ لَهُۥ مِنۢ بَعۡدِهِۦۚ وَهُوَ ٱلۡعَزِيزُ ٱلۡحَكِيمُ ﴿٢﴾

Ohunkóhun tí Allāhu bá ṣí ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìkẹ́ fún àwọn ènìyàn, kò sí ẹni tí ó lè dì í mọ́wọ́ (láti dá a dúró). Ohunkóhun tí Ó bá sì mú dání, kò sí ẹni tí ó lè mú un wá lẹ́yìn Rẹ̀. Òun sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Al-Fath 48:1

إِنَّا فَتَحۡنَا لَكَ فَتۡحٗا مُّبِينٗا ﴿١﴾

Dájúdájú Àwa ṣẹ́gun fún ọ ní ìṣẹ́gun tó fojú hàn

Al-Fath 48:2

لِّيَغۡفِرَ لَكَ ٱللَّهُ مَا تَقَدَّمَ مِن ذَنۢبِكَ وَمَا تَأَخَّرَ وَيُتِمَّ نِعۡمَتَهُۥ عَلَيۡكَ وَيَهۡدِيَكَ صِرَٰطٗا مُّسۡتَقِيمٗا ﴿٢﴾

nítorí kí Allāhu lè ṣàforíjìn ohun tí ó ṣíwájú nínú àṣìṣe rẹ àti ohun tí ó kẹ́yìn (nínú rẹ̀),àti nítorí kí Ó lè ṣàṣepé ìdẹ̀ra Rẹ̀ lé ọ lórí àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ rẹ rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām),

Al-Fath 48:3

وَيَنصُرَكَ ٱللَّهُ نَصۡرًا عَزِيزًا ﴿٣﴾

àti nítorí kí Allāhu lè ṣàrànṣe fún ọ ní àrànṣe tó lágbára.

Al-Fath 48:4

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ فِي قُلُوبِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ لِيَزۡدَادُوٓاْ إِيمَٰنٗا مَّعَ إِيمَٰنِهِمۡۗ وَلِلَّهِ جُنُودُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ وَكَانَ ٱللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمٗا ﴿٤﴾

Òun ni Ẹni tí Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ sínú ọkàn àwọn onígbàgbọ́ òdodo nítorí kí wọ́n lè lékún ní ìgbàgbọ́ sí ìgbàgbọ́ wọn. Ti Allāhu sì ni àwọn ọmọ ogun sánmọ̀ àti ilẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Onímọ̀, Ọlọ́gbọ́n.

Al-Fath 48:18

۞لَّقَدۡ رَضِيَ ٱللَّهُ عَنِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ إِذۡ يُبَايِعُونَكَ تَحۡتَ ٱلشَّجَرَةِ فَعَلِمَ مَا فِي قُلُوبِهِمۡ فَأَنزَلَ ٱلسَّكِينَةَ عَلَيۡهِمۡ وَأَثَٰبَهُمۡ فَتۡحٗا قَرِيبٗا ﴿١٨﴾

Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun Hudaebiyyah). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (ìyẹn ogun Hudaebiyyah)

Al-Fath 48:27

لَّقَدۡ صَدَقَ ٱللَّهُ رَسُولَهُ ٱلرُّءۡيَا بِٱلۡحَقِّۖ لَتَدۡخُلُنَّ ٱلۡمَسۡجِدَ ٱلۡحَرَامَ إِن شَآءَ ٱللَّهُ ءَامِنِينَ مُحَلِّقِينَ رُءُوسَكُمۡ وَمُقَصِّرِينَ لَا تَخَافُونَۖ فَعَلِمَ مَا لَمۡ تَعۡلَمُواْ فَجَعَلَ مِن دُونِ ذَٰلِكَ فَتۡحٗا قَرِيبًا ﴿٢٧﴾

Dájúdájú Allāhu ti sọ àlá Òjíṣẹ́ Rẹ̀ di òdodo pé - tí Allāhu bá fẹ́ - dájúdájú ẹ̀yin yóò wọ inú Mọ́sálásí Haram ní ẹni ìfàyàbalẹ̀, ní ẹni tí ó máa fá irun orí yín, tí ẹ sì máa gé irun (orí yín mọ́lẹ̀), tí kò níí sí ìpáyà fún yín. Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, Ó tún ṣe ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (fún yín).

