وَٱلنَّـٰزِعَٰتِ غَرۡقٗا ﴿1﴾وَٱلنَّـٰزِعَٰتِ غَرۡقٗا
Transliteration: WaalnnaziAAati gharqan
Translation: Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
وَٱلنَّـٰزِعَٰتِ غَرۡقٗا ﴿1﴾وَٱلنَّـٰزِعَٰتِ غَرۡقٗا
Transliteration: WaalnnaziAAati gharqan
Translation: Allāhu fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà èle gba ẹ̀mí àwọn aláìgbàgbọ́ búra.
وَٱلنَّـٰشِطَٰتِ نَشۡطٗا ﴿2﴾وَٱلنَّـٰشِطَٰتِ نَشۡطٗا
Transliteration: Waalnnashitati nashtan
Translation: Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń fi ọ̀nà ẹ̀rọ̀ gba ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo búra.
وَٱلسَّـٰبِحَٰتِ سَبۡحٗا ﴿3﴾وَٱلسَّـٰبِحَٰتِ سَبۡحٗا
Transliteration: Waalssabihati sabhan
Translation: Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń yára gágá níbi àṣẹ Rẹ̀ búra.
فَٱلسَّـٰبِقَٰتِ سَبۡقٗا ﴿4﴾فَٱلسَّـٰبِقَٰتِ سَبۡقٗا
Transliteration: Faalssabiqati sabqan
Translation: Ó tún fi àwọn mọlāika tó máa ṣíwájú ẹ̀mí àwọn onígbàgbọ́ òdodo wọnú Ọgbà Ìdẹ̀ra tààrà búra.
فَٱلۡمُدَبِّرَٰتِ أَمۡرٗا ﴿5﴾فَٱلۡمُدَبِّرَٰتِ أَمۡرٗا
Transliteration: Faalmudabbirati amran
Translation: Ó tún fi àwọn mọlāika tó ń ṣètò nínú sánmọ̀ àti ilé ayé pẹ̀lú àṣẹ Allāhu búra.
يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ ﴿6﴾يَوۡمَ تَرۡجُفُ ٱلرَّاجِفَةُ
Transliteration: Yawma tarjufu alrrajifatu
Translation: Ní ọjọ́ tí ìmìtìtì máa mi gbogbo ayé tìtì.1
تَتۡبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ ﴿7﴾تَتۡبَعُهَا ٱلرَّادِفَةُ
Transliteration: TatbaAAuha alrradifatu
Translation: Ohun tí ó máa tẹ̀lé e máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e.1
قُلُوبٞ يَوۡمَئِذٖ وَاجِفَةٌ ﴿8﴾قُلُوبٞ يَوۡمَئِذٖ وَاجِفَةٌ
Transliteration: Quloobun yawmaithin wajifatun
Translation: Àwọn ọkàn yóò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní ọjọ́ yẹn.
أَبۡصَٰرُهَا خَٰشِعَةٞ ﴿9﴾أَبۡصَٰرُهَا خَٰشِعَةٞ
Transliteration: Absaruha khashiAAatun
Translation: Ojú wọn yó sì wálẹ̀ ní ti ìyẹpẹrẹ.
يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرۡدُودُونَ فِي ٱلۡحَافِرَةِ ﴿10﴾يَقُولُونَ أَءِنَّا لَمَرۡدُودُونَ فِي ٱلۡحَافِرَةِ
Transliteration: Yaqooloona ainna lamardoodoona fee alhafirati
Translation: Wọn yóò wí pé: “Ṣé Wọ́n tún máa dá wa padà sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀mí (bíi tayé ni)?
أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمٗا نَّخِرَةٗ ﴿11﴾أَءِذَا كُنَّا عِظَٰمٗا نَّخِرَةٗ
Transliteration: Aitha kunna AAithaman nakhiratan
Translation: Ṣé nígbà tí a ti di eegun tó kẹfun tán?”
قَالُواْ تِلۡكَ إِذٗا كَرَّةٌ خَاسِرَةٞ ﴿12﴾قَالُواْ تِلۡكَ إِذٗا كَرَّةٌ خَاسِرَةٞ
Transliteration: Qaloo tilka ithan karratun khasiratun
Translation: Wọ́n wí pé: “Ìdápadà òfò nìyẹn nígbà náà (fún ẹni tó pè é ní irọ́.)”
فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ ﴿13﴾فَإِنَّمَا هِيَ زَجۡرَةٞ وَٰحِدَةٞ
Transliteration: Fainnama hiya zajratun wahidatun
Translation: Nítorí náà, igbe ẹyọ kan sì ni.
فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ ﴿14﴾فَإِذَا هُم بِٱلسَّاهِرَةِ
Transliteration: Faitha hum bialssahirati
Translation: Nígbà náà ni wọn yóò bára wọn lórí ilẹ̀ gban̄sasa.
هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ ﴿15﴾هَلۡ أَتَىٰكَ حَدِيثُ مُوسَىٰٓ
Transliteration: Hal ataka hadeethu moosa
Translation: Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ (Ànábì) Mūsā ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
إِذۡ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوًى ﴿16﴾إِذۡ نَادَىٰهُ رَبُّهُۥ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوًى
Transliteration: Ith nadahu rabbuhu bialwadi almuqaddasi tuwan
Translation: (Rántí) nígbà tí Olúwa rẹ̀ pè é ní àfonúfojì mímọ́, Tuwā.
ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ ﴿17﴾ٱذۡهَبۡ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ إِنَّهُۥ طَغَىٰ
Transliteration: Ithhab ila firAAawna innahu tagha
Translation: Lọ bá Fir‘aon, dájúdájú ó ti tayọ ẹnu-ààlà.
فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ ﴿18﴾فَقُلۡ هَل لَّكَ إِلَىٰٓ أَن تَزَكَّىٰ
Transliteration: Faqul hal laka ila an tazakka
Translation: Kí o sì sọ pé: “Ǹjẹ o máa ṣàfọ̀mọ́ ara rẹ (kúrò nínú àìgbàgbọ́) bí?
وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ ﴿19﴾وَأَهۡدِيَكَ إِلَىٰ رَبِّكَ فَتَخۡشَىٰ
Transliteration: Waahdiyaka ila rabbika fatakhsha
Translation: Kí èmi sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́ dé ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ, kí o sì páyà (Rẹ̀).”
فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ ﴿20﴾فَأَرَىٰهُ ٱلۡأٓيَةَ ٱلۡكُبۡرَىٰ
Transliteration: Faarahu alayata alkubra
Translation: Ó sì fi àmì tó tóbi hàn án.
فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ ﴿21﴾فَكَذَّبَ وَعَصَىٰ
Transliteration: Fakaththaba waAAasa
Translation: (Àmọ́) ó pè é ní òpùrọ́. Ó sì yapa (rẹ̀).
ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ ﴿22﴾ثُمَّ أَدۡبَرَ يَسۡعَىٰ
Transliteration: Thumma adbara yasAAa
Translation: Lẹ́yìn náà, ó kẹ̀yìn sí i. Ó sì ń ṣiṣẹ́ (takò ó).
فَحَشَرَ فَنَادَىٰ ﴿23﴾فَحَشَرَ فَنَادَىٰ
Transliteration: Fahashara fanada
Translation: Ó kó (àwọn ènìyàn) jọ, ó sì ké gbàjarì.
فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ ﴿24﴾فَقَالَ أَنَا۠ رَبُّكُمُ ٱلۡأَعۡلَىٰ
Transliteration: Faqala ana rabbukumu alaAAla
Translation: Ó sì wí pé: “Èmi ni olúwa yín, ẹni gíga jùlọ.”
فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ ﴿25﴾فَأَخَذَهُ ٱللَّهُ نَكَالَ ٱلۡأٓخِرَةِ وَٱلۡأُولَىٰٓ
Transliteration: Faakhathahu Allahu nakala alakhirati waaloola
Translation: Nítorí náà, Allāhu gbá a mú pẹ̀lú ìyà ìkẹ́yìn àti àkọ́kọ́ (nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ ìkẹ́yìn yìí àti àkọ́kọ́).1
إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰٓ ﴿26﴾إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَعِبۡرَةٗ لِّمَن يَخۡشَىٰٓ
Transliteration: Inna fee thalika laAAibratan liman yakhsha
Translation: Dájúdájú àríwòye wà nínú ìyẹn fún ẹni tó ń páyà (Allāhu).
ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا ﴿27﴾ءَأَنتُمۡ أَشَدُّ خَلۡقًا أَمِ ٱلسَّمَآءُۚ بَنَىٰهَا
Transliteration: Aantum ashaddu khalqan ami alssamao banaha
Translation: Ṣé ẹ̀yin lẹ lágbára jùlọ ní ìṣẹ̀dá ni tàbí sánmọ̀ tí Allāhu mọ?
رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا ﴿28﴾رَفَعَ سَمۡكَهَا فَسَوَّىٰهَا
Transliteration: RafaAAa samkaha fasawwaha
Translation: Allāhu gbé àjà rẹ̀ ga sókè. Ó sì ṣe é ní pípé tó gún régé.
وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا ﴿29﴾وَأَغۡطَشَ لَيۡلَهَا وَأَخۡرَجَ ضُحَىٰهَا
Transliteration: Waaghtasha laylaha waakhraja duhaha
Translation: Ó ṣe òru rẹ̀ ní dúdú. Ó sì fa ìyálẹ̀ta rẹ̀ yọ jáde.
وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ ﴿30﴾وَٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ ذَٰلِكَ دَحَىٰهَآ
Transliteration: Waalarda baAAda thalika dahaha
Translation: Àti ilẹ̀, Ó tẹ́ ẹ pẹrẹsẹ lẹ́yìn ìyẹn.1
أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا ﴿31﴾أَخۡرَجَ مِنۡهَا مَآءَهَا وَمَرۡعَىٰهَا
Transliteration: Akhraja minha maaha wamarAAaha
Translation: Ó mú omi rẹ̀ àti irúgbìn rẹ̀ jáde láti inú rẹ̀.
وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا ﴿32﴾وَٱلۡجِبَالَ أَرۡسَىٰهَا
Transliteration: Waaljibala arsaha
Translation: Àti àwọn àpáta, Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ ṣinṣin.
مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ ﴿33﴾مَتَٰعٗا لَّكُمۡ وَلِأَنۡعَٰمِكُمۡ
Transliteration: MataAAan lakum walianAAamikum
Translation: Ìgbádùn ni fún yín àti fún àwọn ẹran-ọ̀sìn yín.
فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ ﴿34﴾فَإِذَا جَآءَتِ ٱلطَّآمَّةُ ٱلۡكُبۡرَىٰ
Transliteration: Faitha jaati alttammatu alkubra
Translation: Ṣùgbọ́n nígbà tí ìparun ńlá bá dé,
يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ ﴿35﴾يَوۡمَ يَتَذَكَّرُ ٱلۡإِنسَٰنُ مَا سَعَىٰ
Transliteration: Yawma yatathakkaru alinsanu ma saAAa
Translation: ní ọjọ́ tí ènìyàn yóò rántí ohun tó ṣe níṣẹ́.
وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ ﴿36﴾وَبُرِّزَتِ ٱلۡجَحِيمُ لِمَن يَرَىٰ
Transliteration: Waburrizati aljaheemu liman yara
Translation: Wọ́n sì máa fi Iná hàn kedere fún (gbogbo) ẹni tó ríran.
فَأَمَّا مَن طَغَىٰ ﴿37﴾فَأَمَّا مَن طَغَىٰ
Transliteration: Faamma man tagha
Translation: Nítorí náà, ní ti ẹni tó tayọ ẹnu-ààlà,
وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا ﴿38﴾وَءَاثَرَ ٱلۡحَيَوٰةَ ٱلدُّنۡيَا
Transliteration: Waathara alhayata alddunya
Translation: tí ó tún gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé,
فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ ﴿39﴾فَإِنَّ ٱلۡجَحِيمَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ
Transliteration: Fainna aljaheema hiya almawa
Translation: dájúdájú iná Jẹhīm, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ ﴿40﴾وَأَمَّا مَنۡ خَافَ مَقَامَ رَبِّهِۦ وَنَهَى ٱلنَّفۡسَ عَنِ ٱلۡهَوَىٰ
Transliteration: Waama man khafa maqama rabbihi wanaha alnnafsa AAani alhawa
Translation: Ní ti ẹni tí ó páyà ìdúró níwájú Olúwa rẹ̀, tí ó tún kọ ìfẹ́-inú fún ẹ̀mí (ara rẹ̀),
فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ ﴿41﴾فَإِنَّ ٱلۡجَنَّةَ هِيَ ٱلۡمَأۡوَىٰ
Transliteration: Fainna aljannata hiya almawa
Translation: dájúdájú Ọgbà Ìdẹ̀ra, òhun ni ibùgbé (rẹ̀).
يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا ﴿42﴾يَسۡـَٔلُونَكَ عَنِ ٱلسَّاعَةِ أَيَّانَ مُرۡسَىٰهَا
Transliteration: Yasaloonaka AAani alssaAAati ayyana mursaha
Translation: Wọ́n ń bi ọ́ léèrè nípa Àkókò náà pé: “Ìgbà wo l’ó máa ṣẹlẹ̀?”
فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ ﴿43﴾فِيمَ أَنتَ مِن ذِكۡرَىٰهَآ
Transliteration: Feema anta min thikraha
Translation: Níbo ni ìwọ wà sí ìmọ̀ rẹ̀ ná?1
إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ ﴿44﴾إِلَىٰ رَبِّكَ مُنتَهَىٰهَآ
Transliteration: Ila rabbika muntahaha
Translation: Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ni òpin ìmọ̀ nípa rẹ̀ wà.
إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا ﴿45﴾إِنَّمَآ أَنتَ مُنذِرُ مَن يَخۡشَىٰهَا
Transliteration: Innama anta munthiru man yakhshaha
Translation: Ìwọ kúkú ni olùkìlọ̀ fún ẹni tó ń páyà rẹ̀.
كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا ﴿46﴾كَأَنَّهُمۡ يَوۡمَ يَرَوۡنَهَا لَمۡ يَلۡبَثُوٓاْ إِلَّا عَشِيَّةً أَوۡ ضُحَىٰهَا
Transliteration: Kaannahum yawma yarawnaha lam yalbathoo illa AAashiyyatan aw duhaha
Translation: Ní ọjọ́ tí wọ́n máa rí i, wọn máa dà bí ẹni pé wọn kò gbé ilé ayé tayọ ìrọ̀lẹ́ tàbí ìyálẹ̀ta (ọjọ́) kan.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download