quranm◉

Surah At-Tariq transliteration

◉ Súrá · ∞

86:1

وَٱلسَّمَآءِ وَٱلطَّارِقِ ﴿1﴾

Transliteration: Waalssamai waalttariqi

Translation: (Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.

86:2

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلطَّارِقُ ﴿2﴾

Transliteration: Wama adraka ma alttariqu

Translation: Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?

86:3

ٱلنَّجۡمُ ٱلثَّاقِبُ ﴿3﴾

Transliteration: Alnnajmu alththaqibu

Translation: Ìràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).

86:4

إِن كُلُّ نَفۡسٖ لَّمَّا عَلَيۡهَا حَافِظٞ ﴿4﴾

Transliteration: In kullu nafsin lamma AAalayha hafithun

Translation: Kò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).

86:5

فَلۡيَنظُرِ ٱلۡإِنسَٰنُ مِمَّ خُلِقَ ﴿5﴾

Transliteration: Falyanthuri alinsanu mimma khuliqa

Translation: Nítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.

86:6

خُلِقَ مِن مَّآءٖ دَافِقٖ ﴿6﴾

Transliteration: Khuliqa min main dafiqin

Translation: Wọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.

86:7

يَخۡرُجُ مِنۢ بَيۡنِ ٱلصُّلۡبِ وَٱلتَّرَآئِبِ ﴿7﴾

Transliteration: Yakhruju min bayni alssulbi waalttaraibi

Translation: Ó ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.

86:8

إِنَّهُۥ عَلَىٰ رَجۡعِهِۦ لَقَادِرٞ ﴿8﴾

Transliteration: Innahu AAala rajAAihi laqadirun

Translation: Dájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀

86:9

يَوۡمَ تُبۡلَى ٱلسَّرَآئِرُ ﴿9﴾

Transliteration: Yawma tubla alssarairu

Translation: ní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.

86:10

فَمَا لَهُۥ مِن قُوَّةٖ وَلَا نَاصِرٖ ﴿10﴾

Transliteration: Fama lahu min quwwatin wala nasirin

Translation: Nígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.

86:11

وَٱلسَّمَآءِ ذَاتِ ٱلرَّجۡعِ ﴿11﴾

Transliteration: Waalssamai thati alrrajAAi

Translation: Allāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.

86:12

وَٱلۡأَرۡضِ ذَاتِ ٱلصَّدۡعِ ﴿12﴾

Transliteration: Waalardi thati alssadAAi

Translation: Ó tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.

86:13

إِنَّهُۥ لَقَوۡلٞ فَصۡلٞ ﴿13﴾

Transliteration: Innahu laqawlun faslun

Translation: Dájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).

86:14

وَمَا هُوَ بِٱلۡهَزۡلِ ﴿14﴾

Transliteration: Wama huwa bialhazli

Translation: Kì í sì ṣe àwàdà.

86:15

إِنَّهُمۡ يَكِيدُونَ كَيۡدٗا ﴿15﴾

Transliteration: Innahum yakeedoona kaydan

Translation: Dájúdájú wọ́n ń déte gan-an.

86:16

وَأَكِيدُ كَيۡدٗا ﴿16﴾

Transliteration: Waakeedu kaydan

Translation: Èmi náà sì ń déte gan-an.1

86:17

فَمَهِّلِ ٱلۡكَٰفِرِينَ أَمۡهِلۡهُمۡ رُوَيۡدَۢا ﴿17﴾

Transliteration: Famahhili alkafireena amhilhum ruwaydan

Translation: Nítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download