Al-Qamar 54:9

۞كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ فَكَذَّبُواْ عَبۡدَنَا وَقَالُواْ مَجۡنُونٞ وَٱزۡدُجِرَ ﴿٩﴾

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.1

Al-Qamar 54:10

فَدَعَا رَبَّهُۥٓ أَنِّي مَغۡلُوبٞ فَٱنتَصِرۡ ﴿١٠﴾

Nítorí náà, ó pe Olúwa rẹ̀ pé: “Dájúdájú wọ́n ti borí mi. Bá mi gbẹ̀san.”

Al-Qamar 54:11

فَفَتَحۡنَآ أَبۡوَٰبَ ٱلسَّمَآءِ بِمَآءٖ مُّنۡهَمِرٖ ﴿١١﴾

Nítorí náà, A ṣí àwọn ìlẹ̀kùn sánmọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú omi tó lágbára.

As-Saf 61:9

هُوَ ٱلَّذِيٓ أَرۡسَلَ رَسُولَهُۥ بِٱلۡهُدَىٰ وَدِينِ ٱلۡحَقِّ لِيُظۡهِرَهُۥ عَلَى ٱلدِّينِ كُلِّهِۦ وَلَوۡ كَرِهَ ٱلۡمُشۡرِكُونَ ﴿٩﴾

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó fi ìmọ̀nà àti ẹ̀sìn òdodo (’Islām) rán Òjíṣẹ́ Rẹ̀ nítorí kí Ó lè fi borí gbogbo ẹ̀sìn (mìíràn) pátápátá, àwọn ọ̀ṣẹbọ ìbáà kórira rẹ̀.

As-Saf 61:10

يَـٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ هَلۡ أَدُلُّكُمۡ عَلَىٰ تِجَٰرَةٖ تُنجِيكُم مِّنۡ عَذَابٍ أَلِيمٖ ﴿١٠﴾

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ṣé kí N̄g tọ́ka yín sí òkòwò kan tí ó máa gbà yín là nínú ìyà ẹlẹ́ta-eléro?

As-Saf 61:11

تُؤۡمِنُونَ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦ وَتُجَٰهِدُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ بِأَمۡوَٰلِكُمۡ وَأَنفُسِكُمۡۚ ذَٰلِكُمۡ خَيۡرٞ لَّكُمۡ إِن كُنتُمۡ تَعۡلَمُونَ ﴿١١﴾

Ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, ẹ jagun sójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu pẹ̀lú àwọn dúkìá yín àti ẹ̀mí yín. Ìyẹn lóore jùlọ fún yín tí ẹ bá mọ̀.

As-Saf 61:12

يَغۡفِرۡ لَكُمۡ ذُنُوبَكُمۡ وَيُدۡخِلۡكُمۡ جَنَّـٰتٖ تَجۡرِي مِن تَحۡتِهَا ٱلۡأَنۡهَٰرُ وَمَسَٰكِنَ طَيِّبَةٗ فِي جَنَّـٰتِ عَدۡنٖۚ ذَٰلِكَ ٱلۡفَوۡزُ ٱلۡعَظِيمُ ﴿١٢﴾

(Allāhu) máa forí ẹ̀ṣẹ̀ yín jìn yín. Ó sì máa mu yín wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ibùgbé tó dára nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra gbére. Ìyẹn ni èrèǹjẹ ńlá.

As-Saf 61:13

وَأُخۡرَىٰ تُحِبُّونَهَاۖ نَصۡرٞ مِّنَ ٱللَّهِ وَفَتۡحٞ قَرِيبٞۗ وَبَشِّرِ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿١٣﴾

Àti n̄ǹkan mìíràn tí ẹ tún nífẹ̀ẹ́ sí; (ìyẹn) àrànṣe láti ọ̀dọ̀ Allāhu àti ìṣẹ́gun tó súnmọ́. Kí o sì fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo ní ìró ìdùnnú.

