وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ ﴿1﴾وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ
Transliteration: Waylun lilmutaffifeena
Translation: Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ ﴿1﴾وَيۡلٞ لِّلۡمُطَفِّفِينَ
Transliteration: Waylun lilmutaffifeena
Translation: Ègbé ni fún àwọn olùdín-òṣùwọ̀n-kù,
ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ ﴿2﴾ٱلَّذِينَ إِذَا ٱكۡتَالُواْ عَلَى ٱلنَّاسِ يَسۡتَوۡفُونَ
Transliteration: Allatheena itha iktaloo AAala alnnasi yastawfoona
Translation: àwọn (òǹtajà) tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá wọn n̄ǹkan lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn,wọ́n á gbà á ní ẹ̀kún,
وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ ﴿3﴾وَإِذَا كَالُوهُمۡ أَو وَّزَنُوهُمۡ يُخۡسِرُونَ
Transliteration: Waitha kaloohum aw wazanoohum yukhsiroona
Translation: nígbà tí àwọn (òǹtajà náà) bá sì lo ìwọ̀n fún àwọn (òǹrajà) tàbí lo òṣùwọ̀n fún wọn, wọn yóò dín in kù.
أَلَا يَظُنُّ أُوْلَـٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ ﴿4﴾أَلَا يَظُنُّ أُوْلَـٰٓئِكَ أَنَّهُم مَّبۡعُوثُونَ
Transliteration: Ala yathunnu olaika annahum mabAAoothoona
Translation: Ṣé àwọn wọ̀nyẹn kò mọ̀ dájú pé dájúdájú A máa gbé wọn dìde
لِيَوۡمٍ عَظِيمٖ ﴿5﴾لِيَوۡمٍ عَظِيمٖ
Transliteration: Liyawmin AAatheemin
Translation: ní Ọjọ́ ńlá kan?
يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ ﴿6﴾يَوۡمَ يَقُومُ ٱلنَّاسُ لِرَبِّ ٱلۡعَٰلَمِينَ
Transliteration: Yawma yaqoomu alnnasu lirabbi alAAalameena
Translation: Ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn yóò dìde dúró fún Olúwa gbogbo ẹ̀dá.
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٖ ﴿7﴾كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡفُجَّارِ لَفِي سِجِّينٖ
Transliteration: Kalla inna kitaba alfujjari lafee sijjeenin
Translation: Ní ti òdodo dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú (tó ń dín òṣùwọ̀n kù) kúkú máa wà nínú Sijjīn.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٞ ﴿8﴾وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا سِجِّينٞ
Transliteration: Wama adraka ma sijjeenun
Translation: Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Sijjīn!
كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ ﴿9﴾كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ
Transliteration: Kitabun marqoomun
Translation: Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ aburú ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sínú ilẹ̀ keje ni Sijjīn).
وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ ﴿10﴾وَيۡلٞ يَوۡمَئِذٖ لِّلۡمُكَذِّبِينَ
Transliteration: Waylun yawmaithin lilmukaththibeena
Translation: Ní ọjọ́ yẹn, ègbé ni fún àwọn olùpe-òdodo- nírọ́,
ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ ﴿11﴾ٱلَّذِينَ يُكَذِّبُونَ بِيَوۡمِ ٱلدِّينِ
Transliteration: Allatheena yukaththiboona biyawmi alddeeni
Translation: àwọn tó ń pe Ọjọ́ ẹ̀san ní irọ́.
وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ ﴿12﴾وَمَا يُكَذِّبُ بِهِۦٓ إِلَّا كُلُّ مُعۡتَدٍ أَثِيمٍ
Transliteration: Wama yukaththibu bihi illa kullu muAAtadin atheemin
Translation: Kò sì sí ẹni tó ń pè é ní irọ́ àyàfi gbogbo alákọyọ, ẹlẹ́ṣẹ̀.
إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ ﴿13﴾إِذَا تُتۡلَىٰ عَلَيۡهِ ءَايَٰتُنَا قَالَ أَسَٰطِيرُ ٱلۡأَوَّلِينَ
Transliteration: Itha tutla AAalayhi ayatuna qala asateeru alawwaleena
Translation: Nígbà tí wọ́n bá ń ké àwọn āyah Wa fún un, ó máa wí pé: “Àwọn àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́ (nìwọ̀nyí).”
كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ ﴿14﴾كَلَّاۖ بَلۡۜ رَانَ عَلَىٰ قُلُوبِهِم مَّا كَانُواْ يَكۡسِبُونَ
Transliteration: Kalla bal rana AAala quloobihim ma kanoo yaksiboona
Translation: Rárá (al-Ƙur’ān kì í ṣe àkọsílẹ̀ àlọ́ àwọn ẹni àkọ́kọ́) bí kò ṣe pé ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ aburú l’ó jọba lórí ọkàn wọn.
كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّمَحۡجُوبُونَ ﴿15﴾كَلَّآ إِنَّهُمۡ عَن رَّبِّهِمۡ يَوۡمَئِذٖ لَّمَحۡجُوبُونَ
Transliteration: Kalla innahum AAan rabbihim yawmaithin lamahjooboona
Translation: Rárá (kò rí bí wọ́n ṣe rò ó sí sẹ́), dájúdájú wọn yóò wà nínú gàgá, wọn kò sì níí rí Olúwa wọn ní ọjọ́ yẹn.
ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ ﴿16﴾ثُمَّ إِنَّهُمۡ لَصَالُواْ ٱلۡجَحِيمِ
Transliteration: Thumma innahum lasaloo aljaheemi
Translation: Lẹ́yìn náà, dájúdájú wọn yóò wọ inú iná Jẹhīm.
ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ ﴿17﴾ثُمَّ يُقَالُ هَٰذَا ٱلَّذِي كُنتُم بِهِۦ تُكَذِّبُونَ
Transliteration: Thumma yuqalu hatha allathee kuntum bihi tukaththiboona
Translation: Lẹ́yìn náà, wọ́n máa sọ (fún wọn) pe: “Èyí ni ohun tí ẹ̀ ń pè ní irọ́.”
كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ ﴿18﴾كَلَّآ إِنَّ كِتَٰبَ ٱلۡأَبۡرَارِ لَفِي عِلِّيِّينَ
Transliteration: Kalla inna kitaba alabrari lafee AAilliyyeena
Translation: Ní ti òdodo, dájúdájú ìwé iṣẹ́ àwọn ẹni rere wà nínú ‘illiyyūn.
وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ ﴿19﴾وَمَآ أَدۡرَىٰكَ مَا عِلِّيُّونَ
Transliteration: Wama adraka ma AAilliyyoona
Translation: Kí sì l’ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ‘illiyyūn!
كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ ﴿20﴾كِتَٰبٞ مَّرۡقُومٞ
Transliteration: Kitabun marqoomun
Translation: Ìwé tí wọ́n ti kọ iṣẹ́ rere ẹ̀dá sínú rẹ̀ (tí wọ́n sì fi pamọ́ sí òkè sánmọ̀ ni ‘illiyyūn).
يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ ﴿21﴾يَشۡهَدُهُ ٱلۡمُقَرَّبُونَ
Transliteration: Yashhaduhu almuqarraboona
Translation: Àwọn (mọlāika) tí wọ́n súnmọ́ Allāhu ń jẹ́rìí sí i.
إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ ﴿22﴾إِنَّ ٱلۡأَبۡرَارَ لَفِي نَعِيمٍ
Transliteration: Inna alabrara lafee naAAeemin
Translation: Dájúdájú àwọn ẹni rere máa wà nínú ìgbádùn.
عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ﴿23﴾عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Transliteration: AAala alaraiki yanthuroona
Translation: Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ ﴿24﴾تَعۡرِفُ فِي وُجُوهِهِمۡ نَضۡرَةَ ٱلنَّعِيمِ
Transliteration: TaAArifu fee wujoohihim nadrata alnnaAAeemi
Translation: Ìwọ yóò dá ìtutù ojú ìgbádùn mọ̀ nínú ojú wọn.
يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٖ مَّخۡتُومٍ ﴿25﴾يُسۡقَوۡنَ مِن رَّحِيقٖ مَّخۡتُومٍ
Transliteration: Yusqawna min raheeqin makhtoomin
Translation: Wọn yóò máa fún wọn mu nínú ọtí onídèérí.
خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٞۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ ﴿26﴾خِتَٰمُهُۥ مِسۡكٞۚ وَفِي ذَٰلِكَ فَلۡيَتَنَافَسِ ٱلۡمُتَنَٰفِسُونَ
Transliteration: Khitamuhu miskun wafee thalika falyatanafasi almutanafisoona
Translation: Àlùmísìkí ni (òórùn) ìparí rẹ̀. Kí àwọn alápàáǹtètè ṣàpáǹtètè nínú ìyẹn.
وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ ﴿27﴾وَمِزَاجُهُۥ مِن تَسۡنِيمٍ
Transliteration: Wamizajuhu min tasneemin
Translation: Tẹsnīm ni wọ́n yóò máa pòpọ̀ (mọ́ ọtí náà).
عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ ﴿28﴾عَيۡنٗا يَشۡرَبُ بِهَا ٱلۡمُقَرَّبُونَ
Transliteration: AAaynan yashrabu biha almuqarraboona
Translation: (Tẹsnīm ni) omi ìṣẹ́lẹ̀rú kan, tí àwọn olùsúnmọ́ (Allāhu) yóò máa mu.
إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ ﴿29﴾إِنَّ ٱلَّذِينَ أَجۡرَمُواْ كَانُواْ مِنَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ يَضۡحَكُونَ
Transliteration: Inna allatheena ajramoo kanoo mina allatheena amanoo yadhakoona
Translation: Dájúdájú àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, wọ́n máa ń fi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo rẹ́rìn-ín.
وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ ﴿30﴾وَإِذَا مَرُّواْ بِهِمۡ يَتَغَامَزُونَ
Transliteration: Waitha marroo bihim yataghamazoona
Translation: Nígbà tí wọ́n bá gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá, (àwọn olùdẹ́ṣẹ̀) yóò máa ṣẹ́jú síra wọn ní ti yẹ̀yẹ́.
وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ ﴿31﴾وَإِذَا ٱنقَلَبُوٓاْ إِلَىٰٓ أَهۡلِهِمُ ٱنقَلَبُواْ فَكِهِينَ
Transliteration: Waitha inqalaboo ila ahlihimu inqalaboo fakiheena
Translation: Nígbà tí wọ́n bá sì padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọn, wọ́n á padà tí wọn yóò máa ṣe fáàrí.
وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ ﴿32﴾وَإِذَا رَأَوۡهُمۡ قَالُوٓاْ إِنَّ هَـٰٓؤُلَآءِ لَضَآلُّونَ
Transliteration: Waitha raawhum qaloo inna haolai ladalloona
Translation: Àti pé nígbà tí wọ́n bá rí (àwọn onígbàgbọ́ òdodo) wọ́n á wí pé: “Dájúdájú àwọn wọ̀nyí ni olùṣìnà.”
وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ ﴿33﴾وَمَآ أُرۡسِلُواْ عَلَيۡهِمۡ حَٰفِظِينَ
Transliteration: Wama orsiloo AAalayhim hafitheena
Translation: Àwa kò sì rán wọn ní iṣẹ́ olùṣọ́ sí wọn.
فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ ﴿34﴾فَٱلۡيَوۡمَ ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ مِنَ ٱلۡكُفَّارِ يَضۡحَكُونَ
Transliteration: Faalyawma allatheena amanoo mina alkuffari yadhakoona
Translation: Nítorí náà, ní òní àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo yóò fi àwọn aláìgbàgbọ́ rẹ́rìn-ín.
عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ ﴿35﴾عَلَى ٱلۡأَرَآئِكِ يَنظُرُونَ
Transliteration: AAala alaraiki yanthuroona
Translation: Wọn yóò máa wòran lórí àwọn ibùsùn.
هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ ﴿36﴾هَلۡ ثُوِّبَ ٱلۡكُفَّارُ مَا كَانُواْ يَفۡعَلُونَ
Transliteration: Hal thuwwiba alkuffaru ma kanoo yafAAaloona
Translation: Ṣebí wọ́n ti fi ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe níṣẹ́ san wọ́n lẹ́san (báyìí)?
Transliteration source: English Transliteration by Tanzil. Used under Tanzil's non-commercial terms; see the source and latest updates at Tanzil. Tanzil translation download