إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ﴿1﴾إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ
Transliteration: Itha alssamao infatarat
Translation: Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1
إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ ﴿1﴾إِذَا ٱلسَّمَآءُ ٱنفَطَرَتۡ
Transliteration: Itha alssamao infatarat
Translation: Nígbà tí sánmọ̀ bá fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,1
وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ ﴿2﴾وَإِذَا ٱلۡكَوَاكِبُ ٱنتَثَرَتۡ
Transliteration: Waitha alkawakibu intatharat
Translation: àti nígbà tí àwọn ìràwọ̀ bá já bọ́ káàkiri,
وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ ﴿3﴾وَإِذَا ٱلۡبِحَارُ فُجِّرَتۡ
Transliteration: Waitha albiharu fujjirat
Translation: àti nígbà tí àwọn ibúdò bá ṣàn jára wọn,
وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ ﴿4﴾وَإِذَا ٱلۡقُبُورُ بُعۡثِرَتۡ
Transliteration: Waitha alqubooru buAAthirat
Translation: àti (nígbà tí A bá ta ilẹ̀ sókè), tí A sì mú àwọn òkú jáde (láàyè) láti inú àwọn sàréè,
عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ ﴿5﴾عَلِمَتۡ نَفۡسٞ مَّا قَدَّمَتۡ وَأَخَّرَتۡ
Transliteration: AAalimat nafsun ma qaddamat waakhkharat
Translation: (nígbà náà ni) ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan yóò mọ ohun tí ó tì síwájú (nínú iṣẹ́ rẹ̀) àti ohun tí ó fi sẹ́yìn (nínú orípa iṣẹ́ rẹ̀).
يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ ﴿6﴾يَـٰٓأَيُّهَا ٱلۡإِنسَٰنُ مَا غَرَّكَ بِرَبِّكَ ٱلۡكَرِيمِ
Transliteration: Ya ayyuha alinsanu ma gharraka birabbika alkareemi
Translation: Ìwọ ènìyàn, kí ni ó tàn ọ́ jẹ nípa Olúwa rẹ, Alápọ̀n-ọ́nlé,
ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ ﴿7﴾ٱلَّذِي خَلَقَكَ فَسَوَّىٰكَ فَعَدَلَكَ
Transliteration: Allathee khalaqaka fasawwaka faAAadalaka
Translation: Ẹni t’Ó ṣẹ̀dá rẹ? Ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ní pípé. Ó sì mú ọ dọ́gba jalẹ̀ léèyàn.
فِيٓ أَيِّ صُورَةٖ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ ﴿8﴾فِيٓ أَيِّ صُورَةٖ مَّا شَآءَ رَكَّبَكَ
Transliteration: Fee ayyi sooratin ma shaa rakkabaka
Translation: Ó to ẹ̀yà ara rẹ papọ̀ sínú èyíkéyìí àwòrán tí Ó fẹ́.
كَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ ﴿9﴾كَلَّا بَلۡ تُكَذِّبُونَ بِٱلدِّينِ
Transliteration: Kalla bal tukaththiboona bialddeeni
Translation: Rárá! Bí kò ṣe pé ẹ̀ ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ ﴿10﴾وَإِنَّ عَلَيۡكُمۡ لَحَٰفِظِينَ
Transliteration: Wainna AAalaykum lahafitheena
Translation: Dájúdájú àwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà ní ọ̀dọ̀ yín.
كِرَامٗا كَٰتِبِينَ ﴿11﴾كِرَامٗا كَٰتِبِينَ
Transliteration: Kiraman katibeena
Translation: (Wọ́n jẹ́) alápọ̀n-ọ́nlé, òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá.
يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ ﴿12﴾يَعۡلَمُونَ مَا تَفۡعَلُونَ
Transliteration: YaAAlamoona ma tafAAaloona
Translation: Wọ́n mọ ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٖ ﴿13﴾إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٖ
Transliteration: Inna alabrara lafee naAAeemin
Translation: Dájúdájú àwọn ẹni rere yóò kúkú wà nínú ìgbádùn.
وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٖ ﴿14﴾وَإِنَّ ٱلۡفُجَّارَ لَفِي جَحِيمٖ
Transliteration: Wainna alfujjara lafee jaheemin
Translation: Dájúdájú àwọn ẹni ibi yó sì kúkú wà nínú iná Jẹhīm.
يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ ﴿15﴾يَصۡلَوۡنَهَا يَوۡمَ ٱلدِّينِ
Transliteration: Yaslawnaha yawma alddeeni
Translation: Wọn yóò wọ inú rẹ̀ ní Ọjọ́ ẹ̀san.
وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ ﴿16﴾وَمَا هُمۡ عَنۡهَا بِغَآئِبِينَ
Transliteration: Wama hum AAanha bighaibeena
Translation: Wọn kò sì níí kúrò nínú rẹ̀.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ﴿17﴾وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ
Transliteration: Wama adraka ma yawmu alddeeni
Translation: Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ ﴿18﴾ثُمَّ مَآ أَدۡرَىٰكَ مَا يَوۡمُ ٱلدِّينِ
Transliteration: Thumma ma adraka ma yawmu alddeeni
Translation: Lẹ́yìn náà, kí ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Ọjọ́ ẹ̀san?
يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٞ لِّنَفۡسٖ شَيۡـٔٗاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ ﴿19﴾يَوۡمَ لَا تَمۡلِكُ نَفۡسٞ لِّنَفۡسٖ شَيۡـٔٗاۖ وَٱلۡأَمۡرُ يَوۡمَئِذٖ لِّلَّهِ
Transliteration: Yawma la tamliku nafsun linafsin shayan waalamru yawmaithin lillahi
Translation: (Ọjọ́ ẹ̀san ni) ọjọ́ tí ẹ̀mí kan kò níí kápá kiní kan fún ẹ̀mí kan. Gbogbo àṣẹ ọjọ́ yẹn sì ń jẹ́ ti Allāhu.
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download