An-Nasr 110:1

إِذَا جَآءَ نَصۡرُ ٱللَّهِ وَٱلۡفَتۡحُ ﴿١﴾

Nígbà tí àrànṣe Allāhu (lórí ọ̀tá ẹ̀sìn) àti ṣíṣí ìlú (Mọ́kkah) bá ṣẹlẹ̀,

An-Nasr 110:2

وَرَأَيۡتَ ٱلنَّاسَ يَدۡخُلُونَ فِي دِينِ ٱللَّهِ أَفۡوَاجٗا ﴿٢﴾

tí o sì rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wọnú ẹ̀sìn Allāhu níjọníjọ,

An-Nasr 110:3

فَسَبِّحۡ بِحَمۡدِ رَبِّكَ وَٱسۡتَغۡفِرۡهُۚ إِنَّهُۥ كَانَ تَوَّابَۢا ﴿٣﴾

nítorí náà, ṣe àfọ̀mọ́ àti ẹyìn fún Olúwa rẹ. Kí o sì tọrọ àforíjìn lọ́dọ̀ Rẹ̀.Dájúdájú Ó ń jẹ́ Olùgba-ìronúpìwàdà.

Al-Baqarah 2:48

وَٱتَّقُواْ يَوۡمٗا لَّا تَجۡزِي نَفۡسٌ عَن نَّفۡسٖ شَيۡـٔٗا وَلَا يُقۡبَلُ مِنۡهَا شَفَٰعَةٞ وَلَا يُؤۡخَذُ مِنۡهَا عَدۡلٞ وَلَا هُمۡ يُنصَرُونَ ﴿٤٨﴾

Ẹ bẹ̀rù ọjọ́ kan tí ẹ̀mí kan kò níí rọrọ̀ kiní kan fún ẹ̀mí kan. Wọn kò níí gba ìṣìpẹ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀. Wọn kò níí gba ààrọ̀ l’ọ́wọ́ rẹ̀.Wọn kò sì níí ràn wọ́n lọ́wọ́.2

Al-Baqarah 2:214

أَمۡ حَسِبۡتُمۡ أَن تَدۡخُلُواْ ٱلۡجَنَّةَ وَلَمَّا يَأۡتِكُم مَّثَلُ ٱلَّذِينَ خَلَوۡاْ مِن قَبۡلِكُمۖ مَّسَّتۡهُمُ ٱلۡبَأۡسَآءُ وَٱلضَّرَّآءُ وَزُلۡزِلُواْ حَتَّىٰ يَقُولَ ٱلرَّسُولُ وَٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مَعَهُۥ مَتَىٰ نَصۡرُ ٱللَّهِۗ أَلَآ إِنَّ نَصۡرَ ٱللَّهِ قَرِيبٞ ﴿٢١٤﴾

Tàbí ẹ lérò pé ẹ máa wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra nígbà tí irúfẹ́ (àdánwò) tó kan àwọn tó ti lọ ṣíwájú yín kò ì kàn yín? Ìpọ́njú àti àìlera mú wọn. Wọ́n sì rí àmìwò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Òjíṣẹ́ àti àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo pẹ̀lú rẹ̀ fi sọ pé: “Ìgbà wo ni àrànṣe Allāhu máa dé sẹ́?” Kíyè sí i! Dájúdájú àrànṣe Allāhu súnmọ́.

Al-Baqarah 2:250

وَلَمَّا بَرَزُواْ لِجَالُوتَ وَجُنُودِهِۦ قَالُواْ رَبَّنَآ أَفۡرِغۡ عَلَيۡنَا صَبۡرٗا وَثَبِّتۡ أَقۡدَامَنَا وَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿٢٥٠﴾

Nígbà tí wọ́n jáde sí Jālūt àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n sọ pé: “Olúwa wa, fún wa ní omi sùúrù mu, fi ẹsẹ̀ wa rinlẹ̀ ṣinṣin, kí O sì ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.”

