ٱلۡحَآقَّةُ ﴿1﴾ٱلۡحَآقَّةُ
Transliteration: Alhaqqatu
Translation: Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!
ٱلۡحَآقَّةُ ﴿1﴾ٱلۡحَآقَّةُ
Transliteration: Alhaqqatu
Translation: Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà!
مَا ٱلۡحَآقَّةُ ﴿2﴾مَا ٱلۡحَآقَّةُ
Transliteration: Ma alhaqqatu
Translation: Kí ni Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ ﴿3﴾وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡحَآقَّةُ
Transliteration: Wama adraka ma alhaqqatu
Translation: Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ìṣẹ̀lẹ̀ Òdodo náà?
كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ ﴿4﴾كَذَّبَتۡ ثَمُودُ وَعَادُۢ بِٱلۡقَارِعَةِ
Transliteration: Kaththabat thamoodu waAAadun bialqariAAati
Translation: Àwọn ìjọ Thamūd àti ìjọ ‘Ād pe Àjíǹde (ajámọláya bí àrá) ní irọ́.1
فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ ﴿5﴾فَأَمَّا ثَمُودُ فَأُهۡلِكُواْ بِٱلطَّاغِيَةِ
Transliteration: Faamma thamoodu faohlikoo bialttaghiyati
Translation: Ní ti ìjọ Thamūd, wọ́n fi igbe tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
وَأَمَّا عَادٞ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٖ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٖ ﴿6﴾وَأَمَّا عَادٞ فَأُهۡلِكُواْ بِرِيحٖ صَرۡصَرٍ عَاتِيَةٖ
Transliteration: Waamma AAadun faohlikoo bireehin sarsarin AAatiyatin
Translation: Ní ti ìjọ ‘Ād, wọ́n fi atẹ́gùn líle tó tayọ ẹnu-ààlà pa wọ́n rẹ́.
سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٖ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومٗاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٖ ﴿7﴾سَخَّرَهَا عَلَيۡهِمۡ سَبۡعَ لَيَالٖ وَثَمَٰنِيَةَ أَيَّامٍ حُسُومٗاۖ فَتَرَى ٱلۡقَوۡمَ فِيهَا صَرۡعَىٰ كَأَنَّهُمۡ أَعۡجَازُ نَخۡلٍ خَاوِيَةٖ
Transliteration: Sakhkharaha AAalayhim sabAAa layalin wathamaniyata ayyamin husooman fatara alqawma feeha sarAAa kaannahum aAAjazu nakhlin khawiyatun
Translation: Ó dẹ ẹ́ sí wọn fún òru méje àti ọ̀sán mẹ́jọ láì dáwọ́ dúró. O sì máa rí ìjọ náà tí wọ́n ti kú sínú rẹ̀ bí ẹni pé kùkùté igi dàbínù tó ti luhò nínú ni wọ́n.1
فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٖ ﴿8﴾فَهَلۡ تَرَىٰ لَهُم مِّنۢ بَاقِيَةٖ
Transliteration: Fahal tara lahum min baqiyatin
Translation: Ǹjẹ́ o rí ẹnì kan nínú wọn tó ṣẹ́ kù bí?
وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ ﴿9﴾وَجَآءَ فِرۡعَوۡنُ وَمَن قَبۡلَهُۥ وَٱلۡمُؤۡتَفِكَٰتُ بِٱلۡخَاطِئَةِ
Transliteration: Wajaa firAAawnu waman qablahu waalmutafikatu bialkhatiati
Translation: Fir‘aon àti àwọn tó ṣíwájú rẹ̀ àti àwọn ìlú tí wọ́n dojú rẹ̀ bolẹ̀ dé pẹ̀lú àwọn àṣìṣe.
فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةٗ رَّابِيَةً ﴿10﴾فَعَصَوۡاْ رَسُولَ رَبِّهِمۡ فَأَخَذَهُمۡ أَخۡذَةٗ رَّابِيَةً
Transliteration: FaAAasaw rasoola rabbihim faakhathahum akhthatan rabiyatan
Translation: Wọ́n yapa Òjíṣẹ́ Olúwa wọn. Ó sì gbá wọn mú ní ìgbámú tóléken̄kà.
إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ ﴿11﴾إِنَّا لَمَّا طَغَا ٱلۡمَآءُ حَمَلۡنَٰكُمۡ فِي ٱلۡجَارِيَةِ
Transliteration: Inna lamma tagha almao hamalnakum fee aljariyati
Translation: Dájúdájú nígbà tí omi tayọ ẹnu-ààlà. A gbe yín gun ọkọ̀ ojú-omi.
لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةٗ وَتَعِيَهَآ أُذُنٞ وَٰعِيَةٞ ﴿12﴾لِنَجۡعَلَهَا لَكُمۡ تَذۡكِرَةٗ وَتَعِيَهَآ أُذُنٞ وَٰعِيَةٞ
Transliteration: LinajAAalaha lakum tathkiratan wataAAiyaha othunun waAAiyatun
Translation: Nítorí kí Á lè fi ṣe ìrántí fún yín àti nítorí kí etí tó ń ṣọ́ n̄ǹkan lè ṣọ́ ọ.
فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٞ وَٰحِدَةٞ ﴿13﴾فَإِذَا نُفِخَ فِي ٱلصُّورِ نَفۡخَةٞ وَٰحِدَةٞ
Transliteration: Faitha nufikha fee alssoori nafkhatun wahidatun
Translation: Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè oníwo fún ikú ní fífọn ẹyọ kan,
وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةٗ وَٰحِدَةٗ ﴿14﴾وَحُمِلَتِ ٱلۡأَرۡضُ وَٱلۡجِبَالُ فَدُكَّتَا دَكَّةٗ وَٰحِدَةٗ
Transliteration: Wahumilati alardu waaljibalu fadukkata dakkatan wahidatan
Translation: tí wọ́n gbé ilẹ̀ àti àpáta sókè, tí wọ́n sì rún méjèèjì wómúwómú ní rírún ẹ̀ẹ̀ kan,
فَيَوۡمَئِذٖ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ ﴿15﴾فَيَوۡمَئِذٖ وَقَعَتِ ٱلۡوَاقِعَةُ
Transliteration: Fayawmaithin waqaAAati alwaqiAAatu
Translation: ní ọjọ́ yẹn ni Ìṣẹ̀lẹ̀ máa ṣẹlẹ̀.
وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٖ وَاهِيَةٞ ﴿16﴾وَٱنشَقَّتِ ٱلسَّمَآءُ فَهِيَ يَوۡمَئِذٖ وَاهِيَةٞ
Transliteration: Wainshaqqati alssamao fahiya yawmaithin wahiyatun
Translation: Àti pé sánmọ̀ yó fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ó sì máa fúyẹ́ gẹgẹ ní ọjọ́ yẹn.
وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ ثَمَٰنِيَةٞ ﴿17﴾وَٱلۡمَلَكُ عَلَىٰٓ أَرۡجَآئِهَاۚ وَيَحۡمِلُ عَرۡشَ رَبِّكَ فَوۡقَهُمۡ يَوۡمَئِذٖ ثَمَٰنِيَةٞ
Transliteration: Waalmalaku AAala arjaiha wayahmilu AAarsha rabbika fawqahum yawmaithin thamaniyatun
Translation: Àwọn mọlāika sì máa wà ní àwọn ẹ̀gbẹ́ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Àti pé ní ọjọ́ yẹn, lókè wọn, àwọn (mọlāika) mẹ́jọ ni wọ́n máa ru Ìtẹ́ Olúwa rẹ.
يَوۡمَئِذٖ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٞ ﴿18﴾يَوۡمَئِذٖ تُعۡرَضُونَ لَا تَخۡفَىٰ مِنكُمۡ خَافِيَةٞ
Transliteration: Yawmaithin tuAAradoona la takhfa minkum khafiyatun
Translation: Ní ọjọ́ yẹn, wọn yóò máa ṣẹ́rí yín wá (fún ìṣírò-iṣẹ́). Kò sì níí sí àṣírí yín kan tó máa pamọ́ (fún Wa).
فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ ﴿19﴾فَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِيَمِينِهِۦ فَيَقُولُ هَآؤُمُ ٱقۡرَءُواْ كِتَٰبِيَهۡ
Transliteration: Faamma man ootiya kitabahu biyameenihi fayaqoolu haomu iqraoo kitabiyah
Translation: Nítorí náà, ní ti ẹni tí wọ́n bá fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa sọ pé: “Ẹ gbà, ẹ ka tírà mi wò.
إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ ﴿20﴾إِنِّي ظَنَنتُ أَنِّي مُلَٰقٍ حِسَابِيَهۡ
Transliteration: Innee thanantu annee mulaqin hisabiyah
Translation: Dájúdájú èmi ti mọ àmọ̀dájú pé dájúdájú èmi yóò bá ìṣírò-iṣẹ́ mi pàdé.”
فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ ﴿21﴾فَهُوَ فِي عِيشَةٖ رَّاضِيَةٖ
Transliteration: Fahuwa fee AAeeshatin radiyatin
Translation: Nítorí náà, ó máa wà nínú ìṣẹ̀mí tó máa yọ́nú sí
فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٖ ﴿22﴾فِي جَنَّةٍ عَالِيَةٖ
Transliteration: Fee jannatin AAaliyatin
Translation: nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
قُطُوفُهَا دَانِيَةٞ ﴿23﴾قُطُوفُهَا دَانِيَةٞ
Transliteration: Qutoofuha daniyatun
Translation: Àwọn èso rẹ̀ (sì) máa wà ní àrọ́wọ́tó.
كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ ﴿24﴾كُلُواْ وَٱشۡرَبُواْ هَنِيٓـَٔۢا بِمَآ أَسۡلَفۡتُمۡ فِي ٱلۡأَيَّامِ ٱلۡخَالِيَةِ
Transliteration: Kuloo waishraboo haneean bima aslaftum fee alayyami alkhaliyati
Translation: Ẹ jẹ, kí ẹ sì mu pẹ̀lú ìgbàdún nítorí ohun tí ẹ tì síwájú nínú àwọn ọjọ́ tí ó ti ré kọjá.
وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ ﴿25﴾وَأَمَّا مَنۡ أُوتِيَ كِتَٰبَهُۥ بِشِمَالِهِۦ فَيَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي لَمۡ أُوتَ كِتَٰبِيَهۡ
Transliteration: Waamma man ootiya kitabahu bishimalihi fayaqoolu ya laytanee lam oota kitabiyah
Translation: Ní ti ẹni tí wọ́n bá sì fún ní tírà rẹ̀ ní ọwọ́ òsì rẹ̀, ó máa wí pé: “Háà! Kí wọ́n sì má fún mi ni tírà mi!1
وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ ﴿26﴾وَلَمۡ أَدۡرِ مَا حِسَابِيَهۡ
Transliteration: Walam adri ma hisabiyah
Translation: Àti pé kí èmi sì má mọ ohun tí ìṣírò-iṣẹ́ mi jẹ́.
يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ ﴿27﴾يَٰلَيۡتَهَا كَانَتِ ٱلۡقَاضِيَةَ
Transliteration: Ya laytaha kanati alqadiyatu
Translation: Háà! Kí ikú sì jẹ́ òpin (ọ̀rọ̀ ẹ̀dá).
مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ ﴿28﴾مَآ أَغۡنَىٰ عَنِّي مَالِيَهۡۜ
Transliteration: Ma aghna AAannee maliyah
Translation: Dúkìá mi kò sì rọ̀ mí lọ́rọ̀.
هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ ﴿29﴾هَلَكَ عَنِّي سُلۡطَٰنِيَهۡ
Transliteration: Halaka AAannee sultaniyah
Translation: Agbára mi sì ti parun.”
خُذُوهُ فَغُلُّوهُ ﴿30﴾خُذُوهُ فَغُلُّوهُ
Transliteration: Khuthoohu faghulloohu
Translation: Ẹ mú un, kí ẹ dè é ní ọwọ́ mọ́ ọrùn.
ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ ﴿31﴾ثُمَّ ٱلۡجَحِيمَ صَلُّوهُ
Transliteration: Thumma aljaheema salloohu
Translation: Lẹ́yìn náà, inú iná Jẹhīm ni kí ẹ mú un wọ̀.
ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٖ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعٗا فَٱسۡلُكُوهُ ﴿32﴾ثُمَّ فِي سِلۡسِلَةٖ ذَرۡعُهَا سَبۡعُونَ ذِرَاعٗا فَٱسۡلُكُوهُ
Transliteration: Thumma fee silsilatin tharAAuha sabAAoona thiraAAan faoslukoohu
Translation: Lẹ́yìn náà, inú ẹ̀wọ̀n tí gígùn rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin gígùn thar‘uni kí ẹ kì í sí.
إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ ﴿33﴾إِنَّهُۥ كَانَ لَا يُؤۡمِنُ بِٱللَّهِ ٱلۡعَظِيمِ
Transliteration: Innahu kana la yuminu biAllahi alAAatheemi
Translation: Dájúdájú òun kì í gbàgbọ́ nínú Allāhu, Atóbi.
وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ﴿34﴾وَلَا يَحُضُّ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ
Transliteration: Wala yahuddu AAala taAAami almiskeeni
Translation: Kì í sì gba ènìyàn níyànjú láti bọ́ àwọn mẹ̀kúnnù.
فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٞ ﴿35﴾فَلَيۡسَ لَهُ ٱلۡيَوۡمَ هَٰهُنَا حَمِيمٞ
Transliteration: Falaysa lahu alyawma hahuna hameemun
Translation: Nítorí náà, kò níí sí ọ̀rẹ́ ìmùlẹ̀ kan fún un níbí yìí ní òní.
وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٖ ﴿36﴾وَلَا طَعَامٌ إِلَّا مِنۡ غِسۡلِينٖ
Transliteration: Wala taAAamun illa min ghisleenin
Translation: Kò sì níí sí oúnjẹ kan (fún un) bí kò ṣe (oúnjẹ) àwọnúwẹ̀jẹ̀.
لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ ﴿37﴾لَّا يَأۡكُلُهُۥٓ إِلَّا ٱلۡخَٰطِـُٔونَ
Transliteration: La yakuluhu illa alkhatioona
Translation: Kò sí ẹni tí ó máa jẹ ẹ́ bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ ﴿38﴾فَلَآ أُقۡسِمُ بِمَا تُبۡصِرُونَ
Transliteration: Fala oqsimu bima tubsiroona
Translation: Nítorí náà, Èmi ń fi ohun tí ẹ̀ ń fojú rí búra
وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ ﴿39﴾وَمَا لَا تُبۡصِرُونَ
Transliteration: Wama la tubsiroona
Translation: àti ohun tí ẹ ò fojú rí.
إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ ﴿40﴾إِنَّهُۥ لَقَوۡلُ رَسُولٖ كَرِيمٖ
Transliteration: Innahu laqawlu rasoolin kareemin
Translation: Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀ (tí A fi rán) Òjíṣẹ́, alápọ̀n-ọ́nlé.1
وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٖۚ قَلِيلٗا مَّا تُؤۡمِنُونَ ﴿41﴾وَمَا هُوَ بِقَوۡلِ شَاعِرٖۚ قَلِيلٗا مَّا تُؤۡمِنُونَ
Transliteration: Wama huwa biqawli shaAAirin qaleelan ma tuminoona
Translation: Kì í ṣe ọ̀rọ̀ eléwì. Ohun tí ẹ gbàgbọ́ kéré púpọ̀.
وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٖۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ ﴿42﴾وَلَا بِقَوۡلِ كَاهِنٖۚ قَلِيلٗا مَّا تَذَكَّرُونَ
Transliteration: Wala biqawli kahinin qaleelan ma tathakkaroona
Translation: Kì í sì ṣe ọ̀rọ̀ adábigba. Díẹ̀ lẹ̀ ń lò nínú ìrántí.
تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿43﴾تَنزِيلٞ مِّن رَّبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Transliteration: Tanzeelun min rabbi alAAalameena
Translation: Wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ ﴿44﴾وَلَوۡ تَقَوَّلَ عَلَيۡنَا بَعۡضَ ٱلۡأَقَاوِيلِ
Transliteration: Walaw taqawwala AAalayna baAAda alaqaweeli
Translation: Tí ó bá jẹ́ pé (Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - ) dá àdápa apá kan ọ̀rọ̀ náà mọ́ Wa ni,
لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ ﴿45﴾لَأَخَذۡنَا مِنۡهُ بِٱلۡيَمِينِ
Transliteration: Laakhathna minhu bialyameeni
Translation: Àwa ìbá gbá a mú lọ́wọ́ ọ̀tún.
ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ ﴿46﴾ثُمَّ لَقَطَعۡنَا مِنۡهُ ٱلۡوَتِينَ
Transliteration: Thumma laqataAAna minhu alwateena
Translation: Lẹ́yìn náà, Àwa ìbá já isan ọrùn rẹ̀.
فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ ﴿47﴾فَمَا مِنكُم مِّنۡ أَحَدٍ عَنۡهُ حَٰجِزِينَ
Transliteration: Fama minkum min ahadin AAanhu hajizeena
Translation: Kò sì sí ẹnì kan nínú yín tí ó máa gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ (Wa).
وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ ﴿48﴾وَإِنَّهُۥ لَتَذۡكِرَةٞ لِّلۡمُتَّقِينَ
Transliteration: Wainnahu latathkiratun lilmuttaqeena
Translation: Dájúdájú (al-Ƙur’ān) ni ìrántí fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).
وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ ﴿49﴾وَإِنَّا لَنَعۡلَمُ أَنَّ مِنكُم مُّكَذِّبِينَ
Transliteration: Wainna lanaAAlamu anna minkum mukaththibeena
Translation: Dájúdájú Àwa sì mọ̀ pé àwọn tó ń pe al-Ƙur’ān ní irọ́ wà nínú yín.
وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ ﴿50﴾وَإِنَّهُۥ لَحَسۡرَةٌ عَلَى ٱلۡكَٰفِرِينَ
Transliteration: Wainnahu lahasratun AAala alkafireena
Translation: Dájúdájú al-Ƙur’ān máa jẹ́ àbámọ̀ ńlá fún àwọn aláìgbàgbọ́.
وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ ﴿51﴾وَإِنَّهُۥ لَحَقُّ ٱلۡيَقِينِ
Transliteration: Wainnahu lahaqqu alyaqeeni
Translation: Dájúdájú al-Ƙur’ān ni òdodo tó dájú.
فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ ﴿52﴾فَسَبِّحۡ بِٱسۡمِ رَبِّكَ ٱلۡعَظِيمِ
Transliteration: Fasabbih biismi rabbika alAAatheemi
Translation: Nítorí náà, ṣàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa Rẹ, Atóbi.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download