quranm◉

Surah Ash-Shams transliteration

◉ Súrá · ∞

91:1

وَٱلشَّمۡسِ وَضُحَىٰهَا ﴿1﴾

Transliteration: Waalshshamsi waduhaha

Translation: Allāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.

91:2

وَٱلۡقَمَرِ إِذَا تَلَىٰهَا ﴿2﴾

Transliteration: Waalqamari itha talaha

Translation: Ó tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.

91:3

وَٱلنَّهَارِ إِذَا جَلَّىٰهَا ﴿3﴾

Transliteration: Waalnnahari itha jallaha

Translation: Ó tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.

91:4

وَٱلَّيۡلِ إِذَا يَغۡشَىٰهَا ﴿4﴾

Transliteration: Waallayli itha yaghshaha

Translation: Ó tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.

91:5

وَٱلسَّمَآءِ وَمَا بَنَىٰهَا ﴿5﴾

Transliteration: Waalssamai wama banaha

Translation: Ó tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́nbúra?

91:6

وَٱلۡأَرۡضِ وَمَا طَحَىٰهَا ﴿6﴾

Transliteration: Waalardi wama tahaha

Translation: Ó tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.

91:7

وَنَفۡسٖ وَمَا سَوَّىٰهَا ﴿7﴾

Transliteration: Wanafsin wama sawwaha

Translation: Ó tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.

91:8

فَأَلۡهَمَهَا فُجُورَهَا وَتَقۡوَىٰهَا ﴿8﴾

Transliteration: Faalhamaha fujooraha wataqwaha

Translation: Ó sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.

91:9

قَدۡ أَفۡلَحَ مَن زَكَّىٰهَا ﴿9﴾

Transliteration: Qad aflaha man zakkaha

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.1

91:10

وَقَدۡ خَابَ مَن دَسَّىٰهَا ﴿10﴾

Transliteration: Waqad khaba man dassaha

Translation: Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.

91:11

كَذَّبَتۡ ثَمُودُ بِطَغۡوَىٰهَآ ﴿11﴾

Transliteration: Kaththabat thamoodu bitaghwaha

Translation: Ìjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.

91:12

إِذِ ٱنۢبَعَثَ أَشۡقَىٰهَا ﴿12﴾

Transliteration: Ithi inbaAAatha ashqaha

Translation: (Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).

91:13

فَقَالَ لَهُمۡ رَسُولُ ٱللَّهِ نَاقَةَ ٱللَّهِ وَسُقۡيَٰهَا ﴿13﴾

Transliteration: Faqala lahum rasoolu Allahi naqata Allahi wasuqyaha

Translation: Nígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”

91:14

فَكَذَّبُوهُ فَعَقَرُوهَا فَدَمۡدَمَ عَلَيۡهِمۡ رَبُّهُم بِذَنۢبِهِمۡ فَسَوَّىٰهَا ﴿14﴾

Transliteration: Fakaththaboohu faAAaqarooha fadamdama AAalayhim rabbuhum bithanbihim fasawwaha

Translation: Wọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.

91:15

وَلَا يَخَافُ عُقۡبَٰهَا ﴿15﴾

Transliteration: Wala yakhafu AAuqbaha

Translation: (Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download