Al-Baqarah 2:251

فَهَزَمُوهُم بِإِذۡنِ ٱللَّهِ وَقَتَلَ دَاوُۥدُ جَالُوتَ وَءَاتَىٰهُ ٱللَّهُ ٱلۡمُلۡكَ وَٱلۡحِكۡمَةَ وَعَلَّمَهُۥ مِمَّا يَشَآءُۗ وَلَوۡلَا دَفۡعُ ٱللَّهِ ٱلنَّاسَ بَعۡضَهُم بِبَعۡضٖ لَّفَسَدَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَلَٰكِنَّ ٱللَّهَ ذُو فَضۡلٍ عَلَى ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿٢٥١﴾

Wọ́n sì ṣẹ́gun wọn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Dāwūd pa Jālūt. Allāhu sì fún un ní ìjọba àti ọgbọ́n. Ó tún fi ìmọ̀ mọ̀ ọ́n nínú ohun tí Ó fẹ́. Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, orí ilẹ̀ ìbá ti bàjẹ́. Ṣùgbọ́n Allāhu ni Olóore àjùlọ lórí gbogbo ẹ̀dá.

Ali 'Imran 3:13

قَدۡ كَانَ لَكُمۡ ءَايَةٞ فِي فِئَتَيۡنِ ٱلۡتَقَتَاۖ فِئَةٞ تُقَٰتِلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَأُخۡرَىٰ كَافِرَةٞ يَرَوۡنَهُم مِّثۡلَيۡهِمۡ رَأۡيَ ٱلۡعَيۡنِۚ وَٱللَّهُ يُؤَيِّدُ بِنَصۡرِهِۦ مَن يَشَآءُۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّأُوْلِي ٱلۡأَبۡصَٰرِ ﴿١٣﴾

Àmì kúkú wà fún yín níbi àwọn ìjọ méjì tí wọ́n pàdé (ara wọn). Ìjọ kan ń jà fún ààbò ẹ̀sìn Allāhu. Aláìgbàgbọ́ sì ni ìjọ kejì tí ó ń rí ìjọ kìíní bí ìlọ́po méjì wọn ní rírí ojú.Allāhu ń fi àrànṣe Rẹ̀ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún àwọn olùríran.

Ali 'Imran 3:91

إِنَّ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ وَمَاتُواْ وَهُمۡ كُفَّارٞ فَلَن يُقۡبَلَ مِنۡ أَحَدِهِم مِّلۡءُ ٱلۡأَرۡضِ ذَهَبٗا وَلَوِ ٱفۡتَدَىٰ بِهِۦٓۗ أُوْلَـٰٓئِكَ لَهُمۡ عَذَابٌ أَلِيمٞ وَمَا لَهُم مِّن نَّـٰصِرِينَ ﴿٩١﴾

Dájúdájú àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n sì kú nígbà tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, A ò níí gba ẹ̀kún ilẹ̀ wúrà lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni nínú wọn, ìbáà fi ṣèràpadà (fún ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Iná). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìyà ẹlẹ́ta-eléro ń bẹ fún. Kò sì níí sí àwọn olùrànlọ́wọ́ fún wọn.

Ali 'Imran 3:111

لَن يَضُرُّوكُمۡ إِلَّآ أَذٗىۖ وَإِن يُقَٰتِلُوكُمۡ يُوَلُّوكُمُ ٱلۡأَدۡبَارَ ثُمَّ لَا يُنصَرُونَ ﴿١١١﴾

Wọn kò níí kó ìnira ba yín àyàfi ìpalára díẹ̀. Tí wọ́n bá sì ba yín jà, wọ́n á sá fún yín. Lẹ́yìn náà, A ò níí ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ali 'Imran 3:150

بَلِ ٱللَّهُ مَوۡلَىٰكُمۡۖ وَهُوَ خَيۡرُ ٱلنَّـٰصِرِينَ ﴿١٥٠﴾

Allāhu sì ni Alárànṣe yín.Ó sì lóore jùlọ nínú àwọn alárànṣe.2

Ali 'Imran 3:160

إِن يَنصُرۡكُمُ ٱللَّهُ فَلَا غَالِبَ لَكُمۡۖ وَإِن يَخۡذُلۡكُمۡ فَمَن ذَا ٱلَّذِي يَنصُرُكُم مِّنۢ بَعۡدِهِۦۗ وَعَلَى ٱللَّهِ فَلۡيَتَوَكَّلِ ٱلۡمُؤۡمِنُونَ ﴿١٦٠﴾

Tí Allāhu bá ṣe àrànṣe fún yín, kò sí ẹni tí ó máa borí yín. Tí Ó bá sì yẹpẹrẹ yín, ta sì ni ẹni tí ó máa ṣe àrànṣe fún yín lẹ́yìn Rẹ̀? Allāhu ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.

