سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ ﴿1﴾سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ
Transliteration: Saala sailun biAAathabin waqiAAin
Translation: Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ ﴿1﴾سَأَلَ سَآئِلُۢ بِعَذَابٖ وَاقِعٖ
Transliteration: Saala sailun biAAathabin waqiAAin
Translation: Oníbèéèrè kan bèèrè nípa ìyà tó máa ṣẹlẹ̀
لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ ﴿2﴾لِّلۡكَٰفِرِينَ لَيۡسَ لَهُۥ دَافِعٞ
Transliteration: Lilkafireena laysa lahu dafiAAun
Translation: sí àwọn aláìgbàgbọ́. Kò sì sí ẹni tí ó máa dí i lọ́wọ́
مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ ﴿3﴾مِّنَ ٱللَّهِ ذِي ٱلۡمَعَارِجِ
Transliteration: Mina Allahi thee almaAAariji
Translation: lọ́dọ̀ Allāhu, Onípò-àyè gíga.
تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ ﴿4﴾تَعۡرُجُ ٱلۡمَلَـٰٓئِكَةُ وَٱلرُّوحُ إِلَيۡهِ فِي يَوۡمٖ كَانَ مِقۡدَارُهُۥ خَمۡسِينَ أَلۡفَ سَنَةٖ
Transliteration: TaAAruju almalaikatu waalrroohu ilayhi fee yawmin kana miqdaruhu khamseena alfa sanatin
Translation: Àwọn mọlāika àti mọlāika Jibrīl ń gùnkè wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nínú ọjọ́ kan tí òdiwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ ọdún (tí ẹ bá fẹ́ rìn ín).1
فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا ﴿5﴾فَٱصۡبِرۡ صَبۡرٗا جَمِيلًا
Transliteration: Faisbir sabran jameelan
Translation: Nítorí náà, ṣe sùúrù ní sùúrù tó rẹwà.
إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا ﴿6﴾إِنَّهُمۡ يَرَوۡنَهُۥ بَعِيدٗا
Transliteration: Innahum yarawnahu baAAeedan
Translation: Dájúdájú wọ́n ń wo (ìyà náà) ní ohun tó jìnnà.
وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا ﴿7﴾وَنَرَىٰهُ قَرِيبٗا
Transliteration: Wanarahu qareeban
Translation: A sì ń wò ó ní ohun tó súnmọ́.
يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ ﴿8﴾يَوۡمَ تَكُونُ ٱلسَّمَآءُ كَٱلۡمُهۡلِ
Transliteration: Yawma takoonu alssamao kaalmuhli
Translation: (Ọjọ́ náà ni) ọjọ́ tí sánmọ̀ yó dà bí ògéré epo gbígbóná,
وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ ﴿9﴾وَتَكُونُ ٱلۡجِبَالُ كَٱلۡعِهۡنِ
Transliteration: Watakoonu aljibalu kaalAAihni
Translation: àwọn àpáta yó sì dà bí ẹ̀gbọ̀n òwú-irun,
وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا ﴿10﴾وَلَا يَسۡـَٔلُ حَمِيمٌ حَمِيمٗا
Transliteration: Wala yasalu hameemun hameeman
Translation: ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan kò sì níí bèèrè ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ (rẹ̀).
يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ ﴿11﴾يُبَصَّرُونَهُمۡۚ يَوَدُّ ٱلۡمُجۡرِمُ لَوۡ يَفۡتَدِي مِنۡ عَذَابِ يَوۡمِئِذِۭ بِبَنِيهِ
Transliteration: Yubassaroonahum yawaddu almujrimu law yaftadee min AAathabi yawmiithin bibaneehi
Translation: Wọ́n máa rí ara wọn (wọ́n sì máa dára wọn mọ̀). Ẹlẹ́ṣẹ̀ sì máa fẹ́ kí òun fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà ní ọjọ́ yẹn.
وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ ﴿12﴾وَصَٰحِبَتِهِۦ وَأَخِيهِ
Transliteration: Wasahibatihi waakheehi
Translation: Ìyàwó rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀,
وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ ﴿13﴾وَفَصِيلَتِهِ ٱلَّتِي تُـٔۡوِيهِ
Transliteration: Wafaseelatihi allatee tuweehi
Translation: àti àwọn ẹbí rẹ̀ tó pa tì, tí àwọn sì ń gbà á sọ́dọ̀ nílé ayé,
وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ ﴿14﴾وَمَن فِي ٱلۡأَرۡضِ جَمِيعٗا ثُمَّ يُنجِيهِ
Transliteration: Waman fee alardi jameeAAan thumma yunjeehi
Translation: àti gbogbo ẹni tó wà lórí ilẹ̀ ayé pátápátá, (ó máa fẹ́ fi wọ́n ṣèràpadà ẹ̀mí ara rẹ̀ níbi Ìyà). Lẹ́yìn náà, (ó máa fẹ́) kí Allāhu gba òun là (nínú ìyà Iná).
كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ ﴿15﴾كَلَّآۖ إِنَّهَا لَظَىٰ
Transliteration: Kalla innaha latha
Translation: Rárá! Dájúdájú (ó máa wọ) iná Laṭḥọ̄ (iná tó ń jò fòfò).
نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ ﴿16﴾نَزَّاعَةٗ لِّلشَّوَىٰ
Transliteration: NazzaAAatan lilshshawa
Translation: Ó máa bó awọ orí tòró.
تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ ﴿17﴾تَدۡعُواْ مَنۡ أَدۡبَرَ وَتَوَلَّىٰ
Transliteration: TadAAoo man adbara watawalla
Translation: (Iná) yó máa ké sí ẹni tó kẹ̀yìn sí (ìgbágbọ́ òdodo), tí ó sì takété sí i,
وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ ﴿18﴾وَجَمَعَ فَأَوۡعَىٰٓ
Transliteration: WajamaAAa faawAAa
Translation: ó kó (ọrọ̀) jọ, ó sì fi pamọ́ (kò ná an fún ẹ̀sìn).
إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا ﴿19﴾۞إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ خُلِقَ هَلُوعًا
Transliteration: Inna alinsana khuliqa halooAAan
Translation: Dájúdájú ènìyàn, A ṣẹ̀dá rẹ̀ ní aláìlọ́kàn, ọ̀kánjúà.
إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا ﴿20﴾إِذَا مَسَّهُ ٱلشَّرُّ جَزُوعٗا
Transliteration: Itha massahu alshsharru jazooAAan
Translation: Nígbà tí aburú bá fọwọ́ bà á, ó máa kanra gógó.
وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا ﴿21﴾وَإِذَا مَسَّهُ ٱلۡخَيۡرُ مَنُوعًا
Transliteration: Waitha massahu alkhayru manooAAan
Translation: Nígbà tí ọwọ́ rẹ̀ bá sì ba oore, ó máa yahun.
إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ ﴿22﴾إِلَّا ٱلۡمُصَلِّينَ
Transliteration: Illa almusalleena
Translation: Àyàfi àwọn olùkírun,
ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ ﴿23﴾ٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ دَآئِمُونَ
Transliteration: Allatheena hum AAala salatihim daimoona
Translation: àwọn tí wọ́n dúnnímọ́ ìrun wọn;
وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ ﴿24﴾وَٱلَّذِينَ فِيٓ أَمۡوَٰلِهِمۡ حَقّٞ مَّعۡلُومٞ
Transliteration: Waallatheena fee amwalihim haqqun maAAloomun
Translation: àwọn tó mọ ojúṣe (wọn) nínú dúkìá wọn
لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ ﴿25﴾لِّلسَّآئِلِ وَٱلۡمَحۡرُومِ
Transliteration: Lilssaili waalmahroomi
Translation: sí alágbe àti ẹni tí A ṣe arísìkí ní èèwọ̀ fún;
وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ ﴿26﴾وَٱلَّذِينَ يُصَدِّقُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
Transliteration: Waallatheena yusaddiqoona biyawmi alddeeni
Translation: àwọn tó ń gba ọjọ́ ẹ̀san gbọ́ ní òdodo;
وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ ﴿27﴾وَٱلَّذِينَ هُم مِّنۡ عَذَابِ رَبِّهِم مُّشۡفِقُونَ
Transliteration: Waallatheena hum min AAathabi rabbihim mushfiqoona
Translation: àwọn tó ń páyà ìyà Olúwa wọn,
إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ ﴿28﴾إِنَّ عَذَابَ رَبِّهِمۡ غَيۡرُ مَأۡمُونٖ
Transliteration: Inna AAathaba rabbihim ghayru mamoonin
Translation: dájúdájú ìyà Olúwa wọn kò ṣeé fàyàbalẹ̀ sí;
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ ﴿29﴾وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِفُرُوجِهِمۡ حَٰفِظُونَ
Transliteration: Waallatheena hum lifuroojihim hafithoona
Translation: àwọn tó ń ṣọ́ abẹ́ wọn,
إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ ﴿30﴾إِلَّا عَلَىٰٓ أَزۡوَٰجِهِمۡ أَوۡ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَإِنَّهُمۡ غَيۡرُ مَلُومِينَ
Transliteration: Illa AAala azwajihim aw ma malakat aymanuhum fainnahum ghayru maloomeena
Translation: àyàfi lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó wọn tàbí ẹrúbìnrin wọn ni wọn kò ti lè jẹ́ ẹni-èébú,
فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ ﴿31﴾فَمَنِ ٱبۡتَغَىٰ وَرَآءَ ذَٰلِكَ فَأُوْلَـٰٓئِكَ هُمُ ٱلۡعَادُونَ
Transliteration: Famani ibtagha waraa thalika faolaika humu alAAadoona
Translation: nítorí náà, ẹnikẹ́ni tó bá ń wá n̄ǹkan mìíràn lẹ́yìn ìyẹn, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùtayọ-ẹnu ààlà;
وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ ﴿32﴾وَٱلَّذِينَ هُمۡ لِأَمَٰنَٰتِهِمۡ وَعَهۡدِهِمۡ رَٰعُونَ
Transliteration: Waallatheena hum liamanatihim waAAahdihim raAAoona
Translation: àwọn tó ń ṣọ́ àgbàfipamọ́ wọn àti àdéhùn wọn;
وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ ﴿33﴾وَٱلَّذِينَ هُم بِشَهَٰدَٰتِهِمۡ قَآئِمُونَ
Transliteration: Waallatheena hum bishahadatihim qaimoona
Translation: àwọn tó ń dúró ti ìjẹ́rìí (òdodo) wọn;
وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ ﴿34﴾وَٱلَّذِينَ هُمۡ عَلَىٰ صَلَاتِهِمۡ يُحَافِظُونَ
Transliteration: Waallatheena hum AAala salatihim yuhafithoona
Translation: àti àwọn tó ń ṣọ́ àwọn ìrun wọn.
أُوْلَـٰٓئِكَ فِي جَنَّـٰتٖ مُّكۡرَمُونَ ﴿35﴾أُوْلَـٰٓئِكَ فِي جَنَّـٰتٖ مُّكۡرَمُونَ
Transliteration: Olaika fee jannatin mukramoona
Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni alápọ̀n-ọ́nlé nínú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra.
فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ ﴿36﴾فَمَالِ ٱلَّذِينَ كَفَرُواْ قِبَلَكَ مُهۡطِعِينَ
Transliteration: Famali allatheena kafaroo qibalaka muhtiAAeena
Translation: Kí ló mú àwọn tí kò gbàgbọ́ tí ara wọn kò balẹ̀ níwájú rẹ,
عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ ﴿37﴾عَنِ ٱلۡيَمِينِ وَعَنِ ٱلشِّمَالِ عِزِينَ
Transliteration: AAani alyameeni waAAani alshshimali AAizeena
Translation: tí wọ́n sì jókòó ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí sí ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì (rẹ)?
أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ ﴿38﴾أَيَطۡمَعُ كُلُّ ٱمۡرِيٕٖ مِّنۡهُمۡ أَن يُدۡخَلَ جَنَّةَ نَعِيمٖ
Transliteration: AyatmaAAu kullu imriin minhum an yudkhala jannata naAAeemin
Translation: Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú wọn ń jẹ̀rankàn pé A óò mú òun wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra ni?
كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ ﴿39﴾كَلَّآۖ إِنَّا خَلَقۡنَٰهُم مِّمَّا يَعۡلَمُونَ
Transliteration: Kalla inna khalaqnahum mimma yaAAlamoona
Translation: Rárá o! Dájúdájú Àwa ṣẹ̀dá wọn láti inú ohun tí wọ́n mọ̀.
فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ ﴿40﴾فَلَآ أُقۡسِمُ بِرَبِّ ٱلۡمَشَٰرِقِ وَٱلۡمَغَٰرِبِ إِنَّا لَقَٰدِرُونَ
Transliteration: Fala oqsimu birabbi almashariqi waalmagharibi inna laqadiroona
Translation: Nítorí náà, Èmi ń fi Olúwa àwọn ibùyọ òòrùn àti àwọn ibùwọ̀ òòrùnbúra, dájúdájú Àwa ni Alágbára
عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ ﴿41﴾عَلَىٰٓ أَن نُّبَدِّلَ خَيۡرٗا مِّنۡهُمۡ وَمَا نَحۡنُ بِمَسۡبُوقِينَ
Transliteration: AAala an nubaddila khayran minhum wama nahnu bimasbooqeena
Translation: láti lè fi àwọn tó dára jù wọ́n lọ pààrọ̀ wọn. Kò sì sí ẹni tó lè kó agara bá Wa.
فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ ﴿42﴾فَذَرۡهُمۡ يَخُوضُواْ وَيَلۡعَبُواْ حَتَّىٰ يُلَٰقُواْ يَوۡمَهُمُ ٱلَّذِي يُوعَدُونَ
Transliteration: Fatharhum yakhoodoo wayalAAaboo hatta yulaqoo yawmahumu allathee yooAAadoona
Translation: Nítorí náà, fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n máa sọ ìsọkúsọ (wọn), kí wọ́n sì máa ṣeré títí wọn yóò fi pàdé ọjọ́ wọn tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ ﴿43﴾يَوۡمَ يَخۡرُجُونَ مِنَ ٱلۡأَجۡدَاثِ سِرَاعٗا كَأَنَّهُمۡ إِلَىٰ نُصُبٖ يُوفِضُونَ
Transliteration: Yawma yakhrujoona mina alajdathi siraAAan kaannahum ila nusubin yoofidoona
Translation: Ọjọ́ tí wọn yóò sáré jáde wéréwéré láti inú àwọn sàréè, wọn yó sì dà bí ẹni pé wọ́n ń yára lọ sídìí ohun àfojúsùn kan.
خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ ﴿44﴾خَٰشِعَةً أَبۡصَٰرُهُمۡ تَرۡهَقُهُمۡ ذِلَّةٞۚ ذَٰلِكَ ٱلۡيَوۡمُ ٱلَّذِي كَانُواْ يُوعَدُونَ
Transliteration: KhashiAAatan absaruhum tarhaquhum thillatun thalika alyawmu allathee kanoo yooAAadoona
Translation: Ojú wọn yóò wálẹ̀. Ìyẹpẹrẹ máa bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ọjọ́ yẹn ni èyí tí À ń ṣe ní àdéhùn fún wọn.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download