وَٱلۡفَجۡرِ ﴿1﴾وَٱلۡفَجۡرِ
Transliteration: Waalfajri
Translation: Allāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.
وَٱلۡفَجۡرِ ﴿1﴾وَٱلۡفَجۡرِ
Transliteration: Waalfajri
Translation: Allāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.
وَلَيَالٍ عَشۡرٖ ﴿2﴾وَلَيَالٍ عَشۡرٖ
Transliteration: Walayalin AAashrin
Translation: Ó tún fi àwọn òru mẹ́wàá kan búra.
وَٱلشَّفۡعِ وَٱلۡوَتۡرِ ﴿3﴾وَٱلشَّفۡعِ وَٱلۡوَتۡرِ
Transliteration: WaalshshafAAi waalwatri
Translation: Ó tún fi n̄ǹkan tí eéjì ń pín geerege àti n̄ǹkan tí eéjì kò pín geerege búra.
وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَسۡرِ ﴿4﴾وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَسۡرِ
Transliteration: Waallayli itha yasri
Translation: Ó tún fi òru nígbà tí ó bá dé búra.
هَلۡ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٞ لِّذِي حِجۡرٍ ﴿5﴾هَلۡ فِي ذَٰلِكَ قَسَمٞ لِّذِي حِجۡرٍ
Transliteration: Hal fee thalika qasamun lithee hijrin
Translation: Ǹjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ ﴿6﴾أَلَمۡ تَرَ كَيۡفَ فَعَلَ رَبُّكَ بِعَادٍ
Transliteration: Alam tara kayfa faAAala rabbuka biAAadin
Translation: Ṣé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
إِرَمَ ذَاتِ ٱلۡعِمَادِ ﴿7﴾إِرَمَ ذَاتِ ٱلۡعِمَادِ
Transliteration: Irama thati alAAimadi
Translation: (ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
ٱلَّتِي لَمۡ يُخۡلَقۡ مِثۡلُهَا فِي ٱلۡبِلَٰدِ ﴿8﴾ٱلَّتِي لَمۡ يُخۡلَقۡ مِثۡلُهَا فِي ٱلۡبِلَٰدِ
Transliteration: Allatee lam yukhlaq mithluha fee albiladi
Translation: àwọn tí A kò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُواْ ٱلصَّخۡرَ بِٱلۡوَادِ ﴿9﴾وَثَمُودَ ٱلَّذِينَ جَابُواْ ٱلصَّخۡرَ بِٱلۡوَادِ
Transliteration: Wathamooda allatheena jaboo alssakhra bialwadi
Translation: Àti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonúfojì,
وَفِرۡعَوۡنَ ذِي ٱلۡأَوۡتَادِ ﴿10﴾وَفِرۡعَوۡنَ ذِي ٱلۡأَوۡتَادِ
Transliteration: WafirAAawna thee alawtadi
Translation: àti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
ٱلَّذِينَ طَغَوۡاْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ ﴿11﴾ٱلَّذِينَ طَغَوۡاْ فِي ٱلۡبِلَٰدِ
Transliteration: Allatheena taghaw fee albiladi
Translation: (Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn tó tayọ ẹnu-ààlà nínú ìlú.
فَأَكۡثَرُواْ فِيهَا ٱلۡفَسَادَ ﴿12﴾فَأَكۡثَرُواْ فِيهَا ٱلۡفَسَادَ
Transliteration: Faaktharoo feeha alfasada
Translation: Wọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
فَصَبَّ عَلَيۡهِمۡ رَبُّكَ سَوۡطَ عَذَابٍ ﴿13﴾فَصَبَّ عَلَيۡهِمۡ رَبُّكَ سَوۡطَ عَذَابٍ
Transliteration: Fasabba AAalayhim rabbuka sawta AAathabin
Translation: Olúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلۡمِرۡصَادِ ﴿14﴾إِنَّ رَبَّكَ لَبِٱلۡمِرۡصَادِ
Transliteration: Inna rabbaka labialmirsadi
Translation: Dájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
فَأَمَّا ٱلۡإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكۡرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَكۡرَمَنِ ﴿15﴾فَأَمَّا ٱلۡإِنسَٰنُ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ رَبُّهُۥ فَأَكۡرَمَهُۥ وَنَعَّمَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَكۡرَمَنِ
Transliteration: Faamma alinsanu itha ma ibtalahu rabbuhu faakramahu wanaAAAAamahu fayaqoolu rabbee akramani
Translation: Nítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti pọ́n mi lé.”
وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيۡهِ رِزۡقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَهَٰنَنِ ﴿16﴾وَأَمَّآ إِذَا مَا ٱبۡتَلَىٰهُ فَقَدَرَ عَلَيۡهِ رِزۡقَهُۥ فَيَقُولُ رَبِّيٓ أَهَٰنَنِ
Transliteration: Waamma itha ma ibtalahu faqadara AAalayhi rizqahu fayaqoolu rabbee ahanani
Translation: Ṣùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi.”
كَلَّاۖ بَل لَّا تُكۡرِمُونَ ٱلۡيَتِيمَ ﴿17﴾كَلَّاۖ بَل لَّا تُكۡرِمُونَ ٱلۡيَتِيمَ
Transliteration: Kalla bal la tukrimoona alyateema
Translation: Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
وَلَا تَحَـٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ ﴿18﴾وَلَا تَحَـٰٓضُّونَ عَلَىٰ طَعَامِ ٱلۡمِسۡكِينِ
Transliteration: Wala tahaddoona AAala taAAami almiskeeni
Translation: Àti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
وَتَأۡكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكۡلٗا لَّمّٗا ﴿19﴾وَتَأۡكُلُونَ ٱلتُّرَاثَ أَكۡلٗا لَّمّٗا
Transliteration: Watakuloona altturatha aklan lamman
Translation: Ẹ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
وَتُحِبُّونَ ٱلۡمَالَ حُبّٗا جَمّٗا ﴿20﴾وَتُحِبُّونَ ٱلۡمَالَ حُبّٗا جَمّٗا
Transliteration: Watuhibboona almala hubban jamman
Translation: Àti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
كَلَّآۖ إِذَا دُكَّتِ ٱلۡأَرۡضُ دَكّٗا دَكّٗا ﴿21﴾كَلَّآۖ إِذَا دُكَّتِ ٱلۡأَرۡضُ دَكّٗا دَكّٗا
Transliteration: Kalla itha dukkati alardu dakkan dakkan
Translation: Rárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (tó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلۡمَلَكُ صَفّٗا صَفّٗا ﴿22﴾وَجَآءَ رَبُّكَ وَٱلۡمَلَكُ صَفّٗا صَفّٗا
Transliteration: Wajaa rabbuka waalmalaku saffan saffan
Translation: (tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
وَجِاْيٓءَ يَوۡمَئِذِۭ بِجَهَنَّمَۚ يَوۡمَئِذٖ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكۡرَىٰ ﴿23﴾وَجِاْيٓءَ يَوۡمَئِذِۭ بِجَهَنَّمَۚ يَوۡمَئِذٖ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ وَأَنَّىٰ لَهُ ٱلذِّكۡرَىٰ
Transliteration: Wajeea yawmaithin bijahannama yawmaithin yatathakkaru alinsanu waanna lahu alththikra
Translation: ní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي قَدَّمۡتُ لِحَيَاتِي ﴿24﴾يَقُولُ يَٰلَيۡتَنِي قَدَّمۡتُ لِحَيَاتِي
Transliteration: Yaqoolu ya laytanee qaddamtu lihayatee
Translation: Ó máa wí pé: “Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi.”
فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٞ ﴿25﴾فَيَوۡمَئِذٖ لَّا يُعَذِّبُ عَذَابَهُۥٓ أَحَدٞ
Transliteration: Fayawmaithin la yuAAaththibu AAathabahu ahadun
Translation: Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٞ ﴿26﴾وَلَا يُوثِقُ وَثَاقَهُۥٓ أَحَدٞ
Transliteration: Wala yoothiqu wathaqahu ahadun
Translation: Ẹnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
يَـٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفۡسُ ٱلۡمُطۡمَئِنَّةُ ﴿27﴾يَـٰٓأَيَّتُهَا ٱلنَّفۡسُ ٱلۡمُطۡمَئِنَّةُ
Transliteration: Ya ayyatuha alnnafsu almutmainnatu
Translation: Ìwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
ٱرۡجِعِيٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةٗ مَّرۡضِيَّةٗ ﴿28﴾ٱرۡجِعِيٓ إِلَىٰ رَبِّكِ رَاضِيَةٗ مَّرۡضِيَّةٗ
Transliteration: IrjiAAee ila rabbiki radiyatan mardiyyatan
Translation: padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
فَٱدۡخُلِي فِي عِبَٰدِي ﴿29﴾فَٱدۡخُلِي فِي عِبَٰدِي
Transliteration: Faodkhulee fee AAibadee
Translation: Nítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
وَٱدۡخُلِي جَنَّتِي ﴿30﴾وَٱدۡخُلِي جَنَّتِي
Transliteration: Waodkhulee jannatee
Translation: Wọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download