An-Nisa 4:45

وَٱللَّهُ أَعۡلَمُ بِأَعۡدَآئِكُمۡۚ وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ وَلِيّٗا وَكَفَىٰ بِٱللَّهِ نَصِيرٗا ﴿٤٥﴾

Allāhu sì nímọ̀ jùlọ nípa àwọn ọ̀tá yín. Allāhu tó ní Aláàbò. Allāhu sì tó ní Alárànṣe.

An-Nisa 4:52

أُوْلَـٰٓئِكَ ٱلَّذِينَ لَعَنَهُمُ ٱللَّهُۖ وَمَن يَلۡعَنِ ٱللَّهُ فَلَن تَجِدَ لَهُۥ نَصِيرًا ﴿٥٢﴾

Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu ṣẹ́bi lé. Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá sì ṣẹ́bi lé, o ò níí rí alárànṣe kan fún un.

An-Nisa 4:75

وَمَا لَكُمۡ لَا تُقَٰتِلُونَ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ وَٱلۡمُسۡتَضۡعَفِينَ مِنَ ٱلرِّجَالِ وَٱلنِّسَآءِ وَٱلۡوِلۡدَٰنِ ٱلَّذِينَ يَقُولُونَ رَبَّنَآ أَخۡرِجۡنَا مِنۡ هَٰذِهِ ٱلۡقَرۡيَةِ ٱلظَّالِمِ أَهۡلُهَا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ وَلِيّٗا وَٱجۡعَل لَّنَا مِن لَّدُنكَ نَصِيرًا ﴿٧٥﴾

Kí l’ó ṣe yín tí ẹ ò níí jagun fún (ààbò) ẹ̀sìn Allāhu àti (fún ààbò) àwọn aláìlágbára nínú àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àwọn tó ń sọ pé: “Olúwa wa, mú wa jáde kúrò nínú ìlú yìí, ìlú àwọn alábòsí. Fún wa ní aláàbò kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ́. Kí Ó sì fún wa ní alárànṣe kan láti ọ̀dọ̀ Rẹ.”

An-Nisa 4:123

لَّيۡسَ بِأَمَانِيِّكُمۡ وَلَآ أَمَانِيِّ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِۗ مَن يَعۡمَلۡ سُوٓءٗا يُجۡزَ بِهِۦ وَلَا يَجِدۡ لَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَلِيّٗا وَلَا نَصِيرٗا ﴿١٢٣﴾

Kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn yín, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfẹ́-ọkàn àwọn onítírà (ni òṣùwọ̀n ìdájọ́ ọ̀run. Àmọ́,) ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ aburú kan, A óò san án ní ẹ̀san rẹ̀; kò sì níí rí aláfẹ̀yìntì tàbí alárànṣe kan lẹ́yìn Allāhu.1

Al-An'am 6:34

وَلَقَدۡ كُذِّبَتۡ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ فَصَبَرُواْ عَلَىٰ مَا كُذِّبُواْ وَأُوذُواْ حَتَّىٰٓ أَتَىٰهُمۡ نَصۡرُنَاۚ وَلَا مُبَدِّلَ لِكَلِمَٰتِ ٱللَّهِۚ وَلَقَدۡ جَآءَكَ مِن نَّبَإِيْ ٱلۡمُرۡسَلِينَ ﴿٣٤﴾

Wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ kan lópùrọ́ ṣíwájú rẹ. Wọ́n sì ṣe sùúrù lórí n̄ǹkan tí wọ́n fi pè wọ́n ní òpùrọ́. Wọ́n sì fi ìnira kàn wọ́n títí di ìgbà tí àrànṣe Wa fi dé bá wọn. Kò sì sí aláyìípadà kan fún àwọn ọ̀rọ̀ Allāhu.Dájúdájú ìró àwọn Òjíṣẹ́ ti dé bá ọ.

