quranm◉

Surah Al-'Adiyat transliteration

◉ Súrá · ∞

100:1

وَٱلۡعَٰدِيَٰتِ ضَبۡحٗا ﴿1﴾

Transliteration: WaalAAadiyati dabhan

Translation: Allāhu fi àwọn ẹṣin tó ń sáré tó ń mí hẹlẹhẹlẹ ní ojú-ogun búra.

100:2

فَٱلۡمُورِيَٰتِ قَدۡحٗا ﴿2﴾

Transliteration: Faalmooriyati qadhan

Translation: Ó tún fi àwọn ẹṣin tí pátákò ẹsẹ̀ wọn ń ṣáná (níbi eré sísá) búra.

100:3

فَٱلۡمُغِيرَٰتِ صُبۡحٗا ﴿3﴾

Transliteration: Faalmugheerati subhan

Translation: Ó tún fi àwọn ẹṣin tó ń kọlu ọ̀tá ẹ̀sìn ní òwúrọ̀ kùtùkùtù búra.

100:4

فَأَثَرۡنَ بِهِۦ نَقۡعٗا ﴿4﴾

Transliteration: Faatharna bihi naqAAan

Translation: Wọ́n sì fi (pátákò ẹsẹ̀ wọn) tu eruku (ilẹ̀ ọ̀tá) sókè.

100:5

فَوَسَطۡنَ بِهِۦ جَمۡعًا ﴿5﴾

Transliteration: Fawasatna bihi jamAAan

Translation: Wọ́n tún bẹ́ gìjà pẹ̀lú eruku ẹsẹ̀ wọn sáààrin àkójọ ọ̀tá.

100:6

إِنَّ ٱلۡإِنسَٰنَ لِرَبِّهِۦ لَكَنُودٞ ﴿6﴾

Transliteration: Inna alinsana lirabbihi lakanoodun

Translation: Dájúdájú ènìyàn ni aláìmoore sí Olúwa rẹ̀.

100:7

وَإِنَّهُۥ عَلَىٰ ذَٰلِكَ لَشَهِيدٞ ﴿7﴾

Transliteration: Wainnahu AAala thalika lashaheedun

Translation: Dájúdájú Allāhu sì ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí lórí ìyẹn.

100:8

وَإِنَّهُۥ لِحُبِّ ٱلۡخَيۡرِ لَشَدِيدٌ ﴿8﴾

Transliteration: Wainnahu lihubbi alkhayri lashadeedun

Translation: Àti pé dájúdájú ènìyàn le gan-an níbi ìfẹ́ oore ayé.

100:9

أَفَلَا يَعۡلَمُ إِذَا بُعۡثِرَ مَا فِي ٱلۡقُبُورِ ﴿9﴾

Transliteration: Afala yaAAlamu itha buAAthira ma fee alquboori

Translation: Ṣé kò mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bá tú ohun tó wà nínú sàréè jáde (fún àjíǹde),

100:10

وَحُصِّلَ مَا فِي ٱلصُّدُورِ ﴿10﴾

Transliteration: Wahussila ma fee alssudoori

Translation: tí wọ́n sì tú ohun tó wà nínú igbá-àyà ẹ̀dá síta pátápátá,

100:11

إِنَّ رَبَّهُم بِهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّخَبِيرُۢ ﴿11﴾

Transliteration: Inna rabbahum bihim yawmaithin lakhabeerun

Translation: dájúdájú Olúwa wọn ni Alámọ̀tán nípa wọn ní Ọjọ́ yẹn?

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download