quranm◉

Surah Al-Balad transliteration

◉ Súrá · ∞

90:1

لَآ أُقۡسِمُ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ﴿1﴾

Transliteration: La oqsimu bihatha albaladi

Translation: Èmi (Allāhu) ń fi ìlú yìíbúra.

90:2

وَأَنتَ حِلُّۢ بِهَٰذَا ٱلۡبَلَدِ ﴿2﴾

Transliteration: Waanta hillun bihatha albaladi

Translation: Ìwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).1

90:3

وَوَالِدٖ وَمَا وَلَدَ ﴿3﴾

Transliteration: Wawalidin wama walada

Translation: Èmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.

90:4

لَقَدۡ خَلَقۡنَا ٱلۡإِنسَٰنَ فِي كَبَدٍ ﴿4﴾

Transliteration: Laqad khalaqna alinsana fee kabadin

Translation: Dájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.

90:5

أَيَحۡسَبُ أَن لَّن يَقۡدِرَ عَلَيۡهِ أَحَدٞ ﴿5﴾

Transliteration: Ayahsabu an lan yaqdira AAalayhi ahadun

Translation: Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?

90:6

يَقُولُ أَهۡلَكۡتُ مَالٗا لُّبَدًا ﴿6﴾

Transliteration: Yaqoolu ahlaktu malan lubadan

Translation: Ó (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”

90:7

أَيَحۡسَبُ أَن لَّمۡ يَرَهُۥٓ أَحَدٌ ﴿7﴾

Transliteration: Ayahsabu an lam yarahu ahadun

Translation: Ṣé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?

90:8

أَلَمۡ نَجۡعَل لَّهُۥ عَيۡنَيۡنِ ﴿8﴾

Transliteration: Alam najAAal lahu AAaynayni

Translation: Ṣé A kò ṣe ojú méjì fún un?

90:9

وَلِسَانٗا وَشَفَتَيۡنِ ﴿9﴾

Transliteration: Walisanan washafatayni

Translation: Àti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?

90:10

وَهَدَيۡنَٰهُ ٱلنَّجۡدَيۡنِ ﴿10﴾

Transliteration: Wahadaynahu alnnajdayni

Translation: A sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.

90:11

فَلَا ٱقۡتَحَمَ ٱلۡعَقَبَةَ ﴿11﴾

Transliteration: Fala iqtahama alAAaqabata

Translation: Kò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!

90:12

وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا ٱلۡعَقَبَةُ ﴿12﴾

Transliteration: Wama adraka ma alAAaqabatu

Translation: Kí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?

90:13

فَكُّ رَقَبَةٍ ﴿13﴾

Transliteration: Fakku raqabatin

Translation: (Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.

90:14

أَوۡ إِطۡعَٰمٞ فِي يَوۡمٖ ذِي مَسۡغَبَةٖ ﴿14﴾

Transliteration: Aw itAAamun fee yawmin thee masghabatin

Translation: Tàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.

90:15

يَتِيمٗا ذَا مَقۡرَبَةٍ ﴿15﴾

Transliteration: Yateeman tha maqrabatin

Translation: (Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,

90:16

أَوۡ مِسۡكِينٗا ذَا مَتۡرَبَةٖ ﴿16﴾

Transliteration: Aw miskeenan tha matrabatin

Translation: tàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).

90:17

ثُمَّ كَانَ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلصَّبۡرِ وَتَوَاصَوۡاْ بِٱلۡمَرۡحَمَةِ ﴿17﴾

Transliteration: Thumma kana mina allatheena amanoo watawasaw bialssabri watawasaw bialmarhamati

Translation: Lẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.

90:18

أُوْلَـٰٓئِكَ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَيۡمَنَةِ ﴿18﴾

Transliteration: Olaika ashabu almaymanati

Translation: Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.

90:19

وَٱلَّذِينَ كَفَرُواْ بِـَٔايَٰتِنَا هُمۡ أَصۡحَٰبُ ٱلۡمَشۡـَٔمَةِ ﴿19﴾

Transliteration: Waallatheena kafaroo biayatina hum ashabu almashamati

Translation: Àwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.1

90:20

عَلَيۡهِمۡ نَارٞ مُّؤۡصَدَةُۢ ﴿20﴾

Transliteration: AAalayhim narun musadatun

Translation: Wọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.

Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download