Al-Anfal 8:26

وَٱذۡكُرُوٓاْ إِذۡ أَنتُمۡ قَلِيلٞ مُّسۡتَضۡعَفُونَ فِي ٱلۡأَرۡضِ تَخَافُونَ أَن يَتَخَطَّفَكُمُ ٱلنَّاسُ فَـَٔاوَىٰكُمۡ وَأَيَّدَكُم بِنَصۡرِهِۦ وَرَزَقَكُم مِّنَ ٱلطَّيِّبَٰتِ لَعَلَّكُمۡ تَشۡكُرُونَ ﴿٢٦﴾

Ẹ rántí pé nígbà tí ẹ̀yin kéré ní òǹkà, tí ẹ wà ní ipò ọ̀lẹ (lábẹ́ wọn) lórí ilẹ̀ (ìyẹn nínú ìlú Mọkkah), ẹ sì ń páyà pé àwọn ènìyàn máa ji yín gbé lọ, nígbà náà (Allāhu) ṣe ibùgbé fún yín (nínú ìlú Mọdīnah Onímọ̀ọ́lẹ̀), Ó sì fi àrànṣe Rẹ ṣe ìkúnlọ́wọ́ fún yín. Ó tún pèsè fún yín nínú àwọn n̄ǹkan dáadáa nítorí kí ẹ lè dúpẹ́.

Al-Anfal 8:62

وَإِن يُرِيدُوٓاْ أَن يَخۡدَعُوكَ فَإِنَّ حَسۡبَكَ ٱللَّهُۚ هُوَ ٱلَّذِيٓ أَيَّدَكَ بِنَصۡرِهِۦ وَبِٱلۡمُؤۡمِنِينَ ﴿٦٢﴾

Tí wọ́n bá tún fẹ́ tàn ọ́ jẹ, dájúdájú Allāhu á tó ọ. Òun ni Ẹni tí Ó fi àrànṣe Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo ràn ọ́ lọ́wọ́.

At-Tawbah 9:14

قَٰتِلُوهُمۡ يُعَذِّبۡهُمُ ٱللَّهُ بِأَيۡدِيكُمۡ وَيُخۡزِهِمۡ وَيَنصُرۡكُمۡ عَلَيۡهِمۡ وَيَشۡفِ صُدُورَ قَوۡمٖ مُّؤۡمِنِينَ ﴿١٤﴾

Ẹ jà wọ́n lógun. Allāhu yóò jẹ wọ́n níyà láti ọwọ́ yín. Ó máa yẹpẹrẹ wọn. Ó máa ràn yín lọ́wọ́ lórí wọn. Ó sì máa wo ọkàn ìjọ onígbàgbọ́ òdodo sàn.

At-Tawbah 9:40

إِلَّا تَنصُرُوهُ فَقَدۡ نَصَرَهُ ٱللَّهُ إِذۡ أَخۡرَجَهُ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ثَانِيَ ٱثۡنَيۡنِ إِذۡ هُمَا فِي ٱلۡغَارِ إِذۡ يَقُولُ لِصَٰحِبِهِۦ لَا تَحۡزَنۡ إِنَّ ٱللَّهَ مَعَنَاۖ فَأَنزَلَ ٱللَّهُ سَكِينَتَهُۥ عَلَيۡهِ وَأَيَّدَهُۥ بِجُنُودٖ لَّمۡ تَرَوۡهَا وَجَعَلَ كَلِمَةَ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ ٱلسُّفۡلَىٰۗ وَكَلِمَةُ ٱللَّهِ هِيَ ٱلۡعُلۡيَاۗ وَٱللَّهُ عَزِيزٌ حَكِيمٌ ﴿٤٠﴾

Àfi kí ẹ ràn án lọ́wọ́, Allāhu kúkú ti ràn án lọ́wọ́ nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ lé e jáde (kúrò nínú ìlú). Ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì.Nígbà tí àwọn méjèèjì wà nínú ọ̀gbun, tí (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sì ń sọ fún olùbárìn rẹ̀ pé: “Má ṣe banújẹ́, dájúdájú Allāhu wà pẹ̀lú wa.”2 Nígbà náà, Allāhu sọ ìfàyàbalẹ̀ Rẹ̀ kalẹ̀ fún un. Ó fi àwọn ọmọ ogun kan tí ẹ kò fojú rí ràn án lọ́wọ́. Ó sì mú ọ̀rọ̀ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ wálẹ̀. Ọ̀rọ̀ Allāhu, òhun ló sì lékè. Allāhu sì ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.

Hud 11:63

قَالَ يَٰقَوۡمِ أَرَءَيۡتُمۡ إِن كُنتُ عَلَىٰ بَيِّنَةٖ مِّن رَّبِّي وَءَاتَىٰنِي مِنۡهُ رَحۡمَةٗ فَمَن يَنصُرُنِي مِنَ ٱللَّهِ إِنۡ عَصَيۡتُهُۥۖ فَمَا تَزِيدُونَنِي غَيۡرَ تَخۡسِيرٖ ﴿٦٣﴾

Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ sọ fún mi, tí ó bá jẹ́ pé èmi wà lórí ẹ̀rí tó yanjú láti ọ̀dọ̀ Olúwa mi, tí ìkẹ́ kan sì dé bá mi láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀, ta ni ẹni tí ó máa ràn mí lọ́wọ́ nínú (ìyà) Allāhu tí mo bá yapa Rẹ̀? Kò sí kiní kan tí ẹ lè fi ṣe àlékún rẹ̀ fún mi yàtọ̀ sí ìparun.

Yusuf 12:110

حَتَّىٰٓ إِذَا ٱسۡتَيۡـَٔسَ ٱلرُّسُلُ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ قَدۡ كُذِبُواْ جَآءَهُمۡ نَصۡرُنَا فَنُجِّيَ مَن نَّشَآءُۖ وَلَا يُرَدُّ بَأۡسُنَا عَنِ ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡمُجۡرِمِينَ ﴿١١٠﴾

(A kì í jẹ àwọn ènìyàn níyà) títí di ìgbà tí àwọn Òjíṣẹ́ bá tó sọ̀rètí nù (nípa ìgbàgbọ́ wọn), tí wọ́n sì mọ̀ pé wọ́n ti pe àwọn ní òpùrọ́. Àrànṣe Wa yó sì dé bá wọn. A sì máa gba ẹni tí A bá fẹ́ là. Wọn kò lè dá ìyà Wa padà lórí ìjọ ẹlẹ́ṣẹ̀.

Al-Isra 17:80

وَقُل رَّبِّ أَدۡخِلۡنِي مُدۡخَلَ صِدۡقٖ وَأَخۡرِجۡنِي مُخۡرَجَ صِدۡقٖ وَٱجۡعَل لِّي مِن لَّدُنكَ سُلۡطَٰنٗا نَّصِيرٗا ﴿٨٠﴾

Sọ pé: “Olúwa mi, mú mi wọ inú ìlú ní ìwọ̀lú ọ̀nà òdodo. Mú mi jáde kúrò nínú ìlú ní ìjáde ọ̀nà òdodo. Kí O sì fún mi ní àrànṣe tó lágbára láti ọ̀dọ̀ Rẹ.

Al-Kahf 18:43

وَلَمۡ تَكُن لَّهُۥ فِئَةٞ يَنصُرُونَهُۥ مِن دُونِ ٱللَّهِ وَمَا كَانَ مُنتَصِرًا ﴿٤٣﴾

Kò ní ìjọ kan tí ó máa ràn án lọ́wọ́ mọ́ lẹ́yìn Allāhu. Kò sì lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́.

Al-Anbya 21:43

أَمۡ لَهُمۡ ءَالِهَةٞ تَمۡنَعُهُم مِّن دُونِنَاۚ لَا يَسۡتَطِيعُونَ نَصۡرَ أَنفُسِهِمۡ وَلَا هُم مِّنَّا يُصۡحَبُونَ ﴿٤٣﴾

Tàbí wọ́n ní àwọn ọlọ́hun kan tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn Wa ni? Wọn kò lè ran ara wọn lọ́wọ́. Wọn kò sì lè gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́dọ̀ Wa.

Àwọn kókó